Dídúró Pẹ̀lú “Ìfojúsọ́nà Oníhàáragàgà”
“Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—RÓÒMÙ 8:19.
1. Ìjọra wo ni ó wà láàárín ipò tí àwọn Kristẹni wà lónìí àti ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?
IPÒ tí àwọn Kristẹni tòótọ́ wà lónìí fara jọ ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Àsọtẹ́lẹ̀ kan ran àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní àwọn ọjọ́ wọnnì lọ́wọ́ láti mọ ìgbà tí Mèsáyà yóò fara hàn. (Dáníẹ́lì 9:24-26) Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà yìí tún sọ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù ṣùgbọ́n kò sọ ohunkóhun tí ó lè mú kí àwọn Kristẹni mọ ìgbà tí a óò pa ìlú náà run. (Dáníẹ́lì 9:26b, 27) Lọ́nà kan náà, àsọtẹ́lẹ̀ kan nípasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá mú kí àwọn olóòótọ́ ọkàn tí ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún máa fojú sọ́nà. Nípa síso “ìgbà méje” ti Dáníẹ́lì 4:25 mọ́ “àkókò àwọn Kèfèrí,” wọ́n retí pé Kristi yóò gba agbára Ìjọba ní ọdún 1914. (Lúùkù 21:24, King James Version; Ìsíkíẹ́lì 21:25-27) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé Dáníẹ́lì ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹpẹtẹ, kò sí èyíkéyìí nínú ìwọ̀nyí tí ó mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì òde òní lè ṣírò àkókò náà gan-an tí a óò pa ètò àwọn nǹkan ti Sátánì run. (Dáníẹ́lì 2:31-44; 8:23-25; 11:36, 44, 45) Ṣùgbọ́n, èyí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́, nítorí tí a ń gbé ní “àkókò òpin.”—Dáníẹ́lì 12:4.a
Ṣíṣọ́nà Nígbà Wíwàníhìn-ín Kristi
2, 3. (a) Kí ni ẹ̀rí pàtàkì tí ó fi hàn pé a ń gbé nígbà wíwàníhìn-ín Kristi nínú agbára ọba? (b) Kí ní fi hàn pé àwọn Kristẹni ní láti máa bá a nìṣó láti máa ṣọ́nà nígbà wíwàníhìn-ín Jésù Kristi?
2 Òótọ́ ni pé, àsọtẹ́lẹ̀ kan mú kí àwọn Kristẹni máa fojú sọ́nà kí ó tó di pé a gbé agbára Ìjọba wọ Kristi ní ọdún 1914. Ṣùgbọ́n “àmì” tí Kristi mẹ́nu kàn nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti òpin ètò àwọn nǹkan ń sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí sì ni a óò rí lẹ́yìn tí wíwàníhìn-ín rẹ̀ bá ti bẹ̀rẹ̀. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí—ogun, ọ̀wọ́n oúnjẹ, ìsẹ̀lẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, ìwà àìlófin tí ń pọ̀ sí i, inúnibíni sí àwọn Kristẹni, àti ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà yíká ayé—jẹ́ ẹ̀rí pàtàkì pé a ń gbé nísinsìnyí nígbà wíwàníhìn-ín Kristi nínú agbára ọba.—Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:10, 11.
3 Síbẹ̀, lájorí ọ̀rọ̀ ìdágbére Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, . . . Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Máàkù 13:33, 37; Lúùkù 21:36) Fífarabalẹ̀ ka àyíká ọ̀rọ̀ ìyànjú nípa ṣíṣọ́nà yìí fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣíṣọ́ àmì ìbẹ̀rẹ̀ wíwàníhìn-ín Kristi ni òun ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tòótọ́ láti máa ṣọ́nà nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀. Kí ni àwọn Kristẹni tòótọ́ yóò máa ṣọ́?
4. Ète wo ni àmì tí Jésù fúnni yóò ṣiṣẹ́ fún?
4 Jésù fi àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kíkàmàmà dáhùn ìbéèrè náà pé: “Sọ fún wa, Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ [àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò yọrí sí ìparun ètò àwọn nǹkan ti àwọn Júù], kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Kì í ṣe wíwàníhìn-ín Kristi nìkan ni àmì tí ó sọ tẹ́lẹ̀ náà yóò jẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀, ṣùgbọ́n yóò tún jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò yọrí sí òpin ètò àwọn nǹkan burúkú ti ìsinsìnyí.
5. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé bí òun tilẹ̀ wà níhìn-ín nípa tẹ̀mí, òun ṣì “ń bọ̀”?
5 Jésù fi hàn pé nígbà “wíwàníhìn-ín” (Gíríìkì, pa·rou·siʹa) òun, òun yóò wá pẹ̀lú agbára àti ògo. Nípa irú ‘bíbọ̀’ bẹ́ẹ̀ (tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà erʹkho·mai dúró fún), ó polongo pé: “Nígbà náà sì ni àmì Ọmọ ènìyàn yóò fara hàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò, wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. . . . Wàyí o, ẹ kẹ́kọ̀ọ́ kókó yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́ gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe kan pé: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó [Kristi] ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn. . . . Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀. . . . Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”—Mátíù 24:30, 32, 33, 42, 44.
Èé Ṣe Tí Jésù Kristi Fi Gbọ́dọ̀ Wá?
6. Báwo ni ìparun “Bábílónì Ńlá” yóò ṣe ṣẹlẹ̀?
6 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti wà níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí Ọba láti ọdún 1914, Jésù Kristi ṣì gbọ́dọ̀ ṣèdájọ́ àwọn ètò tí ènìyàn gbé kalẹ̀ àti olúkúlùkù kí ó tó ṣèdájọ́ àwọn tí òun bá rí i pé ó burú. (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 5:10) Láìpẹ́, Jèhófà yóò fi í sínú àwọn alákòóso ìṣèlú láti pa “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé run. (Ìṣípayá 17:4, 5, 16, 17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní pàtó pé Jésù Kristi yóò pa “ọkùnrin oníwà àìlófin” náà—àwọn àlùfáà apẹ̀yìndà ti Kirisẹ́ńdọ̀mù, apá pàtàkì nínú “Bábílónì Ńlá”—run. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A óò ṣí aláìlófin náà payá, ẹni tí Jésù Olúwa yóò fi ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì sọ di asán nípasẹ̀ ìfarahàn wíwàníhìn-ín rẹ̀.”—2 Tẹsalóníkà 2:3, 8.
7. Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, ìdájọ́ wo ni òun yóò ṣe?
7 Láìpẹ́ jọjọ, Kristi yóò ṣèdájọ́ ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè lórí bí wọ́n ṣe hùwà padà sí àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. A kà á pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Yóò sì fi àwọn àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀. . . . Ọba yóò . . . wí fún [àwọn àgùntàn] pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, ẹ ti ṣe é fún mi.’ . . . Àwọn [ewúrẹ́] yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 25:31-46.
8. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe bíbọ̀ Kristi láti mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run?
8 Gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, Jésù ṣèdájọ́ ìkẹyìn lórí gbogbo àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù fi àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí ń jìyà lọ́kan balẹ̀ nípa “ìtura pa pọ̀ pẹ̀lú wa nígbà ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa. Àwọn wọ̀nyí gan-an yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun láti iwájú Olúwa àti láti inú ògo okun rẹ̀, ní àkókò tí òun bá dé láti di àyìnlógo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.” (2 Tẹsalóníkà 1:7-10) Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ arùmọ̀lárasókè tí ó wà níwájú wa wọ̀nyí, kò ha yẹ kí a lo ìgbàgbọ́, kí a sì fi ìháragàgà máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà fún bíbọ̀ Kristi bí?
Fífi Ìháragàgà Dúró De Ìṣípayá Kristi
9, 10. Èé ṣe tí àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń fi ìháragàgà dúró de ìṣípayá Jésù Kristi?
9 “Ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run” kò ni jẹ́ kìkì láti mú ìparun wa sórí àwọn ẹni búburú ṣùgbọ́n yóò tún jẹ́ láti san èrè fún àwọn olódodo. Àwọn ìyókù arákùnrin Kristi ẹni àmì òróró tí ó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ṣì lè jìyà kí ìṣípayá Kristi tó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ń yọ̀ nínú ìrètí ògo wọn ti ọ̀run. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀ níwọ̀n bí ẹ ti jẹ́ alájọpín nínú àwọn ìjìyà Kristi, kí ẹ lè yọ̀, kí ẹ sì ní ayọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú nígbà ìṣípayá ògo rẹ̀.”—1 Pétérù 4:13.
10 Àwọn ẹni àmì òróró pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ títí tí Kristi yóò fi ‘kó wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀’ kí “ìjójúlówó” ìgbàgbọ́ wọn “tí a ti dán wò . . . lè jẹ́ èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn àti ògo àti ọlá nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.” (2 Tẹsalóníkà 2:1; 1 Pétérù 1:7) Nípa irú àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí a fẹ̀mí bí bẹ́ẹ̀, a lè sọ pé: “A . . . fìdí ẹ̀rí nípa Kristi múlẹ̀ gbọn-in láàárín yín, tí ó fi jẹ́ pé ẹ kò kùnà rárá láti dé ojú ìwọ̀n nínú ẹ̀bùn èyíkéyìí, bí ẹ ti ń fi ìháragàgà dúró de ìṣípayá Olúwa wa Jésù Kristi.”—1 Kọ́ríńtì 1:6, 7.
11. Bí wọ́n ti ń dúró de ìṣípayá Jésù Kristi, kí ni àwọn ẹni àmì òróró Kristẹni ń ṣe?
11 Àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró ní irú ìmọ̀lára tí Pọ́ọ̀lù ní, ẹni tó kọ̀wé pé: “Mo ṣírò rẹ̀ pé àwọn ìjìyà àsìkò ìsinsìnyí kò jámọ́ ohunkóhun ní ìfiwéra pẹ̀lú ògo tí a óò ṣí payá nínú wa.” (Róòmù 8:18) A kò ní láti fi kíka ọjọ́ gbé ìgbàgbọ́ wọn ró. Ọwọ́ wọn dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, wọ́n ń fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, “àwọn àgùntàn mìíràn.” (Jòhánù 10:16) Àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí mọ̀ pé ètò àwọn nǹkan burúkú yìí sún mọ́lé, wọ́n sì ń kọbi ara sí ìṣílétí Pétérù náà pé: “Ẹ mú èrò inú yín gbára dì fún ìgbòkègbodò, ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́ lọ́nà pípé pérépéré; ẹ gbé ìrètí yín ka inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, èyí tí a óò mú wá fún yín nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.”—1 Pétérù 1:13.
“Ìfojúsọ́nà Oníhàáragàgà Ìṣẹ̀dá”
12, 13. Báwo ni a ṣe “tẹ” ẹ̀dá ènìyàn “lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo,” kí sì ni àwọn àgùntàn mìíràn ń yán hànhàn fún?
12 Àwọn àgùntàn mìíràn pẹ̀lú ha ní ohun kan tí wọ́n lè máa fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún? Dájúdájú wọ́n ní. Lẹ́yìn sísọ̀rọ̀ nípa ìrètí ológo ti àwọn tí Jèhófà sọ dọmọ gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọmọ” rẹ̀ tí a fi ẹ̀mí bí àti “àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi” nínú Ìjọba ọ̀run, Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:14-21; 2 Tímótì 2:10-12.
13 Nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ni a ‘tẹ̀ lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo,’ a ti bí wọn sínú òǹdè ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Kò ṣeé ṣe fún wọn láti gba ara wọn kúrò nínú irú òǹdè yẹn. (Sáàmù 49:7; Róòmù 5:12, 21) Ẹ wo bí àwọn àgùntàn mìíràn ti ń yàn hànhàn tó fún ‘ìdásílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́’! Ṣùgbọ́n kí ìyẹn tó ṣẹlẹ̀, àwọn nǹkan kan gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìgbà àti àsìkò Jèhófà.
14. Kí ni ‘ṣíṣí àwọn ọmọ Ọlọ́run payá’ yóò ní nínú, báwo sì ni èyí yóò ṣe yọrí sí ‘dídá aráyé sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́’?
14 A gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ‘ṣí àṣẹ́kù ẹni àmì òróró, àwọn ọmọ Ọlọ́run payá.’ Kí ni èyí yóò ní nínú? Nígbà tí ó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, yóò hàn gbangba sí àwọn àgùntàn mìíràn pé a ti fi “èdìdì di” àwọn ẹni àmì òróró nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a sì ti ṣe wọ́n lógo láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi. (Ìṣípayá 7:2-4) A óò tún ‘ṣí àwọn ọmọ Ọlọ́run’ tí a jí dìde ‘payá’ nígbà tí wọ́n bá bá Kristi lọ́wọ́ nínú pípa ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì run. (Ìṣípayá 2:26, 27; 19:14, 15) Lẹ́yìn náà, nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, a óò túbọ̀ ‘ṣí wọn payá’ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tí a ń lò fún pípín àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù fún “ìṣẹ̀dá” tí ó jẹ́ ènìyàn. Èyí yóò yọrí sí ‘dídá aráyé sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́,’ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ wọn yóò sì wọnú “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21; Ìṣípayá 20:5; 22:1, 2) Bí a ti ní irú ìrètí kíkọyọyọ bẹ́ẹ̀, ó ha yani lẹ́nu pé àwọn àgùntàn mìíràn “ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run” pẹ̀lú “ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà” bí?—Róòmù 8:19.
Sùúrù Jèhófà Túmọ̀ Sí Ìgbàlà
15. Kí ni kò yẹ kí a gbàgbé ní ti àkókò tí Jèhófà yàn kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀?
15 Jèhófà ni Olùpa Àkókò Mọ́ Títóbi Jù. Àkókò tí ó ti yàn fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yóò pé pérépéré. Àwọn nǹkan lè má fìgbà gbogbo rí bí a ti retí. Ṣùgbọ́n, a lè ní ìgbàgbọ́ kíkúnrẹ́rẹ́ pé gbogbo ìlérí Ọlọ́run ni yóò ṣẹ. (Jóṣúà 23:14) Ó lè jẹ́ kí àwọn nǹkan máa bá a lọ jù bí ọ̀pọ̀ ti retí. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wá àtilóye àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí a sì mọyì ọgbọ́n rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn! Nítorí ‘ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà, tàbí ta ní ti di agbani-nímọ̀ràn rẹ̀?’”—Róòmù 11:33, 34.
