Ẹ̀kọ́ Arannilọ́wọ́ Fún Àwọn Àkókò Lílekoko Wa
“Mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bálò yóò wà níhìn-ín. . . . Awọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀síwájú lati inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣinilọ́nà a óò sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.”—2 TIMOTEU 3:1, 13, NW.
1, 2. Èéṣe tí a fi níláti lọ́kàn-ìfẹ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí a ń tẹ̀lé?
AHA ń ràn ọ́ lọ́wọ́, tàbí a ń pa ọ lára bí? A ha ń yanjú àwọn ìṣòro rẹ, tàbí a ń mú wọn burú síi bí? Nípasẹ̀ kí ni? Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ ni. Bẹ́ẹ̀ni, ẹ̀kọ́ lè ní ipa títóbi lórí ìgbésí-ayé rẹ fún rere tàbí búburú.
2 Láìpẹ́ yìí àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n mẹ́ta wádìí ọ̀ràn yìí tí wọ́n sì gbé àbájáde ìwádìí wọn jáde nínú ìwé ìròyìn náà Journal for the Scientific Study of Religion. Lóòótọ́, wọ́n lè má wádìí ìwọ tàbí ìdílé rẹ. Síbẹ̀, ohun tí wọ́n rí fihàn pé ìsopọ̀ ṣíṣepàtó kan wà láàárín àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣeyọrísírere, tàbí ìkùnà, ní kíkojú àwọn àkókò wa tí ó nira láti bálò. Nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e, àwa yóò sọ ohun tí wọn ṣàwárí.
3, 4. Àwọn ẹ̀rí díẹ̀ wo ni ó wà pé a ń gbé ní àwọn àkókò lílekoko?
3 Bí ó tì wù kí ó rí, lákọ̀ọ́kọ́, gbé ìbéèrè yìí yẹ̀wò: Ìwọ ha gbà pé àwa ń gbé ní àwọn àkókò tí ó nira láti bálò? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, dájúdájú nígbà náà ìwọ yóò ríi pé ẹ̀rí fihàn pé ìwọ̀nyí jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bálò.” (2 Timoteu 3:1-5, NW) Ọ̀nà tí ó gbà nípalórí àwọn ènìyàn yàtọ̀síra. Fún àpẹẹrẹ, ó ṣeéṣe kí o mọ àwọn ilẹ̀ tí ń pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ nísinsìnyí bí onírúurú ẹgbẹ́ ìyapa ti ń jà fún ìjẹgàba òṣèlú. Níbòmíràn, aáwọ̀ ìsìn àti ẹ̀yà-ìran ń fa ìṣekúpani. Àwọn ṣọ́jà nìkan kọ́ ni à ń palára. Ronú nípa àìmọye àwọn obìnrin àti ọmọdébìnrin tí a ti ṣeníkà tàbí àwọn àgbàlagbà tí a ti fi oúnjẹ, ìpèsè agbára ìmóoru, àti ilé dù. Àìlóǹkà ń jìyà gidigidi, èyí tí ń ṣamọ̀nà sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn olùwá-ibi-ìsádi àti ọ̀pọ̀ ìdààmú ọkàn tí ó tanmọ́ ọn.
4 Àwọn àkókò wa ni a tún sàmì sí pẹ̀lú ìṣòro ètò ọrọ̀-ajé, tí ń yọrísí títi àwọn ilé-iṣẹ́ pa, àìníṣẹ́lọ́wọ́, ìpàdánù owó ìrànwọ́ àti owó ìfẹ̀yìntì, ìlọsílẹ̀ ìníyelórí owó, àwọn oúnjẹ tí kò tó nǹkan tàbí tí ó túbọ̀ kéré síi. Ìwọ ha lè fikún àkọsílẹ̀ àwọn ìṣòro náà? Ó ṣeéṣe. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn yíká ayé ń jìyà àìtó oúnjẹ àti àwọn àrùn. Ó ṣeéṣe kí o ti rí àwọn fọ́tò bíbanilẹ́rù láti Ìlà-Oòrùn Africa tí ń ṣàfihàn àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí wọ́n ti rù. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ní Asia ń jẹ irú ìyà kan náà.
5, 6. Èéṣe tí a fi lè sọ pé àrùn tún jẹ́ apá lílégbákan nínú àwọn àkókò lílekoko wa?
5 Gbogbo wa ti gbọ́ nípa àwọn àrùn tí ń kó jìnnìjìnnì báni tí ń pọ̀ síi. Ní January 25, 1993, ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Bí ó ti ń gbilẹ̀ síi láàárín ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe, ìwà àgàbàgebè àti ìdènà àrùn tí ń ṣe ségesège, àjàkálẹ̀ àrùn AIDS ní Latin America ti wà lójú ọ̀nà àtitayọ ti United States . . . Ọ̀pọ̀ jùlọ nínú ìdàgbàgbèrú náà wá láti inú ìlọsókè iye àkóràn láàárín àwọn . . . obìnrin.” Ní October 1992, ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Kìkì ẹ̀wádún méjì sẹ́yìn ni oníṣẹ́ abẹ àgbà fún United States, tí ń kókìkí ọ̀kan nínú àwọn ìjagunmólú títóbi jùlọ nínú ètò ìlera gbogbogbòò tí ó tíì ṣẹlẹ̀ rí, kéde pé ó tó àkókò láti ‘ṣíwọ́ ṣíṣàníyàn nípa àwọn àrùn tí ń ranni.’” Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ńkọ́? “Àwọn ilé-ìwòsàn tún ti ń kún àkúnya fún àwọn òjìyà àjàkálẹ̀ àrùn tí ó yẹ kí a ti ṣẹ́gun. . . . Àwọn kòkòrò tín-tìn-tín inú ara ń ṣàmújáde àwọn ọgbọ́n ìgbógun jíjáfáfá níti ànímọ́ àbímọ́ni tí ń fún wọn láàyè láti dàgbà kánkán rékọjá ìmújáde àwọn òògùn agbógunti kòkòrò àrùn titun. . . . ‘Àwa ń wọnú sànmánì titun ti àwọn àrùn tí ń ranni.’”
6 Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan, ìwé ìròyìn Newsweek ti January 11, 1993, ròyìn pé: “Kòkòrò àrùn ibà ń ran iye ènìyàn tí a díwọ̀n sí 270 million lọ́dọọdún, o ń pa nǹkan bíi million 2 . . . tí ó sì ń ṣokùnfà ó kérétán 100 million àwọn ọ̀ràn àìsàn lílekoko . . . Ní àkókò kan náà, àrùn náà túbọ̀ ń lágbára púpọ̀ síi níti àìgbóògùn lójú àwọn egbòogi tí ó ti ń wò ó tẹ́lẹ̀rí. . . . Àwọn ọ̀wọ́ kan lè di aláìṣeéwòsàn bí ó bá yá.” Èyí kó jìnnìjìnnì bá ọ.
7. Báwo ni ọ̀pọ̀ lónìí ṣe ń hùwàpadà sí àwọn àkókò ṣíṣòro náà?
7 Ìwọ ti lè ṣàkíyèsí pé ní àwọn àkókò lílekoko wọ̀nyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń wá ìrànlọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro wọn. Ronú nípa àwọn wọnnì tí wọ́n ń yíjú sí àwọn ìwé tí ń sọ nípa kíkojú másùnmáwo tàbí àrùn titun mélòókan. Àwọn mìíràn ń gbékútà níti ìmọ̀ràn nípa ìgbéyàwó tí ń foríṣánpọ́n, àbójútó ọmọdé, ọtí-líle tàbí làásìgbò oògùn, tàbí nípa bí wọn yóò ṣe mú ohun tí iṣẹ́ wọn ń béèrè àti ìkìmọ́lẹ̀ tí wọ́n ń ní nínú ilé wà déédéé. Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n nílò ìrànwọ́ níti gidi! Ìwọ ha ń bá àwọn ìṣòro ara-ẹni fínra tàbí o ń nírìírí àwọn wàhálà tí ogun, ìyàn, tàbí ìjábá dásílẹ̀? Àní bí ìṣòro gíganilára kan bá dàbí aláìlójútùú, ìwọ ni ìdí láti béèrè pé, ‘Èéṣe tí a fi dórí irú ipò lílekoko bí èyí?’
8. Èéṣe tí a fi níláti yíjú sí Bibeli fún ìjìnlẹ̀-òye àti ìtọ́sọ́nà?
8 Ṣáájú kí a tó lè kojú wọn lọ́nà gbígbéṣẹ́ kí a sì rí ìtẹ́lọ́rùn nísinsìnyí àti ní ọjọ́-ọ̀la, a níláti mọ ìdí tí a fi dojúkọ irú àwọn àkókò lílekoko bẹ́ẹ̀. Níti gàsíkíyá, èyí pèsè ìdí fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti gbé Bibeli yẹ̀wò. Èéṣe tí a fi tọ́kasí Bibeli? Nítorí òun nìkanṣoṣo ni ó ní àsọtẹ́lẹ̀ pípéye, ìtàn tí a kọ kí ó tó ṣẹlẹ̀, tí o fi èrèdí àwọn ìṣòro wa hàn, ibi tí a wà, àti ibi tí a ń lọ.
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Inú Ìtàn
9, 10. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ní Matteu orí 24 ṣe ní ìmúṣẹ ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní?
9 Ilé-Ìṣọ́nà ti February 15, 1994, pèsè àtúnyẹ̀wò gbígbàfiyèsí nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ṣíṣekedere ní Matteu orí 24. Bí o bá ṣí Bibeli rẹ sí orí yẹn, ìwọ lè ríi ní ẹsẹ kẹta pé àwọn aposteli Jesu béèrè fún àmì kan nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ ọjọ́-ọ̀la àti ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan. Lẹ́yìn náà, ní ẹsẹ 5 sí 14, Jesu sọtẹ́lẹ̀ nípa èké Kristi, ogun, àìtó oúnjẹ, inúnibíni sí àwọn Kristian, ìwà-àìlófin, àti ìwàásù nípa Ìjọba Ọlọrun lọ́nà gbígbòòrò.
10 Ìtàn ti fẹ̀ríhàn pé àwọn ohun wọnnì ṣẹlẹ̀ níti gidi ní ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan Ju. Bí ó bá ṣe pé ìwọ wàláàyè nígbà yẹn, àwọn àkókò wọ̀nyẹn kò ha ti ní jẹ́ èyí tí ó lekoko bí? Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn nǹkan ń lọ sí òtéńté kan, ìpọ́njú aláìláfiwé lórí Jerusalemu àti ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju. Ní ẹsẹ 15 a bẹ̀rẹ̀ kíka ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ara Romu gbógunti Jerusalemu ní 66 C.E. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnnì dé ògógóró nínú ìpọ́njú tí Jesu mẹ́nukàn nínú ẹsẹ 21—ìparun Jerusalemu ni 70 C.E., ìpọ́njú bíburú jùlọ tí ó tíì dé bá ìlú-ńlá náà rí. Síbẹ̀, ìwọ mọ̀ pé ìtàn kò dópin nígbà yẹn, bẹ́ẹ̀ ni Jesu kò sọ pé yóò rí bẹ́ẹ̀. Ní ẹsẹ 23 sí 28, ó fihàn pé tẹ̀lé ìpọ́njú ti 70 C.E., àwọn nǹkan mìíràn yóò ṣẹlẹ̀.
11. Ní ọ̀nà wo ni ìmúṣẹ Matteu orí 24 ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní fi níí ṣe pẹ̀lú ọjọ́ wa?
11 Àwọn kan lónìí lè nítẹ̀sí láti fọwọ́ rọ́ irú àwọn ọ̀ràn àtẹ̀yìnwá bẹ́ẹ̀ tì ní sísọ pé ‘nígbà náà ńkọ́?’ Ìyẹn yóò jẹ àṣìṣe. Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún ṣe pàtàkì gan-an. Èéṣe? Ó dára, àwọn ogun, ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀, ìyọnu-àjàkálẹ̀, àti inúnibíni nígbà ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ Ju ni a óò gbéyọ nínú ìmúṣẹ títóbi jùlọ lẹ́yìn tí “àkókò àwọn Keferi” bá ti parí ní 1914. (Luku 21:24) Ọ̀pọ̀ tí ó wàláàyè lónìí jẹ́ olùfojúrí Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní, nígbà tí ìmúṣẹ òde-òní yìí bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n àní bí a tilẹ̀ bí ọ lẹ́yìn 1914, ìwọ ti ṣẹlẹ́rìí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jesu. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀rúndún ogún yìí fẹ̀ríhàn lọ́nà jaburata pé àwa ń gbé ní ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ búburú ti ìsinsìnyí.
12. Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ, kí ni a lè máa ṣèrètí láti rí?
12 Èyí túmọ̀sí pé “ìpọ́njú” inú Matteu 24:29 ṣì wà níwájú wa. Yóò kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àràmàǹdà ojú ọ̀run tí ó lè máṣe é finúrò. Ẹsẹ 30 fihàn pé àwọn ènìyàn nígbà náà yóò rí àmì mìíràn—ọ̀kan tí ó fihàn pé ìparun ti súnmọ́lé. Ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ bíbáradọ́gba nínú Luku 21:25-28, ní àkókò ọjọ́-ọ̀la yẹn, ‘àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti fún ìrètí nǹkan wọnnì tí ń bọ̀ sórí ayé.’ Àkọsílẹ̀ Luku tún sọ pé àwọn Kristian yóò gbé orí wọn sókè nígbà náà nítorí ìdáǹdè wọn yóò ti súnmọ́lé gírígírí.
13. Àwọn kókó pàtàkì méjì wo ni wọ́n yẹ fún àfiyèsí wa?
13 Ìwọ lè sọ pé, ‘Gbogbo ìyẹn dára, ó sì ṣeé gbọ́, ṣùgbọ́n mo ronú pé ìṣòro náà ni bí a óò ṣe lóye tí a óò sì dojúkọ àwọn àkókò lílekoko wa?’ Ìwọ tọ̀nà. Kókó wa àkọ́kọ́ ni láti mọ àwọn ìṣòro pàtàkì kí a sì rí bí a ṣe lè yẹra fún wọn. Èyí tí o so mọ́ èyí ni kókó kejì, bí àwọn ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ ṣe lè ṣèrànwọ́ fún wa láti gbé ìgbésí-ayé sísunwọ̀n nísinsìnyí. Bí a ṣe ń mẹ́nukan èyí, ṣí Bibeli rẹ sí 2 Timoteu orí 3, kí o sì rí bí àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn àkókò lílekoko náà.
Àsọtẹ́lẹ̀ kan Nípa Àwọn Àkókò Wa
14. Èéṣe tí ìdí fi wà láti gbàgbọ́ pé ṣíṣàgbéyẹ̀wò 2 Timoteu 3:1-5 lè ṣe wá láǹfààní?
14 Ọlọrun mísí Paulu láti kọ ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn rere sí Timoteu Kristian adúróṣinṣin èyí tí ó ṣèrànwọ́ fún un láti túbọ̀ gbé ìgbésí-ayé aláṣeyọrísírere àti aláyọ̀. Apákan lára ohun tí Paulu kọ jẹ́ èyí tí yóò ní àmúlò pàtàkì ní ọjọ́ wa. Àní bí ìwọ bá tilẹ̀ mọ̀ wọ́n dunjú, máa fọkàn bá àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà nínú 2 Timoteu 3:1-5 (NW) lọ pẹ́kípẹ́kí. Paulu kọ̀wé pé: “Mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bálò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ araawọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni lójú, onírera, asọ̀rọ̀-òdì, aṣàìgbọ́ràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní-ìfẹ́ni-àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọrun, àwọn tí wọn ní àwòrán ìrísí ìfọkànsin Ọlọrun, ṣùgbọ́n tí wọn jásí èké níti agbára rẹ̀.”
15. Èéṣe tí a fi níláti fún 2 Timoteu 3:1 ní àkànṣe àfiyèsí nísinsìnyí?
15 Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí pé, àwọn nǹkan 19 ni a tòlẹ́sẹẹsẹ. Kí a tó ṣàyẹ̀wò ìwọ̀nyí tí a óò sì wá wà ní ipò láti jàǹfààní, kọ́kọ́ lóye rẹ̀ ná. Wo ẹsẹ 1. Paulu sọtẹ́lẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bálò yóò wà níhìn-ín.” Àwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” wo? Ọ̀pọ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ni ó ti wà, irú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ti Pompeii ìgbàanì tàbí ọjọ́ ìkẹyìn ọba tàbí ìdílé ọlọ́ba kan. Bibeli tilẹ̀ mẹ́nukan àwọn ọjọ́ ìkẹyìn díẹ̀, irú bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn Ju. (Iṣe 2:16, 17) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jesu fi ìpìlẹ̀ náà lélẹ̀ fún wa láti lè lóye pé “ọjọ́ ìkẹyìn” tí Paulu mẹ́nukàn tọ́kasí àkókò wa.
16. Ipò wo ni àkàwé àlìkámà àti èpò sọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò wa?
16 Jesu ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àkàwé àlìkámà àti èpò. Àwọn wọ̀nyí ni a gbìn sínú oko tí a sì fi sílẹ̀ láti dàgbà. Ó sọ pé àlìkámà àti èpò dúró fún àwọn ènìyàn—àwọn Kristian tòótọ́ àti ti èké. A fa àkàwé yìí yọ nítorí tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé sáà àkókò gígùn yóò kọjá ṣáájú ìparí gbogbo ètò-ìgbékalẹ̀ búburú náà. Nígbà tí ìyẹn bá dé, ohun kan yóò ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. Kí ni? Ìpẹ̀yìndà, tàbí kíkúrò nínú ìsìn Kristian tòótọ́, tí ń yọrísí èso ìwà-ibi rẹpẹtẹ. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn nínú Bibeli jẹ́rìí síi pé èyí yóò ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò-ìgbékalẹ̀ búburú yìí. Ibi tí a wà nìyẹn, ní ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.—Matteu 13:24-30, 36-43.
17. Ìsọfúnni bíbáradọ́gba wo ni 2 Timoteu 3:1-5 pèsè nípa ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?
17 Ìwọ ha rí ìjẹ́pàtàkì èyí bí? Timoteu Kejì 3:1-5 fún wa ní ìtọ́kasí alábàádọ́gba kan pé ní ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ náà, tàbí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ipò tí ó yí àwọn Kristian ká yóò burú. Paulu kò sọ pé àwọn nǹkan 19 tí òun tòlẹ́sẹẹsẹ ni yóò jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ti dé. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun ń kìlọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a óò níláti bá fínra ní àkókò ìkẹyìn. Ẹsẹ 1 sọ̀rọ̀ nípa “àkókò lílekoko tí ó ṣòro láti bálò.” Gbólóhùn ọ̀rọ̀ yẹn wá láti inú èdè Griki, ó sì túmọ̀sí “àwọn àkókò àyànkalẹ̀ rírorò,” lóréfèé. (Kingdom Interlinear) Ìwọ kò ha gbà pé “rírorò” ṣàpèjúwe ohun tí a ń dojúkọ lónìí lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú? Gbólóhùn onímìísí yìí ń tẹ̀síwájú láti fún wa ní ìjìnlẹ̀-òye nípa àkókò wa.
18. Kí ni a níláti pa àfiyèsí pọ̀ lélórí bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Paulu?
18 Ìfẹ́-ọkàn wa nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí níláti fàyègbà wá láti mọ àwọn àpẹẹrẹ bíbaninínújẹ́ nípa bí sáà wa ti lekoko, tàbí rorò tó. Rántí àwọn kókó méjì tí a ní: (1) láti mọ àwọn ìṣòro tí ó mú àkókò wa lekoko àti láti rí bí a ṣe lè yẹra fún wọn; (2) láti fọkàn sí àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n gbéṣẹ́ nítòótọ́ tí wọ́n sì lè ṣèrànwọ́ fún wa láti gbádùn ìgbésí-ayé sísunwọ̀n. Nítorí náà dípò títẹnumọ́ àwọn ìṣòro, àwa yóò pa àfiyèsí pọ̀ sórí àwọn ẹ̀kọ́ tí ó lè ṣèrànwọ́ fún àwa àti ìdílé wa ní àwọn àkókò lílekoko láti bálò wọ̀nyìí.
Kórè Àwọn Ìbùkún Dídọ́ṣọ̀
19. Ẹ̀rí wo ni o ti rí pé àwọn ènìyàn jẹ́ olùfẹ́ ti araawọn?
