Wọ́n Rí Àlàáfíà Nínú Ayé Onírúkèrúdò
ÀWÒRÁN ìran tí ó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn yìí, ń ṣàpèjúwe ìjà gbígbóná janjan ní Bosnia òun Herzegovina. Àlàáfíà ha lè wà ní irú ibi bẹ́ẹ̀ bí? Ó yani lẹ́nu pé, ìdáhùn náà jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni,. Bí àwùjọ àwọn ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì, Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlà Oòrùn, àti ti Mùsùlùmí, ní ilẹ̀ tí ó kàgbákò náà ṣe ń jà fún àgbègbè ìpínlẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fojú sọ́nà fún àlàáfíà, àwọn kan sì ti rí i.
Ìdílé Djorem ń gbé ní Sarajevo, wọ́n sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Láàárín gbogbo rúkèrúdò tí ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú ńlá náà, wọ́n ń bẹ àwọn aládùúgbò wọn wò gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn, láti ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun pẹ̀lú wọn. (Matteu 24:14) Èé ṣe? Nítorí pé ìdílé Djorem mọ̀ pé Ìjọba yìí jẹ́ gidi, pé a ti fìdí rẹ̀ kalẹ̀ ní àwọn ọ̀run, àti pé òun nìkan ni ìrètí dídára jù lọ fún àlàáfíà aráyé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú ohun tí aposteli Paulu pè ní “ìhìnrere àlàáfíà.” (Efesu 2:17) Ọpẹ́ ni fún àwọn ènìyàn bíi Bozo àti Hena Djorem, ọ̀pọ̀ ń rí àlàáfíà ní Bosnia àti Herzegovina.
Àlàáfíà Tòótọ́ Ń Bọ̀
A ṣì ní púpọ̀ sí i láti sọ nípa ìdílé Djorem. Ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ nípa tọkọtaya mìíràn tí wọ́n ní ìgbọ́kànlé nínú Ìjọba Ọlọrun. Orúkọ wọn ni Artur àti Arina. Àwọn àti àwọn ọmọdékùnrin wọn gbé ní orílẹ̀-èdè olómìnira kan ní ìpínlẹ̀ Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí. Nígbà tí ogun abẹ́lé bẹ́ sílẹ̀, Artur gbèjà ìhà kan. Ṣùgbọ́n, láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Èé ṣe tí mo fi ń bá àwọn tí wọ́n jẹ́ aládùúgbò mi tẹ́lẹ̀ rí jà?’ Ó kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, ó sì gúnlẹ̀ sí Estonia pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro.
Nígbà tí ó ṣèbẹ̀wò sí St. Petersburg, Artur pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ohun tí ó kọ́ nípa Ìjọba Ọlọrun sì wú u lórí púpọ̀. Ìfẹ́ Jehofa ni pé, láìpẹ́, Ìjọba Ọlọrun yóò jẹ́ ìṣàkóso kan ṣoṣo lórí aráyé. (Danieli 2:44) Nígbà náà, ilẹ̀ ayé yóò jẹ́ ibi alálàáfíà, tí kì yóò sí ogun abẹ́lé tàbí ìforígbárí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè mọ́. Isaiah sọ tẹ́lẹ̀ nìpa àkókò náà pé: “Wọn kì yóò pani lára, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò pani run ní gbogbo òkè mímọ́ mi: nítorí ayé yóò kún fún ìmọ̀ Oluwa gẹ́gẹ́ bí omi tí bo òkun.”—Isaiah 11:9.
Ní ṣíṣàkíyèsí àwòrán ayé alálàáfíà ní ọjọ́ iwájú nínú ìwé tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí Ẹlẹ́rìí kan fi hàn án, Artur sọ pé ibi tí ó rí báyìí ni òún ń gbé tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, nísinsìnyí, ogun abẹ́lé ti bà á jẹ́. Ní Estonia lọ́hùn-ún, Artur àti ìdílé rẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ìjọba Ọlọrun nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Àlàáfíà Nínú Rúkèrúdò
Orin Dafidi 37:37 sọ pé: “Máa kíyè sí ẹni pípé, kí o sì máa wo ẹni dídúró ṣinṣin: nítorí àlàáfíà ni òpin ọkunrin náà.” Ní tòótọ́, a kò fi àlàáfíà ẹni tí kò lẹ́bi, tí ó sì dúró ṣinṣin lójú Ọlọrun, mọ sí ọjọ́ iwájú rẹ̀. Ó ń gbádùn rẹ̀ nísinsìnyí. Báwo ni ìyẹn ti ṣeé ṣe? Gbé ìrírí ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Paul yẹ̀ wò.
Paul ń gbé ní àgọ́ àwọn olùwá ibi ìsádi kan tí ó jìnnà réré ní ìwọ̀ oòrun gúúsù Etiopia, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ti gidi, orílẹ̀-èdè alámùúlégbè kan ni ó ti wá. Ní ìlú rẹ̀, ó pàdé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ epo, ọkùnrin yìí sì fún un ní ìwé kan tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye.a Paul kò bá Ẹlẹ́rìí náà pàdé mọ́, ṣùgbọ́n ó fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà. Ogun abẹ́lé lé e lọ sí àgọ́ àwọn olùwá ibi ìsádi ní Etiopia, níbẹ̀ ni ó sì ti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó kọ́. Àwùjọ kékeré kan tẹ́wọ́ gba èyí gẹ́gẹ́ bí òtítọ́. Lórí ìpìlẹ̀ ohun tí wọ́n kọ́, láìpẹ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún àwọn mìíràn ní àgọ́ náà.
Paul kọ̀wé sí orílé-iṣẹ́ Watch Tower Society ní bíbéèrè fún ìrànlọ́wọ́. Ó ya òjíṣẹ́ tí a rán láti Addis Ababa lẹ́nu láti rí ènìyàn 35 tí ń dúró dè é, tí wọ́n ṣe tán láti mọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọrun. A ṣètò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ déédéé.
Báwo ni a ṣe lè sọ pé àwọn ènìyàn bíi Paul ń gbádùn àlàáfíà? Ìgbésí ayé wọn kò rọrùn, ṣùgbọ́n wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun. Nígbà tí rúkèrúdò ayé yìí bá ń dà wọ́n láàmú, wọ́n ń fi ìmọ̀ràn Bibeli sílò pé: “Ẹ máṣe máa ṣàníyàn nipa ohunkóhun, ṣugbọn ninu ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà ati ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ papọ̀ pẹlu ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ awọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọrun.” Nítorí ìdí èyí, wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tí ó ṣọ̀wọ́n lónìí. Àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu sí ìjọ ní Filippi ṣẹ sí wọn lára pé: “Àlàáfíà Ọlọrun tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yoo . . . máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn-àyà yín ati agbára èrò-orí yín nípasẹ̀ Kristi Jesu.” Ní ti gidi, wọ́n nímọ̀lára ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jehofa, “Ọlọrun àlàáfíà.”—Filippi 4:6‚ 7‚ 9.
Àlàáfíà ti Lọ́ọ́lọ́ọ́
Ọba Ìjọba Ọlọrun tí a ti gbé ka orí ìtẹ́, ni Jesu Kristi, tí a pè ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” nínú Bibeli. (Isaiah 9:6) Wòlíì ìgbàanì náà sọ nipa rẹ̀ pé: “Yóò . . . sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí àwọn kèfèrí: ìjọba rẹ̀ yóò sì jẹ́ láti okun dé òkun, àti láti odò títí dé òpin ayé.” (Sekariah 9:10) Àwọn ọ̀rọ̀ báyìí tí a mí sí ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ José.
