Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn?
“Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?”—JÓÒBÙ 14:14.
1, 2. Báwo ni ọ̀pọ̀ ṣe ń wá ìtùnú nígbà tí ikú bá mú ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ràn lọ?
NÍNÚ ilé kan táa ti ń múra fún òkú kí a tó sin ín, ní New York City, tẹbí tọ̀rẹ́ ń fi ìparọ́rọ́ tò minimini kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ pósí kan tó wà ní ṣíṣí sílẹ̀, tí òkú ọmọdékùnrin ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún wà nínú rẹ̀, ẹni tí àrùn jẹjẹrẹ ti mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ ní rèwerèwe. Ìyá ọmọdékùnrin náà, tí ìbànújẹ́ ti bá, ń fi tomijétomijé sọ ní àsọtúnsọ pé: “Inú Tommy a túbọ̀ dùn báyìí. Ṣe ni Ọlọ́run ń fẹ́ kí Tommy wà pẹ̀lú òun ní ọ̀run.” Ohun tí wọ́n ti fi kọ́ ọ nìyẹn, ohun tó sì gbàgbọ́ nìyẹn.
2 Ní Jamnagar, ní Íńdíà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá kìlómítà síhìn-ín, èyí ẹ̀gbọ́n pátápátá lára àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tí baba wọn bí, ń fi ògùṣọ̀ tanná ran àwọn ìtì igi tó wà lórí ibi tí a ti ń dáná sun òkú, níbi táa tẹ́ baba wọn tó ti dolóògbé sí. Bí iná náà ti ta pàrà, bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà Híńdù kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣàdúrà pé: “Ǹjẹ́ kí ọkàn tí kì í kú láé máa bá ìsapá rẹ̀ nìṣó láti di ọ̀kan náà pẹ̀lú ẹni atóbijù.”
3. Àwọn ìbéèrè wo làwọn èèyàn ti ń ronú lé lórí fún ọ̀pọ̀ ọdún?
3 Kò sí àní-àní pé kò sẹ́ni tí ikú kò lè pa. (Róòmù 5:12) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara, a lè máa ṣe kàyéfì pé, ṣé ikú náà lòpin gbogbo ìrìn àjò ẹ̀dá. Nígbà tó ń ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe ṣètò ìyípoyípo ìwàláàyè àwọn irúgbìn, Jóòbù, olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run nígbàanì, ṣàkíyèsí pé: “Ìrètí wà fún igi pàápàá. Bí a bá gé e lulẹ̀, àní yóò tún hù, ẹ̀ka igi rẹ̀ kì yóò sì kásẹ̀ nílẹ̀.” Hẹẹ, èèyàn wá ńkọ́? Jóòbù béèrè pe: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” (Jóòbù 14:7, 14) Jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn ènìyàn ní onírúurú àwùjọ ti ronú lórí ìbéèrè náà pé: Ìwàláàyè ha wà lẹ́yìn ikú bí? Bí ó bá sì wà, irú ìwàláàyè wo? Ní àbárèbábọ̀ rẹ̀, kí làwọn èèyàn wá gbàgbọ́? Èé sì ti ṣe?
Ìdáhùn Jáǹtìrẹrẹ, Kókó Ọ̀rọ̀ Kan Náà
4. Kí ni àwọn ènìyàn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbà gbọ́ nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú?
4 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ afẹnujẹ́ Kristẹni gbà gbọ́ pé lẹ́yìn ikú, ọ̀run rere tàbí ọ̀run àpáàdì ni èèyàn ń lọ. Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ní tiwọn nígbàgbọ́ nínú àtúnwáyé. Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ ti ẹ̀sìn Ìsìláàmù, ọjọ́ ìdájọ́ yóò wà lẹ́yìn ikú, nígbà tí Ọlọ́un-Ọba yóò ṣàgbéyẹ̀wò ìgbésí ayé olúkúlùkù, tí yóò sì yan onítọ̀hún sí àlùjánnà tàbí sínú iná jáànámọ̀. Ní àwọn ilẹ̀ kan, ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nípa àwọn òkú jẹ́ àyípọ̀ àṣà ìbílẹ̀ àti ti àwọn afẹnujẹ́ Kristẹni, àyípọ̀ tí kò yẹ kó wáyé. Fún àpẹẹrẹ, ní Sri Lanka, ṣe ni àwọn ẹlẹ́sìn Búdà àti ti Kátólíìkì máa ń ṣí ilẹ̀kùn àti fèrèsé wọn sílẹ̀ gbayawu nígbà tí ẹnì kan bá kú lágboolé wọn, wọn a kọ ẹsẹ̀ òkú tí wọ́n tẹ́ sínú pósí náà sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé ṣíṣe báyìí yóò mú kó rọrùn fún ẹ̀mí, tàbí ọkàn ẹni tó dolóògbé náà láti jáde kúrò nínú ilé náà. Ó tún wọ́pọ̀ láàárín àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáńtì ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà pé kí a fi nǹkan bo dígí nígbà tí ẹnì kan bá kú, kí ẹnikẹ́ni má bàa wo dígí náà, kí ó sì lọ rí àfarahàn ẹni tó ti kú. Tó bá wá di ogójì ọjọ́ lẹ́yìn tí ẹni náà ti kú, tẹbí tọ̀rẹ́ yóò wá ṣayẹyẹ ìgòkè re ọ̀run ọkàn ẹni tó kú náà.
5. Kí ni olórí ìgbàgbọ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀sìn fohùn ṣọ̀kan lé lórí?
5 Láìka ìyàtọ̀ yìí sí, ó dà bí ẹni pé, ó kéré tán, èrò kan wà tó bára mu nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀sìn. Wọ́n gbà gbọ́ pé ohun kan nínú ènìyàn—à báà pè é ní ọkàn, ẹ̀mí, tàbí òjìji ènìyàn—jẹ́ ohun tí kò leè kú, ó sì ń bá a lọ láti wà láàyè lẹ́yìn tí ara bá ti kú. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀sìn àti ẹ̀ya ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ló gba àìleèkú ọkàn gbọ́. Ìgbàgbọ́ yìí tún jẹ́ ẹ̀kọ́ tí a fàṣẹ sí nínú ẹ̀sìn àwọn Júù. Òun gan-an ni ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àtúnwáyé nínú ẹ̀sìn àwọn Híńdù. Àwọn Mùsùlùmí gbà gbọ́ pé tí ara bá kú, ọkàn ṣì máa ń wà láàyè. Àwọn Atẹ̀lúdò ará Australia, àwọn abọmọlẹ̀ ní Áfíríkà, àwọn ẹlẹ́sìn Ṣintó, àti ti Búdà pàápàá, ẹṣin ọ̀rọ̀ kan náà yìí ni gbogbo wọn fi ń kọ́ni lóríṣiríṣi ọ̀nà.
6. Ojú wo ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan fi ń wo èrò pé ọkàn kì í kú?
6 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn kan wà tí wọ́n gbà gbọ́ pé tí ikú bá ti dé, ìwàláàyè dópin nìyẹn. Lójú tiwọn, èrò pé ọkàn kan tí ó dà bí òjìji, tí kò ní ara, ṣì máa ń wà láàyè ní ti ìmọ̀lára àti ti ìrònú, lóde ara, kò mọ́gbọ́n dání rárá ni. Miguel de Unamuno, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ní ọ̀rúndún ogún, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sípéènì, kọ̀wé pé: “Láti gba àìleèkú ọkàn gbọ́ ni láti fẹ́ kí ọkàn di ohun tí kò leè kú, ṣùgbọ́n láti fi tipátipá fẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò súnni débi pé a óò gbójú fo ìrònú tí ó bọ́gbọ́n mu dá, tí a óò sì hùwà òpònú.” Àwọn mìíràn tí wọ́n tún ní irú ìgbàgbọ́ yìí ni àwọn onírúurú ènìyàn bí àwọn gbajúgbajà ọlọ́gbọ́n èrò orí ìgbàanì, Aristotle àti Epicurus, oníṣègùn Hippocrates, ọlọ́gbọ́n èrò orí, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Scotland, David Hume, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Arébíà, Averroës, àti olórí ìjọba ilẹ̀ Íńdíà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbòmìnira, Jawaharlal Nehru.
7. Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo nípa ìgbàgbọ́ àìleèkú ni a gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò báyìí?
7 Níwọ̀n bí a ti dojú kọ irú àwọn èrò àti ìgbàgbọ́ tó takora wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ béèrè pé: Ṣé lóòótọ́ ni a ní ọkàn tí kò lè kú? Bó bá jẹ́ lóòótọ́ ni ọkàn ń kú, báwo wá ni irú ẹ̀kọ́ èké bẹ́ẹ̀ ṣe wá di apá pàtàkì nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn tó wà lóde òní? Ibo ni èrò náà ti wá? Ó ṣe pàtàkì pé kí a rí ìdáhùn tó tọ̀nà, tó sì tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nítorí ọjọ́ ọ̀la wa rọ̀ mọ́ ọn. (1 Kọ́ríńtì 15:19) Ṣùgbọ́n, lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn ṣe bẹ̀rẹ̀.
Bí Ẹ̀kọ́ Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀
8. Ipa wo ni Socrates àti Plato kó nínú gbígbé èrò náà pé ọkàn kì í kú lárugẹ?
8 Àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì náà, Socrates àti Plato, tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n èrò orí ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa, ni a gbọ́ pé wọ́n wà lára àwọn tó kọ́kọ́ gbé èrò náà jáde pé, ènìyàn ní ọkàn kan tí kò lè kú. Ṣùgbọ́n, àwọn kọ́ ni wọ́n pilẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n tún èrò tí àwọn Gíríìkì ti gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ṣàlàyé mọ́ránmọ́rán, tí wọ́n sì yí i padà di ẹ̀kọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí, wọ́n sì tipa báyìí mú kí ó fa àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé mọ́ra, tí àwọn náà fi wá tẹ́wọ́ gbà á láti ìgbà ayé wọn títí di ìsinsìnyí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn Zoroastrian ti Páṣíà ìgbàanì àti àwọn ará Íjíbítì àtijọ́ pẹ̀lú nígbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, Ibo ni ẹ̀kọ́ yìí ti wá?
9. Kí ni orísun ipa ìdarí tó wọ́pọ̀ nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Íjíbítì, Páṣíà, àti Gíríìsì ìgbàanì?
9 Ìwé náà, The Religion of Babylonia and Assyria, sọ pé: “Ní ayé ìgbàanì, ẹ̀sìn àwọn ará Bábílónì nípa lórí àwọn ará Íjíbítì, Páṣíà, àti Gíríìsì.” Nípa ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn àwọn ará Íjíbítì, ìwé ọ̀hún ń bá àlàyé rẹ̀ lọ pé: “Nítorí àjọṣe tó wà láàárín Íjíbítì àti Bábílónì nígbà àtijọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn wàláà El-Amarna ṣe fi hàn, ó dájú pé àyè tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ ṣí sílẹ̀ fún ojú ìwòye àti àṣà àwọn ará Bábílónì láti wọnú ẹgbẹ́ awo àwọn ará Íjíbítì.”a Ọ̀pọ̀ ohun bẹ́ẹ̀ ni a lè sọ nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ará Páṣíà àti Gíríìkì ìjímìjí.
10. Ojú wo ni àwọn ará Bábílónì fi ń wo ìwàláàyè lẹ́yìn ikú?
10 Àmọ́ ṣá o, ṣé òótọ́ ni pé àwọn ará Bábílónì ìgbàanì nígbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn? Lórí kókó yìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Morris Jastrow Kékeré, ti Yunifásítì Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, kọ̀wé pé: “Àtàwọn èèyàn [Babiloníà] àti àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn, kò sí èyí tí ó retí pé kí ohun tí a bá ti mú wá sí ìyè di èyí tí a óò tún pa rẹ́ ráúráú. [Lójú tiwọn], ikú jẹ́ ọ̀nà àtiré kọjá sínú ayé mìíràn kan, tí ó sì jẹ́ pé ńṣe ni kíkọ̀ láti gbà pé àìleèkú wà [láyé táa wà yìí] kàn túbọ̀ ń mú un ṣe kedere pé dandan ni kí ìwàláàyè mìíràn wà lẹ́yìn ikú.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Bábílónì gbà gbọ́ pé irú ìwàláàyè kan, bákan ṣá, ń bá a lọ lẹ́yìn ikú. Wọ́n fi èyí hàn nípa sísin àwọn nǹkan èlò pọ̀ mọ́ àwọn òkú, kí wọ́n bàa lè lò wọ́n nígbà Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú.
