Ìgbàgbọ́ àti Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ
“Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí.”—HÉBÉRÙ 11:1.
1. Irú ọjọ́ ọ̀la wo ní ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ń fẹ́?
ÌWỌ ha lọ́kàn ìfẹ́ nínú ọjọ́ ọ̀la bí? Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tí wọ́n ń retí ni ọjọ́ ọ̀la kan tí ó lálàáfíà, tí ó bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù, tí ó ní ipò ìgbésí ayé tí ó tẹ́ni lọ́rùn, iṣẹ́ tí ń méso wá, tí ó sì gbádùn mọ́ni, ìlera tí ó jí pépé, àti ẹ̀mí gígùn. Kò sí àní-àní pé gbogbo ìran ènìyàn nínú ìtàn ni ó ti fẹ́ irú nǹkan wọ̀nyí. Lónìí, nínú ayé tí ó kún fún ìjàngbọ̀n yìí, a ń fẹ́ irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ.
2. Báwo ni òṣèlú kan ṣe fi ojú ìwòye kan hàn nípa ọjọ́ ọ̀la?
2 Bí aráyé ti ń forí lé ọ̀rúndún kọkànlélógún, ọ̀nà èyíkéyìí ha wà tí a lè gbà wádìí bí ọjọ́ ọ̀la yóò ṣe rí? Òṣèlú ọmọ Amẹ́ríkà náà, Patrick Henry, sọ ọ̀nà kan, ní èyí tí ó lé ní 200 ọdún sẹ́yìn. Ó wí pé: “N kò mọ bí a ti lè mọ bí ọjọ́ ọ̀la yóò ti rí ju bí ìgbà tí ó ti kọjá ti rí lọ.” Ní ìbámu pẹ̀lú ojú ìwòye yìí, a lè mọ bí ọjọ́ ọ̀la ìdílé ẹ̀dá ènìyàn yóò ti rí dáradára nípa ohun tí ènìyàn ṣe ní ìgbà tí ó ti kọjá. Ọ̀pọ̀ gbà pẹ̀lú èrò yẹn.
Báwo Ni Ìgbà Tí Ó Ti Kọjá Ti Rí?
3. Kí ni àkọsílẹ̀ ìtàn fi hàn nípa ìrètí ọjọ́ ọ̀la?
3 Bí ó bá jẹ́ pé bí ìgbà tí ó ti kọjá ti rí ni ọjọ́ ọ̀la yóò ti rí, ìyẹn ha fún ọ níṣìírí bí? Ọjọ́ ọ̀la ha sàn fún àwọn ìran ìṣáájú láti àwọn sànmánì wọ̀nyí wá bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Láìka ìrètí tí àwọn ènìyàn ti ní fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sí, àti láìka àwọn àṣeyọrí ti ara ní àwọn ibì kan sí, ìtàn ti kún fún ìnilára, ìwà ọ̀daràn, ìwà ipá, ogun, àti òṣì. Ayé yìí ti nírìírí àjálù kan lórí òmíràn, ìjọba ẹ̀dá ènìyàn tí kò kúnjú ìwọ̀n ni ó sì ń fà èyí tí ó pọ̀ jù nínú wọn. Lọ́nà pípéye, Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
4, 5. (a) Èé ṣe tí àwọn ènìyàn fi nírètí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún yìí? (b) Kí ní ṣẹlẹ̀ sí ìrètí tí wọ́n ní fún ọjọ́ ọ̀la?
4 Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ìtàn búburú ti aráyé ṣì ń wáyé—ṣùgbọ́n lọ́nà tí ń pọ̀ sí i, tí ó sì ń ṣèpalára sí i. Ọ̀rúndún ogún yìí jẹ́rìí sí ìyẹn. Aráyé ha ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn àṣìṣe àtijọ́, kí ó sì yẹra fún wọn bí? Ó dára, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, ọ̀pọ̀ nígbàgbọ́ nínú ọjọ́ ọ̀la tí ó sàn jù nítorí pé àlàáfíà ti wà fún ìgbà pípẹ́ ní ìfiwéra, àti nítorí ìtẹ̀síwájú nínú ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àti ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1900, ọ̀jọ̀gbọ́n yunifásítì kan sọ pé, a gbà gbọ́ pé ogun kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́ nítorí pé, “àwọn ènìyàn ti lajú jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Olórí ìjọba Britain tẹ́lẹ̀ rí kan sọ nípa ojú ìwòye tí àwọn ènìyàn ní nígbà náà lọ́hùn-ún pé: “Ohun gbogbo yóò dára síwájú àti síwájú sí i. Ayé tí a bí mi sí nìyí.” Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Lójijì, láìròtẹ́lẹ̀, ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan ní ọdún 1914, gbogbo nǹkan dojú rú.”
5 Láìka ìgbàgbọ́ nínú ọjọ́ ọ̀la tí ó sàn jù, èyí tí ó gbalé gbòde nígbà náà sí, kò pẹ́ tí ọ̀rúndún tuntun náà bẹ̀rẹ̀ tí àjálù tí ó tí ì burú jù láti ọwọ́ ènìyàn—Ogun Àgbáyé Kìíní—fi bo ayé náà mọ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìbàjẹ́ tí ó ṣe, ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1916 nínú ìjà ogun kan, nígbà tí àwọn ọmọ ogun Britain kọlu ti Germany nítòsí Odò Somme ní ilẹ̀ Faransé. Láàárín wákàtí mélòó kan, ilẹ̀ Britain ti pàdánù 20,000 ọmọ ogun, wọ́n sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn ti Germany pẹ̀lú. Ọdún mẹ́rin tí ìpakúpa fi ṣẹlẹ̀ gbẹ̀mí èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́wàá àwọn ológun àti ọ̀pọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ aráàlú. Iye olùgbé ilẹ̀ Faransé dín kù fún ìgbà díẹ̀ nítorí tí wọ́n pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin. Ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀, tí ó fi yọrí sí Ìjórẹ̀yìn Ọrọ̀ Ajé Lọ́nà Gígọntiọ ti àwọn ọdún 1930. Abájọ tí àwọn kan fi sọ pé ọjọ́ tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ tí ayé ya wèrè!
6. Ìgbésí ayé ha sàn jù lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní bí?
6 Ṣé ọjọ́ ọ̀la tí ìran yẹn retí ni èyí? Rárá, òun kọ́. Ìrètí wọn ṣákìí pátápátá; bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo ìwọ̀nyẹn kò yọrí sí ohun kan tí ó sàn jù. Ní kìkì ọdún 21 lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, tàbí ní ọdún 1939, àjálù tí ó túbọ̀ burú jù láti ọwọ́ ènìyàn—Ogun Àgbáyé Kejì—wáyé. Ó gbẹ̀mí nǹkan bí 50 mílíọ̀nù ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé. Jíju bọ́ǹbù lọ́pọ̀ yanturu run àwọn ìlú ńláńlá. Nínú Ogun Àgbáyé Kìíní, a pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ogun nínú ìjà ogun kan láàárín wákàtí mélòó kan, nígbà tí ó jẹ́ pé nínú Ogun Àgbáyé Kejì, bọ́ǹbù átọ́míìkì méjì péré gbẹ̀mí ènìyàn tí ó lé ní 100,000 láàárín ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan. Èyí tí ọ̀pọ̀ ronú pé ó tún burú jù ìyẹn lọ ni fífẹ̀sọ̀-ṣìkà-pani nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Nazi.
