Báwo Ni Agbára Láti Ronú Ṣe Lè Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọ?
ÌGBÌ omi tó lọ sókè lálá jẹ́ ìran àrímáleèlọ, àmọ́ ewu ńlá ló túmọ̀ sí fáwọn atukọ̀ ojú omi. Omi tó ń ru gùdù yẹn lè jẹ́ kí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn.
Bákan náà làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro tó máa dà bí èyí tó fẹ́ bò wọ́n mọ́lẹ̀. Onírúurú àdánwò àti ìdẹwò tó ń wọ àwọn Kristẹni lọ́rùn lè ti han ìwọ náà léèmọ̀. Ó dájú pé wàá fẹ́ kojú wọn lọ́nà tó dára, tí wàá pinnu láti yẹra fún ọkọ̀ rírì nípa tẹ̀mí. (1 Tímótì 1:19) Agbára láti ronú jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ohun tó o lè fi gbèjà ara rẹ. Kí ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lèèyàn sì ṣe ń ní in?
Ọ̀rọ̀ Hébérù náà mezim·mahʹ tá a túmọ̀ sí “agbára láti ronú,” wá látinú ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ kan tó túmọ̀ sí “láti múra sílẹ̀ tàbí wéwèé.” (Òwe 1:4) Ìdí nìyẹn tí àwọn ẹ̀dà Bíbélì kan fi túmọ̀ mezim·mahʹ sí “òye” tàbí “agbára láti mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la.” Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ nì, Jamieson, Fausset, àti Brown ṣàpèjúwe mezim·mahʹ gẹ́gẹ́ bíi “ṣíṣọ́ra lọ́nà téèyàn fi lè yàgò fún ibi kó sì rí ire.” Èyí túmọ̀ sí pé ká máa ronú lórí ohun tó máa tẹ̀yìn àwọn ìgbésẹ̀ tá a bá gbé yọ lọ́jọ́ iwájú àti nísinsìnyí pẹ̀lú. Tá a bá ní agbára láti ronú, a óò fara balẹ̀ ronú lórí ohun tá a fẹ́ ṣe ká tó gbégbèésẹ̀, àgàgà nígbà tá a bá ní ìpinnu pàtàkì láti ṣe.
Nígbà tẹ́ni tó ní agbára láti ronú bá ń ṣe ìpinnu nípa ọjọ́ iwájú tàbí nípa ipò tó bá ara rẹ̀ nísinsìnyí, yóò kọ́kọ́ gbé jàǹbá tàbí ọ̀fìn tó lè wà níbẹ̀ yẹ̀ wò. Tó bá ti rí àwọn ewu tó lè tibẹ̀ jáde, kíá ló máa wá bóun ṣe lè yẹra fún un, tá á ronú lórí ipa tó máa ní lórí àyíká òun àtàwọn tóun ń bá kẹ́gbẹ́. Yóò wá wéwèé ọ̀nà tó máa ní àbájáde rere, tí yóò ní ìbùkún Ọlọ́run pẹ̀lú. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ bíi mélòó kan tó ṣàpèjúwe ohun tá à ń wí yìí yẹ̀ wò.
Yẹra fún Ìdẹkùn Ìwà Pálapàla Láàárín Takọtabo
Nígbà tí ẹ̀fúùfù bá bi ìgbì omi lílágbára lu apá iwájú ọkọ ojú omi kan, ìbìlù láti ọwọ́ iwájú ni wọ́n máa ń pe irú ìyẹn. Àwọn atukọ̀ ojú omi mọ̀ pé ọkọ àwọn lè dojú dé, àyàfi tí wọ́n bá fọgbọ́n kojú ìgbì omi náà nípa jíjẹ́ kí apá iwájú ọkọ náà máa wo ọ̀ọ́kán.
A ń dojú kọ ipò kan náà, bí a ti ń gbé nínú ayé tí ìbálòpọ̀ ti gbòde kan. Ojoojúmọ́ ni ìgbì onírúurú èrò ìbálòpọ̀ ń dojú kọ wá. A ò lè fọwọ́ rọ́ ipa tí wọ́n lè ní lórí ìfẹ́ ìbálòpọ̀ wa sẹ́yìn. A gbọ́dọ̀ lo agbára láti ronú, ká sì kojú ìdẹwò náà láìjáfara, dípò tá a fi máa kóra wa sínú ipò eléwu bẹ́ẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Kristẹni ọkùnrin máa ń ṣiṣẹ́ níbi táwọn tí kò bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin ti ń ṣiṣẹ́, ìyẹn àwọn tí wọ́n ka obìnrin sí ohun èlò ìbálòpọ̀ lásán. Àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lè máa dá àwọn àpárá tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn, kí wọ́n sì máa sọ àwọn ẹ̀dà ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ nípa ìbálòpọ̀ takọtabo. Irú àyíká yìí lè wá gbin èrò ìṣekúṣe sọ́kàn Kristẹni kan ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.
Kristẹni obìnrin kan lè máa ṣiṣẹ́ níbì kan, kó sì wá dojú kọ ìṣòro níbẹ̀. Ó lè jẹ́ àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tí ìlànà ìwà rere tirẹ̀ kò bá tiwọn mu rárá ni wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lè máa fìfẹ́ hàn sí i. Ọkùnrin náà lè kọ́kọ́ máa gba tiẹ̀ rò, kódà kó máa bọ̀wọ̀ fún un nítorí ẹ̀sìn rẹ̀. Tó bá di pé ọkùnrin náà túbọ̀ ń sún mọ́ ọn, rírí tí wọ́n ń rí ara wọn ní gbogbo ìgbà lè mú kí arábìnrin náà fẹ́ kí wọ́n di ojúlùmọ̀ ara wọn.
Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, báwo ni agbára láti ronú ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nírú ipò yẹn? Lákọ̀ọ́kọ́, ó lè jẹ́ ká wà lójúfò sí àwọn ewu nípa tẹ̀mí tó lè tibẹ̀ jáde, èkejì ni pé ó lè sún wa láti wéwèé ohun tó tọ́ tó sì yẹ láti ṣe. (Òwe 3:21-23) Nínú irú àwọn ipò bí ìwọ̀nyí, èèyàn lè là á mọ́lẹ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé àwọn ìlànà tiwa yàtọ̀ sí tiwọn nítorí ohun tá a gbà gbọ́ nínú Ìwé Mímọ́. (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa lè jẹ́ kí ohun tá a sọ yẹn túbọ̀ yé wọn dáadáa. Síwájú sí i, a tún lè dín bá a ṣe ń bá àwọn kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ṣe wọléwọ̀de kù.
Àmọ́ ṣá o, àwọn ohun tó lè mú kéèyàn ṣèṣekúṣe kò mọ síbi iṣẹ́ nìkan. Wọ́n tún lè yọjú bí tọkọtaya kan bá jẹ́ kí àwọn ìṣòro tí wọ́n ń ní ba ìṣọ̀kan àárín àwọn jẹ́. Òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Ìgbéyàwó kan kì í ṣàdédé tú ká. Ó lè jẹ́ pé tọkọtaya náà ò gba tara wọn mọ́, kó jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ń bára wọn sọ̀rọ̀ tàbí kò máà sí àkókò tí wọ́n jọ ń wà pa pọ̀. Wọ́n lè máa lépa ohun ìní ti ara láti fi rọ́pò rádaràda tí ìgbéyàwó wọn ti dà. Nítorí pé wọn kì í ṣe ọ̀rẹ́ ara wọn mọ́, ọkàn wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí àwọn ẹlòmíràn tó jẹ́ ẹ̀yà kejì.”
Òjíṣẹ́ tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí wá sọ pé: “Ó yẹ kí àwọn tọkọtaya máa jókòó pa pọ̀ látìgbàdégbà, kí wọ́n máa fi àkókò yẹn bi ara wọn bóyá ohunkóhun ń pa àjọṣe wọn lára. Wọ́n gbọ́dọ̀ pinnu bí wọ́n ṣe lè máa ṣèkẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n máa gbàdúrà, kí wọ́n sì máa wàásù pa pọ̀. Wọ́n á jàǹfààní gan-an nípa bíbá ara wọn sọ̀rọ̀ ‘nínú ilé, lójú ọ̀nà, nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí wọ́n bá dìde,’ bí àwọn òbí ṣe ń ṣe sí àwọn ọmọ wọn gẹ́lẹ́.”—Diutarónómì 6:7-9.
Bíborí Àwọn Ìwà Tí Kì Í Ṣe Ti Kristẹni
Yàtọ̀ sí pé agbára láti ronú ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìdẹwò nípa ìwà rere ká sì ṣàṣeyọrí, ó tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro tá a lè ní pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Nígbà tí ẹ̀fúùfù bá bi ìgbì omi lu ẹ̀yìn ọkọ̀ ojú omi, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé ibikíbi tí ọkọ̀ náà bá dojú kọ ni ìbìlù yìí á bá a dojú kọ. Ìgbì omi náà lè mú kí ọkọ̀ ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ sí fẹ̀gbẹ́ rìn lọ. Èyí lè mú kí ọkọ̀ náà kẹ̀gbẹ́ sí apá ibi tí ìgbì omi náà ti ń wá kó sì wá bà á jẹ́.
Àwa náà lè ṣubú sínú ewu tó ń wá láti ibi tí a kò ti retí rẹ̀. À ń sin Jèhófà “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. (Sefanáyà 3:9) Bí ọ̀kan nínú wọn bá hùwà kan tí kò bá ti Kristẹni mu, ó lè dà bíi pé ńṣe lonítọ̀hún dà wá, ìyẹn sì lè kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Báwo ni agbára láti ronú kò ṣe ní í jẹ́ ká ṣìwà hù, tá ò sì ní jẹ́ kí ọ̀ràn náà dùn wá ju bó ti yẹ lọ?
Rántí pé “kò sí ènìyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 8:46) Nítorí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Kristẹni arákùnrin kan lè múnú bí wa tàbí kó ṣẹ̀ wá nígbà míì. Mímọ èyí yóò jẹ́ ká múra sílẹ̀ de irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ká sì ronú lórí ohun tó yẹ ká ṣe. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà táwọn kan lára àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ̀ sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ tó ń runni nínú sí i? Dípò tí ì bá fi ba ipò tẹ̀mí rẹ̀ jẹ́, ohun tó parí èrò sí ni pé rírí ojú rere Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì ju rírí ojú rere ènìyàn lọ. (2 Kọ́ríńtì 10:10-18) Irú èrò bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún yíyara gbégbèésẹ̀ nígbà tẹ́nì kan bá mú wa bínú.
Ńṣe ló dà bíi kéèyàn fi ìka ẹsẹ rẹ̀ gbá nǹkan. Nígbà tí èyí bá kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, ìrònú wa láàárín ìṣẹ́jú kan sí méjì àkọ́kọ́ yóò dàrú. Àmọ́ lẹ́yìn tí ìrora náà bá rọlẹ̀, a lè wá ronú lọ́nà tó já geere. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ yára fèsì ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tẹ́nì kan sọ sí wa tàbí ohun tí ò dáa tẹni kan ṣe sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ká sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí ohun tó lè jẹ àbájáde gbígbẹ̀san láìronú jinlẹ̀.
Malcolm, tó ti jẹ́ míṣọ́nnárì fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣe nígbà tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ ẹ́. Ó ní: “Ohun tí mo kọ́kọ́ máa ń ṣe ni pé màá bi ara mi láwọn ìbéèrè tí mo ti ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ pé: Ṣé ìwà wa tó yàtọ̀ síra ló jẹ́ kí n máa bínú sí arákùnrin yìí? Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ohun tó sọ ṣe pàtàkì tó ni? Ṣé kì í ṣe pé ibà ló fẹ́ yọ mi lẹ́nu tára mi fi ń gbóná sódì? Ǹjẹ́ mi ò ní rí i pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ láàárín wákàtí díẹ̀ sí i?” Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Malcolm máa ń rí i pé àríyànjiyàn náà kò ní láárí, ó sì ṣeé gbójú fò dá.a
Malcolm tún sọ pé: “Àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé pẹ̀lú gbogbo ìsapá tí mò ń ṣe láti yanjú ọ̀ràn náà, ńṣe ní arákùnrin náà máa kọ̀ jálẹ̀ tí kò ní fẹ́ ṣe bí ọ̀rẹ́ sí mi. Mo máa ń gbìyànjú láti máà jẹ́ kí èyí nípa lórí mi. Bí mo bá ti rí i pé mo ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe, ojú mìíràn ni mo fi máa ń wo ọ̀ràn náà. Nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, mo máa ń wo ọ̀ràn náà bí èyí tó lè yanjú tó bá yá, dípò kí n máa wò ó bí èyí tí mo gbọ́dọ̀ yanjú kíákíá. N kì í jẹ́ kó pa mí lára nípa tẹ̀mí tàbí kó nípa lórí àjọṣe àárín èmi àti Jèhófà àtàwọn arákùnrin mi.”
Bíi ti Malcolm, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àṣìṣe ẹlòmíràn dà wá láàmú ju bó ti yẹ lọ. Gbogbo ìjọ ni àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n yá mọ́ni tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ wà. Inú wa sì dùn láti rin ọ̀nà Kristẹni “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú wọn. (Fílípì 1:27) Rírántí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ tí Baba wa ọ̀run ń fún wa yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti wo àwọn ọ̀ràn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.—Sáàmù 23:1-3; Òwe 5:1, 2; 8:12.
Ṣíṣàì Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ Nínú Ayé
Agbára láti ronú tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìdẹwò mìíràn. Nígbà tí ẹ̀fúùfù bá bi ìgbì omi lu ẹ̀gbẹ́ ọkọ̀, ìbìlù ẹlẹ́gbẹ̀ẹ́ la máa ń pe irú ìyẹn. Bí ojú ọjọ́ bá dára, irú ìbìlù bẹ́ẹ̀ lè mú kí ọkọ̀ fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ kó kọjú síbòmíràn. Àmọ́ tó bá jẹ́ àkókò tí ìjì ń jà ni, irú ìbìlù ẹlẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ lè dojú ọkọ̀ dé.
Bákan náà, bí a bá lọ fi ara wa fún ìdẹwò láti gbádùn gbogbo ohun tí ayé yìí lè fúnni, ọ̀nà ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì yìí lè tì wá kúrò lójú ọ̀nà nípa tẹ̀mí. (2 Tímótì 4:10) Bá ò bá tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá, ìfẹ́ ayé lè mú ká pa ipa ọ̀nà Kristẹni tá à ń tọ̀ tì pátápátá ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. (1 Jòhánù 2:15) Báwo ni agbára láti ronú ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
Lákọ̀ọ́kọ́, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú ewu tó tún lè yọjú. Gbogbo ọgbọ́n téèyàn lè ronú kàn ni ayé yìí lè fi fà wá. Kì í yé gbé ọ̀nà ìgbésí ayé tó máa dà bí èyí tí gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ máa lépa lárugẹ—ìyẹn ni ìgbésí ayé ṣekárími táwọn olówó, àwọn tó gbáfẹ́, àtàwọn “tó dà bíi pé nǹkan ti ṣẹnuure fún” ń gbé. (1 Jòhánù 2:16) Ó ń fi yé wa pé gbogbo èèyàn lá máa kan sáárá sí wa, wọ́n á sì máa gba tiwa, àgàgà àwọn ojúgbà wa àtàwọn aládùúgbò wa. Agbára láti ronú yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún irú ìpolongo èké bẹ́ẹ̀, yóò máa rán wa létí ìjẹ́pàtàkì ‘wíwà láìsí ìfẹ́ owó,’ níwọ̀n bí Jèhófà ti ṣèlérí fún wa pé ‘òun ò ní fi wá sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’—Hébérù 13:5.
Ìkejì, agbára láti ronú kò ní jẹ́ ká máa tẹ̀ lé àwọn tó ti “yapa kúrò nínú òtítọ́.” (2 Tímótì 2:18) Ó ṣòro gan-an láti lòdì sáwọn tá a fẹ́ràn tá a sì fọkàn tán tẹ́lẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:12, 32-34) Kódà bó tilẹ̀ jẹ́ ipa díẹ̀ làwọn tó ti fi ipa ọ̀nà Kristẹni sílẹ̀ ní lórí wa, síbẹ̀ ó lè ṣèdíwọ́ fún ìlọsíwájú wa nípa tẹ̀mí, kó sì wá fí wa sínú ewu tó bá yá. A lè dà bí ọkọ̀ òkun tó kàn rọra sún kúrò lójú ọ̀nà tó yẹ kó gbà. Bó ṣe ń bá ìrìn àjò náà lọ, irú ọkọ̀ òkun bẹ́ẹ̀ lè lọ gúnlẹ̀ sí ibi tó jìnnà gan-an síbi tó yẹ kó gúnlẹ̀ sí.—Hébérù 3:12.
Agbára láti ronú lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ipò tá a wà nípa tẹ̀mí àti ibi tí à ń lọ. Ó ṣeé ṣe ká wá mọ̀ pé ó yẹ ká túbọ̀ kópa nínú ìgbòkègbodò Kristẹni. (Hébérù 6:11, 12) Wo bí ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan ṣe jẹ́ kí agbára láti ronú ran òun lọ́wọ́ láti lé àwọn góńgó tẹ̀mí bá: “Mo láǹfààní àtilọ kàwé kí n sì di akọ̀ròyìn. Èyí wù mí gan-an, àmọ́ mo rántí ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé ‘ayé ń kọjá lọ,’ àmọ́ ‘ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.’ (1 Jòhánù 2:17) Mo ronú pé ohun tí mo bá fi ìgbésí ayé mi ṣe gbọ́dọ̀ fi ohun tí mo gbà gbọ́ hàn. Àwọn òbí mi ti pa ìgbàgbọ́ Kristẹni tì, mi ò sì fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Nítorí náà, mo pinnu láti gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ìyẹn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Lẹ́yìn tí mo ti ní ìfọ̀kànbalẹ̀ fún ọdún mẹ́rin, mo wá mọ̀ pé mo ṣe yíyàn tó tọ́.”
Kíkojú Ìjì Tẹ̀mí Ká sì Ṣàṣeyọrí
Kí nìdí tó fi jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú fún wa láti ní agbára láti ronú lóde òní? Àwọn atukọ̀ ojú omi ní láti wà lójúfò sí àwọn àmì tó ń fi hàn pé ewu ń bọ̀, àgàgà nígbà tí ìjì bá ń gbára jọ. Bí òtútù bá mú gan-an, tí ẹ̀fúùfù sì túbọ̀ ń le sí i, wọ́n á fa irin tàbí igi tó wà lára aṣọ tapólì ọkọ̀ wọn wálẹ̀, wọ́n á sì múra de ohun búburú tó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ múra láti kojú pákáǹleke tó ga gan-an bí ètò búburú yìí ṣe ń sún mọ́ òpin rẹ̀. Ńṣe ni ìwà àwọn èèyàn túbọ̀ ń burú sí i láwùjọ, tí ‘àwọn èèyàn búburú sì ń tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.’ (2 Tímótì 3:13) Gẹ́gẹ́ bí àwọn atukọ̀ ojú omi ṣe máa ń fetí sáwọn tó ń sọ bí ojú ọjọ́ ṣe máa rí làwa náà ṣe gbọ́dọ̀ kọbi ara sí àwọn ìkìlọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí.— Sáàmù 19:7-11.
Nígbà tá a bá lo agbára láti ronú, à ń fi ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun sílò nìyẹn. (Jòhánù 17:3) A lè máa retí pé àwọn ìṣòro lè dé, ká sì pinnu bí a ó ṣe ṣẹ́pá wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó gbára dì dáadáa láti má ṣe sún kúrò ní ipa ọ̀nà Kristẹni, ìyẹn yóò sì jẹ́ ká lè fi ‘ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lélẹ̀ fún ara wa de ẹ̀yìn ọ̀la’ nípa gbígbé àwọn góńgó tẹ̀mí kalẹ̀ ká sì máa lépa wọn.—1 Tímótì 6:19.
Bí a bá fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú, kò sídìí fún wa “láti fòyà ohun òjijì èyíkéyìí tí ó jẹ́ akún-fún-ìbẹ̀rùbojo.” (Òwe 3:21, 25, 26) Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè rí ìtùnú nínú ìlérí Ọlọ́run pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ.”—Òwe 2:10, 11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti wá àlàáfíà níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Mátíù 5:23, 24. Bí ọ̀ràn náà bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, wọ́n gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti jèrè arákùnrin wọn, gẹ́gẹ́ bá a ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú Mátíù 18:15-17. Wo Ilé Ìṣọ́ October 15, 1999, ojú ìwé 17 sí 22.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ déédéé ń gbé ìgbéyàwó ró