14 Ọlọ́gbọ́n obìnrin ń kọ́ ilé rẹ̀,+
Àmọ́ òmùgọ̀ obìnrin á fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya tirẹ̀ lulẹ̀.
2 Ẹni tó ń rìn nínú ìdúróṣinṣin ń bẹ̀rù Jèhófà,
Àmọ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ ń tàbùkù sí I.
3 Pàṣán ìgbéraga wà ní ẹnu òmùgọ̀,
Àmọ́ ètè àwọn ọlọ́gbọ́n yóò dáàbò bò wọ́n.
4 Tí kò bá sí ẹran ọ̀sìn, ibùjẹ ẹran á mọ́ tónítóní,
Àmọ́ agbára akọ màlúù máa ń mú kí ìkórè pọ̀.
5 Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ olóòótọ́ kì í parọ́,
Àmọ́ ẹlẹ́rìí èké kò lè ṣe kó má parọ́.+
6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n, kò sì rí i,
Àmọ́ ìmọ̀ máa ń wá sọ́dọ̀ àwọn olóye pẹ̀lú ìrọ̀rùn.+
7 Jìnnà sí òmùgọ̀ èèyàn,
Torí o ò ní rí ìmọ̀ ní ẹnu rẹ̀.+
8 Ọgbọ́n ni aláròjinlẹ̀ fi ń lóye ibi tí ọ̀nà rẹ̀ máa já sí,
Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ àwọn òmùgọ̀ ló ń ṣì wọ́n lọ́nà.+
9 Òmùgọ̀ ló ń da ẹ̀bi rẹ̀ sáwàdà,+
Àmọ́ àwọn adúróṣinṣin máa ń fẹ́ láti pa dà wà níṣọ̀kan.
10 Ọkàn èèyàn mọ ìbànújẹ́ rẹ̀,
Àjèjì kò sì lè pín nínú ayọ̀ rẹ̀.
11 Ilé àwọn ẹni burúkú máa pa run,+
Àmọ́ àgọ́ àwọn adúróṣinṣin máa gbilẹ̀.
12 Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó tọ́ lójú èèyàn,+
Àmọ́ nígbẹ̀yìn, á yọrí sí ikú.+
13 Èèyàn lè máa rẹ́rìn-ín, síbẹ̀ kí ọkàn rẹ̀ máa jẹ̀rora,
Ìdùnnú sì lè di ìbànújẹ́.
14 Aláìṣòótọ́ máa gba èrè àwọn ọ̀nà rẹ̀,+
Àmọ́ èèyàn rere máa gba èrè ìwà rẹ̀.+
15 Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́,
Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.+
16 Ọlọ́gbọ́n máa ń ṣọ́ra, ó sì ń yẹra fún ìwà burúkú,
Àmọ́ òmùgọ̀ kì í kíyè sára, ó sì máa ń dá ara rẹ̀ lójú jù.
17 Ẹni tó bá tètè ń bínú máa ń hùwà òmùgọ̀,+
Àmọ́ ẹni tó bá ń ro ọ̀rọ̀ wò ni aráyé ń kórìíra.
18 Aláìmọ̀kan yóò jogún ìwà òmùgọ̀,
Àmọ́ a ó fi ìmọ̀ dé àwọn aláròjinlẹ̀ ládé.+
19 Àwọn èèyàn búburú yóò tẹrí ba níwájú àwọn ẹni rere,
Àwọn èèyàn burúkú yóò sì tẹrí ba ní ẹnubodè àwọn olódodo.
20 Àwọn tó sún mọ́ tálákà pàápàá máa ń kórìíra rẹ̀,+
Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bá olówó ṣọ̀rẹ́.+
21 Ẹni tó bá ń fojú àbùkù wo ọmọnìkejì rẹ̀ ń dẹ́ṣẹ̀,
Àmọ́ ẹni tó bá ń ṣàánú aláìní jẹ́ aláyọ̀.+
22 Àwọn tó ń gbèrò ibi máa ṣìnà.
Àmọ́ àwọn tó ti pinnu láti máa ṣe rere máa rí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́.+
23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè,
Àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ń yọrí sí àìní.+
24 Adé àwọn ọlọ́gbọ́n ni ọrọ̀ wọn;
Àmọ́ ìwà àwọn òmùgọ̀ jẹ́ kìkì ẹ̀gọ̀.+
25 Ẹlẹ́rìí tòótọ́ ń gba ẹ̀mí là,
Àmọ́ ẹlẹ́tàn kò lè ṣe kó má parọ́.
26 Ìbẹ̀rù Jèhófà máa ń fọkàn ẹni balẹ̀ pẹ̀sẹ̀,+
Yóò sì jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.+
27 Ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́ orísun ìyè,
Kì í jẹ́ kéèyàn kó sínú ìdẹkùn ikú.
28 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni ògo ọba,+
Àmọ́ alákòóso tí kò ní àwọn tó ń jọba lé lórí ti ṣubú.
29 Ẹni tí kì í tètè bínú ní ìjìnlẹ̀ òye,+
Àmọ́ ẹni tí kò ní sùúrù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.+
30 Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun,
Àmọ́ owú dà bí àìsàn tó ń mú kí egungun jẹrà.+
31 Ẹni tó ń lu aláìní ní jìbìtì ń gan Ẹni tó dá a,+
Àmọ́ ẹni tó ń ṣàánú tálákà ń yìn Ín lógo.+
32 Ìwà ibi ẹni burúkú ló máa gbé e ṣubú,
Àmọ́ olódodo máa rí ààbò nítorí ìwà títọ́ rẹ̀.+
33 Inú ọkàn olóye ni ọgbọ́n fìdí kalẹ̀ sí,+
Àmọ́ àárín àwọn òmùgọ̀ ló ti máa ń fi ara rẹ̀ hàn.
34 Òdodo máa ń gbé orílẹ̀-èdè lékè,+
Àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ máa ń kó ìtìjú bá orílẹ̀-èdè.
35 Inú ọba máa ń dùn sí ìránṣẹ́ tó ń lo ìjìnlẹ̀ òye,+
Àmọ́ inú rẹ̀ máa ń ru sí èyí tó ń hùwà ìtìjú.+