Máa Fi Ìháragàgà Polongo Ìhìn Rere Náà
“Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín. Ẹ máa sìnrú fún Jèhófà.”—RÓÒMÙ 12:11.
1, 2. Ẹ̀mí wo làwọn Kristẹni máa ń sapá láti ní gẹ́gẹ́ bí oníwàásù ìhìn rere?
Ọ̀DỌ́KÙNRIN kan ń yọ̀ ṣìnkìn nítorí iṣẹ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ níbi iṣẹ́, ńṣe ló ń hára gàgà láti gbọ́ ìtọ́ni ọ̀gá rẹ̀. Ojú rẹ̀ wà lọ́nà gan-an láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí wọ́n kọ́kọ́ yàn fún un, gbogbo ara ló sì fi ń ṣe é. Ó múra tán láti sa gbogbo ipá rẹ̀.
2 Lọ́nà kan náà, àwa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni lè fi ara wa wé ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Níwọ̀n bí ìrètí wa ti jẹ́ láti wà láàyè títí láé, a lè sọ pé ṣe la ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ fún Jèhófà. Dájúdájú, iṣẹ́ pọ̀ lóríṣiríṣi tí Ẹlẹ́dàá wa ní lọ́kàn láti gbé fún wa tí a óò jókòó tì títí ayé. Àmọ́ iṣẹ́ àkọ́kọ́ pàá táa rí gbà ni iṣẹ́ pípolongo ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. (1 Tẹsalóníkà 2:4) Ojú wo la fi ń wo iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wa yìí? Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin yẹn, a fẹ́ fi gbogbo agbára àti ìtara wa ṣe é tayọ̀tayọ̀—àní sẹ́, a fẹ́ fi ìháragàgà ṣe é!
3. Kí ni a ní láti ṣe bí a óò bá kẹ́sẹ járí gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere?
3 Ká sòótọ́, níní irú ẹ̀mí rere yẹn gba aápọn. Ní àfikún sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a ní ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ mìíràn tó lè mu wá lómi nípa tara àti ní ti èrò orí. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń yí i mọ́ ọn láìjẹ́ kí nǹkan wọ̀nyí pa iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lára. Àmọ́, kì í sábàá rọrùn. (Máàkù 8:34) Jésù tẹnu mọ́ ọn pé a ó sapá gidigidi bí a óò bá kẹ́sẹ járí gẹ́gẹ́ bí Kristẹni.—Lúùkù 13:24.
4. Báwo ni àwọn àníyàn ojoojúmọ́ ṣe lè nípa lórí ojú ìwòye wa nípa tẹ̀mí?
4 Iṣẹ́ rẹpẹtẹ tó pọ̀ lọ́rùn wa yìí lè mú kí ọkàn wa pòrúurùu tàbí kó rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì. “Àwọn àníyàn ìgbésí ayé” lè paná ìtara àti ìmọrírì táa ní fún àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run. (Lúùkù 21:34, 35; Máàkù 4:18, 19) Nítorí ẹ̀dá aláìpé táa jẹ́, a lè fi ‘ìfẹ́ tí a ní lákọ̀ọ́kọ́’ sílẹ̀. (Ìṣípayá 2:1-4) Àwọn apá kan nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà lè wá di èyí tí a ń fara ṣe tí a kò fọkàn ṣe. Báwo ni Bíbélì ṣe pèsè ìṣírí tí yóò jẹ́ kí iná ìtara wa máa jó fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?
Bí “Iná Tí Ń Jó” Nínú Ọkàn-Àyà Wa
5, 6. Ojú wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi wo àǹfààní tó ní láti wàásù?
5 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wa ti ṣeyebíye ju ohun téèyàn kàn lè kà sí ohun ṣákálá lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ka iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere sí àǹfààní ńláǹlà, ó tiẹ̀ sọ pé òun ò yẹ lẹ́ni tí à ń fi iṣẹ́ náà síkàáwọ́ rẹ̀. Ó ní: “Èmi, ẹni tí ó kéré ju kékeré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́, ni a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí fún, pé kí n polongo ìhìn rere nípa àwọn ọrọ̀ tí kò ṣeé díwọ̀n ti Kristi fún àwọn orílẹ̀-èdè, kí n sì mú kí àwọn ènìyàn rí bí a ṣe ń bójú tó àṣírí ọlọ́wọ̀ tí a ti fi pa mọ́ tipẹ́tipẹ́ sínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo.”—Éfésù 3:8, 9.
6 Ẹ̀mí tó dáa tí Pọ́ọ̀lù ní nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ fún wa. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ pé: “Ìháragàgà wà ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láti polongo ìhìn rere.” Kò tijú ìhìn rere. (Róòmù 1:15, 16) Ó ní ẹ̀mí tó dáa, ó sì hára gàgà láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.
7. Kí ni Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa rẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Róòmù?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí i pé ó pọndandan láti ní ẹ̀mí ìtara, ìyẹn ló jẹ́ kó ṣí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù létí pé: “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín. Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín. Ẹ máa sìnrú fún Jèhófà.” (Róòmù 12:11) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà táa tú sí “ìmẹ́lẹ́” tún ní ìtumọ̀ tó fara pẹ́ ṣíṣe “sìmẹ̀sìmẹ̀, lílọ́ra.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ní ti gidi a lè má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, síbẹ̀ gbogbo wa gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí ó má bàa di pé àwa náà ti fẹ́ máa ṣe sìmẹ̀sìmẹ̀ nípa tẹ̀mí, kí a sì tètè tún ojú ìwòye wa ṣe báa bá ṣàkíyèsí pé ẹ̀mí yẹn ti ń ràn wá.—Òwe 22:3.
8. (a) Kí ló wá dà bí “iná tí ń jó” nínú ọkàn-àyà Jeremáyà, èé sì ti ṣe? (b) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìrírí Jeremáyà?
8 Ẹ̀mí Ọlọ́run tún lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá dé bá wa. Fún àpẹẹrẹ, nígbà kan ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá wòlíì Jeremáyà, ó sì ń ronú àtidáwọ́ iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ dúró. Ó tiẹ̀ sọ nípa Jèhófà pé: “Èmi kì yóò mẹ́nu kàn án, èmi kì yóò sì sọ̀rọ̀ mọ́ ní orúkọ rẹ̀.” Èyí ha fi hàn pé Jeremáyà kò kúnjú ìwọ̀n rárá nípa tẹ̀mí bí? Ó tì o. Ní tòótọ́, ipò tẹ̀mí jíjí pépé tí Jeremáyà wà, ìfẹ́ rẹ̀ fún Jèhófà, àti ìtara rẹ̀ fún òtítọ́ fún un lágbára láti máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nìṣó. Ó ṣàlàyé pé: “Nínú ọkàn-àyà mi, [ọ̀rọ̀ Jèhófà] wá dà bí iná tí ń jó, tí a sé mọ́ inú egungun mi; pípa á mọ́ra sú mi, èmi kò sì lè fara dà á.” (Jeremáyà 20:9) Kò sóhun tó ṣàjèjì nínú kí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò wo ohun tó wà lọ́kàn-àyà wọn, yóò sì yọ̀ǹda ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún wọn ní fàlàlà, ìyẹn bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá wà nínú ọkàn-àyà wọn bó ṣe wà nínú ti Jeremáyà.—Lúùkù 11:9-13; Ìṣe 15:8.
“Ẹ Má Ṣe Pa Iná Ẹ̀mí”
9. Kí ló lè dènà iṣẹ́ tí ẹ̀mí mímọ́ ń ṣe fún ire wa?
9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí àwọn ará Tẹsalóníkà létí pé: “Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.” (1 Tẹsalóníkà 5:19) Dájúdájú, àwọn ìgbésẹ̀ àti ìṣesí tó lòdì sí àwọn ìlànà Ọlọ́run lè dènà àwọn iṣẹ́ tí ẹ̀mí mímọ́ ń ṣe fún ire wa. (Éfésù 4:30) Àwọn Kristẹni lónìí ní ẹrù iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere. Ojú ribiribi la fi ń wo àǹfààní yìí. Kò kúkú yà wá lẹ́nu pé àwọn tí kò mọ Ọlọ́run ń fojú àbùkù wo iṣẹ́ ìwàásù wa. Àmọ́ tí Kristẹni kan bá mọ̀ọ́mọ̀ pa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tì, iná ẹ̀mí Ọlọ́run tí ń sún un ṣiṣẹ́ lè kú pii.
10. (a) Báwo ni èrò àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa ṣe lè nípa lórí wa? (b) Kí ni ojú ìwòye gíga lọ́lá tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 2:17 nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
10 Àwọn kan tó wà lóde ìjọ Kristẹni lè ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sí iṣẹ́ pípín ìwé kiri lásán-làsàn. Àwọn míì lè fi àṣìṣe ronú pé káwọn èèyàn sáà lè ta wá lọ́rẹ la ṣe ń lọ láti ilé dé ilé. Báa bá jẹ́ kírú èrò òdì bẹ́ẹ̀ nípa lórí ìṣarasíhùwà wa, a ò ní lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lọ́nà tó múná dóko mọ́. Kàkà tí a ó fi jẹ́ kírú èrò bẹ́ẹ̀ nípa lórí wa, ẹ jẹ́ ká ní ojú ìwòye tí Jèhófà àti Jésù ní nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ojú ìwòye gíga lọ́lá yẹn jáde nígbà tó polongo pé: “Àwa kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti jẹ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí pẹ̀lú òtítọ́ inú, bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí a ti rán wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ní iwájú Ọlọ́run, ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ni àwa ń sọ̀rọ̀.”—2 Kọ́ríńtì 2:17.
11. Kí ló mú kí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣì jẹ́ onítara lábẹ́ inúnibíni pàápàá, ipa wo ló sì yẹ kí àpẹẹrẹ wọn ní lórí wa?
11 Kété lẹ́yìn ikú Jésù làwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ti bẹ̀rẹ̀ sí fojú winá inúnibíni. Wọ́n halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n sì pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró. Ṣùgbọ́n, Bíbélì sọ pé wọ́n “kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ìṣe 4:17, 21, 31) Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí Tímótì ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà fi ẹ̀mí rere tó yẹ káwọn Kristẹni ní hàn. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú. Nítorí náà, má tijú ẹ̀rí nípa Olúwa wa, tàbí èmi ẹlẹ́wọ̀n nítorí rẹ̀, ṣùgbọ́n kó ipa tìrẹ nínú jíjìyà ibi fún ìhìn rere ní ìbámu pẹ̀lú agbára Ọlọ́run.”—2 Tímótì 1:7, 8.
Kí Ni Ojúṣe Wa sí Àwọn Aládùúgbò Wa?
12. Kí ni ìdí pàtàkì táa fi ń wàásù ìhìn rere náà?
12 Bí a óò bá ní ẹ̀mí tó dáa nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a gbọ́dọ̀ ní ète tí ó tọ́. Èé ṣe táa fi ń wàásù? A rí ìdí pàtàkì táa fi ń wàásù nínú ọ̀rọ̀ onísáàmù náà, pé: “Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò sì máa fi ìbùkún fún ọ [Jèhófà]. Wọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa ògo ipò ọba rẹ, wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa agbára ńlá rẹ, láti sọ àwọn ìṣe agbára ńlá rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn àti ògo ọlá ńlá ipò ọba rẹ̀.” (Sáàmù 145:10-12) Bẹ́ẹ̀ ni, à ń wàásù kí a lè máa yin Jèhófà ní gbangba, kí a sì sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ níwájú gbogbo aráyé. Kódà nígbà tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń fetí sí wa, fífi tí a ń fi ìṣòtítọ́ pòkìkí iṣẹ́ ìgbàlà náà ń mú ìyìn wá fún Jèhófà.
13. Kí ni ó ń gbún wa ní kẹ́sẹ́ láti sọ fáwọn ẹlòmíì nípa ìrètí ìgbàlà?
13 A tún ń wàásù nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn àti nítorí pé a ò fẹ́ jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 33:8; Máàkù 6:34) Èyí tan mọ́ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nígbà tó ń bá àwọn tó wà lóde ìjọ Kristẹni sọ̀rọ̀, pé: “Èmi jẹ́ ajigbèsè sí àwọn Gíríìkì àti àwọn Aláìgbédè, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn òpònú.” (Róòmù 1:14) Pọ́ọ̀lù gbà pé àìgbọ́dọ̀máṣe ló jẹ́ fóun láti polongo ìhìn rere fáwọn èèyàn, nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí “a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là.” (1 Tímótì 2:4) Lónìí, àwa náà ní irú ìfẹ́ yẹn sáwọn aládùúgbò wa, a sì gbà pé àìgbọ́dọ̀máṣe ni láti jẹ́ iṣẹ́ yẹn fún wọn. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní fáráyé ló sún un tó fi rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé kí ó lè kú fún wọn. (Jòhánù 3:16) Ohun tó ṣe yẹn kò kéré rárá. A ń fara wé ìfẹ́ Jèhófà táa bá ń lo àkókò àti ìsapá nínú sísọ fáwọn ẹlòmíràn nípa ìhìn rere ìgbàlà táa gbé karí ẹbọ Jésù.
14. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàlàyé ayé tó wà lóde ìjọ Kristẹni?
14 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wo àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n di apá kan ẹgbẹ́ àwọn ará tí í ṣe Kristẹni. A gbọ́dọ̀ máa fi àìṣojo wàásù, àmọ́ ká má tìtorí pé a fẹ́ jẹ́ aláìṣojo ká wá máa jà o. Òótọ́ ni pé Bíbélì lo àwọn ọ̀rọ̀ líle nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ayé ní gbogbo gbòò. Ọ̀nà tí kò bára dé ni Pọ́ọ̀lù gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ayé” nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “ọgbọ́n ayé yìí” àti “àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé.” (1 Kọ́ríńtì 3:19; Títù 2:12) Pọ́ọ̀lù tún rán àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Éfésù létí pé nígbà tí wọ́n ṣì ń rìn “ní ìbámu pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí,” wọ́n jẹ́ ‘òkú’ nípa tẹ̀mí. (Éfésù 2:1-3) Gbólóhùn wọ̀nyí àtàwọn míì tó dún bákan náà, bá ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù mu, pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.
15. Kí ni a kì í ṣe nípa àwọn èèyàn tó ṣì wà lóde ìjọ Kristẹni, kí sì ni ìdí tí a kì í fi í ṣe bẹ́ẹ̀?
15 Àmọ́ ṣá o, ẹ jẹ́ ká rántí pé ayé ní gbogbo gbòò, tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, ni irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ ń bá wí o, kì í ṣe àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Àwọn Kristẹni kì í ṣe ìdájọ́ kò-dúró-gbẹ́jọ́ nípa ìhà tí olúkúlùkù yóò kọ sí iṣẹ́ ìwàásù. Kò sí ìdí kankan tó yẹ kí wọ́n fi pe ẹnikẹ́ni ní ewúrẹ́. Àwa kọ́ la máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá dé láti wá ya “àwọn àgùntàn” sọ́tọ̀ kúrò lára “àwọn ewúrẹ́.” (Mátíù 25:31-46) Àwa kọ́ ni onídàájọ́; Jésù ni. Yàtọ̀ síyẹn, a ti rí àwọn kan tó ti jingíri sínú ìwà tó burú jáì pàápàá, tí wọ́n wá tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Bíbélì, tí wọ́n yí padà, tí wọ́n sì di Kristẹni oníwà mímọ́. Fún ìdí yìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò ní fẹ́ bá irú àwọn èèyàn kan rìn, síbẹ̀ a ò ní lọ́ tìkọ̀ láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí Ìjọba náà nígbàkigbà táa bá ní àǹfààní rẹ̀. Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn kan tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣì jẹ́ aláìgbàgbọ́, wọ́n “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” Wọ́n di onígbàgbọ́ ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. (Ìṣe 13:48) Nípa báyìí, a ò lè mọ àwọn tó ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ láìjẹ́ pé a wàásù fún wọn—bóyá léraléra pàápàá. Báa bá ní èyí lọ́kàn, a óò máa fi “ìwà tútù” àti “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” bá àwọn tí kò tíì tẹ́wọ́ gba ìhìn rere ìgbàlà lò, pẹ̀lú ìrètí pé àwọn kan lára wọn ṣì lè tẹ́wọ́ gba ìhìn rere ìyè.—2 Tímótì 2:25; 1 Pétérù 3:15.
16. Kí ni ìdí kan tó fi yẹ ká mú “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” sunwọ̀n sí i?
16 Bí a bá jáfáfá nínú iṣẹ́ kíkọ́ni, a óò túbọ̀ máa hára gàgà láti polongo ìhìn rere. Bí àpẹẹrẹ: Eré ìdárayá kan tó jẹ́ amóríyá lè máà nítumọ̀ lójú ẹni tí kò mọ̀ ọ́n ṣe. Àmọ́ lójú ẹni tó mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa, eré aládùn ni. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn Kristẹni tó bá mú “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” sunwọ̀n sí i ń fi kún ayọ̀ wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (2 Tímótì 4:2; Títù 1:9) Pọ́ọ̀lù gba Tímótì nímọ̀ràn pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Báwo la ṣe lè mú ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa sunwọ̀n sí i?
17. Báwo la ṣe lè “ní ìyánhànhàn” fún ìmọ̀ Bíbélì, báwo sì ni irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láǹfààní?
17 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà náà ni láti gba àfikún ìmọ̀ pípéye sínú. Àpọ́sítélì Pétérù rọ̀ wá pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà.” (1 Pétérù 2:2) Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà táa kọ́ ọmọ ọwọ́ tí ara rẹ̀ le kí ó tó máa yán hànhàn fún wàrà. Ṣùgbọ́n ó lè di dandan kí Kristẹni kan kọ́ bí a ti í “ní ìyánhànhàn” fún ìmọ̀ Bíbélì. A lè ṣe èyí nípa níní ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ètò ìwé kíkà tó jíire. (Òwe 2:1-6) Ó ń béèrè ìsapá àti ìsẹ́ra ẹni bí a óò bá di ọ̀jáfáfá olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n irú ìsapá bẹ́ẹ̀ ń mérè wá. Inú dídùn tó máa ń wá látinú ṣíṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò jẹ́ kí iná ẹ̀mí Ọlọ́run máa jó nínú wa, èyí yóò sì jẹ́ ká máa hára gàgà láti kọ́ àwọn ẹlòmíì ní ohun tí à ń kọ́.
18. Báwo làwọn ìpàdé Kristẹni ṣe lè mú wa gbára dì fún fífi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́?
18 Àwọn ìpàdé Kristẹni tún ń kó ipa pàtàkì nínú báa ṣe lè lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó já fáfá. Nígbà táa bá ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì nígbà àsọyé fún gbogbo ènìyàn àti ní àwọn ìgbà mìíràn táa bá ń jíròrò látinú Ìwé Mímọ́, á dáa kí àwa náà máa fojú bá a lọ nínú Bíbélì tiwa. Ó bọ́gbọ́n mu ká máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa bí ìpàdé ti ń lọ lọ́wọ́, àgàgà àwọn apá ìpàdé tó dá lórí iṣẹ́ ìwàásù wa. A ò gbọ́dọ̀ fojú kéré àwọn àṣefihàn, bóyá ká jẹ́ kí ọkàn wa pínyà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ń béèrè ìsẹ́ra ẹni àti ìpọkànpọ̀. (1 Tímótì 4:16) Àwọn ìpàdé Kristẹni ń gbé ìgbàgbọ́ wa ró, wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìyánhànhàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ń kọ́ wa láti máa fi ìháragàgà pòkìkí ìhìn rere.
A Lè Gbára Lé Ìtìlẹyìn Jèhófà
19. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti máa nípìn-ín déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù?
19 Àwọn Kristẹni tí ‘iná ẹ̀mí ń jó’ nínú wọn, tí wọ́n sì ń hára gàgà láti polongo ìhìn rere ń sapá láti máa nípìn-ín déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (Éfésù 5:15, 16) Òótọ́ ni pé bí ipò nǹkan ṣe rí fún kálukú yàtọ̀ síra, òótọ́ sì ni pé kì í ṣe gbogbo wa ló lè lo iye àkókò kan náà nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí. (Gálátíà 6:4, 5) Àmọ́, ó jọ pé báa ṣe ń bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ tó nípa ìrètí wa ni ohun tó ṣe pàtàkì ju àròpọ̀ iye àkókò táa lò nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. (2 Tímótì 4:1, 2) Báa bá ṣe túbọ̀ ń wàásù, bẹ́ẹ̀ náà la óò túbọ̀ máa mọyì ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ yìí. (Róòmù 10:14, 15) Ìyọ́nú àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò táa ní yóò máa pọ̀ sí i nígbà tí a bá ń bá àwọn olóòótọ́ inú pàdé déédéé, àwọn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n ń kérora, tí wọn kò sì ní ìrètí.—Ìsíkíẹ́lì 9:4; Róòmù 8:22.
20, 21. (a) Iṣẹ́ wo ló ṣì wà níwájú wa? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ti àwọn ìsapá wa lẹ́yìn?
20 Jèhófà ti fi ìhìn rere náà síkàáwọ́ wa. Èyí ni iṣẹ́ àkọ́kọ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 3:6-9) A ń hára gàgà láti fi tọkàntọkàn ṣe ojúṣe yìí tí Ọlọ́run ní ká ṣe, a sì fẹ́ fi gbogbo agbára wa ṣe é. (Máàkù 12:30; Róòmù 12:1) Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ ló ṣì wà nínú ayé, ìyẹn àwọn tí ebi òtítọ́ ń pa. Iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe, ṣùgbọ́n a lè gbára lé ìtìlẹyìn Jèhófà báa ti ń ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.—2 Tímótì 4:5.
21 Jèhófà ń fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, ó sì ti fún wa ní “idà ẹ̀mí,” ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, láti fi dira. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, a lè la ẹnu wa “pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ láti sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìhìn rere di mímọ̀.” (Éfésù 6:17-20) Ǹjẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà jẹ́ tàwa náà, pé: “Ìhìn rere tí a ń wàásù kò fara hàn láàárín yín nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú agbára pẹ̀lú àti nínú ẹ̀mí mímọ́ àti ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.” (1 Tẹsalóníkà 1:5) Àní sẹ́, ẹ jẹ́ ká máa fi ìháragàgà polongo ìhìn rere náà!
Àtúnyẹ̀wò Ráńpẹ́
• Nítorí àwọn àníyàn ìgbésí ayé, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ìtara wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?
• Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ wa láti polongo ìhìn rere fi lè dà bí “iná tí ń jó” nínú ọkàn-àyà wa?
• Àwọn èrò òdì wo la gbọ́dọ̀ yàgò fún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?
• Lápapọ̀, ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ kí iná ìtara wa fún iṣẹ́ ìwàásù má bàa kú?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Kristẹni ń fara wé ìtara Pọ́ọ̀lù àti Jeremáyà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti aládùúgbò ló ń mú kí a máa fi ìháragàgà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà