Ta Ló Ń Darí Èrò Rẹ?
“ẸNÌ kankan kò lè máa pàṣẹ ohun tí màá fọkàn mi rò fún mi! Ẹnì kankan kò sì lè máa pàṣẹ ohun tí màá ṣe fún mi!” Sísọ irú ọ̀rọ̀ yìí ṣàkó, sábà máa ń túmọ̀ sí pé ohun tí o ń ṣe dá ẹ lójú hán-ún, ìpinnu tí o sì ṣe fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. Ṣé ìmọ̀lára rẹ nìyẹn? Òtítọ́ ni kẹ̀, ẹlòmíràn kọ́ ló yẹ kó máa ṣèpinnu fún ẹ. Ṣùgbọ́n ṣé ó wá bọ́gbọ́n mu kí o tètè kẹ̀yìn sí ìmọ̀ràn rere? Ṣé ìyẹn wá ni pé kò sẹ́ni kankan rárá tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu? Tilẹ̀ gbọ́ ná, ṣé ó dá ẹ lójú pé kò sẹ́ni kankan tó ń darí èrò rẹ, tó sì jẹ́ pé o kò mọ̀ rárá?
Fún àpẹẹrẹ, kí Ogun Àgbáyé Kejì tó jà, Joseph Goebbels, mínísítà tó ń bá Hitler gbékèé yíde, di gíwá àwọn ilé iṣẹ́ Germany tí ń ṣe sinimá. Èé ṣe? Nítorí ó mọ̀ pé tọ́wọ́ òun bá tẹ irinṣẹ́ tó lágbára gan-an yìí, ìyẹn lòun yóò máa fi “darí ìgbàgbọ́ àti ìwà àwọn ènìyàn.” (Propaganda and the German Cinema 1933-1945) Bóyá ìwọ mọ̀ nípa bó ṣe fọgbọ́n burúkú lo ọ̀nà yìí àti àwọn ọ̀nà mìíràn, tó yí àwọn ẹni ẹlẹ́ni lórí—àwọn ọmọlúwàbí, ọlọ́pọlọ pípé—tí wọ́n sì wá tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ ọgbọ́n orí Nazi láìwádìí rẹ̀ wò.
Táa bá ní ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ìmọ̀lára àti ojú ìwòye àwọn tí o ń fetí sí ló sábà máa ń pinnu bí o ṣe ń ronú àti bí o ṣe ń hùwà. A ò kúkú wá sọ pé èyí fi gbogbo ara burú o. Bó bá jẹ́ àwọn èèyàn tó ń ro tìrẹ ní rere—bí àwọn olùkọ́, ọ̀rẹ́, tàbí òbí—nígbà náà, wàá jàǹfààní gidi láti inú ìmọ̀ràn wọn. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá lọ jẹ́ àwọn aríre-báni-jẹ, tí àwọn alára ti ṣáko lọ, tàbí tí ìrònú wọn ti díbàjẹ́, àwọn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “àwọn tí ń tan èrò inú jẹ,” yáa ṣọ́ra o!—Títù 1:10; Diutarónómì 13:6-8.
