Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni sísin Jèhófà “ní ẹ̀mí” túmọ̀ sí?
Nígbà tí Jésù Kristi ń jẹ́rìí fún obìnrin ará Samáríà tó wá fa omi nínú kànga Jékọ́bù tó wà nítòsí ìlú Síkárì, Jésù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) A gbọ́dọ̀ máa ṣe ìjọsìn tòótọ́ ‘ní òtítọ́,’ nítorí pé ó gbọ́dọ̀ wà níbàámu pẹ̀lú ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ṣí payá nínú Bíbélì nípa ara rẹ̀ àtàwọn ète rẹ̀. Tẹ̀mítẹ̀mí àti tìtaratìtara ló yẹ ká máa fi ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, kí ó jẹ́ pé ọkàn tó kún fún ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ ló ń sún wa ṣe é. (Títù 2:14) Àmọ́, àyíká ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ohun tó wé mọ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ‘jíjọ́sìn Ọlọ́run ní ẹ̀mí’ ṣe pàtàkì ju irú ọkàn táa fi ń sin Jèhófà.
Ohun tí Jésù bá obìnrin yẹn sọ nídìí kànga kì í ṣe ọ̀ràn bóyá èèyàn ń fìtara ṣẹ̀sìn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Kódà èèyàn lè máa fi ìtara àti ìgbóná ọkàn ṣe ẹ̀sìn èké. Kàkà bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn sísọ pé kì í ṣe orí òkè kan ní Samáríà tàbí nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù—àwọn ibi méjèèjì tó ṣeé fojú rí—la ó ti máa sin Bàbá, Jésù wá tọ́ka sí ọ̀nà tuntun tí a óò máa gbà jọ́sìn, èyí tó sinmi lé irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an. (Jòhánù 4:21) Ó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹni ẹ̀mí.” (Jòhánù 4:24, Charles B. Williams) Ọlọ́run tòótọ́ kì í ṣe ẹlẹ́ran ara, a ò lè rí i, a ò sì lè fọwọ́ bà á. A kò lè fi ìjọsìn rẹ̀ mọ sínú tẹ́ńpìlì kan tàbí orí òkè kan táa lè fojú rí. Fún ìdí yìí, Jésù tọ́ka sí apá kan ìjọsìn tó ré kọjá àwọn ohun táa lè fojú rí.
Yàtọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ fi òtítọ́ ṣe ìjọsìn tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ó tún ní láti jẹ́ èyí tí ẹ̀mí mímọ́ ń darí—ìyẹn ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run tí a kò lè fojú rí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀mí [mímọ́ ní] ń wá inú ohun gbogbo, àní àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” Ó fi kún un pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kí àwa bàa lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti fi fún wa pẹ̀lú inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 2:8-12) Kí Ọlọ́run lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí rẹ̀, ká sì jẹ́ kí ẹ̀mí yẹn máa darí wa. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀mí wa, ìyẹn èrò orí wa, bá ẹ̀mí Ọlọ́run mu, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àti fífi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Máa sin Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́”