Àwọn Àjọyọ̀ Mánigbàgbé Inú Ìtàn Ísírẹ́lì
“Ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún, kí gbogbo tìrẹ tí ó jẹ́ ọkùnrin fara hàn níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí òun yóò yàn . . . , kí ẹnì kankan má sì fara hàn níwájú Jèhófà lọ́wọ́ òfo.”—DIUTARÓNÓMÌ 16:16.
1. Kí ni a lè sọ nípa àwọn àkókò àjọyọ̀ ní àkókò tí a kọ Bíbélì?
KÍ NÍ ń wá sọ́kàn rẹ nígbà tí o bá ronú nípa àjọyọ̀? Ìkẹ́rabàjẹ́ àti ìwà pálapàla ni ó sàmì sí àwọn àjọyọ̀ kan nígbà ìjímìjí. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn àwọn àjọyọ̀ kan lóde òní ṣe rí. Ṣùgbọ́n àwọn àjọyọ̀ tí a là sílẹ̀ nínú Òfin Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì yàtọ̀ pátápátá. Bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ àkókò aláyọ̀, a tún lè ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí “àpéjọpọ̀ mímọ́.”—Léfítíkù 23:2.
2. (a) Kí ni a ń béèrè pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ọkùnrin ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún? (b) Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lo ọ̀rọ̀ náà nínú Diutarónómì 16:16, kí ni “àjọyọ̀”?
2 Àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ ọmọ Ísírẹ́lì—tí àwọn ìdílé wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé lọ́pọ̀ ìgbà—ń rí ìdùnnú títunilára ní rírìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù, ‘ibi tí Jèhófà yàn,’ wọ́n sì máa ń fi ọ̀làwọ́ ṣètọrẹ fún àwọn àjọyọ̀ ńlá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà. (Diutarónómì 16:16) Ìwé náà, Old Testament Word Studies, túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù tí a tú sí “àjọyọ̀” nínú Diutarónómì 16:16 sí “àkókò ìdùnnú ńláǹlà . . . tí a ń fi ìrúbọ àti àsè ṣayẹyẹ àwọn ìgbà tí Ọlọ́run ṣojú rere síni lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.”a
Ìníyelórí Àwọn Àjọyọ̀ Ńlá Náà
3. Àwọn ìbùkún wo ni àwọn àjọyọ̀ mẹ́ta náà tí a ń ṣe lọ́dọọdún mú wá sọ́kàn rẹ?
3 Níwọ̀n bí àwùjọ wọ́n ti jẹ́ ti oníṣẹ́ àgbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbára lé ìbùkún Ọlọ́run ní ti òjò. Àwọn àjọyọ̀ mẹ́ta ńlá tí ó wà nínú Òfin Mósè ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú ìkórè ọkà báálì ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé, ìkórè àlìkámà ní òpin ìgbà ìrúwé, àti ìyókù ìkórè ní òpin ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Ìwọ̀nyí jẹ́ àkókò fún ìdùnnú ńláǹlà àti ìdúpẹ́ lọ́wọ́ Olùgbé ìyípoyípo òjò ró àti Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ eléso. Ṣùgbọ́n, ohun tí ó wé mọ́ àwọn àjọyọ̀ náà ju ìwọ̀nyí lọ.—Diutarónómì 11:11-14.
4. Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé wo ni a ń fi àjọyọ̀ àkọ́kọ́ ṣayẹyẹ rẹ̀?
4 Àjọyọ̀ àkọ́kọ́ ń wáyé ní oṣù àkọ́kọ́ nínú kàlẹ́ńdà Bíbélì àtayébáyé, láti Nísàn 15 sí 21, tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìparí oṣù March tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù April wa. A pè é ní Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú, nítorí tí ó sì ń wáyé ní kété lẹ́yìn Ìrékọjá Nísàn 14, a tún pè é ní “àjọyọ̀ ìrékọjá.” (Lúùkù 2:41; Léfítíkù 23:5, 6) Àjọyọ̀ yìí rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí dídá tí a dá wọn nídè lọ́wọ́ ìṣẹ́ ní Íjíbítì, a sì pe àkàrà aláìwú náà ní “oúnjẹ ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́.” (Diutarónómì 16:3) Ó rán wọn létí pé ìjádelọ wọn kúrò ní Íjíbítì jẹ́ kánjúkánjú débi pé, wọn kò rí àyè láti fi ìwúkàrà sínú ìyẹ̀fun àpòrọ́ wọn, kí wọ́n sì dúró kí ó wú. (Ẹ́kísódù 12:34) Lásìkò àjọyọ̀ yìí, a kò gbọ́dọ̀ rí búrẹ́dì tí ó ní ìwúkàrà nínú ilé ọmọ Ísírẹ́lì kankan. Pípa ni a óò pa olùṣàjọyọ̀ èyíkéyìí, títí kan àtìpó, tí ó bá jẹ búrẹ́dì tí ó ní ìwúkàrà.—Ẹ́kísódù 12:19.
5. Àǹfààní wo ni àjọyọ̀ kejì lè ti múni rántí, àwọn wo sì ni ó yẹ kí ó dara pọ̀ nínú ayọ̀ náà?
5 Àjọyọ̀ kejì ń wáyé lọ́sẹ̀ keje (ọjọ́ 49) lẹ́yìn Nísàn 16, ó sì máa ń bọ́ sí ọjọ́ kẹfà oṣù kẹta, Sífánì, tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìparí oṣù May wa. (Léfítíkù 23:15, 16) A pè é ní Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ (ní ọjọ́ Jésù, a tún pè é ní Pẹ́ńtíkọ́sì, tí ó túmọ̀ sí “Àádọ́ta” ní èdè Gíríìkì), ó sì ń wáyé ní àkókò kan tí ó sún mọ́ àkókò náà láàárín ọdún tí Ísírẹ́lì wọnú májẹ̀mú Òfin ní Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 19:1, 2) Lákòókò àjọyọ̀ yìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olùṣòtítọ́ lè ti ṣàṣàrò lórí àǹfààní tí wọ́n ní láti jẹ́ àwọn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé, gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè mímọ́ ti Ọlọ́run. Jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ènìyàn àrà ọ̀tọ̀ fún Ọlọ́run ń béèrè pé kí wọ́n ṣègbọràn sí Òfin Ọlọ́run, irú bí àṣẹ tí ó sọ pé kí wọ́n fi àníyàn onífẹ̀ẹ́ hàn sí àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, kí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú lè gbádùn àjọyọ̀ náà.—Léfítíkù 23:22; Diutarónómì 16:10-12.
6. Ìrírí wo ni àjọyọ̀ kẹta rán àwọn ènìyàn Ọlọ́run létí rẹ̀?
6 A pe èyí tí ó kẹ́yìn nínú àwọn àjọyọ̀ ńlá mẹ́ta tí a ń ṣe lọ́dọọdún náà ní Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé, tàbí Àjọyọ̀ Àtíbàbà. Ó ń wáyé ní oṣù keje, Tíṣírì, tàbí Étánímù, láti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún sí ọjọ́ kọkànlélógún, tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October wa. (Léfítíkù 23:34) Lásìkò yìí, àwọn ènìyàn Ọlọ́run máa ń gbé lóde ilé wọn tàbí lórí òrùlé wọn, nínú àwọn ibùgbé onígbà díẹ̀ (àtíbàbà) tí a fi àwọn ẹ̀ka àti ewé igi ṣe. Èyí rán wọn létí ìrìn àjò wọn ológójì ọdún láti Íjíbítì sí Ilẹ̀ Ìlérí, nígbà tí orílẹ̀-èdè náà kọ́ láti gbára lé Ọlọ́run fún àwọn àìní wọn ojoojúmọ́.—Léfítíkù 23:42, 43; Diutarónómì 8:15, 16.
