Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín!
NÍ ILÉ ẹ̀kọ́ gíga kan ní Nàìjíríà, ọmọbìnrin kan tí ó gbajúmọ̀ fún ìwà pálapàla takọtabo kúndùn dídá àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbálòpọ̀. Ọ̀kan lára àwọn egbòogi tó júwe fún ìṣẹ́yún ni ọtí sítáòtù tó ní ọ̀pọ̀ ohun kan tí a fi tábà ṣe nínú. Àwọn ìtàn tí ó ń sọ, tí ó máa ń fà yọ láti inú àwọn ìwé arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, fa ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mọ́ra. Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìbálòpọ̀ dánra wò, ọ̀kan nínú wọ́n sì gboyún. Láti ṣẹ́ oyún náà, ó mu egbòogi àdàlú ọtí sítáòtù òun tábà náà. Láàárín wákàtí díẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pọ ẹ̀jẹ̀. Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó kú sílé ìwòsàn.
Nínú ayé òde òní, ọ̀pọ̀ èwe kì í jánu lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, wọ́n sì ń fa ìparun fún àwọn aláìmọ̀kan tí ń tẹ́tí sí wọn. Ọ̀dọ̀ ta ni ó yẹ kí àwọn èwe yíjú sí láti gba ìmọ̀ pípéye tí yóò dáàbò bò wọ́n? Ẹ wo bí ó ti dára tó bí wọ́n bá lè yíjú sí àwọn òbí wọn olùṣèfẹ́-Ọlọ́run, tó ní ẹrù iṣẹ́ títọ́ wọn dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.
Ìṣarasíhùwà Àwọn Ará Áfíríkà sí Ẹ̀kọ́ Nípa Ìbálòpọ̀
Jákèjádò ayé, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ òbí láti bá àwọn ọmọ wọn jíròrò nípa ìbálòpọ̀. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì ní Áfíríkà. Donald, bàbá kan ní Sierra Leone, sọ pé: “Èèwọ̀ ni. Kì í ṣe àṣà ilẹ̀ Áfíríkà láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Obìnrin ará Nàìjíríà kan tó ń jẹ́ Confident fohùn ṣọkàn, ó wí pé: “Àwọn òbí mi ń wo ìbálòpọ̀ bí ohun kan tí a kò gbọ́dọ̀ dárúkọ ní gbangba; èèwọ̀ ni nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa.”
Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan ní Áfíríkà, a ka sísọ àwọn ọ̀rọ̀ tó tan mọ́ ìbálòpọ̀ bí okó, àtọ̀, tàbí nǹkan oṣù, sí ìsọkúsọ. Ìyá kan tó jẹ́ Kristẹni tilẹ̀ kọ̀ fún ọmọbìnrin rẹ̀ láti lo ọ̀rọ̀ náà, “ìbálòpọ̀,” bí ó tilẹ̀ sọ pé ọmọbìnrin náà lè lo ọ̀rọ̀ náà, “àgbèrè.” Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa ìbálòpọ̀ àti àwọn ẹ̀yà ara ìbálòpọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 17:11; 18:11; 30:16, 17; Léfítíkù 15:2) Èyí kì í ṣe láti dáni níjì tàbí láti runi sókè, bí kò ṣe láti dáàbò bo àwọn ènìyàn Ọlọ́run àti láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́.—2 Tímótì 3:16.
Yàtọ̀ sí ti èèwọ̀ inú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, bàbá kan tó jẹ́ ará Nàìjíríà sọ ìdí mìíràn tí àwọn òbí kan ṣe ń lọ́ra, ó wí pé: “Bí mo bá bá àwọn ọmọ mi jíròrò nípa ìbálòpọ̀, ó lè sún wọn hùwà pálapàla.” Àmọ́, ǹjẹ́ ìsọfúnni tí a pèsè lọ́nà tó wuyì, tí a gbé karí Bíbélì, nípa ìbálòpọ̀, ń fún àwọn ọmọ níṣìírí láti jáde lọ, kí wọ́n sì fi dánra wò bí? Rárá, kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ti gidi, ó lè jẹ́ pé bí ìmọ̀ tí àwọn èwe ní ṣe kéré tó ni bí wọ́n ṣe lè kó síjọ̀ngbọ̀n ṣe pọ̀ tó. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n [tí a gbé karí ìmọ̀ pípéye] jẹ́ fún ìdáàbòbò.”—Oníwàásù 7:12.
