Lílo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Ọlọ́run
“Èmi ni Olú Ọ̀run, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí èmi; ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.”—AÍSÁYÀ 46:9, 10.
1, 2. Kí ni àwọn èròǹgbà díẹ̀ tó yàtọ̀ síra nípa ipa tí Ọlọ́run ń kó nínú àwọn àlámọ̀rí ayé?
BÁWO ni Ọlọ́run ṣe kópa nínú àlámọ̀rí ayé tó? Èrò àwọn ènìyàn lórí ọ̀ràn yìí yàtọ̀ síra. Èrò àwọn kan ni pé kò kópa kankan. Wọ́n sọ pé lẹ́yìn tó dá ènìyàn tán, kò fẹ́ sapá kankan lé wọn lórí mọ́ tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni kò lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lójú ìwòye yìí, Ọlọ́run dà bíi bàbá kan tó gbé ọmọ rẹ̀ sórí kẹ̀kẹ́ tuntun, tó jẹ́ kó jókòó dáadáa, tó wá tì í síwájú kí ọmọ rẹ̀ lè máa gun kẹ̀kẹ́ náà lọ. Ni baba náà bá bá tirẹ̀ lọ. Ló bá ku ọmọ nìkan lórí kẹ̀kẹ́; ó ṣeé ṣe kó ṣubú, ó sì lè má ṣubú. Ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, bàbá ti yọwọ́ tirẹ̀ nínú ọ̀ràn náà.
2 Èròǹgbà mìíràn ni pé Ọlọ́run ń darí gbogbo àlámọ̀rí ìgbésí ayé wa láìjáfara rárá, àti pé ohun kan kò lè ṣẹlẹ̀ láìjẹ́ pé ó lọ́wọ́ sí i. Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, àwọn kan lè parí èrò sí pé kì í ṣe àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ nìkan ló ń wá látọwọ́ Ọlọ́run, àmọ́, wọ́n gbà pé òun ló tún ń fa ìwà ọ̀daràn àti àjálù tó ń pọ́n ìran ènìyàn lójú. Bí a bá mọ èyí tó jẹ́ òtítọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn ènìyàn lò, yóò ṣeé ṣe fún wa láti mọ irú ohun tó yẹ ká máa retí látọ̀dọ̀ rẹ̀. Yóò sì mú kí ìrètí wa lágbára sí i pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé kò sí ìkankan nínú àwọn ìlérí rẹ̀ tí kò ní ṣẹ.—Hébérù 11:1.
3. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ète? (b) Èé ṣe tí a fi sọ̀rọ̀ Jèhófà bí ẹni tó ń “ṣẹ̀dá” ète rẹ̀, tó sì ń “gbé e” kalẹ̀?
3 Bí a bá ń sọ̀rọ̀ lórí ipa tí Ọlọ́run ń kó nínú àwọn àlámọ̀rí ènìyàn, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ níbẹ̀ ni pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ète. Ìyẹn sì fara hàn kedere nínú orúkọ rẹ̀ gan-an. “Jèhófà” túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Pẹ̀lú bí Jèhófà ṣe ń ṣe àwọn nǹkan ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ó sọ ara rẹ̀ di Ẹni tí ń mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Lójú ìwòye yìí, a sọ̀rọ̀ Jèhófà bí ẹni tí ó “ṣẹ̀dá,” tàbí tí ń gbé ète rẹ̀ kalẹ̀ nípa àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àti àwọn ìgbésẹ̀ tí yóò gbé. (2 Ọba 19:25; Aísáyà 46:11) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà ya·tsar’, tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “amọ̀kòkò.” (Jeremáyà 18:4) Gan-an gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò kan tó mọṣẹ́ dunjú ṣe lè fi ìṣù amọ̀ mọ àgé tó dáa, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe lè darí, tàbí kó yí àwọn nǹkan lọ́nà tí yóò fi mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Éfésù 1:11.