11, 12. Lẹ́yìn Ìkún Omi, ibo ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ti pilẹ̀?
11 Ó ṣe kedere pé, ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ti wà tipẹ́, láti àkókò Bábílónì ìgbàanì. Ìyẹn ha ṣe pàtàkì bí? Ó ṣe pàtàkì gan-an, torí pé gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, Nímírọ́dù, ọmọ ọmọ Nóà, ló tẹ ìlú Bábélì, tàbí Bábílónì, dó. Lẹ́yìn Ìkún Omi tó kárí ayé ní ọjọ́ Nóà, èdè kan àti ẹ̀sìn kan péré ni ó wà nígbà náà. Kì í ṣe pé Nímírọ́dù “[lòdì] sí Jèhófà” nìkan ni, ṣùgbọ́n òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tún fẹ́ “ṣe orúkọ lílókìkí” fún ara wọn. Nípa títẹ ìlú náà dó àti kíkọ́ ilé gogoro kan síbẹ̀, Nímírọ́dù bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn mìíràn.—Jẹ́nẹ́sísì 10:1, 6, 8-10; 11:1-4.
12 Ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ sọ pé ikú gbígbóná ni Nímírọ́dù kú. Á sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé, lẹ́yìn ikú rẹ̀, ṣe ni àwọn ará Bábílónì máa gbé Nímírọ́dù gẹ̀gẹ̀, tí wọ́n á tilẹ̀ júbà rẹ̀ nítorí pé òun ló tẹ ìlú wọn dó, òun ló kọ́ ọ, òun ló sì kọ́kọ́ jọba níbẹ̀. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọlọ́run náà, Marduk (Méródákì), ni a kà sí ẹni tí ó tẹ Bábílónì dó, tí ó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọba Bábílónì ni a ń pè ní Méródákì, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti dábàá pé Nímírọ́dù tí wọ́n sọ di àkúnlẹ̀bọ náà ló ń jẹ́ Marduk. (2 Àwọn Ọba 25:27; Aísáyà 39:1; Jeremáyà 50:2) Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé èrò náà pé ọkàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú ti wà lóde, ó kéré tán nígbà ikú Nímírọ́dù. Bí ó ti wù kí ó rí, àkọsílẹ̀ ìtàn fi hàn pé lẹ́yìn Ìkún Omi, Bábélì, tàbí Bábílónì, ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ti bẹ̀rẹ̀.
13. Báwo ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ṣe tàn dé gbogbo ilẹ̀ ayé, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
13 Ní àfikún sí i, Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run kò jẹ́ kí ìsapá àwọn tí ń kọ́ ilé gogoro ní Bábélì kẹ́sẹ járí, nípa dída èdè wọn rú. Wọn kò gbédè ara wọn mọ́, ni wọ́n bá fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, ni a bá tú wọn ká “kúrò níbẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:5-9) Àmọ́ ó yẹ ká rántí pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti yí èdè àwọn tó fẹ́ kọ́ ilé gogoro padà, ìrònú àti èròǹgbà wọn kò yí padà. Nítorí èyí, ibikíbi tí wọ́n ń lọ, ni ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn wọn ń bá wọn lọ. Báyìí ni àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Bábílónì—títí kan ti àìleèkú ọkàn—tàn ká ilẹ̀ ayé, tí ó sì di ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀sìn pàtàkì-pàtàkì lágbàáyé. Báyìí ni ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ṣe bẹ̀rẹ̀, èyí tí Bíbélì ṣàpèjúwe lọ́nà yíyẹ gẹ́gẹ́ bíi “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 17:5.
Ilẹ̀ Ọba Ìsìn Èké Àgbáyé Tàn Dé Apá Ìlà Oòrùn Ayé
14. Báwo ni àwọn ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Bábílónì ṣe tàn dé àgbègbè Íńdíà?
14 Àwọn òpìtàn kan sọ pé ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún [3,500] sẹ́yìn, ṣíṣí tí àwọn èèyàn ń ṣí kiri mú kí àwọn ará Yúróòpù aláwọ̀ funfun ṣí wá láti ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá sí Àfonífojì Indus, tó wà ní ilẹ̀ Pakistan àti Íńdíà gan-an báyìí. Láti ibẹ̀ wọ́n tàn kálẹ̀ dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Odò Ganges, títí dé Íńdíà. Àwọn ògbógi kan sọ pé àwọn aṣíkiri náà gbé èrò ẹ̀sìn wọn ka ẹ̀kọ́ àwọn ará Iran àti Bábílónì ìgbàanì. Àwọn èrò ẹ̀sìn wọ̀nyí ló sì wá di gbòǹgbò ẹ̀sìn Híńdù.
15. Báwo ni èrò àìleèkú ọkàn ṣe wá nípa lórí ẹ̀sìn Híńdù òde òní?
15 Ní Íńdíà, wọ́n gbé èrò àìleèkú ọkàn tiwọn gba ọ̀nà ẹ̀kọ́ àtúnwáyé. Bí àwọn amòye inú ẹ̀sìn Híńdù ṣe ń ṣakitiyan láti wá ojútùú sí ìṣòro ìwà ibi àti ìjìyà kárí ayé tí ń bá ènìyàn fínra, ni wọ́n bá gbé ohun tí wọ́n pè ní òfin Kámà kalẹ̀, òfin àṣesílẹ̀ làbọ̀wábá. Pípa tí wọ́n pa òfin yìí pọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ àìleèkú ọkàn ló sún wọn dórí ẹ̀kọ́ àtúnwáyé, èyí tó kọ́ni pé gbogbo ìwà rere àti ìwà láabi tí ẹnì kan bá hù ní ayé eléyìí ni a óò san ẹ̀san rẹ̀ fún un tàbí jẹ ẹ́ níyà lé lórí ní ayé tó ń bọ̀. Wọ́n sọ pé góńgó àwọn olóòótọ́ ni láti wá ìtúsílẹ̀ kúrò nínú àyípo àbítúnbí àti láti wà ní ipò ìdẹ̀ra, tàbí Nirvana. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá, bí ẹ̀sìn Híńdù ṣe ń tàn kálẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀kọ́ àtúnwáyé ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀kọ́ yìí sì ti wá di igi lẹ́yìn ọgbà fún ẹ̀sìn Híńdù òde òní.
16. Ìgbàgbọ́ wo nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú ló wá di èròǹgbà ẹ̀sìn àti àṣà tó gbòde kan láàárín ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ń gbé ni Ìlà Oòrùn Éṣíà?
16 Ara ẹ̀sìn Híńdù ni àwọn ẹ̀sìn mìíràn, bí ẹ̀sìn Búdà, Jéìnì àti ti Síìkì ti jáde. Àwọn náà rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ àtúnwáyé. Síwájú sí i, bí ẹ̀sìn Búdà ṣe wọ ibi tí ó pọ̀ jù nínú ilẹ̀ Ìlà-Oòrùn Éṣíà—China, Korea, Japan, àti ibòmíràn—ó nípa tí ó bùáyà lórí àṣà ìbílẹ̀ àti ẹ̀sìn gbogbo àgbègbè náà. Èyí ló bí àwọn ẹ̀sìn alámùúlùmálà ìgbàgbọ́, tí ó pa díẹ̀ nínú ẹ̀sìn Búdà, díẹ̀ nínú ìbẹ́mìílò, àti díẹ̀ nínú ìjọsìn àwọn baba ńlá pọ̀ mọ́ra. Àwọn tó jẹ́ ògúnnágbòǹgbò lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀sìn Taois, ẹ̀sìn Confucius, àti ti Ṣintó. Nípa báyìí, ìgbàgbọ́ pé ìwàláàyè ń bá a nìṣó lẹ́yìn tí ara ìyára bá ti kú wá di ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn àti àṣà tó gbòde kan láàárín ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ń gbé ní àgbègbè yẹn.
Ẹ̀sìn Àwọn Júù, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti Ìsìláàmù Ńkọ́?
17. Kí ni ìgbàgbọ́ àwọn Júù ìgbàanì nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú?
17 Kí ni àwọn ẹlẹ́sìn Júù, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti ti Ìsìláàmù gbà gbọ́ nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú? Nínú gbogbo ẹ̀sìn táa dárúkọ wọ̀nyí, ẹ̀sìn àwọn Júù ni àgbà gbogbo wọn. Nǹkan bí ẹgbàajì ọdún sẹ́yìn nígbà ayé Ábúráhámù ni ẹ̀sìn yẹn ti wà—tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí Socrates àti Plato tó gbé àbá èrò orí àìleèkú ọkàn kalẹ̀. Àjíǹde àwọn òkú ni àwọn Júù ìgbàanì gbà gbọ́, wọn kò nígbàgbọ́ nínú àìleèkú tí a dá mọ́ ènìyàn. (Mátíù 22:31, 32; Hébérù 11:19) Báwo wá ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ṣe wọnú ẹ̀sìn àwọn Júù? Ìtàn dáhùn rẹ̀.
18, 19. Báwo ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ṣe wọnú ẹ̀sìn àwọn Júù?
18 Ní ọdún 332 ṣááju Sànmánì Tiwa, Alẹkisáńdà Ńlá, ṣẹ́gun ilẹ̀ Àárín Gbùngbùn Ìlà-Oòrùn, títí kan Jerúsálẹ́mù. Bí àwọn arọ́pò Alẹkisáńdà ṣe ń bá ètò rẹ̀, ìyẹn ni sísọni di Hélénì nìṣó, yíyí àṣà ìbílẹ̀ méjì pọ̀—ti Gíríìkì àti ti Júù—ṣẹlẹ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn Júù di ògbógi nínú ìmọ̀ àwọn Gíríìkì, àwọn kan tilẹ̀ di onímọ̀ ọgbọ́n orí.
19 Ọ̀kan nínú irú àwọn Júù ọlọ́gbọ́n èrò orí bẹ́ẹ̀ ni Philo ti Alẹkisáńdíríà, tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Kò kóyán Plato kéré rárá, ó sì gbìyànjú láti fi ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì ṣàlàyé ẹ̀sìn àwọn Júù, ó sì tipa báyìí lànà sílẹ̀ fún àwọn Júù aláròjinlẹ̀ tó dìde lẹ́yìn náà. Èrò àwọn Gíríìkì tún nípa lórí ìwé náà, Talmud—àlàyé tí àwọn rábì kọ lórí àwọn òfin àtẹnudẹ́nu. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopædia Judaica, sọ pé: “Àwọn rábì tí ń kọ́ni ní Talmud nígbàgbọ́ pé ọkàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú.” Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ìwé idán àwọn Júù, bí ìwé Cabala, tilẹ̀ kúkú fi àtúnwáyé kọ́ni. Nítorí náà, ṣe ni èrò àìleèkú ọkàn ti inú ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì rá wọnú ẹ̀sìn àwọn Júù. Kí ni a wá lè sọ nípa bí ó ṣe wọnú Kirisẹ́ńdọ̀mù?
20, 21. (a) Ojú wo ni àwọn Kristẹni ìjímìjí fi wo èrò orí Plato, tàbí ti Gíríìkì? (b) Kí ló fa yíyí èrò Plato pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ Kristẹni?
20 Ojúlówó ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi. Ohun tí Miguel de Unamuno, táa fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan kọ nípa Jésù ni pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù ṣe mọ̀ ọ́n sí, àjíǹde ara ìyára ni òun gbà gbọ́ ní tirẹ̀, kì í ṣe àìleèkú ọkàn, gẹ́gẹ́ bí Plato [tó jẹ́ Gíríìkì] ṣe fi kọ́ni.” Ó kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àìleèkú ọkàn . . . jẹ́ ẹ̀kọ́ èrò orí àwọn abọ̀rìṣà.” Bí ọ̀ràn ṣe wá rí yìí, a wá mọ ìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ fún àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní nípa “ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.
21 Ìgbà wo ni “ẹ̀kọ́ èrò orí àwọn abọ̀rìṣà” yìí rá wọnú Kirisẹ́ńdọ̀mù, báwo ló sì ṣe wọ̀ ọ́? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Encyclopædia Britannica, sọ pé: “Láti agbedeméjì ọ̀rúndún kejì Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa, àwọn Kristẹni tó jẹ́ pé wọ́n ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì máa ń fẹ́ fi àwọn gbólóhùn èrò orí náà ṣàlàyé ìgbàgbọ́ tiwọn láti lè gbé ìmọ̀ wọn yọ àti láti lè yí àwọn abọ̀rìṣà tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé lọ́kàn padà. Ọgbọ́n èrò orí tí ó yá wọn lára jù lọ láti lò ni ti Plato.” Àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí ìjímìjí méjì bẹ́ẹ̀ tí ó nípa púpọ̀ gidigidi lórí ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù ni Origen ti Alẹkisáńdíríà àti Augustine ti Hippo. Èrò Plato nípa jíjinlẹ̀ lórí àwọn méjèèjì, àwọn ló sì ń bẹ nídìí yíyí tí a yí àwọn èrò náà pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni.
22. Báwo ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ṣe wá di apá pàtàkì nínú ẹ̀sìn Ìsìláàmù?
22 Nígbà tí ó jẹ́ pé ipa tí Plato ní lórí ẹ̀sìn àwọn Júù àti Kirisẹ́ńdọ̀mù ló mú èrò àìleèkú ọkàn dé inú ẹ̀sìn wọ̀nyí, ní ti ẹ̀sìn Ìsìláàmù, láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni wọ́n ti gbé èrò náà kalẹ̀ sínú rẹ̀. Kùránì, ìwé mímọ́ ẹ̀sìn Ìsìláàmù, fi kọ́ni pé ènìyàn ní ọkàn tí ó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú. Ó sọ pé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí i níkẹyìn ni pé, yóò wà ní àlùjánnà ní ọ̀run tàbí yóò máa joró nínú iná jáànámọ̀. Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn Lárúbáwá tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kò gbìyànjú láti da ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Ìsìláàmù pọ̀ mọ́ ti ọgbọ́n orí ti Gíríìkì. Ká sòótọ́, iṣẹ́ Aristotle nípa lórí ìgbésí ayé àwọn Lárúbáwá dé àyè kan. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn sì wà gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn Mùsùlùmí.
23. Àwọn ìbéèrè pípọndandan wo nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
23 Ó ṣe kedere pé, àwọn ẹ̀sìn káàkiri ayé ti gbé ọ̀wọ́ ìgbàgbọ́ nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú kalẹ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà tí ó tojú súni tìtorí èrò náà pé ọkàn jẹ́ àìleèkú. Bẹ́ẹ̀ ni, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ti nípa lórí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn, àní ó ti gbà wọ́n lọ́kàn, ó sì ti mú wọn lẹ́rú. Pẹ̀lú gbogbo èyí táa dojú kọ yìí, ó di dandan kí a béèrè pé: Ó ha ṣeé ṣe láti mọ òtítọ́ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú bí? Ìwàláàyè ha wà lẹ́yìn ikú bí? Kí ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀? Èyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a El-Amarna ni ibi tí àwókù ilú àwọn ará Íjíbítì náà, Akhetaton, wà, èyí tí a gbọ́ pé wọ́n kọ́ ní ọ̀rúndún kẹrìnlá ṣááju Sànmánì Tiwa.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Ẹṣin ọ̀rọ̀ kan náà wò ló wà nínú ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn tó pọ̀ jù lọ nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú?
◻ Báwo ni ìtàn àti Bíbélì ṣe tọ́ka sí i pé Bábílónì ìgbàanì ni ibi tí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ti pilẹ̀?
◻ Lọ́nà wo ni ìgbàgbọ́ àwọn ará Bábílónì nípa àìleèkú ọkàn gbà nípa lórí àwọn ẹ̀sìn Ìlà Oòrùn?
◻ Báwo ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ṣe rá wọnú ẹ̀sìn àwọn Júù, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti ti Ìsìláàmù?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
Ṣíṣẹ́gun tí Alẹkisáńdà Ńlá ṣẹ́gun yọrí sí yíyí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Gíríìkì pọ̀ mọ́ ti àwọn Júù
Augustine gbìyànjú láti da ọgbọ́n èrò orí Plato pọ̀ mọ́ ti ẹ̀sìn Kristẹni?
[Àwọn Credit Line]
Alẹkisáńdà: Musei Capitolini, Roma; Augustine: Láti inú ìwé náà, Great Men and Famous Women