Ojúlówó Ìrànwọ́ fún Ìdílé
“Ká sòótọ́, ìdílé ti kòṣòro ní Amẹ́ríkà. Àsọdùn kọ́ lèyí o, pàápàá báa bá ka iye àwọn tí ń jáwèé ìkọ̀sílẹ̀, iye ọmọ tí a ń bí lẹ́yìn òde ìgbéyàwó, [àti] bí àwọn èèyàn ṣe ń hùwà àìdáa sáwọn ògo wẹẹrẹ àti sí ọkọ tàbí aya wọn.”
Ọ̀RỌ̀ tí Tom Brokaw, tí í ṣe alálàyé lórí tẹlifíṣọ̀n lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ wẹ́rẹ́ yìí, ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè. Kí ni ìṣòro yìí túmọ̀ sí?
Lóríṣiríṣi ọ̀nà, ìdílé ni igi lẹ́yìn ọgbà fún àwùjọ. Bí ìdílé bá ti wọ̀jọ̀ngbọ̀n, àwùjọ wọ̀jọ̀ngbọ̀n nìyẹn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìdílé ló ń rí sí àìní àwọn ọmọdé ní ti èrò ìmọ̀lára àti ìṣúná owó. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. Bí ìdílé bá ti wọ̀jọ̀ngbọ̀n, ẹ̀kọ́ wo làwọn ọmọ fẹ́ rí kọ́? Ààbò wọn dà? Irú àgbà wo ni wọn yóò dà?
Ìrànwọ́ kankan ha wà fún ìdílé lákòókò ìṣòro yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìdílé jẹ́ ètò tí Ọlọ́run tìkára rẹ̀ dá sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ó sì ti pèsè ìtọ́sọ́nà tí kò ṣeé má nìí fún ìdílé sínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Kólósè 3:18-21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè yí àwùjọ padà látòkè délẹ̀, síbẹ̀ a lè fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò nínú ìdílé tiwa. A fẹ́ sọ fún ọ nípa àwọn kan tó ti ṣe èyí àti èso rere tó so.
Dídènà Ìkọ̀sílẹ̀
Láwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan, ìkọ̀sílẹ̀ ló ń gbẹ̀yìn ìlàjì gbogbo ìgbéyàwó. Ìforíṣánpọ́n tó gadabú mà lèyí nínú àjọṣepọ̀ ẹ̀dá! Òtítọ́ ni, ọ̀pọ̀ àwọn tí ìkọ̀sílẹ̀ ti sọ di òbí tí ń dá nìkan gbé ẹrù ẹni méjì, ń ṣe iṣẹ́ ribiribi ní títọ́ ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ yóò gbà pé ó sàn kí tọkọtaya yanjú àwọn ìṣòro wọn, kí wọ́n sì máa jọ gbé.
Ìgbéyàwó tọkọtaya kan ní Solomon Islands fẹ́ forí ṣánpọ́n. Ọkọ, tí í ṣe ọmọ olóyè, jẹ́ oníwà ipá, oríṣiríṣi ìwà burúkú ló sì kún ọwọ́ rẹ̀. Ayé wá sú ìyàwó ẹ̀, ló bá fẹ́ gbẹ̀mí ara ẹ̀. Nígbà tó wá yá o, ọkọ rẹ̀ gbà kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa bá òun kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn, kò wulẹ̀ ní mọ̀ pé ohun kan burú nìkan, ṣùgbọ́n ó tún gbọ́dọ̀ “kórìíra ohun búburú.” (Sáàmù 97:10) Ìyẹn kan kíkórìíra àwọn nǹkan bí irọ́ pípa, olè jíjà, ìwà ipá, àti ìmutípara. Ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, kò sì pẹ́ tó fi yọwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú rẹ̀ àti ìbínú fùfù rẹ̀. Ìyípadà yìí ya ìyàwó ẹ̀ lẹ́nu, ìgbéyàwó wọn sì wá túbọ̀ sunwọ̀n sí i, ọpẹ́lọpẹ́ agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ní Gúúsù Áfíríkà, obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbọ́ pé obìnrin tó gba òun síṣẹ́ àti ọkọ rẹ̀ ń gbèrò àtijáwèé ìkọ̀sílẹ̀. Ẹlẹ́rìí náà bá ọ̀gá rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ìgbéyàwó, ó sì fi ìwé náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé hàn án. Ìwé yìí, tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, gbé àwọn ìlànà Bíbélì tó kan ìgbéyàwó jáde lákànṣe, ó sì tẹnu mọ́ bí Bíbélì ṣe ń ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro. Ọ̀gá náà àti ọkọ rẹ̀ ka ìwé náà, wọ́n sì fi tọkàntọkàn gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà nínú rẹ̀ sílò. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé wọn pinnu pé àwọn kò ní kọ ara àwọn sílẹ̀ mọ́—títẹ̀lé ìlànà Bíbélì tún gba ìgbéyàwó mìíràn là.
Ẹ̀sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Ìgbéyàwó tí tọkọtaya ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ńkọ́? Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, Bíbélì fún àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n ṣe ìgbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Àmọ́ o, nígbà mìíràn, ọkọ tàbí aya lè yí ẹ̀sìn rẹ̀ padà. Ó ha yẹ kí ìyẹn fòpin sí ìgbéyàwó ọ̀hún bí? Rárá o.
Ní Botswana, a béèrè lọ́wọ́ obìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa bí ẹ̀sìn rẹ̀ tuntun ṣe yí i padà. Ó ní kí ọkọ òun dáhùn fún òun, ohun tó sì sọ rèé: “Láti ìgbà tí ìyàwó mi ti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀pọ̀ ìyípadà rere ni mo ti rí pé ó ti ṣe. Nísinsìnyí, ó ti di èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, tí ń fọgbọ́n hùwà, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó pinnu láti ṣíwọ́ sìgá mímu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ìṣòro tí mo borí tì. Ṣe ni ìyàwó mi túbọ̀ ń fìfẹ́ hàn, tó ń kẹ́ èmi àti àwọn ọmọ, àti àwọn ẹlòmíràn gẹ̀gẹ̀. Ó túbọ̀ ń mú nǹkan mọ́ra, pàápàá nǹkan táwọn ọmọ ẹ̀ bá ṣe. Mo rí i pé ó ń lo àkókò púpọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, tó ń sapá láti bá àwọn ẹlòmíràn tún ayé wọn ṣe. Èmi náà ti ṣe àwọn àyípadà rere. Mo gbà pé gbogbo èyí jẹ́ nítorí àpẹẹrẹ rẹ̀.” Ẹ wo irú ipa rere tí ìlànà Bíbélì ti ní lórí ìgbéyàwó yìí! Ọ̀pọ̀ èèyàn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ló ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípa ọkọ tàbí aya wọn tí í ṣe Ẹlẹ́rìí.
Nígbà Tí Baba Kò Bá Ṣojúṣe Rẹ̀
Ìbátan tó wà láàárín baba àtọmọ ṣe kókó fún gbígbé ìdílé tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ró. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Àbájọ tí àpilẹ̀kọ náà nínú ìwé ìròyìn The Wilson Quarterly fi sọ pé àwọn baba tí kò ṣojúṣe wọn ló lẹ̀bi ọ̀pọ̀ ìṣòro tí ń bẹ láwùjọ. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Láàárín ọdún 1960 sí 1990, iye àwọn ọmọ tí kì í gbé lọ́dọ̀ baba tó bí wọn lọ́mọ ti lé ní ìlọ́po méjì . . . Àìṣojúṣe baba ni ohun pàtàkì tó ń fa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣòro tó burú jù lọ tó kọlu àwùjọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà.”
Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ tí a kò bá tọwọ́ baba tọ́, ọmọ tí kò wúlò ni wọn yóò dà? Ó tì o. Onísáàmù ìgbàanì sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Ọmọdékùnrin ọlọ́dún mẹ́sàn-án kan ní Thailand rí i pé báyìí lọ̀ràn rí. Màmá rẹ̀ kú nígbà tó wà lọ́mọ ọwọ́, baba rẹ̀ sì fà á lé ìyá rẹ̀ àgbà lọ́wọ́ torí pé kò fẹ́ ọmọ náà. Nítorí pé ọmọ náà nímọ̀lára pé kò sẹ́ni tó fẹ́ràn òun, ó di ọlọ̀tẹ̀ àti jàǹdùkú ládùúgbò. Ó tilẹ̀ fẹ́ ṣe ìyá rẹ̀ àgbà léṣe. Àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàkíyèsí pé ọmọ yìí sábà máa ń dúró lóde Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò, nítorí náà, lọ́jọ́ kan wọ́n ní kó wá kí àwọn nílé.
Wọ́n sọ fún un nípa Ọlọ́run—pé Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí baba. Wọ́n tún sọ fún un nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn olóòótọ́. (Ìṣípayá 21:3, 4) Gbogbo èyí wu ọmọdékùnrin yìí, ojoojúmọ́ ló sì ń padà wá mọ̀ sí i. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà sọ fún un pé ó gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú gbogbo ìwà jàǹdùkú tó ń hù, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló fẹ́ kí Ọlọ́run jẹ́ Baba òun. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Róòmù, pé: “Níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) Yóò tún pọndandan kí ó máa fi ọ̀wọ̀ tó yẹ ìyá rẹ̀ àgbà wọ̀ ọ́. (1 Tímótì 5:1, 2) Láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ìlànà Bíbélì ṣèwà hù—dájúdájú, èyí mú kí ìbágbé òun àti ìyá rẹ̀ àgbà túbọ̀ dán mọ́rán. (Gálátíà 5:22, 23) Àwọn ìyípadà tí àwọn aládùúgbò ṣàkíyèsí pé ọmọ yìí ṣe wú wọn lórí tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fẹ́ kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa bá àwọn ọmọ tiwọn pẹ̀lú kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!
Ẹ̀mí Àlàáfíà
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Kólósè pé: “Ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà yín.” (Kólósè 3:14, 15) Ó dájú pé ẹ̀mí àlàáfíà àti ìfẹ́ àtọkànwá yóò so ìdílé pọ̀. Wọ́n sì lè yanjú aáwọ̀ tó ti ya ìdílé nípa tipẹ́tipẹ́. Rukia, tí ń gbé ní Albania, bá àbúrò rẹ̀ ọkùnrin yodì fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́tàdínlógún nítorí èdèkòyédè kan tí wọ́n jọ ní nínú ìdílé. Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó kẹ́kọ̀ọ́ pé olúkúlùkù ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni a rọ̀ pé kí ó wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. “Kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.”—1 Pétérù 3:11.
Rukia rí i pé òun ní láti wà lálàáfíà pẹ̀lú àbúrò òun. Ó gbàdúrà látòru mọ́jú, nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì sì mọ́, ó gbọ̀nà ilé àbúrò rẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n àyà rẹ̀ ń já. Ọmọ àbúrò Rukia ló ṣílẹ̀kùn, ó sì béèrè tìyanu-tìyanu pé: “Kí lẹ wá ṣe níbí?” Rukia fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sọ pé àbúrò òun lòun wá rí, ó ṣàlàyé pé òun fẹ́ yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín àwọn méjèèjì. Èé ṣe? Nítorí ó ti wá mọ̀ báyìí pé èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run. Àbúrò rẹ̀ fayọ̀ gbà á, nígbà àtúnsopọ̀ náà, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbá ara wọn mọ́ra, tí wọ́n sì ń sunkún ayọ̀—a tún so ìdílé kan pọ̀ nítorí pé wọ́n tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì.
Ẹgbẹ́ Búburú
“Lónìí, wákàtí méje ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọdé fi ń wo tẹlifíṣọ̀n lójoojúmọ́. Nígbà tó bá máa fi parí iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ó ti rí iye ìpànìyàn tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àti ọgọ́rùn-ún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ìwà ipá.” Báyìí ni ìwé náà The 7 Habits of Highly Effective Families wí. Ipa wo ni irú ìwòkuwò bẹ́ẹ̀ ń ní lórí ọmọdé? Ohùn “àwọn ògbógi” kò ṣọ̀kan lórí ìyẹn, ṣùgbọ́n Bíbélì kì wá nílọ̀ gidigidi nípa ẹgbẹ́ búburú. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Ó tún sọ pẹ̀lú pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) A lè tún ayé ìdílé ṣe, bí a bá fi tòyetòye gbà pé ìlànà yìí yẹ ní títẹ̀lé, yálà ẹgbẹ́ búburú náà jẹ́ àwọn ènìyàn gidi tàbí ètò kan lórí tẹlifíṣọ̀n.
Ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá ìyá kan ní Luxembourg kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́jọ́ kan, ó sọ fún Ẹlẹ́rìí náà pé tó bá dalẹ́, àwọn ọmọbìnrin òun méjèèjì tí wọn jẹ́ ọmọ ọdún méje àti mẹ́jọ máa ń ṣèjọ̀ngbọ̀n jù, wọ́n sì máa ń fínràn. Ẹlẹ́rìí náà béèrè ohun tí àwọn ọmọdébìnrin náà ń ṣe lálaalẹ́. Ìyá wọn sọ pé tẹlifíṣọ̀n ni wọ́n máa ń wò nígbà tóun bá ń palẹ̀ ilé ìdáná mọ́. Eré wo ni wọ́n máa ń wò? Ìyá náà fèsì pé: “Ẹ̀, àwọn àwòrán ẹ̀fẹ̀ mà ni o.” Nígbà tí àlejò rẹ̀ sọ pé irú eré bẹ́ẹ̀ sábà máa ń kún fún ìwà ipá, ìyá àwọn ọmọbìnrin náà sọ pé òun yóò máa ṣàkíyèsí wọn.
Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e gan-an, ìyá náà ròyìn pé àyà òun já nígbà tóun rí àwọn àwòrán ẹ̀fẹ̀ tí àwọn ọmọbìnrin òun ń wò. Ohun tí wọ́n ń gbé jáde ni àwọn abàmì ẹ̀dá láti ojúde òfuurufú tí wọ́n ń fìbínú runlé rùnnà. Ó ṣàlàyé fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pé Jèhófà kórìíra ìwà ipá, inú rẹ̀ kò sì ní dùn báa bá ń wo irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 11:5) Nítorí pé àwọn ọmọdébìnrin náà fẹ́ ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí, wọ́n gbà láti máa yàwòrán kí wọ́n sì máa kùn ún dípò wíwo tẹlifíṣọ̀n. Kíákíá ni ìwà ìfínràn wọn dáwọ́ dúró, afẹ́fẹ́ àlàáfíà sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ sí ìdílé wọn.
Ìwọ̀nyí kàn jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé fífi ìlànà Bíbélì sílò ń tún ayé ìdílé ṣe. Ìmọ̀ràn Bíbélì ń ṣiṣẹ́ fún gbogbo onírúurú ipò. Ó ṣeé gbára lé, ó sì ń ní ipa rere tó lágbára. (Hébérù 4:12) Bí àwọn èèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n fi tọkàntọkàn gbìyànjú láti fi ohun tó sọ sílò, a óò fún ìdílé wọn lókun, ìwà wọn yóò sunwọ̀n sí i, wọn ó sì yẹra fún àwọn àṣìṣe. Ká tilẹ̀ sọ pé ẹnì kan ṣoṣo nínú ìdílé ló ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run, síbẹ̀, nǹkan yóò sàn. Lóòótọ́, nínú gbogbo apá ìgbésí ayé, ṣe ló yẹ ká ní ojú ìwòye kan náà tí onísáàmù ní nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.”—Sáàmù 119:105.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
A ti yanjú àwọn ìṣòro ìdílé nípa fífi ìlànà Bíbélì sílò