Nínú àkàwé Jésù, ọkùnrin olóye kan, tí ó rí i tẹ́lẹ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ìjì jà lọ́jọ́ iwájú, kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà, nígbà tí òmùgọ̀ ọkùnrin kan kọ́ tirẹ̀ sórí iyanrìn, tí ìjàǹbá sì bá a. (Mátíù 7:24-27) Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni òbí tó lóye, ń fi ìmọ̀ pípéye àti òye tí yóò ràn àwọn ọmọ náà lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin gbé wọn ró, ní mímọ̀ pé àwọn ọmọ wọn yóò kojú pákáǹleke tó dà bí ìjì láti mú ara wọn bá àwọn ìlànà oníwà àìmọ́ ti ìbálòpọ̀ ti ayé mu.
Obìnrin ará Áfíríkà kan tún sọ ìdí mìíràn tí ọ̀pọ̀ òbí kì í fi í bá àwọn ọmọ wọn jíròrò nípa ìbálòpọ̀, ó wí pé: “Nígbà tí mo wà ní èwe, àwọn òbí mi tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí kò bá mi jíròrò ọ̀ràn ìbálòpọ̀ rárá, nítorí náà, kò wá sọ́kàn mi láti bá àwọn ọmọ mi jíròrò àwọn nǹkan wọ̀nyí.” Ṣùgbọ́n, àwọn pákáǹleke tí àwọn èwe òde òní ń kojú pọ̀ ju ti àwọn èwe ní ọdún 10 tàbí 20 ọdún sẹ́yìn lọ. Èyí kò yani lẹ́nu. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn . . . , àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.”—2 Tímótì 3:1, 13.
Ohun tó tún ń dá kún ìṣòro náà ni pé ọ̀pọ̀ ọmọ ń lọ́ra láti finú han àwọn òbí wọn, tàbí wọn kò lè finú hàn wọ́n. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ alásọgbà lórí àwọn ọ̀ràn kéékèèké pàápàá. Ọ̀dọ́ ọlọ́dún 19 kan kédàárò pé: “N kì í bá àwọn òbí mi jíròrò àwọn ọ̀ràn. Kò sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídánmọ́rán láàárín èmi àti bàbá mi. Kì í tẹ́tí sí mi.”
Àwọn èwe tún lè máa bẹ̀rù pé bíbéèrè ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ yóò ní ìyọrísí búburú. Ọmọbìnrin ọlọ́dún 16 kan wí pé: “N kì í bá àwọn òbí mi jíròrò àwọn ìṣòro ìbálòpọ̀ nítorí bí wọ́n ṣe máa ń hùwà pa dà sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Nígbà kan, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin bi Mọ́mì léèrè àwọn ìbéèrè kan nípa ìbálòpọ̀. Dípò kí Mọ́mì ràn án lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro tó ní, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí èrò ọkàn rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, Mọ́mì yóò pè mí, wọn yóò sì wádìí nípa ẹ̀gbọ́n mi, nígbà mìíràn, wọn yóò máa dọ́gbọ́n ṣiyè méjì nípa ìwà rere rẹ̀. N kò fẹ́ ṣe ohun tí ó lè mú kí ń pàdánù ìfẹ́ tí Mọ́mì ní sí mi, nítorí náà, mo ń fi àwọn ìṣòro mi pa mọ́ fún wọn.”
Èrèdí Ìdánilẹ́kọ̀ọ́?
Dídá àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbálòpọ̀ dé àyè kan tí ó pọ̀ tó kì í wulẹ̀ ṣe ohun tó tọ́ lásán, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun onínúure láti ṣe. Bí àwọn òbí kò bá kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ìbálòpọ̀, àwọn ẹlòmíràn yóò kọ́ wọn—lọ́pọ̀ ìgbà, yóò yá ju bí àwọn òbí ti retí lọ, ó sì sábà ń jẹ́ lọ́nà tí kò bá ìlànà ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ọmọbìnrin ọlọ́dún 13 kan ṣàgbèrè nítorí pé akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan nílé ẹ̀kọ́ sọ fún un pé bí kò bá já ìbálé rẹ̀, yóò kojú ìrora lílekoko lọ́jọ́ iwájú. Ó sọ fún un pé: “Àlùmọ́gàjí ni wọn yóò fi já a fún ọ.” Nígbà tí a wá bi í lẹ́yìn náà pé kí ló dé tí kò sọ ohun tó gbọ́ náà fún ìyá rẹ̀ tó jẹ́ Kristẹni, ọmọbìnrin náà sọ pé a kì í bá àwọn àgbàlagbà jíròrò irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀.
Ọmọbìnrin ará Nàìjíríà kan wí pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi nílé ẹ̀kọ́ gbìyànjú láti mú mi gbà gbọ́ pé gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tí ara rẹ̀ bá pé ló gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀. Wọ́n sọ fún mi pé, bí n kò bá ní ìbálòpọ̀ nísinsìnyí, nígbà ti mo bá pé ọmọ ọdún 21, n ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àìsàn kan tí yóò nípa búburú lórí ipò mi bí obìnrin. Nítorí náà, wọ́n sọ pé láti dènà irú ewu burúkú bẹ́ẹ̀, ó dára láti ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó.”
Nítorí pé ó ti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídánmọ́rán pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó ti mọ̀ pé èyí forí gbárí pẹ̀lú ohun tí òun ti kọ́ nílé. “Bí mo ti máa ń ṣe, mo padà sílé, mo sì sọ ohun tí wọ́n sọ fún mi nílé ẹ̀kọ́ fún ìyá mi.” Ó ṣeé ṣe fún ìyá rẹ̀ láti pèsè ìsọfúnni tí ó borí ìsọfúnni èké náà.—Fi wé Òwe 14:15.
Nípa fífún àwọn ọmọ ní ìmọ̀ tí wọ́n nílò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ọgbọ́n Ọlọ́run nínú àwọn ọ̀ràn ìbálòpọ̀, àwọn òbí ń mú wọn gbára dì láti fòye mọ àwọn ipò eléwu, kí wọ́n sì mọ àwọn ènìyàn tí ń fẹ́ kó wọn nífà. Ó ń ṣèrànwọ́ láti gbà wọ́n lọ́wọ́ ìrora ọkàn tí àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré àti oyún tí a kò fẹ́ ń fà. Ó ń dá kún iyì ara ẹni wọn àti iyì tí àwọn ẹlòmíràn ń ní fún wọn. Ó ń gbà wọ́n lọ́wọ́ èrò òdì àti hílàhílo. Ó ń mú ìṣarasíhùwà gbígbámúṣé, tí ó dára dàgbà nípa ìbálòpọ̀ yíyẹ, tí yóò dá kún ayọ̀ wọn bí wọ́n bá ṣègbéyàwó lẹ́yìn ọ̀la. Ó lè mú kí wọ́n máa bá a lọ láti rí ojú rere Ọlọ́run. Bí àwọn ọmọ bá sì ṣe ń rí àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí a ń fi hàn sí wọn, ó lè mú kí wọ́n túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn sí i.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídánmọ́rán
Kí àwọn òbí lè darí ìmọ̀ràn lọ́nà tí yóò bá ohun tí àwọn ọmọ wọn nílò mu, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ alásọgbà. Láìjẹ́ pé àwọn òbí mọ ohun tó wà nínú àti lọ́kàn àyà àwọn ọmọ wọn, ìmọ̀ràn yíyèkooro pàápàá lè má ṣàǹfààní tó bẹ́ẹ̀, yóò rí bíi ti dókítà tí ń gbìyànjú láti kọ egbòogi fún aláìsàn láìmọ irú àìsàn tó ń ṣe é. Láti jẹ́ agbaninímọ̀ràn gbígbéṣẹ́, àwọn òbí gbọ́dọ̀ mọ èrò àti ìmọ̀lára àwọn ọmọ wọn ní gidi. Ó yẹ kí wọ́n lóye àwọn pákáǹleke àti ìṣòro tí àwọn ọmọ wọn ń kò lójú àti àwọn ìbéèrè tí ń dà wọ́n lọ́kàn rú. Ó ṣe pàtàkì láti fara balẹ̀ tẹ́tí sí àwọn ọmọ, kí a “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jákọ́bù 1:19; Òwe 12:18; Oníwàásù 7:8.
Ó ń gba àkókò, sùúrù, àti ìsapá lọ́dọ̀ àwọn òbí láti mú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa bá a nìṣó, ipò ìbátan kan nínú èyí tí àwọn ọmọ ti lómìnira láti sọ èrò inú wọn jíjinlẹ̀ jù lọ jáde. Àmọ́, ẹ wo bí yóò ti dára tó bí a bá lè ṣe èyí! Bàbá ọlọ́mọ márùn-ún kan láti Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà sọ pé: “Mo jẹ́ bàbá, mo sì tún jẹ́ aláfọ̀rànlọ̀. Àwọn ọmọ ń bá mi jíròrò gbogbo ọ̀ràn, títí kan ọ̀ràn ìbálòpọ̀, ní fàlàlà. Kódà, àwọn ọmọbìnrin ń finú hàn mí. A ń lo àkókò láti jíròrò àwọn ìṣòro wọn. Wọ́n tún ń ṣalábàápín ayọ̀ wọn pẹ̀lú mi.”
Bọ́lá, ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ wí pé: “Èmi kì í fi àṣírí kankan pa mọ́ fún bàbá mi. Bàbá jẹ́ olùgbatẹnirò àti abánikẹ́dùn. Wọn kì í bú mọ́ wa tàbí hùwà òǹrorò sí wa, kódà nígbà tí a bá ṣe àṣìṣe. Kàkà kí wọ́n gbiná jẹ, wọn óò ṣàtúpalẹ̀ ọ̀ràn náà, wọn óò sì fi ohun tí ó yẹ kí a ṣe tàbí ohun tí a kì bá tí ṣe hàn wá. Wọ́n sábà máa ń tọ́ka sí ìwé Ìgbà Èwe àti ìwé Ayọ̀ Ìdílé.”a
Nígbà tó bá ṣeé ṣe, ó dára pé kí àwọn òbí bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ nígbà tí àwọn ọmọ náà ṣì kéré gan-an. Èyí ń fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìjíròrò tí ń bá a lọ jálẹ̀ àwọn ọdún ìbàlágà tí ó sábà máa ń nira. Nígbà tí a kò bá tètè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, ó máa ń ṣòro nígbà mìíràn láti bẹ̀rẹ̀ wọn lẹ́yìnwá ọ̀la, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe. Ìyá ọlọ́mọ márùn-ún kan wí pé: “Mo mú ara mi lọ́ràn-anyàn láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ títí di ìgbà tí kò ti èmi àti ọmọ náà lójú mọ́ níkẹyìn.” Lójú ọ̀pọ̀ ohun tó rọ̀ mọ́ ọn, irú ìsapá bẹ́ẹ̀ yẹ.
Àwọn Ọmọ Tí A Dáàbò Bò Tí Wọ́n sì Láyọ̀
Àwọn ọmọ máa ń mọyì àwọn òbí tó mú wọn gbára dì nípa fífún wọn ní ìmọ̀ tí yóò dáàbò bò wọ́n tìfẹ́tìfẹ́. Gbé ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ará Áfíríkà kan sọ yẹ̀ wò:
Mojísọ́lá sọ, nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún 24, pé: “N ò ní yé dúpẹ́ lọ́wọ́ màmá mi. Ó fún mi ní ẹ̀kọ́ tí mo nílò nípa ìbálòpọ̀ ní àkókò tó yẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tì mí lójú nígbà tí ó ń bá mi jíròrò àwọn ọ̀ràn wọ̀nyẹn tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, nísinsìnyí, mo ń rí àǹfààní ohun tí màmá mi ṣe fún mi.”
Iniobong fi kún un pé: “Inú mi máa ń dùn nígbà gbogbo tí mo bá bojú wẹ̀yìn, tí mo sì ronú ohun tí Mọ́mì ti ṣe fún mi nípa dídá mi lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà pípéye nípa ìbálòpọ̀. Ó ti jẹ́ ìrànwọ́ ṣíṣekókó gidigidi ní títọ́ mi di àgbà obìnrin. Mo jẹ́jẹ̀ẹ́ pé n ó ṣe bákan náà fún àwọn ọmọ mi lọ́jọ́ iwájú.”
Kúnlé, ọmọ ọdún 19, sọ pé: “Àwọn òbí mi ti ràn mí lọ́wọ́ láti kojú pákáǹleke láti ọ̀dọ̀ àwọn obìnrin ayé tí ń fẹ́ kí n bá àwọn lò pọ̀ lọ́fẹ̀ẹ́. Bí kò bá jẹ́ nítorí ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn òbí mi fún mi ni, ǹ bá ti dẹ́ṣẹ̀. N ò ní yé mọrírì ohun tí wọ́n ṣe.”
Christiana wí pé: “Mo jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ láti inú ìjíròrò tí mo ní pẹ̀lú màmá mi nípa ìbálòpọ̀. A ti dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn àrùn aṣekúpani àti oyún tí a kò fẹ́, ó sì ti ṣeé ṣe fún mi láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn àbúrò mi lọ́kùnrin àti lóbìnrin láti tẹ̀ lé. Mo tún ti jèrè ọ̀wọ̀ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn, ọkọ mi ọjọ́ ọ̀la yóò bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú. Ní pàtàkì jù lọ, mo ní ìbátan rere pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run nítorí pé mo ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.”
Bọ́lá, tí a mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀, sọ pé: “Akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan sọ pé ó yẹ kí a máa gbádùn ìbálòpọ̀ láìwọnú àdéhùn ìgbéyàwó. Lójú tirẹ̀, ohun àmúṣeré ni. Ṣùgbọ́n, ó wá mọ̀ pé ohun àmúṣeré kọ́ nígbà tí ó gboyún, tí kò sì lè bá wa ṣèdánwò àṣejáde. Bí n kò bá ti ní bàbá rere láti tọ́ mi sọ́nà, mo ti lè rí bíi tirẹ̀, kí n máa fi ìrírí burúkú tí mo bá ní kọ́ ara mi lẹ́kọ̀ọ́.”
Ẹ wo irú ìbùkún tí ó jẹ́ nígbà tí àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni bá ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà” nínú ayé tí ìbálòpọ̀ ń sín níwín yìí! (2 Tímótì 3:15) Àwọn ìtọ́ni wọn tí wọ́n gbé karí Bíbélì dà bí àtàtà ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tó ń ṣe àwọn ọmọ lọ́ṣọ̀ọ́, tó sì ń mú wọn rẹwà lójú Ọlọ́run. (Òwe 1:8, 9) Ọkàn àwọn ọmọ ń balẹ̀, àwọn òbí sì ń ní ìtẹ́lọ́rùn gidigidi. Bàbá ará Áfíríkà kan, tó sábà máa ń gbìyànjú láti ṣí ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀, wí pé: “Ọkàn wa balẹ̀. A ní ìgbọ́kànlé pé àwọn ọmọ wa mọ ohun tó wu Jèhófà; àwọn ará ìta kò lè ṣì wọ́n lọ́nà. A ní ìgbọ́kànlé pé wọn kì yóò ṣe ohun tí yóò ba ìdílé wa nínú jẹ́. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé wọ́n ti fi hàn pé wọ́n tọ́, wọ́n sì yẹ fún ìgbọ́kànlé wa.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn èwe Kristẹni, tí àwọn òbí ti fún ní ìsọfúnni tí a gbé karí Bíbélì, lè kọ àwọn ìtàn èké tí àwọn èwe mìíràn ń sọ sílẹ̀