4. Báwo ni Ọlọ́run ṣe múra ilẹ̀ ayé sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti gbé?
4 Fún àpẹẹrẹ, Ọlọ́run pète pé ilẹ̀ ayé yóò di ibi ẹlẹ́wà kíkọyọyọ tí àwọn ènìyàn pípé onígbọràn yóò máa gbé. (Aísáyà 45:18) Ó pẹ́ tí Jèhófà ti ń fi ìfẹ́ múra sílẹ̀ de ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ kó tó di pé ó dá wọn. Orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe fìdí ọ̀sán àti òru, ilẹ̀ àti òkun, múlẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ló dá ewéko àti àwọn ẹranko. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ló fi múra ilẹ̀ ayé yìí sílẹ̀ kó lè ṣeé gbé fún ìran ènìyàn. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣe iṣẹ́ náà yọrí pátápátá. Bí ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn nínú Édẹ́nì nìyẹn, párádísè ẹlẹ́wà tí gbogbo nǹkan pé sí, kí wọ́n lè máa gbádùn ìgbésí ayé wọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà kópa tààràtà nínú àlámọ̀rí ayé, ó ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé láti mú ète gíga rẹ̀ ṣẹ. Ǹjẹ́ bí ìdílé ènìyàn ṣe ń pọ̀ sí i mú kí ipa tí ó kó yí padà?
Jèhófà Pààlà sí Àjọṣe Rẹ̀ Pẹ̀lú Ènìyàn
5, 6. Èé ṣe ti Ọlọ́run fi pààlà sí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú ènìyàn?
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ kì í ṣe gbogbo ìgbòkègbodò ènìyàn ló ń darí. Èyí sì nídìí. Ìdí kan ni pé a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run, wọ́n ní òmìnira láti yan ohun tó wù wọ́n, níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù. Jèhófà kò fagbára mú wa láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; bẹ́ẹ̀ ni a kì í ṣe ẹ̀rọ tí ń ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n tí kò lè ronú. (Diutarónómì 30:19, 20; Jóṣúà 24:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ohun táa bá ṣe la óò dáhùn fún, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ti mú kí ó fún wa lómìnira tí ó tó, kí a lè pinnu ọ̀nà tí a ó gbé ìgbésí ayé wa gbà.—Róòmù 14:12; Hébérù 4:13.
6 Ìdí mìíràn tí Ọlọ́run kò fi ń darí gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú kókó tí Sátánì gbé dìde ní Édẹ́nì. Sátánì pe ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run níjà. Ó fi ohun tó dà bí àǹfààní láti dòmìnira lọ Éfà—ó sì tẹ́wọ́ gbà á, Ádámù, ọkọ rẹ̀ náà tún tẹ́wọ́ gbà á níkẹyìn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Abájọ tí Ọlọ́run fi gba àwọn ènìyàn láyè láti ṣàkóso ara wọn fún àkókò kan láti fi hàn bóyá ìpèníjà Sátánì jóòótọ́. Nítorí ìdí yìí, a kò lè sọ pé Ọlọ́run ló lẹ̀bi ìwà ibi táwọn èèyàn ń hù lónìí. Mósè kọ̀wé nípa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn pé: “Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun níhà ọ̀dọ̀ àwọn fúnra wọn; wọn kì í ṣe ọmọ [Ọlọ́run], àbùkù náà jẹ́ tiwọn.”—Diutarónómì 32:5.
7. Kí ni ète Jèhófà fún ayé àti fún ènìyàn?
7 Àmọ́ ṣá o, bí Jèhófà tilẹ̀ fàyè gbà wá láti yan ohun tí ó wù wá, kí a sì máa ṣàkóso ara wa láìbá wa dá sí i, kì í ṣe pé ó wá yọwọ́yọsẹ̀ pátápátá nínú àwọn àlámọ̀rí ayé, tí ì bá máà jẹ́ ká fi bẹ́ẹ̀ nírètí pé yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run, Jèhófà kò yí ète rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ fún ilẹ̀ ayé àti ìran ènìyàn padà. Òun kò ní kùnà láé láti yí ilẹ̀ ayé padà sí párádísè kan tó kún fún àwọn ènìyàn pípé, tí wọ́n jẹ́ onígbọràn, tí wọ́n sì láyọ̀. (Lúùkù 23:42, 43) Àkọsílẹ̀ Bíbélì láti Jẹ́nẹ́sísì títí dé Ìṣípayá ṣàpèjúwe bí Jèhófà ti ń ṣe é ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé láti rí i pé òun mú ète yẹn ṣẹ.