Nípa báyìí, má dẹra nù, kí o wá máa ronú pé kò sẹ́ni tó lè nípa lórí rẹ láé. (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 10:12.) Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ó ti ń ṣẹlẹ̀—àní kí ó máa ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ ju bóo ṣe rò pé ó ń ṣẹlẹ̀—láìjẹ́ pé o fura rárá. Ẹ jẹ́ ká tibi pẹlẹbẹ mọ́ọ̀lẹ̀ jẹ, ká wo ohun tóo pinnu láti rà nígbà tóo bá lọ sọ́jà. Ṣé ìgbà gbogbo ló máa ń jẹ́ ìpinnu tìrẹ pọ́ńbélé, ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání? Ṣé kì í ṣe àwọn ẹlòmíràn, tí èèyàn kì í sábàá rí, ni wọ́n ń fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ yí ohun tó wà lọ́kàn ẹ padà ráúráú? Eric Clark, akọ̀ròyìn tí ń fọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò, gbà pé wọ́n máa ń nípa lórí ẹni. Ó sọ pé: “Bí àwọn ọlọ́jà ti ń polówó lọ́tùn-ún lósì, bẹ́ẹ̀ náà ni kò jẹ́ tuntun sí wa mọ́, ṣùgbọ́n ṣá o, ó dájú pé bẹ́ẹ̀ náà ni ipa tí wọ́n ń ní lórí wa ṣe pọ̀ tó.” Ó tún ròyìn pé, táa bá bi àwọn èèyàn léèrè pé báwo ni wọ́n rò pé ìpolówó ọjà ti gbéṣẹ́ tó, “ọ̀pọ̀ jù lọ ló gbà pé ó gbéṣẹ́ gan-an ni, ṣùgbọ́n wọn ò gbà pé ó gbéṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ àwọn.” Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ ronú pé gbogbo èèyàn ló wà nínú ewu, àfi àwọn nìkan. “Lójú tiwọn, àwọn nìkan ló bọ́.”—The Want Makers.
Sátánì Fẹ́ Mú Wa Bá Bátànì Tirẹ̀ Mu Kẹ̀?
Bóyá ìpolówó ọjà lójoojúmọ́ ń nípa lórí rẹ tàbí kò nípa lórí rẹ, lè máà ní àbájáde wíwúwo. Ṣùgbọ́n o, agbára mìíràn wà tó léwu burúkú. Bíbélì fi hàn kedere pé ọ̀gá ni Sátánì nídìí fífọgbọ́n tanni jẹ. (Ìṣípayá 12:9) Ọgbọ́n tó ń ta fẹ́ jọ èrò olùpolówó ọjà kan, tó sọ pé ọ̀nà méjì ló wà láti gbà nípa lórí àwọn oníbàárà—“nípa títàn wọ́n jẹ tàbí nípa fífọ̀rọ̀ dídùn yí wọn lérò padà.” Bí àwọn agbékèéyíde àti olùpolówó ọjà bá lè ta irú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ bẹ́ẹ̀ láti darí èrò rẹ, wá wo bí Sátánì yóò ti gbówọ́ tó ní títa irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀!—Jòhánù 8:44.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ èyí. Ominú kọ ọ́ pé àwọn kan lára àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ òun lè dẹra nù, kí Sátánì sì wá fi ẹ̀tàn yí wọn mọ́lẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ti sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́ kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 11:3) Má fi ìkìlọ̀ yìí ṣeré o. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o lè dà bí àwọn èèyàn tó gbà pé ìgbékèéyíde àti fífọ̀rọ̀ dídùn yíni lérò padà gbéṣẹ́—“ṣùgbọ́n [tí] wọn ò gbà pé ó gbéṣẹ́ dé ọ̀dọ̀ àwọn.” Ẹ̀rí tó ṣe kedere pé ìgbékèéyíde Sátánì gbéṣẹ́ wà yí wa ká, a lè rí ìwà òǹrorò, ìwà pálapàla, àti ìwà àgàbàgebè tó wọ́pọ̀ nínú ìran yìí.
Fún ìdí yìí, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” (Róòmù 12:2) Ọ̀gbẹ́ni olùtúmọ̀ Bíbélì kan tún ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sọ lọ́nà yìí: “Má ṣe jẹ́ kí ayé tó yí ẹ ká mú ẹ bá bátànì tirẹ̀ mu.” (Róòmù 12:2, Phillips) Sátánì yóò dá gbogbo àrà tó bá lè dá láti mú ẹ bá bátànì tirẹ̀ mu, gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò láyé àtijọ́ ti máa ń ṣu amọ̀ sínú bátànì kan kí ìkòkò náà lè rí bó ti fẹ́. Iṣẹ́ yẹn ni Sátánì ń fi ìṣèlú, iṣẹ́ ajé, ẹ̀sìn, àti eré ìtura ayé ṣe. Báwo tilẹ̀ ni agbára Sátánì ti rinlẹ̀ tó? Bó ṣe gbèèràn lọ́jọ́ àpọ́sítélì Jòhánù ló rí lónìí. Jòhánù sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19; tún wo 2 Kọ́ríńtì 4:4.) Bóo bá ń ṣiyèméjì nípa bí agbára Sátánì ti pọ̀ tó láti tan àwọn èèyàn jẹ, kí ó sì sọ ìrònú wọn dìbàjẹ́, rántí bó ṣe tan odindi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jẹ pátápátá, orílẹ̀-èdè tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 10:6-12) Ohun kan náà ha lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ bí? Ó lè ṣẹlẹ̀, bóo bá ṣí èrò inú rẹ sílẹ̀ fún agbára ẹ̀tàn Sátánì.
Mọ Ohun Tí Ń Lọ
Lápapọ̀, irú àwọn ẹ̀dá burúkú bẹ́ẹ̀ yóò nípa lórí rẹ kìkì bí o bá gbà wọ́n láyè. Nínú ìwé rẹ̀, The Hidden Persuaders, Vance Packard mẹ́nu kan gbólóhùn yìí: “A ṣì ní agbára tó pọ̀ láti já ara wa gbà lọ́wọ́ àwọn ayíniléròpadà wọnnì [tí a kò lè rí]: a lè yàn láti má kọbi ara sí ìyíniléròpadà wọn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo ipò, ọwọ́ wa ni yíyàn náà wà, kò sì sí bí wọ́n ṣe lè tètè rí wa mú, báa bá mọ ohun tí ń lọ.” Bákan náà ló rí tó bá dọ̀ràn ìgbékèéyíde àti ẹ̀tàn.
Àmọ́ ṣá o, láti “mọ ohun tí ń lọ,” o gbọ́dọ̀ ṣí èrò inú rẹ sílẹ̀, kí o sì fàyè gba àwọn agbára tó lè ní ipa rere lórí rẹ. Ọkàn rere, gẹ́gẹ́ bí ara tó le, nílò àwọn ohun aṣaralóore, bí yóò bá máa ṣiṣẹ́ dáadáa. (Òwe 5:1, 2) Àìsí ìsọfúnni léwu, gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni òdì ti léwu. Fún ìdí yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ ni pé ó yẹ kí o dáàbò bo èrò inú rẹ lọ́wọ́ àwọn èròǹgbà àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí ń kóni ṣìnà, síbẹ̀ kò tún wá yẹ kí o máa fojú ẹ̀gàn, ojú àbùkù, wo ìmọ̀ràn tàbí ìsọfúnni tí wọ́n bá fún ẹ.—1 Jòhánù 4:1.
Ìyíniléròpadà tí kò lábòsí nínú yàtọ̀ sí ìgbékèéyíde tó ní bojúbojú nínú. Dájúdájú, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún ọ̀dọ́kùnrin náà Tímótì, pé kó ṣọ́ra fún “àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà [tí] yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́, ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn.” (2 Tímótì 3:13, 14) Níwọ̀n bí gbogbo ohun tóo bá mú wọnú ọkàn rẹ yóò ti nípa lórí rẹ dé ìwọ̀n kan, pàtàkì rẹ̀ ni “mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn,” kí o rí i dájú pé wọ́n jẹ́ àwọn tí ń wá ire rẹ, kì í ṣe ire tara wọn.
Ìwọ ni yóò pinnu ohun tóo fẹ́ ṣe. O lè yàn láti máa ‘dáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí,’ nípa jíjẹ́ kí ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ojú ìwòye ayé yìí jọba lé ìrònú rẹ. (Róòmù 12:2) Ṣùgbọ́n ayé yìí kò ro rere sí ẹ. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kì wá nílọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn.” (Kólósè 2:8) Kò ná Sátánì ní ohunkóhun láti tipa báyìí mú wa bá bátànì tirẹ̀ mu, tàbí kó ‘gbé wa lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀.’ Bí èéfín sìgá tí afẹ́fẹ́ gbé wá sọ́dọ̀ ẹni ló rí. Wíwulẹ̀ mí afẹ́fẹ́ burúkú náà símú lè nípa lórí rẹ.
Bóo bá sì fẹ́, o lè yẹra fún mímí “afẹ́fẹ́” yẹn símú. (Éfésù 2:2) Dípò mímí in símú, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù, pé: “Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Èyí gba ìsapá. (Òwe 2:1-5) Rántí pé Jèhófà kì í ṣe ẹlẹ́tàn. Ó pèsè gbogbo ìsọfúnni táa nílò, ṣùgbọ́n kí o bàa lè jàǹfààní láti inú rẹ̀, o gbọ́dọ̀ fetí sí ìsọfúnni ọ̀hún, kí o sì jẹ́ kí ó nípa lórí ìrònú rẹ. (Aísáyà 30:20, 21; 1 Tẹsalóníkà 2:13) O gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fi òtítọ́ tó wà nínú “ìwé mímọ́,” èyíinì ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí, kún èrò inú rẹ.—2 Tímótì 3:15-17.
Jọ̀wọ́ Ara Rẹ fún Mímọ Tí Jèhófà Ń Mọ Ẹ́
Ìjẹ́pàtàkì ìdí tó fi yẹ kí o ṣègbọràn tinútinú bóo bá fẹ́ jàǹfààní nínú agbára mímọni bí ẹni mọ̀kòkò tí Jèhófà ní, ni Jèhófà alára ṣàkàwé rẹ̀ kedere nígbà tí ó sọ fún wòlíì Jeremáyà láti ṣèbẹ̀wò sí ibi iṣẹ́ amọ̀kòkò kan. Jeremáyà rí i pé amọ̀kòkò náà pèrò dà nípa ohun tí òun yóò fi ohun èlò kan ṣe, nígbà tí ‘ọwọ́ amọ̀kòkò ba ohun tó fẹ́ fi í mọ jẹ́.’ Jèhófà wá sọ pé: “Èmi kò ha lè ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí sí yín, ilé Ísírẹ́lì? . . . Wò ó! Bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí ní ọwọ́ mi, ilé Ísírẹ́lì.” (Jeremáyà 18:1-6) Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn ní Ísírẹ́lì kò ju kìkì ìṣùpọ̀ amọ̀ bọrọgidi lọ́wọ́ Jèhófà, tí òun yóò ṣù rúgúdú láti fi mọ ohunkóhun tó bá wù ú?
Kò ṣẹlẹ̀ rí, pé kí Jèhófà lo agbára ńlá rẹ̀ láti mú kí àwọn èèyàn ṣe nǹkan tí wọn kò fẹ́ ṣe; kì í sì í ṣe òun ló lẹ̀bi àbùkù tó wà lára wọn, gẹ́gẹ́ bó ti lè rí nínú ọ̀ràn amọ̀kòkò. (Diutarónómì 32:4) Àbùkù jẹ yọ nítorí pé àwọn tí Jèhófà fẹ́ mọ lọ́nà rere kọ̀ láti tẹ̀ lé ọ̀nà tó là sílẹ̀. Ìyàtọ̀ jàn-àn-ràn jan-an-ran tó wà láàárín ìwọ àti ìṣùpọ̀ amọ̀ bọrọgidi nìyẹn. O lómìnira láti yan ọ̀nà tó wù ẹ́. Ní lílo òmìnira yìí, o lè yàn láti jọ̀wọ́ ara rẹ fún mímọ tí Jèhófà ń mọ ẹ́, tàbí kí o mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ ọ́.
Ọ̀rọ̀ yìí mà gbàrònú o! Ẹ wo bó ti dára tó láti fetí sí ohùn Jèhófà dípò lílénu bebe pé, “Ẹnì kankan kò lè máa pàṣẹ ohun tí màá ṣe fún mi”! Gbogbo wa la nílò ìdarí Jèhófà. (Jòhánù 17:3) Fìwà jọ onísáàmù náà, Dáfídì, tó gbàdúrà pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.” (Sáàmù 25:4) Rántí ohun tí Ọba Sólómọ́nì sọ, pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i.” (Òwe 1:5) Ṣé wàá fetí sílẹ̀? Bóo bá fetí sílẹ̀, nígbà náà, “agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.”—Òwe 2:11.