Bíbélì Dáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Kàn Wá Gbọ̀ngbọ̀n Lóde Òní
ǸJẸ́ Bíbélì bá ìgbà wa yìí mu? Kí a tó lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, dandan ni kí ìwé àtayébáyé yìí máa tọ́ àwọn tó ń kà á sọ́nà nípa àwọn nǹkan tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn, tó sì bá ìgbà wọn mu. Ǹjẹ́ Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn tó ṣàǹfààní nípa àwọn nǹkan tó kan àwọn èèyàn gbọ̀ngbọ̀n láyé táa wà yìí?
Ẹ jẹ́ ká wo kókó pàtàkì méjì tó wà nílẹ̀ báyìí. Bí a ti ń bá ọ̀rọ̀ lọ, a ó ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn wọ̀nyí.
Èé Ṣe Tí Ọlọ́run Fàyè Gba Ìjìyà?
Lójú àwọn ipò tó wà láyé lónìí, ọ̀kan lára ìbéèrè tó wọ́pọ̀ jù lọ ni: Èé ṣe tí Ọlọ́run fi ń jẹ́ kí àwọn aláìṣẹ̀ jìyà? Ìbéèrè tó sì yẹ kéèyàn béèrè ni, nítorí pé ṣe làwọn èèyàn púpọ̀ sí i ń fojú winá ìwà ọ̀daràn tó burú jáì, ìwà ìbàjẹ́, pípa odindi ẹ̀yà run, àgbákò lọ́tùn-ún lósì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Fún àpẹẹrẹ, ní June 1998, ṣe ni rélùwéè kan tí kì í dúró gbérò lọ́nà lọ sẹrí mọ́ afárá kan ní àríwá Jámánì, ó lé ní ọgọ́rùn-ún èrò ọkọ̀ tó ṣègbé nínú jàǹbá yẹn. Ọ̀ràn àwọn òkú tó sùn lọ bíi rẹ́rẹ tojú sú àwọn ògbóǹkangí oníṣègùn àtàwọn panápaná tó lọ ṣaájò àwọn tó fara pa, tí wọ́n sì lọ gbé òkú. Bíṣọ́ọ̀bù Ìjọ Ajíhìnrere kan béèrè pé: “Ìwọ Ọlọ́run Ọba, Kí ló dé ti irú èyí fi ṣẹlẹ̀?” Bíṣọ́ọ̀bù alára kò mọ ìdáhùn náà.
Ìrírí fi hàn pé ọkàn àwọn aláìṣẹ̀ máa ń gbọgbẹ́ nígbà tí wọ́n bá jìyà ibi láìmọ ohun tó fà á. Ibi tí Bíbélì ti lè ṣèrànwọ́ rèé, torí pé ó ṣàlàyé ìdí táwọn aláìṣẹ̀ fi ń fojú winá ìwà ìkà àti ìjìyà.
Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé àti ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀, kì í ṣe ète rẹ̀ pé kí ìwà ibi àti ìjìyà máa fìtínà aráyé. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé nígbà tó parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀, “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ, ‘Bí mo bá rí ohun tó burú, ṣé màá sọ pé ó “dára gan-an”?’ Ó tì o! Lọ́nà kan náà, nígbà tí Ọlọ́run sọ pé gbogbo ohun tóun dá “dára gan-an,” kò sí ìwà ibi kankan lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, nígbà wo ni ìwà ibi bẹ̀rẹ̀, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀?
