Ìwọ Ha Rántí Bí?
Ìwọ ha ti mọrírì kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà lọ́ọ́lọ́ọ́ bí? Ó dára, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀lé e wọ̀nyí:
▫ Èéṣe tí àwọn Kristian ìjímìjí kò fi ṣe àṣeyẹ ọjọ́ ìbí Jesu?
Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ti sọ, “àwọn Kristian Ìjímìjí kò ṣe ayẹyẹ ìbí [Jesu] nítorí pé wọ́n ka ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹnikẹ́ni sí àṣà ìbọ̀rìṣà.”—12/15, ojú-ìwé 4.
▫ Ó ha yẹ láti darí àdúrà sí Jesu bí?
Rárá, nítorí pé àdúrà jẹ́ ọ̀nà ìjọsìn tí a yàsọ́tọ̀ gedegbe tí ó wà fún Ọlọrun Olodumare nìkanṣoṣo. Nípa dídarí gbogbo àdúrà wa sí Jehofa Ọlọrun, a ń fi hàn pé a ti gba ìtọ́sọ́nà Jesu sí inú ọkàn-àyà wa láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa ní awọn ọ̀run.” (Matteu 6:9)—12/15, ojú-ìwé 25.
▫ Èéṣe tí a fi ṣe ìdájọ́ tí ó yàtọ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tí Ọba Dafidi dá ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹ̀sẹ̀ Anania àti Safira? (2 Samueli 11:2-24; 12:1-14; Ìṣe 5:1-11)
Ọba Dafidi ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo nítorí ẹran ara àìlera. Nígbà tí a gbé ohun tí ó ṣe kò ó lójú, ó ronúpìwàdà, Jehofa sì dáríjì í—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun níláti faramọ́ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yọrísí. Anania àti Safira dẹ́ṣẹ̀ níti pé wọ́n fi ìwà àgàbàgebè parọ́, ní gbígbìyànjú láti tan ìjọ Kristian jẹ tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ‘ṣèké sí ẹ̀mí mímọ́ àti sí Ọlọrun.’ (Ìṣe 5:3, 4) Ẹ̀rí fi hàn pé ìyẹn jẹ́ ọkàn-àyà burúkú, nítorí náà a ṣe ìdájọ́ wọn lọ́nà tí ó túbọ̀ múná.—1/1, ojú-ìwé 27, 28.
▫ Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ọkàn-àyà onídùnnú-ayọ̀?
A níláti mú ojú-ìwòye gbígbéṣẹ́ àti onímọrírì dàgbà nípa àwọn ìbùkún àti àwọn àǹfààní iṣẹ́-ìsìn tí Ọlọrun fún wa, kò sì yẹ kí a gbàgbé láé pé nípa títẹ̀lé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, a ń mú inú rẹ̀ dùn.—1/15, ojú-ìwé 16, 17.
▫ Àwọn ohun méjì wo ni a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn bí a bá níláti fúnni ní ìṣírí tí ó gbéṣẹ́?
Àkọ́kọ́, ronú nípa ohun tí ó yẹ láti sọ, kí ìṣírí rẹ̀ baà lè ṣe pàtó. Èkejì, wá àkókò tí ó bá yẹ láti bá ẹnì kan tí ó yẹ fún oríyìn tàbí tí ó nílò ìgbéró sọ̀rọ̀.—1/15, ojú-ìwé 23.
▫ Èéṣe tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” fi ní ‘imọ̀ ọ̀pẹ ní ọwọ́ wọn’? (Ìṣípayá 7:9)
Jíju imọ̀ ọ̀pẹ fi hàn pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà fi pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ kókìkí Ìjọba Jehofa àti Ọba rẹ̀ tí ó fi òróró yàn, Jesu Kristi. (Wo Lefitiku 23:39, 40.)—2/1, ojú-ìwé 17.
▫ Àwọn ẹ̀kọ́ tí ó níyelórí wo ni a rí nínú ìwé Jobu?
Ìwé Jobu fi hàn wá bí a ṣe lè bójútó àwọn ìṣòro. Ó pèsè àwọn àpẹẹrẹ yíyanilẹ́nu nípa bí a ṣe níláti—tàbí bí a kò ṣe níláti—fún ẹnì kan tí ó ń dojúkọ àdánwò ní àmọ̀ràn. Síwájú síi, ìrírí Jobu fúnra rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti hùwà lọ́nà tí ó wà déédéé nígbà tí a bá rí ara wa tí àwọn ipò tí kò báradé ń bá wa fínra.—2/15, ojú-ìwé 27.
▫ Kí ni àwọn iṣẹ́-ìyanu Jesu kọ́ wa?
Àwọn iṣẹ́-ìyanu Jesu fi ògo fún Ọlọrun, ní fífi àwòṣe kàn lélẹ̀ fún àwọn Kristian láti máa fi ògo fún Ọlọrun. (Romu 15:6) Wọ́n fún ṣíṣe ohun tí ó dára, fífi ìwà ọ̀làwọ́ hàn, àti fífi ìyọ́nú hàn ní ìṣírí.—3/1, ojú-ìwé 8.
▫ Ète wo ni àtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tí a ti múrasílẹ̀ tí àwọn alàgbà ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìyàsímímọ́ ṣiṣẹ́ fún?
Èyí jẹ́rìí sí i pé ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ olùnàgà fún ìrìbọmi lóye àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bibeli lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó sì mọ ohun tí ó ní nínú láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa.—3/1, ojú-ìwé 13.
▫ Báwo ni àwọn àdúrà inú Bibeli ṣe lè ṣe wá láǹfààní?
Nípa yíyẹ àwọn àdúrà inú Ìwé Mímọ́ wò fínnífínní, a lè mọ àwọn wọnnì tí a gbà ní àwọn ipò tí ó jọ tiwa. Wíwá, kíkà, àti ṣíṣàṣàrò lórí irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ lè mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tiwa fúnra wa pẹ̀lú Jehofa sunwọ̀n síi.—3/15, ojú-ìwé 3, 4.
▫ Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọrun?
Ìbẹ̀rù Ọlọrun jẹ́ ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Jehofa, ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ̀ fún un, papọ̀ pẹ̀lú ìfòyà gbígbámúṣé láti máṣe mú un bínú. (Orin Dafidi 89:7)—3/15, ojú-ìwé 10.
▫ Àwọn ọ̀nà mẹ́ta wo ni Bibeli gbà fi hàn pé a ṣe iyebíye ní ojú Ọlọrun?
Bibeli kọ́ni pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa níyelórí lójú Ọlọrun (Luku 12:6, 7); ó mú ohun tí Jehofa kà sí lára wa ṣe kedere (Malaki 3:16); ó sì sọ ohun tí Jehofa ti ṣe láti fi ìfẹ́ tí ó ní fún wa hàn. (Johannu 3:16)—4/1, ojú-ìwé 11, 12, 14.
▫ Èéṣe tí Heberu 10:24, 25 fi rékọjá àṣẹ lásán pé kí àwọn Kristian máa pàdépọ̀?
Àwọn ọ̀rọ̀ Paulu wọ̀nyí fi ọ̀pá-ìdiwọ̀n onímìísí àtọ̀runwá lélẹ̀ fún gbogbo ìpàdé Kristian—níti tòótọ́, fun àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí nígbà tí àwọn Kristian bá péjọ papọ̀.—4/1, ojú-ìwé 16.