Máa Rìn Ní ‘Ipa Ọ̀nà Ìdúróṣánṣán’
WÒLÍÌ Aísáyà polongo pé: “Yóò dára fún olódodo, nítorí pé wọn yóò jẹ èso ìbánilò wọn.” Aísáyà tún sọ pé: “Ipa ọ̀nà olódodo jẹ́ ìdúróṣánṣán.” (Aísáyà 3:10; 26:7) Ní kedere, bí ìbánilò wa yóò bá mú èso rere jáde, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọ́run.
Àmọ́, báwo la ṣe lè máa rìn ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán? Àwọn ìbùkún wo la lè retí àtirí gbà táa bá ń ṣe bẹ́ẹ̀? Báwo sì làwọn ẹlòmíràn ṣe lè jàǹfààní nínú rírọ̀ tí a rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọ́run? Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì fúnni ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú orí kẹwàá ìwé Òwe inú Bíbélì, níbi tó ti sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín olódodo àti ẹni búburú. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó lo gbólóhùn náà, “olódodo” ní ìgbà mẹ́tàlá. Mẹ́sàn-án lára ìwọ̀nyí fara hàn ní ẹsẹ ìkẹẹ̀ẹ́dógún sí ìkejìlélọ́gbọ̀n. Nítorí náà, gbígbé Òwe 10:15-32 yẹ̀ wò yóò fún wa níṣìírí gan-an.a
Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú Ìbáwí
Sólómọ́nì tọ́ka sí ìjẹ́pàtàkì òdodo. Ó sọ pé: “Àwọn nǹkan tí ó níye lórí tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ ni ìlú lílágbára rẹ̀. Ìparun àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ni ipò òṣì wọn. Ìgbòkègbodò olódodo ń yọrí sí ìyè; èso ẹni burúkú ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀.” —Òwe 10:15, 16.
Ọrọ̀ lè jẹ́ ààbò nígbà táa bá dojú kọ àwọn ohun àìdánilójú inú ìgbésí ayé, gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi kan ṣe lè jẹ́ ààbò fún àwọn tó ń gbé inú rẹ̀. Ipò òṣì sì lè ba nǹkan jẹ́ pátápátá nígbà táwọn nǹkan tí a kò retí bá yọjú. (Oníwàásù 7:12) Àmọ́, ó lè jẹ́ ewu tó wà nínú ọrọ̀ àti ipò òṣì ni ọlọgbọ́n ọba náà tún ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Ọlọ́rọ̀ lè gbé gbogbo ọkàn rẹ̀ lé ọrọ̀ tó ní, kó máa lérò pé àwọn ohun iyebíye òun “dà bí ògiri adáàbòboni.” (Òwe 18:11) Tálákà sì lè fàṣìṣe ronú pé ipò òṣì tóun wà kò lè jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la òun nítumọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn méjèèjì á wá kùnà láti ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, yálà olódodo ní nǹkan ti ara lọ́pọ̀ yanturu tàbí níwọ̀nba, ìgbòkègbodò onídùúró-ṣánṣán rẹ̀ yóò yọrí sí ìyè. Lọ́nà wo? Ní ti pé, ohun tó ní tẹ́ ẹ lọ́rùn. Kò jẹ́ kí ipò ìṣúnná owó òun ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìdúró rere tí òun ní lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ì báà jẹ́ olówó ni tàbí tálákà, ipa ọ̀nà olódodo yóò mú ayọ̀ wá fún un nísinsìnyí àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. (Jóòbù 42:10-13) Ẹni ibi kì í jàǹfààní kankan, kódà bó tiẹ̀ lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Dípò tí ì bá fi máa dúpẹ́ nítorí ààbò tí ọrọ̀ rẹ̀ fún un, kó sì máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, ńṣe ló ń lo ọrọ̀ rẹ̀ láti gbé ìgbésí ayé ẹ̀ṣẹ̀.
Ọba Ísírẹ́lì tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ẹni tí ó rọ̀ mọ́ ìbáwí jẹ́ ipa ọ̀nà sí ìyè, ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi ìbáwí àfitọ́nisọ́nà sílẹ̀ ń fa rírìn gbéregbère.” (Òwe 10:17) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ pé ọ̀nà méjì la lè gbà lóye ẹsẹ yìí. Ọ̀nà kan ni pé ẹni tó tẹ́wọ́ gba ìbáwí, tó sì ń lépa òdodo wà ní ipa ọ̀nà sí ìyè, nígbà tẹ́ni tó ń kọ ìbáwí sílẹ̀ ń rìn gbéregbère kúrò ní ojú ọ̀nà yẹn. Ẹsẹ náà tún lè túmọ̀ sí pé “ẹni tó bá gba ìbáwí ń fi ọ̀nà ìyè han [àwọn ẹlòmíràn nítorí pé wọ́n ń jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ rere rẹ̀], ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìbáwí sílẹ̀ ń kó àwọn ẹlòmíràn ṣìnà.” (Òwe 10:17, New International Version) Ní ọ̀nà méjèèjì, ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó láti rọ̀ mọ́ ìbáwí, kí a má sì kọ ìbáwí àfitọ́nisọ́nà sílẹ̀!
Fi Ìfẹ́ Dípò Ìkórìíra
Sólómọ́nì wá pa òwe alápá méjì kan tó ní èrò tó bára mu, tí apá kejì sì ń kín apá àkọ́kọ́ lẹ́yìn. Ó ní: “Níbi tí ẹni tí ń bo ìkórìíra mọ́lẹ̀ bá wà, níbẹ̀ ni ètè èké wà.” Bí ẹnì kan bá kórìíra ẹlòmíràn nínú ọkàn-àyà rẹ̀, tó sì ń fi ọ̀rọ̀ dídùn àti ọ̀rọ̀ ìpọ́nni bo ìkórìíra náà mọ́lẹ̀, ẹlẹ̀tàn ni—ó ní “ètè èké.” Ọba náà wá fi kún un pé: “Ẹni tí ó sì ń mú ìròyìn búburú wá jẹ́ arìndìn.” (Òwe 10:18) Àwọn kan tún wà tó jẹ́ pé kàkà kí wọ́n fi ìkórìíra tí wọ́n ní sí ẹlòmíràn pa mọ́, wọ́n á máa fẹ̀sùn èké kan irú ẹni bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n máa tan ọ̀rọ̀ àbùkù nípa ẹni tí wọ́n kórìíra náà kiri. Ìwà òmùgọ̀ gbáà lèyí nítorí pé ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọjẹ́ náà kò lè ba orúkọ rere onítọ̀hún jẹ́ ní ti gidi. Àti pé nígbà tẹ́ni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà bá fara balẹ̀ yẹ ọ̀rọ̀ náà wò, á mọ̀ pé ẹ̀tanú ló fà á, kò sì ní ka ọ̀rọ̀ ẹni tí ń bani lórúkọ jẹ́ náà sí mọ́. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé aṣení-ṣera-rẹ̀ lọ̀ràn ẹni tó ń tan ìròyìn burúkú kálẹ̀.
Ipa ọ̀nà òdodo ni láti yàgò fún ẹ̀tàn tàbí ìbanilórúkọjẹ́. Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ nínú ọkàn-àyà rẹ.” (Léfítíkù 19:17) Jésù sì gba àwọn olùgbọ́ rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín [pàápàá] àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:44, 45) Ẹ ò rí i pé ó dára jù láti fi ìfẹ́ kún ọkàn-àyà wa dípò ìkórìíra!
‘Ṣàkóso Ètè’
Nígbà tí ọlọgbọ́n ọba náà ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì kíkó ahọ́n níjàánu, ó ní: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.”—Òwe 10:19.
“Òmùgọ̀ . . . ń sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀.” (Oníwàásù 10:14) Ẹnu rẹ̀ sì “ń tú ìwà òmùgọ̀ jáde.” (Òwe 15:2) Èyí kò wá túmọ̀ sí pé gbogbo ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́ ni òmùgọ̀ o. Àmọ́, ẹ ò rí i pé ó rọrùn gan-an kí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ jù di agbódegbà òfófó tàbí ọ̀rọ̀ àhesọ! Ìbanilórúkọjẹ́, ẹ̀dùn ọkàn, àjọṣe tí kò dán mọ́rán, kódà àwọn ìpalára táa lè fojú rí pàápàá lè jẹ́ àbájáde ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tẹ́nì kan sọ. “Níbi tí ọ̀rọ̀ púpọ̀ bá wà, a ò lè wá ẹ̀ṣẹ̀ tì níbẹ̀.” (Òwe 10:19, An American Translation) Láfikún sí i, inú èèyàn kì í dùn láti wà lọ́dọ̀ ẹni tó máa ń ri nǹkan sọ sí gbogbo ọ̀ràn. Kí a má ṣe jẹ́ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ jù.
Yàtọ̀ sí wíwulẹ̀ yẹra fún irọ́ pípa, ẹni tí ó ń ṣàkóso ètè ara rẹ̀ máa ń hùwà tòyetòye. Ó máa ń ronú kó tó sọ̀rọ̀. Nítorí ìfẹ́ tó ní fún àwọn ìlànà Jèhófà àti ìfẹ́ àtọkànwá tó ní láti ran àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó máa ń ronú lórí ipa tí àwọn ọ̀rọ̀ tí òun ń sọ yóò ní lórí àwọn ẹlòmíràn. Àwọn gbólóhùn tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde máa ń jẹ́ ti onífẹ̀ẹ́, yóò sì sọ ọ́ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ó máa ń ṣàṣàrò lórí bí ohun tí òun ń sọ ṣe máa wọni lọ́kàn táa sì ṣèrànwọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí “àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe”—ìyẹn ni pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń mọ́gbọ́n dání, ó sì ń gbayì ní gbogbo ìgbà.—Òwe 25:11.
Ó “Ń Bọ́ Ọ̀pọ̀lọpọ̀”
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ahọ́n olódodo jẹ́ ààyò fàdákà; ọkàn-àyà ẹni burúkú kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí.” (Òwe 10:20) Ohun tí olódodo ń sọ mọ́ gaara—ó dà bíi fàdákà olówó iyebíye, tí a yọ́ mọ́, tí kò sì ní ìdàrọ́ kankan. Bí ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe rí gẹ́ẹ́ nìyí, bí wọ́n ṣe ń mú ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń gbẹ̀mí là tọ àwọn èèyàn lọ. Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Atóbilọ́lá Olùfúnni-nítọ̀ọ́ni wọn, ti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ti ‘fún wọn ní ahọ́n àwọn tí a kọ́, kí wọ́n lè mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn.’ (Aísáyà 30:20; 50:4) Ní ti tòótọ́, ahọ́n wọn dà bí ààyò fàdákà bó ṣe ń sọ òtítọ́ Bíbélì jáde. Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ṣe níye lórí tó lójú àwọn olóòótọ́ ọkàn ju ìpètepèrò àwọn ẹni ibi! Ẹ jẹ́ kí a máa hára gàgà láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run.
Ìbùkún ni olódodo jẹ́ fún àwọn tó yí i ká. Sólómọ́nì tẹ̀ síwájú, ó ní:“Àní ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n àwọn òmùgọ̀ ń kú nítorí tí ọkàn-àyà kù fún wọn.”—Òwe 10:21.
Báwo ni ‘olódodo ṣe ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀’? Ọ̀rọ̀ Hébérù táa lò níhìn-ín ń mú èrò “ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn” wá síni lọ́kàn. Ó jẹ mọ́ títọ́ni sọ́nà àti fífúnni lókun, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ayé ìgbàanì ṣe máa ń bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 16:11; Sáàmù 23:1-3; Orin Sólómọ́nì 1:7) Olódodo máa ń tọ́ àwọn ẹlòmíràn sọ́nà tàbí kó darí wọn sọ́nà òdodo, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ sì ń fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lókun. Nítorí ìdí èyí, wọ́n ń gbé ìgbésí ayé aláyọ̀, tó túbọ̀ fini lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà pẹ̀lú.
Àmọ́, ẹni tó jẹ́ òmùgọ̀ wá ńkọ́? Nítorí pé ọkàn-àyà kù fún un, kò ní ète rere, bẹ́ẹ̀ ni kì í ronú nípa ohun tó lè jẹ́ àbájáde ipa ọ̀nà tí òun ń tọ̀. Ohun tírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ ló máa ń ṣe, kì í ronú nípa àbájáde ohun tí òun ń ṣe. Nítorí náà, ó máa ń forí fá ohun tó bá tìdí rẹ̀ yọ. Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni olódodo máa ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wà láàyè, ẹni tí ọkàn-àyà kù fún kò tiẹ̀ lè mú ara rẹ̀ pàápàá wà láàyè.
Yẹra fún Ìwà Àìníjàánu
Ohun tẹ́nì kan fẹ́ àti ohun tí kò fẹ́ ló sábà máa ń fi irú ẹni téèyàn jẹ́ hàn. Láti fi òkodoro òtítọ́ yìí hàn, ọba Ísírẹ́lì náà sọ pé: “Sí arìndìn, bíbá a lọ ní híhu ìwà àìníjàánu dà bí ìdárayá, ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà fún ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀.”—Òwe 10:23.
Àwọn kan ka ìwà àìníjàánu sí eré ìmárale tàbí eré ìdárayá, wọ́n sì ń ṣe é fún “ìmóríyá” lásánlàsàn. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò ka Ọlọ́run sí ẹni tí gbogbo ènìyàn máa jíhìn fún, wọ́n ò sì bìkítà nípa bí ipa ọ̀nà wọn ṣe burú tó. (Róòmù 14:12) Èrò inú wọn ti dìdàkudà débi tí wọ́n fi rò pé Ọlọ́run kò rí ìwà àìtọ́ tí wọ́n ń hù. Ohun tí ìṣe wọ́n fi hàn pé wọ́n ń wí ni pé: “Jèhófà kò sí.” (Sáàmù 14:1-3; Aísáyà 29:15, 16) Wọ́n mà kúkú gọ̀ o!
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ẹni tó ní ìfòyemọ̀ mọ̀ pé ìwà àìníjàánu kì í ṣe eré ìdárayá rárá. Ó mọ̀ pé kò múnú Ọlọ́run dùn, ó sì lè ba àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti òmùgọ̀ nítorí pé kì í jẹ́ kéèyàn níyì, ó ń ba ìgbéyàwó jẹ́, ó ń pa èrò inú àti ara èèyàn lára, ó sì ń jẹ́ kéèyàn pàdánù ipò tẹ̀mí rẹ̀. Ó mọ́gbọ́n dání láti yẹra fún ìwà àìníjàánu kí a sì nífẹ̀ẹ́ ọgbọ́n bí a ṣe ń nífẹ̀ẹ́ arábìnrin tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n sí wa.—Òwe 7:4.
Kọ́lé Sórí Ìpìlẹ̀ Tí Ó Tọ́
Nígbà tí Sólómọ́nì ń tọ́ka sí ìníyelórí kíkọ́ ìgbésí ayé ẹni sórí ìpìlẹ̀ tó dára, ó sọ pé: “Ohun tí ń da jìnnìjìnnì bo ẹni burúkú—èyíinì ni ohun tí yóò dé bá a; ṣùgbọ́n ìfẹ́-ọkàn àwọn olódodo ni a ó yọ̀ǹda fún wọn. Bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù oníjì ré kọjá, bẹ́ẹ̀ ni ẹni burúkú kò ní sí mọ́; ṣùgbọ́n olódodo jẹ́ ìpìlẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Òwe 10:24, 25.
Ẹni burúkú lè kó jìnnìjìnnì bá àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́, níkẹyìn, ohun tó ń bà á lẹ́rù yóò dà lé e lórí. Nítorí pé kò gbé àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ karí àwọn ìlànà òdodo, ó dà bí ilé tí kò dúró dáadáa, tó lè wó nígbà tí ìjì líle bá dé. Yóò juwọ́ sílẹ̀ nígbà tí ìṣòro bá dé. Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, olódodo dà bí ọkùnrin tó hùwà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jésù. Ó jẹ́ “ọkùnrin olóye, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.” Jésù sọ pé: “Òjò sì tú dà sílẹ̀, ìkún omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ṣùgbọ́n kò ya lulẹ̀, nítorí a ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.” (Mátíù 7:24, 25) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ dúró sán-ún—èrò rẹ̀ àti ìṣe rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn ìlànà Ọlọ́run.
Kí ọlọgbọ́n ọba náà tó máa bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lórí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹni ibi àti olódodo, ó fúnni ní ìkìlọ̀ ṣókí kan, àmọ́ tó jẹ́ èyí tó ṣe pàtàkì. Ó sọ pé: “Bí ọtí kíkan sí eyín àti èéfín sí ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí àwọn tí ó rán an jáde.” (Òwe 10:26) Ọtí kíkan kì í tu eyín lára rárá. Omiró tó wà nínú rẹ̀ máa ń kan bóbó lẹ́nu, ó sì lè wa èèyàn léyín pọ̀. Èéfín máa ń mójú tani. Bákan náà, ó di dandan kí wàhálà dé bá ẹnikẹ́ni tó bá gba ọ̀lẹ ènìyàn síṣẹ́ tàbí tí ó lò ó gẹ́gẹ́ bí aṣojú, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò sì pàdánù.
“Ọ̀nà Jèhófà Jẹ́ Odi Agbára”
Ọba Ísírẹ́lì náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Àní ìbẹ̀rù Jèhófà yóò fi kún àwọn ọjọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọdún tí ó jẹ́ ti àwọn ẹni burúkú ni a óò ké kúrú. Ìfojúsọ́nà àwọn olódodo jẹ́ ayọ̀ yíyọ̀, ṣùgbọ́n ìrètí àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.”—Òwe 10:27, 28.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ló ń tọ́ olódodo sọ́nà, ó sì ń gbìyànjú láti múnú Jèhófà dùn nínú èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀. Ọlọ́run ń bójú tó o, ó sì ń mú àwọn ìfojúsọ́nà rere rẹ̀ ṣẹ. Àmọ́, ẹni burúkú máa ń gbé ìgbésí ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ìrètí rẹ̀ lè dà bí èyí tó nímùúṣẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ fúngbà díẹ̀ ni, nítorí pé ìwà ipá àti àìsàn tó jẹ́ àbájáde bó ṣe lo ìgbésí ayé rẹ̀ sábà máa ń dín ọjọ́ ayé rẹ̀ kù. Ọjọ́ tó bá kú ni gbogbo ìrètí rẹ̀ fọ́ yángá.— Òwe 11:7.
Sólómọ́nì sọ pé: “Ọ̀nà Jèhófà jẹ́ odi agbára fún aláìlẹ́bi, ṣùgbọ́n ìparun ń bẹ fún àwọn aṣenilọ́ṣẹ́.” (Òwe 10:29) Ọ̀nà Jèhófà táa ń sọ níhìn-ín kò tọ́ka sí ọ̀nà ìgbésí ayé tó yẹ ká máa tọ̀, bí kò ṣe ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá ìran ènìyàn lò. Mósè sọ pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Diutarónómì 32:4) Ọ̀nà òdodo Ọlọ́run jẹ́ ààbò fún olódodo àti ìparun fún ẹni ibi.
Ẹ ò rí i bí Jèhófà ṣe jẹ́ odi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tó! “Ní ti olódodo, fún àkókò tí ó lọ kánrin, a kì yóò mú kí ó ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́; ṣùgbọ́n ní ti àwọn ẹni burúkú, wọn kì yóò máa bá a nìṣó ní gbígbé orí ilẹ̀ ayé. Ẹnu olódodo—ó ń so èso ọgbọ́n, ṣùgbọ́n ahọ́n àyídáyidà ni a óò ké kúrò. Ètè olódodo—ó wá mọ ìfẹ́ rere, ṣùgbọ́n ẹnu àwọn ẹni burúkú jẹ́ àyídáyidà.”—Òwe 10:30-32.
Nǹkan máa ń ṣẹnuure fún olódodo, a sì ń bù kún un nítorí pé ó ń rìn ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán. Ní ti tòótọ́, “ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” (Òwe 10:22) Nítorí náà, ǹjẹ́ kí a máa rí i dájú pé a ń hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká tún máa ṣàkóso ètè wa, ká máa fi ahọ́n wa gbé àwọn ẹlòmíràn ró nípa sísọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń gbẹ̀mí là fún wọn, ká sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí ọ̀nà òdodo.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò lórí Òwe 10:1-14, wo Ilé Ìṣọ́ ti July 15, 2001, ojú ìwé 24 sí 27.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ahọ́n lè dà bí “ààyò fàdákà”