Ọlọ́run Ń Gbégbèésẹ̀ Láti Mú Ìfẹ́ Rẹ̀ Ṣẹ
8. Kí ni mímú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí ní nínú?
8 Nínú àwọn àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, Ọlọ́run fi hàn pé òun yóò mú ète òun ṣẹ. Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà mú un dá Mósè lójú pé Òun yóò dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì, òun ó sì mú wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí, ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin. (Ẹ́kísódù 3:8) Ìkéde pàtàkì tó fọkàn ẹni balẹ̀ nìyí. Yóò kan dídá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn—tí àwọn àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń lọ sí nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta—sílẹ̀ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè kan tó lágbára gan-an, tí kò sì fara mọ́ lílọ wọn. (Ẹ́kísódù 3:19) Ilẹ̀ tí wọ́n sì ń lọ rèé, àwọn orílẹ̀-èdè tó lágbára tí yóò fìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú wọn ló ń gbé níbẹ̀. (Diutarónómì 7:1) Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tó lè dé ilẹ̀ náà, wọ́n gbọ́dọ̀ la aginjù tí wọn yóò ti nílò oúnjẹ àti omi kọjá. Bí nǹkan ṣe rí yìí ló fún Jèhófà láyè láti fi agbára rẹ̀ gíga jù lọ àti jíjẹ́ tí ó jẹ́ Ọlọ́run hàn.—Léfítíkù 25:38.
9, 10. (a) Èé ṣe tó fi ṣeé ṣe fún Jóṣúà láti jẹ́rìí sí i pé àwọn ìlérí Ọlọ́run ṣeé gbára lé? (b) Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú agbára tí Ọlọ́run ní láti san èrè fún àwọn olóòótọ́?
9 Ọlọ́run ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àgbàyanu láti mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì. Lákọ̀ọ́kọ́, ó mú àjàkálẹ̀ àrùn mẹ́wàá tó runlérùnnà wá sórí orílẹ̀-èdè Íjíbítì. Ẹ̀yìn ìyẹn ló pín Òkun Pupa sí méjì, èyí tó mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè yè bọ́ nígbà táwọn ọmọ ogun Íjíbítì tó ń lépa wọ́n ṣègbé. (Sáàmù 78:12, 13, 43-51) Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún tọ́jú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láàárín ogójì ọdún tí wọ́n fi wà nínú aginjù, ó fi mánà bọ́ wọn, ó pèsè omi fún wọn, ó tilẹ̀ tún rí sí i pé aṣọ wọn kò gbó bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wọn kò wú. (Diutarónómì 8:3, 4) Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí tán, Jèhófà tún tì wọ́n lẹ́yìn láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Jóṣúà, tó lo ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú àwọn ìlérí Jèhófà fojú ara rẹ̀ rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Abájọ tó fi fi ìdánilójú sọ fún àwọn àgbààgbà ọkùnrin tó wà nígbà ayé rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín.”—Jóṣúà 23:14.
10 Gẹ́gẹ́ bíi ti Jóṣúà ìgbàanì, àwọn Kristẹni lónìí ní ìdánilójú pé Ọlọ́run ṣe tán láti gbégbèésẹ̀ nítorí àwọn tó ń sìn ín, ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdánilójú yìí jẹ́ apá pàtàkì kan nínú ìgbàgbọ́ wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.
Ọlọ́run Mọ Ohun Tí Yóò Ṣẹlẹ̀ Lọ́la
11. Àwọn kókó wo ló mú kí Ọlọ́run lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
11 Títí di báyìí, a ti rí i dájú pé bí Ọlọ́run tilẹ̀ fàyè gbà wá pé kí a yan ohun tó wù wá, tó sì tún fún àwọn ènìyàn lómìnira láti máa ṣàkóso ara wọn, síbẹ̀ ó lágbára láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ, ó sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n kókó kan tún wà tó mú kí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe ní ìmúṣẹ láìkùnà. Kókó náà ni pé Jèhófà mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la. (Aísáyà 42:9) Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ sọ pé: “Ẹ rántí àwọn nǹkan àkọ́kọ́ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, pé èmi ni Olú Ọ̀run, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí èmi; Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe; Ẹni tí ń wí pé, ‘Ìpinnu tèmi ni yóò dúró, gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe.’” (Aísáyà 46:9, 10) Àgbẹ̀ kan tí kì í ṣe àgbẹ̀ kúẹ́kúẹ́ mọ ìgbà tí yóò gbin irúgbìn, ó sì mọ ibi tí òun yóò gbìn ín sí, ṣùgbọ́n bí àwọn nǹkan yóò ṣe rí gan-an lè máà dá a lójú. Àmọ́, “Ọba ayérayé” ní ìmọ̀ pípéye láti mọ àkókò pàtó tí yóò mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ, ó sì mọ ibi tí òun yóò ti mú un ṣẹ.—1 Tímótì 1:17.
