Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Yin Jèhófà Lógo!
“Yin [Jèhófà, NW] ní ògo ní ilẹ̀ ìmọ́lẹ̀.”—AÍSÁYÀ 24:15.
1. Ojú wo ni àwọn wòlíì Jèhófà fi wo orúkọ rẹ̀, ìṣarasíhùwà wo sì ni ìyẹn fi yàtọ̀ sí ti inú Kirisẹ́ńdọ̀mù lónìí?
JÈHÓFÀ—orúkọ títayọ lọ́lá tí Ọlọ́run ń jẹ́! Ẹ wo bí àwọn wòlíì ìgbàanì, tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ ti kún fún ayọ̀ tó láti sọ̀rọ̀ ní orúkọ yẹn! Pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà, wọ́n yin Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ wọn lógo, ẹni tí orúkọ rẹ̀ fi í hàn gẹ́gẹ́ bí Atóbilọ́lá Olùpète. (Aísáyà 40:5; Jeremáyà 10:6, 10; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 36:23) Kódà àwọn tí a pè ní wòlíì kékeré pàápàá wà lára àwọn tí wọ́n yin Jèhófà lógo jù lọ lọ́nà tí ó dún ketekete. Ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí ni Hágáì. Nínú ìwé Hágáì, tí ó ní ẹsẹ 38 péré, a lo orúkọ Ọlọ́run nígbà 35. Irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í mọ́yán lórí mọ́ nígbà tí a bá ti fi orúkọ oyè náà “Olúwa” rọ́pò orúkọ ṣíṣeyebíye náà, Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí àwọn àpọ́sítélì adárarégèé ti Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe lò ó nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì wọn.—Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 11:5.
2, 3. (a) Báwo ni a ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ó gbàfiyèsí ṣẹ nípa ìmúpadàbọ̀sípò Ísírẹ́lì? (b) Ìdùnnú wo ni àṣẹ́kù àwọn Júù àti àwọn olùbákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn nípìn-ín nínú rẹ̀?
2 Nínú Aísáyà 12:2, a lo irú orúkọ náà lọ́nà alápá méjì.a Wòlíì náà polongo pé: “Kíyè sí i, Ọlọ́run ni ìgbàlà mi; èmi óò gbẹ́kẹ̀ lé e, èmi kì yóò sì bẹ̀rù: nítorí [Jáà Jèhófà, NW] ni agbára mi àti orin mi: òun pẹ̀lú sì di ìgbàlà mi.” (Tún wo Aísáyà 26:4, NW.) Nípa báyìí, nǹkan bí 200 ọdún ṣáájú kí a tó dá Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn Bábílónì, Jáà Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà fún wọn ní ìdálójú pé òun ni Olùgbàlà ńlá wọn. Ìgbèkùn wọn yóò jẹ́ láti ọdún 607 sí 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Aísáyà tún kọ̀wé pé: “Èmi ni [Jèhófà, NW] tí ó ṣe ohun gbogbo . . . Tí ó wí ní ti Kírúsì pé, Olùṣọ́ àgùntàn mi ni, yóò sì mú gbogbo ìfẹ́ mi ṣẹ: tí ó wí ní ti Jerúsálẹ́mù pé, A óò kọ́ ọ: àti ní ti tẹ́ńpìlì pé, A óò fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀.” Ta ni Kírúsì yìí? Lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, Ọba Kírúsì ti Páṣíà ni, ẹni tí ó ṣẹ́gun Bábílónì ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa.—Aísáyà 44:24, 28.
3 Ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Aísáyà kọ sílẹ̀, Kírúsì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà nígbèkùn pé: “Ta ni nínú yín nínú gbogbo ènìyàn rẹ̀? kí Ọlọ́run rẹ̀ kí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, tí ó wà ní Júdà, kí ó sì kọ́ ilé [Jèhófà, NW] Ọlọ́run Ísírẹ́lì, òun ni Ọlọ́run, tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù.” Àṣẹ́kù Júù tí wọ́n ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ papọ̀ pẹ̀lú àwọn Nétínímù tí wọn kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọkùnrin àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n dé sákòókò ṣíṣayẹyẹ Àsè Àgọ́ ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n sì rúbọ sí Jèhófà lórí pẹpẹ rẹ̀. Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, ní oṣù kejì, wọ́n fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì kejì lélẹ̀, pẹ̀lú igbe ìdùnnú ńlá àti ògo fún Jèhófà.—Ẹ́sírà 1:1-4; 2:1, 2, 43, 55; 3:1-6, 8, 10-13.
4. Báwo ni Aísáyà orí 35 àti 55 ṣe ní ìmúṣẹ?
4 A óò mú àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò tí Jèhófà sọ ṣẹ ní Ísírẹ́lì lọ́nà tí ó lógo pé: “Aginjù àti ilẹ̀ gbígbẹ yóò yọ̀ fún wọn; ijù yóò yọ̀, yóò sì tanná bí líílì. . . . Wọn óò rí ògo [Jèhófà, NW], àti ẹwà Ọlọ́run wa.” “Ayọ̀ ni ẹ óò fi jáde, àlàáfíà ni a óò fi tọ́ yín: àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké yóò bú sí orin níwájú yín . . . Yóò sì jẹ́ orúkọ fún [Jèhófà, NW], fún àmì ayérayé, tí a kì yóò ké kúrò.”—Aísáyà 35:1, 2; 55:12, 13.
5. Èé ṣe tí ìdùnnú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi kalẹ́?
5 Ṣùgbọ́n, ìdùnnú náà kò kalẹ́. Àwọn alámùúlégbè wọ́n wá àjọṣepọ̀ alámùúlùmálà ìgbàgbọ́ fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà. Àwọn Júù kọ́kọ́ fàáké kọ́rí, ní pípolongo pé: “Kì í ṣe fún àwa pẹ̀lú ẹ̀yin, láti jùmọ̀ kọ́ ilé fún Ọlọ́run wa; ṣùgbọ́n àwa tìkára wa ni yóò jùmọ̀ kọ́lé fún [Jèhófà, NW] Ọlọ́run Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Kírúsì ọba, ọba Páṣíà, ti pàṣẹ fún wa.” Àwọn alámùúlégbè wọ̀nyẹn wá di alátakò gbígbóná janjan báyìí. Wọ́n “mú ọwọ́ àwọn ènìyàn Júdà rọ, wọ́n sì yọ wọ́n ní ẹnu nínú kíkọ́lé náà.” Wọ́n tún parọ́ nípa bí ipò náà ṣe rí fún agbapò Kírúsì, Atasásítà, ẹni tí ó fòfin de kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà. (Ẹ́sírà 4:1-24) Iṣẹ́ náà dẹnu kọlẹ̀ fún ọdún 17. Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn Júù ṣubú sínú ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ní àkókò yẹn.
“Jèhófà Àwọn Ọmọ Ogun” Sọ̀rọ̀
6. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn pa dà sí ipò Ísírẹ́lì? (b) Èé ṣe tí ìtumọ̀ ṣíṣe kedere tí orúkọ Hágáì ní fi bá a mu wẹ́kú?
6 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà fi ‘okun àti agbára rẹ̀’ hàn fún àǹfààní Ísírẹ́lì nípa rírán àwọn wòlíì, ní pàtàkì, Hágáì àti Sekaráyà, láti mú kí àwọn Júù wà lójúfò sí ẹrù iṣẹ́ wọn. Orúkọ Hágáì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọjọ́ àsè, nítorí ó dà bíi pé ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí A Bí Lọ́jọ́ Àsè.” Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, ó bẹ̀rẹ̀ sí sàsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù Àsè Àgọ́, tí a béèrè pé kí àwọn Júù “kí ó máa yọ̀.” (Diutarónómì 16:15) Nípasẹ̀ Hágáì, Jèhófà sọ ìhìn iṣẹ́ mẹ́rin ní sáà 112 ọjọ́.—Hágáì 1:1; 2:1, 10, 20.
7. Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ Hágáì fún wa níṣìírí?
7 Nígbà tí ó ń nasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, Hágáì wí pé: “Báyìí ni [Jèhófà, NW] àwọn ọmọ ogun wí.” (Hágáì 1:2a) Ta ni “àwọn ọmọ ogun” wọ̀nyẹn lè jẹ́? Wọ́n jẹ́ ẹgbàágbèje áńgẹ́lì Jèhófà, tí a sábà máa ń tọ́ka sí nínú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí agbo ọmọ ogun. (Jóòbù 1:6; 2:1; Orin Dáfídì 103:20, 21; Mátíù 26:53) Kò ha fún wa níṣìírí lónìí pé, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fúnra rẹ̀ ń lo agbo ọmọ ogun ọ̀run tí kò ṣeé ṣẹ́gun yìí láti darí iṣẹ́ wa, ti mímú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé bí?—Fi wé Àwọn Ọba Kejì 6:15-17.
8. Ojú ìwòye wo ni ó nípa lórí Ísírẹ́lì, kí sì ni ó yọrí sí?
8 Kí ni kókó ẹ̀kọ́ ìhìn iṣẹ́ tí Hágáì kọ́kọ́ jẹ́? Àwọn ènìyàn náà ti wí pé: “Àkókò kò tí ì dé, àkókò tí à bá fi kọ́ ilé [Jèhófà, NW].” Wọn kò fi kíkọ́ tẹ́ńpìlì, tí ó dúró fún ìmúpadàbọ̀sípò ìjọsìn àtọ̀runwá, sì ipò àkọ́kọ́ mọ́. Wọ́n ti darí àfiyèsí wọn sí kíkọ́ ilé tí ó dà bí ààfin fún ara wọn. Ojú ìwòye onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ti dín ìtara ọkàn wọn fún ìjọsìn Jèhófà kù. Ní ìyọrísí rẹ̀, a ti mú ìbùkún rẹ̀ kúrò. Pápá wọn kò so èso mọ́, wọn kò sì ní ẹ̀wù fún àkókò òtútù mímú rinrin. Owó tí ń wọlé fún wọn ti di èyí tí kò tó nǹkan, ṣe ni ó sì dà bíi pé wọ́n ń fi owó sínú ajádìí àpò.—Hágáì 1:2b-6.
9. Ìṣílétí tí ó lágbára, tí ó sì ń gbéni ró wo ni Jèhófà pèsè?
9 Nígbà méjì, Jèhófà fúnni ní ìṣílétí lílágbára pé: “Ẹ kíyè sí ọ̀nà yín.” Ó ṣe kedere pé, Serubábélì, gómìnà Jerúsálẹ́mù, àti àlùfáà àgbà Jóṣúàb dáhùn pa dà, wọ́n sì fi ìgboyà fún gbogbo ènìyàn náà níṣìírí láti ‘gba ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn gbọ́, àti ọ̀rọ̀ Hágáì wòlíì, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run wọ́n ti rán an, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù níwájú Jèhófà.’ Ní àfikún sí i, ‘Hágáì ìránṣẹ́ Jèhófà jíṣẹ́ Jèhófà fún àwọn ènìyàn, pé, Èmi wà pẹ̀lú yín, ni Jèhófà wí.’—Hágáì 1:5, 7-14.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe lo agbára rẹ̀ fún àǹfààní Ísírẹ́lì?
10 Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ní Jerúsálẹ́mù ti lè rò pé ògo tẹ́ńpìlì tí a tún kọ́ náà yóò jẹ́ “asán” ní ìfiwéra pẹ̀lú tẹ́ńpìlì ti tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní nǹkan bí ọjọ́ 51 lẹ́yìn náà, Jèhófà sún Hágáì láti polongo ìhìn iṣẹ́ kejì. Ó pòkìkí pé: ‘Múra gírí, Ìwọ Serubábélì, ni Jèhófà wí, kí o sì múra gírí, Ìwọ Jóṣúà, ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà; ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà, ni Jèhófà wí, kí ẹ sì ṣiṣẹ́: nítorí èmí wà pẹ̀lú yín, ni Jèhófà àwọn ọmọ ogun wí. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’ Jèhófà, ẹni tí yóò lo agbára ńláǹlà rẹ̀ nígbà tí àkókò bá tó láti ‘mi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,’ yóò rí sí i pé gbogbo àtakò, àní ìfòfindè láti ọwọ́ ilẹ̀ ọba kan, ni a ṣẹ́pá. Láàárín ọdún márùn-ún, a mú kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà wá sí ìparí kíkọyọyọ.—Hágáì 2:3-6.
11. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi ‘ògo tí ó pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ’ kún tẹ́ńpìlì kejì?
11 A mú ìlérí kan tí ó gbàfiyèsí ṣẹ: “‘Àwọn ohun fífani lọ́kàn mọ́ra ti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì jáde wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí,’ ni Jèhófà àwọn ọmọ ogun wí.” (Hágáì 2:7, NW) “Àwọn ohun fífani lọ́kàn mọ́ra” wọ̀nyẹn jẹ́ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n wá jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì yẹn, bí ó ṣe ń fi ògo wíwà níbẹ̀ rẹ̀ ọlọ́lá ńlá hàn. Báwo ni a ṣe lè fi tẹ́ńpìlì tí a tún kọ́ yìí wéra pẹ̀lú èyí tí a kọ́ ní ọjọ́ Sólómọ́nì? Wòlíì Ọlọ́run polongo pé: ‘Ògo ilé ìkẹyìn yí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ, ni Jèhófà àwọn ọmọ ogun wí.’ (Hágáì 2:9) Nínú ìmúṣẹ àkọ́kọ́ tí àsọtẹ́lẹ̀ náà ní, tẹ́ńpìlì tí a tún kọ́ náà wà pẹ́ ju ilé ìṣáájú lọ. Ó ṣì wà títí di ìgbà tí Mèsáyà fara hàn ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Síwájú sí i, ṣáájú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ apẹ̀yìndà tó ṣìkà pa á ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Mèsáyà fúnra rẹ̀ mú ògo wá fún un nígbà tí ó wàásù òtítọ́ níbẹ̀.
12. Ète wo ni àwọn tẹ́ńpìlì méjì àkọ́kọ́ ṣiṣẹ́ fún?
12 Tẹ́ńpìlì àkọ́kọ́ àti ìkejì ní Jerúsálẹ́mù ṣiṣẹ́ fún ète pàtàkì kan, ní dídúró fún àwọn apá pàtàkì ti iṣẹ́ ìsìn àlùfáà tí Mèsáyà yóò ṣe àti ní mímú kí ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà máa bá a nìṣó ní ilẹ̀ ayé, títí di ìgbà tí Mèsáyà yóò fara hàn ní ti gidi.—Hébérù 10:1.
Tẹ́ńpìlì Tẹ̀mí Ológo
13. (a) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ní ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ni ó ṣẹlẹ̀ láti ọdún 29 sí ọdún 33 Sànmánì Tiwa? (b) Ipa pàtàkì wo ni ẹbọ ìràpadà Jésù kó nínú àwọn ìdàgbàsókè yí?
13 Àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò tí Hágáì sọ ha ní ìtumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ fún ẹ̀yìnwá ọ̀la bí? Dájúdájú, ó ṣe bẹ́ẹ̀! Tẹ́ńpìlì tí a tún kọ́ ní Jerúsálẹ́mù di àárín gbùngbùn ìjọsìn tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n ó dúró fún tẹ́ńpìlì tẹ̀mí kan tí ó tún lógo jù ú lọ fíìfíì. Èyí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa, nígbà tí, Jèhófà fòróró yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, nígbà tí a batisí Jésù ní odò Jọ́dánì, tí ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e lórí gẹ́gẹ́ bí àdàbà. (Mátíù 3:16) Lẹ́yìn tí Jésù ti parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ti ilẹ̀ ayé nínú ikú ìrúbọ, a jí i dìde sí ọ̀run, ibi tí Ibi Mímọ́ Jù Lọ inú tẹ́ńpìlì yẹn ń ṣàpẹẹrẹ, níbẹ̀ ni ó sì ti gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ kalẹ̀ fún Jèhófà. Ìtóye ẹbọ yìí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà, ní bíbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ó sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún fífi òróró yàn wọ́n, ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ọmọ abẹ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Jèhófà. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn tí wọ́n fòtítọ́ ṣe títí dójú ikú nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì náà lórí ilẹ̀ ayé yóò yọrí sí àjíǹde sí ọ̀run ní ọjọ́ ọ̀la, fún iṣẹ́ ìsìn àlùfáà tí ń bá a nìṣó.
