Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà
“Ìbùkún Olúwa ní ń múni là, kì í sì í fi làálàá pẹ̀lú rẹ̀.”—ÒWE 10:22.
1, 2. (a) Báwo ni aṣáájú ọ̀nà kan ṣe sọ ìmọ̀lára rẹ̀ jáde nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún? (b) Èé ṣe tí àwọn aṣáájú ọ̀nà fi wà ní ipò nínírìírí ayọ̀ sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn ní kíkún sí i?
“AYỌ̀ wo ni ó lè ju rírí kí ẹnì kan tí o bá kẹ́kọ̀ọ́ di aláápọn olùyin Jèhófà? Ó ń wúni lórí, ó sì ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun láti rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti lágbára tó ní sísún àwọn ènìyàn láti ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn láti lè wu Jèhófà.” Ohun tí aṣáájú ọ̀nà kan láti Kánádà, tí ó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fún ohun tí ó lé ní ọdún 32, kọ nìyẹn. Ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọnà rẹ̀, ó sọ pé: “N kò rò pé ohun mìíràn wà tí mo lè ṣe. N kò rò pé ohun mìíràn wà tí ó lè mú irú ayọ̀ kan náà wá.”
2 Ìwọ ha gbà pé ayọ̀ ńlá ń bẹ nínú ṣíṣàjọpín nínú ríran ẹnì kan lọ́wọ́ sí ojú ọ̀nà ìyè bí? Dájúdájú, kì í ṣe àwọn aṣáájú ọ̀nà nìkan ni ó ń nírìírí irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀. Gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ni ó wà lábẹ́ àṣẹ náà láti “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” wọ́n sì ń tiraka láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 28:19) Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí ó ti ṣeé ṣe fún àwọn aṣáájú ọ̀nà láti lo ọ̀pọ̀ wákàtí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, wọ́n sábà máa ń wà ní ipò nínírìírí ayọ̀ sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn ní kíkún sí i. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tún ní àwọn èrè míràn. Fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣáájú ọ̀nà, wọn yóò sì sọ fún ọ pé ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà jẹ́ ọ̀nà àgbàyanu kan láti gbà nírìírí ‘ìbùkún Jèhófà tí ń múni là.’—Òwe 10:22.
3. Kí ní lè ru wá sókè bí a ti ń bá sísin Jèhófà nìṣó?
3 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a sọ fún àwọn aṣáájú ọ̀nà láti onírúurú ibi lágbàáyé láti ṣàpèjúwe àwọn ìbùkún tí wọ́n ti gbádùn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ẹ jẹ́ kí a gbé ohun tí wọ́n ní í sọ yẹ̀ wò. Ṣùgbọ́n, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì bí àìlera, ọjọ́ ogbó, tàbí àwọn àyíká ipò míràn bá ń dín ohun tí o lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn kù. Rántí pé, ohun tí ó ṣe pàtàkì ni láti sin Jèhófà tọkàntọkàn, láyìíká ipò èyíkéyìí. Síbẹ̀, gbígbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn aṣáájú ọ̀nà díẹ̀ lè fi kún ìfẹ́ ọkàn rẹ láti lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tí ń mérè wá yìí, bí ó bá ṣeé ṣe.
Ìtẹ́lọ́rùn Jíjinlẹ̀ àti Ayọ̀
4, 5. (a) Èé ṣe tí ṣíṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn fi jẹ́ ìrírí tí ń mérè wá tó bẹ́ẹ̀? (b) Kí ni ìmọ̀lára àwọn aṣáájú ọ̀nà nípa nínípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún?
4 Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírí gbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Bẹ́ẹ̀ ni, fífúnni láìmọtara-ẹni-nìkan ní èrè tirẹ̀. (Òwe 11:25) Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì nígbà tí ó bá kan ṣíṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ní tòótọ́, ẹ̀bùn wo ni a lè fún ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa tí ó ju ríràn án lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ Ọlọ́run, tí ń ṣamọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun lọ?—Jòhánù 17:3.
