Di Ìgbọ́kànlé Rẹ Mú Ṣinṣin Títí Dé Òpin
FOJÚ inú wo ọkọ̀ òfuurufú kékeré kan tí ń fò gba ti ojú ọjọ́ ti kò dára. Awakọ̀ òfuurufú náà kò lè rí àwọn ohun tí ó wà nílẹ̀ mọ́. Kùrukùru ṣíṣú dùdù bò ó lójú. Kò lè ríran kọjá gíláàsì iwájú ọkọ̀ rẹ̀, síbẹ̀ ó mọ̀ dájú pé, òun lè parí ìrìn àjò òun láìséwu. Kí ni ó fa ìgbọ́kànlé rẹ̀?
Ó ní irin iṣẹ́ tí ó péye tí ó ń ràn án lọ́wọ́ láti fò la àárín òfuurufú kọjá, kí ó sì balẹ̀ sínú òkùnkùn. Bí ó ṣe ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ní pàtàkì nítòsí pápákọ̀ òfuurufú náà, iná atọ́ka ń darí rẹ̀ nípasẹ̀ ìṣiṣẹ́ mànàmáná, àwọn olùdarí ìrìnnà òfuurufú ń fi rédíò bá a sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀.
Lọ́nà àfiwéra, a lè dojú kọ ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú ìgbọ́kànlé, àní bí ipò ayé tilẹ̀ ń burú sí i lójoojúmọ́. Ìrìn àjò wa la ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí já lè gùn sí i ju bí àwọn kan ti rò lọ, ṣùgbọ́n a lè ní ìgbọ́kànlé pé, a wà lójú ọ̀nà náà àti pé a dé sí àkókò. Èé ṣe tí a fi lè ní ìdánilójú tó bẹ́ẹ̀? Nítorí pé, a ní ìtọ́sọ́nà tí ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí ohun tí ojú ẹ̀dá ènìyàn kò lè rí.
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ‘fìtílà sí ipa ọ̀nà wa,’ ó sì “dáni lójú, ó ń sọ òpè di ọlọgbọ́n.” (Orin Dafidi 19:7; 119:105) Bí iná atọ́ka tí ń fi ipa ọ̀nà tí awakọ̀ òfuurufú yóò wakọ̀ gbà hàn, lọ́nà tí ó péye, Bibeli sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la lọ́nà pípéye, ó sì fún wa ní àwọn ìtọ́ni ṣíṣe kedere láti baà lè rí i dájú pé, a dé ibi tí a ń lọ láyọ̀. Ṣùgbọ́n, láti lè jàǹfààní láti inú ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e.
Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Heberu, Paulu rọ àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ Kristian láti ‘di ìgbọ́kànlé tí wọ́n ní ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mú ṣinṣin ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in títí dé òpin.’ (Heberu 3:14) Ìgbẹ́kẹ̀lé lè mì, bí a kò bá ‘dì í mú ṣinṣin.’ Nítorí náà ìbéèrè náà dìde pé, Báwo ni a ṣe lè di ìgbọ́kànlé wa nínú Jehofa mú títí dé òpin?
Lo Ìgbàgbọ́ Rẹ
Kí awakọ̀ òfuurufú kan tó lè lo àwọn irin iṣẹ́ láti fò, tí yóò gbára lé àwọn irin iṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn olùdarí ìrìnnà òfuurufú pátápátá, ó nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ó tó àti ọ̀pọ̀ wákàtí láti fò. Lọ́nà tí ó jọra, Kristian kan ní láti máa bá a nìṣó láti lo ìgbàgbọ́ rẹ̀ kí ó baà lè di ìgbọ́kànlé rẹ̀ mú nínú ìtọ́sọ́nà Jehofa, ní pàtàkì nígbà tí àwọn àyíká ipò tí ó nira bá dìde. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Nitori a ní ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan naa irú èyí tí a kọ̀wé nipa rẹ̀ pé: ‘Mo lo ìgbàgbọ́, nitori naa mo sọ̀rọ̀,’ awa pẹlu lo ìgbàgbọ́ ati nitori naa a sọ̀rọ̀.” (2 Korinti 4:13) Nípa báyìí, nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere Ọlọrun, a ń lo ìgbàgbọ́ wa, a sì ń fún un lókun.
Magdalena, tí ó lo ọdún mẹ́rin nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ṣàlàyé ìníyelórí ìgbòkègbodò ìwàásù pé: “Màmá mi kọ́ mi pé láti lè di ìgbàgbọ́ lílágbára mú, ó ṣe kókó pé kí a bìkítà nípa ire tẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn. Mo rántí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ṣàkàwé bí ìmọ̀lára wa ṣe rí. Lẹ́yìn tí a dá wa sílẹ̀ kúrò ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ravensbrück, èmi àti màmá mi de ilé wa ní ọjọ́ Friday. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, ní ọjọ́ Sunday, a dara pọ̀ mọ́ àwọn ará wa nínú wíwàásù láti ilé dé ilé. Mo gbà gbọ́ dájú pé bí a bá pọkàn pọ̀ sórí ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Ọlọrun, àwọn ìlérí wọnnì yóò túbọ̀ jẹ́ gidi sí wa.”—Fi wé Ìṣe 5:42.
Dídi ìgbọ́kànlé wa mú ṣinṣin títí dé òpin ń béèrè ìgbòkègbodò tẹ̀mí ní àwọn ọ̀nà míràn. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ohun dídára mìíràn tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun. Bí a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Berea, tí a sì fi taápọntaápọn ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́, yóò ràn wá lọ́wọ́ ‘láti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin.’ (Heberu 6:11; Ìṣe 17:11) Ní tòótọ́, ìdákẹ́kọ̀ọ́ ń béèrè àkókò àti ìpinnu. Ó ṣeé ṣe pé, ìyẹ́n jẹ́ ìdí tí Paulu fi kìlọ̀ fún àwọn Heberu nípa ewu jíjẹ́ “onílọ̀ọ́ra,” tàbí onímẹ̀ẹ́lẹ́, nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀.—Heberu 6:12.
Ìwà ìmẹ́lẹ́ lè ní àbájáde bíbani lẹ́rù nínú ọ̀pọ̀ apá ìgbésí ayé. Solomoni ṣàkíyèsí pé “nípa ọ̀lẹ ọwọ́, ilé a . . . máa jò.” (Oniwasu 10:18) Bó pẹ́ bó yá, òrùlé tí a kò tọ́jú yóò bẹ̀rẹ̀ sí í jò. Bí a bá dẹ ọwọ́ wa nípa tẹ̀mí, tí a sì kùnà láti di ìgbàgbọ́ wa mú, iyè méjì lè yọ́ wọlé. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ṣíṣàṣàrò déédéé lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ yóò fún ìgbàgbọ́ wa lókun, yóò sì dáàbò bò ó.—Orin Dafidi 1:2, 3.
Gbígbé Ìgbẹ́kẹ̀lé Ró Nípasẹ̀ Ìrírí
Dájúdájú, awakọ̀ òfuurufú kan ń kẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ ìrírí àti nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn irin iṣẹ́ òun ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Bákan náà, ìgbọ́kànlé wa nínú Jehofa ń dàgbà sí i nígbà tí a bá rí ẹ̀rí àbójútó onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Joṣua nírìírí ìyẹn, ó sì rán àwọn ọmọ Israeli ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ létí pé: “Ẹ̀yin . . . mọ̀ ní àyà yín gbogbo, àti ní ọkàn yín gbogbo pé, kò sí ohun kan tí ó tàsé nínú ohun rere gbogbo tí OLUWA Ọlọrun yín ti sọ ní ti yín; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣẹ fún yín, kò sì sí ohun tí ó tàsé nínú rẹ̀.”—Joṣua 23:14.
Josefina, arábìnrin adélébọ̀ kan láti Philippines, kọ́ irú ẹ̀kọ́ kan náà. Ó ṣàlàyé bí ìgbésí ayé ṣe rí ṣáájú kí ó tó rí òtítọ́ pé: “Ọkọ mi máa ń mu ọtí gan-an, nígbà tí ó bá sì mu ọtí yó, yóò bínú, yóò sì lù mí. Ìgbéyàwó wa tí kò láyọ̀ tún ní ipa lórí ọmọkùnrin wa. Èmi àti ọkọ mi ń ṣiṣẹ́, a ń gba owó tí ó jọjú, ṣùgbọ́n tẹ́tẹ́ ni a ń fi èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú owó ọ̀yà wa ta. Ọ̀rẹ́ ọkọ mi kò níye, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ń bá a ṣọ̀rẹ́ kí ó baà lè san owó ọtí wọn, àwọn kan tilẹ̀ ń rọ ọ́ lọ́tí, kí wọ́n lè wulẹ̀ fi rẹ́rìn-ín.
“Nǹkan yí padà nígbà tí a mọ Jehofa, tí a sì fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sọ́kàn. Ọkọ mi kò mu ọtí mọ́, a ti dáwọ́ tẹ́tẹ́ títa dúró, a sì ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, tí wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́. Ìgbéyàwó wa jẹ́ aláyọ̀, ọmọkùnrin wa sì ń dàgbà di ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó rẹwà. A ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí díẹ̀, ṣùgbọ́n a ní owó tí ó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìrírí ti fi hàn pé Jehofa dà bíi Bàbá onífẹ̀ẹ́, tí ó ń tọ́ wa sí ọ̀nà tí ó tọ́ ní gbogbo ìgbà.”
Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí àwọn ìsọfúnni tí wọ́n rí gbà nípasẹ̀ rédíò àti ṣíṣàyẹ̀wò irin iṣẹ́ kan, àwọn awakọ̀ òfuurufú nígbà míràn máa ń rí i pé ó yẹ kí àwọ́n tún ipa ọ̀nà àwọn ṣe. Bákan náà a lè ní láti yí ọ̀nà wa padà ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni Jehofa. “Etí rẹ̀ óò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, Èyíyìí ni ọ̀nà, ẹ máa rìn nínú rẹ̀, nígbà tí ẹ̀yín bá yí sí apá ọ̀tún, tàbí nígbà tí ẹ̀yín bá yí sí apá òsì.” (Isaiah 30:21) Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀, a ń gba ìmọ̀ràn tí ń mú wa wà lójúfò sí àwọn ewu nípa tẹ̀mí. Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí ni ẹgbẹ́ kíkó.
Ẹgbẹ́ Kíkó Lè Mú Wa Ṣáko Lọ
Ọkọ̀ òfuurufú kékeré kan lè ṣìnà bí a kò bá ṣe àwọn àtúnṣe tí ó yẹ. Bákan náà, ipa ìdarí tí ó wà lóde ń kọlu àwọn Kristian lónìí léraléra. A ń gbé nínú ayé tí ìfẹ́ ti ara jẹ lógún, níbi tí ọ̀pọ̀ ti ń yọ ṣùtì sí àwọn ìlànà tẹ̀mí, tí wọ́n ń fi ìjẹ́pàtàkì púpọ̀ sí i hàn fún owó àti adùn. Paulu kìlọ̀ fún Timoteu pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò “nira lati bálò.” (2 Timoteu 3:1-5) Ní pàtàkì, ẹgbẹ́ búburú lè nípa lórí àwọn ọ̀dọ́langba tí ń yán hànhàn fún dídi ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà àti dídi olókìkí.—2 Timoteu 2:22.
Amanda, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 17, ṣàlàyé pé: “Fún àkókò kan àwọn ọmọ kíláàsì mi bomi paná ìgbàgbọ́ mi dé ìwọ̀n àyè kan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé, ìsìn mí káni lọ́wọ́ kò, kò sì lọ́gbọ́n nínú, èyí sì bẹ̀rẹ̀ sí í kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Ṣùgbọ́n, àwọn òbí mi ràn mí lọ́wọ́ láti lóye pé àwọn ìtọ́sọ́nà Kristian ń ṣiṣẹ́ láti dáàbò bò wá dípò kíká wa lọ́wọ́ kò. Wàyí o, mo rí i pé àwọn ìlànà wọ̀nyí ń ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní ìgbésí ayé tí ń tẹ́ni lọ́rùn ju ti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ mi ọjọ́sí ní ilé ẹ̀kọ́. Mo ti kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn tí wọ́n tọ́jú mi ní ti gidi—àwọn òbí mi àti Jehofa—mo sì ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà.”
Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, a óò bá àwọn ènìyàn tí ń sọ̀rọ̀ ìṣáátá nípa èrò ìgbàgbọ́ wa pàdé. Wọ́n lè fara hàn bí ọlọ́gbọ́n féfé, ṣùgbọ́n lójú Ọlọrun, ẹni ti ara, tí kò ní ojú ìwòye tẹ̀mí ni wọ́n. (1 Korinti 2:14) Àwọn Ẹlẹ́mìí tàbítàbí, ọlọ́gbọ́n ayé jẹ́ àwùjọ tí ń nípa lórí ẹni ní Korinti ti ìgbà ayé Paulu. Ẹ̀kọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí wọ̀nyí ṣeé ṣe kí ó ti mú kí àwọn Kristian ará Korinti kan sọ ìgbàgbọ́ nù nínú ìrètí àjíǹde. (1 Korinti 15:12) Aposteli Paulu kìlọ̀ pé: “Ẹ máṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà. Awọn ẹgbẹ́ búburú a máa ba awọn àṣà-ìhùwà wíwúlò jẹ́.”—1 Korinti 15:33.
Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ rere ń fún wa lókun nípa tẹ̀mí. Láàárín ìjọ Kristian, a ní àǹfààní láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn tí ń gbé ìgbésí ayé ìgbàgbọ́. Norman, arákùnrin kan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní 1939, ṣì jẹ́ orísun ìṣírí ńláǹlà fún gbogbogbòò síbẹ̀. Kí ni ó mú kí ojú ìwòye rẹ̀ nípa tẹ̀mí ṣe rekete? Ó fèsì pé: “Àwọn ìpàdé àti ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin olùṣòtítọ́ ṣe pàtàkì. Irú ẹgbẹ́ yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti rí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ètò àjọ Ọlọrun àti ti Satani ní kedere.”
Agbára Ìtannijẹ Ọrọ̀
Brian, onírìírí awakọ̀ òfuurufú kan, ṣàlàyé pé “ó lè ṣòro fún awakọ̀ òfuurufú kan nígbà míràn láti gba àwọn irin iṣẹ́ rẹ̀ gbọ́—kìkì nítorí pé agbára ìsúnniṣe rẹ̀ kò fara mọ́ ọn. Àwọn onírìírí awakọ̀ ọmọ ogun òfuurufú ti fò ní dídorí kodò nítorí pé àwọn iná tí ó wà lórí ilẹ̀ dà bí ìràwọ̀—àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn irin iṣẹ́ wọn sọ fún wọn pé kò rí bẹ́ẹ̀.”
Lọ́nà tí ó jọra, agbára ìsúnniṣe onímọtara-ẹni-nìkan wa lè ṣì wá lọ́nà nípa tẹ̀mí. Jesu wí pé ọrọ̀ ní “agbára ìtannijẹ,” Paulu sì kìlọ̀ pé ‘ìfẹ́ owó ti mú ọ̀pọ̀ ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́.’—Marku 4:19; 1 Timoteu 6:10.
Bí iná ìtannijẹ tí ń tàn yinrin, àwọn góńgó ti ara tí ń dán yinrin lè darí wa sí ọ̀nà òdì. Kàkà tí a óò fi máa yọ̀ nínú “ìfojúsọ́nà . . . fún awọn ohun tí a ń retí,” a lè fà wá kúrò lójú ọ̀nà nípasẹ̀ ṣekárími ti ayé tí ń kọjá lọ. (Heberu 11:1; 1 Johannu 2:16, 17) Bí a bá “pilẹ̀pinnu” láti gbé ìgbésí ayé ọlọ́rọ̀, a kì yóò ní àkókò kankan tí ó ṣẹ́kù fún ìdàgbàsókè nípa tẹ̀mí.—1 Timoteu 6:9; Matteu 6:24; Heberu 13:5.
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Patrick, tí ó sì ti gbéyàwó gbà pé òun àti aya òun fi àwọn góńgó tẹ̀mí rúbọ láti lè gbádùn ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ tí wọ́n ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gìnnì àti ilé aláruru nípa ìdarí lórí wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò sọ ìrètí Ìjọba náà nù, a rò pé a ṣì lè gbé ìgbésí ayé oníyọ̀tọ̀mì pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó yá, a rí i pé ayọ̀ tòótọ́ ń wá láti inú ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa àti láti inú dídàgbà nípa tẹ̀mí. Wàyí o, ìgbésí ayé wa nísinsìnyí rọrùn. A ti dín wákàtí tí a fi ń ṣiṣẹ́ kù, a sì ti di aṣáájú ọ̀nà déédéé.”
Ìgbàgbọ́ Sinmi Lórí Ọkàn-Àyà Ṣíṣí Sílẹ̀
Ọkàn-àyà ṣíṣí sílẹ̀ tún ń kó ipa pàtàkì nínú gbígbé ìgbọ́kànlé ró nínú Jehofa. Òtítọ́ ni pé, “ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà pẹlu ìdánilójú fún awọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba gbàǹgbà [tàbí, “ẹ̀rí tí ó dájú ṣáká,” àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW] awọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Heberu 11:1) Ṣùgbọ́n, láìjẹ́pé a ní ọkàn-àyà ṣíṣí sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ó máà dá wa lójú ṣáká. (Owe 18:15; Matteu 5:6) Nítorí ìdí yìí, aposteli Paulu wí pé “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.”—2 Tessalonika 3:2.
Nígbà náà, báwo ni a ṣe lè jẹ́ kí ọkàn-àyà wa, wà ní ṣíṣí sílẹ̀ sí gbogbo ẹ̀rí tí ó dájú ṣáká tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó? Nípa mímú àwọn ànímọ́ ìwà-bí-Ọlọ́run dàgbà, àwọn ànímọ́ tí ń bomi rin ìgbàgbọ́, tí ó sì ń sún un ṣiṣẹ́. Peteru rọ̀ wá láti ‘fi kún ìgbàgbọ́ wa, ìwà funfun, ìmọ̀, ìkóra-ẹni-níjàánu, ìfaradà, ìfọkànsin Ọlọrun, ìfẹ́ni ará, àti ìfẹ́.’ (2 Peteru 1:5-7; Galatia 5:22, 23) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, bí a bá gbé ìgbésí ayé anìkànjọpọ́n tàbí tí a ń fún Jehofa ní kìkì iṣẹ́ ìsìn mápòóòrọ́wọ́ọ̀mi, a kò lè retí lọ́nà tí ó lọ́gbọ́n nínú pé kí ìgbàgbọ́ wa dàgbà.
Esra “múra tán ní ọkàn rẹ̀” láti ka Ọ̀rọ̀ Jehofa àti láti fi í sílò. (Esra 7:10) Bákan náà, Mika ní ọkàn-àyà ṣíṣí sílẹ̀. “Nítorí náà èmi óò ní ìrètí sí Oluwa: èmi óò dúró de Ọlọrun ìgbàlà mi: Ọlọrun mi yóò gbọ́ tèmi.”—Mika 7:7.
Magdalena, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní ìṣáájú, pẹ̀lú fi sùúrù dúró de Jehofa. (Habakkuku 2:3) Ó wí pé: “A ti ní paradise tẹ̀mí. Èyí tí ó tẹ̀ lé e, Paradise tí a lè fojú rí, yóò dé láìpẹ́. Ní báyìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń dara pọ̀ mọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá náà. Rírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ń rọ́ wá sínú ètò àjọ Ọlọrun ń mú ọkàn mi yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.”
Wíwo Ọlọrun Ìgbàlà Wa
Dídi ìgbọ́kànlé wa mú ṣinṣin títí dé òpin ń béèrè lílo ìgbàgbọ́ wa àti fífetí sílẹ̀ dáradára sí ìtọ́sọ́nà tí a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ Jehofa àti ètò àjọ rẹ̀. Dájúdájú ó yẹ kí a sapá. Inú awakọ̀ òfuurufú kan máa ń dùn jọjọ nígbà tí ó bá balẹ̀, tí ó sì la kùrukùru ṣíṣú dùdù kọjá, lẹ́yìn ìrìn àjò gígùn kan, tí ó nira. Ilẹ̀ ayé tẹ́ rẹrẹ níwájú rẹ̀—ó tutù yọ̀yọ̀, ó sì fani mọ́ra. Ibi ìbalẹ̀sí ní pápákọ̀ òfuurufú wà nísàlẹ̀, tí ń dúró dè é láti kí i káàbọ̀.
Ìrírí amúnilọ́kànyọ̀ ń dúró dè wá pẹ̀lú. Ayé burúkú, tí ó dágùdẹ̀ yìí yóò fàyè sílẹ̀ fún ilẹ̀ ayé tuntun òdodo. Ìkíni káàbọ̀ àtọ̀runwá ń dúró dè wá. A lè gúnlẹ̀ síbẹ̀ bí a bá kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ onipsalmu náà pé: “Ìwọ ni ìrètí mi, Oluwa Ọlọrun; ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe mi. . . . Nípasẹ̀ rẹ ni ìyìn mí wà nígbà gbogbo.”—Orin Dafidi 71:5, 6.