16. Ta ni ó tóótun láti jàǹfààní sùúrù Jèhófà?
16 Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, níwọ̀n bí ẹ ti ń dúró de nǹkan wọ̀nyí [ìparun “ọ̀run” àti “ilẹ̀ ayé” ti àtijọ́ àti fífi tí a óò fi “ọ̀run tuntun” àti “ilẹ̀ ayé tuntun” tí Ọlọ́run ṣèlérí rọ́pò rẹ̀], ẹ sa gbogbo ipá yín kí òun lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà. Síwájú sí i, ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.” Nítorí sùúrù Jèhófà, a ti fún ọ̀pọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ láǹfààní láti la “ọjọ́ Jèhófà” já, èyí tí yóò dé “gẹ́gẹ́ bí olè.” (2 Pétérù 3:9-15) Sùúrù rẹ̀ tún ń jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ‘máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà wa yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.’ (Fílípì 2:12) Jésù wí pé a gbọ́dọ̀ ‘kíyè sí ara wa, kí a sì wà lójúfò,’ bí a bá fẹ́ jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà, kí a sì kẹ́sẹ járí ní “dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn” ní àkókò tí ó bá wá fún ìdájọ́.—Lúùkù 21:34-36; Mátíù 25:31-33.
Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Fífi Ìfaradà Dúró
17. Àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wo ni ó yẹ kí a fi sọ́kàn?
17 Pọ́ọ̀lù rọ àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí láti tẹ ojú wọn mọ́, ‘àwọn ohun tí a kò rí, kì í ṣe àwọn ohun tí a ń rí.’ (2 Kọ́ríńtì 4:16-18) Kò fẹ́ kí ohunkóhun ṣú bò wọ́n lójú ní ti èrè ti ọ̀run tí a gbé ka iwájú wọn. Yálà a wà lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tàbí àwọn àgùntàn mìíràn, ẹ jẹ́ kí a fi ọkàn wa sí ìrètí àgbàyanu tí a gbé ka iwájú wa, kí a má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a ‘máa fi ìfaradà dúró dè é,’ kí a fi hàn pé “àwa kì í ṣe àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun, ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.”—Róòmù 8:25; Hébérù 10:39.
18. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé pẹ̀lú ìgbọ́kànlé a lè fi ìgbà àti àsìkò lé Jèhófà lọ́wọ́?
18 Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé a lè fi ìgbà àti àsìkò lé Jèhófà lọ́wọ́. Ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀ “kì yóò pẹ́” ní ìbámu pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkókò rẹ̀. (Hábákúkù 2:3) Ní báyìí ná, ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì ní ìtumọ̀ pàtàkì fún wa. Ó wí pé: “Mo pàṣẹ fún ọ lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù, ẹni tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣèdájọ́ àwọn alààyè àti òkú, àti nípasẹ̀ ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀, wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú . . . Ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.”—2 Tímótì 4:1-5.
19. Kí ni àkókò ṣì wà fún àwọn ènìyàn Jèhófà láti ṣe, èé sì ti ṣe?
19 Ìwàláàyè wà nínú ewu—tiwa àti ti àwọn aládùúgbò wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:16) Àkókò tó kù fún ètò àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí kúrú gan-an. Bí a ti ń fi ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà dúró de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ arùmọ̀lárasókè tí ó wà níwájú wa, ẹ jẹ́ kí a máa mọ̀ nígbà gbogbo pé ìgbà àti àsìkò Jèhófà ṣì nìyí fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. A gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ náà dé ibi tí yóò ti tẹ́ ẹ lọ́rùn. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti wí: “Nígbà náà ni òpin yóò dé.”—Mátíù 24:14.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo orí 10 àti 11 ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Lọ́nà Àtúnyẹ̀wò
◻ Nípa kíka ọjọ́, báwo ni ipò wa ṣe jọ ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?
◻ Èé ṣe tí àwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà,” àní nígbà wíwàníhìn-ín Kristi?
◻ Èé ṣe tí ìṣẹ̀dá tí ó jẹ́ ènìyàn fi ń fìháragàgà fojú sọ́nà fún “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run”?
◻ Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé pẹ̀lú ìgbọ́kànlé a lè fi ìgbà àti àsìkò lé Jèhófà lọ́wọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ wà lójúfò ní ìfojúsọ́nà fún bíbọ̀ Kristi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ọwọ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, wọn kò gbé ìgbàgbọ́ wọn karí kíka ọjọ́