Ẹ̀yin Òbí, Ẹ̀kọ́ Wo Làpẹẹrẹ Yín ń Kọ́ni?
“Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.”—ÉFÉSÙ 5:1, 2.
1. Irú ìtọ́sọ́nà wo ni Jèhófà pèsè fún àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́?
JÈHÓFÀ ni Olùdásílẹ̀ ètò ìdílé. Ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ni ìdílé kọ̀ọ̀kan ti wá, nítorí pé òun ló dá ìdílé àkọ́kọ́ sílẹ̀, tó sì fún tọkọtaya àkọ́kọ́ ní agbára ìbímọ. (Éfésù 3:14, 15) Ó fún Ádámù àti Éfà nítọ̀ọ́ni pàtó nípa iṣẹ́ wọn, ó sì tún fún wọn láǹfààní jaburata láti lo àtinúdá wọn bí wọ́n ti ń bójú tó àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28-30; 2:6, 15-22) Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣẹ̀, ipò tí ìdílé ní láti dojú kọ wá lọ́jú pọ̀ pátápátá. Síbẹ̀, Jèhófà fi ìfẹ́ pèsè ìtọ́sọ́nà tí yóò ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti lè kojú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀.
2. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi ìtọ́ni tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán kún ìmọ̀ràn táa kọ sílẹ̀? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ káwọn òbí bi ara wọn?
2 Gẹ́gẹ́ bí Atóbilọ́lá Olùfúnni Nítọ̀ọ́ni wa, Jèhófà ti ṣe ohun tó ju ká kàn pèsè ìtọ́sọ́nà táa ti kọ sílẹ̀, nípa ohun tó yẹ ká ṣe àti èyí tó yẹ ká yẹra fún. Láyé àtijọ́, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì, àtàwọn olórí ìdílé ló lò láti fúnni nítọ̀ọ́ni táa ti kọ sílẹ̀ àti èyí táa fẹnu sọ. Lọ́jọ́ tiwa lónìí, àwọn wo ló ń lò láti fúnni ní irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tí a ń fẹnu sọ? Àwọn Kristẹni alàgbà àti àwọn òbí ló ń lò. Bóo bá jẹ́ òbí, ǹjẹ́ ò ń ṣe ipa tìrẹ láti fún ìdílé rẹ̀ nítọ̀ọ́ni lọ́nà tí Jèhófà là sílẹ̀?—Òwe 6:20-23.
3. Kí làwọn olórí ìdílé lè rí kọ́ lára Jèhófà ní ti kíkọ́ni lọ́nà tó gbéṣẹ́?
3 Báwo ló ṣe yẹ ká firú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ni láàárín ìdílé? Jèhófà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Lọ́nà tó ṣe kedere, ó sọ àwọn ohun tó tọ́ táa gbọ́dọ̀ ṣe àti àwọn ohun búburú táa gbọ́dọ̀ sá fún, kò sì tún dẹ́kun sísọ wọ́n ní àsọtúnsọ. (Ẹ́kísódù 20:4, 5; Diutarónómì 4:23, 24; 5:8, 9; 6:14, 15; Jóṣúà 24:19, 20) Ó lo àwọn ìbéèrè tí ń múni ronú jinlẹ̀. (Jóòbù 38:4, 8, 31) Nípasẹ̀ lílo àkàwé àti ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn kan, ó ń ru ìmọ̀lára wa sókè, ó sì ń mọ ọkàn-àyà wa, bí amọ̀kòkò ṣe ń famọ̀ mọ̀kòkò. (Jẹ́nẹ́sísì 15:5; Dáníẹ́lì 3:1-29) Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn nígbà tẹ́ẹ bá ń kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́?
4. Kí la kọ́ lára Jèhófà ní ti báa ṣe ń báni wí, èé sì ti ṣe tí ìbáwí fi ṣe pàtàkì?
4 Bó bá dọ̀ràn ohun tó tọ́, Jèhófà kò gba gbẹ̀rẹ́ rárá o, ṣùgbọ́n ó mọ ipa tí àìpé lè ní lórí ẹ̀dá. Nítorí náà, kó tó di pé yóò fìyà jẹ àwọn èèyàn aláìpé, yóò ti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, yóò ti kì wọ́n nílọ̀ léraléra, yóò sì ti tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn létí lọ́pọ̀ ìgbà. (Jẹ́nẹ́sísì 19:15, 16; Jeremáyà 7:23-26) Tó bá sì fẹ́ báni wí, níwọ̀n-níwọ̀n ni yóò ṣe é, kò jẹ́ ṣe é láṣejù. (Sáàmù 103:10, 11; Aísáyà 28:26-29) Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ la ṣe ń báwọn ọmọ wa lò, a jẹ́ pé lóòótọ́ la mọ Jèhófà, á sì wá rọrùn fáwọn náà láti mọ̀ ọ́n.—Jeremáyà 22:16; 1 Jòhánù 4:8.
5. Kí làwọn òbí lè kọ́ lára Jèhófà nípa fífetísílẹ̀?
5 Lọ́nà tò yani lẹ́nu, Jèhófà máa ń tẹ́tí sí wa, gẹ́gẹ́ bí Baba onífẹ̀ẹ́ tí ń gbé lókè ọ̀run. Kì í pàṣẹ wàá lásán. Ó máa ń rọ̀ wá pé ká tú ọkàn-àyà wa jáde sóun. (Sáàmù 62:8) Báa bá sì wá fi èrò tí kò tọ́ hàn, kò jẹ́ bú mọ́ wa látòde ọ̀run kí gbogbo ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ló fi ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mà ṣe wẹ́kú o, ó wí pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n”! (Éfésù 4:31–5:1) Ẹ ò rí bí àpẹẹrẹ tí Jèhófà fi lélẹ̀ fáwọn òbí ti dára tó, bí wọ́n ti ń wọ́nà àtifún àwọn ọmọ wọn nítọ̀ọ́ni! Àpẹẹrẹ kan tó wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin ló jẹ́, ọ̀kan tó mú ká fẹ́ rìn ní ọ̀nà ìgbésí ayé tí òun fẹ́.
Ipa Tí Àpẹẹrẹ Ń Ní Lórí Ẹni
6. Báwo ni ìwà àti àpẹẹrẹ àwọn òbí ṣe ń nípa lórí àwọn ọmọ wọn?
6 Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, àpẹẹrẹ tún ń nípa tó jinlẹ̀ lórí àwọn èwe. Báwọn òbí fẹ́, bí wọ́n kọ̀, ó di dandan kí àwọn ọmọ wọn kọ́ àpẹẹrẹ wọn. Èyí lè mú inú òbí dùn—nígbà mí-ìn ó sì lè dà wọ́n lọ́kàn rú—bí wọ́n bá gbọ́ táwọn ọmọ wọn ń sọ ohun táwọn fúnra wọn ti sọ rí. Bí ìwà àti ìṣe àwọn òbí bá fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fáwọn ohun tẹ̀mí, èyí máa ń nípa tó dára lórí àwọn ọmọ.—Òwe 20:7.
7. Irú àpẹẹrẹ òbí wo ni Jẹ́fútà fi lélẹ̀ fún ọmọbìnrin rẹ̀, kí ló sì yọrí sí?
7 Bíbélì ṣàkàwé ipa tí àpẹẹrẹ òbí máa ń ní lórí ọmọ. Jẹ́fútà, tí Jèhófà lò láti ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jagun, tó sì ṣẹ́gun fún wọn, jẹ́ olórí ìdílé. Àkọsílẹ̀ táa rí nípa èsì tó fún ọba Ámónì fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jẹ́fútà ti ka ìtàn nípa bí Jèhófà ṣe bá Ísírẹ́lì lò. Ṣe ló ń sọ ìtàn náà bí ẹni pé òun ló kọ ọ́, ó sì fi ìgbàgbọ́ lílágbára tó ní nínú Jèhófà hàn. Kò sí àní-àní pé àpẹẹrẹ tiẹ̀ ló ran ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti nírú ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tó ní, èyí tó mú kó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí àpọ́nbìnrin tó fi gbogbo ayé rẹ̀ fún Jèhófà.—Onídàájọ́ 11:14-27, 34-40; Fi wé Jóṣúà 1:8.
8. (a) Irú ìṣarasíhùwà rere wo ni àwọn òbí Sámúẹ́lì fi hàn? (b) Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe jàǹfààní?
8 Táa bá ń sọ̀rọ̀ àwọn ọmọ tó yanjú, àwòfiṣàpẹẹrẹ ni Sámúẹ́lì jẹ́, ó tún jẹ́ wòlíì olóòótọ́ sí Ọlọ́run jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Ṣé ó wù ọ́ kí àwọn ọmọ tìẹ náà yanjú bíi tiẹ̀? Gbé àpẹẹrẹ tí àwọn òbí Sámúẹ́lì, Ẹlikénà àti Hánà, fi lélẹ̀ yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò nǹkan kò gún régé délẹ̀délẹ̀ lágboolé wọn, wọn kì í pa lílọ jọ́sìn ní Ṣílò jẹ, níbi tí àgọ́ ìjọsìn mímọ́ wà. (1 Sámúẹ́lì 1:3-8, 21) Ronú nípa bí ẹ̀mí tí Hánà fi gbàdúrà ti jinlẹ̀ tó. (1 Sámúẹ́lì 1:9-13) Ṣàkíyèsí ojú ìwòye àwọn méjèèjì nípa ìjẹ́pàtàkì mímú ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tí èèyàn bá jẹ́ fún Ọlọ́run ṣẹ. (1 Sámúẹ́lì 1:22-28) Ó dájú pé àpẹẹrẹ rere wọn ran Sámúẹ́lì lọ́wọ́ láti mú àwọn ànímọ́ tó jẹ́ kó lè tọ ọ̀nà tó tọ́ dàgbà—àní nígbà tí àwọn ènìyàn tó yí i ká pàápàá tó yẹ kí wọ́n máa sin Jèhófà kò tiẹ̀ ka ọ̀nà Ọlọ́run sí rárá. Nígbà tó yá, Jèhófà fa ẹrù iṣẹ́ lé Sámúẹ́lì lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 2:11, 12; 3:1-21.
9. (a) Kí ló ní ipa rere lórí Tímótì nínú ilé wọn? (b) Irú èèyàn wo ni Tímótì wá dà?
9 Ṣé kò wù ọ́ kí ọmọ rẹ̀ dà bí Tímótì, ẹni tó jẹ́ pé nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti ń bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ pọ̀? Baba Tímótì sì rèé, kì í ṣe onígbàgbọ́, ṣùgbọ́n ìyá tó bí i lọ́mọ àti ìyá-ìyá rẹ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa fífi ìmọrírì hàn fún nǹkan tẹ̀mí. Ó dájú pé èyí ṣèrànwọ́ gidigidi láti fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ fún ìgbésí ayé Tímótì gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. A sọ fún wa pé màmá rẹ̀, Yùníìsì, àti ìyá-ìyá rẹ̀ Lọ́ìsì ní “ìgbàgbọ́ . . . láìsí àgàbàgebè kankan.” Ìgbésí ayé wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni kì í ṣe ìgbésí ayé alágàbàgebè; ohun tí wọ́n ń sọ pé àwọn gbà gbọ́ gan-an ni wọ́n ń tẹ̀ lé, wọ́n sì kọ́ Tímótì ọ̀dọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tímótì fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán àti pé òun bìkítà nípa ire àwọn ẹlòmíràn.—2 Tímótì 1:5; Fílípì 2:20-22.
10. (a) Àpẹẹrẹ wo láti ìta ló lè nípa lórí àwọn ọmọ wa? (b) Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tí a bá kíyè sí irú ìsọ̀rọ̀ àti ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọmọ wa?
10 Kì í ṣe àwọn àpẹẹrẹ ti inú ilé nìkan ló ń nípa lórí àwọn ọmọ wa. Wọ́n láwọn ọmọ tí wọ́n jọ ń lọ sílé ìwé, àpẹẹrẹ àwọn olùkọ́ wà níbẹ̀ tó jẹ́ pé iṣẹ́ wọn ni láti darí ìrònú àwọn èwe, àwọn èèyàn kan tún wà láwùjọ wọn tó gbà pé gbogbo ènìyàn ló yẹ kó tẹ̀ lé àwọn àṣà ẹ̀yà tàbí ti ẹgbẹ́ àwùjọ tó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, àpẹẹrẹ àwọn ìlú-mọ̀ọ́ká eléré ìdárayá táwọn èèyàn ń gbóṣùbà fún nítorí àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe tún ń bẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni tàwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba táwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń sọ itú tí wọ́n ń pa. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé lojú wọn ti rí màbo níbi tógun gbígbóná ti jà. Ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu bí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá jẹ yọ nínú ọ̀rọ̀ tàbí ìṣarasíhùwà àwọn ọmọ wa? Kí la máa ń ṣe nígbà tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ jíjágbe mọ́ wọn tàbí nínà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀ yanjú ìṣòro yẹn? Dípò tí a óò fi jẹ́ kí ara wa bù máṣọ nítorí ohun táwọn ọmọ wa sọ tàbí ṣe, ǹjẹ́ kò ní dáa ká bi ara wa pé, ‘Ohunkóhun ha wà nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá wa lò, tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ báa ṣe lè yanjú ìṣòro yìí bí?’—Fi wé Róòmù 2:4.
11. Nígbà táwọn òbí bá ṣàṣìṣe, báwo lèyí ṣe lè nípa lórí ìṣarasíhùwà àwọn ọmọ wọn?
11 Àmọ́ ṣá o, kò lè jẹ́ ìgbà gbogbo ni àwọn òbí aláìpé yóò máa lo ọ̀nà tó dára jù lọ láti yanjú ìṣòro. Wọ́n á ṣàṣìṣe. Tí àwọn ọmọ bá wá mọ̀ bẹ́ẹ̀, ṣé yóò dín ọ̀wọ̀ tí wọ́n ní fáwọn òbí wọn kù? Ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀ o, báwọn òbí bá gbìyànjú láti fojú bíńtín wo àṣìṣe wọn nípa lílo ọlá àṣẹ wọn lọ́nà lílekoko. Ṣùgbọ́n ìyọrísí rẹ̀ lè yàtọ̀ gidigidi bí àwọn òbí bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba àṣìṣe wọn láìjanpata. Nípa èyí, wọ́n lè fi àpẹẹrẹ tó ṣeyebíye lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n ní láti kọ́ ohun kan náà.—Jákọ́bù 4:6.
Ẹ̀kọ́ Tí Àpẹẹrẹ Wa Lè Kọ́ni
12, 13. (a) Kí ló yẹ káwọn ọmọ kọ́ nípa ìfẹ́, báwo la sì ṣe lè fi èyí kọ́ wọn dáadáa? (b) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́?
12 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye ló wà táa lè kọ́ àwọn ọmọ lọ́nà tó gbéṣẹ́ nígbà tí a bá fi àpẹẹrẹ rere gbe ọ̀rọ̀ ẹnu wa táa fi ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́sẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò.
13 Fífi Ìfẹ́ Àìmọtara-Ẹni-Nìkan Hàn: Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a lè lo àpẹẹrẹ láti jẹ́ kó túbọ̀ ta gbòǹgbò nínú àwọn ọmọ wa ni ohun tí ìfẹ́ túmọ̀ sí. “Àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí [Ọlọ́run] ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:19) Òun ni Orísun ìfẹ́, òun ló sì fi àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó ga lọ́lá jù lọ hàn. Nínú Bíbélì, ó lé ní ìgbà ọgọ́rùn-ún tí a mẹ́nu kan ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà yìí, tí a ń pè ní a·gaʹpe. Òun ni ànímọ́ táa fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. (Jòhánù 13:35) Ó yẹ ká fi irú ìfẹ́ yẹn hàn sí Ọlọ́run àti Jésù Kristi, ó sì tún yẹ káwọn èèyàn máa fi irú rẹ̀ hàn sí ara wọn lẹ́nì kìíní kejì—àní ó yẹ ká fi hàn sáwọn èèyàn tó jẹ́ pé ara wa kì í fi bẹ́ẹ̀ yá mọ́ wọn. (Mátíù 5:44, 45; 1 Jòhánù 5:3) Ká tó lè fi ìfẹ́ yìí kọ́ àwọn ọmọ wa lọ́nà tó gbéṣẹ́, ìfẹ́ yìí gbọ́dọ̀ wà ní ọkàn-àyà wa, kó sì hàn nínú ìgbésí ayé wa. Àmọ́ ṣá o, ìwà wa ń sọ irú ẹni táa jẹ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu wa lọ. Nínú ìdílé, ó ṣe pàtàkì káwọn ọmọ rí i pé ìfẹ́ wà láàárín wa, kí wọ́n sì mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn, kí wọ́n tún rí àwọn ànímọ́ mìíràn tó fara pẹ́ ẹ, irú bíi jíjẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹni ọ̀wọ́n ni wọ́n jẹ́ sí wa. Bí àwọn ànímọ́ wọ̀nyí kò bá sí, ọmọ lè rán, ọpọlọ rẹ̀ lè máà jí pépé, ó tiẹ̀ lè sọ ìmọ̀lára ọmọ dìdàkudà. Ó tún ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọ rí báa ṣe ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ìdílé wa àti báa ṣe ń fi hàn pé wọ́n jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n sí wa.—Róòmù 12:10; 1 Pétérù 3:8.
14. (a) Báwo la ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ láti ṣe ojúlówó iṣẹ́, tó ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá? (b) Báwo lo ṣe lè ṣe èyí nínú ìdílé rẹ?
14 Kíkọ́ bí a ṣe ń ṣiṣẹ́: Iṣẹ́ jẹ́ apá pàtàkì ìgbésí ayé. Béèyàn bá fẹ́ níyì lọ́wọ́ ara ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kò kọ́ báa ti í ṣe ojúlówó iṣẹ́. (Oníwàásù 2:24; 2 Tẹsalóníkà 3:10) Báa bá ní kí ọmọ ṣiṣẹ́ kan, tó sì jẹ́ pé a ò kọ́ ọ tẹ́lẹ̀ bí yóò ṣe ṣe é, ṣùgbọ́n tí kò wá ṣe é dáadáa, táa sì wá fara ya, táà ń fìbínú sọ̀rọ̀, kò dájú pé yóò kọ́ báa ti í ṣe ojúlówó iṣẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà táwọn ọmọ bá kọ́ nǹkan nípa ṣíṣe é pẹ̀lú àwọn òbí wọn, táa sì gbóríyìn fún wọn lọ́nà tó yẹ, ó dájú pé wọn á mọ́ báa ti ń ṣiṣẹ́ tí ń tẹ́ni lọ́rùn. Báwọn òbí bá tún fi àlàyé kún àpẹẹrẹ tí wọ́n ń fi lélẹ̀, àwọn ọmọ kò wulẹ̀ ní kọ́ bí wọn yóò ṣe rí i pé iṣẹ́ kan di ṣíṣe, ṣùgbọ́n wọn a kọ́ bí wọ́n ṣe lè borí ìṣòro, bí wọ́n ṣe lè tẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣe iṣẹ́ títí tí wọn yóò fi parí ẹ̀, wọn yóò sì kọ́ báa ṣe ń ronú jinlẹ̀ àti báa ti ń ṣèpinnu. Nínú irú ipò yìí, a lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Jèhófà pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́, pé ó ń ṣiṣẹ́ rere, àti pé Jésù ń fara wé Baba rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31; Òwe 8:27-31; Jòhánù 5:17) Bó bá jẹ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ ní ìdílé kan ń ṣe, bó sì jẹ́ òwò ni wọ́n ń ṣe, díẹ̀ lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé náà lè jọ máa ṣiṣẹ́. Tàbí kí màmá máa kọ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń se oúnjẹ àti bí wọ́n ṣe ń palẹ̀ mọ́ lẹ́yìn oúnjẹ. Baba tó jẹ́ pé ó níṣẹ́ síbi tó jìnnà sílé lè ṣètò pé kóun pẹ̀lú àwọn ọmọ òun ṣe iṣẹ́ tí òun ní sílé. Ẹ wo bó ti ṣàǹfààní tó nígbà tí àwọn òbí bá ní in lọ́kàn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní nǹkan lọ́nà tí wọ́n á fi múra wọn sílẹ̀ de ẹ̀yìn ọ̀la, tí kì í kàn-án ṣe pé kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́ báyìí nìkan!
15. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbàgbọ́? Ṣàkàwé.
15 Dídi ìgbàgbọ́ mú lójú hílàhílo: Ìgbàgbọ́ pẹ̀lú jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa. Nígbà táa bá jíròrò ìgbàgbọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, àwọn ọmọ lè kọ́ láti mọ báwọn ṣe lè ṣàlàyé rẹ̀. Wọ́n tún lè wá mọ àwọn àmì tó ń fi hàn pé ìgbàgbọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà nínú ọkàn-àyà wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá rí àwọn òbí wọn tí ń fi ìgbàgbọ́ tí kò mì hàn lójú àwọn àdánwò lílekoko, ẹ̀kọ́ yìí lè wà lọ́kàn wọn jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Obìnrin kan wà ní Panama tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí pá a láyà pé òun máa lé e jáde nílé bí kò bá dẹ́kun sísin Jèhófà. Síbẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọmọ kéékèèké mẹ́rin tó ní, ó máa ń fẹsẹ̀ rìn kìlómítà mẹ́rìndínlógún, lẹ́yìn náà ni yóò wá wọ bọ́ọ̀sì fún ọgbọ̀n kìlómítà mìíràn kó tó lè dé Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nítòsí. Nítorí àpẹẹrẹ tó wúni lórí yìí, ogún èèyàn látinú ìdílé rẹ̀ ló ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́.
Fífi Àpẹẹrẹ Lélẹ̀ Nínú Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́
16. Èé ṣe táa fi dámọ̀ràn kíka Bíbélì lójoojúmọ́?
16 Ọ̀kan lára àwọn àṣà tó ṣeyebíye jù lọ tí ìdílé lè dá sílẹ̀—àṣà tí yóò ṣàǹfààní fún àwọn òbí, tí yóò sì jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn ọmọ láti tẹ̀ lé ni—kíka Bíbélì déédéé. Bó ṣe wù kó rí, ka Bíbélì díẹ̀ lójúmọ́. Kì í ṣe bí ibi táa kà ti pọ̀ tó ló ṣe pàtàkì. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni ṣíṣe é déédéé àti ọ̀nà táa gbà ṣe é. Ní ti àwọn ọmọ, ohun tí o lè fi kún Bíbélì kíkà náà ni títẹ́tí sí kásẹ́ẹ̀tì Iwe Itan Bibeli Mi, bó bá wà lédè rẹ. Kíka apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ ká fi èrò Ọlọ́run sọ́kàn. Bó bá sì jẹ́ pé ìdílé lápapọ̀ ló ń ka Bíbélì yìí, tí kì í ṣe pé olúkúlùkù ń dá tiẹ̀ kà, èyí lè ran gbogbo ìdílé náà lọ́wọ́ láti rìn ní ọ̀nà Jèhófà. Ohun tí a rọ̀ wá láti máa ṣe nìyẹn nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ táa wò ní àwọn Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́,” èyí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Ẹ̀yin Ìdílé—Ẹ Jẹ́ Kí Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́ Jẹ́ Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Yín!—Sáàmù 1:1-3.
17. Báwo ni kíka Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìdílé àti mímọ àwọn ẹsẹ pàtàkì-pàtàkì sórí ṣe ń ṣèrànwọ́ láti fi ìmọ̀ràn Éfésù 6:4 sọ́kàn?
17 Kíka Bíbélì papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ nínú lẹ́tà rẹ̀, tí a mí sí, èyí tó kọ sí àwọn Kristẹni ní Éfésù, pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ní ṣáńgílítí, “ìlànà èrò orí” túmọ̀ sí “fífi nǹkan síni lọ́kàn”; nítorí náà a rọ àwọn Kristẹni baba láti fi Jèhófà Ọlọ́run sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn—kí wọ́n ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ èrò Ọlọ́run. Fífún àwọn ọmọ níṣìírí láti mọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì-pàtàkì sórí lè ṣèrànwọ́ láti lè ṣe èyí. Ìdí táa fi ń ṣe èyí ni pé kí èrò Jèhófà lè máa darí èrò àwọn ọmọ, kí ìfẹ́-ọkàn àti ìwà wọn bàa lè máa fi ìlànà Ọlọ́run hàn bí wọ́n ti ń dàgbà yálà àwọn òbí wà pẹ̀lú wọn tàbí wọn kò sí. Bíbélì ló jẹ́ ìpìlẹ̀ fún irú èrò bẹ́ẹ̀.—Diutarónómì 6:6, 7.
18. Nígbà táa bá ń ka Bíbélì, kí la nílò láti lè (a) lóye rẹ̀ kedere? (b) jàǹfààní láti inú ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀? (d) ṣe àwọn ohun tó fi hàn nípa ète Jèhófà? (e) jàǹfààní láti inú ohun tó sọ nípa ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn?
18 Àmọ́ ṣá o, bí Bíbélì yóò bá nípa lórí ìgbésí ayé wa, ó pọndandan pé ká mọ ohun tó sọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lo jẹ́ pé kí wọ́n tó lè lóye àwọn ẹsẹ kan wọn gbọ́dọ̀ kà á lọ́pọ̀ ìgbà. Láti lè lóye àwọn gbólóhùn kan dáadáa, ó lè béèrè pé ká yẹ àwọn ọ̀rọ̀ wò nínú ìwé atúmọ̀ èdè tàbí ká lo ìwé náà, Insight on the Scriptures. Bó bá jẹ́ pé ìmọ̀ràn tàbí àṣẹ ló wà nínú ẹsẹ náà, ẹ gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipò òde òní tó mú kó yẹ ní títẹ̀lé. Lẹ́yìn náà, ẹ wá lè béèrè pé, ‘Báwo ni fífi ìmọ̀ràn yìí sílò ṣe lè ṣàǹfààní fún wa?’ (Aísáyà 48:17, 18) Bí ẹsẹ náà bá ń sọ nípa àwọn apá kan nínú ète Jèhófà, ẹ lè béèrè pé, ‘Báwo lèyí ṣe nípa lórí ìgbésí ayé wa?’ Ó sì lè jẹ́ pé àkọsílẹ̀ kan tó sọ nípa ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn ni ẹ̀ ń kà. Wàhálà wo ni wọ́n dojú kọ nínú ìgbésí ayé wọn? Báwo ni wọ́n ṣe kojú rẹ̀? Báwo la ṣe lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ wọn? Gbogbo ìgbà ni kí ẹ máa fàyè sílẹ̀ láti jíròrò ohun tí àkọsílẹ̀ náà túmọ̀ sí nínú ìgbésí ayé wa lóde ìwòyí.—Róòmù 15:4; 1 Kọ́ríńtì 10:11.
19. Nípa jíjẹ́ aláfarawé Ọlọ́run, kí la óò máa pèsè fún àwọn ọmọ wa?
19 Ọ̀nà rere lèyí mà jẹ́ láti tẹ èrò Ọlọ́run mọ́ wa lọ́kàn o! Nípa báyìí, a óò lè ràn wá lọ́wọ́ ní ti gidi láti di “aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) A óò sì pèsè àpẹẹrẹ tó yẹ kí àwọn ọmọ wa tẹ̀ lé.
Ǹjẹ́ O Rántí?
◻ Báwo làwọn òbí ṣe lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ Jèhófà?
◻ Èé ṣe tó fi yẹ káwọn òbí fi àpẹẹrẹ rere gbe ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà lẹ́sẹ̀?
◻ Kí làwọn ẹ̀kọ́ díẹ̀ tó jẹ́ pé nípa àpẹẹrẹ ló dára jù kí àwọn òbí fi wọ́n kọni?
◻ Báwo la ṣe lè jàǹfààní ní kíkún láti inú kíka Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìdílé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọ̀pọ̀ ń gbádùn kíka Bíbélì lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé