Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
A San Èrè fún Ìwà Títọ́ Jóòbù
JÓÒBÙ jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, olùgbèjà àwọn opó, ọmọ òrukàn, àti àwọn tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́. (Jóòbù 29:12-17; 31:16-21) Àmọ́, lójijì, àjálù dé bá a, ó pàdánù ọrọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀, àti ìlera rẹ̀. Ó ṣeni láàánú pé, ọkùnrin olókìkí yìí, tí ó ti jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún àwọn tí a ń ni lára kò rí ìrànwọ́ kankan gbà nígbà tí ó nílò rẹ̀. Kódà aya rẹ̀ alára sọ fún un pé “bú Ọlọ́run, kí o sì kú!” “Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀,” Élífásì, Bílídádì, àti Sófárì kò sì tù ú nínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n dọ́gbọ́n sọ pé Jóòbù ti ṣẹ̀, nítorí náà ó tọ́ kí ìyà jẹ ẹ́.—Jóòbù 2:9; 4:7, 8; 8:5, 6; 11:13-15.
Láìka ìyà púpọ̀ yìí sí, Jóòbù dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Nítorí èyí, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Jèhófà nawọ́ àánú sí Jóòbù, ó sì bù kún un. Àkọsílẹ̀ bí ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ pèsè ìdánilójú fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ń pa ìwà títọ́ mọ́ pé láìpẹ́ a óò san èrè fún àwọn pẹ̀lú.
Dídá A Láre àti Mímú Un Padà Bọ̀ Sípò
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà bá Élífásì, Bílídádì, àti Sófárì wí. Ní bíbá Élífásì, tí ó hàn gbangba pé ó jẹ́ ẹni tí ó dàgbà jù láàárín wọn sọ̀rọ̀, ó wí pé: “Ìbínú mi gbóná sí ìwọ àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ méjèèjì, nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa mi bí ìránṣẹ́ mi Jóòbù ti ṣe. Wàyí o, ẹ mú akọ màlúù méje àti àgbò méje fún ara yín, kí ẹ sì tọ ìránṣẹ́ mi Jóòbù lọ, kí ẹ sì rú ẹbọ sísun nítorí ara yín; Jóòbù ìránṣẹ́ mi yóò sì fúnra rẹ̀ gbàdúrà fún yín.” (Jóòbù 42:7, 8) Ronú nípa ohun tí èyí túmọ̀ sí!
Jèhófà béèrè ẹbọ tí ó jọjú lọ́wọ́ Élífásì, Bílídádì, àti Sófárì, bóyá láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ wọn ti wúwo tó. Ní tòótọ́, yálà wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀ọ́mọ̀, wọ́n ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ní sísọ pé òun “kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,” àti pé yálà Jóòbù jẹ́ olóòótọ́ tàbí kò jẹ́ olóòótọ́ kò gbún un rárá. Élífásì tilẹ̀ sọ pé lójú Ọlọ́run, Jóòbù kò ní láárí ju òólá! (Jóòbù 4:18, 19; 22:2, 3) Abájọ tí Jèhófà fi wí pé: “Ẹ kò sọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa mi”!
Ṣùgbọ́n, kò tán síbẹ̀. Élífásì, Bílídádì, àti Sófárì pẹ̀lú dẹ́ṣẹ̀ sí Jóòbù alára nípa sísọ fún un pé òun ni ó fọwọ́ ara rẹ̀ fa ìṣòro tí ó dé bá a. Àwọn ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí wọ́n fi kàn án àti ọ̀rọ̀ àìfọ̀rọ̀-rora-ẹni-wò tí wọ́n sọ ba Jóòbù lọ́kàn jẹ́, ó sì mú un sorí kọ́, tí ó fi kígbe pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ óò máa sún ọkàn mi bínú, tí ẹ ó sì máa fi ọ̀rọ̀ fọ́ mi sí wẹ́wẹ́?” (Jóòbù 10:1; 19:2) Fojú inú wo bí ojú yóò ti ti àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí tó nísinsìnyí tí wọ́n ní láti gbé ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn lọ síwájú Jóòbù!
Ṣùgbọ́n Jóòbù kò ní yọ̀ wọ́n nítorí tí a tẹ́ wọn. Ní tòótọ́, Jèhófà ní kí ó gbàdúrà fún àwọn tí ó fẹ̀sùn kàn án. Jóòbù ṣe gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni tí a fún un, a sì bù kún un nítorí èyí. Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà wo àìsàn rẹ̀ tí ó bani lẹ́rù sàn. Lẹ́yìn náà, àwọn arákùnrin, arábìnrin, àti alábàákẹ́gbẹ́ Jóòbù tẹ́lẹ̀ rí wá tù ú nínú, “wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti fún un ní ẹyọ owó, olúkúlùkù sì fún un ní òrùka wúrà.”a Ní àfikún sí i, Jóòbù “ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá àgùntàn àti ẹgbàáta ràkúnmí àti ẹgbẹ̀rún àdìpọ̀ méjì-méjì màlúù àti ẹgbẹ̀rún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”b Ó sì hàn gbangba pé aáwọ̀ tí ó wà láàárín Jóòbù àti aya rẹ̀ parí. Kò pẹ́ kò jìnnà, a fi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹta bù kún Jóòbù, ó sì wà láàyè láti rí ìran mẹ́rin ti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀.—Jóòbù 42:10-17.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Jóòbù fi àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá lélẹ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní. Ó jẹ́ “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán,” ọkùnrin tí inú Jèhófà dùn láti pè ní “ìránṣẹ́ mi.” (Jóòbù 1:8; 42:7, 8) Ṣùgbọ́n, èyí kò túmọ̀ sí pé Jóòbù jẹ́ ẹni pípé. Nígbà kan nínú àdánwò rẹ̀, ó ní èrò tí ó lòdì pé Ọlọ́run ni ó fa àjálù bá òun. Ó tilẹ̀ ṣe lámèyítọ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá ènìyàn lò. (Jóòbù 27:2; 30:20, 21) Òdodo tirẹ̀ ni ó sì polongo kì í ṣe ti Ọlọ́run. (Jóòbù 32:2) Ṣùgbọ́n Jóòbù kọ̀ láti kẹ̀yìn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ó sì fi ìrẹ̀lẹ̀ gba àtúnṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run. Ó gbà pé: “Mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kò lóye . . . mo . . . yíhùn padà, mo sì ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.”—Jóòbù 42:3, 6.
Nígbà tí a bá wà lábẹ́ àdánwò àwa pẹ̀lú lè ronú, sọ̀rọ̀, tàbí hùwà lọ́nà tí kò yẹ. (Fi wé Oníwàásù 7:7.) Síbẹ̀síbẹ̀, bí ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run bá jinlẹ̀, a kò ní ṣọ̀tẹ̀ sí i tàbí kí a bínú nítorí tí òun yọ̀ǹda kí a nírìírí ìnira. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò di ìwà títọ́ wa mú, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ a óò sì ká ìbùkún. Onísáàmù náà sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.”—Sáàmù 18:25.
Kí ara Jóòbù tó yá, Jèhófà ní kí ó gbàdúrà fún àwọn tí ó ti ṣẹ̀ ẹ́. Ẹ wo irú àpẹẹrẹ àtàtà tí èyí jẹ́ fún wa! Jèhófà fẹ́ kí a dárí ji àwọn tí ó ṣẹ̀ wá, kí ó tó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ tiwa jì wá. (Mátíù 6:12; Éfésù 4:32) Bí a kò bá múra tán láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn, nígbà tí ìdí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ bá wà fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ a lè retí pé kí Jèhófà fi àánú hàn fún wa bí?—Mátíù 18:21-35.
Gbogbo wa ń dojú kọ àdánwò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (2 Tímótì 3:12) Síbẹ̀, bí i Jóòbù a lè pa ìwà títọ́ mọ́. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò ká èrè ńlá. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Wò ó! Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ni a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.”—Jákọ́bù 5:11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A kò lè sọ iye tí “ẹyọ owó” (Hébérù, qesi·tahʹ) tó. Ṣùgbọ́n “ọgọ́rùn-ún ẹyọ owó” ra ilẹ̀ tí ó jọjú ní ọjọ́ Jékọ́bù. (Jóṣúà 24:32) Nítorí náà, “ẹyọ owó” tí olùṣèbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan fún un kì í ṣe ẹ̀bùn kékeré lásán.
b Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, a mẹ́nu kan ẹ̀yà àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà níhìn-ín nítorí ìníyelórí wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ tí ó lè bímọ.