Naḥmanides—Ó Ha Fi Hàn Pé Èké Ni Ẹ̀sìn Kristẹni Bí?
SÀNMÁNÌ AGBEDEMÉJÌ. Kí ni wọ́n mú wá sọ́kàn? Ṣe Ogun Ìsìn ni? Ṣe Ìwádìí Gbógun Ti Àdámọ̀ ni? Ṣe ìdálóró ni? Bí kò tilẹ̀ jẹ́ sáà kan tí a sábà máa ń so pọ̀ mọ́ ìjíròrò ìsìn ní gbangba, ní àkókò yẹn, ní ọdún 1263, ọ̀kan nínú àwọn ìjiyàn títayọ jù lọ nínú ìtàn Europe ṣẹlẹ̀ nípa àwọn Júù àti Kristẹni. Àwọn wo ni ó kàn? Àwọn àríyànjìyan wo ni a gbé dìde? Báwo ni ó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lónìí, láti dá ìsìn tòótọ́ mọ́ yàtọ̀?
Kí Ní Tanná Ran Ìjiyàn Náà?
Jálẹ̀ Sànmánì Agbedeméjì, Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì gbé ara rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn tòótọ́. Ṣùgbọ́n, àwọn Júù kò tí ì jáwọ́ nínú jíjẹ́wọ́ pé, àwọn ni àyànfẹ́ Ọlọ́run. Àìṣeéṣe ṣọ́ọ̀ṣì náà láti yí àwọn Júù lọ́kàn pa dà nípa ìjẹ́pàtàkì yíyí ẹ̀sìn pa dà, yọrí sí ìjákulẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà sì ni ìyọrísí rẹ̀ jẹ́ ìwà ipá àti inúnibíni. Nígbà Ogun Ìsìn, ẹgbẹẹgbàarùn-ún àwọn Júù ni a pa nípakúpa tàbí ni a dáná sun lórí òpó igi, nígbà tí a ní kí wọ́n yàn láàárín batisí àti ikú. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ìkórìíra àwùjọ àwọn Júù, tí ṣọ́ọ̀ṣì súnná sí, gbalẹ̀ kan nígbà náà lọ́hùn-ún.
Ṣùgbọ́n, ẹ̀mí tí ó yàtọ̀ gbalé gbòde ní Sípéènì ti Kátólíìkì ti ọ̀rúndún kejìlá àti ìkẹtàlá. A fún àwọn Júù ní òmìnira ìsìn—níwọ̀n bí wọn kò bá ti ta ko ẹ̀sìn Kristẹni—a sì tilẹ̀ fún wọn ní ipò pàtàkì ní àgbàlá ọba. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn nǹkan bí ọ̀rúndún kan tí wọ́n ti ń jàǹfààní irú ojú rere bẹ́ẹ̀, àwọn àlùfáà ìjọ Dominic gbé ìgbésẹ̀ láti dín agbára ìdarí àwọn Júù láwùjọ kù, àti láti yí àwọn Júù pa dà sí ẹ̀sìn Kátólíìkì. Àwọn ọmọlẹ́yìn Dominic fúngun mọ́ Ọba James Kìíní ti Aragon láti ṣètò fún ìjiyàn ọlọ́lá àṣẹ, èyí tí ète rẹ̀ jẹ́ láti fẹ̀rí hàn pé gbàrọgùdù ẹ̀sìn ni ti àwọn Júù, àti pé, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo àwọn Júù yí ẹ̀sìn wọn pa dà.
Èyí kọ́ ni ìjiyàn àkọ́kọ́ láàárín àwọn Júù àti Kristẹni. Ní ọdún 1240, ìjiyàn ọlọ́lá àṣẹ kan wáyé ní Paris, ní ilẹ̀ Faransé. Olórí ète rẹ̀ ni láti ṣàyẹ̀wò Talmud, ìwé kan tí àwọn Júù kà sí mímọ́. Àmọ́, ìwọ̀nba òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ díẹ̀ ni a fún àwọn Júù tí wọ́n kópa nínú rẹ̀. Lẹ́yìn tí ṣọ́ọ̀ṣì polongo pé òun gbégbá orókè nínú ìjiyàn yí, a dáná sun ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀dà Talmud ní àwọn gbàgede.
Ṣùgbọ́n ẹ̀mí ìráragbaǹkan tí Ọba James Kìíní ti Aragon ní kò yọ̀ǹda fún irú àyẹ̀wò yẹ̀yẹ́ bẹ́ẹ̀. Ní mímọ èyí, àwọn ọmọlẹ́yìn Dominic gbìyànjú ọ̀nà míràn. Gẹ́gẹ́ bí Hyam Maccoby ti sọ ọ́ nínú ìwé rẹ̀, Judaism on Trial, wọ́n ké sí àwọn Júù fún ìjiyàn kan “ní dídíbọ́n bí ẹní yẹ́ wọn sí àti bí ẹní fọgbọ́n yí wọn lérò pa dà, dípò fífi wọ́n bú, irú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Paris.” Àwọn ọmọlẹ́yìn Dominic yan Pablo Christiani, Júù kan tí ó ti di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, tí ó sì ti di àlùfáà ìjọ Dominic, gẹ́gẹ́ bí aṣojú wọn. Nípa lílo ìmọ̀ tí Pablo Christiani ní nínú Talmud àti ìwé àwọn rábì, àwọn ọmọlẹ́yìn Dominic ní ìdánilójú pé wọ́n lè fìdí òtítọ́ ọ̀rọ̀ àwọn múlẹ̀.
Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Yan Naḥmanides?
Ògúnná gbòǹgbò kan ṣoṣo ni ó di ipò tẹ̀mí mú ní Sípéènì láti ṣojú fún àwọn Júù nínú ìjiyàn náà—Moses ben Naḥman, tàbí Naḥmanides.a A bí i ní nǹkan bí 1194, ní ìlú Gerona, láti ìgbà ọ̀dọ́langba rẹ̀ ni Naḥmanides ti fi ara rẹ̀ hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Bíbélì àti Talmud. Nígbà tí yóò fi pé ẹni 30 ọdún, ó ti kọ àwọn ìwé tí ń ṣàlàyé lórí apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú Talmud, kò pẹ́ kò jìnnà, ó di abẹnugan nínú ṣíṣe alárinà awuyewuye lórí àwọn ìwé Maimonides, tí ó fẹ́ pín àwùjọ àwọn Júù níyà.b Ní ìran rẹ̀, a ka Naḥmanides sí Júù ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ jù lọ lórí Bíbélì àti Talmud, tí ó sì ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé Maimonides nìkan ṣoṣo ni ó gba ipò iwájú lọ́wọ́ rẹ̀ ní ti agbára ìdarí tí ó ní lórí ẹ̀sìn àwọn Júù ní sáà yẹn.
Naḥmanides lo agbára ìdarí ńláǹlà lórí àwùjọ àwọn Júù ní Catalonia, Ọba James Kìíní pàápàá kàn sí i lórí onírúurú ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba. Àwọn Júù àti Kèfèrí bọ̀wọ̀ fún agbára ìrònú jíjinlẹ̀ tí ó ní. Àwọn ọmọlẹ́yìn Dominic rí i pé, láti baà lè fi àbùkù olóroǹbó kan àwọn Júù, òun, tí ó jẹ́ òléwájú nínú àwọn rábì wọn, ni àwọn yóò jẹ́ kí ó jiyàn.
Naḥmanides lọ́ tìkọ̀ láti gbà láti jiyàn, ní mímọ̀ pé, àwọn ọmọlẹ́yìn Dominic kò ní èrò kí ètò náà lọ láìṣojúsàájú. Ó ní láti máa dáhùn àwọn ìbéèrè, ṣùgbọ́n, kò lè béèrè ìbéèrè kankan. Bí ó ti wù kí ó rí, ó gbà sí ọba lẹ́nu, ní bíbèèrè pé kí a yọ̀ǹda fún òun láti sọ̀rọ̀ fàlàlà nínú ìdáhùnpadà òun. Ọba James Kìíní gbà bẹ́ẹ̀. Irú ìyọ̀ǹda bẹ́ẹ̀ fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí ó láàlà kò ṣẹlẹ̀ rí, kò sì tún ṣẹlẹ̀ mọ́ jálẹ̀ Sànmánì Agbedeméjì, ẹ̀rí kedere pé ọba kò kóyán Naḥmanides kéré. Síbẹ̀, ọkàn Naḥmanides kò balẹ̀. Bí wọ́n bá kà á sí alátakò àṣerégèé nínú ìjiyàn náà, àbájáde rẹ̀ yóò jẹ́ jàǹbá fún òun àti àwùjọ àwọn Júù. Ìwà ipá lè bẹ́ sílẹ̀ nígbàkigbà.
Naḥmanides Wàákò Pẹ̀lú Pablo Christiani
Ààfin ọba, ní Barcelona, ni ojúkò tí ìjiyàn náà ti wáyé. Ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a ṣe é—July 20, 23, 26, àti 27, 1263. Ọba fúnra rẹ̀ ni ó darí ìjókòó kọ̀ọ̀kan, àwọn ènìyàn kàǹkàkàǹkà nínú Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba, àti àwùjọ àwọn Júù àdúgbò pésẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú.
Ní ti ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n mọ ohun tí ìjiyàn náà yóò yọrí sí. Nínú àkọsílẹ̀ wọn tí a fọwọ́ sí, àwọn ọmọlẹ́yìn Dominic sọ pé, ète ìjiyàn náà ‘kì í ṣe láti jiyàn lórí ìgbàgbọ́ bí ẹni pé ó jẹ́ ọ̀ràn iyè méjì, ṣùgbọ́n kí a baà lè pa àṣìṣe àwọn Júù run, kí a sì mú ìdánilójú ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Júù kúrò.’
Bí ó tilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni 70 ọdún, Naḥmanides fi agbára ìrònú ṣíṣe kedere rẹ̀ hàn, nípa fífẹ́ láti fi ìjíròrò náà mọ sórí kìkì àwọn ọ̀ràn pàtàkì. Ó bẹ̀rẹ̀ ní sísọ pé: “Àwọn ìjiyàn [àtẹ̀yìnwá] láàárín àwọn kèfèrí àti àwọn Júù jẹ́ lórí ọ̀pọ̀ apá àṣà ìsìn, èyí tí lájorí ìlànà ìgbàgbọ́ kò sinmi lé. Ṣùgbọ́n, nínú àgbàlá ọba yìí, èmi yóò fẹ́ láti jiyàn lórí kìkì àwọn ọ̀ràn tí gbogbo awuyewuye sinmi lé lórí.” Ìgbà yẹn ni a tó gbà pé kí a fi kókó ọ̀rọ̀ náà mọ sórí, bóyá Mèsáyà náà ti wá, bóyá Ọlọ́run ni tàbí ènìyàn, àti bóyá àwọn Júù ni ó ní ojúlówó òfin lọ́wọ́ tàbí àwọn Kristẹni.
Nínú ìnasẹ̀ ìjiyàn rẹ̀, Pablo Christiani polongo pé òun yóò fẹ̀rí hàn láti inú Talmud pé Mèsáyà ti wá. Naḥmanides fèsì pé, bí ọ̀ràn náà bá rí báyìí, èé ṣe tí àwọn rábì ti wọ́n tẹ́wọ́ gba Talmud kò fi tẹ́wọ́ gba Jésù? Dípò tí yóò fi gbé àríyànjiyàn rẹ̀ karí ìrònú ṣíṣe kedere ti Ìwé Mímọ́, léraléra ni Christiani ń tọ́ka sí àwọn àyọkà dídíjú tí àwọn rábì kọ, láti fìdí ìjiyàn rẹ̀ múlẹ̀. Ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, Naḥmanides fi hàn pé, èké ni ìwọ̀nyí, nípa fífi hàn pé a ṣàyọlò wọn láìronú lórí àyíká ọ̀rọ̀ wọn. Ó bọ́gbọ́n mu pé Naḥmanides lè fi hàn pé òun dá yàtọ̀ ní ti ìdáńgájíá nínú ìjiyàn lórí àwọn ìwé wọ̀nyí, tí òun ti fi gbogbo ìgbésí ayé òun kẹ́kọ̀ọ́. Àní nígbà tí Christiani tọ́ka sí Ìwé Mímọ́ pàápàá, ìjiyàn rẹ̀ darí àfiyèsí sí àwọn kókó tí ó rọrùn láti fi hàn pé wọ́n jẹ́ èké.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbéèrè nìkan ni a yọ̀ǹda fún un láti dáhùn, ó ṣeé ṣe fún Naḥmanides láti gbé ìjiyàn lílágbára kalẹ̀, tí ó fi ìdí tí àwọn Júù àti àwọn onílàákàyè mìíràn kò fi tẹ́wọ́ gba ipò tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì dì mú. Nípa ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan, ó polongo pé: “Èrò inú Júù èyíkéyìí tàbí tí ènìyàn kankan kì yóò yọ̀ǹda fún un láti gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé . . . yóò gba inú ọlẹ̀ obìnrin Júù kan kọjá . . . tí a [óò] sì fi lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn . . . tí wọ́n pa á.” Naḥmanides sọ ní pàtó pé: “Ohun tí ẹ gbà gbọ́—tí ó sì jẹ́ ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ yín—kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún ìrònú [tí ó bọ́gbọ́n mu].”
Ní títẹnumọ́ àìṣedéédéé kan tí kò tí ì jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn Júù títí di ọjọ́ òní ronú pé ó ṣeé ṣe kí Jésù jẹ́ Mèsáyà náà, Naḥmanides tẹnu mọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lílékenkà tí ṣọ́ọ̀ṣì jẹ. Ó wí pé: “Wòlíì sọ pé ní àkókò Mèsáyà, . . . wọn yóò fi idà wọn rọ ohun èèlò ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòje; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́. Láti ọjọ́ ará Násárétì náà títí di ìsinsìnyí, gbogbo ayé ti kún fún ìwà ipá àti olè jíjà. [Ní tòótọ́], àwọn Kristẹni ta ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ sílẹ̀ ju àwọn orílẹ̀-èdè yòó kù lọ, wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla. Ẹ wo bí yóò ti ṣòro fún yín tó, olúwa mi ọba, àti àwọn ìjòyè rẹ wọ̀nyí bí wọn kò bá ní . . . kọ́ ogun jíjà mọ́!”—Aísáyà 2:4.
Lẹ́yìn ìjókòó kẹrin, ọba mú ìjiyàn náà wá sópin. Ó sọ fún Naḥmanides pé: “N kò tí ì rí ẹni tí ó fakọ yọ nínú ìjiyàn bíi tìrẹ rí.” Láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ní fífọwọ́ sọ̀yà fún Naḥmanides ní ti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti ààbò, Ọba James Kìíní ti Aragon ní kí ó máa lọ sílé, pẹ̀lú ẹ̀bùn 300 dinar. Nígbà tí bíṣọ́ọ̀bù Gerona béèrè fún un, Naḥmanides ṣàkọsílẹ̀ ìjiyàn náà.
Bí àwọn ọmọlẹ́yìn Dominic tilẹ̀ sọ pé àwọn gbégbá orókè, inú bí wọn gidigidi. Lẹ́yìn náà, wọn fẹ̀sùn kan Naḥmanides pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí ṣọ́ọ̀ṣì, ní lílo àkọsílẹ̀ tí ó ṣe nípa ìjiyàn náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Nítorí tí ojú rere tí ọba fi hàn sí Naḥmanides kò tẹ́ wọn lọ́rùn, àwọn ọmọlẹ́yìn Dominic ké gbàjarè sí Póòpù Clement Kẹrin. Bí ó tilẹ̀ ti lé ní ẹni 70 ọdún, a lé Naḥmanides kúrò ní Sípéènì.c
Ibo Ni A Ti Lè Rí Òtítọ́?
Ìjiyàn ìhà méjèèjì ha ràn wá lọ́wọ́ láti dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ bí? Níwọ̀n bí ọ̀kọ̀ọ̀kan tí tẹnu mọ́ àṣìṣe ìhà kejì, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó gbé ìhìn iṣẹ́ ṣíṣe kedere ti òtítọ́ jáde. Ohun tí Naḥmanides fi hàn pé èké ni lọ́nà tí ó rọrùn fún un dáadáa, kì í ṣe ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́, bí kò ṣe ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí ènìyàn gbé kalẹ̀, irú bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, tí Kirisẹ́ńdọ̀mù hùmọ̀ ní àwọn ọ̀rúndún lẹ́yìn Jésù. Ìwà pálapàla Kirisẹ́ńdọ̀mù àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ búburú jáì rẹ̀, tí Naḥmanides fi ìgboyà tẹnu mọ́, pẹ̀lú jẹ́ ọ̀ràn àkọsílẹ̀ tí kò ṣeé já ní koro.
Lábẹ́ àwọn ipò wọ̀nyí, kò ṣòro láti lóye ìdí tí ìjiyàn tí ó fara mọ́ ẹ̀sìn Kristẹni kò fi wú Naḥmanides àti àwọn Júù míràn lórí. Ní àfikún sí i, Pablo Christiani gbé ìjiyàn rẹ̀ karí àwọn ìwé àwọn rábì tí a ṣì lò, kò gbé e karí ìrònú ṣíṣe kedere láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.
Rárá o, Naḥmanides kò fi hàn pé èké ni ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́. Ní àkókò rẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ èké ti mú kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ti ẹ̀kọ́ Jésù àti ẹ̀rí jíjẹ́ tí ó jẹ́ Mèsáyà fara sin. Ní ti gidi, Jésù àti àwọn àpọ́sítélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìfarahàn irú àwọn ẹ̀kọ́ apẹ̀yìndà bẹ́ẹ̀.—Mátíù 7:21-23; 13:24-30, 37-43; Tímótì Kíní 4:1-3; Pétérù Kejì 2:1, 2.
Bí ó ti wù kí ó rí, a lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ kedere lónìí. Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ̀yin yóò fi dá wọn mọ̀. . . . Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde.” (Mátíù 7:16, 17) A rọ̀ ọ́ láti wá ẹ̀rí ìdámọ̀ yẹn. Jẹ́ kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìwádìí tí ó ní ète nínú, nípa àwọn ẹ̀rí tí Ìwé Mímọ́ fi hàn. Nípa báyìí, ìwọ yóò kọ́ ìtumọ̀ tòótọ́ nípa gbogbo ìlérí Ọlọ́run tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Mèsáyà náà àti ìṣàkóso rẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ Júù tọ́ka sí Naḥmanides gẹ́gẹ́ bí “Ramban,” ọ̀rọ̀ ìgékúrú aṣeésọ-dorúkọ lédè Hébérù, tí a fà yọ láti inú àwọn lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ń bẹ nínú orúkọ náà, “Rabbi Moses Ben Naḥman.”
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Maimonides—Ọkùnrin Náà Tí Ó Mú Ìsìn Júù Ṣe Kedere,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti March 1, 1995, ojú ìwé 20 sí 23.
c Ní 1267, Naḥmanides gúnlẹ̀ sí ibi tí a mọ̀ sí Ísírẹ́lì lónìí. Àwọn ọdún tí ó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀ kún fún àṣeyọrí. Ó fìdí wíwà àwọn Júù múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì dá ibùdó ìkẹ́kọ̀ọ́ kan sílẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Ó tún parí ìwé àlàyé kan lórí Torah, ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ó sì di olórí àwùjọ àwọn Júù nípa tẹ̀mí ní ìhà àríwá ìlú Acre tí ó wà ní etíkun, ibi tí ó kú sí ní 1270.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Naḥmanides fa kòmóòkun ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ ní Barcelona
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 19 sí 20: A mú un jáde láti inú Illustrirte Pracht - Bibel/Heilige Schrift des Alten und Neuen Testaments, nach der deutschen Uebersetzung D. Martin Luther’s