Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Nikodémù
“BÍ ẸNIKẸ́NI bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Lúùkù 9:23) Àwọn apẹja àti agbowó orí kan táwọn èèyàn ń tẹ́ńbẹ́lú tẹ́wọ́ gba ìkésíni yẹn láìjanpata. Wọ́n fi gbogbo nǹkan sílẹ̀ kí wọ́n lè tẹ̀ lé Jésù.—Mátíù 4:18-22; Lúùkù 5:27, 28.
Ìpè Jésù yẹn ṣì ń dún lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ti dáhùn sí ìpè náà. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan wà tínú wọn dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àmọ́ tí wọ́n ń lọ́ tìkọ̀ láti ‘sẹ́ ara wọn kí wọ́n sì gbé òpó igi oró wọn.’ Wọ́n ń lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ àti àǹfààní jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù.
Kí nìdí táwọn kan fi ń sá fún títẹ́wọ́ gba ìkésíni Jésù, tí wọn ò sì fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run? Ká sọ tòótọ́, àwọn tí a kò bá fi kọ́ láti kékeré pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, bí ẹ̀sìn àwọn Júù àti ti Kristẹni ṣe fi ń kọ́ni, lè nílò ọ̀pọ̀ àkókò kí wọ́n tó gbà pé Ẹlẹ́dàá kan tó jẹ́ alágbára ńlá gbogbo wà ní ti gidi. Síbẹ̀ náà, lẹ́yìn táwọn kan bá ti gbà pé Ọlọ́run wà ní ti gidi, wọ́n tún ń lọ́ tìkọ̀ láti tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù. Wọ́n lè máa bẹ̀rù ohun táwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ máa rò nípa wọn bí wọ́n bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn mìíràn tó gbójú fo òtítọ́ náà dá pé àkókò kánjúkánjú là ń gbé yìí, ti yíjú sí lílépa òkìkí àti ọlá. (Mátíù 24:36-42; 1 Tímótì 6:9, 10) Bó ti wù kó rí, ẹ̀kọ́ kan wà tí àwọn tó ń sún ìpinnu wọn láti di ọmọlẹ́yìn Jésù síwájú lè kọ́ nínú ìtàn Nikodémù, ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ alákòóso àwọn Júù nígbà ayé Jésù.
Ó Ní Àgbàyanu Àǹfààní
Nǹkan bí oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ni Nikodémù ti rí Jésù ‘gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.’ Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ní Jerúsálẹ́mù nígbà Ìrékọjá ọdún 30 Sànmánì Tiwa wú Nikodémù lórí gan-an débi pé ó wá ní òru láti wá sọ fún Jésù pé òun gbà á gbọ́ àti láti wá túbọ̀ mọ̀ nípa olùkọ́ yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù sọ ìjìnlẹ̀ òtítọ́ fún Nikodémù nípa ìdí tó fi pọn dandan láti ‘di àtúnbí’ kí a tó lè wọ Ìjọba Ọlọ́run. Àkókò yìí kan náà ni Jésù sọ ọ̀rọ̀ náà pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:1-16.
Ẹ ò rí i pé ìrètí ńlá ló wà fún Nikodémù yìí! Ó láǹfààní láti bá Jésù kẹ́gbẹ́, kó sì fojú ara rẹ̀ rí onírúurú apá ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bí alákòóso àwọn Júù àti olùkọ́ kan ní Ísírẹ́lì, òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yé Nikodémù dáadáa. Ó sì tún ní ìjìnlẹ̀ òye, bí a ṣe rí i nínú bó ṣe mọ̀ pé Jésù ni olùkọ́ tí ó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nikodémù nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí, ó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ẹ wo bó ṣe ní láti ṣòro tó fún mẹ́ńbà ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ti àwọn Júù láti gbà pé ọmọ káfíńtà lásán-làsàn yìí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Gbogbo irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ló ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn tó lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.
Ìfẹ́ tí Nikodémù ní sí ọkùnrin ará Násárétì yìí kò dín kù. Ọdún méjì ààbọ̀ lẹ́yìn náà, nígbà Àjọyọ̀ Àtíbàbà, Nikodémù wà ní ìpàdé kan tí àwọn Sànhẹ́dírìn ṣe. Nikodémù ṣì jẹ́ “ọ̀kan lára wọn” nígbà yẹn. Àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí rán àwọn onípò àṣẹ láti lọ mú Jésù wá. Àwọn onípò àṣẹ náà padà wá, wọ́n sì ròyìn pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” Àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣẹ̀sín pé: “A kò tíì ṣi ẹ̀yin náà lọ́nà, àbí a ti ṣe bẹ́ẹ̀? Kò sí ọ̀kan nínú àwọn olùṣàkóso tàbí àwọn Farisí tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àbí ó wà? Ṣùgbọ́n ogunlọ́gọ̀ yìí tí kò mọ Òfin jẹ́ ẹni ègún.” Nikodémù kò lè mú ọ̀rọ̀ náà mọ́ra mọ́. Ó fọhùn pé: “Òfin wa kì í ṣèdájọ́ ènìyàn láìjẹ́ pé ó ti kọ́kọ́ gbọ́ ti ẹnu rẹ̀, kí ó sì wá mọ nǹkan tí ó ń ṣe, àbí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀?” Bí àwọn Farisí yòókù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣáátá rẹ̀ nìyẹn, tí wọ́n sọ pé: “Ìwọ pẹ̀lú kò ti Gálílì wá, àbí ibẹ̀ ni o ti wá? Ṣe ìwádìí káàkiri, kí o sì rí i pé kò sí wòlíì kankan tí a óò gbé dìde láti Gálílì.”—Jòhánù 7:1, 10, 32, 45-52.
Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Nikodémù rí i tí a gbé òkú Jésù sọ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi oró. Ó dara pọ̀ mọ́ Jósẹ́fù ará Arimatíà, tí òun náà jẹ́ mẹ́ńbà Sànhẹ́dírìn, láti múra òkú Jésù sílẹ̀ fún sísin. Fún ète yẹn, Nikodémù mú “àdìpọ̀ òjíá àti àwọn álóè” wá, èyí tó wọn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n pọ́n-ùn àwọn ará Róòmù, tó jẹ́ méjìléláàádọ́rin ìwọ̀n pọ́n-ùn ti àwọn Gẹ̀ẹ́sì. Owó ńlá gan-an nìyẹn. Ó tún gba ìgboyà gidi láti jẹ́ kí wọ́n mọ òun mọ́ “afàwọ̀rajà yẹn,” bí àwọn Farisí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe pe Jésù. Bí wọ́n ṣe múra òkú Jésù fún sísin tán ni wọn tẹ́ ẹ sí ibojì tuntun kan nítòsí. Àní, ní àkókò tá à ń wí yìí pàápàá, àwọn èèyàn ò tíì mọ Nikodémù sí ọmọ ẹ̀yìn Jésù síbẹ̀!—Jòhánù 19:38-42; Mátíù 27:63; Máàkù 15:43.
Ìdí Tí Kò Fi Gbégbèésẹ̀
Jòhánù kò sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Nikodémù kò fi ‘gbé igi oró rẹ̀,’ kí ó sì máa tọ Jésù lẹ́yìn nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀. Àmọ́, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tá a fi lè mọ ìdí tí Farisí yìí kò fi gbégbèésẹ̀ pàtó.
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jòhánù sọ pé olùṣàkóso àwọn Júù yìí “wá sí ọ̀dọ̀ [Jésù] ní òru.” (Jòhánù 3:2) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ pé: “Wíwá tí Nikodémù wá lóru, kì í ṣe nítorí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe láti yẹra fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó lè máa ṣèdíwọ́ nígbà tó bá ń fọ̀rọ̀ wá Jésù lẹ́nu wò.” Àmọ́, Jòhánù tọ́ka sí Nikodémù gẹ́gẹ́ bí “ọkùnrin tí ó wá sọ́dọ̀ [Jésù] ní òru ní ìgbà àkọ́kọ́,” nínú àyíká ọ̀rọ̀ kan náà tó ti tọ́ka sí Jósẹ́fù ará Arimatíà gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún àwọn Júù.” (Jòhánù 19:38, 39) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Nikodémù wá sọ́dọ̀ Jésù ní òru nítorí “ìbẹ̀rù àwọn Júù,” bí àwọn mìíràn nígbà ayé rẹ̀ ṣe máa ń bẹ̀rù níní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Jésù.—Jòhánù 7:13.
Ṣé o ò tíì sún ìpinnu rẹ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù síwájú nítorí ohun tí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí àwọn ojúlùmọ̀ rẹ lè sọ? Òwe kan sọ pé: “Wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn.” Báwo lo ṣe lè kojú ìbẹ̀rù yẹn? Òwe náà ń bá a lọ, ó ní: “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.” (Òwe 29:25) Láti gbé irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ ró nínú Jèhófà, o ní láti wá fi ojú ara rẹ rí i pé Ọlọ́run yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá wà nínú ìṣòro. Gbàdúrà sí Jèhófà, kí o sì bẹ̀ ẹ́ pé kí ó fún ọ ní ìgboyà láti ṣe àwọn ìpinnu kéékèèké pàápàá nípa ìjọsìn rẹ. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tó o ní nínú Jèhófà yóò pọ̀ débi tí wàá fi lè ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tó wà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ó tún lè jẹ́ ipò iyì tí Nikodémù wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹgbẹ́ alákòóso ni kò jẹ́ kó gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì ti sísẹ́ ara rẹ̀. Ó ní láti jẹ́ pé ó ṣì ka ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Sànhẹ́dírìn sí bàbàrà ní àkókò yẹn. Ṣé o kì í lọ́ tìkọ̀ láti di ọmọlẹ́yìn Kristi nítorí pé o lè pàdánù ipò ọlá láwùjọ tàbí nítorí pé o ní láti fi ìrètí dídé ipò gíga du ara rẹ? Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí tá a lè fi wé iyì níní àǹfààní láti sin Ẹni Gíga Jù Lọ ní ọ̀run òun ayé, tó ṣe tán láti ṣe ohun tó o bá béèrè níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀ fún ọ.—Sáàmù 10:17; 83:18; 145:18.
Ohun mìíràn tó tún lè mú kí Nikodémù máa fònídónìí fọ̀ladọ́la ni ọrọ̀ tó ní. Gẹ́gẹ́ bí Farisí, ó lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn mìíràn, “tí wọ́n jẹ́ olùfẹ́ owó.” (Lúùkù 16:14) Òtítọ́ náà pé ó lè ra àdìpọ̀ òjíá àti àwọn álóè olówó iyebíye fi hàn pé ọlọ́rọ̀ ni lóòótọ́. Àwọn kan lóde òní ń fi nǹkan falẹ̀, wọn kò fẹ́ tètè pinnu láti tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ jíjẹ́ Kristẹni nítorí pé wọ́n ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun ìní wọn. Àmọ́, Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀. . . . Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:25-33.
Ó Pàdánù Ọ̀pọ̀ Àǹfààní
Ó yẹ fún àfiyèsí pé, ìtàn Nikodémù, tó wà nínú ìwé Ìhìn Rere Jòhánù nìkan, kò sọ fún wa bóyá ó wá di ọmọlẹ́yìn Jésù níkẹyìn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìtàn àtẹnudẹ́nu kan sọ pé Nikodémù di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ó ṣe batisí, àwọn Júù ṣe inúnibíni sí i, wọ́n rọ̀ ọ́ lóyè, wọ́n sì lé e kúrò ní Jerúsálẹ́mù níkẹyìn. Ohun yòówù kí ọ̀ràn náà jẹ́, ohun tó dájú ni pé: Ó pàdánù ọ̀pọ̀ àǹfààní nípa fífi òní dónìí fọ̀ladọ́la nígbà tí Jésù wà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé.
Ká ní Nikodémù ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Jésù látìgbà tó ti kọ́kọ́ bá Olúwa pàdé ni, ì bá ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù tímọ́tímọ́. Nikodémù ì bá di ọmọ ẹ̀yìn tó tayọ nítorí ìmọ̀, ìjìnlẹ̀ òye, àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀, àti nítorí pé àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Bẹ́ẹ̀ ni o, ì bá ti gbọ́ àwọn àgbàyanu ọ̀rọ̀ látẹnu Olùkọ́ Ńlá náà, ì bá ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú àwọn àkàwé Jésù, ì bá ti fi ojú ara rẹ̀ rí àwọn iṣẹ́ ìyanu kíkàmàmà tí Jésù ṣe, ì bá sì jèrè okun nínú ọ̀rọ̀ ìdágbére tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó pàdánù gbogbo ìyẹn.
Àdánù ńlá ni àìṣèpinnu fà fún Nikodémù. Ara ohun tó pàdánù ni ìkésíni ọlọ́yàyà tí Jésù nawọ́ rẹ̀ sí àwọn èèyàn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mátíù 11:28-30) Nikodémù pàdánù àǹfààní rírí ìtura yìí gbà lọ́dọ̀ Jésù fúnra rẹ̀!
Ìwọ Ńkọ́?
Láti ọdún 1914 ni Jésù Kristi ti wà ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run. Nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀, ara ohun tó sọ ni pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Kí òpin náà tó dé, iṣẹ́ ìwàásù jákèjádò ayé gbọ́dọ̀ di ṣíṣe ní àṣeparí. Jésù Kristi fẹ́ kí àwọn aláìpé kópa nínú iṣẹ́ náà. Ìwọ náà lè nípìn-ín nínú iṣẹ́ yìí.
Nikodémù gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Jésù ti wá. (Jòhánù 3:2) Látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o ti kọ́, ìwọ náà ti lè dé ìparí èrò kan náà. O ti lè ṣe àwọn ìyípadà kan láti mú kí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. O tiẹ̀ ti lè máa lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó o bàa lè túbọ̀ ní ìmọ̀ Bíbélì sí i. Ó yẹ ká kan sáárá sí ọ nítorí àwọn ìsapá wọ̀nyí. Síbẹ̀, Nikodémù ní láti ṣe ju wíwulẹ̀ gbà pé Jésù ni ẹni tí Ọlọ́run rán. Ó ní láti “sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí ó sì máa tọ [Jésù] lẹ́yìn nígbà gbogbo.”—Lúùkù 9:23.
Fi ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa sọ́kàn. Ó kọ̀wé pé: “Ní bíbá a ṣiṣẹ́ pọ̀, àwa ń pàrọwà fún yín pẹ̀lú pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀. Nítorí ó wí pé: ‘Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.’ Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.”—2 Kọ́ríńtì 6:1, 2.
Ìsinsìnyí ló yẹ kó o ní ìgbàgbọ́ tó máa mú ọ gbégbèésẹ̀. Láti ṣe èyí, máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tó o ti kọ́ nínú Bíbélì. Máa gbàdúrà sí Jèhófà, kí o sì máa bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Bí o ṣe ń rí i pé ó ń ràn ọ́ lọ́wọ́, ìmọrírì rẹ àti ìfẹ́ tó o ní fún un yóò sún ọ láti fẹ́ ‘sẹ́ níní ara rẹ, kí o sì gbé òpó igi oró rẹ láti ọjọ́ dé ọjọ́, kí o sì máa tọ Jésù Kristi lẹ́yìn nígbà gbogbo.’ Ṣé wàá gbégbèésẹ̀ nísinsìnyí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Lákọ̀ọ́kọ́, Nikodémù fìgboyà gbèjà Jésù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Láìfi àtakò pè, Nikodémù ṣèrànwọ́ láti múra òkú Jésù sílẹ̀ fún sísin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àdúrà lè fún ọ lókun láti gbégbèésẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ṣé wàá tẹ́wọ́ gba àǹfààní ṣíṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi?