‘Títa Iyọ̀’ Ní Mozambique
FRANCISCO COANA, mẹ́ḿbà ìgbìmọ̀ orílẹ̀-èdè Mozambique, lo ọdún mẹ́wàá ní “ibùdó ìtúnkọ́lẹ́kọ̀ọ́.” Ó sọ ìrírí rẹ̀: “Mo mọ̀ pé àwa yóò wà níhìn-ín fún ìgbà díẹ̀, nítorí náà mo béèrè lọ́wọ́ alábòójútó àyíká bóyá mo lè máa bá a lọ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ṣùgbọ́n báwo ni mo ṣe lè ya àkókò tí ó tó sọ́tọ̀ fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn, níwọ̀n bí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jehofa ni gbogbo àwọn tí ó wà ní ibùdó náà? Mo sọ pé èmi yóò jáde lọ sí Milange, ìlú kan tí ó wà ní kìlómítà 47 sí wa, láti rí àwọn ènìyàn láti wàásù fún.
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ kò yọ̀ọ̀da fún wa láti fi ibùdó náà sílẹ̀, òfin yìí ni wọ́n kò fi ọwọ́ dan-in dan-in mú. Mo lè rántí pé mo lọ sínú igbó, tí mo kúnlẹ̀, tí mo sì gbàdúrà fún ọ̀nà láti wàásù fún àwọn ènìyàn àdúgbò. Láìpẹ́ Jehofa dáhùn.
“Mo kàn sí ọkùnrin kan tí ó ní kẹ̀kẹ́, mo sì bá a ṣe àdéhùn. Ó gbà pé bí mo bá lè ro hẹkta 3/4 nínú oko òun ṣáájú kí ìgbà òjò tó bẹ̀rẹ̀, òun yóò fi kẹ̀kẹ́ òun san owó ọ̀yà fún mi. Nítorí náà mo lo òwúrọ̀ kọ̀ọ̀kan ní ríro oko rẹ̀. Jehofa bùkún ìṣètò yìí, níwọ̀n bí mo ti gba kẹ̀kẹ́ mi nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.
“Ìyọrísí rẹ̀ ni pé ó ṣeé ṣe fún mi láti lọ sí ìlú títóbi ti Milange tí mo sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mi lọ lọ́nà gbígbéṣẹ́ ní pápá tí ń mésojáde yìí. Níwọ̀n bí iṣẹ́ wa ti wà lábẹ́ ìfòfindè, mo níláti wá ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan láti fi ojú àwọn ènìyàn mọ òtítọ́. Pẹ̀lú àwọn ìwé àti ìwé ìròyìn tí mo tẹ̀ bọ abẹ́ ṣẹ́ẹ̀tì mi, mo gbé ìwọ̀nba iyọ̀ díẹ̀ sínú àpò kan tí mo sì ń lọ káàkiri ní ṣíṣòwò iyọ̀ títà. Kàkà kí ń tà á fún meticais 5, èmi yóò dá meticais 15 lé e. (Bí ó bá jẹ́ ọ̀pọ̀kúyọ̀kú, àwọn ènìyàn yóò ra gbogbo rẹ̀, èmi kì yóò sì ní iyọ̀ mọ́ rárá láti lò fún iṣẹ́ ìwàásù mi!) Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ mi lọ báyìí:
“‘Ẹ ǹlẹ́ onílé o! Mo ń ta iyọ̀ lónìí.’
“‘Èló ni?’
“‘Meticais 15.’
“‘Rárá o. Ìyẹn ti wọ́n jù kẹ̀!’
“‘Òtítọ́ ni, mo gbà pé ó wọ́n. Ṣùgbọ́n bí o bá rò pé ó wọ́n nísinsìnyí, wulẹ̀ dúró díẹ̀ síi nítorí pé yóò túbọ̀ wọ́n síi ní ọjọ́-iwájú. Ìwọ ha mọ̀ pé Bibeli sọ èyí tẹ́lẹ̀?’
“‘Èmi kò ka ìyẹn rí nínú Bibeli mi.’
“‘Bẹ́ẹ̀ni, ó wà níbẹ̀. Gbé Bibeli rẹ wá, jẹ́ kí ń fi hàn ọ́.’
“Pẹ̀lú ìyẹn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ kan yóò bẹ̀rẹ̀ ní lílo Bibeli rẹ̀, tí tèmi yóò sì wà níbẹ̀ lábẹ́ ṣẹ́ẹ̀tì mi. Èmi yóò tọ́ka sí Ìṣípayá orí 6, nípa àwọn ipò lílekoko àti ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ. Bí mo bá ṣàkíyèsí ìdáhùnpadà tí ó báradé, èmi yóò mú Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye tàbí Ihinrere lati Mu Ọ Layọ jáde tí èmi yóò sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli gidi.
“Ìyọrísí rẹ̀ ni pé ó ṣeé ṣe fún mi láti bẹ̀rẹ̀ àwùjọ àwọn olùfìfẹ́hàn ẹlẹ́ni 15 ní Milange. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ kí ọwọ́ àwọn aláṣẹ tó tẹ̀ wá. Ní ọjọ́ kan bí mo ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan, àwọn ọlọ́pàá wọlé lójijì wọ́n sì fàṣẹ ọba mú wa. Gbogbo wa, títíkan àwọn ọmọ kéékèèké nínú ìdílé náà, ni a mú lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n àdúgbò. Lẹ́yìn lílo oṣù kan níbẹ̀, gbogbo wa ni a tún rán padà lọ sí ibùdó.”
Àwọn ìrírí wọ̀nyí kò dín ìtara àwọn arákùnrin wa kù. Ní òdìkejì, Francisco àti ìdílé rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n wà ní àwọn ibùdó náà, ń jọ́sìn wọ́n sì ń wàásù nísinsìnyí ní òmìnira ní Mozambique.