A ní Ìdí Láti Ké Jáde fún Ìdùnnú-ayọ̀
“Wọn óò rí ayọ̀ àti inú dídùn gbà, ìkáàánú òun ìmí ẹ̀dùn yóò sì fò lọ.”—ISAIAH 35:10.
1. Àwọn wo ni wọ́n ní ìdí pàtàkì fún ìdùnnú-ayọ̀ lónìí?
BÓYÁ o ti ṣàkíyèsí pé ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ni ó ní ojúlówó ìdùnnú-ayọ̀ lónìí. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi Kristian tòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìdùnnú-ayọ̀. Ìfojúsọ́nà fún rírí ìdùnnú-ayọ̀ kan náà wà níwájú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn tí wọn kò tí ì ṣe batisí, tọmọdé tàgbà, tí ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí. Òtítọ́ náà pé, o ń ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nísinsìnyí nínú ìwé ìròyìn yìí fi hàn pé, ìdùnnú-ayọ̀ yìí ti di tìrẹ tàbí pé ó ṣeé ṣe kí ó tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́.
2. Báwo ni ìdùnnú-ayọ̀ ti Kristian ṣe yàtọ̀ sí ipò wíwọ́pọ̀ tí àwọn ènìyàn púpọ̀ jù lọ wà?
2 Àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jù lọ nímọ̀lára pé, ohun kan ti sọnù nínú ìgbésí ayé wọn. Ìwọ ńkọ́? Òtítọ́ ni pé, o lè máà ní gbogbo ohun-ìní ti ara tí o lè lò, dájúdájú kì í ṣe ohun gbogbo ni àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn ẹni ńlá lónìí ní. O sì lè fẹ́ láti ní ìlera tí ó dára sí i tàbí okun púpọ̀ sí i. Síbẹ̀, a lè sọ láìṣeéjá-ní-koro ní ti ìdùnnú-ayọ̀ pé, o ní ọrọ̀ àti ìlera ju ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù olùgbé ilẹ̀ ayé lọ. Lọ́nà wo?
3. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kún fún ìtumọ̀ wo ni ó yẹ kí a fún ní àfiyèsí, èé sì ti ṣe?
3 Rántí ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ pé: “Nǹkan wọnyi ni mo ti sọ fún yín, kí ìdùnnú-ayọ̀ mi lè wà ninu yín kí a sì lè sọ ìdùnnú-ayọ̀ yín di kíkún.” (Johannu 15:11) “Kí a . . . lè sọ ìdùnnú-ayọ̀ yín di kíkún.” Ẹ wo irú àpèjúwe tí èyí jẹ́! Kíkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà ìgbésí ayé Kristian jinlẹ̀ yóò ṣí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí tí ìdùnnú-ayọ̀ wa fi ní láti di kíkún payá. Ṣùgbọ́n, wàyí o, kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kún fún ìtumọ̀, tí ó wà nínú Isaiah 35:10. Wọ́n kún fún ìtumọ̀ nítorí pé, wọ́n kàn wá gbọ̀ngbọ̀n lónìí. A kà pé: “Àwọn ẹni ìràpadà Oluwa yóò padà, wọn óò wá sí Sioni ti àwọn ti orin, ayọ̀ àìnípẹ̀kun yóò sì wà ní orí wọn: wọn óò rí ayọ̀ àti inú dídùn gbà, ìkáàánú òun ìmí-ẹ̀dùn yóò sì fò lọ.”
4. Irú ìdùnnú-ayọ̀ wo ni a mẹ́nu kàn nínú Isaiah 35:10, èé sì ti ṣe tí ó fi yẹ kí a fún èyí ní àfiyèsí?
4 “Ayọ̀ àìnípẹ̀kun.” Ọ̀rọ̀ náà, “àìnípẹ̀kun,” jẹ́ ìtumọ̀ pípéye fún ohun tí Isaiah kọ ní èdè Heberu. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ mìíràn ti fi hàn, ohun tí ẹsẹ yìí tẹnu mọ́ ni “láéláé.” (Orin Dafidi 45:6; 90:2; Isaiah 40:28) Nítorí náà, ayọ̀ náà kì yóò lópin, nínú ipò tí yóò yọ̀ọ̀da fún—àní, tí yóò ṣe ìdáláre fún—ayọ̀ àìnípẹ̀kun. Ìyẹn kò ha dún bí ohun tí ó dára bí? Ṣùgbọ́n, bóyá ẹsẹ yẹn gbún ọ ní kẹ́ṣẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí tí a sọ lórí ipò àbá èrò orí, tí ó mú kí o ronú pé: ‘Ní ti gidi, ìyẹn kò kàn mí tó bí àwọn ìṣòro àti àníyàn mi ojoojúmọ́ ṣe kàn mí tó.’ Ṣùgbọ́n, òtítọ́ náà fi òdì kejì hàn. Ìlérí alásọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Isaiah 35:10 ní ìtumọ̀ fún ọ lónìí. Láti mọ bí ó ṣe rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a yẹ orí tí ó lárinrin yìí wò, Isaiah 35, kí a sì ṣàkíyèsí apá kọ̀ọ̀kan nínú àyíká ọ̀rọ̀ náà. Mọ̀ dájú pé, ìwọ yóò gbádùn ohun tí a óò rí.
Àwọn Ènìyàn Tí Ó Yẹ Kí Wọ́n Yọ̀
5. Nínú àyíká ipò alásọtẹ́lẹ̀ wo ni a ti rí Isaiah orí 35?
5 Láti ràn wá lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí a wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣáájú, ìtàn àtẹ̀yìnwá, tí ó wà fún àsọtẹ́lẹ̀ amúnilọ́kànyọ̀ yìí. Wòlíì Heberu náà, Isaiah kọ ọ́, ní nǹkan bí ọdún 732 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Ìyẹ́n jẹ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ṣáájú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Babiloni tó pa Jerusalemu run. Gẹ́gẹ́ bí Isaiah 34:1, 2 ti fi hàn, Ọlọrun ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, òun yóò gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè, bí Edomu, tí a mẹ́nu kàn ní Isaiah 34:6. Ẹ̀rí fi hàn kedere pé, ó lo àwọn ará Babiloni ìgbàanì láti ṣe ìyẹn. Lọ́nà tí ó jọra, Ọlọrun mú kí àwọn ará Babiloni sọ Juda dahoro nítorí àwọn Júù jẹ́ aláìṣòtítọ́. Kí ni ó yọrí sí? A kó àwọn ènìyàn Ọlọrun lọ sí ìgbèkùn, ilẹ̀ wọn sì wà ní ahoro fún 70 ọdún.—2 Kronika 36:15-21.
6. Ìyàtọ̀ wo ni ó wà láàárín ohun tí a sọ pé yóò dé sórí àwọn ará Edomu àti ohun tí a sọ pé yóò dé sórí àwọn Júù?
6 Ṣùgbọ́n, ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà láàárín àwọn ará Edomu àti àwọn Júù. Ẹ̀san àtọ̀runwá lórí àwọn ará Edomu kò lópin; àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n parẹ́ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Àní, o ṣì lè ṣèbẹ̀wò sí àwọn ahoro òkìtì àlàpà ní agbègbè ibi tí àwọn ará Edomu ń gbé nígbà kan rí, irú bí òkìtì àlàpà Petra tí ó lókìkí káàkiri àgbáyé. Ṣùgbọ́n, kò sí orílẹ̀-èdè kankan tàbí àwọn ènìyàn kankan tí a lè tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ‘àwọn ará Edomu’ lónìí. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìsọdahoro Juda láti ọwọ́ àwọn ará Babiloni yóò ha jẹ́ títí láé, ní sísọ ilẹ̀ náà di èyí tí kò ní ìdùnnú-ayọ̀ títí ayérayé bí?