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run ṣẹ̀dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, tí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára kan tọ obìnrin náà wá, tó fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò ṣòótọ́ àti pé kò lẹ́tọ̀ọ́ sí ipò ọba aláṣẹ àgbáyé. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Ẹ̀dá yìí, Sátánì Èṣù, tún sọ lẹ́yìn ìgbà náà pé tí ìpọ́njú bá dé bá ènìyàn, kíá ló máa gbàgbé Ọlọ́run. (Jóòbù 2:1-5) Kí ni Jèhófà ṣe sóhun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Ó na sùúrù sí i ni, ó jẹ́ kí àkókò tó pọ̀ kọjá kí ó lè hàn kedere pé èèyàn kò lè darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀ láìjẹ́ pé Ọlọ́run lọ́wọ́ sí i. (Jeremáyà 10:23) Nígbà táwọn ẹ̀dá bá gbé ìgbésẹ̀ tó lòdì sófin àti ìlànà Ọlọ́run, ẹ̀ṣẹ̀ ló máa ń yọrí sí, èyí ló sì máa ń fa àgbákò. (Oníwàásù 8:9; 1 Jòhánù 3:4) Àmọ́ o, lójú ìpọ́njú wọ̀nyí pàápàá, Jèhófà mọ̀ pé àwọn kan lára ẹ̀dá ènìyàn yóò pa ìwà títọ́ mọ́ sí òun.
Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà ló ti kọjá báyìí, látìgbà tí ọ̀tẹ̀ burúkú yẹn ti ṣẹlẹ̀ lọ́gbà Édẹ́nì. Ǹjẹ́ ìyẹn ò ti pẹ́ jù? Jèhófà ì bá ti pa Sátánì àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ run tipẹ́tipẹ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀rí kò ha fi hàn pé ohun tó dáa ni láti dúró títí a ó fi mú gbogbo iyèméjì kúrò nípa ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní sí ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, ká sì tún rí i pé àwọn ènìyàn kan kò ní sẹ́ ẹ? Lóde òní, ǹjẹ́ kì í gba ilé ẹjọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó dá ẹjọ́ àre tàbí ti ẹ̀bi?
Lójú ìwòye ìjẹ́pàtàkì ọ̀ràn yìí, tó kan Jèhófà àti aráyé—ìyẹn, ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ àgbáyé àti ìwà títọ́ ẹ̀dá ènìyàn—àbí ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu gan-an pé Ọlọ́run fàkókò sílẹ̀! Àwa náà kúkú ti rójú ayé báyìí, a ti róhun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá pa òfin Ọlọ́run tì, tí wọ́n sì ń ṣe bó ṣe wù wọ́n. Nǹkan burúkú ló máa ń dá sílẹ̀ kárí ayé. Ìdí sì nìyí tí ọ̀pọ̀ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ fi ń jìyà lónìí.
Àmọ́, ọ̀rọ̀ wa ti fẹ́ dayọ̀ o, nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ìwà ibi kò ní máa bá a lọ títí ayé. Lọ́rọ̀ kan, láìpẹ́ Jèhófà yóò mú ìwà ibi àtàwọn tó ń fi ṣèwà hù kúrò. Ìwé Òwe 2:22 sọ pé: “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.” Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run lè máa retí àkókò náà, tó kù sí dẹ̀dẹ̀ báyìí, nígbà tí “ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.
Ṣé a wá rí i báyìí pé kedere ni Bíbélì ṣàlàyé ìdí táwọn aláìṣẹ̀ fi ń jìyà. Ó tún mú un dá wa lójú pé ìwà ibi àti ìjìyà yóò dópin láìpẹ́. Ṣùgbọ́n o, bí onírúurú ìṣòro ti ń bá wa fínra báyìí, a ń fẹ́ ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì míì.
Kí Ni Ète Ìgbésí Ayé?
Ju ti ìgbàkígbà rí lọ nínú ìtàn aráyé, ó jọ pé ìgbà yìí làwọn èèyàn ń làkàkà jù lọ láti mọ ète tí a fi wà láàyè. Ọ̀pọ̀ ń bi ara wọn léèrè pé, ‘Kí ni mo wà láyé fún? Báwo ni ìgbésí ayé mi ṣe lè lójú?’ Onírúurú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ló ń mú wọn béèrè ìbéèrè wọ̀nyí.
Bóyá àjálù tó já lu ẹnì kan ló fayé sú onítọ̀hún. Fún àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1998, wọ́n jí ọmọdébìnrin ọlọ́dún méjìlá kan tí ń gbé nílùú Bavaria, ní Jámánì gbé, wọ́n sì pa á. Ọdún kan lẹ́yìn náà, ìyá ọmọ náà sọ pé ojoojúmọ́ ayé lòun fi ń wádìí nípa ète ìgbésí ayé—síbẹ̀ ó lóun ò tíì rí i. Àwọn ọ̀dọ́ kan pẹ̀lú ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìgbésí ayé wà fún. Wọ́n ń wá ààbò, àṣeyọrí, kí wọ́n sì rẹ́ni fojú jọ, ṣùgbọ́n àgàbàgebè àti ìwà ìbàjẹ́ ni wọ́n ń rí níbi gbogbo, ó sì ń bà wọ́n nínú jẹ́. Ní tàwọn míì, iṣẹ́ ni wọ́n gbájú mọ́, ṣùgbọ́n ìgbẹ̀yìn ló máa tó yé wọn pé agbára, ipò ọlá, àti dúkìá kò lè paná ìfẹ́ tí wọ́n ní láti tọpinpin ìdí tí wọ́n fi wà láàyè.
Ohun yòówù kó máa sún èèyàn láti wádìí ète ìgbésí ayé, ìbéèrè yìí ṣì ń fẹ́ ìdáhùn tó múná dóko, tó sì tẹ́ni lọ́rùn. Níbí yìí pẹ̀lú, Bíbélì wúlò gan-an. Ó sọ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó ní ète, ẹni tí kì í dédé ṣe nǹkan láìnídìí. Ìbéèrè kan rèé, Ǹjẹ́ o lè dédé bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé láìnídìí? Kò jọ bẹ́ẹ̀ rárá, nítorí pé ilé kíkọ́ ń náni lówó gan-an, ó sì lè gba ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún kéèyàn tó kọ́ ọ tán. Ìdí tóo fi ń kọ́lé ni kí ìwọ tàbí ẹlòmíràn lè máa gbé inú rẹ̀. Bí ọ̀ràn ti Jèhófà ṣe rí náà nìyẹn. Gbogbo làálàá tó ṣe nígbà tó ń dá ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun alààyè tí ń bẹ nínú rẹ̀ kì í ṣe láìnídìí, tàbí láìní ète. (Fi wé Hébérù 3:4.) Kí ni ète tó fi dá ilẹ̀ ayé?
Wòlíì Aísáyà pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀.” Àní, òun ni “Ẹni tí ó fìdí [ilẹ̀ ayé] múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Bẹ́ẹ̀ ni o, látìgbà tí Jèhófà ti dá ilẹ̀ ayé ló ti jẹ́ ète rẹ̀ pé kí a máa gbé inú rẹ̀. Sáàmù 115:16 sọ pé: “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, Ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” Ìdí nìyí tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà dá ilẹ̀ ayé kí àwọn èèyàn onígbọràn tí yóò máa bójú tó o lè máa gbé inú rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28.
Ṣé ọ̀tẹ̀ Ádámù àti Éfà kò ti jẹ́ kí Jèhófà yí ète rẹ̀ padà báyìí? Ó tì o. Báwo ló ṣe dá wa lójú pé bẹ́ẹ̀ ló rí? Tóò, gbé kókó yìí yẹ̀ wò: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ náà ní Édẹ́nì ni a kọ Bíbélì. Ká ní Ọlọ́run ti pa ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tì ni, kí ló dé tí Bíbélì kò sọ bẹ́ẹ̀? Ó ṣe kedere pé ète rẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti aráyé kò yí padà.
Ìyẹn nìkan kọ́ o, ète Jèhófà kò kùnà rí. Nípasẹ̀ Aísáyà, Ọlọ́run fún wa ní ìdánilójú yìí: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ti ń rọ̀, àti ìrì dídì, láti ọ̀run, tí kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin ní tòótọ́, kí ó sì mú kí ó méso jáde, kí ó sì rú jáde, tí a sì fi irúgbìn fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún olùjẹ ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:10, 11.
Ohun Tí Ọlọ́run Ń Retí Látọ̀dọ̀ Wa
Dájúdájú a lè ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọ́run yóò mú ète rẹ̀ ṣẹ, pé àwọn èèyàn onígbọràn ni yóò máa gbé ilẹ̀ ayé títí láé. Bí a óò bá wà lára àwọn tí yóò láǹfààní láti máa gbé orí ilẹ̀ ayé títí lọ, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba sọ, ó ní: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13; Jòhánù 17:3.
Gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ète Jèhófà fáráyé túmọ̀ sí mímọ Ọlọ́run tòótọ́ àti mímú ìgbésí ayé wa bá ohun tó béèrè nínú Ìwé Mímọ́ mu. Bí a bá ń ṣe èyí nísinsìnyí, a lè ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí párádísè ilẹ̀ ayé, níbi tí a kò ti ní ṣíwọ́ kíkọ́ nǹkan tuntun nípa Ọlọ́run àtàwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ àgbàyanu. (Lúùkù 23:43) Ìrètí yìí mà ga o!
Ọ̀pọ̀ tó ń fẹ́ kí ìgbésí ayé àwọn ní ète ló ń yíjú sí Bíbélì, wọ́n sì ń ní ayọ̀ ńláǹlà, àní nísinsìnyí pàápàá. Fún àpẹẹrẹ, ìgbésí ayé ọ̀dọ́mọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alfred kò lójú. Ó kórìíra bí ẹ̀sìn ti ń lọ́wọ́ sí ogun, àgàbàgebè àti ìwà ìbàjẹ́ àwọn òṣèlú sì ń bí i nínú. Alfred ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará Íńdíà tí ń gbé ní Àríwá Amẹ́ríkà nítorí ó rò pé òun á lè tibẹ̀ mòye ète ìgbésí ayé, ṣùgbọ́n nígbà tó sú u, ṣe ló padà sí Yúróòpù. Nígbà táyé wá sú u, ó bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn egbòogi olóró, ó sì ń gbọ́ àwọn orin burúkú. Àmọ́ o, nígbà tó ṣe, Alfred fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Bíbélì fínnífínní, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti mọ ojúlówó ète ìgbésí ayé, ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́.
Ìmọ́lẹ̀ Àtàtà Tó Tàn sí Òpópónà Wa
Kí wá ló yẹ kó jẹ́ èrò wa báyìí nípa Bíbélì? Ǹjẹ́ ó wúlò lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wúlò, nítorí pé ó ń tọ́ wa sọ́nà nípa àwọn ohun tó ń lọ lọ́wọ́. Bíbélì ṣàlàyé pé kì í ṣe Ọlọ́run ló fa ìwà ibi, ó sì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa ní ète tó ṣe gúnmọ́. Ìyẹn nìkan kọ́, Bíbélì tún ṣe àlàyé tó kún nípa àwọn ọ̀ràn míì tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn lónìí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé nípa àwọn kókó ọ̀rọ̀ bí ìgbéyàwó, ọmọ títọ́, àjọṣepọ̀ ẹ̀dá, àti ìrètí tó wà fáwọn òkú.
Bí o ò bá tíì fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú Bíbélì, jọ̀wọ́ wá àyè ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tóo bá rí bí àwọn ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ti wúlò tó nínú ìgbésí ayé, èrò rẹ lè wá bá ti onísáàmù náà mu, ẹni tó ń gba ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, tó sì kọ ọ́ lórin pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.”—Sáàmù 119:105.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Ọlọ́run fi yọ̀ǹda kí àwọn aláìṣẹ̀ máa jìyà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
O lè gbádùn ìgbésí ayé tó ní ète