Jehofa Lè Sọ Ọ́ Di Alágbára
“Ó ń fi agbára fún aláàárẹ̀; ó sì fi agbára kún àwọn tí kò ní ipá.”—ISAIAH 40:29.
1, 2. Àwọn ẹ̀rí wo ni ó wà nípa agbára ńlá Jehofa?
ỌLỌRUN “alágbára ńlá” ni Jehofa. A lè rí ẹ̀rí “agbára ayérayé ati Jíjẹ́ Ọlọrun” ti Ọlọrun nínú ìtóbilọ́lá àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ tí a lè fojúrí. Àwọn wọnnì tí wọ́n kọ̀ láti gba irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ nípa Jíjẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ kò ní àwíjàre.—Orin Dafidi 147:5; Romu 1:19, 20, NW.
2 Agbára Jehofa túbọ̀ ń di èyí tí ó hàn gbangba bí àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ṣe ń ṣèwádìí jinlẹ̀ sí inú àgbáyé, pẹ̀lú àìmọye àwọn ìṣùpọ̀-ìràwọ̀ rẹ̀ tí wọ́n fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún million ọdún jìnnà síra. Ní alẹ́ dídára kan ṣùgbọ́n tí ó ṣókùnkùn, bojúwo òkè ọ̀run kí o sì kíyèsíi bí ìmọ̀lára rẹ̀ kò bá ní rí bíi ti onipsalmu náà pé: “Nígbà ti mo wo ọ̀run rẹ, iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti ìràwọ̀, ti ìwọ ti ṣe ìlànà sílẹ̀. Kí ni ènìyàn, tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀? àti ọmọ ènìyàn ti ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò.” (Orin Dafidi 8:3, 4) Ẹ sì wo bí Jehofa ṣe ṣètọ́jú àwa ènìyàn tó! Ó pèsè ilé orí ilẹ̀-ayé rírẹwà kan fún ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Kódà erùpẹ̀-ilẹ̀ rẹ̀ lágbára—láti mú kí ewéko dàgbà, kí ó sì mú oúnjẹ aṣaralóore, tí a kò kó èérí bá jáde. Ènìyàn àti ẹranko ń rí agbára ti ara ìyára gbà láti inú bí Ọlọrun ṣe fi agbára rẹ̀ hàn yìí.—Genesisi 1:12; 4:12; 1 Samueli 28:22.
3. Yàtọ̀ sí àwọn ohun tí a lè fojúrí ní àgbáyé, àwọn ohun mìíràn wo ni ó tún ń fi agbára Ọlọrun hàn?
3 Yàtọ̀ sí pé àwọn ọ̀run dùn-ún wò tí àwọn ohun-ọ̀gbìn àti ẹranko sì ń múniláyọ̀, wọ́n ń fi agbára Ọlọrun hàn fún wa. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Awọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere lati ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nitori a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ awọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé ati Jíjẹ́ Ọlọrun rẹ̀.” (Romu 1:20, NW) Ṣùgbọ́n ẹ̀rí mìíràn wà nípa agbára rẹ̀ tí ó yẹ fún àfiyèsí àti ìmọrírì wa. O lè ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ni ó tún ń fi agbára Ọlọrun hàn ju àgbáyé lọ?’ Jesu Kristi ni ìdáhùn náà. Ní tòótọ́, lábẹ́ ìmísí aposteli Paulu sọ pé Kristi náà tí a kàn mọ́gi ni “agbára Ọlọrun ati ọgbọ́n Ọlọrun.” (1 Korinti 1:24, NW) O lè béèrè pé, ‘Èéṣe ti ìyẹn fi rí bẹ́ẹ̀? Ipa wo ni ó sì lè ní lórí ìgbésí-ayé mi nísinsìnyí?’
Ó Fi Agbára Hàn Nípasẹ̀ Ọmọkùnrin Rẹ̀
4. Bawo ni a ṣe fi agbára Ọlọrun hàn nípa ti Ọmọkùnrin rẹ̀?
4 A kọ́kọ́ fi agbára Ọlọrun hàn nígbà tí ó dá Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo, tí ó dá ní àwòrán rẹ̀. Ọmọkùnrin ẹ̀mí yìí ṣiṣẹ́sin Jehofa gẹ́gẹ́ bí “ọ̀gá òṣìṣẹ́” nípa lílo agbára ńlá Ọlọrun fún ṣíṣẹ̀dá àwọn nǹkan mìíràn. (Owe 8:22, 30, NW) Paulu kọ lẹ́tà sí àwọn Kristian ará ní Kolosse pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo awọn ohun mìíràn ní awọn ọ̀run ati lórí ilẹ̀-ayé, awọn ohun tí a lè rí ati awọn ohun tí a kò lè rí . . . Gbogbo awọn ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀ ati fún un.”—Kolosse 1:15, 16, NW.