Nígbà kan, José wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó jẹ́ akópayàbáni, a sì fàṣẹ ọba mú un nígbà tí ó ń gbèrò láti ju bọ́m̀bù sínú àgọ́ ọlọ́pàá. Ó ronú pé ìwà ipá nìkan ni ó lè sọ ọ́ di kàn-ánńpá fún ìjọba láti mú ipò nǹkan dára sí i ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Nígbà tí ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìyàwó rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
Lẹ́yìn tí a dá José sílẹ̀, òun pẹ̀lú kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 85:8 sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ sí i lára pé: “Èmi óò gbọ́ bí Ọlọrun Oluwa yóò ti wí: nítorí tí yóò sọ àlàáfíà sí àwọn ènìyàn rẹ̀, àti sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n, ẹsẹ náà parí pẹ̀lú ìkìlọ̀ kan pé: “Kí wọn kí ó máà tún padà sí wèrè.” Nítorí náà, ẹnì kan tí ń wá àlàáfíà Jehofa kì yóò lórí láyà láti ṣe bí ó ti fẹ́ tàbí ṣe lòdì sí ìfẹ́ Rẹ̀.
Lónìí, José àti ìyàwó rẹ̀ jẹ́ Kristian òjíṣẹ́. Wọ́n ń darí àwọn ẹlòmíràn sí Ijọba Jehofa gẹ́gẹ́ bí ojútùú sí àwọn ìṣòro tí José ti gbìyànjú tẹ́lẹ̀ láti fi àwọn bọ́m̀bù àgbélérọ yanjú. Wọ́n ti múra tán láti fọkàn tán Bibeli, tí ó sọ pé: “Oluwa yóò fúnni ní èyí tí ó dára.” (Orin Dafidi 85:12) Ní ti gidi, láìpẹ́ yìí, José ṣèbẹ̀wò sí àgọ́ ọlọ́pàá tí ó ti pète láti run tẹ́lẹ̀. Èé ṣe? Kí ó baà lè bá àwọn ìdílé tí ó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun.
Àwọn Ènìyàn Àlàáfíà
Bibeli sọ nínú Orin Dafidi 37:10, 11, pé: “Nítorí pé nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí: ní tòótọ́ ìwọ óò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọ́n óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” Ẹ wo irú ìfojúsọ́nà ológo tí ìyẹn jẹ́!
Ṣùgbọ́n, ṣàkíyèsí pé, àlàáfíà Jehofa wà fún kìkì “àwọn ọlọ́kàn tútù.” Àwọn tí ń wá àlàáfíà ní láti kọ́ láti jẹ́ ẹni àlàáfíà. Bí ó ti rí nìyẹn ní ti ọ̀ràn Keith, tí ń gbé New Zealand. A ṣàpèjúwe Keith gẹ́gẹ́ bí “alágbára ní ìrísí, gbajúmọ̀, òfinràn, àti alárìíyànjiyàn.” Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àjọ ìpàǹpá kan, ó sì ń gbé ní ilé olódi ní ti gidi, tí ajá mẹ́ta ń ṣọ́ ọgbà rẹ̀, kí àwọn ọ̀yọjúràn má baà wọlé. Ìyàwó rẹ̀, tí ó bí ọmọ mẹ́fà fún un, ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Nígbà tí Keith pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ìhìn rere náà ní ipa jíjinlẹ̀ lórí rẹ̀. Láìpẹ́, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí. Ó gé irun rẹ̀ tí ó gùn dé ìbàdí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun fún àwọn alájọṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àwọn kan lára àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
Gẹ́gẹ́ bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọlọ́kàn títọ́ káàkiri ayé, Keith ti bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Peteru sílò pé: “Ẹni tí yoo bá nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè tí yoo sì rí awọn ọjọ́ rere, . . . kí ó yípadà kúrò ninu ohun búburú kí ó sì máa ṣe ohun rere; kí ó máa wá àlàáfíà kí ó sì máa lépa rẹ̀.” (1 Peteru 3:10‚ 11) Ìyàwó Keith tẹ́lẹ̀ rí gbà láti fẹ́ ẹ padà, ọkùnrin náà sì ti ń kọ́ láti “máa wá àlàáfíà kí ó sì máa lépa rẹ̀” nísinsìnyí.
