Fífòyemọ Ìlànà Ń Fi Hàn Pé A Dàgbà Dénú
ẸGBẸ́ búburú a máa ba àwọn ìwà wíwúlò jẹ́. Ohun tí o bá fúnrúngbìn ni ìwọ yóò ká. (Kọ́ríńtì Kíní 15:33; Gálátíà 6:7) Yálà nípa ti ara tàbí nípa ti ẹ̀mí, gbólóhùn kọ̀ọ̀kan jẹ́ àpẹẹrẹ òtítọ́ ìpìlẹ̀ kan—ìlànà kan—ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì pèsè ìpìlẹ̀ fún àwọn òfin. Òfin ní tirẹ̀ lè wà fún kìkì ìgbà díẹ̀, ó sì sábà máa ń ṣe pàtó. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ìlànà gbòòrò, ó sì lè wà títí láé. Nípa báyìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá láti ronú nípa ìlànà tí ó wé mọ́ ọ̀ràn kan, níbikíbi tí ó bá ti ṣeé ṣe.
Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Webster’s Third New International Dictionary, túmọ̀ ìlànà gẹ́gẹ́ bí “òtítọ́ ní gbogbogbòò tàbí òtítọ́ ìpìlẹ̀: òfin, ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́, tàbí èrò gbígbòòrò, tí ó sì jẹ́ ìpìlẹ̀ tí a gbé àwọn òfin, ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́, tàbí èrò míràn kà tàbí tí a ti fà wọ́n yọ.” Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè fún ọmọ kan ní òfin pé, “Má fọwọ́ sí ojú sítóòfù yẹn.” Ṣùgbọ́n, fún àgbàlagbà kan, gbólóhùn náà, “Ojú sítóòfù yẹn gbóná o” ti tó. Ṣàkíyèsí pé èyí tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn jẹ́ gbólóhùn tí ó gbòòrò. Nítorí ó ń darí ohun tí ẹnì kan lè ṣe—bóyá kí a gbóúnjẹ léná, kí a yan nǹkan, tàbí kí a fẹ́ pa sítóòfù náà—lọ́nà kan, ó di ìlànà.
Dájúdájú, àwọn ìlànà tẹ̀mí ni àwọn ìlànà pàtàkì ìgbésí ayé; wọ́n ń darí ìjọsìn wa sí Ọlọ́run àti ayọ̀ wa. Ṣùgbọ́n, àwọn kan ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ìsapá tí a béèrè fún láti lè ronú jinlẹ̀ lórí ìlànà. Wọ́n ń yan ìrọ̀rùn tí ó wà nínú òfin láàyò, nígbà tí wọ́n bá ní ìpinnu kan láti ṣe. Èyí kò bọ́gbọ́n mu, ó sì lòdì sí àpẹẹrẹ tí àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ ìgbàanì ní àkókò tí a kọ Bíbélì fi lélẹ̀.—Róòmù 15:4.
Àwọn Ọkùnrin Atẹ̀lélànà Ọlọ́run
Láàárín àwọn ènìyàn aláìpé, a lè pe Ébẹ́lì ní ọkùnrin àkọ́kọ́ pàá tí ó jẹ́ atẹ̀lélànà Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí ó ti ronú jinlẹ̀ lórí ìlérí nípa “irú-ọmọ” náà, kí ó sì wòye pé ìràpadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yóò ní fífi ẹ̀jẹ̀ rúbọ nínú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Nítorí èyí, ó fi “àkọ́bí ẹran ọ̀sìn . . . rẹ̀” rúbọ sí Ọlọ́run. Gbólóhùn náà “àní nínú àwọn tí ó sanra” fi hàn pé Ébẹ́lì fún Jèhófà ni èyí tí ó dára jù lọ nínú ohun ìní rẹ̀. Síbẹ̀, yóò lé ní ẹgbàá ọdún lẹ́yìn ikú Ébẹ́lì kí Ọlọ́run tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí a ń béèrè nípa ìrúbọ. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí Ébẹ́lì, ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì jẹ́ atẹ̀lélànà, ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Kéènì, fi ẹ̀mí gbà-máà-póò-rọ́wọ́ọ̀-mi hàn nínú ìrúbọ rẹ̀ sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ìṣarasíhùwà rẹ̀ kò wúni lórí, ohun kan nípa ìrúbọ rẹ̀ fi hàn pé kò sí ìlànà lọ́kàn rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 4:3-5.
Nóà pẹ̀lú jẹ́ ọkùnrin atẹ̀lélànà Ọlọ́run. Bí àkọsílẹ̀ Bíbélì tilẹ̀ fi hàn pé Ọlọ́run pàṣẹ fún un ní pàtó pé kí ó kan áàkì kan, a kò kà nípa àṣẹ kankan pé kí ó wàásù fún àwọn ẹlòmíràn. Síbẹ̀, a pe Nóà ní “oníwàásù òdodo.” (Pétérù Kejì 2:5) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti lè pàṣẹ fún Nóà láti wàásù, kò sí àní-àní pé òye rẹ̀ nípa ìlànà àti ìfẹ́ rẹ̀ fún àwọn aládùúgbò rẹ̀ pẹ̀lú sún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Níwọ̀n bí a ti ń gbé ní àkókò tí ó jọ ti Nóà, ẹ jẹ́ kí a fara wé ìwà rere àti àpẹẹrẹ rẹ̀.
Láìdàbí àwọn àlùfáà ọjọ́ rẹ̀, Jésù kọ́ àwọn ènìyàn láti ronú nípa ìlànà tí ó wé mọ́ nǹkan. Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè jẹ́ àpẹẹrẹ kan. Gbogbo rẹ̀ dá lórí títẹ̀lé ìlànà. (Mátíù, orí 5-7) Jésù kọ́ni lọ́nà yí nítorí pé, bí Ébẹ́lì àti Nóà tí ó ti gbé ayé ṣáájú rẹ̀, ó mọ Ọlọ́run dunjú. Àní gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, ó bọ̀wọ̀ fún òtítọ́ ìpìlẹ̀ náà pé: “Ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wà láàyè, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLÚWA jáde.” (Diutarónómì 8:3; Lúùkù 2:41-47) Bẹ́ẹ̀ ni, àṣírí jíjẹ́ atẹ̀lélànà Ọlọ́run ni láti mọ Jèhófà dunjú, kí a mọ ohun tí ó fẹ́, àti ohun tí kò fẹ́, àti àwọn ète rẹ̀. Nígbà tí a bá jẹ́ kí àwọn ìlànà wọ̀nyí nípa Ọlọ́run darí ìgbésí ayé wa, ní ti gidi, wọn yóò di ìlànà tí ó wà láàyè.—Jeremáyà 22:16; Hébérù 4:12.
Ìlànà àti Ọkàn Àyà
Bóyá nítorí ìjìyà àìgbọràn, ó ṣeé ṣe láti ṣègbọràn sí òfin kan bí kò tilẹ̀ tọkàn ẹni wá. Ṣùgbọ́n, fífaramọ́ ìlànà fagi lé irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀, gbàrà tí ẹnì kan bá ti gbà kí ìlànà darí òun, yóò máa ṣègbọràn sí i látọkàn wá. Gbé ọ̀ràn Jósẹ́fù yẹ̀ wò, bí Ébẹ́lì àti Nóà, ó gbé ayé ṣáájú kí a tó gbé májẹ̀mú Òfin Mósè kalẹ̀. Nígbà tí aya Pọ́tífárì gbìyànjú láti sún un dẹ́sẹ̀ lọ, Jósẹ́fù fèsì pé: “Èmi óò ha ti ṣe hù ìwà búburú ńlá yìí, kí èmi sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” Bẹ́ẹ̀ ni, Jósẹ́fù mọ ìlànà náà pé ọkọ àti aya jẹ́ “ara kan.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:24; 39:9.
Lónìí, ayé ti pa ìlànà òdodo tì. Wọ́n ń fi ìwọra gba ìwà ipá àti ìwà pálapàla sínú ọpọlọ wọn. Ewu ibẹ̀ ni pé, a lè dán Kristẹni kan wò láti tọ́ àwọn pàrùpárù oúnjẹ wò—sinimá, fídíò, tàbí ìwé—bóyá ní bòókẹ́lẹ́. Nígbà náà, ẹ wo bí a óò ṣe gbóríyìn fún wa tó, nígbà tí a bá ṣe bíi Jósẹ́fù ní kíkọ ìwà búburú sílẹ̀ nítorí tí ó lòdì sí ìlànà, ní rírántí pé àwọn adúróṣinṣin nìkan ni Ọlọ́run yóò pa mọ́ la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ já. (Mátíù 24:21) Bẹ́ẹ̀ ni, ní pàtàkì, bí a ṣe ń hùwà ní ìkọ̀kọ̀ ni ó ń fi irú ẹni tí a jẹ́ gan-an hàn, kì í ṣe bí a ṣe ń hùwà ní gbangba.—Orin Dáfídì 11:4; Òwe 15:3.
Bákan náà, bí a bá jẹ́ kí ìlànà Bíbélì darí wa, a kò ní máa wá ọ̀nà àbáyọ nínú òfin Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ sì ni a kò ní gbìyànjú láti rí bí a ṣe lè rìn jìnnà tó láìrú òfin kan ní pàtó. Irú ìrònú bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìpara-ẹni-láyò; yóò ṣèpalára fún wa nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Wo Ohun Tí Ó Wà Lẹ́yìn Òfin
Dájúdájú, òfin ń kó ipa tí ó ṣe kókó nínú ìgbésí ayé Kristẹni. Wọ́n dà bí alóre tí ń ṣèrànwọ́ láti dáàbò bò wá, àwọn ìlànà pàtàkì sì wà lẹ́yìn wọn. Kíkùnà láti róye àwọn ìlànà wọ̀nyí lè bomi paná ìfẹ́ wa fún àwọn òfin tí ó so mọ́ ọn. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì fi èyí hàn.
Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì ní Òfin Mẹ́wàá, àkọ́kọ́ nínú rẹ̀ ka ìjọsìn ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Jèhófà léèwọ̀. Pé Jèhófà ni ó dá ohun gbogbo jẹ́ òtítọ́ ìpìlẹ̀ tí ó wà lẹ́yìn òfin yìí. (Ẹ́kísódù 20:3-5) Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà ha jẹ́ kí ìlànà yí darí ìgbésí ayé wọn bí? Jèhófà fúnra rẹ̀ dáhùn pé: “‘Ìwọ ni bàbá wa’ [ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí] fún àkójọ igi, [wọ́n sì kígbe pé] òkúta ‘ni Ìyá wa.’ Ṣùgbọ́n wọ́n ti kẹ̀yìn sí èmi [Jèhófà], wọ́n sì ti yí ojú wọn kúrò lọ́dọ̀ mi.” (Jeremáyà 2:27, The New English Bible) Ẹ wo irú ìwà àìgbatẹnirò àti àìtẹ̀lélànà gbáà tí èyí jẹ́! Ẹ sì wo bí ó ti dun Jèhófà dé ọkàn àyà tó!—Orin Dáfídì 78:40, 41; Aísáyà 63:9, 10.
Àwọn Kristẹni pẹ̀lú ní òfin tí Ọlọ́run fún wọn. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n ní láti yẹra fún ìbọ̀rìṣà, ìwà pálapàla, àti àṣìlò ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Nígbà tí o bá ronú nípa rẹ̀, a lè rí àwọn ìlànà tí ń bẹ lẹ́yìn rẹ̀, irú bí: Ọlọ́run yẹ fún ìjọsìn wa tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé; a gbọ́dọ̀ jẹ́ olùṣòtítọ́ sí alábàáṣègbéyàwó wa; àti pé Jèhófà ni Olùfúnni-ní-ìyè. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Ẹ́kísódù 20:5; Orin Dáfídì 36:9) Bí a bá róye àwọn ìlànà tí ń bẹ lẹ́yìn àwọn àṣẹ wọ̀nyí, tí a sì mọrírì wọn gidigidi, a óò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ fún ire wa. (Aísáyà 48:17) Fún àwa, “àwọn àṣẹ” Ọlọ́run “kì í ṣe ẹrù ìnira.”—Jòhánù Kíní 5:3.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà kan, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa òfin Ọlọ́run tì, ìgbà tí yóò fi di àkókò Jésù “àwọn onímọ̀ òfin” wọn, àwọn akọ̀wé, ti ṣe àṣerégèé. Wọ́n ti gbé àwọn òfin àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ rẹpẹtẹ tí ó dènà ìjọsìn mímọ́ gaara kalẹ̀, wọ́n sì bo ìlànà Ọlọ́run mọ́lẹ̀. (Mátíù 23:2, NEB) Wọ́n gbà pé àwọn kò lè ṣàṣeyọrí, wọ́n di aláìnírètí, àwọn mìíràn sì di alágàbàgebè. (Mátíù 15:3-9) Ọ̀pọ̀ nínú àwọn òfin ènìyàn náà kì í jẹ́ kí a fi ojú àánú hàn. Nígbà tí ó fẹ́ wo ọkùnrin kan ti ọwọ́ rẹ̀ gbẹ hangogo sàn, Jésù béèrè lọ́wọ́ àwọn Farisí tí ó wà níbẹ̀ pé: “Ó ha bófin mu ní sábáàtì láti ṣe iṣẹ́ rere?” Àìfèsì wọn fi hàn pé wọ́n gbà pé kò bófin mu, èyí mú kí Jésù ní “ẹ̀dùn ọkàn gidigidi sí yíyigbì ọkàn àyà wọn.” (Máàkù 3:1-6) Àwọn Farisí lè ṣaájò ẹran ọ̀sìn kan (okòwò kan) tí ó nù tàbí tí ó fara pa ní Sábáàtì ṣùgbọ́n wọn kò jẹ́ ṣaájò ọkùnrin tàbí obìnrin—àyàfi bí ó bá jẹ́ ohun tí ó mẹ́mìí lọ́wọ́. Ní tòótọ́, àwọn òfin ènìyàn àti ọ̀rínkinniwín rẹ̀ gbà wọ́n lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ débi pé, bí àwọn èèrùn tí ń rìn lọ rìn bọ̀ lórí àwòrán mèremère kan, wọn kò rí àwòrán náà kedere—ìlànà àtọ̀runwá.—Mátíù 23:23, 24.
Àní àwọn èwe pàápàá, nígbà tí ọkàn àyà wọn bá mọ́, lè mú ọlá wá fún Jèhófà nípa fífi ìmọrírì hàn fún àwọn ìlànà Bíbélì. Olùkọ́ Rebecca ọmọ ọdún 13 béèrè lọ́wọ́ gbogbo kíláàsì bóyá ẹnì kan wà tí yóò fẹ́ láti ta tẹ́tẹ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ sọ pé àwọn kò fẹ́ ta tẹ́tẹ́. Síbẹ̀, nígbà tí ó mẹ́nu kan onírúurú ipò, gbogbo wọ́n gbà pé àwọn yóò ta lọ́nà kan tàbí òmíràn, àyàfi Rebecca nìkan. Olùkọ́ náà béèrè lọ́wọ́ Rebecca bí yóò bá ra tíkẹ́ẹ̀tì oríire oní 20 sẹ́ǹtì tí wọ́n ń tà láti kówó jọ fún ṣíṣe ohun rere kan. Rebecca ní rárá, ó sì fún un ní àwọn ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò fi jẹ́ títa tẹ́tẹ́. Olùkọ́ náà wá sọ fún gbogbo kíláàsì pé: ‘Ní èrò tèmi, Rebecca ni ẹnì kan ṣoṣo tí ń bẹ níhìn-ín tí ó ní ohun tí mo lè pè ní “ìlànà” ní ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà gan-an.’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó rọrùn fún Rebecca láti fèsì pé, “Ó lòdì sí ìsìn mi,” ṣùgbọ́n ó ronú jinlẹ̀ ju ìyẹn lọ; ó lè dáhùn ìdí tí tẹ́tẹ́ títa fi lòdì àti ìdí tí òun fi kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀.
Àwọn àpẹẹrẹ bí Ébẹ́lì, Nóà, Jósẹ́fù, àti Jésù fi hàn wá bí a ṣe ń jàǹfààní nípa lílo “ìmòye” wa àti “agbára ìmọnúúrò” wa, ní jíjọ́sìn Ọlọ́run. (Òwe 2:11; Róòmù 12:1) Yóò dára bí àwọn Kristẹni alàgbà bá lè fara wé Jésù bí wọ́n ‘ṣe ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó wọn.’ (Pétérù Kíní 5:2) Bí Jésù ti fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀ dáradára, àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ ìlànà Ọlọ́run ni wọ́n ń láásìkí lábẹ́ ipò ọba aláṣẹ Jèhófà.—Aísáyà 65:14.