19 Paulu bẹ̀rẹ̀ àkọsílẹ̀ rẹ̀ nípa sísàsọtẹ́lẹ̀ pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, “àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ araawọn.” (2 Timoteu 3:2) Kí ni ó nílọ́kàn? Ìwọ yóò tọ̀nà láti sọ pé jálẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin wà tí wọn jẹ́ aṣiṣẹ́sinraawọn, ajọra-ẹni-lójú. Síbẹ̀, kò sí iyèméjì pé àléébù yìí wọ́pọ̀ lónìí lọ́nà tí kò sí irú rẹ̀ rí. Ó légbákan lára àwọn ènìyàn kan. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀nà ìwàhíhù nínú agbo òṣèlú àti iṣẹ́ okòwò. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin ń lépa agbára àti òkìkí lọ́nàkọnà. Lọ́pọ̀ ìgbà ìyẹn jẹ́ ní iyekíye tí yóò ná àwọn ẹlòmíràn, nítorí pé àwọn olùfẹ́ ara-ẹni bẹ́ẹ̀ kò bìkítà nípa bí wọ́n ṣe pa àwọn ẹlòmíràn lára. Wọ́n ń yára pẹjọ́ tàbí rẹ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ. Ìwọ lè lóye ìdí tí ọ̀pọ̀ fi pe èyí ní “ìran ènìyàn tèmi ṣáá.” Àwọn ènìyànkénìyàn àti onírera pọ̀ jaburata.
20. Báwo ni ìmọ̀ràn Bibeli ṣe yàtọ̀ sí ẹ̀mí fífẹ́ràn ara-ẹni tí ó gbòdekan yìí?
20 A kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní rán wa létí àwọn ìrírí bíbaninínújẹ́ tí a ti ní nínú ìbálò pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ “olùfẹ́ araawọn.” Ó ṣì jẹ́ òtítọ́ síbẹ̀síbẹ̀ pé nípa mímọ ìṣòro yìí láìṣẹ̀tàn, Bibeli ń ṣèrànwọ́ fún wa, nítorí ó ń kọ́ wa bí a ó ṣe yẹra fún pàkúté yìí. Ohun tí ó sọ nìyí: “Ẹ máṣe ṣe ohunkóhun láti inú góńgó ìlépa onímọtara-ẹni-nìkan tàbí láti inú ọ̀pọ̀ yanturu ìfẹ́-ọkàn láti fọ́nnu, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ sí araayín lẹ́nìkínní kejì, kí ẹ máa gbà á rò nígbà gbogbo pé àwọn ẹlòmíràn sàn ju ẹ̀yin tìkáraayín lọ. Kí ẹ sì máa wá ire-àǹfààní ara yín lẹ́nìkínní kejì, kìí ṣe ti ara yin nìkan.” “Máṣe ronú nìpa araarẹ lọ́nà gíga ju bí ó ṣe yẹ kí ó ṣe lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìrònú yín.” Ìmọ̀ràn dídára jùlọ yẹn ni a rí nínú Fillipi 2:3, 4 àti Romu 12:3, bí a ti túmọ̀ rẹ̀ nínú ẹ̀dà Today’s English Version.
21, 22. (a) Ẹ̀rí gbígbòòrò wo ni ó wà pé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè ṣèrànwọ́ lónìí? (b) Ipa wo ni ìmọ̀ràn Ọlọrun ti ní lórí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n jẹ́ olórí pípé?
21 Ẹnìkan lè ṣàtakò pé, ‘Ìyẹn dún bí ohun tí ó dára, ṣùgbọ́n kò gbéṣẹ́.’ Óò, dájúdájú ó gbéṣẹ́. Ó lè ṣiṣẹ́, ó sì ń ṣiṣẹ́ fún àwọn ènìyàn olórí pípé lónìí. Ní 1990 òǹṣèwé fún Yunifásítì Oxford tẹ ìwé The Social Dimensions of Sectarianism. Orí 8 ní àkòrí náà “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Orílẹ̀-èdè Katoliki Kan,” ó sì ṣàpèjúwe ìwádìí kan ní Belgium. A kà pé: “Ní yíyíjú sí ìfanimọ́ra gbígbéniró ti dídi Ẹlẹ́rìí kan, yàtọ̀ sí ìfanimọ́ra ti ‘Òtítọ́ náà’ fúnraarẹ̀, àwọn tí a wádìí èrò wọn nígbà mìíràn tún mẹ́nukan ànímọ́ tí ó ju ẹyọkan. . . . Ọ̀yàyà, ìwà-bí-ọ̀rẹ́, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan jẹ́ àwọn nǹkan tí a mẹ́nukàn déédéé jùlọ, ṣùgbọ́n àìlábòsí, àti ìṣesí gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní ‘fífi àwọn ìlànà Bibeli ṣèwàhù’ tún jẹ́ àwọn ànímọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí fọkànsìkẹ́.”
22 A lè fi òye yẹn wé àwòrán kan tí a yà pẹ̀lú kámẹ́rà kan tí ó ní awò gbígbòòrò; bí o bá lo awò aṣeédíwọ̀n, tàbí kámẹ́rà tí ń fa àwòrán mọ́ra dípò rẹ̀, ìwọ lè rí àwọn nǹkan tí ó súnmọ́ ọ pẹ́kípẹ́kí, ọ̀pọ̀ àwọn ìrírí ìgbésí-ayé níti gidi. Ìwọ̀nyí yóò ní nínú àwọn ọkùnrin tí wọn ti jẹ́ ọ̀fẹgẹ̀, ajẹgàba lénilórí, tàbí onímọtara-ẹni-nìkan paraku ṣùgbọ́n tí wọ́n túbọ̀ jẹ́ oníwà tútù nísinsìnyí, wọ́n ti di ọkọ àti baba ti ń fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti inúrere hàn sí àwọn alábàáṣègbéyàwó wọn, àwọn ọmọ, àti àwọn mìíràn. Yóò tún ní nínú àwọn obìnrin tí ń jẹgàba tàbí tí wọ́n ní ọkàn líle tẹ́lẹ̀rí ṣùgbọ́n tí wọ́n ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kọ́ ọ̀nà ìsìn Kristian tòótọ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ ni ó wà. Nísinsìnyí, jọ̀wọ́ sọ ọ́ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí. Kì yóò ha sàn jù fún ọ láti wà ní àyíká irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ju kí o fìgbà gbogbo máa dojúkọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ araawọn ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ bí? Ìyẹn kì yóò ha mú kí ó rọrùn jù láti kojú àwọn àkókò wa lílekoko bí? Nítorí náà, ǹjẹ́ títẹ̀lé irú àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli bẹ́ẹ̀ kò ha ni mú ọ láyọ̀ síi bí?
23. Èéṣe tí yóò fi yẹ láti fún 2 Timoteu 3:2-5 ní àfiyèsí síwájú síi?
23 Bí ó ti wù kí ó rí, a ti ṣàgbéyẹ̀wò kìkì ohun àkọ́kọ́ nínú àkọsílẹ̀ Paulu tí a kọ sí 2 Timoteu 3:2-5. Àwọn yòókù ń kọ́? Ǹjẹ́ fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò wọn yóò ha tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìṣòro pàtàkì ti àkókò wa kí o baà lè yẹra fún wọn àti láti lè mú kí o lóye ipa ọ̀nà tí yóò mú ayọ̀ tí ó túbọ̀ pọ̀ wá fún ìwọ àti àwọn olólùfẹ̀ẹ́ rẹ? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn kí o sì jèrè ìbùkún dídọ́ṣọ̀.
Àwọn Kókó Láti Rántí
◻ Àwọn ẹ̀rí díẹ̀ wo ni ó wà pé a ń gbé ní àwọn àkókò lílekoko?
◻ Èéṣe tí a fi lè ní ìdánilójú pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
◻ Kí ni àwọn kókó pàtàkì méjì tí a lè fàyọ láti inú ìkẹ́kọ̀ọ́ 2 Timoteu 3:1-5?
◻ Ní àkókò yìí tí ọ̀pọ̀ jẹ́ olùfẹ́ ti araawọn, báwo ni àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli ti ṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn Jehofa?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Fọ́tò òkè lápá òsì: Andy Hernandez/Sipa Press; fọ́tò ìsàlẹ̀ lápá ọ̀tún: Jose Nicolas/Sipa Press