Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ní Filippi 2:9, Paulu sọ nípa Jesu pé: “Ọlọrun . . . gbé e sí ipò gíga . . . ó sì fi inúrere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.” Kí ni orúkọ tuntun yìí? Bí Jesu bá sì rẹlẹ̀ sí Jehofa, báwo ni orúkọ Jesu ṣe lékè gbogbo orúkọ mìíràn?
Filippi 2:8, 9 kà pé: “Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó [Jesu] rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró. Fún ìdí yii gan-an pẹlu ni Ọlọrun fi gbé e sí ipò gíga tí ó sì fi inúrere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.”
Àyọkà yìí kò túmọ̀ sí pé, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Jehofa nìkan ni ó ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn pátápátá, Jesu gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹnì kan náà pẹ̀lú Jehofa. Bí àyíká ọ̀rọ̀ Filippi orí 2 ti fi hàn, Jesu gba orúkọ rẹ̀ tí a gbé ga, lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀. Ṣáájú ìgbà náà, kò tí ì ní in. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, Jehofa ti fìgbà gbogbo jẹ́ ẹni gíga lọ́lá jù lọ, ipò rẹ̀ kò sì tí ì yí padà. Òkodoro òtítọ́ náà pé, Jesu gba orúkọ kan tí ó ga lọ́lá ju orúkọ tí ó ní ṣáájú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé jẹ́rìí pé kì í ṣe ẹni kan náà pẹ̀lú Jehofa. Nígbà tí Paulu wí pé a fún Jesu ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, ó ní in lọ́kàn pé, nísinsìnyí, Jesu ní orúkọ tí ó ga lọ́lá jú lọ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọrun.
Kí ni orúkọ Jesu tí ó ga lọ́lá? Isaiah 9:6 ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn. Nígbà tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Messia tí ń bọ̀ náà, Jesu, ẹsẹ náà sọ pé: “Ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀: a óò sì máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun Alágbára, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Níhìn-ín, “orúkọ” Jesu ní í ṣe pẹ̀lú ipò gíga rẹ̀ àti ọlá àṣẹ rẹ̀, tí ó jẹ́ bákan náà pẹ̀lú bí a ṣe lóye “orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn,” tí a mẹ́nu kàn ní Filippi 2:9 sí. A pàṣẹ fún gbogbo eékún láti tẹ̀ ba fún Jesu, ní mímọyì ọlá àṣẹ onípò gíga tí Jehofa ti fún un—ipò ọlá àṣẹ tí ó ga ju èyí tí a fún ẹ̀dá mìíràn lọ. Ọ̀rọ̀ náà “mìíràn” nínú ìtumọ̀ yìí kò sí nínú ìpìlẹ̀ ẹsẹ ìwé Griki ní tààràtà, ṣùgbọ́n, òye ẹsẹ náà ni a fi túmọ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀. “Orúkọ” Jesu kò lékè orúkọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n ó lékè orúkọ gbogbo ẹ̀dá mìíràn.
Ẹ wo bí a ti kún fún ayọ̀ tó láti dara pọ̀ mọ́ àwọn áńgẹ́lì àti ẹ̀dá ènìyàn ní títẹ eékún ba, ní mímọyì orúkọ Jesu! A ń ṣe èyí nípa fífi ara wa sábẹ́ Jesu nínú ipò alágbára, tí a sì gbé ga, tí Jehofa fún un—“fún ògo Ọlọrun Baba.”—Filippi 2:11; Matteu 28:18.