Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó Wà Nínú Àkọsílẹ̀ Ìbí Jésù
ÀWỌN ìṣẹ̀lẹ̀ tó wé mọ́ ìbí Jésù máa ń wú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lórí. A máa ń rí èyí nínú àìmọye àwòrán Ìbí Jésù táwọn èèyàn máa ń fi hàn àtàwọn eré Ìbí Jésù tí wọ́n máa ń ṣe káàkiri ayé lásìkò ọdún Kérésìmesì. Òótọ́ làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wé mọ́ ìbi Jésù máa ń wúni lórí àmọ́ kì í ṣe tìtorí àtidánilárayá la ṣe kọ wọ́n sínú Bíbélì. Dípò ìyẹn, wọ́n jẹ́ apá kan gbogbo Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí fún kíkọ́ni àti fún mímú àwọn nǹkan tọ́.—2 Tímótì 3:16.
Ká ní Ọlọ́run fẹ́ káwọn Kristẹni máa ṣayẹyẹ ìbi Jésù ni, Bíbélì ì bá ti sọ ọjọ́ tó jẹ́ gan-an fún wa. Àbó ṣe bẹ́ẹ̀? Lẹ́yìn tí Albert Barnes, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bíbélì ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, sọ pé a bí Jésù lákòókò táwọn olùṣọ́ àgùntàn wà níta gbangba tí wọ́n ń ṣọ́ agbo ẹran wọn lóru, ó wá sọ pé: “Èyí mú kó ṣe kedere pé a bí Olùgbàlà wa ṣáájú ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù December . . . Òtútù máa ń mú gan-an lásìkò yìí pàápàá láwọn agbègbè olókè ńláńlá nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ọlọ́run ò sọ ọjọ́ ìbí [Jésù]. . . . Kò sì pọn dandan pé ká mọ ọjọ́ yẹn; ká ló pọn dandan ni, Ọlọ́run ì bá ti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀.”
Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, kedere làwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ ọjọ́ tí Jésù kú fún wa. Ọjọ́ àjọ̀dún Ìrékọjá lọjọ́ náà, èyí tó bọ́ sí ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn àwọn Júù, nígbà ìrúwé. Síwájú sí i, Jésù dìídì pa á láṣẹ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣayẹyẹ ọjọ́ náà ní ìrántí òun. (Lúùkù 22:19) Kò síbì kankan tí Bíbélì ti pa á láṣẹ pé ká ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù tàbí ti ẹnikẹ́ni. Ó bani nínú jẹ́ pé àríyànjiyàn tó ń lọ lórí ọjọ́ ìbí Jésù lè máà jẹ́ kéèyàn ka ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó wáyé láàárín àkókò náà sí.
Àwọn Òbí Tí Ọlọ́run Yàn
Irú àwọn òbí wo ni Ọlọ́run yàn láti bá a tọ́ Ọmọ rẹ̀ nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé tó wà ní Ísírẹ́lì? Ǹjẹ́ Ó ronú pé ẹni tó lókìkí tó sì lówó lọ́wọ́ ló yẹ kó jẹ́? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ànímọ́ Ọlọ́run táwọn òbí yìí ní ni Jèhófà kíyè sí. Gbé orin ìyìn tí Màríà kọ, èyí tó wà ní Lúùkù 1:46-55 yẹ̀ wò. Ẹ̀yìn ìgbà tó gbọ́ nípa àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tó ní láti di ìyá Mèsáyà náà ló kọrin yìí. Lára ohun tó sọ ni pé: “Ọkàn mi gbé Jèhófà ga lọ́lá, . . . nítorí tí ó ti bojú wo ipò rírẹlẹ̀ ẹrúbìnrin rẹ̀.” Ó fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ka ara rẹ̀ sí ẹni tó wà ní “ipò rírẹlẹ̀,” ẹrúbìnrin Jèhófà. Ohun tó ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn dáradára tó wà nínú orin tí Màríà kọ fi hàn pé ẹni tẹ̀mí tó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ ni òun náà, síbẹ̀ òun la kà sí ẹni tó yẹ láti jẹ́ ìyá Ọmọ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.
Ọkọ Màríà náà ńkọ́, tó wá di alágbàtọ́ Jésù? Gbẹ́nàgbẹ́nà tó mọṣẹ́ dunjú ni Jósẹ́fù. Mímú tó mú iṣẹ́ rẹ̀ lọ́kùn-únkún-dùn ló jẹ́ kó lè gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀ tó wá ní, ó kéré tán, ọmọkùnrin márùn-ún àti ọmọbìnrin méjì nínú. (Mátíù 13:55, 56) Jósẹ́fù kì í ṣe ọlọ́rọ̀. Ó ti ní láti jẹ́ ìjákulẹ̀ gan-an fún Jósẹ́fù pé òun ò rówó ra àgùntàn láti fi rúbọ nígbà tí àkókò tó fún Màríà láti gbé àkọ́bí rẹ̀ wá sí tẹ́ńpìlì. Ohun àfidípò tágbára àwọn tí ò rí já jẹ lè ká ni wọ́n lò. Ohun tí òfin Ọlọ́run sọ nípa obìnrin tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ni pé: “Bí agbára rẹ̀ kò bá ká àgùntàn, nígbà náà, kí ó mú oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, ọ̀kan fún ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un, kí obìnrin náà sì mọ́.”—Léfítíkù 12:8; Lúùkù 2:22-24.
Bíbélì sọ pé Jósẹ́fù “jẹ́ olódodo.” (Mátíù 1:19) Bí àpẹẹrẹ, kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ wúńdíá títí tíyẹn fi bí Jésù. Èyí bẹ́gi dínà awuyewuye èyíkéyìí tí ì bá wáyé nípa ẹni tó jẹ́ Bàbá Jésù gan-an. Kò lè rọrùn rárá pé kí tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ra wọn máà ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n sì jọ máa gbénú ilé kan náà. Àmọ́ èyí fi hàn pé àwọn méjèèjì ló fi ọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní jíjẹ́ òbí Ọmọ Ọlọ́run.—Mátíù 1:24, 25.
Jósẹ́fù tún jẹ́ ẹni tẹ̀mí bí i ti Màríà. Ọdọọdún ló máa ń pa iṣẹ́ rẹ̀ tì táá sì mú ìdílé rẹ̀ rìnrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ta láti Násárétì lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àjọ̀dún Ìrékọjá tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. (Lúùkù 2:41) Bákan náà, Jósẹ́fù ti ní láti kọ́ Jésù tó ṣì jẹ́ ọmọdé ní àṣà jíjọ́sìn nínú sínágọ́gù tó wà ládùúgbò wọn, níbi tí wọ́n ti ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣàlàyé rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. (Lúùkù 2:51; 4:16) Fún ìdí yìí, kò sí iyèméjì pé ojúlówó ìyá àti bàbá alágbàtọ́ tó yẹ ni Jèhófà yàn fún Ọmọ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
Ìbùkún Ńláǹlà fún Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Olùṣọ́ Àgùntàn
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè rọrùn rárá fún ìyàwó Jósẹ́fù tí oyún rẹ̀ ti pé oṣù mẹ́sàn-án báyìí, síbẹ̀ Jósẹ́fù mú ọ̀nà ìlú àwọn baba ńlá rẹ̀ pọ̀n láti lọ forúkọ sílẹ̀ níbàámu pẹ̀lú òfin Késárì. Nígbà tí tọkọtaya náà dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọn ò ríbi tí wọ́n á wọ̀ sí láàárín ìlú náà tí èrò kúnnú rẹ̀ fọ́fọ́. Bí ipò nǹkan ṣe rí yìí ló sọ wọ́n dèrò ilé àwọn ẹran ọ̀sìn kan, níbi tí wọ́n bí Jésù sí tí wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran. Kí ìgbàgbọ́ àwọn òbí onírẹ̀lẹ̀ yìí lè lágbára sí i, Jèhófà pèsè ohun kan láti fi dá wọn lójú pé bíbí tí wọ́n bímọ yìí jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́, ṣé àwọn àgbààgbà tó jẹ́ olókìkí láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ló rán sí tọkọtaya náà? Rárá o. Dípò ìyẹn, àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó múṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, tí wọ́n wà níta níbi tí wọ́n ti ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní gbogbo òru, ni Jèhófà Ọlọ́run fi ọ̀ràn náà hàn.
Áńgẹ́lì Ọlọ́run yọ sí wọn ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, pé wọ́n á rí Mèsáyà náà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí “ní ìdùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.” Ǹjẹ́ gbígbọ́ táwọn ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí gbọ́ pé Mèsáyà náà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí wà ní ilé ẹran ọ̀sìn mú kí ọkàn wọn gbọgbẹ́ tàbí mú kára wọn bù máṣọ? Rárá o! Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n fi agbo ẹran wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì mú ọ̀nà Bẹ́tílẹ́hẹ́mù pọ̀n. Nígbà tí wọ́n rí Jésù, wọ́n sọ ohun tí Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ fún wọn fún Jósẹ́fù àti Màríà. Ó dájú pé èyí túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ tọkọtaya náà lókun pé gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ wà níbàámu pẹ̀lú ète Ọlọ́run. Ní ti “àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà,” wọ́n “padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń yìn ín fún gbogbo ohun tí wọ́n gbọ́, tí wọ́n sì rí.” (Lúùkù 2:8-20) Dájúdájú, ohun tó tọ̀nà ni Jèhófà ṣe pẹ̀lú bó ṣe fi ọ̀ràn náà han àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó bẹ̀rù Ọlọ́run.
Ohun tá a sọ lókè yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa irú èèyàn tó yẹ ká jẹ́ láti jàǹfààní ojú rere Jèhófà. A ò gbọ́dọ̀ máa wọ́nà àtidi olókìkí tàbí ọlọ́rọ̀. Dípò èyí, a gbọ́dọ̀ dà bí Jósẹ́fù, Màríà àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyẹn, ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run ká sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nípa fífi àwọn ohun tẹ̀mí ṣáájú àwọn ohun tara. Ká sòótọ́, a lè rí ẹ̀kọ́ dáadáa kọ́ tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láàárín àkókò tá a bí Jésù.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kí ni fífi tí Màríà fi ẹyẹlé méjì rúbọ fi hàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọlọ́run yàn láti fi ìbí Jésù han ìwọ̀nba àwọn onírẹ̀lẹ̀ olùṣọ́ àgùntàn