7. Báwo ni àwọn Júù tí a kó ní ìgbèkùn ní Babiloni ti ṣe lè dáhùn padà sí Isaiah orí 35?
7 Níhìn-ín, àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu inú Isaiah orí 35 ní ìtumọ̀ tí ó ṣe pàtàkì. A lè pè é ní àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò, nítorí pé, ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ nígbà tí àwọn Júù padà sí ilẹ̀ wọn ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa. A fún àwọn ọmọ Israeli tí wọ́n ti wà ní ìgbèkùn ní Babiloni ní òmìnira láti padà sí ilẹ̀ wọn. (Esra 1:1-11) Síbẹ̀, títí di ìgbà tí ìyẹ́n ṣẹlẹ̀, àwọn Júù tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni, tí wọ́n ti gbé àsọtẹ́lẹ̀ àtọ̀runwá yìí yẹ̀ wò, lè ti ṣe kàyéfì nípa irú ipò tí àwọn yóò bá pàdé ní Judah, ilẹ̀ orílẹ̀-èdè wọn. Ipò wo sì ni àwọn fúnra wọn yóò wà? Àwọn ìdáhùn rẹ̀ ní í ṣe ní tààràtà pẹ̀lú ohun tí ó mú wa ní ìdí ní tòótọ́ láti ké jáde fún ìdùnnú-ayọ̀. Ẹ jẹ́ kí a wò ó.
8. Ipò wo ni àwọn Júù rí nígbà tí wọ́n padà sí Babiloni? (Fi wé Esekieli 19:3-6; Hosea 13:8.)
8 Kódà, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọ́n lè padà sí ilẹ̀ wọn, lójú àwọn Júù, ipò náà dájúdájú kì yóò dà bí èyí tí yóò ṣẹnuure. Ilẹ̀ wọn ti wà ní ahoro fún ẹ̀wádún méje, gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé ènìyàn kan. Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ náà? Àwọn pápá tí a gbin nǹkan sí, ọgbà àjàrà tàbí ọgbà igi eléso yóò ti di aginjù. Àwọn ọgbà tàbí àwọn ilẹ̀ tí a pààlà sí, tí a ń bomi rin, yóò ti di ilẹ̀ gbígbẹ háúháú tàbí aṣálẹ̀. (Isaiah 24:1, 4; 33:9; Esekieli 6:14) Tún ronú nípa àwọn ẹranko ẹhànnà tí yóò kún ibẹ̀. Àwọn wọ̀nyí yóò ní àwọn ẹran apẹranjẹ, irú bíi kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, nínú. (1 Awọn Ọba 13:24-28; 2 Awọn Ọba 17:25, 26; Orin Solomoni 4:8) Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì yóò gbójú fo béárì, tí ó ní agbára láti pa ọkùnrin, obìnrin tàbí ọmọdé jẹ. (1 Samueli 17:34-37; 2 Awọn Ọba 2:24; Owe 17:12) A kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti mẹ́nu kan àwọn paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró mìíràn, tàbí àkéekèe. (Genesisi 49:17; Deuteronomi 32:33; Jobu 20:16; Orin Dafidi 58:4; 140:3; Luku 10:19) Ká ní o wà pẹ̀lú àwọn Júù tí ń padà bọ̀ láti Babiloni ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ó ṣeé ṣe kí o ti lọ́ tìkọ̀ láti rìn ní irú agbègbè bẹ́ẹ̀. Ibẹ̀ kì í ṣe paradise rárá nígbà tí wọ́n dé.
9. Ìdí wo ni àwọn tí wọ́n padà ní fún ìrètí àti ìgbọ́kànlé?
9 Síbẹ̀, Jehofa fúnra rẹ̀ ti ṣamọ̀nà àwọn olùjọsìn rẹ̀ wá sí ilé, ó sì ní agbára láti yí ipò ìdahoro padà pátápátá. O ha gbà pé Ẹlẹ́dàá náà lè ṣe ìyẹn bí? (Jobu 42:2; Jeremiah 32:17, 21, 27, 37, 41) Nítorí náà, kí ni òun yóò ṣe—kí ni ó ṣe—fún àwọn Júù tí ń padà àti fún ilẹ̀ wọn? Ipa wo ni èyí ní lórí àwọn ènìyàn Ọlọrun lóde òní àti lórí ipò tìrẹ—ní lọ́ọ́lọ́ọ́ àti ní ọjọ́ ọ̀la? Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ kí a wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún.
Ẹ Kún fún Ìdùnnú-Ayọ̀ Nítorí Ipò Tí Ó Yí Padà
10. Ìyípadà wo ni Isaiah 35:1, 2 sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?
10 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí Kirusi bá yọ̀ǹda fún àwọn Júù láti padà sí ilẹ̀ tí ó ti di ahoro yẹn? Ka àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá náà nínú Isaiah 35:1, 2: “Aginjù àti ilẹ̀ gbígbẹ yóò yọ̀ fún wọn; ijù yóò yọ̀, yóò sì tanná bíi lílì. Ní títanná yóò tanná; yóò sì yọ̀ àní pẹ̀lú ayọ̀ àti orin: ògo Lebanoni ni a óò fi fún un, ẹwà Karmeli òun Ṣaroni; wọn óò rí ògo Oluwa, àti ẹwà Ọlọrun wa.”
11. Ìmọ̀ wo tí Isaiah ti ní nípa ilẹ̀ náà ni ó lò?
11 Ní àkókò tí a kọ Bibeli, a mọ Lebanoni, Karmeli, àti Ṣaroni mọ ẹwà wọn títutù yọ̀yọ̀. (1 Kronika 5:16; 27:29; 2 Kronika 26:10; Orin Solomoni 2:1; 4:15; Hosea 14:5-7) Isaiah lo àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyẹn láti júwe bí ilẹ̀ tí a yí padà náà yóò ṣe rí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun. Ṣùgbọ́n, èyí yóò ha nípa lórí ilẹ̀ lásán bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ kọ́!
12. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé, àsọtẹ́lẹ̀ inú Isaiah orí 35 dá lé àwọn ènìyàn lórí?
12 Isaiah 35:2 sọ nípa ilẹ̀ náà pé, “yóò sì yọ̀ àní pẹ̀lú ayọ̀ àti orin.” A mọ̀ pé ilẹ̀ àti àwọn ewéko kò ‘yọ̀ pẹ̀lú ayọ̀’ tí ó ṣeé fojú rí. Síbẹ̀, yíyí wọn padà láti di ọlọ́ràá àti amésojáde lè mú kí àwọn ènìyàn nímọ̀lára lọ́nà yẹn. (Lefitiku 23:37-40; Deuteronomi 16:15; Orin Dafidi 126:5, 6; Isaiah 16:10; Jeremiah 25:30; 48:33) Ìyípadà tí ó ṣeé fojú rí nínú ilẹ̀ náà yóò ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìyípadà nínú àwọn ènìyàn náà, nítorí pé àwọn ènìyàn ni àsọtẹ́lẹ̀ náà dá lé lórí. Nítorí náà, a ní ìdí láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah bí èyí tí ó darí àfiyèsí ní pàtàkì sórí àwọn ìyípadà nínú àwọn Júù tí wọ́n padà, pàápàá ní pàtàkì ìdùnnú-ayọ̀ wọn.
13, 14. Ìyípadà wo nínú àwọn ènìyàn ni Isaiah 35:3, 4 sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?