7. Báwo ni a ṣe jàǹfààní láti inú ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ayẹyẹ àjọyọ̀ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì?
7 Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn àjọyọ̀ kan tí ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n jẹ́ mánigbàgbé nínú ìtàn àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ìjímìjí. Ó yẹ kí èyí fún wa níṣìírí lónìí, níwọ̀n bí a ti ké sí àwa pẹ̀lú láti pé jọ déédéé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún nínú àwọn àpéjọ ńlá àti àpéjọpọ̀.—Hébérù 10:24, 25.
Ní Àkókò Àwọn Ọba Ìlà Dáfídì
8. (a) Ayẹyẹ mánigbàgbé wo ni ó wáyé ní ọjọ́ Ọba Sólómọ́nì? (b) Òtéńté títóbilọ́lá ti Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí ó jẹ́ amápẹẹrẹṣẹ wo ni a lè fojú sọ́nà fún?
8 Ayẹyẹ mánigbàgbé kan nígbà Àjọyọ̀ Àtíbàbà wáyé nígbà àkóso aláásìkí Ọba Sólómọ́nì, ọmọ Dáfídì. “Ìjọ títóbi gan-an” kóra jọ láti àwọn ìpẹ̀kun Ilẹ̀ Ìlérí fún Àjọyọ̀ Àtíbàbà àti yíya tẹ́ńpìlì sí mímọ́. (2 Kíróníkà 7:8) Nígbà tí ó parí, Ọba Sólómọ́nì tú àwọn olùṣàjọyọ̀ náà ká, wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn, wọ́n ń yọ̀, wọ́n sì ń ṣàríyá nínú ọkàn-àyà wọn lórí gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀ àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 8:66) Ìyẹn jẹ́ àjọyọ̀ mánigbàgbé kan ní tòótọ́. Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń fojú sọ́nà fún òtéńté títóbilọ́lá Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí ó jẹ́ amápẹẹrẹṣẹ lópin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Sólómọ́nì Títóbi Jù náà, Jésù Kristi. (Ìṣípayá 20:3, 7-10, 14, 15) Ní àkókò yẹn, àwọn ènìyàn tí ń gbé ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, títí kan àwọn tí a jí dìde àti àwọn tí ó la Amágẹ́dónì já, yóò ṣọ̀kan nínú ìjọsìn onídùnnú ti Jèhófà Ọlọ́run.—Sekaráyà 14:16.
9-11. (a) Kí ni ó fa àjọyọ̀ mánigbàgbé ní ọjọ́ Ọba Hesekáyà? (b) Àpẹẹrẹ wo ni ọ̀pọ̀ tí ó wá láti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá fi lélẹ̀, kí sì ni ó rán wa létí rẹ̀ lónìí?
9 Àjọyọ̀ títayọlọ́lá mìíràn tí Bíbélì ròyìn rẹ̀ wáyé lẹ́yìn àkóso Ọba Áhásì búburú, tí ó ti tẹ́ńpìlì pa, tí ó sì sún ìjọba Júdà sínú ìpẹ̀yìndà. Ọba Hesekáyà rere ló jẹ tẹ̀ lé Áhásì. Ní ọdún àkọ́kọ́ ìjọba rẹ̀, ní ọmọ ọdún 25, Hesekáyà bẹ̀rẹ̀ ètò ńlá ti ìmúpadàbọ̀sípò àti ìṣàtúnṣe. Lọ́gán ni ó ṣí tẹ́ńpìlì, tí ó sì ṣètò fún àtúnṣe rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ọba fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé nínú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá rírorò ti Ísírẹ́lì ní àríwá, ó ké sí wọn láti wa ṣayẹyẹ Ìrékọjá àti ti Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú. Ọ̀pọ̀ wá, láìka ìfiṣẹ̀sín àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn sí.—2 Kíróníkà 30:1, 10, 11, 18.
10 Àjọyọ̀ náà ha yọrí sí rere bí? Bíbélì ròyìn pé: “Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a rí ní Jerúsálẹ́mù fi ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà ṣe àjọyọ̀ àwọn àkàrà aláìwú ní ọjọ́ méje; àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà sì ń fi àwọn ohun èlò orin olóhùn gooro mú ìyìn wá fún Jèhófà lójoojúmọ́.” (2 Kíróníkà 30:21) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ àtàtà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn tí ń fara da àtakò, tí wọ́n sì ń rìnrìn àjò ọ̀nà jínjìn láti lọ sí àpéjọpọ̀!
11 Fún àpẹẹrẹ, gbé àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè mẹ́ta ti “Ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run,” tí a ṣe ní Poland ní ọdún 1989 yẹ̀ wò. Àwùjọ ńlá láti Soviet Union àtijọ́ àti àwọn orílẹ̀-èdè Ìlà Oòrùn Yúróòpù mìíràn, níbi tí a ti fòfin de iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà, wà lára àwọn 166,518 ènìyàn tí ó pé jọ. Ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdomb ròyìn pé: “Fún àwọn kan tí ó wá sí àpéjọpọ̀ yìí, ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí wọn yóò wà nínú àpéjọ ńlá ti àwọn ènìyàn Jèhófà tí ó lé ní 15 sí 20. Ọkàn-àyà wọ́n kún fún ìmọrírì bí wọ́n ti wo ẹgbẹẹgbàárùn-ún ènìyàn ní àwọn pápá ìṣeré ìdárayá, tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ wọn nínú àdúrà, tí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ wọn nínú kíkọrin ìyìn sí Jèhófà.”—Ojú ìwé 279.
12. Kí ni ó fa àjọyọ̀ mánigbàgbé nígbà ìṣàkóso Ọba Jòsáyà?
12 Lẹ́yìn ikú Hesekáyà, àwọn ará Júdà tún ṣubú lẹ́ẹ̀kan si sínú ìjọsìn èké lábẹ́ Ọba Mánásè àti Ámónì. Ìjọba ọba rere náà, Jòsáyà ọ̀dọ́, tí ó fìgboyà gbégbèésẹ̀ ní mímú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò, ni ó tẹ̀ lé e. Nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún 25, Jòsáyà pàṣẹ pé kí a tún tẹ́ńpìlì ṣe. (2 Kíróníkà 34:8) Nígbà tí wọ́n ń ṣe àtúnṣe náà lọ́wọ́, wọ́n rí Òfin tí Mósè kọ nínú tẹ́ńpìlì. Ohun tí Ọba Jòsáyà kà nínú Òfin Ọlọ́run wọ̀ ọ́ lọ́kàn gidigidi, ó sì ṣètò pé kí a kà á sí etígbọ̀ọ́ gbogbo ènìyàn. (2 Kíróníkà 34:14, 30) Lẹ́yìn náà, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ̀wé rẹ̀, ó ṣètò láti ṣayẹyẹ Ìrékọjá. Ọba náà tún fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa fífi ìwà ọ̀làwọ́ ṣètọrẹ fún ayẹyẹ náà. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, Bíbélì ròyìn pé: “A kò . . . ṣe irú ìrékọjá bẹ́ẹ̀ rí ní Ísírẹ́lì láti àwọn ọjọ́ Sámúẹ́lì wòlíì.”—2 Kíróníkà 35:7, 17, 18.
13. Kí ni ayẹyẹ àjọyọ̀ Hesekáyà àti Jòsáyà rán wa létí rẹ̀ lónìí?
13 Àtúnṣe tí Hesekáyà àti Jòsáyà ṣe jọ ìmúpadàbọ̀sípò àgbàyanu ti ìjọsìn tòótọ́ tí ó ti ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ láti ìgbà tí a ti gbé Jésù Kristi gun orí ìtẹ́ ní ọdún 1914. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí gan-an ní pàtàkì ní ti àtúnṣe tí Jòsáyà ṣe, a ti gbé ìmúpadàbọ̀sípò ti òde òní yìí karí ohun tí a kọ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ní jíjọ ọjọ́ Hesekáyà àti ti Jòsáyà, àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀, tí a ti ń ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì lọ́nà tí ń múni lọ́kàn yọ̀, tí a sì ti ń ṣàmúlò àwọn ìlànà Bíbélì lọ́nà tí ó ṣe kòńgẹ́ àkókò, ti sàmì sí ìmúpadàbọ̀sípò ti òde òní. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó ṣe batisí ti fi kún ayọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kún fún ìtọ́ni wọ̀nyí. Bí àwọn ọmọ́ Ísírẹ́lì tí ó ronú pìwà dà ní ọjọ́ Hesekáyà àti Jòsáyà, àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ batisí ti kẹ̀yìn sí àwọn àṣà búburú ti Kirisẹ́ńdọ̀mù àti ìyókù ayé Sátánì. Ní ọdún 1997, iye tí ó lé ní 375,000 ni ó ṣe batisí ní fífi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Ọlọ́run mímọ́ náà, Jèhófà, hàn—ìpíndọ́gba iye tí ó lé ní 1,000 lójoojúmọ́.
Lẹ́yìn Ìgbèkùn
14. Kí ni ó fa àjọyọ̀ mánigbàgbé ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa?
14 Lẹ́yìn ikú Jòsáyà, orílẹ̀-èdè náà tún yíjú sí ìjọsìn èké tí ń rẹni nípò wálẹ̀ lẹ́ẹ̀kan si. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà fìyà jẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ nípa mímú kí àwọn ọmọ ogun Bábílónì kọlu Jerúsálẹ́mù. A run ìlú náà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀, a sì sọ ilẹ̀ náà dahoro. Fún 70 ọdún tí ó tẹ̀ lé e, àwọn Júù di ìgbèkùn ní Bábílónì. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run ta àṣẹ́kù Júù tí ó ronú pìwà dà jí, wọ́n sì padà sí Ilẹ̀ Ìlérí láti mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò. Wọ́n dé ìlú Jerúsálẹ́mù tí a ti run náà ní oṣù keje ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ohun àkọ́kọ́ tí wọn ṣe ni láti gbé pẹpẹ kan kalẹ̀ láti máa rúbọ ojoojúmọ́ déédéé, gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú Òfin ti lànà rẹ̀. Èyí ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé mìíràn. “Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe àjọyọ̀ àtíbàbà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ̀wé rẹ̀.”—Ẹ́sírà 3:1-4.
15. Iṣẹ́ wo ni ó dúró de àṣẹ́kù tí a mú padà bọ̀ sípò ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, báwo sì ni ipò tí ó jọ ọ́ ṣe wáyé ní ọdún 1919?
15 Iṣẹ́ bàǹtàbanta kan ń bẹ níwájú àwọn ìgbèkùn tí ó padà wá náà—títún tẹ́ńpìlì Ọlọ́run àti Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn ògiri rẹ̀ kọ́. Ọ̀pọ̀ àtakò wá láti ọ̀dọ̀ àwọn òjòwú aládùúgbò. Nígbà tí a kọ́ tẹ́ńpìlì náà, ó jẹ́ “ọjọ́ àwọn ohun kékeré.” (Sekaráyà 4:10) Ipò náà jọ ti àwọn olùṣòtítọ́ Kristẹni ẹni àmì òróró ní 1919. Ní ọdún mánigbàgbé yẹn, a tú wọn sílẹ̀ nínú ìgbèkùn tẹ̀mí ti Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Wọn kò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ, wọ́n sì dojú kọ ayé òǹrorò. Yóò ha ṣeé ṣe fún àwọn ọ̀tá Ọlọ́run láti dá ìlọsíwájú ìjọsìn tòótọ́ dúró bí? Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn múni rántí ayẹyẹ àjọyọ̀ méjì tí a ṣàkọsílẹ̀ kẹ́yìn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.
16. Kí ní ṣe pàtàkì nípa àjọyọ̀ kan ní ọdún 515 ṣááju Sànmánì Tiwa?
16 A tún tẹ́ńpìlì náà kọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín ní oṣù Ádárì ọdún 515 ṣááju Sànmánì Tiwa, tí ó ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú àkókò tí a ń ṣe àjọyọ̀ Nísàn, ìgbà ìrúwé. Bíbélì ròyìn pé: “Wọ́n . . ń bá a lọ ní fífi ayọ̀ yíyọ̀ ṣe àjọyọ̀ àwọn àkàrà aláìwú fún ọjọ́ méje; nítorí pé Jèhófà mú kí wọ́n máa yọ̀, ó sì yí ọkàn-àyà ọba Asíríà padà síhà ọ̀dọ̀ wọn láti fún ọwọ́ wọn lókun nínú iṣẹ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.”—Ẹ́sírà 6:22.
17, 18. (a) Àjọyọ̀ mánigbàgbé wo ni ó wáyé ní ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) Báwo ni a ṣe wà nínú irú ipò kan náà lónìí?
17 Ní 60 ọdún lẹ́yìn náà, ní ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Tiwa, a tún ṣe ohun mánigbàgbé kan. Àjọyọ̀ Àtíbàbà ọdún yẹn sàmì sí ìparí títún àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́. Bíbélì ròyìn pé: “Gbogbo ìjọ àwọn tí wọ́n padà láti oko òǹdè ṣe àwọn àtíbàbà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú àtíbàbà; nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀ láti ọjọ́ Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì títí di ọjọ́ yẹn, bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà wà.”—Nehemáyà 8:17.
18 Ẹ wo irú ìmúpadàbọ̀sípò mánigbàgbé ti ìjọsìn tòótọ́ Ọlọ́run tí èyí jẹ́ lójú àtakò mímúná! Ipò nǹkan lónìí rí bákan náà. Láìka ọ̀pọ̀ inúnibíni àti àtakò sí, iṣẹ́ títóbilọ́lá ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti dé òpin ilẹ̀ ayé, a sì ti ṣèkìlọ̀ ìhìn iṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run jákèjádò. (Mátíù 24:14) Àṣekágbá fífi èdìdì di ìyókù 144,000 ẹni àmì òróró ti sún mọ́lé. A ti kó iye tí ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún “àwọn àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè sínú “agbo kan” pẹ̀lú àṣẹ́kù ẹni àmì òróró náà. (Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 7:3, 9, 10) Ẹ wo irú ìmúṣẹ àgbàyanu ti àsọtẹ́lẹ̀ amápẹẹrẹṣẹ ti Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí èyí jẹ́! Iṣẹ́ títóbilọ́lá ti ìkórèwọlé yìí yóò máa bá a nìṣó wọnú ayé tuntun, nígbà tí a óò ké sí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tí a jí dìde láti dara pọ̀ nínú ṣíṣayẹyẹ Àjọyọ̀ Àtíbàbà tí ó jẹ́ amápẹẹrẹṣẹ.—Sekaráyà 14:16-19.
Ní Ọ̀rúndún Kìíní Sànmánì Tiwa
19. Kí ní mú kí Àjọyọ̀ Àtíbàbà ní ọdún 32 Sànmánì Tiwa tayọ lọ́lá?
19 Láìsí àní-àní, àwọn ayẹyẹ àjọyọ̀ tí Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Kristi lọ, wà lára àwọn àjọyọ̀ títayọlọ́lá jù lọ tí a ṣàkọsílẹ̀ nínú Bíbélì. Fún àpẹẹrẹ, gbé lílọ tí Jésù lọ sí Àjọyọ̀ Àtíbàbà (tàbí, Àwọn Àgọ́) ní ọdún 32 Sànmánì Tiwa, yẹ̀ wò. Ó lo àkókò náà láti kọ́ni ní àwọn òtítọ́ ṣíṣe pàtàkì, ó sì ti ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. (Jòhánù 7:2, 14, 37-39) Àṣà títan àwọn ọ̀pá fìtílà ńlá mẹ́rin nínú àgbàlá inú tẹ́ńpìlì jẹ́ ohun tí ó máa ń wáyé déédéé nígbà àjọyọ̀ yìí. Èyí ń fi kún gbígbádùn àwọn ìgbòkègbodò àjọyọ̀ tí a ń ṣe dalẹ́. Ó ṣe kedere pé, àwọn fìtílà ńlá wọ̀nyí ni Jésù ń sọ̀rọ̀ bá nígbà tí ó sọ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”—Jòhánù 8:12.
20. Èé ṣe tí Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Tiwa fi tayọ lọ́lá?
20 Lẹ́yìn èyí ni Ìrékọjá àti Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú ti ọdún mánigbàgbé náà, 33 Sànmánì Tiwa wáyé. Ní Ọjọ́ Ìrékọjá náà, àwọn ọ̀tá Jésù ṣekú pa á, ó sì di Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ìrékọjá tí ó jẹ́ amápẹẹrẹṣẹ, tí ó kú láti “kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòhánù 1:29; 1 Kọ́ríńtì 5:7) Ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ní Nísàn 16, Ọlọ́run jí Jésù dìde pẹ̀lú ara tẹ̀mí tí kò lè kú. Èyí ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú fífi àkọ́so ìkórè ọkà báálì rúbọ, gẹ́gẹ́ bí Òfin ti lànà rẹ̀. Nípa báyìí, Jésù Kristi Olúwa tí a jí dìde di “àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.”—1 Kọ́ríńtì 15:20.
21. Kí ní ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
21 Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ti ọdún 33 Sànmánì Tiwa jẹ́ èyí tí ó tayọ lọ́lá ní tòótọ́. Ní ọjọ́ yìí, ọ̀pọ̀ Júù àti aláwọ̀ṣe kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù, títí kan nǹkan bí 120 ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bí àjọyọ̀ náà ti ń lọ lọ́wọ́, Jésù Kristi Olúwa tí a jí dìde tú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sórí àwọn 120 náà. (Ìṣe 1:15; 2:1-4, 33) A tipa bẹ́ẹ̀ fòróró yàn wọ́n, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè tuntun tí Ọlọ́run yàn nípasẹ̀ májẹ̀mú tuntun tí Jésù Kristi ṣalárinà rẹ̀. Lásìkò àjọyọ̀ yẹn, àlùfáà àgbà àwọn Júù fi ìṣù búrẹ́dì méjì tí ó ní ìwúkàrà, tí a fi àkọ́so ìkórè àlìkámà ṣe, rúbọ sí Ọlọ́run. (Léfítíkù 23:15-17) Àwọn ìṣù búrẹ́dì tí ó ní ìwúkàrà wọ̀nyí dúró fún 144,000 ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, tí Jésù ‘rà fún Ọlọ́run’ láti sìn gẹ́gẹ́ bí “ìjọba kan àti àlùfáà . . . wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3) Òtítọ́ náà pé àwọn alákòóso ọ̀run wọ̀nyí wá láti inú ẹ̀ka méjì ti aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn Júù àti Kèfèrí, lè tún jẹ́ amápẹẹrẹṣẹ fún ìṣù búrẹ́dì méjì tí ó ní ìwúkàrà.
22. (a) Èé ṣe tí àwọn Kristẹni kì í fi í ṣayẹyẹ àwọn àjọyọ̀ inú májẹ̀mú Òfin? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e?
22 Nígbà tí májẹ̀mú tuntun náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó túmọ̀ sí pé májẹ̀mú Òfin láéláé náà ti ṣíwọ́ níníyelórí lójú Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 3:14; Hébérù 9:15; 10:16) Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kò lófin. Wọ́n wá sábẹ́ òfin àtọ̀runwá, tí Jésù Kristi fi kọ́ni, tí a sì kọ sórí ọkàn-àyà wọn. (Gálátíà 6:2) Nítorí náà, àwọn Kristẹni kì í ṣe àjọyọ̀ ọdọọdún mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, tí ó jẹ́ ara májẹ̀mú Òfin ti láéláé. (Kólósè 2:16, 17) Síbẹ̀síbẹ̀, a lè rí ohun púpọ̀ kọ́ láti inú ìṣarasíhùwà tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣáájú àkókò Kristẹni ní sí àwọn àjọyọ̀ wọn àti sí àwọn ìpàdé mìíràn fún ìjọsìn. Nínú àpilẹ̀kọ wa tí ó tẹ̀ lé e, a óò gbé àwọn àpẹẹrẹ tí ó dájú pé yóò sún gbogbo wa láti mọrírì ìjẹ́pàtàkì lílọ sí àwọn ìkórajọpọ̀ Kristẹni déédéé, yẹ̀ wò.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tún wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde, Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 820, ìlà 1, ìpínrọ̀ 1 àti 3, lábẹ́ “Festival” (Àjọyọ̀).
b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Ète wo ni àwọn àjọyọ̀ ńlá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní Ísírẹ́lì ṣiṣẹ́ fún?
◻ Kí ní ṣẹlẹ̀ nígbà àjọyọ̀ ọjọ́ Hesekáyà àti Jòsáyà?
◻ Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé wo ni a ṣayẹyẹ rẹ̀ ní ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa, èé sí ti ṣe tí ó fi jẹ́ ìṣírí fún wa?
◻ Kí ní ṣe pàtàkì nípa Ìrékọjá àti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́ Nínú Àjọyọ̀ náà Lónìí
Gbogbo àwọn tí yóò jàǹfààní pípẹ́títí láti inú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ Jésù gbọ́dọ̀ gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú náà dúró fún. Àjọyọ̀ amápẹẹrẹṣẹ yìí jẹ́ ayẹyẹ onídùnnú tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe nítorí ìdáǹdè wọn kúrò nínú ayé búburú yìí àti ìtúsílẹ̀ wọn kúrò nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà Jésù. (Gálátíà 1:4; Kólósè 1:13, 14) Ọjọ́ méje—nọ́ńbà tí a lò nínú Bíbélì láti ṣàpẹẹrẹ ìpépérépéré tẹ̀mí—ni a fi ṣe àjọyọ̀ gidi náà. Gbogbo àkókò tí ìjọ Kristẹni tí a fòróró yàn fi wà lórí ilẹ̀ ayé ni a fi ń ṣe àjọyọ̀ amápẹẹrẹṣẹ náà, a sì gbọ́dọ̀ ṣe é pẹ̀lú “òtítọ́ inú àti òtítọ́.” Èyí túmọ̀ sí wíwà lójúfò nígbà gbogbo fún ìwúkàrà ìṣàpẹẹrẹ náà. A lo ìwúkàrà nínú Bíbélì láti dúró fún àwọn ẹ̀kọ́ sísọni dìbàjẹ́, àgàbàgebè, àti ìwà burúkú. Àwọn olùjọsìn tòótọ́ ti Jèhófà gbọ́dọ̀ kórìíra irú ìwúkàrà bẹ́ẹ̀, ní ṣíṣàìjẹ́ kí ó ba ìgbésí ayé wọn jẹ́, kí wọ́n sì máà jẹ́ kí ó ba ìjẹ́mímọ́ ìjọ Kristẹni jẹ́.—1 Kọ́ríńtì 5:6-8; Mátíù 16:6, 12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
A máa ń fi ìtì ọkà báálì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kórè rúbọ lọ́dọọdún ní Nísàn 16, ọjọ́ tí a jí Jésù dìde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ó lè jẹ́ pé àwọn fìtílà tí a ń tàn nígbà àjọyọ̀ ni Jésù ń sọ̀rọ̀ bá, nígbà tí ó pe ara rẹ̀ ní “ìmọ́lẹ̀ ayé”