Àlàáfíà Jehofa ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ là, títí kan eléré ìdárayá tẹ́lẹ̀ rí kan, tí a bí ní U.S.S.R. àtijọ́. Ọkùnrin yìí gba àmì ẹ̀yẹ nínú eré Olympic, ṣùgbọ́n ó tojú sú u, ó sì yíjú sí oògùn líle àti ọtí. Lẹ́yìn ọdún 19 mánigbàgbé tí ó ní ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọlọ́dún mẹ́ta lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Siberia, sísá pamọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi tí ń lọ sí Canada, àti ìgbà méjì tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú nítorí oògùn olóró tí ó ti di bárakú fún un nínú, ó gbàdúrà sí Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́ láti rí ojúlówó ète ìgbésí ayé. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń sọ èdè Russia ràn án lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀. Lónìí, bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn, ọkùnrin yìí ti rí àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun àti pẹ̀lú ara rẹ̀.
Ìrètí Àjíǹde
Paríparí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Bozo àti Hena Djorem ní Sarajevo. Tọkọtaya yìí ní ọmọbìnrin ọlọ́dún márùn-ún kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Magdalena. Ní July tí ó kọjá, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kúrò nílé láti kópa lẹ́ẹ̀kan sí i nínú iṣẹ́ ìgbòkègbodò ìwàásù wọn, nígbà tí ohun ìjà tí ó bú gbàù pa gbogbo wọn. Kí ni, ní ti àlàáfíà tí wọ́n ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn? Ǹjẹ́ ohun ìjà tí ó pa wọ́n ha fi hàn pé èyí kì í ṣe àlàáfíà tòótọ́ bí?
Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí, ọ̀ràn ìbànújẹ́ ń ṣẹlẹ̀. Bọ́m̀bù tàbí àwọn ohun ìjà míràn ń pànìyàn. Àìsàn tàbí jàm̀bá ń pa àwọn mìíràn. Ọ̀pọ̀ ni ọjọ́ ogbó ń pa. Èyí kò yọ àwọn tí ń gbádùn àlàáfíà Ọlọrun sílẹ̀, ṣùgbọ́n pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ kò ní kí wọ́n máà nírètí.
Jesu ṣèlérí fún Marta ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Emi ni àjíǹde ati ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ ninu mi, bí ó tilẹ̀ kú, yoo yè.” (Johannu 11:25) Ìdílé Djorem gba èyí gbọ́, gẹ́gẹ́ bí gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣe. Ìdílé Djorem sì ní ìgbàgbọ́ pé bí àwọn bá kú, a óò jí wọn dìde sórí ilẹ̀ ayé kan tí yóò jẹ́ ibi àlàáfíà tòótọ́ nígbà náà. Jehofa Ọlọrun “yoo . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.
Kété kí ó tó kú, Jesu sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Mo fi àlàáfíà mi fún yín. . . . Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà yín dààmú.” (Johannu 14:27) A bá ìdílé Djorem yọ̀ pé wọ́n ní àlàáfíà náà àti pé wọn yóò gbádùn rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú àjíǹde. A bá àwọn tí ń jọ́sìn Jehofa, Ọlọrun àlàáfíà yọ̀. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Wọ́n ń gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun. Wọ́n ń mú àlàáfíà pẹ̀lú àwọn mìíràn dàgbà. Wọ́n sì ní ìgbọ́kànlé nínú ọjọ́ iwájú alálàáfíà. Àní, wọ́n ti rí àlàáfíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń gbé nínú ayé onírúkèrúdò. Ní tòótọ́, gbogbo àwọn tí ń jọ́sìn Ọlọrun ní ẹ̀mí àti òtítọ́ ń gbádùn àlàáfíà. Ǹjẹ́ kí ìwọ pẹ̀lú rí irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Wọ́n ti rí àlàáfíà, bí wọ́n tilẹ̀ ń gbé nínú ayé onírúkèrúdò