13 Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ẹ jẹ́ kí a gbé púpọ̀ sí i nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá yìí yẹ̀ wò, láti lè rí bí ó ṣe ní ìmúṣẹ lẹ́yìn òmìnira àwọn Júù àti ìpadàbọ̀ wọn láti Babiloni. Ní ẹsẹ 3 àti 4, Isaiah sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìyípadà míràn nínú àwọn tí wọ́n padà pé: “Ẹ mú ọwọ́ àìlera le, ẹ sì mú eékún àìlera lókun. Ẹ sọ fún àwọn aláìláyà pé, ẹ tújú ká, ẹ má bẹ̀rù: wò ó, Ọlọrun yín óò wá ti òun ti ẹ̀san, Ọlọrun ti òun ti ìgbẹ̀san; òun yóò wá, yóò sì gbà yín.”
14 Kò ha fún wa lókun láti ronú pé Ọlọrun wa, ẹni tí ó lè yí ipò ìdahoro ilẹ̀ padà, lọ́kàn-ìfẹ́ tó bẹ́ẹ̀ nínú àwọn olùjọsìn rẹ̀ bí? Kò fẹ́ kí àwọn Júù tí a kó nígbèkùn náà ṣàárẹ̀, rẹ̀wẹ̀sì, tàbí ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la. (Heberu 12:12) Ronú nípa ipò àwọn Júù tí a kó nígbèkùn wọ̀nyẹn. Bí kò bá sí ti ìrètí tí wọ́n lè rí nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọrun nípa ọjọ́ ọ̀la ni, ì bá ti ṣòro fún wọn láti ní ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára. Ńṣe ni ó dà bíi pé wọ́n wà nínú àjàalẹ̀ tí ó ṣókùnkùn biribiri, tí wọn kò lómìnira láti rìn kiri, kí wọ́n sì jẹ́ aláápọn nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa. Lójú wọn, ó ti lè dà bíi pé kò sí ìmọ́lẹ̀ kankan níwájú wọn.—Fi wé Deuteronomi 28:29; Isaiah 59:10.
15, 16. (a) Kí ni a lè parí èrò sí pé Jehofa ṣe fún àwọn tí ó padà? (b) Èé ṣe tí àwọn tí ó padà kò fi ní láti retí iṣẹ́ ìyanu oníwòsàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí ni Ọlọrun ṣe ní ìbámu pẹ̀lú Isaiah 35:5, 6?
15 Ṣùgbọ́n, ẹ wo bí èyí ti ṣe yí padà nígbà tí Jehofa mú kí Kirusi tú wọn sílẹ̀ láti padà sílé! Kò sí ẹ̀rí kankan nínú Bibeli pé nípa iṣẹ́ ìyanu, Ọlọrun la ojú Júù kankan tí ó padà, ṣí etí adití èyíkéyìí, tàbí wo ẹsẹ̀ èyíkéyìí tí ó ti rọ tàbí tí ó ti gé sọnù sàn. Ṣùgbọ́n, ní ti gidi, ó ṣe ohun tí ó kọ yọyọ ju ìyẹn lọ. Ó mú wọn padà bọ̀ sínú ìmọ́lẹ̀ àti òmìnira ilẹ̀ wọn ọ̀wọ́n.
16 Kò sí ẹ̀rí kankan pé, àwọn tí ó padà náà retí kí Jehofa ṣe irú iṣẹ́ ìyanu oníwòsàn nípa ti ara bẹ́ẹ̀. Wọn ti ní láti mọ̀ pé Ọlọrun kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún Isaaki, Samsoni, tàbí Eli. (Genesisi 27:1; Onidajọ 16:21, 26-30; 1 Samueli 3:2-8; 4:15) Àmọ́ bí wọ́n bá retí àtúnṣe ipò wọn látọ̀runwá lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, a kò já wọn kulẹ̀. Dájúdájú, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ẹsẹ 5 àti 6 rí ìmúṣẹ tòótọ́. Isaiah ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó péye pé: “Nígbà náà ni ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití yóò sì ṣí. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò kọrin.”
Sísọ Ilẹ̀ Náà Di Paradise
17. Àwọn ìyípadà tí ó ṣeé fojú rí wo ni ó hàn gbangba pé Jehofa mú wa?