7. Kí ní jẹ́ òtítọ́ gan-an nípa ọ̀rúndún yìí látòkè délẹ̀?
7 Ọ̀pọ̀ orísun ìsọfúnni sọ pé bí a bá fi àwọn ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ogun abẹ́lé, àti ikú tí àwọn ìjọba ti fi pa àwọn ọmọ ìlú wọn kún un, iye àwọn tí a ti pa ní ọ̀rúndún yìí yóò tó nǹkan bí 200 mílíọ̀nù. Orísun ìsọfúnni kan tilẹ̀ pè é ní 360 mílíọ̀nù. Fojú inú wo bí gbogbo rẹ̀ ti jẹ́ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó—ìrora, omijé, làásìgbò, ẹ̀mí tó ṣègbé! Ní àfikún sí i, ní ìpíndọ́gba, nǹkan bí 40,000 ènìyàn, pàápàá jù lọ àwọn ọmọdé, ń kú lójoojúmọ́ nítorí àwọn ohun tí òṣì ń fà. Ìlọ́po mẹ́ta iye yẹn ni a ń pa nípa ìṣẹ́yún lójoojúmọ́. Bákan náà, nǹkan bí bílíọ̀nù kan ènìyàn ni ó tòṣì débi pé wọn kò lè ra oúnjẹ tí wọ́n nílò láti ṣe iṣẹ́ òòjọ́ tí ó bójú mu. Gbogbo àwọn ipò wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí ohun tí a ti sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí.—2 Tímótì 3:1-5, 13; Mátíù 24:3-12; Lúùkù 21:10, 11; Ìṣípayá 6:3-8.
Kò Sí Ojútùú Láti Ọ̀dọ̀ Ènìyàn
8. Èé ṣe tí kò fi ṣeé ṣe fún àwọn aṣáájú ènìyàn láti yanjú àwọn ìṣòro ayé?
8 Bí ọ̀rúndún ogún yìí ṣe ń lọ sópin rẹ̀, a lè fi ìrírí rẹ̀ kún ti àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá. Kí sì ni gbogbo ìtàn yẹn mú kí ó yé wa? Ó mú kí ó yé wa pé àwọn aṣáájú ẹ̀dá ènìyàn kò tí ì yanjú àwọn ìṣòro pàtàkì tí ayé ní, pé wọn kò yanjú wọn nísinsìnyí, wọn kì yóò sì yanjú wọn lọ́jọ́ ọ̀la. Ó kọjá agbára wọn láti pèsè irú ọjọ́ ọ̀la tí a ń fẹ́, láìka bí wọ́n ti lè ní ète rere tó sí. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ó sì wà ní ipò àkóso kò fi bẹ́ẹ̀ ní ète rere; wọ́n ń wá ipò àti agbára fún ète ìgbéra-ẹni-lárugẹ àti nítorí àwọn ohun ìní ti ara, kì í ṣe fún àǹfààní àwọn ẹlòmíràn.
9. Èé ṣe tí ìdí fi wà láti ṣiyè méjì nípa pé sáyẹ́ǹsì ní ojútùú sí àwọn ìṣòro ènìyàn?
9 Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ha lè pèsè ojútùú bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ bí a bá ṣàyẹ̀wò ìgbà tí ó ti kọjá. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń ṣiṣẹ́ fún ìjọba ti ná owó tabua, wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ àkókò, àti ìsapá ní ṣíṣe àwọn ohun ìjà oníkẹ́míkà, afàrùnṣeni, àti irú àwọn ohun ìjà mìíràn tí ń ṣèparun lọ́nà tí ń bani lẹ́rù. Àwọn orílẹ̀-èdè, títí kan àwọn tí ó tòṣì paraku, ń ná iye tí ó lé ní 700 bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún lórí àwọn ohun ìjà! Síwájú si, lápa kan, ‘ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì’ ni ó mú àwọn kẹ́míkà tí ó ti dá kún bíba afẹ́fẹ́, ilẹ̀, omi, àti oúnjẹ jẹ́, jáde.
10. Èé ṣe tí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ pàápàá kò mú ọjọ́ ọ̀la tí ó sàn jù dá wa lójú?
10 A ha lè retí pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ ayé yóò ṣèrànwọ́ láti gbé ọjọ́ ọ̀la tí ó sàn jù ró nípa kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìwà híhù tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, gbígba ti àwọn ẹlòmíràn rò, àti ìfẹ́ aládùúgbò bí? Rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń kó àfiyèsí jọ sórí iṣẹ́ ìgbésí ayé, sórí kíkó owó jọ. Wọ́n ń fún ẹ̀mí ìbáradíje gidigidi níṣìírí, kì í ṣe ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ kì í kọ́ni ní ìwà rere. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọ́n gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún ìṣekúṣe, tí ó ti yọrí sí ìlọsókè púpọ̀ nínú oyún àwọn ọ̀dọ́langba àti àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré.
11. Báwo ni àkọsílẹ̀ àwọn ìṣòwò ńlá ṣe múni ṣiyè méjì nípa ọjọ́ ọ̀la?
11 A óò ha sún àwọn àjọ ìṣòwò ńláńlá ti ayé yìí lójijì láti ṣètọ́jú pílánẹ́ẹ̀tì wa dáradára, kí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn nípa ṣíṣe àwọn ohun tí yóò ṣàǹfààní ní ti gidi, tí kò sì ní jẹ́ fún èrè jíjẹ nìkan? Kò dájú pé ìyẹn yóò ṣeé ṣe. Wọn yóò ha jáwọ́ nínú pípèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tí ó kún fún ìwà ipá àti ìwà pálapàla tí ń dá kún sísọ èrò inú àwọn ènìyàn, pàápàá àwọn èwe, dìbàjẹ́ bí? Ìgbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá kò fúnni níṣìírí rárá nítorí pé, fún apá tí ó pọ̀ jù lọ, tẹlifíṣọ̀n ti di kòtò ẹ̀gbin ti ìwà pálapàla àti ìwà ipá.
12. Kí ni ipò ènìyàn nípa àìsàn àti ikú?
12 Ní àfikún sí i, bí ó ti wù kí àwọn dókítà jẹ́ olóòótọ́ inú tó, wọn kò lè ṣẹ́gun àìsàn àti ikú. Fún àpẹẹrẹ, ní òpin Ogun Àgbáyé Kìíní, kò ṣeé ṣe fún wọn láti kápá ìtànkálẹ̀ àrùn gágá ilẹ̀ Sípéènì; kárí ayé, ó gba ẹ̀mí 20 mílíọ̀nù ènìyàn. Lónìí, àrùn ọkàn àyà, àrùn jẹjẹrẹ, àti àwọn àrùn panipani mìíràn gbalé gbòde. Bẹ́ẹ̀ sì ni agbo àwọn oníṣègùn kò tí ì ṣẹ́gun ìyọnu àjàkálẹ̀ AIDS tòní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìròyìn kan tí ó jẹ́ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tí a mú jáde ní November 1997, dórí èrò náà pé, ọwọ́ tí àrùn AIDS gbà ń tàn kálẹ̀ lọ́po lọ́nà méjì iye tí a fojú díwọ̀n tẹ́lẹ̀. Ní bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti kú nítorí rẹ̀. Ní ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹ́ta mìíràn ni ó tún ti kó o.
Ojú Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi Ń Wo Ọjọ́ Ọ̀la
13, 14. (a) Ojú wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo ọjọ́ ọ̀la? (b) Èé ṣe tí ẹ̀dá ènìyàn kò fi lè mú ọjọ́ ọ̀la sísàn jù wá?
13 Ṣùgbọ́n, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé aráyé ní ọjọ́ ọ̀la amọ́kànyọ̀, ọ̀kan tí ó sàn jù lọ! Ṣùgbọ́n wọn kò retí pé ìsapá ènìyàn ni yóò mú ọjọ́ ọ̀la sísàn jù yẹn wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń wojú Ẹlẹ́dàá, Jèhófà Ọlọ́run. Ó mọ bí ọjọ́ ọ̀la yóò ṣe rí, yóò sì jẹ́ ọ̀kan tí ó jẹ́ àgbàyanu! Òun tún mọ̀ pé ẹ̀dá ènìyàn kò lè mú irú ọjọ́ ọ̀la bẹ́ẹ̀ wá. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ni ó dá wọn, ó mọ ibi tí agbára wọ́n mọ, ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wa ní kedere pé òun kò dá ènìyàn pẹ̀lú agbára láti ṣàṣeyọrí ní ṣíṣàkóso ara rẹ̀ láìsí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Fífi tí Ọlọ́run fi àyè gba ìṣàkóso ènìyàn tí kò gbára lé e, fún àkókò pípẹ́ ti fi àìlágbára yẹn hàn gbangba rékọjá iyèméjì èyíkéyìí. Òǹṣèwé kan sọ pé: “Èrò inú ènìyàn ti gbìyànjú gbogbo àpapọ̀ ìṣàkóso tí ó ṣeé ṣe, asán ni gbogbo rẹ̀ jásí.”
14 Ní Jeremáyà 10:23, a ka ọ̀rọ̀ wòlíì tí a mí sí náà pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Síwájú sí i, Sáàmù 146:3 wí pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” Ní tòótọ́, nítorí tí a bí wa pẹ̀lú àìpé, gẹ́gẹ́ bí Róòmù 5:12 ti fi hàn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé kí a má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ara wa. Jeremáyà 17:9 sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ.” Nípa báyìí, Òwe 28:26 polongo pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn ni ẹni tí yóò sá àsálà.”
15. Níbo ni a ti lè rí ọgbọ́n tí yóò tọ́ wa sọ́nà?
15 Ibo ni a ti lè rí ọgbọ́n yìí? “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni ohun tí òye jẹ́.” (Òwe 9:10) Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ó ní ọgbọ́n tí ó lè ṣamọ̀nà wa la àwọn àkókò bíbani lẹ́rù wọ̀nyí já. Ó sì ti mú kí ọgbọ́n rẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́, tí òun mí sí fún ìtọ́sọ́nà wa.—Òwe 2:1-9; 3:1-6; 2 Tímótì 3:16, 17.
Ọjọ́ Ọ̀la Ìṣàkóso Ènìyàn
16. Ta ní ti pinnu bí ọjọ́ ọ̀la yóò ṣe rí?
16 Nígbà náà, kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa nípa ọjọ́ ọ̀la? Ó sọ fún wa pé dájúdájú, ọjọ́ ọ̀la kì yóò gbé ohun tí ẹ̀dá ènìyàn ti ṣe ní àtẹ̀yìnwá yọ. Nítorí náà, ojú ìwòye Patrick Henry kò tọ̀nà. Kì í ṣe ẹ̀dá ènìyàn ni yóò pinnu ọjọ́ ọ̀la ilẹ̀ ayé yìí àti ti àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí rẹ̀, bí kò ṣe Jèhófà Ọlọ́run. Ìfẹ́ rẹ̀ ni a óò ṣe lórí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe ìfẹ́ ènìyàn tàbí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lórí ilẹ̀ ayé yìí. “Ọ̀pọ̀ ni ìwéwèé tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ènìyàn, ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn Jèhófà ni yóò dúró.”—Òwe 19:21.
17, 18. Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún ọjọ́ wa?
17 Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún àkókò wa? Ó ti pète láti mú òpin dé bá ètò nǹkan ìsinsìnyí tí ó jẹ́ oníwà ipá àti oníwà pálapàla. Láìpẹ́, ìṣàkóso tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ yóò rọ́pò ìṣàkóso búburú ti ẹ̀dá ènìyàn tí ó ti wà fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà ní Dáníẹ́lì 2:44 wí pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [àwọn tí ó wà lónìí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [ní ọ̀run] èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ìjọba náà yóò tún mú agbára búburú tí Sátánì Èṣù ń lò lórí ẹni kúrò, ohun tí ẹ̀dá ènìyàn kò lè ṣe. Ìṣàkóso rẹ̀ lórí ayé yìí yóò dópin títí láé.—Róòmù 16:20; 2 Kọ́ríńtì 4:4; 1 Jòhánù 5:19.
18 Ṣàkíyèsí pé Ìjọba ọ̀run yóò pa gbogbo ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn run. A kì yóò fi ìṣàkóso ilẹ̀ ayé yìí sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn mọ́. Ní ọ̀run, àwọn tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣàkóso gbogbo àlámọ̀rí ilẹ̀ ayé fún àǹfààní aráyé. (Ìṣípayá 5:10; 20:4-6) Lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ẹ̀dá ènìyàn olùṣòtítọ́ yóò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà Ìjọba Ọlọ́run. Èyí ni ìṣàkóso tí Jésù kọ́ wa láti gbàdúrà fún nígbà tí ó sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ inú rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.
19, 20. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ètò Ìjọba náà? (b) Kí ni àkóso rẹ̀ yóò ṣe fún aráyé?
19 Ìjọba Ọlọ́run ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ìgbàgbọ́ wọn sínú rẹ̀. Òun ni “ọ̀run tuntun” tí àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé nípa rẹ̀, nígbà tí ó sọ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tuntun ni “ilẹ̀ ayé tuntun” tí ọ̀run tuntun, Ìjọba Ọlọ́run, yóò ṣàkóso. Ìṣètò yìí ni Ọlọ́run ṣí payá nínú ìran tí a fún àpọ́sítélì Jòhánù, tí ó kọ̀wé pé: “Mo . . . rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan; nítorí ọ̀run ti ìṣáájú àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú ti kọjá lọ . . . [Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:1, 4.
20 Ṣàkíyèsí pé ilẹ̀ ayé tuntun náà yóò jẹ́ ti òdodo. Gbogbo àwọn ìsọ̀rí àwùjọ aláìṣòdodo ni a óò ti mú kúrò nípasẹ̀ ìṣe Ọlọ́run, ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Òwe 2:21, 22 sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.” Sáàmù 37:9 sì ṣèlérí pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” Ìwọ kì yóò ha fẹ́ láti gbé nínú irú ayé tuntun bẹ́ẹ̀ bí?
Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
21. Èé ṣe tí a fi lè ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà?
21 A ha lè ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà bí? Tẹ́tí sí ohun tí ó sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà: “Ẹ rántí àwọn nǹkan àkọ́kọ́ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, pé èmi ni Olú Ọ̀run, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí èmi; Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe; Ẹni tí ń wí pé, ‘Ìpinnu tèmi ni yóò dúró, gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe.’” Apá tí ó kẹ́yìn ẹsẹ 11 sọ pé: “Àní mo ti sọ ọ́; èmi yóò mú un wá pẹ̀lú. Mo ti gbé e kalẹ̀, èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.” (Aísáyà 46:9-11) Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti àwọn ìlérí rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹni pé àwọn ìlérí wọ̀nyẹn ti ní ìmúṣẹ. Bíbélì sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.”—Hébérù 11:1.
22. Èé ṣe tí a fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
22 Àwọn ènìyàn onírẹ̀lẹ̀ ń fi irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ hàn nítorí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Fún àpẹẹrẹ, nínú Sáàmù 37:29, a kà pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” A ha lè gba èyí gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí Hébérù 6:18 wí pé: “Kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” Ọlọ́run ha ni ó ni ilẹ̀ ayé tí yóò fi fi fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ bí? Ìṣípayá 4:11 polongo pé: “Ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ ni wọ́n ṣe wà tí a sì dá wọn.” Nípa báyìí, Sáàmù 24:1 wí pé: “Ti Jèhófà ni ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ̀.” Jèhófà ni ó dá ilẹ̀ ayé, òun ni ó ni ín, yóò sì fi fún àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Láti lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú èyí, àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò fi hàn wá bí Jèhófà ti pa àwọn ìlérí tí ó ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá àti ní ọjọ́ wa, àti ìdí tí a fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá pé òun yóò ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ iwájú.
Àwọn Kókó fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Kí ní ti ṣẹlẹ̀ sí ìrètí àwọn ènìyàn jálẹ̀ ìtàn?
◻ Èé ṣe tí kò fi yẹ láti yíjú sí ẹ̀dá ènìyàn láti mú ọjọ́ ọ̀la tí ó sàn jù wá?
◻ Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run nípa ọjọ́ ọ̀la?
◻ Èé ṣe ti a fi ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Lọ́nà pípéye, Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn . . . láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23
[Credit Line]
Bọ́ǹbù: Fọ́tò U.S. National Archives; àwọn ọmọ tí ebi ti pa kú: WHO/OXFAM; àwọn olùwá ibi ìsádi: UN PHOTO 186763/J. Isaac; Mussolini àti Hitler: Fọ́tò U.S. National Archives