5 Kò yani lẹ́nu pé àwọn tí ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn jíjinlẹ̀ tí wọ́n ń rí gbà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Aṣáájú ọ̀nà kan láti Britain, tí ó jẹ́ ẹni ọdún 64, sọ pé: “Mo mọ̀ pé kò sí iṣẹ́ mìíràn tí ó lè mú irú ìtẹ́lọ́rùn tí mo ti rí nínú ṣíṣàjọpín òtítọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn wá fún mi.” Opó kan láti Democratic Republic of Congo sọ ohun tí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà túmọ̀ sí fún un pé: “Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà jẹ́ ìtùnú gidi fún mi lẹ́yìn tí mo pàdánù ọkọ mi ọ̀wọ́n. Bí mo ti ń jáde tó nínú iṣẹ́ ìsìn pápá láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni ìrántí àdánù mi túbọ̀ ń dín kù sí i. Mo gbé ìgbàgbọ́ mi karí àwọn ìlérí Jèhófà, mo sì máa ń ronú lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ nípa bí mo ṣe lè ran àwọn tí mo ń bá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn. Ní òpin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, oorun mi máa ń dùn, ọkàn mi sì máa ń kún fún ayọ̀.”
6. Ayọ̀ àrà ọ̀tọ̀ wo ni àwọn aṣáájú ọ̀nà kan ti ní?
6 Àwọn kan tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ti ní àkànṣe ayọ̀ ti sísìn ní àwọn àgbègbè àdádó, wọ́n dá àwọn ìjọ sílẹ̀, tí ó wá di àwọn àyíká lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Fún àpẹẹrẹ, arábìnrin kan, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún ọdún 33, wà ní Abashiri, Hokkaido (erékùṣù tí ó kángun sí àríwá Japan). Ó rántí pé nígbà àpéjọ àyíká tí ó kọ́kọ́ lọ—ní gbogbo Hokkaido—ìwọ̀nba 70 péré ni ó wà níjokòó. Nísinsìnyí ńkọ́? Àyíká 12 ni ó wà ní erékùṣù yẹn, pẹ̀lú àròpọ̀ 12,000 akéde. Finú wòye bí ọkàn rẹ̀ ti kún fún ayọ̀ tó nígbà tí ó lọ sí àpéjọ àti àpéjọpọ̀ pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùpòkìkí Ìjọba ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní erékùṣù yẹn!
7, 8. Ayọ̀ wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn aṣáájú ọ̀nà alákòókò pípẹ́ ti ní?
7 Àwọn aṣáájú ọ̀nà ọlọ́jọ́ pípẹ́ mìíràn ti láyọ̀ rírí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn tí wọ́n ṣe batisí, tí wọ́n sì nàgà fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn gíga sí i. Ní Japan, arábìnrin kan tí ó ti sìn níbi mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a yàn án sí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà láti 1957 rántí fífi ìwé ìròyìn Jí! sóde fún omidan kan tí ó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìfowópamọ́. Obìnrin náà ṣe batisí láàárín oṣù mẹ́sàn-án. Lẹ́yìn náà, ó ṣègbéyàwó, òun àti ọkọ rẹ̀ sí di aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Ẹ wo irú ayọ̀ tí ó jẹ́ fún arábìnrin aṣáájú ọ̀nà náà nígbà tí alábòójútó àyíká tuntun àti aya rẹ̀—akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí—ṣèbẹ̀wò sí ìjọ rẹ̀, ní ibi iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ kẹta!
8 Abájọ tí àwọn tí wọ́n ti sọ iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà di iṣẹ́ ìgbésí ayé fi ń wò ó gẹ́gẹ́ bí “àǹfààní tí kò ṣeé díye lé, tí ó yẹ kí a ṣìkẹ́,” gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí ó ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ọdún 22 ti sọ ọ́!
Ẹ̀rí Àbójútó Jèhófà
9. Gẹ́gẹ́ bí Olùpèsè Gíga Lọ́lá, kí ni Jèhófà ṣèlérí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí sì ni èyí túmọ̀ sí fún wa?
9 Jèhófà, Olùpèsè Gíga Lọ́lá, ṣèlérí láti pèsè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ní bíbójú tó wọn nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Abájọ tí Ọba Dáfídì fi lè sọ pé: “Èmi ti wà ní èwe, èmi sì dàgbà; èmi kò tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú ọmọ rẹ̀ kí ó máa ṣagbe oúnjẹ.” (Orin Dáfídì 37:25) Dájúdájú, ìmúdánilójú àtọ̀runwá yìí kò yẹ ojúṣe wa láti pèsè nípa ti ara fún ìdílé wa kúrò lọ́rùn wa, kò sì fún wa láṣẹ láti kófà ìwà ọ̀làwọ́ àwọn Kristẹni ará wa. (Tẹsalóníkà Kíní 4:11, 12; Tímótì Kíní 5:8) Síbẹ̀, nígbà tí a bá fínnúfíndọ̀ ṣèrúbọ nínú ìgbésí ayé wa láti lè sin Jèhófà ní kíkún sí i, òun kì yóò fi wá sílẹ̀ láé.—Mátíù 6:33.
10, 11. Láti inú ìrírí, kí ni ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà mọ̀ nípa agbára Jèhófà láti pèsè?
10 Àwọn aṣáájú ọ̀nà kárí ayé mọ̀ láti inú ìrírí pé, Jèhófà ń pèsè fún àwọn tí wọ́n bá fi ara wọn sábẹ́ àbójútó rẹ̀. Gbé ọ̀ràn tọkọtaya aṣáájú ọ̀nà kan tí wọ́n ṣí lọ sí ìlú kékeré kan tí àìní wà fún àwọn oníwàásù Ìjọba yẹ̀ wò. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, wọn kò fi bẹ́ẹ̀ rí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ṣe, àpò wọn sì ti gbẹ. Lẹ́yìn náà, wọ́n gba ìwé gbèsè dọ́là 81 fún ìbánigbófò ọkọ wọn. Arákùnrin náà ṣàlàyé pé: “Kò sí bí a ṣe lè san án. A gbàdúrà gan-an ní alẹ́ ọjọ́ yẹn.” Ní ọjọ́ kejì, wọ́n gba káàdì kan láti ọ̀dọ̀ ìdílé kan tí àwọn fúnra wọn kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ. Káàdì náà ṣàlàyé pé, ìdílé náà rí àsanpadà gbà lórí owó orí wọn, níwọ̀n bí ó sì ti ju iye tí wọ́n retí lọ, wọ́n fẹ́ láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú tọkọtaya aṣáájú ọ̀nà náà. Ìwé sọ̀wédowó fún dọ́là 81 ni ó wà nínú rẹ̀! Arákùnrin aṣáájú ọ̀nà náà sọ pé: “N kò lè gbàgbé ọjọ́ yẹn—orí mi wú! A mọrírì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ìdílé yìí gan-an.” Jèhófà pẹ̀lú mọrírì irú inú rere bẹ́ẹ̀, tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí ó fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ níṣìírí láti ní.—Òwe 19:17; Hébérù 13:16.
11 Ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà lè ròyìn irú ìrírí kan náà. Bi wọ́n, wọn yóò sì sọ fún ọ pé a kò “kọ” àwọn “sílẹ̀” rí. Ní wíwẹ̀yìn pa dà sí ohun tí ó lé ní ọdún 55 nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, aṣáájú ọ̀nà ẹni ọdún 72 kan sọ pé, “Jèhófà kò já mi kulẹ̀ rí.”—Hébérù 13:5, 6.
“Ọ̀nà Títayọ Lọ́lá Láti Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà Pẹ́kípẹ́kí Sí I”
12. Èé ṣe tí iṣẹ́ pípolongo ìhìn rere fi jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tó bẹ́ẹ̀?
12 Pé Jèhófà tilẹ̀ ní kí a polongo ìhìn rere Ìjọba rẹ̀ ṣí àǹfààní kan sílẹ̀ fún wa. Ó kà wá sí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀ nínú ìgbòkègbodò tí ń gbẹ̀mílà yí—bí a tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn aláìpé. (Kọ́ríńtì Kíní 3:9; Tímótì Kíní 4:16) Bí a ti ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn, bí a ti ń polongo òpin sí ìwà ibi, bí a ti ń ṣàlàyé nípa ìfẹ́ rẹ̀ àgbàyanu ní pípèsè ìràpadà fún àwọn ènìyàn, bí a ti ń ṣí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó wà láàyè, tí a sì ń fi àwọn ohun iyebíye tí ó wà nínú rẹ̀ kọ́ àwọn aláìlábòsí ọkàn, a máa ń rí i pé a túbọ̀ ń sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà, pẹ́kípẹ́kí sí i.—Orin Dáfídì 145:11; Jòhánù 3:16; Hébérù 4:12.
13. Kí ni àwọn kan sọ nípa ipa tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní lórí ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Jèhófà?
13 Ó ṣeé ṣe fún àwọn aṣáájú ọ̀nà láti lo àkókò púpọ̀ sí i lóṣooṣù ní kíkọ́ nípa Jèhófà àti kíkọ́ni nípa rẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe rò pé èyí ṣe ń nípa lórí ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Ọlọ́run? Alàgbà kan ní ilẹ̀ Faransé, tí ó ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ohun tí ó lé ní ọdún mẹ́wàá, dáhùn pé: “Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà jẹ́ ọ̀nà títayọ lọ́lá láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí sí i.” Aṣáájú ọ̀nà míràn ní ilẹ̀ yẹn, tí ó ti lo ọdún 18 nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, sọ pé: “Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà fún wa láǹfààní láti ‘tọ́ ọ wò, kí a sì rí i pé rere ni Olúwa,’ ní mímú kí a mú ipò ìbátan lílágbára dàgbà pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa lójoojúmọ́.” (Orin Dáfídì 34:8) Arábìnrin kan ní Britain, tí ó ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà fún 30 ọdún, nímọ̀lára lọ́nà kan náà. Ó sọ pé: “Níní láti gbára lé ẹ̀mí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ń mú kí n túbọ̀ sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí. Ní tòótọ́, mo ti nímọ̀lára pé ẹ̀mí Jèhófà ni ó darí mi lọ́pọ̀ ìgbà sí ilé kan pàtó ní àkókò yíyẹ.”—Fi wé Ìṣe 16:6-10.
14. Báwo ni àwọn aṣáájú ọ̀nà ṣe ń jàǹfààní láti inú lílo Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì láti fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn lójoojúmọ́?
14 Ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà rí i pé lílo Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì lójoojúmọ́ láti ṣàlàyé òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ àti láti fi kọ́ni ti ran àwọn lọ́wọ́ láti dàgbà nínú ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Arákùnrin ọlọ́dún 85 kan, ní Sípéènì, tí ó ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ọdún 31, ṣàlàyé pé: “Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ti ràn mí lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ jíjinlẹ̀ nínú Bíbélì, ìmọ̀ tí mo ti lò láti fi ran ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀.” Arábìnrin kan láti Britain, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún ọdún 23, sọ pé: “Iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa yán hànhàn fún oúnjẹ tẹ̀mí.” Ṣíṣàlàyé ‘ìrètí tí ń bẹ nínú rẹ’ fún àwọn ẹlòmíràn lè fún ìdánilójú tí ìwọ fúnra rẹ ní nínú àwọn ohun tí o gbà gbọ́, tí ó ṣeyebíye sí ọ, lókun. (Pétérù Kíní 3:15) Aṣáájú ọ̀nà kan láti Australia sọ pé: “Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mú ìgbàgbọ́ mi sunwọ̀n sí i, bí mo ti ń sọ ọ́ jáde fún àwọn ẹlòmíràn.”
15. Kí ni ọ̀pọ̀ ti múra tán láti ṣe láti lè wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, kí wọ́n sì máa bá a lọ, èé sì ti ṣe?
15 Ní kedere, ó dá àwọn òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wọ̀nyí lójú pé àwọn ti yan apá iṣẹ́ ìsìn kan tí ń mú àìlóǹkà ìbùkún wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi múra tán láti ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn, àní tí wọ́n tilẹ̀ ń fi iṣẹ́ ìgbésí ayé wọn àti ọrọ̀ àlùmọ́nì wọn rúbọ pàápàá, kí wọ́n baà lè wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, kí wọ́n sì máa bá a lọ!—Òwe 28:20.
Ọkàn Rẹ Ha Ń Yánhànhàn Láti Ṣe Púpọ̀ Sí I Bí?
16, 17. (a) Bí o bá ń ṣiyè méjì pé o lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, kí ni o lè ṣe? (b) Kí ni ìmọ̀lára àwọn kan tí kò ṣeé ṣe fún láti ṣe aṣáájú ọ̀nà?
16 Lẹ́yìn gbígbé ohun tí àwọn aṣáájú ọ̀nà sọ nípa àwọn ìbùkún iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà yẹ̀ wò, bóyá ìwọ ń ṣiyè méjì pé o lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí o kò bá aṣáájú ọ̀nà kan, tí ó ti ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, sọ̀rọ̀? Ó tún lè ṣàǹfààní fún ọ láti bá ọ̀kan nínú àwọn alàgbà ìjọ, ọ̀kan tí ó mọ̀ ọ́—tí ó mọ ipò ìlera rẹ, ibi ti agbára rẹ mọ, àti ojúṣe ìdílé tí o ní—sọ̀rọ̀. (Òwe 15:22) Ọ̀rọ̀ tí ó sọ ojú abẹ níkòó tí àwọn ẹlòmíràn sọ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò kínníkínní bóyá ó ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. (Fi wé Lúùkù 14:28.) Bí ó bá ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ìbùkún rẹ yóò ga lọ́lá ní tòótọ́.—Málákì 3:10.
17 Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ olùṣòtítọ́ akéde Ìjọba tí kò ṣeé ṣe fún láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ńkọ́, bí wọ́n tilẹ̀ ń yànhànhàn láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? Fún àpẹẹrẹ, gbé ìmọ̀lára Kristẹni arábìnrin kan, tí ń làkàkà láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dàgbà ní òun nìkan, yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Inú mi máa ń bà jẹ́, nítorí mo ti fìgbà kan jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, nítorí àyíká ipò mi, n kò lè jáde iṣẹ́ ìsìn pápá bí mo ti ń ṣe tẹ́lẹ̀.” Arábìnrin yìí nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ gidigidi, ó sì fẹ́ láti gbọ́ bùkátà lórí wọn. Lọ́wọ́ kan náà, ó ń yánhànhàn láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ó ṣàlàyé pé: “Mo fẹ́ràn iṣẹ́ òjíṣẹ́.” Àwọn Kristẹni olùfọkànsìn yòó kù, tí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run ń sún wọn láti fẹ́ sin Jèhófà “tinútinú wọn gbogbo,” ní irú ìmọ̀lára kan náà.—Orin Dáfídì 86:12.
18. (a) Kí ni Jèhófà ń retí láti ọ̀dọ̀ wa? (b) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a rẹ̀wẹ̀sì bí àwọn àyíká ipò bá ń dín ohun tí a lè ṣe kù?
18 Rántí pé iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn ni Jèhófà ń retí láti ọ̀dọ̀ wa. Ohun tí èyí jẹ́ lè yàtọ̀ síra gidigidi láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan sí òmíràn. Ó ṣeé ṣe fún àwọn kan láti ṣe ìyípadà nínú àlámọ̀rí wọn, láti baà lè sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ọ̀pọ̀ míràn ń forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, yálà lóòrèkóòrè tàbí léraléra, ní lílo 60 wákàtí lóṣooṣù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn Jèhófà ń yọ̀ǹda ara wọn tọkàntọkàn fún iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni gẹ́gẹ́ bí akéde ìjọ. Nítorí náà, bí àìlera, ọjọ́ ogbó, ojúṣe ìdílé, tàbí àwọn àyíká ipò míràn bá ń dín ohun tí o lè ṣe kù ní tòótọ́, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ pé gbogbo ohun tí o lè ṣe ni o ń ṣe, iṣẹ́ ìsìn rẹ ṣeyebíye lójú Ọlọ́run, bí ti àwọn tí ó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti ṣeyebíye!
Gbogbo Wa Lè Fi Ẹ̀mí Aṣáájú Ọ̀nà Hàn
19. Kí ni ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà?
19 Bí kò bá tilẹ̀ ṣeé ṣe fún ọ láti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, o lè fi ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà hàn. Kí ni ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà? Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1988 sọ pé: “A lè tumọ rẹ̀ pàtó gẹgẹbi níní ẹ̀mí-ìrònú aláìyẹhùn síhà àṣẹ naa lati waasu kí a sì sọnidi ọmọ-ẹhin, jíjẹ́ ẹni tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́-àdéhùn ní kíkún lati fi ìfẹ́ ati ìdàníyàn hàn sí awọn eniyan, jíjẹ́ ẹni tí ńfi ara-ẹni rúbọ, rírí ìdùnnú-ayọ̀ ní títẹ̀lé Ọ̀gá naa tímọ́tímọ́, ati rírí ìdùnnú ninu awọn nǹkan ti ẹmi, kii ṣe ti ara.” Báwo ni o ṣe lè fi ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà hàn?
20. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè fi ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà hàn?
20 Bí o bá jẹ́ òbí tí ó ní àwọn ọmọ kéékèèké, o lè gbà wọ́n nímọ̀ràn tọkàntọkàn láti sọ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà di iṣẹ́ ìgbésí ayé. Ìṣarasíhùwà rere tí o ní sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè tẹ ìjẹ́pàtàkì sísọ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà di ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn mọ́ wọn lọ́kàn. O lè ké sí àwọn aṣáájú ọ̀nà àti àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn aya wọn wá sí ilé rẹ, kí àwọn ọmọ rẹ baà lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ àwọn tí ó ti rí ayọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. (Fi wé Hébérù 13:7.) Àní ní àwọn ilé tí kì í ṣe ìsìn kan ṣoṣo ni wọ́n ń ṣe pàápàá, àwọn òbí onígbàgbọ́, nípa ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ, lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti sọ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún di góńgó kan nínú ìgbésí ayé.—Tímótì Kejì 1:5; 3:15.
21. (a) Báwo ni gbogbo wá ṣe lè ti àwọn tí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà lẹ́yìn? (b) Kí ni àwọn alàgbà lè ṣe láti fún àwọn aṣáájú ọ̀nà níṣìírí?
21 Nínú ìjọ, gbogbo wa pátá lè ṣètìlẹ́yìn tọkàntọkàn fún àwọn tí ó ṣeé ṣe fún láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, ìwọ ha lè ṣe àkànṣe ìsapá láti bá aṣáájú ọ̀nà kan ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, pàápàá ní àwọn ìgbà tí aṣáájú ọ̀nà náà kò bá ní rí ẹni bá ṣiṣẹ́? Ìwọ lè rí i pé “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” yóò wà. (Róòmù 1:11, 12) Bí o bá jẹ́ alàgbà, o tilẹ̀ lè ṣe púpọ̀ sí i láti fún àwọn aṣáájú ọ̀nà níṣìírí. Nígbà tí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà bá pàdé, ó yẹ kí wọ́n máa gbé àìní àwọn aṣáájú ọ̀nà yẹ̀ wò déédéé. Nígbà tí aṣáájú ọ̀nà kan bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí ó bá ń bá àwọn ìṣòro kan yí, má ṣe yára dábàá pé kí ó fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé dídá irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè pọn dandan nínú àwọn ọ̀ràn kan, má ṣe gbàgbé pé iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà jẹ́ àǹfààní ṣíṣeyebíye kan tí ìránṣẹ́ alákòókò kíkún náà lè ṣìkẹ́ gidigidi. Ó lè jẹ́ ìṣírí díẹ̀ àti àwọn ìmọ̀ràn tí ó múná dóko tàbí ìrànlọ́wọ́ ni gbogbo ohun tí a ń fẹ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì Society ní Sípéènì kọ̀wé pé: “Nígbà tí àwọn alàgbà bá fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà níṣìírí, tí wọ́n ti àwọn aṣáájú ọ̀nà lẹ́yìn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, tí wọ́n sì ń bójútó wọn déédéé, ayọ̀ àwọn aṣáájú ọ̀nà túbọ̀ máa ń pọ̀ sí i, wọ́n máa ń nímọ̀lára pé àwọn wúlò, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti máa báa lọ láìka àwọn ìdènà tí ó lè dìde sí.”
22. Nínú àkókò lílekoko nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn yí, kí ni ó yẹ kí a pinnu láti ṣe?
22 A ń gbé ní àkókò lílekoko nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Jèhófà ti fi iṣẹ́ tí ń gbẹ̀mílà lé wa lọ́wọ́ láti ṣe parí. (Róòmù 10:13, 14) Yálà a lè nípìn-ín nínú iṣẹ́ yìí fún àkókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà tàbí kò ṣeé ṣe fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a fi ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà hàn. Ẹ jẹ́ kí a ní ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Ẹ jẹ́ kí a pinnu láti fún Jèhófà ní ohun tí ó béèrè lọ́wọ́ wa—iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn. Ẹ sì jẹ́ kí a rántí pé, bí a bá ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, yálà ó jọ ẹyọ owó kéékèèké opó náà tàbí òróró olówó ńlá ti Màríà, iṣẹ́ ìsìn wa jẹ́ tọkàntọkàn, Jèhófà sì mọyì iṣẹ́ ìsìn tí a ṣe tọkàntọkàn!
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èé ṣe tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fi mú ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ wá?
◻ Láti inú ìrírí, kí ni ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà mọ̀ nípa agbára Jèhófà láti bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
◻ Ipa wo ni àwọn aṣáájú ọ̀nà rò pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọ́n ní lórí ìbátan wọn pẹ̀lú Jèhófà?
◻ Báwo ni o ṣe lè fi ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà hàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn aṣáájú ọ̀nà ń rí ayọ̀ ńlá láti inú sísọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn ọmọ rẹ lè jàǹfààní láti inú kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùpòkìkí Ìjọba alákòókò kíkún
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn alàgbà lè fún àwọn aṣáájú ọ̀nà níṣìírí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá