“Ẹ Fìdí Ọkàn-àyà Yín Múlẹ̀ Gbọn-in”
“Ẹ nílò ìfaradà, kí ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tán, kí ẹ lè rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà.”—HÉBÉRÙ 10:36.
1, 2. (a) Kí ní ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Èé ṣe tó fi rọrùn kí ìgbàgbọ́ di ahẹrẹpẹ?
NÍNÚ gbogbo àwọn tó kọ Bíbélì, kò sẹ́ni tó mẹ́nu kan ìgbàgbọ́ tó àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Léraléra, ó tún sọ nípa àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ti di ahẹrẹpẹ tàbí tí ìgbàgbọ́ wọn ti kú. Bí àpẹẹrẹ, Híméníọ́sì àti Alẹkisáńdà “ní ìrírí rírì ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn.” (1 Tímótì 1:19, 20) Démásì kọ Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ nítorí “ó nífẹ̀ẹ́ ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (2 Tímótì 4:10) Àwọn kan “sẹ́ ìgbàgbọ́,” nípa híhùwà tí ń dójú tini, ìwà tí kò tọ́ sí Kristẹni. Wọ́n ti fi ọgbọ́n èké tan àwọn mìíràn jẹ́, wọ́n sì “yapa kúrò nínú ìgbàgbọ́.”—1 Tímótì 5:8; 6:20, 21.
2 Èé ṣe tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn fi pàdánù báyìí? Tóò, “ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Ohun tí a kò lè rí ni à ń gbà gbọ́. A kò nílò ìgbàgbọ́ fún àwọn nǹkan táa ti rí. Ó rọrùn láti ṣiṣẹ́ fún ọrọ̀ ti a lè fojú rí jù láti ṣiṣẹ́ fún ọrọ̀ tẹ̀mí tí a kò lè fojú rí. (Mátíù 19:21, 22) Ọ̀pọ̀ nǹkan táa lè fojú rí—irú bí “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú”—máa ń tètè fà wá mọ́ra tìtorí ẹran ara àìpé wa, wọ́n sì lè sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ.—1 Jòhánù 2:16.
3. Irú ìgbàgbọ́ wo ló yẹ kí Kristẹni ní?
3 Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé, “ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” Irú ìgbàgbọ́ yẹn ni Mósè ní. Ó “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà” ó sì “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:6, 24, 26, 27) Irú ìgbàgbọ́ yìí ni Kristẹni nílò. Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú, Ábúráhámù jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nínú èyí.
Ìgbàgbọ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ Tí Ábúráhámù Ní
4. Báwo ni ìgbàgbọ́ Ábúráhámù ṣe nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀?
4 Úrì ni Ábúráhámù ń gbé nígbà tó gbọ́ ìlérí Ọlọ́run pé òun yóò di baba irú-ọmọ tí yóò jẹ́ ìbùkún fún àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3; Ìṣe 7:2, 3) Nítorí ìlérí yẹn, Ábúráhámù ṣègbọràn sí Jèhófà, ó kọ́kọ́ ṣí lọ sí Háránì, lẹ́yìn náà ó gbéra, ó di Kénáánì. Níbẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé irú-ọmọ Ábúráhámù ni òun yóò fún ní ilẹ̀ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 12:7; Nehemáyà 9:7, 8) Ṣùgbọ́n, púpọ̀ lára ohun tí Jèhófà ṣèlérí ló jẹ́ pé ó di ẹ̀yìn ikú Ábúráhámù kó tó mú un ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù alára kò dá ní ilẹ̀ kan ní Kénáánì—bó bá yẹ̀ ní hòrò Mákípẹ́là, tó rà fún ibi ìsìnkú. (Jẹ́nẹ́sísì 23:1-20) Síbẹ̀, ó gba ọ̀rọ̀ Jèhófà gbọ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó nígbàgbọ́ nínú “ìlú ńlá [ọjọ́ ọ̀la] tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 11:10) Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ló gbé e ró jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.
5, 6. Báwo ni a ṣe fi ìlérí Jèhófà dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù wò?
5 A rí èyí ní pàtàkì ní ti ìlérí náà pé irú-ọmọ Ábúráhámù yóò di orílẹ̀-èdè ńlá. Kí èyí tó lè ṣẹlẹ̀, Ábúráhámù gbọ́dọ̀ bímọ, ó sì mú sùúrù fún ìgbà pípẹ́ kí Ọlọ́run tó wá fi ọ̀kan ta á lọ́rẹ. A kò mọ ọjọ́ orí rẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́ ìlérí Ọlọ́run, àmọ́, Jèhófà kò tíì fún ní ọmọ nígbà tó rìnrìn àjò gígùn lọ sí Háránì. (Jẹ́nẹ́sísì 11:30) Ó gbé Háránì pẹ́ dé bí pé ó ‘kó ẹrù àti ọkàn jọ rẹpẹtẹ,’ nígbà tí ó sì fi máa ṣí lọ sí Kénáánì, ó ti di ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin, Sárà sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin. Síbẹ̀, wọn kò tí ì bímọ. (Jẹ́nẹ́sísì 12:4, 5) Nígbà tí Sárà lé ní ẹni àádọ́rin ọdún ló ti gba kámú pé òun kò lè bímọ fún Ábúráhámù mọ́. Ìdí nìyẹn tó fi tẹ̀ lé àṣà ìgbà náà, tí ó fi fi Hágárì, ẹrúbìnrin rẹ̀, fún Ábúráhámù, ìyẹn sì bí ọmọkùnrin kan fún un. Àmọ́ kì í ṣe ọmọ táa ṣèlérí nìyí. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀, jáde. Síbẹ̀, nígbà tí Ábúráhámù bẹ̀bẹ̀ nítorí wọn, Jèhófà ṣèlérí láti bù kún Íṣímáẹ́lì.—Jẹ́nẹ́sísì 16:1-4, 10; 17:15, 16, 18-20; 21:8-21.
6 Nígbà tó tó àkókò lójú Ọlọ́run—ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ gbọ́ ìlérí náà nìyẹn o—Ábúráhámù ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún àti Sárà ẹni àádọ́rùn-ún ọdún bí ọmọkùnrin jòjòló kan, Ísákì. Àrà mérìíyìírí nìyẹn mà jẹ́ fún wọn o! Lójú tọkọtaya arúgbó yìí, ṣe ló dà bí àjíǹde, nígbà tí ara wọn ‘tó ti kú’ tún jí lákọ̀tún. (Róòmù 4:19-21) Wọ́n ti mú sùúrù fún ìgbà pípẹ́ lóòótọ́, ṣùgbọ́n nígbà tí ìlérí náà ṣẹ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n rí i pé sùúrù àwọn kò já sí asán.
7. Kí ni ìgbàgbọ́ ní í ṣe pẹ̀lú ìfaradà?
7 Àpẹẹrẹ Ábúráhámù rán wa létí pé kò yẹ kí ìgbàgbọ́ wa wà fún ìgbà kúkúrú. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbàgbọ́ ní í ṣe pẹ̀lú ìfaradà nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ nílò ìfaradà, kí ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tán, kí ẹ lè rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà. . . . Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun, ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Hébérù 10:36-39) Ọ̀pọ̀ ti mú sùúrù fún ìgbà pípẹ́ láti rí ìmúṣẹ ìlérí náà. Àwọn kan tilẹ̀ mú sùúrù jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wọn. Ìgbàgbọ́ wọn lílágbára ló gbé wọn ró. Gẹ́gẹ́ bí ti Ábúráhámù, wọn yóò gba èrè rẹ̀ nígbà tó bá tó àkókò lójú Jèhófà.—Hábákúkù 2:3.
Fífetísí Ọlọ́run
8. Báwo ni a ṣe ń fetí sí Ọlọ́run lónìí, èé sì ti ṣe tí ìyẹn yóò fi fún ìgbàgbọ́ wa lókun?
8 Ó kéré tán, ohun mẹ́rin ló fún ìgbàgbọ́ Ábúráhámù lókun, àwọn ohun wọ̀nyí sì lè ran àwa pẹ̀lú lọ́wọ́. Èkíní, ó fi hàn pé òun ‘gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ń bẹ’ nípa fífetísílẹ̀ nígbà tí Jèhófà bá a sọ̀rọ̀. Nípa báyìí, kò dà bí àwọn Júù ọjọ́ Jeremáyà, tí wọ́n gba Jèhófà gbọ́, àmọ́ tí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. (Jeremáyà 44:15-19) Lónìí, Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn ojú ìwé Bíbélì, ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó mí sí, èyí tí Pétérù sọ pé ó dà bí “fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn . . . nínú ọkàn-àyà yín.” (2 Pétérù 1:19) Nígbà tí a bá fara balẹ̀ ka Bíbélì, a ń “fi àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́” wa. (1 Tímótì 4:6; Róòmù 10:17) Síwájú sí i, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” ó ń pèsè ìtọ́sọ́nà nípa bí a ṣe lè lo àwọn ìlànà Bíbélì, kí a sì lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. (Mátíù 24:45-47) Fífetísílẹ̀ sí Jèhófà nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà wọ̀nyí pọndandan láti lè ní ìgbàgbọ́ lílágbára.
9. Kí ni yóò yọrí sí bí a bá nígbàgbọ́ tòótọ́ nínú ìrètí Kristẹni?
9 Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù tún ní í ṣe gidigidi pẹ̀lú ìrètí rẹ̀. “Lórí ìpìlẹ̀ ìrètí, ó ní ìgbàgbọ́, kí ó lè di baba ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 4:18) Ohun kejì tó lè ràn wá lọ́wọ́ nìyẹn. A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé Jèhófà ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa ń ṣiṣẹ́ kára, . . . a sì ń tiraka, nítorí tí a ti gbé ìrètí wa lé Ọlọ́run alààyè.” (1 Tímótì 4:10) Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni a gba ìrètí Kristẹni gbọ́, gbogbo ìgbésí ayé wa látòkè délẹ̀ yóò fi ìgbàgbọ́ wa hàn, gẹ́gẹ́ bó ti rí nínú ọ̀ràn Ábúráhámù.
Bíbá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀
10. Irú àdúrà wo ni yóò fún ìgbàgbọ́ wa lókun?
10 Ábúráhámù bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, èyí sì ni ohun kẹta tó fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun. Lónìí, àwa pẹ̀lú lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀, nípa lílo àǹfààní àdúrà nípasẹ̀ Jésù Kristi. (Jòhánù 14:6; Éfésù 6:18) Lẹ́yìn tí Jésù ṣe àkàwé tó fi ìjẹ́pàtàkì gbígbàdúrà nígbà gbogbo hàn, ló wá béèrè pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?” (Lúùkù 18:8) Àdúrà tí ń gbé ìgbàgbọ́ ró yàtọ̀ sí àdúrà oréfèé tàbí èyí táa ti há sórí. Ó jẹ́ àdúrà tó nítumọ̀ jíjinlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àdúrà àtọkànwá ṣe pàtàkì nígbà táa bá ní àwọn ìpinnu pàtàkì láti ṣe tàbí nígbà tí ìdààmú ọkàn bá dé bá wa.—Lúùkù 6:12, 13; 22:41-44.
11. (a) Báwo ni a ṣe fún Ábúráhámù lókun nígbà tí ó sọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀ fún Ọlọ́run? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ábúráhámù?
11 Nígbà tí Ábúráhámù ń darúgbó lọ, tí Jèhófà kò sì tíì fún un ní irú-ọmọ tó ṣèlérí, ó bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa àníyàn ọkàn rẹ̀. Jèhófà fi í lọ́kàn balẹ̀. Kí ló wá yọrí sí? Ábúráhámù “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà; òun sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á sí òdodo fún un.” Lẹ́yìn náà, Jèhófà fún un ní àmì kan kó lè dá a lójú pé òun yóò mú ọ̀rọ̀ òun ṣẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 15:1-18) Báa bá sọ gbogbo ohun tí ń bẹ lọ́kàn wa fún Jèhófà nínú àdúrà, táa tẹ́wọ́ gba àwọn ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, táa sì ṣègbọràn sí i pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún, nígbà náà, Jèhófà yóò fún ìgbàgbọ́ wa lókun.—Mátíù 21:22; Júúdà 20, 21.
12, 13. (a) Báwo ni a ṣe bù kún Ábúráhámù nígbà tó tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà? (b) Irú àwọn ìrírí wo ló lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun?
12 Ohun kẹrin tó fún ìgbàgbọ́ Ábúráhámù lókun ni ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ṣe fún un nígbà tó tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Nígbà tí Ábúráhámù lọ gba Lọ́ọ̀tì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọba tó gbé sùnmọ̀mí wá, Jèhófà jẹ́ kí ó ṣẹ́gun wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 14:16, 20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù gbé gẹ́gẹ́ bí àtìpó ní ilẹ̀ tí irú-ọmọ rẹ̀ yóò jogún, Jèhófà bù kún ún nípa ti ara. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 14:21-23.) Jèhófà darí ìsapá ìránṣẹ́ Ábúráhámù láti wá aya tó yẹ Ísákì. (Jẹ́nẹ́sísì 24:10-27) Àní, Jèhófà “bù kún Ábúráhámù nínú ohun gbogbo.” (Jẹ́nẹ́sísì 24:1) Èyí mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára gan-an, ó sì tún mú kí ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run túbọ̀ di tímọ́tímọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí Jèhófà fi pè é ní “ọ̀rẹ́ mi.”—Aísáyà 41:8; Jákọ́bù 2:23.
13 Àwa pẹ̀lú lónìí ha lè ní irú ìgbàgbọ́ lílágbára bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí Ábúráhámù, bí a bá dán Jèhófà wò nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀, òun yóò bú kún wa pẹ̀lú, ìyẹn yóò sì fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Bí àpẹẹrẹ, wíwo Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdún 1998 gààràgà fi hàn pé a bù kún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ́nà àgbàyanu nígbà tí wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ láti wàásù ìhìn rere.—Máàkù 13:10.
Àkọsílẹ̀ Tí Ń Fi Ìgbàgbọ́ Hàn Lónìí
14. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún ìgbétáásì Ìròyìn Ìjọba No. 35?
14 Ní October 1997, ìgbétáásì yíká ayé tí a ṣe nípa Ìròyìn Ìjọba No. 35 kẹ́sẹ járí lọ́nà kíkọyọyọ, ọpẹ́lọpẹ́ ìtara tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí fi hàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Àpẹẹrẹ kan ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Gánà. Nǹkan bí mílíọ̀nù méjì àti ààbọ̀ ẹ̀dà ni a pín ní èdè mẹ́rin, ìyọrísí rẹ̀ ni pé, nǹkan bí ẹgbàá [2,000] èèyàn ń rọ̀ wá láti wá máa bá àwọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní Kípírọ́sì, Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n ń pín Ìròyìn Ìjọba fura pé àlùfáà kan ń tẹ̀ lé wọn. Nígbà tó ṣe, wọ́n fi ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba lọ̀ ọ́. Àmọ́, ó ti gba ẹ̀dà kan tẹ́lẹ̀, ó wí pé: “Ọ̀rọ̀ tí ń bẹ nínú rẹ̀ wú mi lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí inú mi fi dùn láti kí àwọn tó ṣe é jáde pé, wọ́n kú iṣẹ́ o.” Ní Denmark, a pín mílíọ̀nù kan ààbọ̀ ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba, àbájáde rẹ̀ sí dára. Obìnrin tó jẹ́ alukoro ilé iṣẹ́ kan níbẹ̀ wí pé: “Kò sẹ́ni tí ọ̀rọ̀ inú àṣàrò kúkúrú náà kò kàn. Ó rọrùn láti lóye, ó ń ru ìtara ẹni sókè, ó sì ń fúnni ní ẹ̀mí láti fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Ó sọjú abẹ níkòó!”
15. Àwọn ìrírí wo ló fi hàn pé Jèhófà bù kún ìsapá náà láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi gbogbo?
15 Ní ọdún 1998, a sapá láti wàásù fún àwọn ènìyàn, kì í ṣe ní ilé wọn nìkan, ṣùgbọ́n, ní ibi gbogbo. Ní ilẹ̀ Côte d’Ivoire, tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì bẹ èjìlélógún lé ní ọ̀ọ́dúnrún [322] ọkọ̀ òkun wò ní etíkun. Wọ́n fi ìwé ńlá ẹ̀tàdínláàádọ́ta lé ní igba [247], ìwé ìròyìn ẹgbàá kan àti ọ̀rìnlénígba-lé-mẹ́rin [2,284], ìwé pẹlẹbẹ ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta [500], àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àṣàrò kúkúrú síta, wọ́n sì tún fún àwọn awakọ̀ òkun ní fídíò tí wọ́n lè máa wò lẹ́nu irin àjò wọn. Ní Kánádà, Ẹlẹ́rìí kan lọ sí ilé ìtọ́kọ̀ṣe. Ẹni tí ó ni ilé iṣẹ́ náà nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, arákùnrin náà sì wà níbẹ̀ fún wákàtí mẹ́rin àti ààbọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò tí ó lò gan-an lápapọ̀ jẹ́ nǹkan bí wákàtí kan nítorí àwọn oníbàárà tí wọ́n ń já lu ọ̀rọ̀ wọn. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ kan tí yóò máa bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́wàá alẹ́. Nígbà mìíràn ṣá o, ó máa ń di ọ̀gànjọ́ òru kò tó bẹ̀rẹ̀, ó sì máa ń tó aago méjì ìdájí kó tó parí. Ètò náà peni níjà lóòótọ́, àmọ́ nǹkan ṣẹnuure níbẹ̀. Ọkùnrin náà pinnu láti máa ti ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ lọ́jọ́ Sunday, kò bàa lè máa wá sí ìpàdé. Kò sì pẹ́ tí òun pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ fi ń tẹ̀ síwájú dáradára.
16. Àwọn ìrírí wo ló fi hàn pé ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè àti ìwé ńlá náà, Ìmọ̀ jẹ́ irinṣẹ́ lílágbára nínú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni?
16 Ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? àti ìwé ńlá Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ṣì jẹ́ irin iṣẹ́ lílágbára nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni. Ní Ítálì, obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan tí ń dúró de bọ́ọ̀sì tẹ́wọ́ gba ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba. Lọ́jọ́ kejì, wọ́n tún dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè. Ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n máa ń lo ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀ ní ibi ìdúró de ọkọ̀. Lẹ́yìn oṣù kan ààbọ̀, ó pinnu láti fi ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé sílẹ̀, kí ó sì padà sí ìlú rẹ̀ ní Guatemala, kí ó lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ. Ní Màláwì, inú bí obìnrin kan tí kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lobina, nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Síbẹ̀, àwọn ọmọbìnrin náà ṣàjọpín òtítọ́ Bíbélì pẹ̀lú màmá wọn nígbà tí wọ́n bá lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ní June 1997, Lobina rí ìwé Ìmọ̀, gbólóhùn náà, “Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ,” sì fà á mọ́ra. Ní oṣù July, ó gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní August, ó lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè, ó sì fetí sílẹ̀ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látòkè délẹ̀. Nígbà tí oṣù náà yóò fi parí, ó ti fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, ó sì ti tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi. Oṣù November 1997 ló ṣe ìrìbọmi.
17, 18. Báwo ni àwọn fídíò Society ti ṣe wúlò nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti “rí” àwọn nǹkan tẹ̀mí?
17 Fídíò Society ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti “rí” nǹkan tẹ̀mí. Ní ilẹ̀ Mauritius, ọkùnrin kan fi ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ìyapa tó wà níbẹ̀. Míṣọ́nnárì kan fi ìṣọ̀kan tó wà láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà hàn án, nípa lílo fídíò náà, United by Divine Teaching. Ó wú ọkùnrin náà lórí, ó wí pé: “Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń gbádùn Párádísè ní tiyín!” Ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin kan ní Japan fi fídíò náà, Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name, han ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, ìyẹn sì sún un láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Lẹ́yìn wíwo fídíò United by Divine Teaching, ó fẹ́ di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀wọ́ fídíò mẹ́ta tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, The Bible—A Book of Fact and Prophecy, ràn án lọ́wọ́ láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Níkẹyìn, fídíò Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault jẹ́ kí ó rí i pé Jèhófà máa ń fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ lókun láti lè fara da àtakò Sátánì. Ọkùnrin ọ̀hún ṣèrìbọmi ní October 1997.
18 Díẹ̀ péré nínú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìrírí táa gbádùn nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá nìyí. Wọ́n fi hàn pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbàgbọ́ tí ń ṣiṣẹ́, àti pé Jèhófà ń fún ìgbàgbọ́ yẹn lókun nípa bíbùkún ìgbòkègbodò wọn.—Jákọ́bù 2:17.
Ní Ìgbàgbọ́ Lónìí
19. (a) Báwo ni a ṣe wà ní ipò tó sàn ju ti Ábúráhámù lọ? (b) Àwọn mélòó ló pé jọ ní ọdún tó kọjá láti ṣayẹyẹ ikú ìrúbọ tí Jésù kú? (d) Àwọn orílẹ̀-èdè wo ni wọ́n fakọyọ ní ti iye àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí wọn lọ́dún tó kọjá? (Wo ṣáàtì lójú ìwé 12 sí 15.)
19 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni ipò àwa tí a wà lónìí fi sàn ju ti Ábúráhámù lọ. A mọ̀ pé Jèhófà mú gbogbo ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ. Àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù jogún ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè ńlá. (1 Àwọn Ọba 4:20; Hébérù 11:12) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní nǹkan bí ẹgbàá dín mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [1,971] ọdún lẹ́yìn tí Ábúráhámù fi Háránì sílẹ̀, Jésù, àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kan, ṣe ìbatisí nínú odò nípasẹ̀ Jòhánù Oníbatisí, Jèhófà alára sì tún fi ẹ̀mí mímọ́ batisí rẹ̀, kí ó lè di Mèsáyà, tí í ṣe Irú-Ọmọ Ábúráhámù nípa tẹ̀mí lọ́nà kíkún. (Mátíù 3:16, 17; Gálátíà 3:16) Ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà fún àwọn tí yóò lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lè bù kún ara wọn nísinsìnyí nípasẹ̀ rẹ̀. Lọ́dún tó kọjá, 13,896,312 ènìyàn ló pé jọ ní Nísàn 14 láti ṣayẹyẹ ìfẹ́ àgbàyanu yìí. Èyí mà dá Jèhófà láre o, Ọba Awímáyẹhùn!
20, 21. Báwo ni àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe bù kún ara wọn nípasẹ̀ Irú-Ọmọ Ábúráhámù ní ọ̀rúndún kìíní, báwo sì ni wọ́n ṣe ń bù kún ara wọn lónìí?
20 Ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè—bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì nípa ti ara—lo ìgbàgbọ́ nínú Irú-Ọmọ Ábúráhámù, wọ́n sì di ọmọ Ọlọ́run tí a fi òróró yàn, mẹ́ńbà “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tuntun, nípa tẹ̀mí. (Gálátíà 3:26-29; 6:16; Ìṣe 3:25, 26) Ìrètí wọn nípa ìyè àìleèkú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí ní ọ̀run láti jẹ́ ajùmọ̀ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọ́run dá wọn lójú hán-ún hán-ún. Kìkì àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni a óò bù kún lọ́nà yìí, díẹ̀ lára wọn ló ṣẹ́kù báyìí. (Ìṣípayá 5:9, 10; 7:4) Lọ́dún tó kọjá, 8,756 fẹ̀rí hàn pé àwọn gbà gbọ́ pé àwọn wà lára iye yẹn nípa jíjẹ àti mímu nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ, nígbà ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí.
21 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ló jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ìṣípayá 7:9-17. Nítorí pé wọ́n bù kún ara wọn nípasẹ̀ Jésù, wọ́n ní ìrètí ìyè ayérayé lórí párádísè ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 21:3-5) Àwọn 5,888,650 tí wọ́n nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún 1998 jẹ́ ẹ̀rí pé, ogunlọ́gọ̀ “ńlá” ni wọ́n lóòótọ́. Ó múni lọ́kàn yọ̀ gan-an ní pàtàkì láti rí i pé fún ìgbà àkọ́kọ́, ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti Ukraine ròyìn iye akéde tó ju 100,000. Èyí tó tún pabanbarì ni ìròyìn láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà—1,040,283 akéde lóṣù August! Orílẹ̀-èdè mẹ́ta péré nìyẹn nínú orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlógún tó ròyìn akéde tó lé ní 100,000 lọ́dún tó kọjá.
Ìrètí Tí Yóò Nímùúṣẹ Láìpẹ́
22, 23. (a) Èé ṣe táa fi ní láti fìdí ọkàn-àyà wa múlẹ̀ gbọn-in lónìí? (b) Báwo ni a ṣe lè dà bí Ábúráhámù, tí a kò ní dà bí àwọn aláìnígbàgbọ́ tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn?
22 A rán àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí létí nípa bí a ti rìn jìnnà tó nínú ìmúṣẹ àwọn ìlérí Jèhófà. Ní ọdún 1914, a gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀ wíwàníhìn-ín rẹ̀ nínú agbára Ìjọba. (Mátíù 24:3; Ìṣípayá 11:15) Ní tòótọ́, Irú-Ọmọ Ábúráhámù ti ń ṣàkóso nísinsìnyí ní ọ̀run! Jákọ́bù sọ fún àwọn Kristẹni ọjọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ mú sùúrù; ẹ fìdí ọkàn-àyà yín múlẹ̀ gbọn-in, nítorí wíwàníhìn-ín Olúwa ti sún mọ́lé.” (Jákọ́bù 5:8.) A dúpẹ́ pé wíwàníhìn-ín náà ti ní ìmúṣẹ! Ẹ ò rí i pé a ní ìdí púpọ̀ láti fìdí ọkàn-àyà wa múlẹ̀ gbọn-in!
23 Ǹjẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé àti àdúrà tí ó nítumọ̀ mú kí ìgbọ́kànlé wa nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run máa dọ̀tun nígbà gbogbo. Ǹjẹ́ kí a má ṣe dẹ́kun gbígbádùn ìbùkún Jèhófà bí a ti ń ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, a óò dà bí Ábúráhámù, kì í ṣe bí àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn di ahẹrẹpẹ, tí ìgbàgbọ́ wọn sì kú, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ. Ohunkóhun kò gbọ́dọ̀ yà wá kúrò nínú ìgbàgbọ́ mímọ́ wa. (Júúdà 20) Àdúrà wa ni pé, kó rí bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 1999, kó sì máa rí bẹ́ẹ̀ lọ fáàbàdà.
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
◻ Báwo ni a ṣe lè fetí sí Ọlọ́run lónìí?
◻ Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú gbígbàdúrà tó nítumọ̀ sí Ọlọ́run?
◻ Bí a bá ṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà Jèhófà, báwo ni a óò ṣe fún ìgbàgbọ́ wa lókun?
◻ Àwọn apá wo nínú ìròyìn ọdọọdún (ojú ìwé 12 sí 15) ló dùn mọ́ ọ jù lọ?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 12-15]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1998 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Báa bá ń fetí sí Ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìgbọ́kànlé wa nínú ìlérí rẹ̀ yóò máa dọ̀tun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
A ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun nígbà táa bá ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà