Cyril Lucaris—Ọkùnrin Tó Mọyì Bíbélì
Lọ́jọ́ kan nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1638. Jìnnìjìnnì bá àwọn apẹja tó wà lójú agbami Òkun Marmara nítòsí Constantinople (ibi tí à ń pè ní Istanbul lónìí), tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ ọba Ottoman, nígbà tí wọ́n rí òkú èèyàn tó léfòó sórí omi. Nígbà tí wọ́n wo òkú náà láwòfín, ẹ̀rù bà wọ́n láti mọ̀ pé bíṣọ́ọ̀bù Constantinople, ẹni tó jẹ́ olórí Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, ni àwọn kan ti yín lọ́rùn pa. Báwọn èèyàn ṣe dá ẹ̀mí Cyril Lucaris légbodò nìyẹn, gbajúmọ̀ sì lọkùnrin yìí láàárín àwọn ẹlẹ́sìn tó wà ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún.
LUCARIS kò pẹ́ láyé kó lè fojú ara rẹ̀ rí ìmúṣẹ ohun tó ní lọ́kàn—ìyẹn ni títẹ Ìwé Mímọ́ Kristẹni jáde lédèe Gíríìkì tí gbogbo èèyàn ń sọ nígbà yẹn. Ohun mìíràn tí Lucaris tún ní lọ́kàn láti ṣe ò tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá—ìyẹn ni rírí i pé Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì padà di ìjọ tó ní “ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tó ṣe tààrà.” Ta lọkùnrin yìí? Kí làwọn ìṣòro tó dojú kọ nínú akitiyan rẹ̀?
Àìmọ̀wé Àwọn Kan Yà Á Lẹ́nu
A bí Cyril Lucaris lọ́dún 1572. Venice (táa mọ̀ sí Iráklion báyìí), táwọn ará Candia ti gbà, tó wà ní Kírétè la bí i sí. Nítorí tó lẹ́bùn tó pọ̀, ó kàwé ní Venice àti Padua nílẹ̀ Ítálì, lẹ́yìn ìyẹn ló lọ káàkiri orílẹ̀-èdè náà àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Tìtorí inú tó ń bí i sí ìyapa tó wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì tirẹ̀ àti pé ohun táwọn ẹgbẹ́ alátùn-únṣe ẹ̀sìn ń ṣe ní Yúróòpù wù ú, ó ṣeé ṣe kó ti lọ́ ṣèbẹ̀wò sí Geneva, níbi táwọn ọmọlẹ́yìn Calvin ti gbà nígbà yẹn.
Nígbà tí Lucaris lọ sí Poland, ó rí i pé àìmọ̀wé ti sọ ipò tẹ̀mí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tó wà níbẹ̀ dìdàkudà. Nígbà tó padà wá sí Alẹkisáńdíríà àti Constantinople, ó yà á lẹ́nu láti rí i pé, wọ́n ti gbé àga ìwàásù, ìyẹn ni orí ibi tí wọ́n ń dúró sí ka Ìwé Mímọ́, kúrò nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan!
Nígbà tó di 1602, Lucaris lọ sí Alẹkisáńdíríà, ibẹ̀ ló ti wá gbapò mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan, Bíṣọ́ọ̀bù Meletios, nínú ìjọ tó wà níbẹ̀. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí àwọn onírúurú ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn, àwọn alátùn-únṣe ẹ̀sìn tí wọ́n wà ní Yúróòpù. Nínú ọ̀kan nínú lẹ́tà tó kọ, ó sọ níbẹ̀ pé, onírúurú àṣà tó lòdì pátápátá ní Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì fàyè gbà. Nínú lẹ́tà mìíràn, ó tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì pé kí ìjọ náà fi “ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tó ṣe tààrà” rọ́pò ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, kí wọ́n sì rí i pé àṣẹ Ìwé Mímọ́ nìkan ṣoṣo làwọ́n gbára lé.
Ó tún ya Lucaris lẹ́nu pé ojú tí wọ́n fi ń wo àṣẹ tí àwọn Baba Ṣọ́ọ̀ṣì ń lò lórí ìjọ náà ni wọ́n fi ń wo àwọn ọ̀rọ̀ Jésù àti ti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ó ti sú mi láti máa gbọ́ kí àwọn èèyàn máa sọ pé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí ènìyàn gbé kalẹ̀ bá Ìwé Mímọ́ dọ́gba.” (Mátíù 15:6) Ó fi kún un pé, lérò tòun o, jíjọ́sìn ère burú jáì. Gẹ́gẹ́ bí àkíyèsí rẹ̀, gbígbàdúrà sí “àwọn ẹni mímọ́” tàbùkù Alárinà náà, Jésù.—1 Tímótì 2:5.
Wọ́n Gbé Oyè Bíṣọ́ọ̀bù Lọ Sórí Àtẹ
Àwọn èrò tó ní wọ̀nyẹn àti ìkórìíra tó ní sí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì, sọ Lucaris di ọ̀tá àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit àtàwọn Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tó fara mọ́ bíbá àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ṣe nǹkan pọ̀, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí i. Pẹ̀lú bí àtakò yẹn ṣe le tó, wọ́n yan Lucaris sípò bíṣọ́ọ̀bù Constantinople lọ́dún 1620. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Ilẹ̀ Ọba Ottoman ló máa ń yan bíṣọ́ọ̀bù Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Ìjọba Ottoman lè rọ bíṣọ́ọ̀bù kan lóyè, wọ́n sì lè yan tuntun, ó sinmi lórí bí owó bá ṣe wà lọ́wọ́ àwọn tó bá ń dupò náà tó.
Ni àwọn ọ̀tá Lucaris bá bẹ̀rẹ̀ sí bà á lórúkọ jẹ́ kiri, tí wọ́n sì ń dìtẹ̀ mọ́ ọn, pàápàá jù lọ àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit àtàwọn àlùfáà àgbà tágbára ń bẹ lọ́wọ́ wọn, táwọn èèyàn sì ń bẹ̀rù, àwọn tí wọ́n ń pè ní Congregatio de Propaganda Fide (Ìgbìmọ̀ Agbẹ́sìnga). Ìwé náà, Kyrillos Loukaris, sọ pé: “Láti lè kẹ́sẹ járí nínú ohun tí wọ́n dáwọ́ lé yìí, àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit lo gbogbo ọ̀nà tí wọ́n lè lò—ọgbọ́n àrékérekè, irọ́ burúkú, àpọ́nlé orí ahọ́n lásán, pabanbarì nínú ohun tí wọ́n ṣe ni fífúnni ní rìbá, èyí tó jẹ́ ohun èlò tó gbéṣẹ́ jù lọ láti fa ojú àwọn àgbà òṣèlú [ilẹ̀ Ottoman] mọ́ra.” Ní àbárèbábọ̀ rẹ̀, lọ́dún 1622, wọ́n lé Lucaris lọ sí erékùṣù Rhodes, ni Gregory ti Amasya bá fi ọ̀kẹ́ kan owó fàdákà ra ipò náà. Àmọ́, Gregory kò rí iye tó ṣèlérí gbé sílẹ̀, ni Anthimus ti Adrianople bá ra ipò ọ̀hún, kò sì pẹ́ tóun náà tún fi kọ̀wé fi ipò náà sílẹ̀. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ nígbà tí wọ́n tún padà yan Lucaris sí ipò yẹn.
Lucaris pinnu láti lo àǹfààní tuntun tó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ yìí láti kó ìmọ̀ sọ́pọlọ àwọn àlùfáà Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àti àwọn ọmọ ìjọ wọn nípa títẹ Bíbélì kan tó túmọ̀ àti àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tó jẹ́ ti ẹ̀sìn jáde. Kí iṣẹ́ yìí lè kẹ́sẹ járí, ó ṣètò láti gbé ẹ̀rọ ìtẹ̀wé wọ Constantinople, ó lo ọlá aṣojú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀rọ náà dé ní June ọdún 1627, àwọn ọ̀tá Lucaris fẹ̀sùn kàn án pé tìtorí ọ̀ràn ìṣèlú ló ṣe gbé e wọ̀lú, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n bà á jẹ́. Lucaris ní láti lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó wà ní Geneva.
Ìtumọ̀ ti Ìwé Mímọ́ Kristẹni
Ọ̀wọ̀ gíga tí Lucaris ní fún Bíbélì àti agbára tó mọ̀ pé Bíbélì ní ló túbọ̀ mú kí ìfẹ́ rẹ̀ gbóná sí i láti jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn gbáàtúù. Ó mọ̀ pé èdè táa lò nínú Bíbélì Gíríìkì ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò yé ọ̀pọ̀ èèyàn mọ́. Nítorí náà, ìwé tí Lucaris kọ́kọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n túmọ̀ ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó ní kí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Gíríìkì tí wọ́n ń sọ ní ìgbà ayé rẹ̀. Maximus Callipolites, ọ̀mọ̀wé kan tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé, ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ní March 1629. Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ló gbà pé àṣejù ló jẹ́ fún ẹnì kan láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́, bó ti wù kí ó nira tó fún àwọn tó ń kà á láti lóye. Láti pẹ̀tù sí wọn lọ́kàn, Lucaris jẹ́ kí àwọn ẹsẹ tó wá láti inú ìtumọ̀ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wà ní ẹ̀gbẹ́ ìtumọ̀ tó bóde mu, ó wá fi àlàyé díẹ̀ kún un. Nítorí pé kò pẹ́ tí Callipolites kú lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ náà, Lucaris fúnra rẹ̀ ló kà á, láti yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní. Ọdún 1638, kété lẹ́yìn tí Lucaris fúnra rẹ̀ kú la tó tẹ ìtumọ̀ yìí jáde.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Lucaris lo ìṣọ́ra gan-an, ọ̀pọ̀ bíṣọ́ọ̀bù ló tako ìtumọ̀ náà. Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ inú ìtumọ̀ náà, ó hàn gbangba-gbàǹgbà pé Lucaris nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé Ìwé Mímọ́, táa kọ ní èdè ìbílẹ̀ àwọn ènìyàn, ni “ọ̀rọ̀ atunilára, táa fi fún wa láti ọ̀run.” Ó gba àwọn èèyàn níyànjú pé “kí wọ́n sapá láti mọ gbogbo ohun tí ń bẹ nínú [Bíbélì],” ó sì tún wí pé, kò tún sí ọ̀nà mìíràn táa fi lè kọ́ nípa “àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ ní tààràtà . . . èyí táa tọ́jú nípasẹ̀ Ìhìn Rere mímọ́ tó ti ọ̀run wá.”—Fílípì 1:9, 10.
Lucaris dẹ́bi fún àwọn tó ní káwọn èèyàn má ka Bíbélì àtàwọn tí kò gba ti ìtumọ̀ ìwé ìpilẹ̀ṣẹ̀ táa ṣe, ó ní: “Báa bá sọ̀rọ̀ tàbí kàwé tí kò sì sí ẹni tó lóye rẹ̀, ńṣe ló dà bí ẹni ń sọ̀rọ̀ sí atẹ́gùn lásán.” (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 14:7-9.) Nígbà tó ń mú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ náà wá síparí, ó kọ̀wé pé: “Bóo ṣe ń ka Ìhìn Rere mímọ́ tó ti ọ̀run wá yìí ní èdè tìrẹ, ronú nípa àǹfààní tóo jẹ nípa kíkà á, . . . ǹjẹ́ kí Ọlọ́run máa ṣamọ̀nà rẹ̀ sí rere.”—Òwe 4:18.
Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́
Lẹ́yìn tí Lucaris ti gbé ìgbésẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ títúmọ̀ Bíbélì yẹn, ó gbé ìgbésẹ̀ mìíràn tó gba ìgboyà. Ní ọdún 1629, ó tẹ ìwé Confession of Faith (Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́) jáde ní Geneva. Ìwé náà kún fún àwọn ohun tí òun alára gbà gbọ́ tó sì retí pé kí Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tẹ́wọ́ gbà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, The Orthodox Church, ti sọ, ìwé náà, Confession “járọ́ tó wà nínú ìgbàgbọ́ Ìjọ Ọ́tọ́ọ́dọ̀sì nípa ipò àwọn àlùfáà àti bí wọ́n ṣe wà ní ìpele-ìpele, ó bẹnu àtẹ́ lu bíbọlá fún ère àti gbígbàdúrà sí àwọn ẹni mímọ́, ó ní ìbọ̀rìṣà gbáà ló jẹ́.”
Ìwé náà, Confession, ní àpilẹ̀kọ méjìdínlógún nínú. Àpilẹ̀kọ rẹ̀ kejì sọ pé Ọlọ́run ló mí sí kíkọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti pé àṣẹ tí wọ́n ní ju ti ṣọ́ọ̀ṣì lọ. Ó wí pé: “A gbà pé látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Ìwé Mímọ́ ti wá . . . A gbà pé àṣẹ tí Ìwé Mímọ́ ni ga ju ti Ṣọ́ọ̀ṣì lọ. Kí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ yàtọ̀ pátápátá sí pé kí ènìyàn kọ́ni.”—2 Tímótì 3:16.
Àpilẹ̀kọ kẹjọ àti ìkẹwàá sọ pé Jésù Kristi ni Alarinà kan ṣoṣo táa ní, Àlùfáà Àgbà, àti Orí ìjọ. Lucaris kọ̀wé pé: “Àwa gbà pé Jésù Kristi Olúwa wa ti jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Baba Rẹ̀, Ó sì ń ti ibẹ̀ bẹ̀bẹ̀ fún wa, ó di ipò ojúlówó àlùfáà àgbà àti ipò alárinà mú, èyí tó bófin mu.”—Mátíù 23:10.
Àpilẹ̀kọ kejìlá sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì lè ṣìnà, ó lè fi dúdú pe funfun, àmọ́ ìmọ́lẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ lè gbà á sílẹ̀, ìyẹn tí àwọn òjíṣẹ́ ẹ̀sìn náà bá ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ kejìdínlógún, Lucaris sọ pé àròsọ lásán ni pọ́gátórì jẹ́, ó ní: “Ó hàn gbangba pé a kò ní tẹ́wọ́ gba àròsọ pọ́gátórì.”
Àsomọ́ tó wà nínú ìwé Confession, kún fún ọ̀pọ̀ ìbéèrè àti ìdáhùn. Ibẹ̀ ni Lucaris ti kọ́kọ́ tẹnu mọ́ ọn pé gbogbo olóòótọ́ ló gbọ́dọ̀ ka Ìwé Mímọ́ àti pé ó léwu bí Kristẹni kan kò bá ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó wá fi kún un pé a gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ìwé Àpókírífà.—Ìṣípayá 22:18, 19.
Ìbéèrè kẹrin sọ pé: “Ojú wo ló yẹ ká fi máa wo àwọn ère ìsìn?” Lucaris dáhùn pé: “Ọlọ́run àti Ìwé Mímọ́ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ya èrekére fún ara rẹ, tàbí ohun tó jọ ohunkóhun tó wà ní òkè ọ̀run, tàbí èyí tó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé; ìwọ kò gbọ́dọ̀ bọlá fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n; [Ẹ́kísódù 20:4, 5]’ níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá nìkan ṣoṣo, Ẹni tó dá ọ̀run òun ayé ló yẹ ká jọ́sìn tí kì í ṣe ẹ̀dá, nígbà náà, Òun nìkan ló yẹ ká máa sin. . . . Jíjọ́sìn àti jíjúbà [àwọn ère ìsìn] èyí tí Ìwé Mímọ́ kà léèwọ̀ là ń ṣe, ṣùgbọ́n o, ẹ máà jẹ́ ká gbàgbé pé Ẹlẹ́dàá àti Adẹ́dàá ló yẹ ká máa jọ́sìn, dípò tí a ó fi máa jọ́sìn àwọ̀, iṣẹ́ ọnà, àti ẹ̀dá.”—Ìṣe 17:29.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Lucaris kò lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ gbogbo àṣìṣe náà nígbà ayé rẹ̀, ìyẹn nígbà sànmánì òkùnkùn nípa tẹ̀mí, a síbẹ̀, ó ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà láti rí i pé Bíbélì ní àṣẹ lórí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì àti pé a fi ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn.
Kété lẹ́yìn tí Lucaris mú ìwé Confession, jáde, ni àtakò tó gbóná girigiri tún dìde. Ní ọdún 1633, Cyril Contari, olórí ìlú Bèróà (tí a ń pè ní Aleppo báyìí), ẹnì tó jẹ́ ọ̀tá Lucaris ní ti gidi, tí àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit sì ń ràn lọ́wọ́, gbìyànjú láti bá ìjọba ilẹ̀ Ottoman dì í, kí wọ́n lè gbé òye bíṣọ́ọ̀bù fún òun. Àmọ́, ète náà forí ṣánpọ́n nígbà tí Contari kò rówó san. Ní Lucaris bá ń lo ipò náà lọ. Nígbà tó tún di ọdún kejì, Athanasius ti Tẹsalóníkà san ọ̀kẹ́ mẹ́ta owó fàdákà kó lè rí ipò yìí gbà. Ni wọ́n bá tún rọ Lucaris lóyè. Ṣùgbọ́n láàárín oṣù kan, wọ́n pè é padà, wọ́n sì gbé oyè rẹ̀ fún un padà. Nígbà tó fi máa di àkókò yìí, Cyril Contari ti kó ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ owó fàdákà jọ. Ìgbà yìí ni wọ́n lé Lucaris lọ sí Rhodes. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣètò, wọ́n sì pè é padà wá sílé.
Ṣùgbọ́n, lọ́dún 1638, àwọn ẹlẹ́sìn Jesuit àti àwọn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì pawọ́ pọ̀, wọ́n fẹ̀sùn kan Lucaris pé ó fẹ́ dojú ìjọba ilẹ̀ Ottoman bolẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, ọbá wọn pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa á. Ní wọ́n bá fi ọlọ́pàá mú Lucaris, nígbà tó sì di July 27, 1638, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi wà á lọ bí ẹni pé wọ́n fẹ́ gbé e lọ sí ilẹ̀ mìíràn. Bí ọkọ̀ náà ṣe dójú agbami, ni wọ́n bá yín in lọ́rùn. Wọ́n sin òkú rẹ̀ sí etíkun náà, nígbà tó yá, wọ́n tún wá wú u jáde, wọ́n sì jù ú sínú òkun. Àwọn apẹja ló padà wá rí òkú náà, kó tó di pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣètò bí wọ́n ṣe sin ín.
Ẹ̀kọ́ Táa Rí Kọ́
Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Kò yẹ ká gbójú fò ó pé ọ̀kan lára olórí ète [Lucaris] ni láti la àwọn àlùfáà àti agbo wọn lóye, kó sì jẹ́ kí ìmọ̀ wọn gbé pẹ́ẹ́lí sí i, nítorí pé ní ọ̀rúndún kẹfà àti ní kùtùkùtù ìkeje, ìmọ̀ ti tán lọ́pọlọ wọn pátápátá.” Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìṣòro ni kò jẹ́ kí Lucaris lé góńgó rẹ̀ bá. Ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n rọ̀ ọ́ lóyè bíṣọ́ọ̀bù. Nígbà tó di ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lẹ́yìn ikú rẹ̀, ẹgbẹ́ alákòóso ṣọ́ọ̀ṣì ní Jerúsálẹ́mù sọ pé gbogbo ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́ àdámọ̀ lásán. Wọ́n kéde pé “kì í ṣe ẹnikẹ́ni ló lè máa ka” Ìwé Mímọ́, “àyàfi kìkì àwọn tó fẹ́ wo ohun tẹ̀mí láwòfín lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe ìwádìí tó yẹ ní ṣíṣe tán”—ìyẹn ni, àwọn àlùfáà táa gbà pé àwọn ni ọ̀mọ̀wé ayé.
Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn ti bomi paná ìsapá náà láti jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tẹ agbo wọn lọ́wọ́. Wọ́n fi tìpá-tìkúùkù pa ẹni tó fẹ́ tọ́ka sí àwọn àṣìṣe ìgbàgbọ́ wọn tí kò bá Bíbélì mu lẹ́nu mọ́. Wọ́n fi hàn pé àwọn ni ọ̀tá tó burú jù lọ tí kò fẹ́ kí òmìnira ìsìn gbérí, tí wọ́n sì fẹ́ tẹ òtítọ́ rì. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé, ẹ̀mí burúkú yìí ṣì wà títí di òní olónìí. Tí èèyàn bá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn àlùfáà bá dá wàhálà sílẹ̀ nítorí àtidènà òmìnira ìrònú àti ọ̀rọ̀ sísọ, ó máa ń múni sorí kọ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ìwé rẹ̀, Confession, ó fara mọ́ ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan àti ẹ̀kọ́ àyànmọ́ àti àìleèkú ọkàn—gbogbo èyí sì jẹ́ ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Lucaris ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà láti rí i pé Bíbélì ní àṣẹ lórí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì àti pé a fi ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Lucaris àti Ìwé Codex Alexandrinus
Ọ̀kan lára ohun iyebíye tó wà ní Ilé Ìkówèésí ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni ìwé Codex Alexandrinus, ìyẹn ni Bíbélì kan táa fọwọ́ kọ ní ọ̀rúndún kárùn-ún Sànmánì Tiwa. Nínú ojú ìwé okòó lé lẹ́gbẹ̀rin [820] tó ní tẹ́lẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti mẹ́tàléláàádọ́rin[773] ló kù.
Nígbà tí Lucaris ń ṣe bíṣọ́ọ̀bù Alẹkisáńdíríà, ní Íjíbítì, ìwé tó ní kò lóǹkà. Nígbà tó tún di bíṣọ́ọ̀bù ní Constantinople, ó gbé ìwé Codex Alexandrinus lọ́wọ́ lọ. Lọ́dún 1624, ó gbé ìwé náà fún aṣojú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sí ilẹ̀ Turkey gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, James Kìíní. Ọba yìí ló wá gbé e fún ẹni tó jẹ tẹ̀ lé e, ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ìyẹn ni Charles Kìíní.
Lọ́dún 1757, wọ́n gbé ilé Ìkówèésí ti Ọba fún orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìwé àfọwọ́kọ alábala tó pójú owó yìí ti wà ní ibi táa gbé e sí ní Ibi Ìpàtẹ Àwọn Iṣẹ́ Ọnà ti John Ritblat ní Ilé Ìkówèésí ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì táa ṣẹ̀sẹ̀ kọ́.
[Àwọn Credit Line]
Láti inú ìwé The Codex Alexandrinus in Reduced Photographic Facsimile, 1909
Gewerbehalle, Ìdìpọ̀ Kẹwàá
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Bib. Publ. Univ. de Genève