Àwọn Ọjọ́ Alásọtẹ́lẹ̀ Danieli àti Ìgbàgbọ́ Wa
“Aláyọ̀ ni ẹni náà tí ó ń wà ní ìfojúsọ́nà tí ó sì dé ní àkókò ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé márùndínlógójì ọjọ́ náà!”—DANIELI 12:12, NW.
1. Èéṣe ti ọ̀pọ̀ fi kùnà láti rí ayọ̀ tòótọ́, kí sì ni a so ayọ̀ tòótọ́ pọ̀ mọ́?
OLÚKÚLÙKÙ ni ó fẹ́ láti láyọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, àwọn díẹ̀ péré ni wọ́n láyọ̀. Èéṣe? Lápákan nítorí pé ọ̀pọ̀ jùlọ ń wá ayọ̀ ní àwọn ibi tí kò tọ́. Ayọ̀ ni a ń wá nínú àwọn nǹkan bíi ẹ̀kọ́-ìwé, ọrọ̀, iṣẹ́ ìgbésí-ayé, tàbí ìlépa agbára. Ṣùgbọ́n, Jesu so ayọ̀ pọ̀ mọ́ jíjẹ́ kí àìní ẹni nípa tẹ̀mí, àánú, ìmọ́gaara ní ọkàn-àyà, àti àwọn ànímọ́ tí ó farajọ ọ́ jẹni lọ́kán, ní ibẹ̀rẹ̀ Ìwáásù rẹ̀ Lórí Òkè. (Matteu 5:3-10) Irú ayọ̀ tí Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ gidi a sì máa tọ́jọ́.
2. Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀, kí ni yóò ṣamọ̀nà sí ayọ̀ ní àkókò òpin, àwọn ìbéèrè wo ní ó sì dìde nípa èyí?
2 Fún àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró ní àkókó òpin, ayọ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun kan ní àfikún síi. Nínú ìwé Danieli, a kà pé: “Lọ, Danieli, nítorí pé a ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí a sì fi èdìdì dì wọ́n pa títí di àkókò òpin. Aláyọ̀ ni ẹni náà tí ó ń wà ní ìfojúsọ́nà tí ó sì dé ní àkókò ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé márùndínlógójì ọjọ́ náà!” (Danieli 12:9, 12, NW) Sáà àkókò wo ni àwọn 1,335 ọjọ́ wọ̀nyí kárí? Èéṣe tí àwọn wọnnì tí wọ́n gbé nínú wọn fi láyọ̀? Èyí ha ní ohunkóhun láti ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa lónìí bí? A ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí bí a bá wẹ̀yìnpadà sí àkókò náà tí Danieli kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ní kété lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ Israeli kúrò ní oko-òǹdè ní Babiloni àti ní ọdún kẹta ti Kirusi ọba Persia.—Danieli 10:1.
Ìmúpadàbọ̀sípò kan Mú Ayọ̀ Wá
3. Ìgbésẹ̀ wo nípa Ọba Kirusi ni ó mú ayọ̀ ńlá wá fún àwọn Ju olùṣòtítọ́ ní 537 B.C.E., ṣùgbọ́n àǹfààní wo ni Kirusi kò fún àwọn Ju?
3 Fún àwọn Ju, ìtúsílẹ̀ kúrò ní Babiloni jẹ́ àkókò kan fún ìhó-ayọ̀ tòótọ́. Lẹ́yìn tí àwọn Ju ti farada ìgbèkùn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́rin ọdún, Kirusi Ńlá késí wọ́n láti padà sí Jerusalemu láti tún tẹmpili Jehofa kọ́. (Esra 1:1, 2) Àwọn wọnnì tí wọ́n dáhùnpadà mú ọ̀nà wọn pọ̀n pẹ̀lú ìfojúsọ́nà gíga, wọ́n sì dé sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọ́n ní 537 B.C.E. Bí ó ti wù kí ó rí, Kirusi kò késí wọ́n láti wá mú ìjọba kan lábẹ́ ọmọ-ìran Ọba Dafidi padàbọ̀sípò.
4, 5. (a) Nígbà wo ni a bi ipò-ọba ti Dafidi ṣubú? Èéṣe? (b) Ìdánilójú wo ni Jehofa fúnni pé ipò-ọba ti Dafidi ni a óò mú padàbọ̀sípò?
4 Ìyẹn ní ìtumọ̀ pàtàkì. Ní nǹkan bíi ọ̀rúndún márùn-ún ṣáájú, Jehofa ti ṣèlérí fún Dafidi pé: “A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títíláé: a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títíláé.” (2 Samueli 7:16) Lọ́nà tí kò múniláyọ̀, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ọmọ-ìran kábíyèsí ti Dafidi jásí ọlọ̀tẹ̀, ẹbi ẹ̀jẹ̀ orílẹ̀-èdè náà sí di gíga débi pé ní 607 B.C.E., Jehofa yọ̀ọ̀da pé kí ipò-ọba Dafidi di èyí tí a bìṣubú. Yàtọ̀ sí sáà àkókò kúkúrú lábẹ́ ìdílé àwọn Maccabee, Jerusalemu wà lábẹ́ ìjọbalénilórí àwọn àjòjì láti ìgbà náà títí fi di ìgbà ìparun rẹ̀ kejì ní 70 C.E. Nípa báyìí, ní 537 B.C.E., “àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,” nínú èyí tí kì yóò sí ọmọkùnrin Dafidi kankan tí yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba, ń báa nìṣó.—Luku 21:24, NW.
5 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jehofa kò gbàgbé ìlérí rẹ̀ fún Dafidi. Nípasẹ̀ ọ̀wọ́ àwọn ìran àti àlá, ó tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Danieli ṣípayá kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́-ọ̀la ayé èyí tí yóò wà la àwọn ọ̀rúndún já láti ìgbà ìjọba lé ayé lórí nípasẹ̀ Babiloni dé àkókò náà nígbà tí ọba kan ní ìlà Dafidi yóò ṣàkóso lẹ́ẹ̀kan síi nínú ìjọba ti àwọn ènìyàn Jehofa. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí, tí a kọ sílẹ̀ nínú Danieli orí 2, 7, 8, àti 10 sí 12, mú un dá àwọn Ju olùṣòtítọ́ lójú pé, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìtẹ́ Dafidi nítòótọ́ ni “a ó sì fi ìdí . . . rẹ múlẹ̀ títíláé.” Dájúdájú, irú òtítọ́ tí a ṣípayá bẹ́ẹ̀ mú ayọ̀ wá fún àwọn Ju wọnnì tí wọ́n padà wá sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọ́n ní 537 B.C.E.!
6. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Danieli yẹ kí ó ní ìmúṣẹ ní àkókò wa?
6 Ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn olùṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bibeli fi ìdánilójú sọ pé gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Danieli látòkèdélẹ̀ tí fẹ́rẹ̀ẹ́ ní ìmúṣẹ wọn tán ṣáájú ìbí Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n ó ṣe kedere pé bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ọ̀ràn yìí rí. Ní Danieli 12:4, angẹli kan sọ fún Danieli pé: “Sé ọ̀rọ̀ náà mọ́hùn-ún, kí o sì fi èdìdì di ìwé náà, títí fi di ìgbà ìkẹyìn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò máa wádìí rẹ̀, ìmọ̀ yóò sì di púpọ̀.” Bí a bá níláti tú èdìdì tí a fi di ìwé Danieli—kí a ṣí ìtumọ̀ rẹ̀ payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́—kìkì ní àkókò òpin, ó dájú lọ́nàkọnà pé díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ gbọ́dọ̀ níí ṣe pẹ̀lú àkókò yẹn.—Wo Danieli 2:28; 8:17; 10:14.
7. (a) Nígbà wo ni àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè dópin, ìbéèrè kánjúkánjú wo ni a sì níláti dáhùn nígbà náà? (b) Àwọn wo ni kìí ṣe “ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà”?
7 Ní 1914 àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè dópin, àkókò òpin fún ayé yìí sì bẹ̀rẹ̀. Ìjọba ti Dafidi ni a mú padàbọ̀sípò, kìí ṣe ní Jerusalemu ti orí ilẹ̀-ayé, ṣùgbọ́n láìṣeérí nínú “àwọsánmà ọ̀run.” (Danieli 7:13, 14) Ní àkókò yẹn, nítorí pé àwọn “èpò” ayédèrú Ìsìn-Kristian ń gbilẹ̀, ipò Ìsìn-Kristian tòótọ́ kò ṣe kedere—ó kérétán lójú ìwòye ènìyàn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìbéèrè pàtàkì kan ni a níláti dáhùn: “Ta ni níti gidi ni ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà?” (Matteu 13:24-30; 24:45, NW) Ta ni yóò ṣojú fún Ìjọba ti Dafidi tí a mú padàbọ̀sípò lórí ilẹ̀-ayé? Kìí ṣe àwọn arákùnrin Danieli nípa ti ẹran-ara, àwọn Ju. A ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí pé wọ́n kò ní ìgbàgbọ́ wọ́n sì kọsẹ̀ lára Messia náà. (Romu 9:31-33) A kò rí ẹrú olùṣòtítọ́ náà láàárín àwọn ètò-àjọ Kristẹndọm ní ọ̀nà èyíkéyìí! Iṣẹ́ burúkú wọn fẹ̀rí hàn pé Jesu kò mọ̀ wọ́n. (Matteu 7:21-23) Nígbà náà, ta ni ó jẹ́?
8. Àwọn wo ni ẹ̀rí ti fihàn pé wọ́n jẹ́ “ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà” ní àkókò òpin? Báwo ni a ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
8 Láìsí iyèméjì kankan, ẹgbẹ́ kékeré ti àwọn ẹni-àmì-òróró arákùnrin Jesu tí a mọ̀ sí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní 1914 ṣùgbọ́n tí a ti mọ̀ yàtọ̀ láti 1931 wá gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni. (Isaiah 43:10) Àwọn nìkanṣoṣo ni wọ́n ti polongo Ìjọba náà tí a mú padàbọ̀sípò ní ìlà Dafidi. (Matteu 24:14) Àwọn nìkanṣoṣo ni wọ́n ti ń báa lọ ní ìyàsọ́tọ̀ kúrò nínú ayé tí wọ́n sì gbé orúkọ Jehofa galọ́lá. (Johannu 17:6, 14) Àwọn nìkanṣoṣo sì ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọrun ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ti ní ìmúṣẹ lé lórí. Lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ni ọ̀wọ́ àwọn sáà alásọtẹ́lẹ̀ tí a tòlẹ́sẹẹsẹ nínú Danieli orí 12 tí ó ní nínú àwọn 1,335 ọjọ́ tí yóò mú ayọ̀ wá.
Àwọn 1,260 Ọjọ́ Náà
9, 10. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó sàmì sí “àkókò kan, àti àwọn àkókò, àti ìdajì àkókò” ti Danieli 7:25, nínú àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ mìíràn wo ní a sì ti mẹ́nukan sáà àkókò tí ó bá èyí dọ́gba?
9 Ní Danieli 12:7, a kà nípa sáà àkókò alásọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ pé: “Yóò jẹ́ àkókò kan, àwọn àkókò, àti ààbọ̀ àkókò; nígbà tí yóò sì ti ṣe àṣepé ìfúnká àwọn ènìyàn mímọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ní a óò sì parí.”a Sáà àkókò yìí kan-náà ni a mẹ́nukàn nínú Ìfihàn 11:3-6, tí ó sọ pé àwọn ẹlẹ́rìí Ọlọrun yóò wàásù nínú aṣọ ọ̀fọ̀ fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ tí a ó sì pa wọ́n lẹ́yìn náà. Lẹ́ẹ̀kan síi, ní Danieli 7:25, a kà pé: “Òun ó sì máa sọ̀rọ̀ ńlá sí Ọ̀gá-Ògo, yóò sì dá àwọn ènìyàn-mímọ́ ti Ọ̀gá-Ògo lágara, yóò sì rò láti yí àkókò àti òfin padà; a ó sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ títí fi di ìgbà àkókò kan, àti àwọn àkókò, àti ìdajì àkókò.”
10 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí a sọ gbẹ̀yìn yìí, “òun” jẹ́ agbára ayé karùn-ún ní kíkà á láti orí Babiloni. Òun ni ‘ìwo náà, ìwo kékeré,’ tí a gbé ‘agbára ìjọba àti ògo àti ìjọba’ fún Ọmọkùnrin ènìyàn nígbà agbára ìṣàkóso rẹ̀. (Daniel 7:8, 14) Ìwo ìṣàpẹẹrẹ yìí, tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ Britain aláyélúwà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, gbèrú nígbà ogun àgbáyé kìn-ín-ní di agbára ayé aláwẹ́ méjì ti Gẹ̀ẹ́sì-òun-America, tí United States ń jọbalélórí nísinsìnyí. Fún àwọn àkókò, tàbí ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀, agbára yìí yóò fòòró àwọn ẹni mímọ́ yóò sì gbìyànjú láti yí àkókò àti òfin padà. Níkẹyìn, àwọn ẹni mímọ́ ni a ó fi lé e lọ́wọ́.—Wo Ìfihàn 13:5, 7 pẹ̀lú.
11, 12. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni wọ́n ṣamọ̀nà sí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn 1,260 ọjọ́ alásọtẹ́lẹ̀ náà?
11 Báwo ni gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bíbáradọ́gba wọ̀nyí ṣe ní ìmúṣẹ? Fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní, àwọn ẹni-àmì-òróró arákùnrin Jesu kìlọ̀ ní gbangba pé 1914 yóò rí ìparí àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè. Nígbà tí ogun bẹ́ sílẹ̀, ó hàn kedere pé ìkìlọ̀ náà ni a ti ṣàìfiyèsí. Satani lo “ẹranko ẹhànnà” rẹ̀, ètò-àjọ ìṣèlú ayé tí Ilẹ̀-Ọba Britain jọbalélórí nígbà náà, nínú ìsapá láti “yí àkókò àti òfin padà,” láti sún àkókò tí Ìjọba Ọlọrun yóò ṣàkóso síwájú. (Ìfihàn 13:1, 2, NW) Satani kùnà. Ìjọba Ọlọrun ni a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọ̀run, jìnnà réré sí àrọ́wọ́tó ènìyàn.—Ìfihàn 12:1-3.
12 Fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ogun náà túmọ̀sí àkókò ìdánwò kan. Láti January 1914 ni wọ́n ti ń fi Photo-Drama of Creation hàn, ìfàwòrán kan tí a gbékarí Bibeli hàn tí ó pàfiyèsí sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Danieli. Ní ìgbà ẹ̀rùn ọdún yẹn ní Ìhà-Àríwá Apá-Ìlàjì Ilẹ̀-Ayé, ogun bẹ́ sílẹ̀. Ní October, àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ náà dópin. Ní ìparí ọdún yẹn, àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró náà ń retí inúnibíni, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú òtítọ́ náà pé ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọdún tí a yàn fún 1915 ni ìbéèrè tí Jesu bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Ẹ̀yin lè mu nínú ago tí èmi ó mu?” tí a gbékarí Matteu 20:22.
13. Báwo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣe wàásù nínú aṣọ ọ̀fọ̀ nígbà 1,260 ọjọ́ náà, kí ni ó sì ṣẹlẹ̀ ní òpin àkókò yẹn?
13 Fún ìdí yìí, láti December 1914, ẹgbẹ́ kékeré àwọn ẹlẹ́rìí yìí ‘wàásù nínú aṣọ ọ̀fọ̀,’ ní fífi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ faradà bí wọ́n ṣe ń kéde àwọn ìdájọ́ Jehofa. Ohun kan tí ó dáyàfo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní 1916, ni ikú C. T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Bible and Tract Society. Bí ìrusókè ìmọ̀lára àkókò ogun ṣe ń tànkálẹ̀, wọ́n ṣalábàápàdé àwọn ìlòdìsíni tí ń ga síi. A fi àwọn kan sẹ́wọ̀n. Àwọn kọ̀ọ̀kan, bíi Frank Platt ní England àti Robert Clegg ní Canada, ni àwọn aláṣẹ oníwà-ìkà bíburú bàlùmọ̀ dálóró. Níkẹyìn, ní June 21, 1918, J. F. Rutherford, ààrẹ titun, papọ̀ pẹ̀lú àwọn olùdarí Watch Tower Bible and Tract Society, ni a dájọ́ ìjìyà ọlọ́jọ́ gbọọrọ nínú ẹ̀wọ̀n fún lórí àwọn ẹ̀sùn èké. Nípa bẹ́ẹ̀, ní òpin àkókò alásọtẹ́lẹ̀ náà, “ìwo kékeré” náà fòpin sí iṣẹ́ ìwàásù ìtagbangba tí a ṣètòjọ náà.—Danieli 7:8.
14. Báwo ni àwọn nǹkan ṣe yípadà fún àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró náà ní 1919 àti lẹ́yìnwá ìgbà náà?
14 Ìwé Ìfihàn sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e. Lẹ́yìn sáà àkókò kúkúrú ti àìṣiṣẹ́mọ́—tí a sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ti ìdùbúlẹ̀ nínú ikú ní ojú pópó—àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró náà di alààyè àti alákitiyan-iṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan síi. (Ìfihàn 11:11-13) Ní March 26, 1919, ààrẹ àti àwọn olùdarí Watch Tower Bible and Tract Society náà ni a túsílẹ̀, a sì dá wọn láre pátápátá lẹ́yìn náà kúrò nínú àwọn ẹ̀sùn èké tí a fi kàn wọ́n. Lọ́gán lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ wọn, àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró náà bẹ̀rẹ̀ síí tún ètò ṣe fún ìgbòkègbodò síwájú síi. Nípa báyìí, ní ìmúṣẹ ègbé àkọ́kọ́ ti inú Ìṣípayá, wọ́n jáde wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ti àìṣiṣẹ́mọ́ bí àwọn eéṣú tẹ̀mí tí èéfín nínípọn bá rìn, èyí tí ó jẹ́ àmì ìkìlọ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la ṣíṣókùnkùn kan fún ìsìn èké. (Ìfihàn 9:1-11) Ní ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ tí ó tẹ̀lé e, a foúnjẹ tẹ̀mí gbé wọn ró a sì múra wọn sílẹ̀ fún ohun tí ó wà níwájú. Ní 1921 wọ́n tẹ ìwé titun kan jáde, Duru Ọlọrun, tí a ṣètò láti ran àwọn ẹni titun àti àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti kọ́ nípa àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ Bibeli. (Ìfihàn 12:6, 14) Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ ní sáà mìíràn kan tí ó sàmì sí àkókò pàtàkì.
Àwọn 1,290 Ọjọ́ Náà
15. Ni ọ̀nà wo ni a lè gbà ṣírò ìbẹ̀rẹ̀ àwọn 1,290 ọjọ́ náà? Nígbà wo ni àkókò yìí dópin?
15 Angeli náà sọ fún Danieli pé: “Láti àkókò náà tí a ti mú apá-ẹ̀ka ìgbà gbogbo [“ẹbọ tí ń báa lọ títí,” àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé] náà kúrò, tí ìfisípò ohun ìsúni-fún-ìríra náà tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro sì ti wà, ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ yóò wà.” (Danieli 12:11, NW) Lábẹ́ Òfin Mose, “ẹbọ tí ń báa lọ títí náà” ni a ń sun lórí pẹpẹ nínú tẹ́ḿpìlì ní Jerusalemu. Àwọn Kristian kìí rú àwọn ẹbọ sísun, ṣùgbọ́n wọn a máa rú ẹbọ títílọ tẹ̀mí. Paulu tọ́ka sí èyí nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo, èyíinì ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.” (Heberu 13:15; fiwé Hosea 14:2.) Ẹbọ tí ń báa lọ títí yìí ni a mú kúrò ní June 1918. Nígbà náà, kí ni “ohun ìsúni-fún-ìríra” náà—apá-ẹ̀ka kejì tí a níláti wọ̀nà fún? Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tí àwọn agbára tí ó jagunmólú náà gbéga ní ìparí Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní ni.b Ó ń súni-fún-ìríra nítorí pé àwọn aṣáájú Kristẹndọm gbé e sí ipò Ìjọba Ọlọrun, ní mímú kí Ìmùlẹ̀ náà dúró gẹ́gẹ́ bí ìrètí kanṣoṣo tí ènìyàn ní fún àlàáfíà. Wọ́n dábàá Ìmùlẹ̀ náà ní January 1919. Bí a bá ka 1,290 ọjọ́ (ọdún mẹ́ta, oṣù méje) láti ìgbà náà wá, a óò parí rẹ̀ sí September 1922.
16. Ní ìparí 1,290 ọjọ́ náà, báwo ni ó ṣe hàn gbangba pé àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró náà ti múratán láti gbégbèésẹ̀?
16 Kí ni ó ṣẹlẹ̀ nígbà náà? Ó dára, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni a tùlára nísinsìnyí, wọ́n dòmìnira kúrò lọ́wọ́ Babiloni Ńlá, wọ́n sì ti múratán láti gbégbèésẹ̀. (Ìfihàn 18:4) Ní àpéjọpọ̀ kan tí a ṣe ní September 1922 ní Cedar Point, Ohio, U.S.A., wọ́n bẹ̀rẹ̀ síi fi àìbẹ̀rù polongo àwọn ìdájọ́ Ọlọrun sórí Kristẹndọm. (Ìfihàn 8:7-12) Oró-ìtani àwọn eéṣú náà bẹ̀rẹ̀ síi tọró níti gidi! Ní àfikún, ègbé kejì ti inú Ìfihàn bẹ̀rẹ̀. Ọ̀pọ̀ tìrìgàngàn àwọn Kristian agẹṣinjagun—tí ó jẹ́ kìkì àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró ní ìbẹ̀rẹ̀ tí àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá sì mú pọ̀ síi lẹ́yìn náà—bẹ́ gìjà la ilẹ̀-ayé já. (Ìfihàn 7:9; 9:13-19) Bẹ́ẹ̀ni, òpin 1,290 ọjọ́ náà mú ayọ̀ wá fún àwọn ènìyàn Ọlọrun.c Ṣùgbọ́n púpọ̀ síi ṣì wà ní ìpamọ́.
Àwọn 1,335 Ọjọ́ Náà
17. Nígbà wo ni 1,335 ọjọ́ náà bẹ̀rẹ̀ tí ó sì parí?
17 Danieli 12:12 (NW) sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni náà tí ó ń wà ní ìfojúsọ́nà tí ó sì dé ní ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé márùndínlógójì ọjọ́!” Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, àwọn 1,335 ọjọ́ wọ̀nyí, tàbí ọdún mẹ́ta, oṣù mẹ́jọ àti ààbọ̀, bẹ̀rẹ̀ ní ìparí sáà àkókò tí ó ṣáájú. Bí a bá kà á láti September 1922, èyí mú wa dé apá ìparí ìgbà ìrúwé (Ìhà-Àríwá Apá-Ìlàjì Ilẹ̀-Ayé) ti 1926. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò àwọn 1,335 ọjọ́ wọnnì?
18. Àwọn òtítọ́ wo ni ó tọ́kasí i pé lẹ́yìn lọ́hùn-ún ní 1922 ìtẹ̀síwájú ṣì wà láti ní?
18 Láìka bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ni àmì ìjẹ́pàtàkì tó sí ní 1922, ẹ̀rí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fihàn pé àwọn kan ṣì fi pẹ̀lú ìyánhànhàn wẹ̀yìnpadà sí ìgbà tí ó ti kọjá. Àwọn ìwé Studies in the Scriptures, tí C. T. Russell kọ, ṣì jẹ́ àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì. Síwájú síi, ìwé-kékeré tí ó ní ìpínkiri gbígbòòrò náà Millions Now Living Will Never Die gbé ojú-ìwòye náà kalẹ̀ pé ní 1925, àwọn ète Ọlọrun nípa mímú ilẹ̀-ayé padàbọ̀sípò Paradise àti jíjí àwọn olùṣòtítọ́ ìgbà láéláé dìde yóò bẹ̀rẹ̀ síí ní ìmúṣẹ. Ó dàbí ẹni pé ìfaradà àwọn ẹni-àmì-òróró ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn kan tí wọ́n ń bá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kẹ́gbẹ́pọ̀ kò nímọ̀lára ìsúnniṣe láti ṣàjọpín ìhìnrere náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
19, 20. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe yípadà fún àwọn ènìyàn Ọlọrun ní àwọn 1,335 ọjọ́ náà? (b) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni wọ́n sàmì sí òpin sáà àkókò oní-1,335 ọjọ́ náà, kí ni wọ́n sì fihàn nípa àwọn ènìyàn Jehofa?
19 Bí àwọn 1,335 ọjọ́ náà ti ń tẹ̀síwájú, gbogbo èyí yípadà. Láti fi okun fún àwọn ará, àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Ile-Iṣọ Na gẹ́gẹ́ bí àwùjọ tí a ń ṣe déédéé ní a ṣètò. A tẹnumọ́ iṣẹ́-ìsìn pápá. Bẹ̀rẹ̀ ní May 1923, gbogbo ènìyàn ni a késí láti nípìn-ín nínú iṣẹ́-ìsìn pápá ní ọjọ́ Tuesday àkọ́kọ́ nínú gbogbo oṣù, a sì ya àkókò sọ́tọ̀ nígbà ìpàdé ìjọ àárín ọ̀sẹ̀ láti fún wọn níṣìírí nínú iṣẹ́ yìí. Ní August 1923, ní àpéjọ kan ní Los Angeles, California, U.S.A., a fihàn pé òwé-àkàwé Jesu nípa àgùtàn àti ewúrẹ́ ní a óò múṣẹ ṣáájú Ìgbà-Ìjọba Ẹlẹ́gbẹ̀rún-Ọdún. (Matteu 25:31-40) Ọdún 1924 ṣẹlẹ́rìí ìfilọ́lẹ̀ ibùdó ilé-iṣẹ́ radio WBBR, èyí tí a lò láti gbé ìhìnrere náà sáfẹ́fẹ́. Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Ìbí Orílẹ̀-Èdè Náà” nínú ìtẹ̀jáde Ile-Iṣọ Na ti March 1, 1925 (Gẹ̀ẹ́sì), fúnni ní òye tí a túnṣe bọ̀sípò nípa Ìfihàn orí 12. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, àwọn Kristian olùṣòtítọ́ lè lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ onírọ̀ọ́kẹ̀kẹ̀ ti 1914 sí 1919 dáradára.
20 Ọdún 1925 wá sí ìparí rẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kìí ṣe nígbà náà! Láti àwọn ọdún 1870 wá, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ti ń ṣiṣẹ́sìn pẹ̀lú déètì lọ́kàn—àkọ́kọ́ 1914, lẹ́yìn náà 1925. Nísinsìnyí, wọ́n mọ̀ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́sìn fún bí Jehofa bá ṣe fẹ́ kí ó pẹ́ tó. Ìtẹ̀jáde Ile-Iṣọ Na ti January 1, 1926 (Gẹ̀ẹ́sì), gbé ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan tí ó ní àmì ìjẹ́pàtàkì náà jáde “Ta Ni Yóò Bọlá fún Jehofa?” tí ó fún ìjẹ́pàtàkì orúkọ Ọlọrun ní ìtẹnumọ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Wàyí o ní àkótán, ní May 1926 ní àpéjọpọ̀ London, England, ìgbèròpinnu kan tí ó ní àkòrí náà “Gbólóhùn Ẹ̀rí kan fún Àwọn Olùṣàkóso Ayé” ni a tẹ́wọ́gbà. Èyí pòkìkí òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọrun àti ìparun ayé Satani tí ń bọ̀ láìfọ̀rọ̀bọpobọyọ̀. Ní àpéjọpọ̀ kan-náà, ìwé oní-gbankọgbì ọ̀rọ̀ náà Deliverance ni a mú jáde, èyí tí ó di àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ tí a tẹ̀jáde láti rọ́pò ìwé Studies in the Scriptures. Iwájú ni àwọn ènìyàn Ọlọrun ń wò nísinsìnyí, kìí ṣe ẹ̀yìn. Àwọn 1,335 ọjọ́ náà wá sí ìparí.
21. Kí ni ìfaradà jálẹ̀ sáà àkókò oní-1,335 ọjọ̀ náà túmọ̀sí fún àwọn ènìyàn Ọlọrun nígba náà lọ́hùn-ún, kí sì ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa sáà àkókò yìí túmọ̀sí fún wa?
21 Àwọn kan kò múratán láti mú araawọn bá àwọn ìdàgbàsókè wọ̀nyí mu, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n lo ìfaradà láyọ̀ nítòótọ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí a ti ń bojúwẹ̀yìn wo ìmúṣẹ àwọn sáà àkókò alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí, awa pẹ̀lú láyọ̀ nítorí pé ìgbọ́kànlé wa ni a fún lókun pé ẹgbẹ́ kékeré ti àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí wọ́n gbé jálẹ àwọn àkókò wọ̀nyẹn níti tòótọ́ jẹ́ ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà. Ní ọ̀pọ̀ ọdún láti ìgbà náà wá, ètò-àjọ Jehofa ti gbòòrò lọ́nà gígadabú, ṣùgbọ́n ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà ṣì wà ní àárín gbùngbùn rẹ̀, tí wọ́n ń tọ́ ọ sọ́nà. Ó ti múnilóríyá tó, nígbà náà, láti mọ̀ pé fún àwọn ẹni-àmì-òróró àti àgùtàn mìíràn, ayọ̀ púpọ̀ síi ṣì wà ní ìpamọ́! Èyí ní a óò rí bí a tí ń gbé òmíràn nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Danieli yẹ̀wò.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò lórí bí a ṣe lè ṣírò àwọn sáà àkókò alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí, wo ìwé Our Incoming World Government—God’s Kingdom, orí 8, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Wo ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà April 1, 1986, ojú-ìwé 8 sí 18.
c Wo ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà January 1, 1991, ojú-ìwé 12, àti ìwé 1975 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú-ìwé 132.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Báwo ni a ṣe mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Danieli ni a óò múṣẹ ní àkókò wa?
◻ Èéṣe tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé pé àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró ni “ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà”?
◻ Nígbà wo ní àwọn 1,260 ọjọ́ náà bẹ̀rẹ̀ tí ó sì parí?
◻ Ìtura àti ìmúpadàbọ̀sípò wo ni àwọn 1,290 ọjọ́ náà múwá fún àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró?
◻ Èéṣe tí àwọn wọnnì tí wọ́n faradà títí di òpin 1,335 ọjọ́ náà fi láyọ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
ÀWỌN SÁÀ ÀKÓKÒ ALÁSỌTẸ́LẸ̀ TI DANIELI
1,260 ọjọ́:
December 1914 sí June 1918
1,290 ọjọ́:
January 1919 sí September 1922
1,335 ọjọ́:
September 1922 sí May 1926
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Láti 1919 wá ó ti ṣe kedere pé “ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà” ni àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Orílé-iṣẹ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní Geneva, Switzerland
[Credit Line]
Fọ́tò UN