Pásítọ̀ Méjì Tó Mọyì Àwọn Ìwé Tí Russell Kọ
NÍ 1891, Charles Taze Russell, tó ṣe iṣẹ́ títayọ láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ olùjọsìn Jèhófà, ṣèbẹ̀wò sí Yúróòpù fún ìgbà àkọ́kọ́. Àwọn ìròyìn kan tá a gbọ́ ni pé nígbà tí Russell tẹsẹ̀ dúró nílùú Pinerolo, lórílẹ̀-èdè Ítálì, ó rí Ọ̀jọ̀gbọ́n Daniele Rivoire, tó jẹ́ pásítọ̀ tẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ́ ẹ̀sìn kan tí wọ́n ń pè ní àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo.a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Rivoire ṣì jẹ́ Ọmọlẹ́yìn Waldo lẹ́yìn tó fiṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀, síbẹ̀ kò ní ẹ̀tanú, ó sì ka ọ̀pọ̀ ìwé tí C. T. Russell kọ.
Ní 1903, Rivoire túmọ̀ ìwé The Divine Plan of the Ages, tó jẹ́ ti Russell, sí èdè Italian, ó sì fi owó ara rẹ̀ tẹ̀ ẹ́ jáde. Ó ti ṣe èyí tipẹ́ kó tó di pé àwọn tó ni ìwé ọ̀hún mú ẹ̀dà ti èdè Italian jáde. Ohun tí Rivoire kọ sí ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìwé náà ni pé: “A fi ẹ̀dà tá a kọ́kọ́ mú jáde ní èdè Italian yìí sábẹ́ ààbò Olúwa. Ǹjẹ́ kí ó bù kún un, láìka àwọn àṣìṣe inú rẹ̀ sí, kí ó lè mú kí a gbé orúkọ rẹ̀ mímọ́ jù lọ lárugẹ, kí ó sì fún àwọn ọmọ rẹ̀ tó ń sọ èdè Italian níṣìírí láti ní ìfọkànsìn púpọ̀ sí i. Ǹjẹ́ kí ọkàn gbogbo àwọn tó bá mọrírì ìjìnlẹ̀ ọrọ̀, ọgbọ́n, ìmọ̀, ète àti ìfẹ́ Ọlọ́run, nípa kíka ìwé yìí, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ẹni tó jẹ́ pé oore ọ̀fẹ́ rẹ̀ ló mú kó ṣeé ṣe láti tẹ ìwé yìí jáde.”
Rivoire tún bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ ìwé ìròyìn Zion’s Watchtower and Herald of Christ’s Presence sí èdè Italian. Ìwé ìròyìn yìí, tó jẹ́ ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a mú jáde níbẹ̀rẹ̀, máa ń jáde lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún ní 1903. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Rivoire kò di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún, síbẹ̀ ó nífẹ̀ẹ́ tó ga sí títan ìhìn Bíbélì ká bá a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nínú àwọn ìwé táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ jáde.
“Ńṣe Ló Dà Bíi Pé Ìpẹ́ Jábọ́ Kúrò ní Ojú Mi”
Pásítọ̀ mìíràn tó jẹ́ Ọmọlẹ́yìn Waldo, tóun náà ò kóyán àwọn ìtẹ̀jáde Russell kéré ni Giuseppe Banchetti. Bàbá Giuseppe, tó yí padà kúrò nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì fi ẹ̀kọ́ Waldo kọ́ ọmọ rẹ̀. Ní 1894, Giuseppe di pásítọ̀, ó sì ṣe òjíṣẹ́ fún onírúurú àwùjọ àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ní Apulia àti Abruzzi àti ní àwọn erékùṣù Elba àti Sicily.
A gbé ẹ̀dà ìwé Divine Plan of the Ages ti Russell jáde ní èdè Italian ní 1905. Banchetti kọ ìwé kan tó gbámúṣé lórí rẹ̀. Ìwé náà jáde nínú La Rivista Cristiana, tó jẹ́ ìwé ìròyìn àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì. Banchetti kọ ọ́ pé: “Fún àwa,” ìwé Russell “ni ìwé tí àlàyé rẹ̀ ṣe kedere jù lọ, òun sì ni atọ́nà tó dájú tí Kristẹni èyíkéyìí lè lò láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó ṣàǹfààní, tó sì lérè . . . Bí mo ṣe kà á tán báyìí, ńṣe ló dà bíi pé ìpẹ́ jábọ́ kúrò ní ojú mi, bí ẹni pé ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ ṣe tààrà, ó sì rọrùn sí i. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo rò pé ó takora tẹ́lẹ̀ ni mo wá rí i pé kò takora rárá. Àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣòro láti lóye tẹ́lẹ̀ wá rọrùn, ó sì di ohun ìtẹ́wọ́gbà. Àwọn ohun tó dà bíi pé kò ṣeé lóye títí di àkókò yìí ti wá ṣe kedere. Ìwéwèé títayọlọ́lá nípa ìgbàlà ayé nípasẹ̀ Kristi wá yé mi yékéyéké débi pé èmi náà lè sọ bíi ti Àpọ́sítélì tó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o!”—Róòmù 11:33.
Gẹ́gẹ́ bí Remigio Cuminetti ṣe sọ ọ́ ní ọdún 1925, Banchetti “nífẹ̀ẹ́ tó ga” sí ìwé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì “dá a lójú hán-únhán-ún” pé àwọn ẹ̀kọ́ wọn ló tọ̀nà. Banchetti tún wá bí òun ṣe máa sọ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ di mímọ̀ ní ọ̀nà tirẹ̀.
Ó hàn kedere nínú àwọn ìwé tí Banchetti kọ pé, bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni òun náà ṣe gbà gbọ́ pé àjíǹde ti orí ilẹ̀ ayé yóò wà, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi kọ́ni. Ó tún fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó ṣàlàyé pé ọdún tí Jésù kú ti wà lákọsílẹ̀, Ọlọ́run sì ṣí i payá nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa àádọ́rin ọ̀sẹ̀. (Dáníẹ́lì 9:24-27) Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tó là á mọ́lẹ̀ láìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n sọ pé òun kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì òun. Ó sọ pé ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ló yẹ kí wọ́n máa ṣe Ìrántí ikú Jésù Kristi, “ìyẹn ni ọjọ́ náà gán-an tí àyájọ́ ọ̀hún bọ́ sí.” (Lúùkù 22:19, 20) Kò fara mọ́ àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n ti Darwin rárá, ó sì sọ pé kò yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ máa lọ́wọ́ nínú ogun ayé.—Aísáyà 2:4.
Ní àkókò kan, Banchetti ń bá ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ J. Campbell Wall fèròwérò lórí àwọn ìwé Russell. Ohun tí Banchetti fi fèsì àríwísí Wall ni pé: “Ó dá mi lójú pé tó o bá ka ìdìpọ̀ mẹ́fà ti Russell, wàá ní ayọ̀ tó kún rẹ́rẹ́, tó sì jinlẹ̀, wàá tún wá fi tọkàntọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ mi. Kì í ṣe pé mò ń ṣagbátẹrù ẹ̀kọ́ ìsìn o; àmọ́ mo ka àwọn ìwé wọ̀nyẹn lọ́dún mọ́kànlá sẹ́yìn, ojoojúmọ́ ni mo sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé ó fi irú ìmọ́lẹ̀ yẹn hàn mí, àti irú ìtùnú bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ìwé kan tá a gbé ka Ìwé Mímọ́ látìbẹ̀rẹ̀ dópin.”
“Fetí Sílẹ̀, Fetí Sílẹ̀, Fetí Sílẹ̀”
Ó yẹ fún àfiyèsí pé àwọn pásítọ̀ méjèèjì yìí tí wọ́n jẹ́ Ọmọlẹ́yìn Waldo—ìyẹn Daniele Rivoire àti Giuseppe Banchetti—mọrírì ọ̀nà tí Russell gbà ṣàlàyé Bíbélì. Banchetti kọ̀wé pé: “Mo sọ pé kò sí èyíkéyìí nínú àwa tá a jẹ́ Ajíhìnrere, kódà àwọn pásítọ̀ wa tàbí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn tó mọ gbogbo nǹkan tán. Rárá o, a ní ọ̀pọ̀ nǹkan, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan mìíràn láti kọ́. . . . [Ńṣe ló yẹ ká] . . . fara balẹ̀, ká fetí sílẹ̀, kì í ṣe ká máa rò pé a mọ gbogbo nǹkan tán, ká má sì ta ko ohun tí wọ́n bá ní ká gbé yẹ̀ wò. Dípò ìyẹn, ẹ jẹ́ ká fetí sílẹ̀, fetí sílẹ̀, fetí sílẹ̀.”
Ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ń fetí sílẹ̀ sí ìhìn Ìjọba náà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń mú wá sílé wọn. Ibi gbogbo làwọn tí kò ní ẹ̀tanú, tí òùngbẹ òtítọ́ Bíbélì ń gbẹ ti ń dáhùn sí ìkésíni Jésù pé: “Wá di ọmọlẹ́yìn mi.”—Máàkù 10:17-21; Ìṣípayá 22:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ Pierre Vaudès, tàbí Peter Waldo, tó jẹ́ oníṣòwò kan nílùú Lyons, ilẹ̀ Faransé ní ọ̀rúndún kejìlá ni wọ́n fi pe ẹgbẹ́ yìí. Wọ́n yọ Waldo kúrò nínú Ìjọ Kátólíìkì nítorí ohun tí ó gbà gbọ́. Fún àfikún ìsọfúnni nípa àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo, wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo—Látorí Jíjẹ́ Aládàámọ̀ Dórí Jíjẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì” nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2002.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ọ̀jọ̀gbọ́n Daniele Rivoire
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Giuseppe Banchetti
[Credit Line]
Banchetti: La Luce, April 14, 1926