Jesu Ha Ti Níláti Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọrun Bí?
Ẹtì kan fún Àwọn Onígbàgbọ́ Nínú Mẹ́talọ́kan
“BÁWO ni Jesu ṣe ti níláti ní ìgbàgbọ́? Òun ni Ọlọrun; ó mọ̀ ohun gbogbo ó sì ń rí ohun gbogbo láìsí pé ó ń yíjú sí ẹlòmíràn kan. Wàyí o ìgbàgbọ́ wémọ́ gbígbáralé ẹlòmíràn kan ní pàtó àti gbígba èyí tí a kò rí gbọ́; nítorí náà, pé Jesu-Ọlọrun ti níláti ní ìgbàgbọ́ ni a ṣátì.”
Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ọmọ ilẹ̀ France náà Jacques Guillet ti wí, ìyẹn ni èrò tí ó gba iwájú jùlọ nínú ìsìn Katoliki. Àlàyé yìí ha yà ọ́ lẹ́nu bí? Ìwọ ti lè ronú pé níwọ̀n bí Jesu ti jẹ́ àpẹẹrẹ fún awọn Kristian nínú ohun gbogbo, ó tún gbọ́dọ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe ìgbàgbọ́. Bí o bá ronú bẹ́ẹ̀, o kò tíì gbà pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ aláìjampata ti Kristẹndọm nípa Mẹ́talọ́kan.
Aboyún-ọ̀rọ̀ ni ìbéèrè náà nípa ìgbàgbọ́ Jesu jẹ́ níti gidi fún àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Katoliki, Protẹstanti, àti Orthodox tí wọ́n gbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan gẹ́gẹ́ bí “lájorí ohun-ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ àti ìgbésí-ayé Kristian.”a Bí ó ti wù kí ó rí, kìí ṣe gbogbo wọn ni wọ́n sẹ́ pé Jesu ní ìgbàgbọ́. Jacques Guillet tẹnumọ́ ọn pé “kò ṣeéṣe láti máṣe gbà pé Jesu ní ìgbàgbọ́,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Guillet jẹ́wọ́ pé, lójú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan, “àsé” ló jẹ́.
Onísìn Jesuit ọmọ ilẹ̀ France náà Jean Galot, àti iye tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn bíi tirẹ̀, ni ọ̀rọ̀ wọn ṣe kedere ní wíwí pé ní jíjẹ́ “Ọlọrun tòótọ́ àti ènìyàn tòótọ́, . . . Kristi kò lè gbàgbọ́ nínú araarẹ̀.” Ìwé ìròyìn La Civiltà Cattolica ròyìn pé, “Ìgbàgbọ́ wémọ́ gbígba ẹlòmíràn gbọ́, kìí ṣe gbígba ara-ẹni gbọ́.” Nígbà náà, ohun ìdènà tí ó wà fún mímọ̀ nípa ìgbàgbọ́ Jesu ni ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ aláìjampata ti Mẹ́talọ́kan, níwọ̀n bí àwọn ìpìlẹ̀ èrò méjèèjì ti takora.
Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn sọ pé, “Àwọn ìwé Ìhìnrere kò sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ Jesu rí.” Níti gidi, àwọn èdè-ọ̀rọ̀ náà tí a lò nínú Ìwé Mímọ́ Kristian lédè Griki pi·steuʹo (gbàgbọ́, ní ìgbàgbọ́) àti piʹstis (ìgbàgbọ́) sábà máa ń tọ́kasí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nínú Ọlọrun tàbí nínú Kristi, dípò kí ó jẹ́ ìgbàgbọ́ Jesu nínú Bàbá rẹ̀ ọ̀run. A ha níláti tìtorí èyí parí èrò pé Ọmọkùnrin Ọlọrun kò ní ìgbàgbọ́ bí? Kí ni a lè lóye láti inú ohun tí ó ṣe tí ó sì sọ? Kí ni Ìwé Mímọ́ wí?
Àdúrà Láìsí Ìgbàgbọ́ Kẹ̀?
Jesu jẹ́ ẹni tí ó máa ń gbàdúrà. Ó ń gbàdúrà lábẹ́ ipò gbogbo—nígbà tí a batisí rẹ̀ (Luku 3:21, NW); ní gbogbo òru ṣáájú kí ó tó yan àwọn aposteli rẹ̀ 12 (Luku 6:12, 13); àti ṣáájú ìpaláradà rẹ̀ lọ́nà ìyanu lórí òkè-ńlá, nígbà tí ó wà pẹ̀lú àwọn aposteli Peteru, Johannu, àti Jakọbu. (Luku 9:28, 29, NW) Ó ń gbàdúrà lọ́wọ́ nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “Kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà,” nítorí náà ó kọ́ wọn ní Àdúrà Oluwa (“Bàbá Wa tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run”). (Luku 11:1-4, NW; Matteu 6:9-13, NW) Ó dá gbàdúrà fún àkókò gígùn ní kùtùkùtù òwúrọ̀ (Marku 1:35-39); lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, lórí òkè-ńlá, lẹ́yìn tí ó ti jẹ́ kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ kúrò (Marku 6:45, 46); papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. (Luku 22:32; Johannu 17:1-26) Bẹ́ẹ̀ni, àdúrà jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ìgbésí-ayé Jesu.
Ó máa ń gbàdúrà ṣáájú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, fún àpẹẹrẹ, ṣáájú kí ó tó jí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lasaru dìde, ó wí pé: “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi. Lóòótọ́, emi mọ̀ pé iwọ ń gbọ́ tèmi nígbà gbogbo; ṣugbọn nítìtorí ogunlọ́gọ̀ tí ó dúró yíká ni mo fi sọ̀rọ̀, kí wọ́n lè gbàgbọ́ pé iwọ ni ó rán mi jáde.” (Johannu 11:41, 42, NW) Ìdánilójú náà pé Bàbá rẹ̀ yóò dáhùn àdúrà yẹn fi bí agbára ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti tó hàn. Ìsokọ́ra yìí láàárín àdúrà sí Ọlọrun àti ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ ṣe kedere láti inú ohun tí Kristi sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá gbàdúrà fún tí ẹ sì béèrè ẹ ní ìgbàgbọ́ pé ẹ kúkú ti rí wọn gbà.”—Marku 11:24, NW.
Bí Jesu kò bá ní ìgbàgbọ́, èéṣe tí ó fi gbàdúrà sí Ọlọrun? Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí kò bá ìwé mímọ́ mu ti Kristẹndọm, pé Jesu jẹ́ ènìyàn ó sì tún jẹ́ Ọlọrun ní àkókò kan náà, ń sọ ìhìn-iṣẹ́ Bibeli di èyí tí ń rúnilójú. Ó ń ṣèdíwọ́ fún àwọn ènìyàn láti lóye bí Bibeli ṣe rọrùn tó àti agbára rẹ̀. Ta ni ọkùnrin náà Jesu ń gbàdúrà sí? Ṣé araarẹ̀ ni? Ṣé kò mọ̀ pé Ọlọrun ni òun ni? Àti pé bí ó bá jẹ́ Ọlọrun tí ó sì mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ó fi gbàdúrà?
Àwọn àdúrà Jesu ní ọjọ́ tí ó lò kẹ́yìn nínú ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé tilẹ̀ fún wa ní òye jíjinlẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ dídúrógbọnyin nínú Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Ní fifi ìrètí àti ìfojúsọ́nà onígbọkànlé hàn, ó béèrè pé: “Nitori naa nísinsìnyí iwọ, Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ pẹlu ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.”—Johannu 17:5, NW.
Ní mímọ̀ pé àwọn àdánwò òun tí ó lekoko jùlọ àti ikú ti súnmọ́tòsí, ní alẹ́ ọjọ́ tí ó wà nínú ọgbà Getsemane lórí àwọn Òkè Olifi, “ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ní ẹ̀dùn-ọkàn ó sì dààmú gidigidi,” ó sì wí pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi àní títí dé ikú.” (Matteu 26:36-38, NW) Lẹ́yìn náà ni ó kúnlẹ̀ tí ó sì gbàdúrà pé: “Baba, bí iwọ bá fẹ́, mú ife yii kúrò lórí mi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́-inú mi ni kí ó ṣẹ, bíkòṣe tìrẹ.” Nígbà náà ni “áńgẹ́lì kan lati ọ̀run farahàn án ó sì fún un lókun.” Ọlọrun tẹ́tísí àdúrà rẹ̀. Nítorí bí èrò ìmọ̀lára rẹ̀ ti jinlẹ̀ tó àti bí àdánwò rẹ̀ ti lekoko tó, “òógùn rẹ̀ sì wá dàbí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀.”—Luku 22:42-44, NW.
Kí ni àwọn ìjìyà Jesu, àìní rẹ̀ fún ìgbéró, àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fihàn? Jacques Guillet kọ̀wé pé: “Ohun kan dájú, Jesu gbàdúrà, àdúrà sì jẹ́ apá-ìhà ṣíṣekókó kan nínú ìgbésí-ayé rẹ̀ àti nínú ìgbésẹ̀ rẹ̀. Ó gbàdúrà bí ènìyàn tií gbàdúrà, ó sì gbàdúrà nítorí àwọn ènìyàn. Wàyí o, a kò lè ronú pé àwọn ènìyàn yóò gbàdúrà láìní ìgbàgbọ́. A óò ha ronú pé Jesu yóò gbàdúrà láìní ìgbàgbọ́ bí?”
Níbi tí a gbé e kọ́ sí lórí òpó-igi oró ní kété ṣáájú ikú rẹ̀, Jesu kígbe pẹ̀lú ohùn rara, ní fífa ọ̀rọ̀ yọ nínú psalmu ti Dafidi. Lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ní ohùn rara, ó kígbe àdúrà ẹ̀bẹ̀ tí ó kẹ́yìn pé: “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi sí.” (Luku 23:46, NW; Matteu 27:46) Ìtumọ̀ kan lédè Italian tí ó wáyé láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka ìsìn, Parola del Signore, sọ pé Jesu ‘fi ìwàláàyè rẹ sí ọwọ́’ Bàbá.
Jacques Guillet ṣàlàyé pé: “Ní fífi hàn wá pé a kan Kristi mọ́ àgbélébùú, tí ó sì ń fi ohùn rara késí Bàbá rẹ̀ ní fífa ọ̀rọ̀ inú psalmu tí àwọn ọmọ Israeli yọ, àwọn òǹkọ̀wé Ìhìnrere mú wa gbàgbọ́ dájú pé igbe yẹn, igbe Ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo náà, igbe làásìgbò níti gidi, igbe ìgbọ́kànlé pátápátá, jẹ́ igbe ìgbàgbọ́, igbe ikú tí a kú sínú ìgbàgbọ́.”
Bí ẹ̀rí ìgbàgbọ́ síṣe kedere tí ń múnijígìrì yìí ti dojúkọ wọ́n, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan gbìyànjú láti fìyàtọ̀ sáàárín ìgbàgbọ́ àti “ìgbọ́kànlé.” Bí ó ti wù kí ó rí, irú ìfìyàtọ̀sí bẹ́ẹ̀ ni a kò gbékarí Ìwé Mímọ́.
Ṣùgbọ́n kí ni ohun náà ní pàtó tí àwọn àdánwò lílekoko tí Jesu faradà fihàn nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀?
A Sọ “Aláṣepé Ìgbàgbọ́ Wa” Di Pípé
Ní orí kọkànlá nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Heberu, aposteli Paulu mẹ́nukan àwọsánmà ńlá ti àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ tí wọ́n wà ṣáájú àkókò àwọn Kristian. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ní títọ́ka sí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ títóbi jùlọ àti èyí tí ó pé: “A . . . ń fi tọkàntara wo Olórí Aṣojú ati Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jesu. Nitori ìdùnnú-ayọ̀ tí a gbéka iwájú rẹ̀ ó farada òpó igi oró, ó tẹ́ḿbẹ́lú ìtìjú . . . Ẹ ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nipa ẹni naa tí ó ti farada irúfẹ́ òdì ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lati ẹnu awọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lòdì sí ire ara wọn, kí ó má baà rẹ̀ yín kí ẹ sì rẹ̀wẹ̀sì ninu ọkàn yín.”—Heberu 12:1-3, NW.
Èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn sọ pé ẹsẹ̀ yìí kò sọ̀rọ̀ nípa “ìgbàgbọ́ ti Jesu gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan” bíkòṣe wí pé, òun jẹ́ “apilẹ̀ṣẹ̀ tàbí olùpilẹ̀ ìgbàgbọ́.” Èdè Griki náà te·lei·o΄tes tí ó farahàn nínú àpólà ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́kasí ẹnìkan tí ń sọdi pípé, tí ń mú ohun kan ṣẹ tàbí tí ń sọ ọ́ di pípé pérépéré. Gẹ́gẹ́ bí “Aláṣepé,” Jesu sọ ìgbàgbọ́ di pípé pérépéré ní èrò ìtumọ̀ ti pé wíwá rẹ̀ sí orí ilẹ̀-ayé mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ṣẹ tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fìdí ìpìlẹ̀ kan tí ó túbọ̀ fìdímúlẹ̀ gbọnyin lélẹ̀ fún ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n èyí ha túmọ̀ sí pé òun kò ní ìgbàgbọ́ bí?
Àwọn apá àyọkà ọ̀rọ̀ láti inú lẹ́tà sí àwọn Heberu tí o lè rí nínú àpótí tí ó wà ní ojú-ìwé 15 mú iyèméjì kúrò. Jesu ni a sọ dí pípé nípasẹ̀ àwọn ìjìyà àti ìgbọràn rẹ̀. Bí òun tilẹ̀ ti jẹ́ ẹni pípé tẹ́lẹ̀, àwọn ìrírí rẹ̀ sọ ọ́ di pípé àti pípé pérépéré nínú ohun gbogbo, àní nínú ìgbàgbọ́ pàápàá, kí ó baà lè tóótun ní kíkún gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà fún ìgbàlà àwọn Kristian tòótọ́. Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Bàbá rẹ̀ “pẹlu igbe ẹkún kíkankíkan ati omijé,” ó jẹ́ “olùṣòtítọ́” sí Ọlọrun, ó sì ní ‘ìbẹ̀rù fún Ọlọrun.’ (Heberu 3:1, 2, NW; 5:7-9, NW) Heberu 4:15, sọ pé ‘dán an wò ní gbogbo ọ̀nà’ gan-an gẹ́gẹ́ “bí awa fúnra wa,” ìyẹn ni pé, bíi ti Kristian olùṣòtítọ́ èyíkéyìí tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ la “onírúurú àdánwò” kọjá. (Jakọbu 1:2, 3, NW) Ó ha lọ́gbọ́n nínú láti gbàgbọ́ pé a lè dán Jesu wo “bí” ti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láìjẹ́ pé a dán an wò nínú ìgbàgbọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn náà bí?
Àwọn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, ìgbọ́ràn, ìjìyà, àdánwò, ìṣòtítọ́, àti ìbẹ̀rù fún Ọlọrun jẹ́rìí sí ìgbàgbọ́ pípéye tí Jesu ní. Wọ́n fihàn pé ó di “Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa” kìkì lẹ́yìn tí a ti sọ ọ́ di pípé nínú ìgbàgbọ́ tirẹ̀. Lọ́nà síṣe kedere, òun kìí ṣe Ọlọrun Ọmọ, gẹ́gẹ́ bí Mẹ́talọ́kan ti sọ.—1 Johannu 5:5.
Òun Kò Ha Gba Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Gbọ́ Bí?
Ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan ti darí ìrònú àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn débi pé wọ́n bá a dé orí ojú-ìwòye aláṣerégèé ti gbígbà pé Jesu “kò lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀” nítorí pé “gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun náà gan-an, òun kò lè ṣe ju pípòkìkí ọ̀rọ̀ náà lọ.”—Angelo Amato, Gesù il Signore, ìwé kan tí ó ní àmì ìfàṣẹsí ti àjọ ṣọ́ọ̀ṣì.
Síbẹ̀, kí ni àwọn ìtọ́ka tí Jesu ń ṣe lemọ́lemọ́ sí Ìwé Mímọ́ fihàn níti gidi? Nígbà tí a dán an wò, ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Ìwé Mímọ́ nígbà mẹ́ta. Èsì rẹ̀ kẹta sọ fún Satani pé Ọlọrun nìkanṣoṣo ni Jesu ń sìn. (Matteu 4:4, 7, 10) Ní àwọn ìgbà mélòókan Jesu mẹ́nukan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó kan òun fúnraarẹ̀, ní fífi ìgbàgbọ́ hàn nínú ìmúṣẹ wọn. (Marku 14:21, 27; Luku 18:31-33; 22:37; fiwé Luku 9:22; 24:44-46.) Láti inú àyẹ̀wò yìí a gbọ́dọ̀ parí èrò pé Jesu mọ Ìwé Mímọ́ tí Bàbá rẹ̀ mísí, ó fi wọ́n sílò pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ó sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó sọ nípa àdánwò, ìjìyà, ikú, àti àjíǹde rẹ̀.
Jesu, Àwòkọ́ṣe Ìgbàgbọ́ tí Ó Yẹ Láti Ṣàfarawé
Jesu níláti ja ìjà ìgbàgbọ́ títí dé òpin kí ó baà lè di ìdúróṣinṣin síhà ọ̀dọ̀ Bàbá rẹ̀ mú àti láti “ṣẹ́gun ayé.” (Johannu 16:33, NW) Láìsí ìgbàgbọ́, kò ṣeéṣe kí ọwọ́ ẹni tẹ irú ìṣẹ́gun bẹ́ẹ̀. (Heberu 11:6; 1 Johannu 5:4) Nítorí ìgbàgbọ́ aṣẹ́gun yẹn, òun jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Dájúdájú òun ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun òtítọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìjíròrò tí ó túbọ̀ gbòòrò síi nípa àìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ni a lè rí nínú ìwé pẹlẹbẹ náà Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
A Sọ Jesu, “Aláṣepé,” Di Pípé
Heberu 2:10, NW: “Nitori ó yẹ fún ẹni naa tí ohun gbogbo torí rẹ̀ wà ati nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo fi wà, ní mímú ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ọmọ wá sínú ògo, lati sọ Olórí Aṣojú ìgbàlà wọn di pípé nípasẹ̀ awọn ìjìyà.”
Heberu 2:17, 18, NW: “Nitori naa ó di dandan fún un lati dàbí ‘awọn arákùnrin’ rẹ̀ ní ọ̀nà gbogbo, kí ó lè di àlùfáà àgbà tí ó jẹ́ aláàánú ati olùṣòtítọ́ ninu awọn ohun tí ó jẹmọ́ ti Ọlọrun, kí ó baà lè rú ẹbọ ìpẹ̀tù fún ẹ̀ṣẹ̀ awọn ènìyàn. Nitori níti pé oun fúnra rẹ̀ ti jìyà nígbà tí a ń dán an wò, ó lè wá ṣe àrànṣe fún awọn wọnnì tí a ń dánwò.”
Heberu 3:2, NW: “Oun jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ẹni naa tí ó ṣe é bẹ́ẹ̀, bí Mose pẹlu ti jẹ́ ní gbogbo ilé Ẹni yẹn.”
Heberu 4:15, NW: “Nitori awa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni kan tí kò lè bánikẹ́dùn fún awọn àìlera wa, bíkòṣe ẹni kan tí a ti dánwò ní gbogbo ọ̀nà bí awa fúnra wa, ṣugbọn tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.”
Heberu 5:7-9, NW: “Ní awọn ọjọ́ rẹ̀ ninu ẹran-ara Kristi ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ ati ìtọrọ pẹlu sí Ẹni naa tí ó lè gbà á là kúrò ninu ikú, pẹlu igbe ẹkún kíkankíkan ati omijé, a sì gbọ́ ọ pẹlu ojúrere nitori ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọrun. Bí oun tilẹ̀ jẹ́ Ọmọkùnrin, ó kọ́ ìgbọràn lati inú awọn ohun tí ó jìyà rẹ̀; ati lẹ́yìn tí a ti sọ ọ́ di pípé ó di ẹni tí ó ní ẹrù-iṣẹ́ fún mímú ìgbàlà àìnípẹ̀kun wá.”