Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìyàsímímọ́ Kristẹni Ní Òmìnira
“Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá . . . wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 3:17.
1. Ta ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ya ara wọn sí mímọ́ fún, èé sì ti ṣe tí wọ́n fi ń lo àwọn irinṣẹ́ tí a fi òfin gbé kalẹ̀?
ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ gbà gbọ́ pé ẹ̀sìn wọn yóò wà títí láé. Nítorí náà, wọ́n fojú sọ́nà fún sísin Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” títí ayérayé. (Jòhánù 4:23, 24) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù, àwọn Kristẹni wọ̀nyí ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run láìkù síbì kan, wọ́n sì ti pinnu láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Láti ṣe èyí, wọ́n gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Bí wọ́n ti ń fi gbogbo ọkàn lépa ọ̀nà ìyàsímímọ́ Kristẹni wọn nínú òmìnira tí Ọlọ́run ti fún wọn, Àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi ọ̀wọ̀ tí ó yẹ hàn fún ipa tí ìjọba “aláṣẹ onípò gíga” ń kó, wọ́n sì ń lo àwọn ọ̀nà àti ìpèsè tí a fi òfin gbé kalẹ̀ lọ́nà yíyẹ. (Róòmù 13:1; Jákọ́bù 1:25) Fún àpẹẹrẹ, Àwọn Ẹlẹ́rìí ń lo Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ tí a fi òfin gbé kalẹ̀—ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní ní onírúurú orílẹ̀-èdè—tí ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí iṣẹ́ wọn, ti ríran àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́, pàápàá jù lọ lọ́nà tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni Àwọn Ẹlẹ́rìí ya ara wọn sí mímọ́ fún, kì í ṣe irinṣẹ́ èyíkéyìí tí a fi òfin gbé kalẹ̀, yíyà tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà yóò sì wà títí láé.
2. Èé ṣe tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ní ìmọrírì gidigidi fún Watch Tower Society àti àwọn irinṣẹ́ mìíràn bẹ́ẹ̀ tí a fi òfin gbé kalẹ̀?
2 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ tí ó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ó di dandan fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù láti ‘sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, kí wọ́n máa kọ́ wọn.’ (Mátíù 28:19, 20) Iṣẹ́ yìí yóò máa bá a lọ títí di òpin ètò àwọn nǹkan, nítorí Jésù tún sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:3, 14) Lọ́dọọdún, àwọn ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé Watch Tower Society àti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn bẹ́ẹ̀ tí a fi òfin gbé kalẹ̀, ń pèsè àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Bíbélì, ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ, àti ìwé ìròyìn fún ìlò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ìgbòkègbodò ìwàásù wọn kárí ayé. Nítorí náà, àwọn irinṣẹ́ tí a fi òfin gbé kalẹ̀ wọ̀nyí ṣe pàtàkì púpọ̀ nínú ríran àwọn ìránṣẹ́ tí ó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run lọ́wọ́ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wọn fún un.
3. Ọ̀nà wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti gbà lo ọ̀rọ̀ náà, “Society,” tẹ́lẹ̀?
3 Ẹnì kan lè jiyàn pé ọ̀nà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń gbà sọ̀rọ̀ nípa Watch Tower Society—tàbí lọ́pọ̀ ìgbà, “Society” ní pọ́ńbélé—ń fi hàn pé ojú tí wọ́n fi ń wò ó ju ti irinṣẹ́ tí a fi òfin gbé kalẹ̀ lọ. Wọn kò ha gbà pé ohun tí ó bá ti sọ ni abẹ gé lórí ọ̀ràn ìjọsìn bí? Ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, mú kókó yìí ṣe kedere, nígbà tí ó ṣàlàyé pé: “Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ [June 1, 1938] tọ́ka sí ‘Society,’ èyí kò túmọ̀ sí irinṣẹ́ tí a fi òfin gbé kalẹ̀ lásán, bí kò ṣe ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí ó dá irinṣẹ́ tí a fi òfin gbé kalẹ̀ yẹn sílẹ̀, tí ó sì ń lò ó.”a Nítorí náà, gbólóhùn náà dúró fún “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45) Ọ̀nà yìí ni Àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́pọ̀ ìgbà ti gbà lo ọ̀rọ̀ náà, “Society, nígbà kan.” Àmọ́ ṣáá o, ẹgbẹ́ tí a fi òfin gbé kalẹ̀ àti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí a lè gbé fúnra wọn. A máa ń dìbò yan àwọn olùdarí Watch Tower Society ni, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ni ó ń yan Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́.
4. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ṣe máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ láti lè yẹra fún àṣìlóye? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a wà déédéé ní ti ìlò ọ̀rọ̀?
4 Láti lè yẹra fún àṣìlóye, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbìyànjú láti lo ìṣọ́ra nípa bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀. Dípò sísọ pé, “Society kọ́ni pé,” ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí máa ń yàn láti lo irú gbólóhùn bí, “Bíbélì sọ pé” tàbí, “mo lóye pé Bíbélì kọ́ni pé.” Ní ọ̀nà yìí, wọ́n ń tẹnu mọ́ ìpinnu ara ẹni tí Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ti ṣe ní títẹ́wọ́gba àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọ́n sì tún ń yẹra fún gbígbin èrò èké síni lọ́kàn pé Àwọn Ẹlẹ́rìí wà lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti tẹ̀ lé àṣẹ ẹgbẹ́ ẹ̀ya ìsìn kan. Dájúdájú, àwọn àbá lórí ìlò ọ̀rọ̀ kò yẹ kí ó di àríyànjiyàn. Ó ṣe tán, ìlò ọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì kìkì nígbà tí ó bá mú àṣìlóye kúrò. Ó ń béèrè ìwàdéédéé Kristẹni. Bíbélì gbà wá níyànjú “láti má jà lórí ọ̀rọ̀.” (2 Tímótì 2:14, 15) Ìwé Mímọ́ tún gbé ìlànà yìí kalẹ̀: “Láìjẹ́ pé ẹ sọ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn láti lóye jáde nípasẹ̀ ahọ́n, báwo ni a ó ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ?”—1 Kọ́ríńtì 14:9.
Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Dín Nínílò Òfin Kù
5. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lóye 1 Kọ́ríńtì 10:23?
5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ṣàǹfààní.” Ó fi kún un pé: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ní ń gbéni ró.” (1 Kọ́ríńtì 10:23) Dájúdájú, Pọ́ọ̀lù kò ní i lọ́kàn pé ó bófin mu láti ṣe àwọn ohun tí ó ṣe kedere pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà léèwọ̀. Òfin ṣíṣe kedere díẹ̀ ni ó ń darí ìgbésí ayé Kristẹni ní ìfiwéra pẹ̀lú nǹkan bí 600 òfin tí a fún Ísírẹ́lì ìgbàanì. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ọ̀ràn ni a gbé ka ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù. Ẹnì kan tí ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ń gbádùn òmìnira tí ń wá láti inú ìdarí ẹ̀mí Ọlọ́run. Níwọ̀n bí ó ti sọ òtítọ́ di tirẹ̀, Kristẹni kan máa ń tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tí ó ti fi Bíbélì kọ́, ó sì máa ń gbára lé ìdarí Ọlọ́run nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Èyí ń ran Kristẹni tí ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ náà lọ́wọ́ láti pinnu ohun tí yóò “gbéni ró,” tí yóò sì “ṣàǹfààní” fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ẹlòmíràn. Ó mọ̀ pé ìpinnu tí òun bá ṣe yóò nípa lórí ipò ìbátan òun pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹni tí òun ya ara òun sí mímọ́ fún.
6. Ní àwọn ìpàdé Kristẹni, báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a ti sọ òtítọ́ di tiwa?
6 Ẹlẹ́rìí kan ń fi hàn pé òun ti sọ òtítọ́ di ti òun nípa dídáhùn ní àwọn ìpàdé Kristẹni. Lákọ̀ọ́kọ́, ó lè ka ohun tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ jáde. Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, òun yóò tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ní ọ̀rọ̀ ara rẹ̀. Ó ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀rí hàn pé òun ń mú agbára ìrònú òun sunwọ̀n sí i, pé kì í ṣe pé òun wulẹ̀ ń tún ohun tí àwọn ẹlòmíràn ti sọ sọ. Ní gbígbé àwọn ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ní ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ ti òtítọ́, lọ́nà tí ó ti ọkàn rẹ̀ wá, yóò mú inú rẹ̀ dùn, yóò sì fi hàn pé ohun tí ó ń sọ dá a lójú.—Oníwàásù 12:10; fi wé Róòmù 14:5b.
7. Àwọn ìpinnu wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti fínnúfíndọ̀ ṣe?
7 Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn ni ó ń sún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣiṣẹ́. (Mátíù 22:36-40) Lóòótọ́, ìfẹ́ bí ti Kristi ni ó dè wọ́n pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé. (Kólósè 3:14; 1 Pétérù 5:9) Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n ti fúnra rẹ̀ pinnu láti polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, láti wà láìdásí tọ̀túntòsì ní ti ọ̀ràn ìṣèlú, láti ta kété sí ẹ̀jẹ̀, láti yẹra fún irú àwọn eré ìnàjú kan, àti láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n Bíbélì. Ìwọ̀nyí kì í ṣe àwọn ìpinnu tí a fi agbára gbé kà wọ́n lórí. Wọ́n jẹ́ àwọn ìpinnu tí ó jẹ́ ara ọ̀nà ìgbésí ayé tí àwọn tí ó ṣeé ṣe kí ó di Ẹlẹ́rìí fínnúfíndọ̀ yàn ṣáájú kí wọ́n tó gbé ìgbésẹ̀ ìyàsímímọ́ Kristẹni rárá.
Wọ́n Ha Ń Jíhìn fún Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Kan Bí?
8. Ìbéèrè wo ni a ní láti mú ṣe kedere si?
8 Bíbélì fi hàn kedere pé a kì í fipá mú àwọn Kristẹni tòótọ́ láti sin Ọlọ́run. Ó wí pé: “Jèhófà ni Ẹ̀mí náà; níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” (2 Kọ́ríńtì 3:17) Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè mú òtítọ́ yìí bá èrò níní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀ dọ́gba?—Mátíù 24:45-47.
9, 10. (a) Báwo ni ìlànà ipò orí ṣe ṣeé mú lò nínú ìjọ Kristẹni? (b) Kí ni títẹ̀ lé ìlànà ipò orí mú kí ó pọn dandan nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?
9 Láti dáhùn ìbéèrè yìí, a gbọ́dọ̀ ní ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìlànà ipò orí lọ́kàn. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ní Éfésù 5:21-24, a fi Kristi hàn gẹ́gẹ́ bí “orí ìjọ,” tí ìjọ “wà ní ìtẹríba fún.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóye pé àwọn arákùnrin tẹ̀mí ti Jésù ni ó para pọ̀ jẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye. (Hébérù 2:10-13) A ti yan ẹrú olóòótọ́ yìí láti pèsè “oúnjẹ [tẹ̀mí] . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ní àkókò òpin yìí, Kristi ti yan ẹrú yìí “lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé òun jẹ́ Kristẹni yẹ kí ó bọ̀wọ̀ fún ipò rẹ̀.
10 Ètè ipò orí jẹ́ láti pa ìṣọ̀kan mọ́ àti láti rí sí i pé “ohun gbogbo . . . ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́ríńtì 14:40) Kí èyí lè ṣeé ṣe ní ọ̀rúndún kìíní, a yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró díẹ̀ lára ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti ṣojú fún ẹgbẹ́ náà lódindi. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà ti jẹ́rìí sí i, àbójútó tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ọ̀rúndún kìíní yìí lò rí ìtẹ́wọ́gbà àti ìbùkún Jèhófà. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìṣètò náà. Bẹ́ẹ̀ ni, wọ̀n gbà á tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì kún fún ọpẹ́ fún àbájáde àtàtà tí ó mú wá.—Ìṣe 15:1-32.
11. Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti òde òní?
11 Ìníyelórí irú ètò bẹ́ẹ̀ ṣì ń bẹ títí di ìsinsìnyí. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mẹ́wàá ni ó para pọ̀ jẹ́ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbogbo wọ́n sì ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Wọ́n ń pèsè ìdarí tẹ̀mí fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ọ̀rúndún kìíní ti ṣe. (Ìṣe 16:4) Bí ti àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí ń fayọ̀ gbára lé àwọn arákùnrin tí ó dàgbàdénú náà ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso fún ìtọ́sọ́nà àti ìdarí tí a gbé karí Bíbélì, nínú ọ̀ràn ìjọsìn. Bí àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tilẹ̀ jẹ́ ẹrú Jèhófà àti Kristi, bí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù, Bíbélì fún wa nítọ̀ọ́ni pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.”—Hébérù 13:17.
12. Ta ni Kristẹni kọ̀ọ̀kan yóò jíhìn fún?
12 Ipò àbójútó tí Ìwé Mímọ́ yan Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sí ha túmọ̀ sí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ jíhìn iṣẹ́ rẹ̀ fún un bí? Ìyẹn kò ní bá ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí àwọn Kristẹni tí ó wà ní Róòmù mu, pé: “Èé ṣe tí o ń dá arákùnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èé ṣe tí o tún ń fojú tẹ́ńbẹ́lú arákùnrin rẹ? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run . . . Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Róòmù 14:10-12.
13. Èé ṣe tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ròyìn ìgbòkègbodò ìwàásù wọn?
13 Ṣùgbọ́n, kì í ha ṣe òtítọ́ pé a retí pé kí Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ròyìn ìgbòkègbodò ìwàásù rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n ìwé Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ṣàlàyé ète tí a fi ń ṣe èyí ní kedere, ìwé náà sọ pé: “Awọn ọmọlẹhin Jesu Kristi ijimiji nifẹẹ ninu rirohin itẹsiwaju wọn ninu iṣẹ iwaasu. (Mark 6:30) Bi aasiki ti nbá iṣẹ naa, awọn irohin oniṣiro ni a kojọpọ pẹlu akọsilẹ awọn iriri ara-ọtọ nipa awọn wọnni tí wọn ńnípìn-ín ninu wiwaasu ihin-rere naa. . . . (Iṣe 2:5-11, 41, 47; 6:7; 1:15; 4:4) . . . Bawo ni eyi ti jẹ iṣiri tó fun awọn oṣiṣẹ Kristian oloootọ wọnni lati gbọ́ irohin ohun tí wọn ti ṣaṣepari rẹ̀! . . . Bẹẹ gẹgẹ, eto-ajọ Jehofah lode-oni nsapa lati pa akọsilẹ tí ó peye mọ́ niti iṣẹ tí a nṣe ní imuṣẹ Matthew 24:14.”
14, 15. (a) Báwo ni 2 Kọ́ríńtì 1:24 ṣe kan Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso? (b) Orí kí ni Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ gbé ìpinnu ara ẹni kà, ní mímọ òtítọ́ wo?
14 Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso jẹ́ ìpèsè onífẹ̀ẹ́ àti àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí ó yẹ láti fara wé. (Fílípì 3:17; Hébérù 13:7) Nípa rírọ̀mọ́ Kristi àti títẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe wọn, ó ṣeé ṣe fún wọn láti sọ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ní àsọtúnsọ, wí pé: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.” (2 Kọ́ríńtì 1:24) Nípa kíkíyèsí bí nǹkan ti ń lọ, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso máa ń pe àfiyèsí sí àwọn àǹfààní kíkọbiara sí ìmọ̀ràn Bíbélì, ó máa ń pèsè ìmọ̀ràn nípa bí a ṣe lè fi àwọn òfin àti ìlànà Bíbélì sílò, ó máa ń ṣe kìlọ̀kìlọ̀ nípa àwọn ewu tí ó fara sin, ó sì máa ń pèsè ìṣírí tí àwọn “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀ nílò fún wọn. Ó ń tipa báyìí ṣe iṣẹ́ ìríjú Kristẹni rẹ̀, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa ayọ̀ wọn mọ́, ó sì ń gbé wọn ró nínú ìgbàgbọ́, kí wọ́n baà lè dúró gbọn-in gbọn-in.—1 Kọ́ríńtì 4:1, 2; Títù 1:7-9.
15 Bí Ẹlẹ́rìí kan bá gbé ìpinnu rẹ̀ ka orí ìmọ̀ràn Bíbélì tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso pèsè, ó yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni, nítorí ẹ̀kọ́ tí òun fúnra rẹ̀ ti kọ́ láti inú Bíbélì ti mú kí ó dá a lójú pé èyí ni ọ̀nà tí ó yẹ láti tọ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ó ń nípa lórí Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan láti lo ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yíyè kooro, tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso pèsè, ní mímọ̀ dáradára pé ìpinnu tí òun bá ṣe yóò nípa lórí ipò ìbátan òun pẹ̀lú Ọlọ́run, tí òun ya ara òun sí mímọ́ fún.—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Akẹ́kọ̀ọ́ àti Ọmọ Ogun
16. Bí ìpinnu lórí ìwà híhù tilẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni, èé ṣe tí a fi ń yọ àwọn kan lẹ́gbẹ́?
16 Ṣùgbọ́n, bí ìpinnu lórí ìwà híhù bá jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni, èé ṣe tí a fi ń yọ àwọn kan nínú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́gbẹ́? Kò sí ẹni tí ń fi àdábọwọ́ ti ara rẹ̀ pinnu pé dídá irú ẹ̀ṣẹ̀ kan pàtó ń béèrè ìyọlẹ́gbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ sọ pé kí a gbé ìgbésẹ̀ yìí kìkì nígbà tí mẹ́ńbà ìjọ kan bá lọ́wọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ bíburú lékenkà, bí irú èyí tí a là lẹ́sẹẹsẹ nínú orí karùn-ún ìwé Kọ́ríńtì Kìíní, tí kò sì ronú pìwà dà. Nípa báyìí, nígbà tí a lè yọ Kristẹni kan lẹ́gbẹ́ fún ṣíṣàgbèrè, èyí ń wáyé kìkì nígbà tí ẹni náà bá kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí ti àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́. Kì í ṣe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni ó ń tẹ̀ lé àṣà Kristẹni yìí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ pé: “Ẹgbẹ́ àwùjọ kọ̀ọ̀kan ni ó ní ẹ̀tọ́ láti dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ tí kò mú ara wọn bá ẹgbẹ́ mu, tí wọ́n lè wu ire àwọn tí ó kù léwu. Ní ti ìsìn, ìgbàgbọ́ pé ìjìyà náà [ìyọlẹ́gbẹ́] ń nípa lórí ìdúró ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run, túbọ̀ ń fún ẹ̀tọ́ náà lágbára si.”
17, 18. Báwo ni a ṣe lè ṣàkàwé ìtọ̀nà ìyọlẹ́gbẹ́?
17 Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:2; Ìṣe 17:11) A lè fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń pèsè wé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ ti ilé ẹ̀kọ́, tí ìgbìmọ̀ ẹ̀kọ́ gbé kalẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbìmọ̀ náà kọ́ ni orísun ẹ̀kọ́ tí a fi ń kọ́ni, ṣùgbọ́n òun ni ó gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ náà kalẹ̀, òun ni ó ń pinnu ọ̀nà tí a óò gbà kọ́ni, òun sì ni ó ń mú ìtọ́ni tí ó pọn dandan jáde. Bí ẹnì kan bá kọ̀ jálẹ̀ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ilé ẹ̀kọ́ náà béèrè, tí ó dá ìṣòro sílẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tàbí tí ó kó ìtìjú bá ilé ẹ̀kọ́ náà, a lè lé e dànù. Àwọn alákòóso ilé ẹ̀kọ́ ní ẹ̀tọ́ láti gbégbèésẹ̀ fún àǹfààní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lápapọ̀.
18 Yàtọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ọmọ ogun Jésù Kristi, tí a fún nítọ̀ọ́ni láti “ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 6:12; 2 Tímótì 2:3) Bí ó ṣe sábà máa ń rí, títẹpẹlẹ mọ́ híhùwà tí kò yẹ Kristẹni ọmọ ogun lè mú kí Ọlọ́run máà tẹ́wọ́ gbà wá. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a fi ẹ̀bùn òmìnira ṣíṣe yíyàn jíǹkí rẹ̀, Kristẹni ọmọ ogun kàn lè ṣèpinnu tí ó wù ú, ṣùgbọ́n òun ni yóò gbé ẹrù àbájáde ìpinnu rẹ̀. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Kò sí ènìyàn tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun tí ń kó wọnú àwọn iṣẹ́ òwò ìgbésí ayé, kí ó bàa lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà ẹni tí ó gbà á síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹnì kan bá díje nínú àwọn eré pàápàá, a kì í dé e ládé láìjẹ́ pé ó díje ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àfilélẹ̀.” (2 Tímótì 2:4, 5) Àwọn Kristẹni tí ó dàgbà dénú, títí kan Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, wà fún Aṣáájú wọn, Jésù Kristi nìkan, wọ́n ń pa “ìlànà àfilélẹ̀” mọ́, kí wọ́n baà lè jèrè ẹ̀bùn ìwàláàyè títí láé.—Jòhánù 17:3; Ìṣípayá 2:10.
19. Ní gbígbé òtítọ́ nípa ìyàsímímọ́ Kristẹni yẹ̀ wò fínnífínní, kí ni a lè nídàánilójú rẹ̀?
19 Àwọn òtítọ́ wọ̀nyí kò ha mú un ṣe kedere pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pé wọn kì í ṣe ẹrú ènìyàn? Bí àwọn Kristẹni tí ó ti ya ara wọn sí mímọ́, ti ń gbádùn òmìnira tí Kristi tìtorí rẹ̀ dá wọn sílẹ̀, wọ́n ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ darí ìgbésí ayé wọn, bí wọ́n ti ń fi ìṣọ̀kan sìn pẹ̀lú àwọn ará wọn nínú ìjọ Ọlọ́run. (Sáàmù 133:1) Ó tún yẹ kí ẹ̀rí èyí mú iyèméjì èyíkéyìí tí a lè ní nípa orísun okun wọn kúrò. Wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ onísáàmù náà ní kíkọrin pé: “Jèhófà ni okun mi àti apata mi. Òun ni ọkàn-àyà mi gbẹ́kẹ̀ lé, a sì ti ràn mí lọ́wọ́, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn-àyà mi ń yọ ayọ̀ ńláǹlà, èmi yóò sì fi orin mi gbé e lárugẹ.”—Sáàmù 28:7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde ní 1993.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Ọ̀nà wo ni Watch Tower Society àti àwọn irinṣẹ́ mìíràn bẹ́ẹ̀ tí a fi òfin gbé kalẹ̀ ń gbà ran Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́?
◻ Báwo ni àwọn Kristẹni ṣe ń jàǹfààní nínú ipa tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kó?
◻ Èé ṣe tí àwọn ènìyàn Jèhófà fi ń ròyìn ìgbòkègbodò ìwàásù wọn?
◻ Lábẹ́ ipò wo ni yíyọ Kristẹni tí ó ti ṣèyàsímímọ́ lẹ́gbẹ́ ti tọ̀nà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ọ̀rúndún kìíní pa ìṣọ̀kan ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ mọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jákèjádò ayé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn òmìnira tí Kristi tìtorí rẹ̀ dá wọn sílẹ̀