Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àpẹẹrẹ Ìfara-Ẹni-Rúbọ àti Ìdúróṣinṣin
FÚN ọ̀dọ́ àgbẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Èlíṣà, ọjọ́ kan tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú títúlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ojoojúmọ́ di ọjọ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Bí ó ti ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ní pápá ni Èlíjà, wòlíì tí ó tayọ jù lọ ní Ísírẹ́lì, dé e lálejò láìròtẹ́lẹ̀. Èlíṣà ti lè ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ni ó lè wá rí mi fún?’ Kò dúró pẹ́ kí ó tó rí èsì. Èlíjà ju ẹ̀wù oyè rẹ̀ sára Èlíṣà, ní fífihàn pé lọ́jọ́ kan, Èlíṣà yóò di arọ́pò òun. Èlíṣà kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìpè yí. Lójú ẹsẹ̀, ó fi pápá rẹ̀ sílẹ̀ láti di òjíṣẹ́ fún Èlíjà.—Àwọn Ọba Kìíní 19:19-21.
Ní nǹkan bí ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, àkókò náà tó tí Èlíjà yóò lọ. A pe àkọsílẹ̀ lílọ rẹ̀ ní “ọ̀kan nínú àwọn ìtàn tí ó wúni lórí jù lọ” nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.
Èlíjà Múra Àtilọ
Èlíjà fẹ́ láti ṣèbẹ̀wò ìkẹyìn sí Bẹ́tẹ́lì, Jẹ́ríkò, àti Jọ́dánì. Èyí yóò ní fífẹsẹ̀rin ọ̀pọ̀ ibùsọ̀ nínú, tí àwọn kan nínú rẹ̀ yóò sì jẹ́ gbígba àgbègbè tí ó ní òkè gbágungbàgun kọjá. Bí wọ́n ti ń gúnlẹ̀ sí ìlú kọ̀ọ̀kan nínú ìrìn àjò náà Èlíjà ń rọ Èlíṣà pé kí ó dúró síbẹ̀. Ṣùgbọ́n Èlíṣà tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé òun yóò bá ọ̀gá òun dé òpin ìrìn àjò náà.—Àwọn Ọba Kejì 2:1, 2, 4, 6.
Nígbà tí ó dé Bẹ́tẹ́lì àti Jẹ́ríkò, “àwọn ọmọ àwọn wòlíì” tọ Èlíṣà wá.a Wọ́n bi í pé: “Ìwọ ha mọ̀ pé Olúwa yóò mú olúwa rẹ lọ kúrò lórí rẹ lónìí?” Ó fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, èmi mọ̀, ẹ pa ẹnu yín mọ́.”—Àwọn Ọba Kejì 2:3, 5.
Èlíjà àti Èlíṣà gbéra láti lọ sí Odò Jọ́dánì. Nígbà tí wọ́n dé Jọ́dánì, Èlíjà ṣe iṣẹ́ ìyanu kan bí 50 ọmọ wòlíì ti ń wò ó láti òkèèrè. “Èlíjà sì mú agbádá rẹ̀, ó sì lọ́ ọ lù, ó sì lu omi náà, ó sì pín wọn níyà síhìn-ín àti sọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì kọjá ní ilẹ̀ gbígbẹ.”—Àwọn Ọba Kejì 2:8.
Gbàrà tí wọ́n kọjá, Èlíjà sọ fún Èlíṣà pé: “Béèrè ohun tí èmi ó ṣe fún ọ kí a tó mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” Èlíṣà béèrè fún “ipa méjì” nínú ẹ̀mí Èlíjà—ìyẹn ni, ìpín méjì tí ó tọ́ sí ọmọkùnrin àkọ́bí gẹ́gẹ́ bí àṣà. Ní tòótọ́, Èlíṣà bọlá fún Èlíjà gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin àkọ́bí ti ń bọlá fún bàbá rẹ̀. Síwájú sí i, a fi òróró yàn án láti di arọ́pò Èlíjà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Jèhófà ní Ísírẹ́lì. Nítorí náà, ohun tí ó béèrè fún kì í ṣe ti onímọtara-ẹni-nìkan, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ohun tí kò yẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, ní mímọ̀ pé Jèhófà nìkan ni ó lè fàṣẹ sí ohun tí ó béèrè fún yìí, Èlíjà fèsì lọ́nà tí ó fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn pé: “Ìwọ béèrè ohun kan tí ó ṣòro.” Lẹ́yìn náà ó fi kún un pé: “Bí o bá rí mi nígbà tí a bá mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ, yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rí mi, kì yóò ṣẹlẹ̀.”—Àwọn Ọba Kejì 2:9, 10, NW; Diutarónómì 21:17.
Kò sí iyè méjì pé Èlíṣà túbọ̀ pinnu láti dúró gbágbágbá ti ọ̀gá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, “kẹ̀kẹ́ iná àti ẹṣin iná” fara hàn. Ní ojú Èlíṣà kòrókòró, ẹ̀fúùfù líle gbé Èlíjà sókè—lọ́nà ìyanu, a gbé e lọ sí ibò míràn.b Èlíṣà mú ẹ̀wù oyè Èlíjà, ó sì pa dà lọ sí bèbè Odò Jọ́dánì. Ó lu odò náà, ní wíwí pé: “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Èlíjà wà?” Odò náà pín sí méjì, ní fífi ẹ̀rí tí ó ṣe kedere hàn pé Èlíṣà ní ìtìlẹ́yìn àtọ̀runwá gẹ́gẹ́ bí arọ́pò Èlíjà.—Àwọn Ọba Kejì 2:11-14.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Nígbà tí a nawọ́ ìkésíni láti ṣe iṣẹ́ ìsìn àkànṣe pẹ̀lú Èlíjà sí i, ojú ẹsẹ̀ ni Èlíṣà fi pápá rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìránṣẹ́ fún wòlíì títayọ jù lọ ní Ísírẹ́lì. Ó hàn kedere pé, díẹ̀ nínú iṣẹ́ rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú, nítorí a mọ̀ ọ́n sì ẹni tí ó “ń tú omi sí ọwọ́ Èlíjà.”c (Àwọn Ọba Kejì 3:11) Síbẹ̀síbẹ̀, Èlíṣà wo iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan, ó sì fi ìdúróṣinṣin dúró ti Èlíjà gbágbágbá.
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ń fi irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ bẹ́ẹ̀ hàn. Àwọn kan ti fi “pápá” wọn, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, sílẹ̀, láti wàásù ìhìn rere ní àwọn ìpínlẹ̀ jíjìnnà réré tàbí láti sìn gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Àwọn mìíràn ti rìnrìn àjò lọ sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi iṣẹ́ ìkọ́lé ti Society. Ọ̀pọ̀ ti tẹ́wọ́ gba ohun tí a lè pé ní iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú. Síbẹ̀, kò sí ẹni tí ń sin Jèhófà tí iṣẹ́ rẹ̀ kò ṣe pàtàkì. Jèhófà mọyì gbogbo àwọn tí ó bá fi tinútinú sìn ín, yóò sì bú kún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọn.—Máàkù 10:29, 30.
Èlíṣà dúró gbágbágbá ti Èlíjà títí dé òpin. Ó kọ̀ láti fi wòlíì àgbàlagbà náà sílẹ̀ àní nígbà tí ó fún un ní àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kò sí iyè méjì pé, ipò ìbátan tímọ́tímọ́ tí ó ti mú dàgbà pẹ̀lú Èlíjà mú kí irú ìfẹ́ onídùúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ gbádùn mọ́ ọn. Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń sakun láti fún ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lókun, kí wọ́n sì túbọ̀ sún mọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. A óò bù kún ìdè ìṣọ̀kan tímọ́tímọ́, nítorí Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.”—Sámúẹ́lì Kejì 22:26, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ náà, “àwọn ọmọ àwọn wòlíì,” lè túmọ̀ sí ilé ẹ̀kọ́ kan tí ó wà fún àwọn tí a pè fún iṣẹ́ yìí tàbí kí ó wulẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àjùmọ̀ṣe àwọn wòlíì.
b Àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà ni Èlíjà kọ ìhìn iṣẹ́ rẹ ránṣẹ́ sí Ọba Jèhórámù ti Júdà.—Kíróníkà Kejì 21:12-15.
c Ó jẹ́ àṣà fún ìránṣẹ́ kan láti tú omi sí ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè fi fọ̀ ọwọ́, ní pàtàkì, lẹ́yìn oúnjẹ. Àṣà yí fara jọ ti wíwẹ ẹsẹ̀, tí ó jẹ́ ìwà aájò àlejò, ọ̀wọ̀, àti ní ọ̀pọ̀ àyíká ipò, ó jẹ́ ìrẹ̀lẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 24:31, 32; Jòhánù 13:5.