12. Nígbà ayé Nóà, ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi hàn pé òun mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la?
12 Ṣàgbéyẹ̀wò bí Ọlọ́run ṣe fi hàn pé òun mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la nígbà ayé Nóà. Nítorí ìwà búburú tó kún gbogbo ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run pinnu láti mú òpin dé bá àwọn aláìgbọràn ènìyàn. Ó yan àkókò tí òun yóò ṣe é, ìyẹn ní ọgọ́fà ọdún sí àkókò tó sọ ìpinnu rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:3) Yíyàn tí Jèhófà yan àkókò pàtó yẹn fi hàn pé, ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ju wíwulẹ̀ pa àwọn ènìyàn oníwà ibi run, torí pé ìgbàkigbà ló lè ṣèyẹn. Àkókò tí Jèhófà yàn tún pèsè ọ̀nà àbáyọ fún àwọn olódodo. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 5:29.) Nítorí ọgbọ́n tí Ọlọ́run ní, ó ti mọ àkókò láti yan iṣẹ́ tí yóò yọrí sí mímú ète yìí ṣẹ. Ó fún Nóà ní ìsọfúnni tó kún rẹ́rẹ́. Nóà ní láti kan ọkọ̀ áàkì kan “fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀,” a ó sì fi àkúnya omi pa àwọn oníwà ibi run.—Hébérù 11:7; Jẹ́nẹ́sísì 6:13, 14, 18, 19.
Iṣẹ́ Ọkọ̀ Kíkàn Tó Fakíki
13, 14. Èé ṣe tí kíkan áàkì fi jẹ́ iṣẹ́ tó peni níjà?
13 Fojú bí nǹkan ṣe rí fún Nóà wo iṣẹ́ tí a yàn fún un yìí. Ènìyàn Ọlọ́run tí Nóà jẹ́ mú kó mọ̀ pé Jèhófà lè pa àwọn tí kò bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ run. Àmọ́, iṣẹ́ wà láti ṣe ṣáájú ìyẹn—iṣẹ́ kan tó gba ìgbàgbọ́. Kíkan ọkọ̀ áàkì náà yóò jẹ́ iṣẹ́ kan tó lágbára. Ọlọ́run ti sọ ìwọ̀n rẹ̀. Áàkì náà yóò gùn ju àwọn kan lára pápá ìṣeré tó wà lóde òní, yóò sì ga tó ilé alájà márùn-ún. (Jẹ́nẹ́sísì 6:15) Àwọn tó fẹ́ kan ọkọ̀ náà kò kan ọkọ̀ rí, wọn ò sì tó nǹkan. Wọn ò ní àwọn irin iṣẹ́ ńláńlá àti àwọn ohun èlò tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó lóde òní. Ní àfikún sí i, níwọ̀n bí Nóà kò ti ní agbára àtimọ ọjọ́ iwájú bíi ti Jèhófà, kò sí ọ̀nà kankan fún un láti mọ bí ipò nǹkan ṣe máa rí bí ọdún ti ń gorí ọdún, kò mọ̀ bóyá ipò nǹkan yóò mú kí iṣẹ́ ọkọ̀ kíkàn náà yá kánkán tàbí yóò mú kó falẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí onírúurú ìbéèrè ti wá sí Nóà lọ́kàn. Níbo la ti fẹ́ rí àwọn ohun èlò táa fẹ́ fi kan ọkọ̀ náà? Báwo lòun ó ṣe káwọn ẹranko jọ? Irú oúnjẹ wo ni wọn ó jẹ, báwo sì ni yóò ṣe pọ̀ tó? Ìgbà wo gan-an ni Àkúnya Omi tí Ọlọ́run sọ yóò dé?
14 Ipò àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tún wà níbẹ̀ o. Ìwà ibi pọ̀ lọ jàra. Àwọn Néfílímù alágbára—ìyẹn àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tí àwọn obìnrin ènìyàn bí fún àwọn áńgẹ́lì burúkú—tún ti fi ìwà ipá kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-4, 13) Yàtọ̀ sí ìyẹn, iṣẹ́ áàkì kíkàn kì í ṣe iṣẹ́ téèyàn lè yọ́ ṣe. Nǹkan tí Nóà ń ṣe yóò máa ya àwọn ènìyàn lẹ́nu, òun náà yóò sì máa ṣàlàyé fún wọn. (2 Pétérù 2:5) Ǹjẹ́ ó lè retí pé kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà á? Bóyá ni! Ọdún díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, Énọ́kù olóòótọ́ kéde ìparun àwọn ẹni ibi. Àwọn ènìyàn kò tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ rẹ̀ rárá débi pé Ọlọ́run “mú un lọ,” tàbí ká sọ ọ́ lọ́nà mìíràn, ó dín ìgbésí ayé rẹ̀ kù, ó dájú pé ó ṣe èyí kí àwọn ọ̀tá Rẹ̀ má bàa rí i pa. (Jẹ́nẹ́sísì 5:24; Hébérù 11:5; Júúdà 14, 15) Kì í wá ṣe pé Nóà yóò ṣe irú iṣẹ́ kan náà tí wọ́n fojú burúkú wò nìkan ni, àmọ́ ó tún ní láti kan áàkì pẹ̀lú. Bí Nóà ti ń kan áàkì náà, áàkì yìí yóò jẹ́ ohun ìránnilétí gbọnmọ-gbọnmọ pé, bí àwọn alájọgbáyé rẹ̀ ti jẹ́ olubi tó, ó dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́!
15. Èé ṣe tí Nóà fi ní ìgbọ́kànlé pé òun lè ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún òun?
15 Nóà mọ̀ pé Ọlọ́run Olódùmarè yóò ti iṣẹ́ náà lẹ́yìn, yóò sì fìbùkún sí i. Ṣé kì í ṣe Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yan iṣẹ́ náà fún un ni? Jèhófà ti mú un dá Nóà lójú pé òun àti ìdílé rẹ̀ yóò wọnú áàkì tí a kàn parí, kí a lè pa wọ́n mọ́ láàyè la Àkúnya Omi tí yóò kárí ayé já. Ọlọ́run tilẹ̀ fi àdéhùn kan tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ti ìlérí náà lẹ́yìn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:18, 19) Ó ṣeé ṣe kí Nóà ti mọ̀ pé Jèhófà ti ronú jinlẹ̀ nípa iṣẹ́ náà, ó sì ti mọ ohun tó ń béèrè kó tó fà á lé òun lọ́wọ́. Àti pé, Nóà mọ̀ pé Jèhófà ní agbára láti ṣèrànwọ́ fóun nígbà tó bá yẹ. Nítorí náà, ìgbàgbọ́ Nóà sún un ṣiṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bíi ti Ábúráhámù tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀, Nóà “gbà gbọ́ ní kíkún pé ohun tí [Ọlọ́run] ti ṣèlérí ni ó lè ṣe pẹ̀lú.”—Róòmù 4:21.
16. Bí iṣẹ́ áàkì kíkàn náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, báwo ni ìgbàgbọ́ Nóà ṣe túbọ̀ lágbára sí i?
16 Bí ọdún ti ń gorí ọdún tí iṣẹ́ áàkì náà sì ń lójú ni ìgbàgbọ́ Nóà túbọ̀ ń lágbára sí i. Àwọn ìṣòro ọ̀nà táa máa gbà kan ọkọ̀ náà àti kúlẹ̀kúlẹ̀ gbogbo tó yí i ká di èyí tó yanjú. Àwọn àdánwò di èyí tí a ṣẹ́pá. Kò sí àtakò kankan tó lè dá iṣẹ́ náà dúró. Ìdílé Nóà rí ìtìlẹ́yìn àti ààbò Jèhófà. Bí Nóà ṣe ń báa nìṣó ni ‘ìjójúlówó ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.’ (Jákọ́bù 1:2-4) Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, iṣẹ́ áàkì kíkàn parí, Àkúnya Omi dé, Nóà àti ìdílé rẹ̀ sì là á já. Nóà rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run, bí Jóṣúà ṣe wá rí i níkẹyìn. A san èrè fún ìgbàgbọ́ Nóà.
Jèhófà Ti Iṣẹ́ Náà Lẹ́yìn
17. Àwọn ọ̀nà wo ni àkókò tiwa fi bá àwọn ọjọ́ Nóà dọ́gba?
17 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ọjọ́ tiwa yóò da bí ọjọ́ Nóà. Ọlọ́run tún ti pinnu láti pa àwọn ẹni ibi run, ó sì ti ṣètò àkókò tí èyí yóò ṣẹlẹ̀. (Mátíù 24:36-39) Ó tún ti ṣètò ọ̀nà tí òun yóò gbà pa àwọn olódodo mọ́. Bó ṣe jẹ́ pé Nóà ni láti kan áàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ní láti kéde ète Jèhófà, kí wọ́n fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ni, kí wọ́n sì sọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 28:19.
18, 19. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń ti ìwàásù ìhìn rere náà lẹ́yìn?
18 Tí kì í bá ṣe pé Jèhófà wà pẹ̀lú Nóà ni, tó ń tì í lẹ́yìn, tó sì ń fún un lókun, ì bá má ṣeé ṣe fún un láti kan áàkì náà. (Fi wé Sáàmù 127:1.) Bákan náà, tí kò bá sí ìtìlẹ́yìn Jèhófà ni, bóyá ni ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ì bá fi lè dúró, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti pé kó gbèrú. Èyí ni Gàmálíẹ́lì, Farisí kan tí a buyì fún, tó tún jẹ́ olùkọ́ Òfin, jẹ́wọ́ rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Nígbà tí Sànhẹ́dírìn àwọn Júù fẹ́ pa àwọn àpọ́sítélì, ó kìlọ̀ fún ilé ẹjọ́ náà pé: “Ẹ má tojú bọ ọ̀ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ wọn jẹ́ẹ́; (nítorí pé, bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ ènìyàn ni ìpètepèrò tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ kì yóò lè bì wọ́n ṣubú.)”—Ìṣe 5:38, 39.
19 Àṣeyọrí iṣẹ́ ìwàásù náà ní ọ̀rúndún kìíní àti lóde òní, ti fi hàn pé iṣẹ́ yìí kì í ṣe iṣẹ́ ènìyàn, iṣẹ́ Ọlọ́run ni. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jíròrò àwọn ipò tó mórí ẹni yá gágá àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ yìí kẹ́sẹ járí lọ́nà gbígbòòrò bẹ́ẹ̀.
Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Láé!
20. Àwọn wo ló ń tì wá lẹ́yìn bí a ti ń wàásù ìhìn rere náà?
20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ń báṣẹ́ nìṣó lójú méjèèjì. Ó ń ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn, ó sì ń fún wọn lókun bí wọ́n ti ń báa lọ láti parí iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà ṣáájú kí àkókò tí Ọlọ́run yàn láti fòpin sí ètò àwọn nǹkan búburú yìí tó dé. (2 Tímótì 3:1; Mátíù 24:14) Jèhófà ń pè wá láti di “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Ó tún dá wa lójú pé Kristi Jésù wà pẹ̀lú wa nínú iṣẹ́ yìí, àti pé a lè gbẹ́kẹ̀ lé ìtìlẹ́yìn àti ìdarí àwọn áńgẹ́lì.—Mátíù 28:20; Ìṣípayá 14:6.
21. Ìdánilójú wo la ní, tí kò sì yẹ ká juwọ́ sílẹ̀ nínú rẹ̀ láé?
21 Ìgbàgbọ́ tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ lò nínú àwọn ìlérí Jèhófà ló mú kí wọ́n la ìkún omi já. Àwọn tí wọ́n lo irú ìgbàgbọ́ kan náà lónìí yóò la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ já. (Ìṣípayá 7:14) Ní ti tòótọ́, àkókò amóríyá là ń gbé. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì ṣì wà níwájú o! Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò gbégbèésẹ̀ láti mú ọ̀run tuntun ológo àti ayé tuntun tí òdodo ń gbé wá. (2 Pétérù 3:13) Jọ̀wọ́, má ṣe juwọ́ sílẹ̀ láé nínú ìdánilójú tí o ní pé, ohunkóhun tí Ọlọ́run bá sọ, ló lágbára láti ṣe.—Róòmù 4:21.
Àwọn Kókó Tó Yẹ Ká Rántí
◻ Èé ṣe tí Jèhófà kì í darí gbogbo ìgbòkègbodò ènìyàn?
◻ Báwo ni agbára tí Jèhófà ní láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ ṣe hàn gbangba nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì?
◻ Báwo ni agbára tí Jèhófà ní láti rí ọjọ́ iwájú ṣe hàn kedere ní ọjọ́ Nóà?
◻ Ìgbẹ́kẹ̀lé wo la lè ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run?