Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Yóò ha bọ́gbọ́n mu fún Kristẹni kan láti tọ oníṣègùn ìlera ọpọlọ lọ bí?
Àwọn ìròyìn láti àwọn ilẹ̀ kan fi hàn pé, àìsàn tí ó jẹ mọ́ èrò ìmọ̀lára àti ọpọlọ ń pọ̀ sí i ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (Tímótì Kejì 3:1) Ó máa ń ṣe àwọn Kristẹni láàánú púpọ̀ nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé olúkúlùkù ni ó gbọ́dọ̀ pinnu fúnra rẹ̀, yálà láti wá ìtọ́jú fún àìsàn rẹ̀ àti, bí yóò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, irú ìtọ́jú tí yóò gbà.a “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Àwọn kan tí àrùn ọpọlọ dídàrú, ìsínwín amúnirẹ́rìn-ín wẹ̀sìwẹ̀sì, ìsoríkọ́ tí ń múni ṣìwà hù, àìsàn àìlékóra-ẹni-níjàánu tí kò ṣeé ṣàkóso, àìsàn amúniṣera-ẹni-léṣe, àti àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ mìíràn tí ń fa ìrora ọkàn ti bá jà, ti lè gbé ìgbésí ayé tí ó sàn díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ìrànwọ́ tí ó tọ́ lọ́dọ̀ àwọn amọṣẹ́dunjú.
Ní àwọn ibì kan, ó ti di àṣà láti máa wá ìtọ́jú. Nínú ọ̀pọ̀ ọ̀ràn, kì í ṣe ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ ni ń yọ agbàtọ́jú náà lẹ́nu, ṣùgbọ́n ìṣòro kíkojú àwọn ipò kan nínú ìgbésí ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì ni ó ń fúnni ní ìrànwọ́ tí ó gbéṣẹ́ jù lọ nínú yíyanjú àwọn ìṣòro tí ó nira nínú ìgbésí ayé. (Orin Dáfídì 119:28, 143) Nípasẹ̀ Bíbélì, Jèhófà fúnni ní ọgbọ́n, agbára ìrònú, àti ìmọ̀ tòótọ́—àwọn nǹkan tí ń fún wa lókun ní ti ọpọlọ àti ìmọ̀lára. (Òwe 2:1-11; Hébérù 13:6) Àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tí kò bọ́gbọ́n mu nígbà míràn, nítorí ìdàrúdàpọ̀ líle koko tí inú lọ́hùn-ún. (Jóòbù 6:2, 3) Jákọ́bù 5:13-16 fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ níṣìírí láti ké sí àwọn alàgbà fún ìrànlọ́wọ́ àti ìmọ̀ràn. Kristẹni kan lè máa ṣàìsàn nípa tẹ̀mí, tàbí kí ipò kan tí kò ṣeé yí padà tàbí másùn máwo aninilára kó ìdààmú bá a, ó sì lè nímọ̀lára pé a kò fi ìdájọ́ òdodo bá òun lò. (Oníwàásù 7:7; Aísáyà 32:2; Kọ́ríńtì Kejì 12:7-10) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà lọ́dọ̀ àwọn alàgbà, àwọn tí yóò ‘fi òróró pa á lórí’—ìyẹn ni pé, wọn yóò fi òye gbin ìmọ̀ràn Bíbélì tí ń tuni nínú sí i lọ́kàn—wọn yóò sì “gbàdúrà lé e lórí.” Kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí rẹ̀? “Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde [láti inú ipò àìnírètí rẹ̀ tàbí ìmọ̀lára rẹ̀ pé Ọlọ́run ti pa òun tì].”
Ṣùgbọ́n, bí wàhálà àti ìpòrúurùu ọpọlọ ẹnì kan bá ń bá a lọ láìka ìrànlọ́wọ́ tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí ń fúnni sí ńkọ́? Àwọn kan tí wọ́n wà ní ipò yìí ti yàn láti lọ ṣàyẹ̀wò ara wọn kúnnákúnná. (Fi wé Òwe 14:30; 16:24; Kọ́ríńtì Kìíní 12:26.) Ìṣòro kan nínú ara lè jẹ́ okùnfà wàhálà èrò ìmọ̀lára tàbí ti ọpọlọ. Yíyanjú irú ìṣòrò bẹ́ẹ̀ ti pèsè ìtura fún ẹni tí ń ṣàìsàn èrò ìmọ̀lára náà.b Bí a kò bá rí ìṣòro kankan nínú ara rẹ̀, dókítà náà lè dábàá wíwà ìtọ́jú lọ sọ́dọ̀ amọṣẹ́-ìṣètọ́jú-ilera-ọpọlọ-dunjú, tí a bá béèrè fún un. Nígbà náà, kí ni a lè ṣe? Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ, ìpinnu tí olúkúlùkù ní láti gbé yẹ̀ wò fúnra rẹ̀ ni èyí. Àwọn mìíràn kò ní láti ṣe lámèyítọ́ tàbí dáni lẹ́jọ́.—Róòmù 14:4.
Síbẹ̀síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ lo ọgbọ́n ṣíṣeé múlò, kí a sì ṣọ́ra láti má ṣe gbàgbé àwọn ìlànà Bíbélì. (Òwe 3:21; Oníwàásù 12:13) Nínú ọ̀ràn àìsàn ti ara, àwọn agbàtọ́jú ní yíyàn nípa onírúurú ìtọ́jú tí wọ́n bá fẹ́, láti orí ìṣègùn ìbílẹ̀ títí dé ọ̀nà ìgbàtọ́jú bíi lílo àwọn ohun ìṣẹ̀dá àti èyí tí a lè fojú rí, lílo abẹ́rẹ́ akupọ́ńṣọ̀, àti ìfegbòogi-bíntín-ṣèwòsàn. Onírúurú àwọn oníṣègùn ìlera ọpọlọ ni ó wà pẹ̀lú. Lára wọn ni àwọn afìrònú-aláìsàn-ṣèwòsàn àti àwọn mìíràn tí ó jẹ́ pé wọ́n lè wádìí dé inú ìtàn agbàtọ́jú náà, láti gbìyànjú láti mọ ìdí tí ìwà rẹ̀ fi ń ṣe ségesège, tàbí tí ó fi ń ní èrò ìmọ̀lára tí ń bà á nínú jẹ́. Àwọn olùfìwà-ṣètọ́jú-àrùn-ọpọlọ lè gbìyànjú láti ran agbàtọ́jú náà lọ́wọ́ láti kọ́ ìlànà ìwà tuntun. Àwọn oníṣègùn ìlera ọpọlọ kan gbà gbọ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àìsàn ọpọlọ ni a lè fi egbòogi wòsàn.c A ròyìn pé, àwọn mìíràn dábàá irú oúnjẹ àti fítámìn kan pàtó.
Àwọn agbàtọ́jú àti àwọn ìdílé wọn ní láti kíyè sára nígbà tí wọ́n bá ń gbé àwọn yíyàn wọ̀nyí yẹ̀ wò. (Òwe 14:15) Lọ́nà tí ó ṣe pàtàkì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Paul McHugh, olùdarí Ẹ̀ka Ìtọ́jú Àrùn Ọpọlọ àti Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Nípa Ìhùwàsí ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti Yunifásítì Johns Hopkins, sọ pé iṣẹ́ ìṣètọ́jú ìlera ọpọlọ “jẹ́ iṣẹ́ ọnà ìṣègùn tí a kò tí ì mú dàgbà. Kò rọrùn láti fi ẹ̀rí àwọn àbá rẹ̀ fún àyẹ̀wò àti ìtọ́jú ara hàn, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣiṣẹ́gbòdì apá dídíjú jù lọ nínú ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn—èrò inú àti ìṣarasíhùwà.” Ipò yìí ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìwà òdì pẹ̀lú jìbìtì, àti àwọn ìtọ́jú tí a gbé karí èrò rere tí ìpalára tí ó lè ṣe ju rere tí ó lè ṣe lọ.
Ó yẹ kí a mẹ́nu kàn án pẹ̀lú pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùtọ́jú-alárùn-ọpọlọ àti afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá ń gba oyè akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, tí wọ́n sì ń gboyè jáde, ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ń bẹ tí wọn kò ní ẹ̀rí ìtóótun kankan ní ti ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́, tí wọ́n ń gbani nímọ̀ràn, tí wọ́n sì ń ṣètọ́jú láìlọ́gàá. Àwọn kan ti ná owó rẹpẹtẹ lórí wíwá ìtọ́jú lọ sọ́dọ̀ irú àwọn ẹni tí kò tóótun bẹ́ẹ̀.
Àní nígbà tí ó bá di ti olùtọ́jú ìlera ọpọlọ tí ó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ pàápàá, àwọn ohun kan wà tí a ní láti gbé yẹ̀ wò. Nígbà tí a bá ń yan dókítà ìṣègùn tàbí oníṣẹ́ abẹ, a ní láti rí i dájú pé, yóò bọ̀wọ̀ fún ojú ìwòye wa, tí a gbé karí Bíbélì. Bákan náà, yóò léwu láti wá ìtọ́jú lọ sọ́dọ̀ olùtọ́jú ìlera ọpọlọ tí ó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kan, tí kò bọ̀wọ̀ fún ojú ìwòye wa ní ti ìsìn àti ìwà híhù. Ọ̀pọ̀ Kristẹni, láìka wàhálà ọpọlọ àti ti èrò ìmọ̀lára sí, ń làkàkà gidigidi láti ní “ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.” (Róòmù 15:5) Irú àwọn bẹ́ẹ̀ ń bìkítà lọ́nà títọ́ nípa ẹnikẹ́ni tí ó lè nípa lórí ìrònú tàbí ìṣarasíhùwà wọn. Àwọn oníṣègùn kan ka ìkálọ́wọ́kò èyíkéyìí tí ìgbàgbọ́ Ìwé Mímọ́ bá gbé kalẹ̀ bí èyí tí kò pọn dandan, tí ó sì lè ṣèpalára fún ìlera ọpọlọ. Wọ́n lè fọwọ́ sí àwọn ìwà tí Bíbélì dá lẹ́bi, irú bí ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ tàbí àìṣòótọ́ láàárín lọ́kọláya, àní kí wọ́n tilẹ̀ dábàá rẹ̀.
Àwọn èrò wọ̀nyí wà nínú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’” (Tímótì Kìíní 6:20) Wọ́n ta ko òtítọ́ nípa Kristi, wọ́n sì jẹ́ apá kan “ọgbọ́n èrò orí àti ẹ̀tàn òfìfo” ti ayé yìí. (Kólósè 2:8) Ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì ṣe kedere: “Kò sí ọlọgbọ́n, kò sí ìmòye, tàbí ìgbìmọ̀ sí Olúwa.” (Òwe 21:30) Àwọn oníṣègùn ìlera ọpọlọ, tí wọ́n bá ń pe “ibi ní rere, àti rere ní ibi” jẹ́ ẹgbẹ́ búburú. Dípò ṣíṣèrànwọ́ láti mú ọkàn tí ń dààmú lára dá, wọn yóò “ba àwọn àṣà ìhùwà wíwúlò jẹ́.”—Aísáyà 5:20; Kọ́ríńtì Kìíní 15:33.
Nítorí náà, Kristẹni kan tí ó bá rò pé ó pọn dandan láti wá ìtọ́jú lọ sọ́dọ̀ olùtọ́jú ìlera ọpọlọ tí ó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọ́ṣẹ́ ní láti yẹ ìtóótun, ìwà, àti ìfùsì oníṣègùn náà wò, àti àbájáde tí ìtọ́jú èyíkéyìí tí a bá dábàá lè ní. Bí Kristẹni kan tí wàhálà dé bá kò bá lè ṣe èyí fúnra rẹ̀, bóyá ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan tàbí ìbátan tí ó dàgbà dénú lè ṣèrànwọ́. Kristẹni kan tí kò ní ìdánilójú nípa bí ìtọ́jú kan ní pàtó ti bọ́gbọ́n mu tó lè rí i pé bíbá àwọn alàgbà inú ìjọ sọ̀rọ̀ lè ṣèrànwọ́—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó ni ìpinnu ìkẹyìn (tàbí àwọn òbí rẹ̀, tàbí ìpinnu àjùmọ̀ṣe láàárín ọkọ àti aya).d
Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣe púpọ̀ lónìí láti dín ìjìyà kù, ju bí ó ti lè ṣe ní àtijọ́ lọ. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àìsàn ní ń bẹ—ti ara àti ti ọpọlọ—tí a kò lè wòsàn ní lọ́ọ́lọ́ọ́, tí a sì ní láti fara dà jálẹ̀ ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (Jákọ́bù 5:11) Ní báyìí ná, “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú,” àwọn alàgbà, àti àwọn mìíràn nínú ìjọ ń nawọ́ ìyọ́nú sí àwọn tí ń ṣàìsàn, wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Jèhófà fúnra rẹ̀ sì ń fún wọn lókun láti fara dà á títí di àkókò ológo yẹn, nígbà tí àìsàn kì yóò sì mọ́.—Mátíù 24:45; Orin Dáfídì 41:1-3; Aísáyà 33:24.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà míràn, a lè ní kí ẹnì kan lọ yẹ agbára ìṣiṣẹ́ ọpọlọ rẹ̀ wò, bóyá nígbà tí a bá fẹ́ gbà á sí iṣẹ́ gíga kan. Yálà ẹnì kan gbà láti ṣe irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ tàbí kò gbà jẹ́ ìpinnu ara ẹni, ṣùgbọ́n a ní láti ṣàkíyèsí pé, àyẹ̀wò ọpọlọ kì í ṣe ìtọ́jú àrùn ọpọlọ.
b Wo “Jíja-àjàṣẹ́gun nínú Ìjà-ogun Lodisi Ìsoríkọ́,” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, March 1, 1990.
c Ó dà bí ẹni pé àwọn àrùn ọpọlọ kan máa ń ṣẹ́ pẹ́rẹ́ bí a bá lo egbòogi tí ó tọ́ sí i. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ lo àwọn egbòogi wọ̀nyí pẹ̀lú ìṣọ́ra lábẹ́ ìtọ́sọ́nà dókítà ìṣègùn tàbí olùtọ́jú-alárùn-ọpọlọ kan tí ó nírìírí, tí ó sì já fáfá, níwọ̀n bí àìlo egbòogi lọ́nà tí ó yẹ ti lè ní àbájáde búburú.
d Wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ìdààmú Ọpọlọ—Nigbati Ó Bá Ńpọ́n Kristian kan Lójú” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, October 15, 1988.