5-7. (a) Ní ìgbà àtijọ́, báwo ni ọ̀nà tí Ọlọrun gbà fi agbára rẹ̀ hàn ṣe kan àwọn ẹ̀dá ènìyàn? (b) Ìdí wo ni ó wà láti gbàgbọ́ pé a lè fi agbára Ọlọrun hàn nínú ọ̀ràn ti àwọn Kristian lónìí?
5 Àwa jẹ́ apákan ‘àwọn ohun tí a dá sórí ilẹ̀-ayé.’ Nítorí náà Ọlọrun ha lè nawọ́ agbára rẹ̀ sí àwa ẹ̀dá ènìyàn bí? Ó dára, jálẹ̀ gbogbo ìbálò Ọlọrun pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, Jehofa máa ń gbin àlékún agbára sínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti ìgbà-dé-ìgbà kí ó baà lè ṣeé ṣe fún wọn láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Mose mọ̀ pé ní gbogbogbòò àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé ń wàláàyè fún 70 tàbí 80 ọdún. (Orin Dafidi 90:10) Mose fúnraarẹ̀ ńkọ́? Ó gbé ayé fún 120 ọdún, síbẹ̀ “ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù.” (Deuteronomi 34:7) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn kò túmọ̀sí pé Ọlọrun ń jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan máa wàláàyè fún àkókò gígùn bẹ́ẹ̀ tàbí láti pa irú okunra bẹ́ẹ̀ mọ́, ó fi ẹ̀rí hàn pé Jehofa lè fi agbára fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn.
6 Ohun mìíràn tí ó túbọ̀ fi agbára-ìṣe Ọlọrun láti fi agbára fún ọkùnrin àti obìnrin hàn síwájú síi ni ohun tí ó ṣe fún aya Abrahamu. “Sara fúnra rẹ̀ pẹlu gba agbára lati lóyún irú-ọmọ, àní nígbà tí ó ti rékọjá ààlà ọjọ́-orí pàápàá, níwọ̀n bí ó ti ka ẹni naa tí ó ṣèlérí sí olùṣòtítọ́.” Tàbí kí o gbé bí Ọlọrun ṣe fi agbára fún àwọn onídàájọ́ àti àwọn mìíràn ní Israeli yẹ̀wò: “Gideoni, Baraku, Samsoni, Jefta, Dafidi, ati Samueli ati awọn wòlíì yòókù, awọn ẹni tí ó jẹ́ pé . . . lati inú ipò àìlera a sọ wọ́n di alágbára.”—Heberu 11:11, 32-34, NW.
7 Irú agbára bẹ́ẹ̀ lè ṣiṣẹ́ nínú ọ̀ràn tiwa pẹ̀lú. Óò, a lè ṣàì retí irú-ọmọ nísinsìnyí nípasẹ̀ iṣẹ́-ìyanu, a sì lè ṣàì fi agbára hàn bíi ti Samsoni. Ṣùgbọ́n a lè jẹ́ alágbára, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti mẹ́nukàn án fún àpẹẹrẹ àwùjọ àwọn ènìyàn kan ní Kolosse. Bẹ́ẹ̀ni, Paulu kọ̀wé sí àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé, irú àwọn tí a ń rí nínú àwọn ìjọ lónìí, ó sì sọ pé a ‘tí sọ wọn di alágbára pẹlu gbogbo agbára.’—Kolosse 1:11, NW.
8, 9. Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, báwo ni a ṣe fi agbára Jehofa hàn nípa ti àwọn ẹ̀dá ènìyàn bíi tiwa?
8 Nígbà isẹ́-òjíṣẹ́ Jesu lórí ilẹ̀-ayé, Jehofa mú un ṣe kedere pé agbára rẹ̀ ń tipa Ọmọkùnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, nígbà kan tí àwọn ògìdìgbó wọ́ tọ Jesu ní Kapernaumu, “agbára Jehofa sì wà níbẹ̀ fún un lati ṣe ìmúláradá.”—Luku 5:17, NW.
9 Lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, Jesu fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ pé wọn yóò ‘gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá dé sórí wọn.’ (Iṣe 1:8, NW) Ẹ wo bí èyí ṣe jẹ́ òtítọ́ tó! Òpìtàn kan ròyìn nípa àwọn ìdàgbàsókè tí ó wáyé ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn Pẹntikọsti ní 33 C.E. pé: “Pẹlu agbára ńlá ni awọn aposteli fi ń bá a lọ ní jíjẹ́ ẹ̀rí nipa àjíǹde Jesu Oluwa.” (Iṣe 4:33, NW) Paulu fúnraarẹ̀ jẹ́ ẹnì kan tí a sọ di alágbára fún iṣẹ́ náà tí Ọlọrun ti fàṣẹ yàn fún un láti ṣe. Lẹ́yìn ìyílọ́kànpadà àti ìpadàríran rẹ̀, ó “ń bá a nìṣó ní títúbọ̀ gba agbára ó sì ń mú ẹnu awọn Júù tí ń gbé ní Damasku wọhò bí ó ti fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn lọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu pé èyí ni Kristi naa.”—Iṣe 9:22, NW.
10. Báwo ni agbára láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ṣe ṣèrànwọ́ nínú ọ̀ràn ti Paulu?
10 Dájúdájú Paulu nílò àlékún agbára, nígbà tí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò okun tẹ̀mí àti ti ọpọlọ tí ó ń béèrè láti lè ṣàṣeparí ìrìn-àjò míṣọ́nnárì mẹ́ta tí ó gbá ìrìn-àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún ibùsọ̀. Ó tún foríti onírúurú àwọn ipò lílekoko, ní fífarada ìfisẹ́wọ̀n àti dídojúkọ ikú ajẹ́rìíkú. Lọ́nà wo? Ó dáhùn pé: “Oluwa dúró lẹ́bàá mi ó sì fi agbára sínú mi, pé nípasẹ̀ mi kí a lè ṣàṣeparí ìwàásù naa ní kíkún.”—2 Timoteu 4:6-8, 17, NW; 2 Korinti 11:23-27.
11. Níti agbára Ọlọrun, ìrètí wo ni Paulu tọ́ka sí fún àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Kolosse?
11 Kò yanilẹ́nu, nígbà náà, pé, nígbà tí Paulu ń kọ̀wé sí awọn “arákùnrin” rẹ̀ “ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Kristi” ní Kolosse, ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé a lè sọ wọ́n ‘di alágbára pẹlu gbogbo agbára dé ìwọ̀n agbára ńlá [Jehofa] ológo kí wọ́n baà lè faradà á ní kíkún kí wọ́n sì máa ní ìpamọ́ra pẹlu ìdùnnú-ayọ̀.’ (Kolosse 1:2, 11, NW) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lákọ̀ọ́kọ́ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ni a darí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sí, gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ipasẹ̀ Kristi lè jàǹfààní ńláǹlà láti inú ohun tí Paulu kọ̀wé rẹ̀.
A Fi Agbára fún Wọn ní Kolosse
12, 13. Kí ni ó pilẹ̀ lẹ́tà náà sí àwọn ara Kolosse, ọ̀nà wo ni ó sì ti ṣeé ṣe kí wọ́n gbà dáhùnpadà sí i?
12 Ìjọ tí ó wà ní Kolosse, tí ó wà ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Romu ní Asia, ni ó ṣeé ṣe kí a ti dá sílẹ̀ nípa ìwàásù Kristian olùṣòtítọ́ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Epafra. Ó dàbí ẹni pé nígbà tí ó gbọ́ nípa ìfisẹ́wọ̀n Paulu ní Romu ní nǹkan bíi 58 C.E., Epafra pinnu láti bẹ aposteli náà wò kí ó sì fún un ní ìṣírí pẹ̀lú ìròyìn rere ti ìfẹ́ àti ìdúróṣinṣin ti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní Kolosse. Ó ṣeé ṣe pẹ̀lú pé Epafra ti sọ ìròyìn tòótọ́ nípa àwọn ìṣòro kan tí ó ń fẹ́ àmójútó ní ìjọ Kolosse. Bákan náà, Paulu ní ìsúnniṣe láti kọ lẹ́tà ìṣírí àti ìyànjú kan sí ìjọ náà. Ìwọ pẹ̀lú lè rí ìṣírí ńláǹlà gbà láti orí 1 lẹ́tà náà, nítorí pé ó tànmọ́lẹ̀ sórí bí Jehofa ṣe lè sọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ di alágbára.
13 Ìwọ lè ronú bí ìmọ̀lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin ní Kolosse yóò ti rí nígbà tí Paulu ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí “awọn olùṣòtítọ́ arákùnrin ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Kristi.” Wọ́n yẹ ní gbígbóríyìn fún nítorí ‘ìfẹ́ wọn fún gbogbo àwọn ẹni mímọ́’ àti fún ‘síso èso ìhìnrere’ láti ìgbà tí wọ́n ti di Kristian! A ha lè sọ àwọn gbólóhùn kan náà wọ̀nyí nípa ìjọ wa, àti gbogbo wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan bí?—Kolosse 1:2-8, NW.
14. Kí ni ìfẹ́-ọkàn Paulu nípa àwọn ará Kolosse?
14 Ìròyìn tí Paulu rí gbà ru ú sókè tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi sọ fùn àwọn ará Kolosse pé òun kò dẹ́kun gbígbàdúrà fún wọn àti bíbèèrè pé kí wọ́n ‘lè kún fún ìmọ̀ pípéye nipa ìfẹ́-inú [Ọlọrun] ninu ọgbọ́n gbogbo ati ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí wọ́n lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jehofa.’ Ó gbàdúrà pé ‘kí wọ́n máa bá a lọ ní síso èso ninu iṣẹ́ rere gbogbo kí wọ́n sì máa pọ̀ sí i ninu ìmọ̀ pípéye nipa Ọlọrun, tí a ti sọ wọ́n di alágbára pẹlu gbogbo agbára dé ìwọ̀n agbára ńlá rẹ̀ ológo kí wọ́n baà lè faradà á ní kíkún kí wọ́n sì máa ní ìpamọ́ra pẹlu ìdùnnú-ayọ̀.’—Kolosse 1:9-11, NW.
A Fi Agbára fún Wa Lónìí Pẹ̀lú
15. Báwo ni a ṣe lè fi irú ìṣarasíhùwà kan náà tí a rí nínú ohun tí Paulu kọ sí àwọn ará Kolosse hàn?
15 Ẹ wo irú àpẹẹrẹ rere tí Paulu fi lélẹ̀ fún wa! Àwọn ará wa káàkiri ilẹ̀-ayé nílò àwọn àdúrà wa láti lè lo ìfaradà kí wọ́n sì pa ìdùnnú wọn mọ́ láìka ìjìyà wọn sí. Bíi Paulu, a níláti ṣe pàtó nínu àwọn àdúrà wa nígbà tí a bá gbọ́ ìròyìn pé àwọn ará ní àwọn ìjọ mìíràn, tàbí ní ilẹ̀ mìíràn, ń dojúkọ ìṣòro lílekoko. Ó lè jẹ́ pé ìjọ kan tí ó wà nítòsí ni ìjábá ti ìṣẹ̀dá tàbí àwọn ìṣòro tẹ̀mí kan kọlù. Tàbí ó sì lè jẹ́ pé àwọn Kristian ń lo ìfaradà ní ilẹ̀ kan tí ogun abẹ́lé tàbí ìpànìyàn láàárín ẹ̀yà kan sí èkejì ti ń jà rànyìn. Nínú àdúrà a níláti béèrè pé kí Ọlọrun ran àwọn ará wa lọ́wọ́ ‘kí wọn lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jehofa,’ kí wọ́n máa báa nìṣó ní síso èso Ìjọba bí wọ́n ṣe ń lo ìfaradà, kí wọ́n sì lè máa pọ̀ síi nínú ìmọ̀. Ní ọ̀nà yìí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ń gba agbára ẹ̀mí rẹ̀, ‘bí a ti ń sọ wọ́n di alágbára pẹ̀lú gbogbo agbára.’ Ó lè dá ọ lójú pé Bàbá rẹ yóò gbọ́ yóò sì dáhùn.—1 Johannu 5:14, 15, NW.
16, 17. (a) Gẹ́gẹ́ bí Paulu ti kọ̀wé, kí ni a níláti kún fún ọpẹ́ fún? (b) Ní ọ̀nà wo ni a gbà dá àwọn ènìyàn Ọlọrun sílẹ̀ tí a sì dáríjì wọn?
16 Paulu kọ̀wé pé àwọn ará Kolosse níláti máa ‘dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba tí ó mú wọn yẹ fún kíkópa ninu ogún awọn ẹni mímọ́ ninu ìmọ́lẹ̀.’ Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá wa ọ̀run fún àyè wa nínú ìṣètò rẹ̀, yálà nínú pápá àkóso Ìjọba rẹ̀ ti òkè ọ̀run tàbí ti orí ilẹ̀-ayé. Báwo ni Ọlọrun ṣe mú kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé tóótun lójú ìwòye tirẹ̀? Paulu kọ̀wé sí àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni-àmì-òróró pé: “Ó dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ọlá-àṣẹ òkùnkùn ó sì ṣí wa nípò lọ sínú ìjọba Ọmọkùnrin ìfẹ́ rẹ̀, nípasẹ̀ ẹni tí a gba ìtúsílẹ̀ wa nipa ìràpadà, ìdáríjì awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—Kolosse 1:12-14, NW.
17 Ohun yòówù kí ìrètí wa jẹ́, ti ọ̀run tàbí ti orí ilẹ̀-ayé, a ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun lójoojúmọ́ fún ìdáǹdè wa kúrò lọ́wọ́ ètò-ìgbékalẹ̀ búburú yìí, tí a ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínú ìpèsè ṣíṣeyebíye ẹbọ ìràpadà Ọmọkùnrin ọ̀wọ́n fún Jehofa. (Matteu 20:28) Àwọn Kristian tí a fi ẹ̀mí yàn ti jàǹfààní láti inú ìràpadà náà tí a lò fún wọn lọ́nà àkànṣe kí a baà lè ‘ṣí wọn nípò sínú ìjọba Ọmọkùnrin ìfẹ́ Ọlọrun.’ (Luku 22:20, 29, 30, NW) Ṣùgbọ́n “àwọn àgùtàn mìíràn” pẹ̀lú ń jàǹfààní láti inú ẹbọ náà àní nísinsìnyí pàápàá. (Johannu 10:16, NW) Wọ́n lè rí ìdáríjì Ọlọrun gbà kí wọ́n baà lè ní ìdúró òdodo níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ rẹ̀. Wọ́n ń ní ìpín títóbi nínú pípolongo “ìhìnrere ìjọba yìí” ní àkókò òpin yìí. (Matteu 24:14, NW) Ní àfikún sí ìyẹn, wọ́n ní ìrètí àgbàyanu ti dídi olódodo pátápátá àti ẹni pípe níti ara-ìyára, ní òpin Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún ti Kristi. Bí o ṣe ń ka àpèjúwe inú Ìṣípayá 7:13-17, wò ó bí o kò bá gbà pé ìwọ̀nyí yóò jẹ́ ẹ̀rí gbígba ìdáǹdè àti ìbùkún.
18. Mímú àwọn nǹkan rẹ́ wo tí a mẹ́nukàn ní Kolosse ni Ọlọrun ṣì ń ṣe àṣeparí rẹ̀?
18 Lẹ́tà Paulu ràn wá lọ́wọ́ láti mọ iye gbèsè tí a jẹ ọkùnrin títóbilọ́lá jùlọ náà tí ó tí ì gbé aye rí. Kí ni Ọlọrun ṣàṣeparí nípasẹ̀ Kristi? “[Ohun ni] lati tún tipasẹ̀ rẹ̀ mú gbogbo awọn ohun mìíràn padà rẹ́ pẹlu ara rẹ̀ nipa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ tí oun ta sílẹ̀ lórí òpó igi oró, yálà wọn ìbáà ṣe awọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé tabi awọn ohun tí ń bẹ ní awọn ọ̀run.” Ète Ọlọrun ni láti mú gbogbo ẹ̀dá wá sínú ìṣọ̀kan pátápátá pẹ̀lú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà ṣáájú ìṣọ̀tẹ̀ ní Edeni. Ẹni náà tí a lò láti dá ohun gbogbo ni Ẹnì kan náà tí a ń lò nísinsìnyí láti lè ṣe àṣeparí mímú ohun gbogbo rẹ́ yìí.—Kolosse 1:20, NW.
Kí Ni Ète Tí A Fi Sọ Wá Di Alágbára?
19, 20. Lórí kí ni jíjẹ́ ẹni mímọ́ àti aláìlábàwọ́n wa sinmi lé?
19 Ọ̀pọ̀ ẹrù-iṣẹ́ já lé àwa tí a ti mú bá Ọlọrun rẹ́ léjìká. Nígbà kan rí a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a sì yà wá nípa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, tí a ti ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jesu tí ọkàn wa kò sì ṣiṣẹ́ lórí àwọn iṣẹ́ tí ó burú mọ́, níti gidi a dúró ní ipò “mímọ́ ati ní àìlábàwọ́n, ati ní àìfi àyè sílẹ̀ fún ẹ̀sùn kankan níwájú [Ọlọrun].” (Kolosse 1:21, 22, NW) Ìwọ rò ó wò ná, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun kò ti tijú àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ olùṣòtítọ́ ti ìgbàanì, bẹ́ẹ̀ ni òun kò tijú wa, láti ké pè é gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun wa. (Heberu 11:16) Lónìí, kò sí ẹnì kan tí ó lè fẹ̀sùn kàn wá pé a kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ orúkọ rẹ̀ tí ó lókìkí, tàbí pé a ń bẹ̀rù pípolongo orúkọ náà títí dé òpin ilẹ̀-ayé!
20 Síbẹ̀ kíyèsí ìkìlọ̀ tí Paulu fi kún ọ̀rọ̀ inú Kolosse 1:23 pé: “Amọ́ ṣáá o, kìkì bí ẹ bá ń bá a lọ ninu ìgbàgbọ́, tí ẹ fìdímúlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ naa tí ẹ sì fẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tí a kò sì ṣí yín nípò kúrò ninu ìrètí ìhìnrere yẹn tí ẹ gbọ́, tí a sì wàásù ninu gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ó sinmi lórí mímú ìdúró wa gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí Jehofa, ní títẹ̀lé ipasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n. Jehofa àti Jesu ti ṣe ohun púpọ̀ fún wa! Ǹjẹ́ kí a fi ìfẹ́ wa hàn fún wọn nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn Paulu.
21. Èéṣe tí a fi ní ìdí ńláǹlà fún kíkún fún ayọ̀ lónìí?
21 Àwọn Kristian ní Kolosse ti níláti kún fún ayọ̀ láti gbọ́ pé ‘ìhìnrere tí wọ́n gbọ́’ ni a ti “wàásù ninu gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” Lónìí ó tilẹ̀ tún dùnmọ́ni ju ìyẹn lọ láti gbọ́ bí a ti ṣe polongo ìhìnrere Ìjọba náà tó nípasẹ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n lé ní million mẹ́rin àti ààbọ̀ fíìfífì ní àwọn ilẹ̀ tí ó lé ní 230. Họ́wù, lọ́dọọdún iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 300,000 láti orílẹ̀-èdè gbogbo wá ni a ń mú bá Ọlọrun rẹ́!—Matteu 24:14; 28:19, 20.
22. Àní bi a bá tilẹ̀ nírìírí ìjìyà, kí ni Ọlọrun lè ṣe fún wa?
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó hàn gbangba pé a ti Paulu mọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n nígbà tí ó fi ń kọ lẹ́tà náà sí àwọn ará Kolosse, òun kò kédàárò nípa ìpín rẹ̀ lọ́nàkọnà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí pé: “Mo ń yọ̀ nísinsìnyí ninu awọn ìjìyà mi fún yín.” Paulu mọ ohun tí ó túmọ̀ sí ‘láti máa faradà á ní kíkún ati láti máa ní ìpamọ́ra pẹlu ìdùnnú-ayọ̀.’ (Kolosse 1:11, 24, NW) Ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé òun kò ṣe èyí pẹ̀lú okun ti òun. Jehofa ti fi agbára fún un! Bákan náà ni ó rí lónìí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí tí a ti fi sẹ́wọ̀n tí a sì ti ṣe inúnibíni sí kò tí ì pàdánù ìdùnnú-ayọ̀ wọn nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ti wá mọrírì ìjótìítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun bí a ṣe rí i nínú Isaiah 40:29-31 (NW) pé: “Ó ń fi agbára fún aláàárẹ̀ . . . Àwọn tí ń ní ìrètí nínú Jehofa yóò jèrè agbára padà.”
23, 24. Kí ni àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ náà tí a mẹ́nukàn ní Kolosse 1:26?
23 Ìṣẹ́-òjíṣẹ́ ìhìnrere náà tí ó dálé Kristi lórí ṣe pàtàkì púpọ̀ fún Paulu. Ó fẹ́ kí àwọn mìíràn mọrírì ìníyelórí ipa-iṣẹ́ Kristi nínú ète Ọlọrun, nítorí náà ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ tí a ti fi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ awọn ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan tí ó ti kọjá ati kúrò lọ́dọ̀ awọn ìran tí ó ti kọjá.” Bí ó ti wù kí ó rí kò níláti máa fìgbà gbogbo jẹ́ àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀. Paulu fikún un pé: “Ṣugbọn nísinsìnyí a ti fi í hàn kedere fún awọn ẹni mímọ́ rẹ̀.” (Kolosse 1:26, NW) Nígbà tí ìṣọ̀tẹ̀ bẹ́ sílẹ̀ ní Edeni, Jehofa ṣe ìlérí àwọn ohun dídárajù tí ń bọ̀, ní sísọtẹ́lẹ̀ pé ‘irú-ọmọ obìnrin náà yóò fọ orí ejò náà.’ (Genesisi 3:15) Kí ni èyí túmọ̀ sí? Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rúndún, ó ti jẹ́ àdììtú. Lẹ́yìn náà ni Jesu wá, ó sì “tan ìmọ́lẹ̀ sórí ìyè ati àìdíbàjẹ́ nípasẹ̀ ìhìnrere.”—2 Timoteu 1:10, NW.
24 Bẹ́ẹ̀ni, “àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀” náà dá lórí Kristi àti Ìjọba Messia náà. Paulu mẹ́nukan “awọn ohun tí ń bẹ ní awọn ọ̀run,” ní títọ́ka sí àwọn wọnnì tí wọn yóò ṣàjọpín pẹ̀lú Kristi nínú ipò ìṣàkóso Ìjọba. Àwọn wọ̀nyí yóò jẹ́ irin-iṣẹ́ fún mímú àwọn ìbùkún tí kò ní ààlà wá fún “awọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé,” àwọn wọnnì tí wọn yóò gbádùn paradise títíláé níhìn-ín. Ìwọ lè rí bí ó ṣe bá a mu tó, nígbà náà, fún Paulu láti tọ́kasí “ọrọ̀ ológo nipa àṣírí mímọ́-ọlọ́wọ̀ yii.”—Kolosse 1:20, 27, NW.
25. Gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn ní Kolosse 1:29, kí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣarasíhùwà wa nísinsìnyí?
25 Paulu ń fojúsọ́nà fún àyè rẹ̀ nínú Ìjọba náà. Síbẹ̀ ó mọ̀ pé kì í ṣe ohun kan tí òun lè wulẹ̀ jókòó tẹtẹrẹ kí òun sì máa retí. “Emi ń ṣiṣẹ́ kára nítòótọ́, mo ń tiraka ní ìbámu pẹlu ìṣiṣẹ́ rẹ̀ èyí tí ó sì ń fi agbára ṣiṣẹ́ ninu mi.” (Kolosse 1:29, NW) Kíyèsíi pé Jehofa tipasẹ̀ Kristi, mú kí Paulu di alágbára láti ṣàṣeparí iṣẹ́-òjíṣẹ́ agbẹ̀mílà kan. Jehofa lè ṣe ohun kan náà fún wa lónìí. Ṣùgbọ́n a lè bí araawa pé, ‘Mo ha ṣì ní ẹ̀mí ajíhìnrere ti mo ní nígbà tí mo kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bí?’ Kí ni ìdáhùn rẹ? Kí ni ó lè ran ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti máa báa nìṣó ‘ní ṣíṣiṣẹ́ kára àti títiraka ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ agbára Jehofa’? Orí ọ̀ràn yìí gan-an ni ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e dálé.
Ìwọ Ha Fiyèsíi Bí?
◻ Èéṣe tí a fi lè ní ìdánilójú pé Jehofa lè fi agbára rẹ̀ hàn nítorí ti àwọn ẹ̀dá ènìyàn?
◻ Kí ni ó pilẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Paulu ní Kolosse orí 1?
◻ Báwo ni Ọlọrun ṣe ń ṣe ìmú nǹkan rẹ́ tí a mẹ́nukàn ní Kolosse 1:20?
◻ Nípasẹ̀ agbára rẹ̀, kí ni Jehofa lè ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ wa?
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
KOLOSSE