14. (a) Ìdùnnú wo ni ó bá ìgbòkègbodò onítara ti ìjọ Kristẹni ìjímìjí rìn? (b) Èé ṣe tí ìdùnnú yìí kò fi kalẹ́?
14 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù tí wọ́n ronú pìwà dà—àti lẹ́yìn náà àwọn Kèfèrí—rọ́ wá sínú ìjọ Kristẹni yẹn, wọ́n sì lọ́wọ́ nínú pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí ń bọ̀ láti ṣàkóso ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn nǹkan bí 30 ọdún, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lè sọ pé, a ti wàásù ìhìn rere náà “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kólósè 1:23) Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, ìpẹ̀yìndà ńláǹlà kan bẹ̀rẹ̀, iná òtítọ́ sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bùlàbùlà. Ẹ̀mí dídá ẹ̀ya ìjọ sílẹ̀ tí ó gbilẹ̀ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù, èyí tí a gbé karí ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà àti ọgbọ́n ìmọ̀ ọ̀ràn, bo ojúlówó ìsìn Kristẹni mọ́lẹ̀.—Ìṣe 20:29, 30.
15, 16. (a) Báwo ni a ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ ní 1914? (b) Ìkójọpọ̀ wo ni ó sàmì sí ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún àti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún?
15 Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún kọjá. Lẹ́yìn náà, ní àwọn ọdún 1870, àwùjọ àwọn Kristẹni olóòótọ́ ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀. Láti inú Ìwé Mímọ́, ó ṣeé ṣe fún wọn láti tọ́ka sí ọdún náà, 1914, gẹ́gẹ́ bí èyí tí yóò sàmì sí ìparí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Àkókò yẹn ni “ìgbà” méje ìṣàpẹẹrẹ (2,520 ọdún ti ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn tí ó dà bí ẹranko) dópin pẹ̀lú gbígbé tí a gbé Kristi Jésù gorí ìtẹ́ ní ọ̀run—Ẹni náà “tí ó ni ín” gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 21:24; Dáníẹ́lì 4:25; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 21:26, 27) Ní pàtàkì láti 1919 wá, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀nyí, tí a mọ̀ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí, ti ń lọ́wọ́ nínú títan ìhìn rere Ìjọba tí ń bọ̀ náà kálẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ayé tokunratokunra. Ní 1919 ni ẹgbẹ̀rún mélòó kan lára àwọn wọ̀nyí dáhùn sí ìpè fún ìgbésẹ̀ náà, èyí tí a sọ ní àpéjọpọ̀ ní Cedar Point, Ohio, U.S.A. Wọ́n pọ̀ sí i ní iye títí di ọdún 1935, nígbà tí 56,153 ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá. Ní ọdún yẹn, 52,465 ti ṣàjọpín nínú búrẹ́dì àti wáìnì ìṣàpẹẹrẹ níbi Ìṣe Ìrántí ikú Jésù tí a ń ṣe ní ọdọọdún, wọ́n sì tipa báyìí fi àmì hàn pé àwọn ní ìrètí dídi àlùfáà pẹ̀lú Kristi Jésù nínú apá ti òkè ọ̀run nínú tẹ́ńpìlì ńlá nípa tẹ̀mí ti Jèhófà. Wọn yóò tún ṣiṣẹ́ sìn pẹ̀lú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ nínú Ìjọba Mèsáyà rẹ̀.—Lúùkù 22:29, 30; Róòmù 8:15-17.
16 Bí ó ti wù kí ó rí, Ìṣípayá 7:4-8 àti 14:1-4 fi hàn pé a fi àpapọ̀ iye àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí mọ sí 144,000, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni a ti kó jọ ní ọ̀rúndún kìíní, kí ìpẹ̀yìndà ńlá náà tó bẹ̀rẹ̀. Láti ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àti títí di ọ̀rúndún ogún, Jèhófà ti ń parí kíkó àwùjọ yìí jọ, àwọn tí a fi omi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fọ̀ mọ́ tónítóní, tí a polongo ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ètùtù ẹbọ Jésù, tí a sì fi èdìdì dì wọ́n nígbẹ̀yìngbẹ́yín gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró láti mú kí iye àwọn 144,000 náà pé rẹ́gí.
17. (a) Ìkójọpọ̀ wo ni ó ti bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ọdún 1930? (b) Èé ṣe tí Jòhánù 3:30 fi ṣe pàtàkì níhìn-ín? (Tún wo Lúùkù 7:28.)
17 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e nígbà tí a bá ti yan gbogbo mẹ́ńbà àwọn ẹni òróró tán? Ní 1935, ní apéjọpọ̀ mánigbàgbé kan ní Washington, D.C., U.S.A., a sọ ọ́ di mímọ̀ pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti Ìṣípayá 7:9-17 jẹ́ àwùjọ kan tí a óò dá mọ̀ “lẹ́yìn” tí a bá ti kó àwọn 144,000 jọ tán, kádàrá àwùjọ yìí sì jẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè ilẹ̀ ayé kan. Lẹ́yìn tí ó ti dá Jésù tí a fòróró yàn náà mọ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere, Jòhánù Oníbatisí, ẹni tí àjíǹde rẹ̀ yóò jẹ́ sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára “àwọn àgùntàn míràn,” sọ nípa Mèsáyà pé: “Ẹni yẹn gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní pípọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní pípẹ̀dín.” (Jòhánù 1:29; 3:30; 10:16; Mátíù 11:11) Iṣẹ́ Jòhánù Oníbatisí ti mímúra àwọn ọmọ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún Mèsáyà ti ń lọ sópin bí Jésù, nígbà náà lọ́hùn-ún, ṣe gba iṣẹ́ yíyan iye tí ń pọ̀ sí i náà tí yóò wà lára àwọn 144,000 lọ́wọ́ rẹ̀. Ní àwọn ọdún 1930, òdì kejì ìyẹn ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Iye kan tí ń dín kù sí i ni a “pè tí a sì yàn” láti wà lára àwọn 144,000 nígbà tí ó sì jẹ́ pé ìbísí ńláǹlà bẹ̀rẹ̀ nínú iye “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn míràn.” Ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i bí ètò ìgbékalẹ̀ ayé búburú ti ń sún mọ́ òpin rẹ̀ ní Amágẹ́dónì.—Ìṣípayá 17:14b.
18. (a) Èé ṣe tí a fi lè retí pẹ̀lú ìdánilójú pé “àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí ó wà láàyè nísinsìnyí kì yóò kú láé”? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a kọbi ara sí Hágáì 2:4 tìtaratìtara?
18 Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1920, ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn kan tí a gbé kalẹ̀ láti ọwọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni a pe àkòrí rẹ̀ ní “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tí Ó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kì Yóò Kú Láé.” Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, èyí ti lè gbé èrò àṣerégèé ti nǹkan yóò dára yọ. Ṣùgbọ́n lónìí, a lè sọ gbólóhùn yẹn pẹ̀lú ìdánilójú gbangba. Ìmọ́lẹ̀ tí ń túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i lórí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti rúgúdù tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé tí ń kú lọ yìí ń fi hàn gbangba pé, òpin ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì ti sún mọ́lé gidigidi! Ìròyìn Ìṣe Ìrántí fún 1996 fi hàn pé 12,921,933 ni ó pésẹ̀, lára àwọn tí 8,757 péré (.068 nínú ìpín ọ̀rún) ti fi hàn pé àwọn ní ìrètí ti ọ̀run nípa ṣíṣàjọpín nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ. Ìmúpadàbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí a dẹwọ́ wa nínú iṣẹ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni, Hágáì 2:4 sọ pé: ‘Ẹ múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà, ni Jèhófà wí, kí ẹ sì ṣiṣẹ́: nítorí èmí wà pẹ̀lú yín, ni Jèhófà àwọn ọmọ ogun wí.’ Ǹjẹ́ kí a pinnu pé kó sí ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tàbí ti ayé tí yóò bomi paná ìtara wa fún iṣẹ́ Jèhófà láé!—Jòhánù Kíní 2:15-17.
19. Báwo ni a ṣe lè nípìn-ín nínú ìmúṣẹ Hágáì 2:6, 7?
19 Ó jẹ́ ìdùnnú wa láti nípìn-ín nínú ìmúṣẹ òde òní ti Hágáì 2:6, 7 pé: ‘Báyìí ni Jèhófà àwọn ọmọ ogun wí, pé, Ẹ̀rìnkan ṣá, nígbà díẹ̀ sí i, ni èmi óò mi àwọn ọ̀run, àti ayé, àti òkun, àti ìyàngbẹ ilẹ̀. Èmi óò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè, àwọn ohun fífani lọ́kàn mọ́ra ti gbogbo orílẹ̀-èdè, yóò sì dé: èmi óò sì fi ògo kún ilé yìí, ni Jèhófà àwọn ọmọ ogun wí.’ Ìwọra, ìwà ìbàjẹ́, àti ìkórìíra ń gbalé gbòde jákèjádò ayé ní ọ̀rúndún ogún yìí. Ó ti wà nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀ ní tòótọ́, Jèhófà sì ti bẹ̀rẹ̀ sí “mì” í, nípa mímú kí Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ‘kéde ọjọ́ ẹ̀san rẹ̀.’ (Aísáyà 61:2) Mímì àkọ́kọ́ yìí yóò dé òtéńté rẹ̀ nígbà tí ìparun ayé náà bá ṣẹlẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì, ṣùgbọ́n ṣáájú ìgbà náà, Jèhófà ń kó “àwọn ohun fífani lọ́kàn mọ́ra ti gbogbo orílẹ̀-èdè” jọ fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀—àwọn ọlọ́kàn tútù, àwọn ẹni bí àgùntàn tí wọ́n ń bẹ ní ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 6:44) Nísinsìnyí, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yìí “ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀” nínú àgbàlá ilé ìjọsìn rẹ̀ ti ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 7:9, 15.
20. Níbo ni a ti lè rí ohun ìṣúra tí ó ṣeyebíye jù lọ?
20 Iṣẹ́ ìsìn nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Jèhófà ń mú èrè tí ó níye lórí ju ìṣúra ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì èyíkéyìí lọ wá. (Òwe 2:1-6; 3:13, 14; Mátíù 6:19-21) Ní àfikún sí i, Hágáì 2:9 sọ pé: ‘Ògo ilé ìkẹyìn yí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ, ni Jèhófà àwọn ọmọ ogun wí: níhìn-ín yìí ni èmi óò sì fi àlàáfíà fúnni, ni Jèhófà àwọn ọmọ ogun wí.’ Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí fún wa lónìí? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wa tí ó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A lo gbólóhùn náà “Jáà Jèhófà” fún ìtẹnumọ́ àrà ọ̀tọ̀. Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 1248.
b Jéṣúà nínú Ẹ́sírà àti àwọn ìwé inú Bíbélì míràn.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Àpẹẹrẹ àwọn wòlíì wo ni ó yẹ kí a tẹ̀ lé ní ti orúkọ Jèhófà?
◻ Ìṣírí wo ni a rí gbà láti inú ìhìn iṣẹ́ lílágbára tí Jèhófà fi ránṣẹ́ sí Ísírẹ́lì tí a mú pa dà bọ̀ sípò?
◻ Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ológo wo ni ó wà lẹ́nu iṣẹ́ lónìí?
◻ Àwọn ìkójọpọ̀ wo ni ó ti ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé ní àwọn ọ̀rúndún kọkàndínlógún àti ogún, ìfojúsọ́nà kíkọyọyọ wo sì ni èyí mú wá?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ogun ọ̀run ti Jèhófà ń darí Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ń mú wọn dúró