17 Dájúdájú, àwọn tí wọ́n padà náà yóò ti ní ìdí láti ké jáde pẹ̀lú ìdùnnú nítorí irú àwọn ipò tí Isaiah ń bá a nìṣó láti júwe pé: “Nítorí omi yóò tú jáde ní aginjù, àti ìṣàn omi ní ijù. Ilẹ̀ yíyan yóò sì di àbàtà, àti ilẹ̀ òǹgbẹ yóò di ìsun omi; ní ibùgbé àwọn diragoni, níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀, ni óò jẹ́ ọgbà fún eésú òun ìyè.” (Isaiah 35:6b, 7) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a lè máà rí i lórí ẹkùn náà látòkèdélẹ̀ lónìí, ẹ̀rí náà fi hàn pé, agbègbè tí ó jẹ́ Judah nígbà kan rí, jẹ́ “pápá paradise.”a
18. Báwo ni ó ti ṣeé ṣe kí àwọn Júù tí ó padà ti dáhùn padà sí àwọn ìbùkún Ọlọrun?
18 Ní ti àwọn ohun tí ó fa ìdùnnú-ayọ̀, ronú nípa bí ìmọ̀lára àwọn àṣẹ́kù Júù yóò ti rí nígbà tí a dá wọn padà sí Ilẹ̀ Ìlérí! Wọ́n ní àǹfààní láti gba ilẹ̀ tí ó ti di ahoro náà, tí àwọn ọ̀wàwà àti ẹranko mìíràn bẹ́ẹ̀ ń gbé, kí wọ́n sì yí i padà. Ìwọ kì yóò ha rí ìdùnnú-ayọ̀ nínú ṣíṣe irú iṣẹ́ imúpadàbọ̀sípò bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì bí o bá mọ̀ pé Ọlọrun ń bù kún ìsapá rẹ?
19. Ní ọ̀nà wo ni pípadà láti ìgbèkùn Babiloni fi jẹ́ pẹ̀lú ipò àfilélẹ̀?
19 Ṣùgbọ́n, kì í wulẹ̀ ṣe pé, gbogbo àwọn Júù tí a kó ní ìgbèkùn ní Babiloni tàbí tí ó padà, ni ó nípìn-ín nínú ìyípadà onídùnnú-ayọ̀ yẹn. Ọlọrun gbé àwọn ohun àbéèrèfún kalẹ̀. Kò sí ẹni tí àwọn àṣà ìsìn ìbọ̀rìṣà Babiloni ti kó èérí bá, tí ó ní ẹ̀tọ́ láti padà. (Danieli 5:1, 4, 22, 23; Isaiah 52:11) Bẹ́ẹ̀ sì ni ẹnikẹ́ni tí ó fi ìwà òmùgọ̀ lépa ọ̀nà tí kò bọ́gbọ́n mu kò lè padà. Gbogbo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni kò tóótun. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tí ó dójú ìwọ̀n ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun, tí ó kà sí mímọ́ lọ́nà tí ó láàlà, lè padà sí Judah. Wọ́n lè rin ìrìn àjò bíi pé Ọ̀nà Ìwà Mímọ́ ni wọ́n ń rìn. Isaiah mú ìyẹn ṣe kedere ní ẹsẹ 8 pé: “Òpópó kan yóò sì wà níbẹ̀, àti ọ̀nà kan, a óò sì máa pè é ní, Ọ̀nà ìwà mímọ́; aláìmọ́ kì yóò kọjá níbẹ̀; nítorí òun óò wà pẹ̀lú wọn: àwọn èrò ọ̀nà náà, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ òpè, wọn kì yóò ṣì í.”
20. Kí ni àwọn Júù kò ní láti bẹ̀rù bí wọ́n ti ń padà, kí sì ni ó yọrí sí?
20 Kò sí ìdí fún àwọn Júù tí ń padà náà láti bẹ̀rù pé àwọn ènìyàn oníwà-bí-ẹranko tàbí àwọn agbo onísùnmọ̀mí yóò kọlù wọ́n. Èé ṣe? Nítorí pé, Jehofa kì yóò gba irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ láyè láti wà ní Ọ̀nà yẹn pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ti rà padà. Nítorí náà, wọ́n lè rin ìrìn àjò náà pẹ̀lú ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tí ó kún fún ìdùnnú-ayọ̀ àti ìfojúsọ́nà aláyọ̀. Ṣàkíyèsí bí Isaiah ṣe kásẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí nílẹ̀ pé: “Kìnnìún kì yóò sí níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹranko búburú kì yóò gùn ún, a kì yóò rí i níbẹ̀; ṣùgbọ́n àwọn tí a rà padà ni yóò máa rìn níbẹ̀: Àwọn ẹni ìràpadà Oluwa yóò padà, wọn óò wá sí Sioni ti àwọn ti orin, ayọ̀ àìnípẹ̀kun yóò sì wà ní orí wọn: wọn óò rí ayọ̀ àti inú dídùn gbà, ìkáàánú òun ìmí-ẹ̀dùn yóò sì fò lọ.”—Isaiah 35:9, 10.
21. Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwa lónìí wo ìmúṣẹ Isaiah orí 35 tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?
21 Ẹ wo irú àsọtẹ́lẹ̀ alápèjúwe, tí a ní níhìn-ín! Ṣùgbọ́n, kò yẹ kí a fi ojú wo èyí gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìtàn àtijọ́ lásán, bíi pé ó jẹ́ ìtàn olóyinmọmọ kan tí kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ipò wa tàbí ọjọ́ ọ̀la wa. Òtítọ́ náà ni pé, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ kíkàmàmà láàárín àwọn ènìyàn Ọlọrun lónìí, nítorí náà, ní tòótọ́, ó kàn wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ó pèsè ìdí tí ó yè kooro fún wa láti ké jáde fún ìdùnnú-ayọ̀. A sọ̀rọ̀ lórí àwọn apá wọ̀nyí tí ó kan ìgbésí ayé rẹ nísinsìnyí àti ní ọjọ́ ọ̀la nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti inú ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa ẹkùn náà, onímọ̀ nípa ọ̀gbìn àti àbójútó ilẹ̀, Walter C. Lowdermilk (tí ń ṣojú fún Ètò Àjọ Tí Ń Bójú Tó Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè) parí èrò pé: “Ilẹ̀ yìí ti fìgbà kan rí jẹ́ pápá paradise.” Ó tún fi hàn pé, ojú ọjọ́ tí ó wà níbẹ̀ kò tí ì yí padà ní pàtàkì “láti àkókò àwọn ará Romu wá,” àti pé “‘aṣálẹ̀’ náà tí ó gba ibi tí ó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá nígbà kan rí, jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn, kì í ṣe ti ìṣẹ̀dá.”
Ìwọ́ Ha Rántí Bí?
◻ Nígbà wo ni Isaiah orí 35 ní ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́?
◻ Kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ti àsọtẹ́lẹ̀ náà?
◻ Báwo ni Jehofa ṣe mú Isaiah 35:5, 6 ṣẹ?
◻ Àwọn ìyípadà wo nínú ilẹ̀ náà àti ipò wọn ni àwọn Júù tí ó padà ní ìrírí rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn òkìtì àlàpà Petra, ní agbègbè ibi tí àwọn ará Edomu gbé nígbà kan rí
[Credit Line]
Garo Nalbandian
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Nígbà tí àwọn Júù wà ní ìgbèkùn, púpọ̀ nínú ilẹ̀ Judah dà bí aginjù, tí ó kún fún àwọn ẹranko rírorò, bíi béárì àti kìnnìún
[Àwọn Credit Line]
Garo Nalbandian
Béárì àti Kìnnìún: Safari-Zoo of Ramat-Gan, Tel Aviv