Ayẹyẹ Ìgbéyàwó Àrà Ọ̀tọ̀
NÍ ÀRÍWÁ Mòsáńbíìkì, àfonífojì ọlọ́ràá kan wà tí àwọn òkè ẹlẹ́wà yí ká—àwọn kan kún fún òkúta, ewéko títutù yọ̀yọ̀ sì bo àwọn mìíràn. Ibí ni abúlé Fíngoè wà. Ní àwọn alẹ́ mímọ́lẹ̀ ní ìgbà òtútù, àwọn ìràwọ̀ a máa tàn yinrinyinrin ní ojú ọ̀run, òṣùpá a sì mọ́lẹ̀ rokoṣo débi pé yóò tànmọ́lẹ̀ sí àwọn ilé tí a fi koríko bò, tí àwọn ará abúlé ń gbé. Àgbègbè dáradára yìí ni ayẹyẹ ìgbéyàwó aláìlẹ́gbẹ́ kan ti wáyé.
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ènìyàn rin ìrìn ọ̀pọ̀ wákàtí, àní ọ̀pọ̀ ọjọ́, láti pésẹ̀ síbi àkànṣe àṣeyẹ yìí. Àwọn kan la aginjù àti àgbègbè eléwu, tí àwọn pẹnlẹpẹ̀, kìnnìún, àti erin ń gbé kọjá. Ní àfikún sí ẹrù ara wọn, ọ̀pọ̀ àlejò gbé adìyẹ, ewúrẹ́, àti àwọn irè oko dání. Lẹ́yìn tí wọ́n dé abúlé náà, wọ́n lọ sí àgbègbè gbayawu kan tí a ti máa ń ṣe àwọn àpéjọpọ̀ Kristẹni. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n nítorí ìrìn àjò náà, inú wọ́n ń dùn, ojú wọn tí ó kún fún ẹ̀rín músẹ́ sì fi ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ohun tí yóò tẹ̀ lé e hàn.
Àwọn wo ló fẹ́ ṣègbéyàwó? Wọ́n mà pọ̀ o! Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tọkọtaya. Àwọn wọ̀nyí kò wá kópa nínú ayẹyẹ ìgbéyàwó ayé-gbọ́-ọ̀run-mọ̀, níbi tí ọ̀pọ̀ àwọn olùṣègbéyàwó ti kóra jọpọ̀ láti jọ ṣe é lẹ́ẹ̀kan náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ tọkọtaya olóòótọ́ inú àti elérò rere tí kò ṣeé ṣe fún tẹ́lẹ̀ láti forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nítorí pé wọ́n ń gbé ní àwọn àgbègbè tí ó jìnnà sí àwọn ọ́fíìsì ìforúkọsílẹ̀. Gbogbo tọkọtaya wọ̀nyí wá mọ̀ nípa ìlànà àtọ̀runwá nípa ìgbéyàwó nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé wọ́n ní láti ṣègbéyàwó ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin orílẹ̀ èdè kí wọ́n lè wu Ẹlẹ́dàá wọn, Olùdá ìgbéyàwó sílẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù àti Màríà ti ṣègbọràn sí òfin ìforúkọsílẹ̀ nígbà ìbí Jésù.—Lúùkù 2:1-5.
Mímúrasílẹ̀ fún Ìṣẹ̀lẹ̀ Náà
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mòsáńbíìkì pinnu láti ṣèrànwọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n kàn sí àwọn Ilé Iṣẹ́ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìdájọ́ àti Ọ̀ràn Abẹ́lé ní Màpútò, olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, láti mọ àwọn ìlànà tí òfin là sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn míṣọ́nnárì tí ó wà ní olú ìlú ìpínlẹ̀ Tete kàn sí àwọn aláṣẹ àdúgbò láti ṣe kòkáárí àwọn ètò náà síwájú sí i. A dá ọjọ́ kan tí àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìfàṣẹsíwèé àti Ìdánimọ̀ yóò rìnrìn àjò lọ sí abúlé Fíngoè. Kí ọjọ́ náà tó kò, ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ lẹ́tà kan tí ó pèsè ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtọ́ni sí gbogbo ìjọ tí ọ̀ràn náà kàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ládùúgbò ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún ìṣẹ̀lẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ náà.
Ní Sunday, May 18, 1997, míṣọ́nnárì mẹ́ta pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba mẹ́ta dé sí Fíngoè. Àwọn aláṣẹ àdúgbò ti pèsè àwọn ibùwọ̀ tí ó dára fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba sítòsí ilé tí wọn yóò ti ṣiṣẹ́. Àmọ́ ṣá o, bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣaájò àwọn òṣìṣẹ́ náà wú wọn lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi yàn láti wọ̀ sọ́dọ̀ àwọn míṣọ́nnárì nínú ahéré abúlé. Ó yà wọ́n lẹ́nu láti gbọ́ pé ọ̀kan lára àwọn agbọ́únjẹ jẹ́ alàgbà ní ìjọ àdúgbò àti pé alábòójútó arìnrìn-àjò kan wà láàárín àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ayẹyẹ ìgbéyàwó náà. Bákan náà, wọ́n ṣàkíyèsí bí àwọn míṣọ́nnárì náà ti ń ṣàwàdà, àwọn tí ó jẹ́ pé, láìráhùn, wọ́n ń sun inú ahéré lásán, korobá kékeré kan sì ni wọ́n fi ń bomi wẹ̀. Wọn kò rí irú ìdè lílágbára bẹ́ẹ̀ rí láàárín àwọn ènìyàn tí ó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́ ṣá o, ohun tí ó wú wọn lórí jù lọ ni ìgbàgbọ́ tí a fi hàn nípa ṣíṣe ìsapá ńláǹlà láti ṣègbọràn sí òfin orílẹ̀ èdè àti ìṣètò Ọlọ́run.
Àṣeyẹ Dídùnyùngbà
Gbàrà tí àwọn tọkọtaya náà dé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ fún ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ti ìgbéyàwó náà: gbígba ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí. Gbogbo wọ́n fi sùúrù dúró sórí ìlà níwájú àwọn òṣìṣẹ́ Ilé Iṣẹ́ Ìforúkọsílẹ̀ láti pèsè ìsọfúnni nípa ara wọn. Wọ́n wá tẹ̀ síwájú sí ìlà mìíràn láti ya fọ́tò, lẹ́yìn èyí tí wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tí ó wá láti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìdánimọ̀ láti gba káàdì ìdánimọ̀ wọn. Lẹ́yìn èyí, wọ́n padà sọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ Ilé Iṣẹ́ Ìforúkọsílẹ̀ fún ṣíṣe ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó, èyí tí ó wà ní góńgó ẹ̀mí wọn. Tẹ̀ lé èyí, wọ́n fi sùúrù dúró di ìgbà tí a óò pe orúkọ wọn lórí ẹ̀rọ gbohùngbohùn. Gbígba ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń ru ìmọ̀lára sókè. Ayọ̀ náà pọ̀ bí tọkọtaya kọ̀ọ̀kan ti na ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó wọn sókè bí àmì ẹ̀yẹ tí ó ṣeyebíye.
Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn gbígbóná janjan. Síbẹ̀, ooru àti erukutu kò dí ayọ̀ àṣeyẹ náà lọ́wọ́.
Aṣọ tí àwọn ọkùnrin wọ̀ ṣe ṣémúṣémú, ọ̀pọ̀ nínú wọ́n wọ jákẹ́ẹ̀tì àti táì. Àwọn obìnrin wọ aṣọ ìbílẹ̀, tí ó ní nínú aṣọ aláràbarà gígùn tí a ń pè ní capulana tí wọ́n ró mọ́dìí. Àwọn kan fi irú aṣọ náà pọn ọmọ.
Gbogbo nǹkan lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ, ṣùgbọ́n àwọn tọkọtaya tí a fẹ́ fún ní ìwé ẹ̀rí lọ́jọ́ kan ṣoṣo ti pọ̀ jù. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba fi inú rere pinnu láti máa bá iṣẹ́ nìṣó. Wọ́n sọ pé àwọn kò lè fi “àwọn arákùnrin wa” sílẹ̀ láìdá wọn lóhùn lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe ìsapá ńláǹlà láti wà níbẹ̀. Ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìfara-ẹni-rúbọ yìí ni a kò ní gbàgbé láé.
Nígbà tí ó di òru, òtútù mú gan-an. Nígbà tí ó jẹ́ pé inú ahéré ni a fi àwọn díẹ̀ wọ̀ sí, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tọkọtaya náà wà ní ìta, wọ́n kóra jọ sídìí iná. Èyí kò ba ayọ̀ àṣeyẹ náà jẹ́ rárá. Ẹ̀rín àti orin tí a ń fi ohùn mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kọ bo ìtapàpà iná mọ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ ń sọ ìtàn ìrìn àjò wọn, bí wọ́n ti diwọ́ mọ́ àwọn ìwé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà.
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn kan gbìyànjú láti lọ sí ìgboro abúlé náà láti lọ ta àwọn adìyẹ, ewúrẹ́, àti àwọn irè oko tí wọ́n kó wá, kí wọ́n lè fi san owó ìforúkọsílẹ̀ ìgbéyàwó wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ẹranko wọnnì “rúbọ̀” ní tòótọ́, nípa títà wọ́n ní owó pọ́ọ́kú. Fún àwọn òtòṣì, ewúrẹ́ ṣe iyebíye, ó sì gbówó lórí; síbẹ̀, wọ́n múra tán láti ṣe ìrúbọ yìí kí wọ́n lè ṣègbéyàwó, kí wọ́n sì mú inú Ẹlẹ́dàá wọn dùn.
Àwọn Ìnira Ìrìn Àjò Náà
Àwọn kan lára àwọn tọkọtaya náà ti rin ọ̀nà jíjìn dé ibẹ̀. Bí ó ti rí nìyẹn fún Chamboko àti Nhakulira, aya rẹ̀. Wọ́n sọ ohun tí ojú wọ́n rí ní alẹ́ ọjọ́ kejì ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí wọ́n ti ń fi ẹsẹ̀ wọn yáná. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni ọdún 77 ni Chamboko, tí ojú rẹ̀ kan fọ́, tí ojú kejì kò sì ríran dáadáa, ó rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta láìsí bàtà lẹ́sẹ̀, bí àwọn ìyókù ará ìjọ rẹ̀ ti bá a wá, nítorí ó ti pinnu láti mú ìgbépọ̀ ọlọ́dún 52 bá òfin mu.
Anselmo Kembo, tí ó jẹ́ ẹni ọdún 72, ti bá Neri gbé pọ̀ fún nǹkan bí 50 ọdún. Ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ìrìn àjò wọn, ẹ̀gún ńlá kan gún un lẹ́sẹ̀ nígbà tí ó ń ro oko rẹ̀. Wọ́n sáré gbé e lọ sí ọsibítù fún ìtọ́jú. Síbẹ̀síbẹ̀, ó pinnu pé òun yóò rinsẹ̀ lọ àjò náà, tìrọ́jú-tìrọ́jú ló tiro lọ sí iyàn-níyàn Fíngoè. Ó rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Anselmo kò lè pa ayọ̀ rẹ̀ mọ́ra bí ó ti di ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó rẹ̀ mú.
Ṣẹ̀ṣẹ̀-gbéyàwó mìíràn tí ó yẹ fún àfiyèsí ni Evans Sinóia, tí ó jẹ́ akóbìnrinjọ tẹ́lẹ̀ rí. Nígbà tí ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó pinnu láti mú ìgbépọ̀ òun àti aya rẹ̀ àkọ́kọ́ bá òfin mu, ṣùgbọ́n obìnrin náà kọ̀ jálẹ̀, ó fi í sílẹ̀ lọ bá ọkùnrin mìíràn. Aya rẹ̀ kejì, tí ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbà láti fẹ́ ẹ. Àwọn méjèèjì jọ rin àgbègbè eléwu tí kìnnìún àti àwọn ẹranko ẹhànnà mìíràn ń gbé. Lẹ́yìn ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta, àwọn náà ṣe ìgbéyàwó wọn ní àṣeyọrí, lábẹ́ òfin.
Ní ọjọ́ Friday, ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn tí àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kọ́kọ́ dé, ni iṣẹ́ náà parí. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé 468 káàdì ìdánimọ̀ àti 374 ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí ni a ṣe. Iye ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó tí a ṣe jẹ́ 233! Gbogbo àgbègbè náà ni ó kún fún ayọ̀ ńlá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti di ọwọ́ àárẹ̀, gbogbo wọ́n gbà pé ìsapá wọn kò já sí asán rárá. Láìsí àní-àní, àṣeyẹ yẹn kò ní parẹ́ láé lọ́kàn gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀. Ayẹyẹ ìgbéyàwó àrà ọ̀tọ̀ gbáà ni!