Mímú Òmìnira Tẹ̀mí Wá fún Àwọn Tí Wọ́n Wà ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
“A TI ń dúró dè yín.” “Fún àwọn òru bíi mélòó kan tí ó ti kọjá wọ̀nyí, mo ti lálàá pé ẹ ń bọ̀.” “Ẹ ṣeun fún yíyan ẹnì kan láti bẹ̀ wá wò déédéé.” “Inú wa dùn láti sọ ìmoore wa jáde fún gbogbo ìbùkún tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí, tí a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ àti fún oúnjẹ tẹ̀mí tí ó ń fún wa ní àkókò tí ó yẹ.”
Kí ni ó fa àwọn ọ̀rọ̀ ìmoore wọ̀nyí? Ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn tí a há mọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Mexico sọ. Wọ́n mọrírì àfiyèsí tí wọ́n ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ó ti mú òmìnira tẹ̀mí wá fún wọn, àní nígbà tí wọ́n wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n pàápàá. Ní Mexico, ọgbà ẹ̀wọ̀n 42 ń bẹ níbi tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ déédéé fún àìní tẹ̀mí àwọn tí a há mọ́ ibẹ̀. A ń pe àwọn ibi wọ̀nyí ní Centro Readaptación Social (Ibùdó Ìmúnipadàbọ̀sípò Ní Ti Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà). A máa ń ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé nínú ọ̀kan nínú àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí, ó sì ti yọrí sí rere. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìṣirò kan tí a ṣe láìpẹ́ yìí, nǹkan bí 380 ènìyàn ní ń wá sí àwọn ìpàdé ní àwọn ibi wọ̀nyí. Ní àkókò yẹn, a ń darí ìpíndọ́gba 350 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn 37 ti tóótun láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, 32 sì ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, ní fífi àmì èyí hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi.
Bí A Ṣe Ń Ṣe Iṣẹ́ Náà
Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ ní àwọn ibi wọ̀nyí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọn yóò lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá tí ń bójú tó ibẹ̀ láti béèrè fún ìwé àṣẹ láti wọnú ọgbà ẹ̀wọ̀n, ní ṣíṣàlàyé ète ìbẹ̀wò wọn—láti kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní bí wọ́n ṣe lè mú ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run lọ́nà tí inú rẹ̀ dùn sí.
Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan àwọn aláṣẹ ti fúnni ní ìyọ̀ǹda. Àwọn ọ̀gá wọ̀nyí mọrírì ìtọ́ni Bíbélì tí a ń fún àwọn tí a há mọ́. Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n ti kíyè sí i pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣègbọràn sí ìlànà ààbò tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ibi wọ̀nyí. Wọ́n ti gbà kí àwọn òjíṣẹ́ tí ń ṣèbẹ̀wò wọ̀nyí lo àwọn ọ́fíìsì, yàrá ìjẹun, àti yàrá ìṣiṣẹ́ fún ṣíṣe àwọn ìpàdé wọn. Níbì kan, a tilẹ̀ gba Àwọn Ẹlẹ́rìí láyè láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kékeré kan, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí tí alábòójútó arìnrìn-àjò ní gúúsù ìlà oòrùn Mexico sọ ṣe fi hàn.
“Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1991, a bẹ̀rẹ̀ síí ṣèbẹ̀wò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní Tehuantepec, Oaxaca, níbi tí a ti rí òùngbẹ tẹ̀mí ńláǹlà. Kò pẹ́ tí a fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 27. Lójú ìwòye ọkàn ìfẹ́ tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà fi hàn, a ṣètò fún àwọn ìpàdé ìjọ márùn-ún. Ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà, tí ó fi ìfẹ́ ńlá hàn fún Jèhófà, pinnu láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kékeré kan sínú àyíká ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, kí wọ́n baà lè rí ibi tí wọn yóò ti máa ṣèpàdé. Ó tọ alábòójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n náà lọ, ó sì béèrè fún ìyọ̀ǹda, àwọn aláṣẹ náà sì bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ gidigidi. Ní ìbẹ̀rẹ̀ December 1992, àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́fà tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìn rere. Nítorí ìtẹ̀síwájú tí wọ́n fi hàn, a ṣètò láti ṣe Ìṣe Ìrántí nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. A béèrè lọ́wọ́ alábòójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fún ìyọ̀ǹda láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ wá—búrẹ́dì àti wáìnì—lẹ́yìn ìjíròrò oníwákàtí mẹ́rin, a yọ̀ǹda fún wa.
“Ó ṣẹlẹ̀ pé ní April 3, 1993 (ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí náà), a dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀. Nígbà tí ọ̀kan tí ó jẹ́ akéde gba ìwé ìdásílẹ̀ rẹ̀, ó béèrè pé òun fẹ́ bá alábòójútó ọgbà ẹ̀wọ̀n náà sọ̀rọ̀ láti tọrọ ìyọ̀ǹda fún dídúró títí di ẹ̀yìn ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí náà. Èyí ya alábòójútó náà lẹ́nu gidigidi, níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ ìbéèrè tí ó ṣàjèjì, ṣùgbọ́n nítorí ọkàn ìfẹ́ ńláǹlà tí ẹlẹ́wọ̀n náà fi hàn sí pípésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí ní ọgbà ẹ̀wọ̀n níbẹ̀, ó gbà. Ẹni 53 ni ó pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí náà, tí wọ́n da omijé ayọ̀ lójú lẹ́yìn tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà parí. A ti fohùn ṣọ̀kan láti pe àwùjọ yìí ní ‘Freedom Cereso’ (Àwọn Olómìnira ní Cereso), nítorí pé wọ́n wà lómìnira nípa tẹ̀mí.”
A mọrírì iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gidigidi ní àwọn ibi wọ̀nyí. Nínú ọ̀kan lára àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí, ní gbangba, ẹni tí ń bójú tó ibẹ̀ dábàá lílọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “ọ̀nà ìgbàtọ́jú” fún títètè mú àwọn tí a há mọ́ pa dà bọ̀ sípò.
Ètò Ìmúnipadàbọ̀sípò Tí Ó Kẹ́sẹ Járí
Ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti yọrí sí ìmúnipadàbọ̀sípò pátápátá fún ọ̀pọ̀ ẹlẹ́wọ̀n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pé àwọn tí wọ́n ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n rí máa ń pa dà sí ìgbésí ayé ọ̀daràn, nígbà tí a bá dá wọn sílẹ̀, àwọn tí wọ́n ti tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní tòótọ́ ti yí pa dà pátápátá. Ìyípadà wọn rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Kì í ṣe àwọn àgbèrè . . . tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra ènìyàn, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀ ohun tí àwọn kan lára yín sì ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—Kọ́ríńtì Kíní 6:9-11.
Ìyípadà títayọ lọ́lá nínú àkópọ̀ ìwà wọn hàn kedere nígbà tí wọ́n sọ ìmọ̀lára wọn jáde. Miguel, tí ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Campeche ní Campeche City, sọ ọ́ lọ́nà yí: “Lónìí, mo lè fi ìdùnnú sọ pé mo ka ara mi mọ́ àwọn àgùntàn míràn tí wọ́n ní ìrètí tí a kọ sínú Pétérù Kejì 3:13 àti Mátíù 5:5.” José, tí ó wà ní Koben, ọgbà ẹ̀wọ̀n Campeche, sọ pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n, tí ẹ̀ṣẹ̀ mi sí burú púpọ̀, mo lóye pé aláàánú ni Jèhófà, ó sì ń tẹ́tí sí àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ mi. Ó lè dárí ẹ̀sẹ̀ mi jì mí, kí ó sì fún mi ní àǹfààní láti lo ìyókù ìgbésí ayé mi nínú nínípìn-ín nínú ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run. A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn alàgbà wa fún àkókò tí wọ́n ń lò láti bẹ̀ wá wò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, kí a baà lè jàǹfààní nínú àwọn ìlérí Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ wo irú ìbùkún lílárinrin tí èyí jẹ́! Mo ha lè sọ pé ẹlẹ́wọ̀n ni mí bí? Rárá o, Jèhófà ti fún mi ní òmìnira tẹ̀mí tí mo nílò.”
Kí ní ń mú kí àwọn apànìyàn, afipábánilòpọ̀, jóléjólé, olè, àti àwọn mìíràn yí pa dà láti di Kristẹni tí ń gbé ìgbésí ayé tí ó tọ́? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ọkùnrin kan náà wọ̀nyí sọ, agbára ìyínipadà ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìkẹ́gbẹ́pọ̀ rere pẹ̀lú àwọn ènìyàn olùfọkànsìn gidi ni. Ọ̀ràn Tiburcio, tí a há mọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Mazatlán, Sinaloa, fi ìkẹ́sẹjárí ètò ìmúnipadàbọ̀sípò yí hàn kedere. Ó ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Concordia, Sinaloa, ibi tí ó ti ní ìṣòro nítorí ìbínú fùfù rẹ̀. Aya rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì máa ń hùwà ìkà sí i, àní nígbà tí ó bá wá bẹ̀ ẹ́ wò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n pàápàá. Obìnrin náà mú sùúrù, kò sì dẹ́kun bíbẹ̀ ẹ́ wò, nítorí náà ọkọ rẹ̀ ní kí ó mú ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, wá fún òun, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ fúnra rẹ̀.a Lẹ́yìn náà, ó ní kí ẹnì kan máa wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n láti wá bá òun kẹ́kọ̀ọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn sì bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà sí rere. A gbé e lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Mazatlán, níbi tí àwùjọ kan tí ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà, nísinsìnyí, ó ti di akéde. Ó sọ pé: “Nísinsìnyí, pẹ̀lú aya mi àti àwọn ọmọ mi àti àwọn tí a jọ wà ní àhámọ́, mo dúpẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún mi láti tẹ́tí sí àwọn òtítọ́ Bíbélì ní ibí yìí, pẹ̀lú ìrètí pé ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́, a óò dá mi sílẹ̀, n óò sì lè lọ sí gbogbo àpéjọ àti ìpàdé ìjọ.”
Bákan náà, ẹnì kan tún ni Conrado, tí ó dúpẹ́ púpọ̀ fún àwọn ìyípadà tí ó ṣeé ṣe fún un láti ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó ní ìṣòro ìdílé tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí aya rẹ̀ fi kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Nítorí náà ó wá orísun ìtura nínú oògùn líle. Láìpẹ́, ó di oníṣòwò oògùn líle. A fàṣẹ ọba mú un, a sì rán an lẹ́wọ̀n fún kíkó igbó àti kokéènì láti ibì kan sí ibòmíràn. Nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, àwùjọ kan wà níbẹ̀ tí ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì ké sí i láti wá kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn. Ó sọ ìmọ̀lára rẹ̀ jáde lọ́nà yí pé: “Ọ̀nà tí a gbà darí àwọn ìpàdé náà létòlétò, ètò fífi àwọn ìtẹ̀jáde ṣàyẹ̀wò nǹkan, àti òtítọ́ náà pé a gbé ohun gbogbo karí Bíbélì wú mi lórí. Kíá ni mo béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé.” Ìyẹn jẹ́ ní January 1993. Nísinsìnyí, Conrado ti kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó sì ń bá a nìṣó láti máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọ Kristẹni.
Àwọn Erékùṣù Islas Marías
Ọgbà ẹ̀wọ̀n kan tí ń kò jìnnìjìnnì báni wà ní Mexico, tí ó ní erékùṣù mẹ́rin, tí a ń pè ní Islas Marías. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà lè rìnrìn-àjò káàkiri àwọn erékùṣù ìfìyàjẹni náà lórí èyí tí a há wọn mọ́. Àwọn mìíràn ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú àwọn aya àti ọmọ wọn.
A ti dá ìjọ kékeré kan sílẹ̀ níbẹ̀. Àwọn arákùnrin mẹ́ta láti Mazatlán máa ń rìnrìn-àjò lọ síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lóṣù, ní ṣíṣèrànwọ́ láti darí àwọn ìpàdé, pípèsè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, àti fífúnni ní ìṣírí. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, alábòójútó àyíká máa ń lọ láti bẹ̀ wọ́n wò. Ìpíndọ́gba iye àwọn tí ń wá jẹ́ 20 sí 25. Wọ́n ní akéde mẹ́rin tí ó ti ṣèrìbọmi àti méjì tí kò tí ì ṣèrìbọmi. Alábòójútó arìnrìn-àjò náà ròyìn pé “àwọn kan ń fẹsẹ̀ rin kìlómítà 17 [ibùsọ̀ 10] láti wá sí ìpàdé lọ́jọ́ Sunday, wọ́n sì ní láti tètè kúrò ní ìpàdé, kí wọ́n baà lè tètè dé ọgbà ẹ̀wọ̀n kí wọ́n tó pe orúkọ. Bí wọ́n bá yára rìn, ó ń gba ohun tí ó lé ní wákàtí méjì láti pa dà.” Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà, tí ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn, sọ láìpẹ́ yìí pé: “Tẹ́lẹ̀ rí, mo máa ń fẹ́ pé kí a tètè dá mi sílẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ó lè jẹ́ nígbàkígbà tí Jèhófà bá fẹ́, níwọ̀n bí mo ti ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe níhìn-ín.”
A láyọ̀ láti rí i pé òtítọ́ ń lo agbára rẹ̀ láti dá àwọn olóòótọ́ ọkàn tí ń wá ọ̀nà láti wu Jèhófà sílẹ̀. Àwọn tí ó lé ní méjìlá lára àwọn wọ̀nyí, tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, ni a ti dá sílẹ̀, tí wọ́n ti ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé tí ó lọ́lá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run nísinsìnyí, àwọn kan tilẹ̀ ti di alàgbà nínú ìjọ. A ti fi agbára tí Bíbélì ní láti wo ọkàn àyà sàn, àti láti tún àwọn ènìyàn ṣe hàn lọ́nà tí ó múni jí gìrì. Gbàrà tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, tí a há mọ́ nítorí híhùwà àìtọ́, ti wọnú ipa ọ̀nà ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n nírìírí òmìnira tòótọ́ tí Jésù ṣèlérí nígbà tí ó wí pé: “Ẹ óò sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:32; Orin Dáfídì 119:105.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọ̀pọ̀ jàǹfààní nínú òtítọ́ Kristẹni tí wọ́n kọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n