‘Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín’
“Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—JÒHÁNÙ 13:35.
1. Ànímọ́ wo ni Jésù tẹnu mọ́ nígbà tó kù díẹ̀ kó kú?
“Ẹ̀YIN ọmọ kéékèèké.” (Jòhánù 13:33) Gbólóhùn ìfẹ́ni yẹn ni Jésù lò fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lálẹ́ to ṣáájú ọjọ́ ikú rẹ̀. A ò rí i nínú àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere pé Jésù ti lo irú gbólóhùn ìfẹ́ni yìí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣáájú àkókò yìí. Àmọ́, ní òru mánigbàgbé yẹn, Jésù lo ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ yìí láti fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó ní sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ hàn. Kódà, nǹkan bí ọgbọ̀n ìgbà ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ lóru ọjọ́ yẹn. Kí ló mú kó tẹnu mọ́ ànímọ́ yìí tó bẹ́ẹ̀?
2. Kí nìdí tí fífi ìfẹ́ hàn fi ṣe pàtàkì fáwọn Kristẹni?
2 Jésù ṣàlàyé ìdí tí ìfẹ́ fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35; 15:12, 17) Jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi wé mọ́ fífi ìfẹ́ ará hàn. Kì í ṣe oríṣi aṣọ kan tàbí àwọn àṣà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ la fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀, bí kò ṣe ìfẹ́ ọlọ́yàyà tí wọ́n ní láàárín ara wọn. Níní irú ìfẹ́ títayọ yìí jẹ́ ìkejì lára àwọn ohun pàtàkì mẹ́ta tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní ànímọ́ tó pọn dandan yìí?
“Ṣíṣe É Ní Ìwọ̀n Kíkúnrẹ́rẹ́ Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ”
3. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fúnni nípa ìfẹ́?
3 Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ní ọ̀rúndún kìíní, ìfẹ́ títayọ yìí kò mù rárá lónìí láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tòótọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pé: “Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ kò nílò kí a máa kọ̀wé sí yín, nítorí Ọlọ́run ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; ní ti tòótọ́, ẹ sì ń ṣe é sí gbogbo àwọn ará.” Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “[Ẹ] máa bá a lọ ní ṣíṣe é ní ìwọ̀n kíkúnrẹ́rẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ.” (1 Tẹsalóníkà 3:12; 4:9, 10) Ó yẹ kí àwa náà fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò, ká gbìyànjú láti máa fi ìfẹ́ hàn láàárín ara wa “ní ìwọ̀n kíkúnrẹ́rẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
4. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù àti Jésù ṣe sọ, àwọn wo ló yẹ ká fún ní àfiyèsí àkànṣe?
4 Nínú lẹ́tà onímìísí kan náà yẹn, Pọ́ọ̀lù gba àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ níyànjú láti “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́” kí wọ́n sì “ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Lákòókò mìíràn, ó rán àwọn Kristẹni létí pé ó yẹ ‘kí àwọn tí wọ́n ní okun máa ru ẹrù àìlera àwọn tí kò lókun.’ (Róòmù 15:1) Jésù náà fúnni nímọ̀ràn nípa ṣíṣèrànwọ́ fáwọn aláìlera. Lẹ́yìn tí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Pétérù má sẹ́ òun lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n á wá mú òun, ó sọ fún Pétérù pé: “Gbàrà tí o bá ti padà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.” Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn yẹn náà á ti kọ Jésù sílẹ̀ wọ́n á sì torí èyí nílò ìrànlọ́wọ́. (Lúùkù 22:32; Jòhánù 21:15-17) Nítorí náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé ká jẹ́ kí ìfẹ́ dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ní àìlera nípa tẹ̀mí tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi ìjọ Kristẹni sílẹ̀. (Hébérù 12:12) Èé ṣe tó fi yẹ ká ṣe èyí? Àkàwé méjì tí Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè yìí.
Àgùntàn àti Ẹyọ Owó Tó Sọ Nù
5, 6. (a) Àwọn àkàwé ṣókí méjì wo ni Jésù ṣe? (b) Kí làwọn àkàwé wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
5 Nígbà tí Jésù fẹ́ kọ́ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn to ti ṣáko lọ, ó sọ àkàwé kúkúrú méjì. Ọ̀kan dá lórí olùṣọ́ àgùntàn kan. Jésù sọ pé: “Ọkùnrin wo nínú yín tí ó ní ọgọ́rùn-ún àgùntàn, nígbà tí ọ̀kan nínú wọn bá sọnù, tí kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún sílẹ̀ sẹ́yìn ní aginjù, kí ó sì wá ọ̀kan tí ó sọnù lọ títí yóò fi rí i? Nígbà tí ó bá sì ti rí i, a gbé e lé èjìká rẹ̀, a sì yọ̀. Nígbà tí ó bá sì dé ilé, a pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, a sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí àgùntàn mi tí ó sọnù.’ Mo sọ fún yín pé báyìí ni ìdùnnú púpọ̀ yóò ṣe wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà ju lórí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún àwọn olódodo tí wọn kò nílò ìrònúpìwàdà.”—Lúùkù 15:4-7.
6 Àkàwé kejì dá lórí obìnrin kan. Jésù sọ pé: “Tàbí obìnrin wo tí ó ní ẹyọ owó dírákímà mẹ́wàá, bí ó bá sọ ẹyọ owó dírákímà kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó sì gbá ilé rẹ̀, kí ó sì fara balẹ̀ wá a kiri títí yóò fi rí i? Nígbà tí ó bá sì ti rí i, a pe àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò rẹ̀ jọ, a sọ pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, nítorí mo ti rí ẹyọ owó dírákímà tí mo sọnù.’ Mo sọ fún yín, báyìí ni ìdùnnú ṣe máa ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà.”—Lúùkù 15:8-10.
7. Ẹ̀kọ́ méjì wo la rí kọ́ nínú àkàwé àgùntàn àti ẹyọ owó tó sọ nù?
7 Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú àwọn àkàwé ṣókí méjì yìí? Wọ́n jẹ́ ká mọ (1) bó ṣe yẹ kí ọ̀ràn àwọn tó ti di aláìlera rí lára wa àti (2) ohun tó yẹ ká ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Ó Sọ Nù àmọ́ Ó Ṣì Ṣeyebíye
8. (a) Báwo ni olùṣọ́ àgùntàn àti obìnrin kan ti ṣe nígbà tí nǹkan sọ nù lọ́wọ́ wọn? (b) Kí ni ohun táwọn èèyàn méjì yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ nípa ojú tí wọ́n fi wo ohun tó sọ nù lọ́wọ́ wọn?
8 Inú àkàwé méjèèjì ni nǹkan kan ti sọ nù, àmọ́ kíyè sí ohun táwọn tí nǹkan wọn sọ nù ṣe. Olùṣọ́ àgùntàn náà kò sọ pé: ‘Kí ni màá máa torí àgùntàn kan ṣoṣo ṣe wàhálà sí nígbà tí mo ṣì ní mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún? Ẹyọ kan tó sọ nù yìí ò ba ohunkóhun jẹ́ o jàre.’ Obìnrin náà ò sọ pé: ‘Kí ni màá máa torí ẹyọ owó kan péré da ara mi láàmú sí? Mẹ́sàn-án tí mo ní ṣì tó fún mi o jàre.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni olùṣọ́ àgùntàn náà wá àgùntàn rẹ̀ tó sọ nù bí ẹni pé ẹyọ kan yẹn péré ló ní. Owó ẹyọ kan tó sọ nù lọ́wọ́ obìnrin náà dùn ún wọ akínyẹmí ará bí ẹni pé kò ní òmíràn mọ́. Inú àkàwé méjèèjì lohun tó sọ nù ti ṣeyebíye sí ẹni tó ni ín. Kí lèyí ṣàpèjúwe?
9. Kí ni àníyàn tí olùṣọ́ àgùntàn àti obìnrin náà ṣe ṣàpèjúwe?
9 Kíyè sí bí Jésù ṣe parí àkàwé méjèèjì, ó ní: “Báyìí ni ìdùnnú púpọ̀ yóò ṣe wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà,” àti “báyìí ni ìdùnnú ṣe máa ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà.” Nítorí náà, dé àyè kan, ńṣe ni àníyàn olùṣọ́ àgùntàn yìí àti ti obìnrin náà ń fi bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára Jèhófà àtàwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ tó wà lọ́run hàn. Bí nǹkan tó sọ nù ṣe ṣeyebíye lójú olùṣọ́ àgùntàn náà àti obìnrin náà, bẹ́ẹ̀ làwọn tó ti ṣáko lọ tí wọn ò sì bá àwọn èèyàn Ọlọ́run pé jọ mọ́ ṣe ṣeyebíye lójú Jèhófà. (Jeremáyà 31:3) Àwọn èèyàn yìí lè jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí lóòótọ́, àmọ́ èyí ò fi dandan túmọ̀ sí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ ń ṣòjòjò nípa tẹ̀mí, síbẹ̀ wọ́n ṣì lè máa pa àwọn òfin Jèhófà mọ́ dé àyè kan. (Sáàmù 119:176; Ìṣe 15:29) Ìdí rèé, bíi ti ìgbà àtijọ́, tí Jèhófà fi ń lọ́ra láti “ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀.”—2 Àwọn Ọba 13:23.
10, 11. (a) Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tó ti ṣáko lọ kúrò nínú ìjọ? (b) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àkàwé méjèèjì tí Jésù ṣe fi hàn, báwo la ṣe lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé à ń ṣàníyàn nípa wọn?
10 Bíi ti Jèhófà àti Jésù, àwa náà máa ń ṣàníyàn gan-an nípa àwọn tára wọn ò le nípa tẹ̀mí tí wọn kì í sì í wá sí ìjọ Kristẹni mọ́. (Ìsíkíẹ́lì 34:16; Lúùkù 19:10) Ojú àgùntàn tó sọ nù lá fi ń wo àwọn tára wọn ò le nípa tẹ̀mí o, a ò kà wọ́n sí ẹni tó ti re àjò àrèmábọ̀. A kì í ronú pé: ‘Kí la fẹ́ máa torí ẹnì kan ṣoṣo tó ní àìlera tẹ̀mí ṣe wàhálà fún? Ìjọ á kúkú máa lọ bó ṣe yẹ láìsí ẹni náà níbẹ̀.’ Kàkà ká ronú lọ́nà yìí, bíi ti Jèhófà, àwa náà máa ń fojú ẹni tó ṣeyebíye wo àwọn tó ti ṣáko lọ àmọ́ tí wọ́n fẹ́ padà.
11 Nígbà náà, báwo la ṣe lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé lóòótọ́ là ń ṣàníyàn nípa wọn? Àkàwé méjì tí Jésù ṣe fi hàn pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀ (1) nípa lílo ìdánúṣe, (2) nípa fífẹ̀sọ̀ ṣe é àti (3) ká má ṣe jẹ́ kó sú wa. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.
Lo Ìdánúṣe
12. Kí ni gbólóhùn náà “wá ọ̀kan tí ó sọnù lọ” jẹ́ ká mọ̀ nípa irú ẹ̀mí tí olùṣọ́ àgùntàn náà ní?
12 Nínú àkàwé àkọ́kọ́, Jésù sọ pé olùṣọ́ àgùntàn náà á “wá ọ̀kan tí ó sọnù lọ.” Olùṣọ́ àgùntàn náà lo ìdánúṣe àti ìsapá ńláǹlà láti wá àgùntàn tó sọ nù ní àwárí. Ipò nǹkan tó le koko, ewu àti ọ̀nà jíjìn kò dá a dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni olùṣọ́ àgùntàn yìí á wá ẹran rẹ̀ “títí yóò fi rí i.”—Lúùkù 15:4.
13. Báwo làwọn olóòótọ́ ayé ọjọ́un ṣe bójú tó àwọn tó jẹ́ aláìlera, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé irú àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì bẹ́ẹ̀?
13 Lọ́nà kan náà, ríran ẹnì kan tó nílò ìṣírí lọ́wọ́ sábà máa ń béèrè pé kí ẹni náà tó fẹ́ ṣèrànwọ́ lo ìdánúṣe. Àwọn olóòótọ́ ayé ọjọ́un mọ̀ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jónátánì, tó jẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù Ọba, kíyè sí i pé Dáfídì ọ̀rẹ́ òun àtàtà nílò ìṣírí, Jónátánì “dìde . . . ó sì lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hóréṣì, kí ó bàa lè fún ọwọ́ rẹ̀ lókun nípa ti Ọlọ́run.” (1 Sámúẹ́lì 23:15, 16) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, nígbà tí Nehemáyà tó jẹ́ Gómìnà kíyè sí i pé ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá àwọn kan nínú àwọn ará òun tí wọ́n jẹ́ Júù, ńṣe ló “dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀” tó sì gbà wọ́n níyànjú pé ‘kí wọ́n fi Jèhófà sọ́kàn.’ (Nehemáyà 4:14) Lọ́jọ́ tòní, àwa náà fẹ́ ‘dìde’—ká lo ìdánúṣe—láti fún àwọn tára wọn ò le nípa tẹ̀mí lókun. Àmọ́ àwọn wo ló yẹ kó ṣe èyí nínú ìjọ?
14. Àwọn wo nínú ìjọ Kristẹni ló yẹ kó ṣèrànwọ́ fáwọn aláìlera?
14 Àwọn Kristẹni alàgbà ló ni ẹrù iṣẹ́ náà láti “fún àwọn ọwọ́ tí kò lera lókun [kí wọ́n] sì mú àwọn eékún tí ń gbò yèpéyèpé le gírígírí,” àti láti “sọ fún àwọn tí ń ṣàníyàn nínú ọkàn-àyà pé: ‘Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ má fòyà.’” (Aísáyà 35:3, 4; 1 Pétérù 5:1, 2) Àmọ́ o, wàá kíyè sí i pé kì í ṣe kìkì àwọn alàgbà ni Pọ́ọ̀lù fún nímọ̀ràn láti máa “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́,” àti láti “máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera.” Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo “ìjọ àwọn ará Tẹsalóníkà” ni Pọ́ọ̀lù darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. (1 Tẹsalóníkà 1:1; 5:14) Nítorí náà, gbogbo Kristẹni pátá la yan iṣẹ́ ṣíṣèrànwọ́ fáwọn tára wọn ò le nípa tẹ̀mí fún. Gẹ́gẹ́ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn inú àkàwé náà, Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ múra tán láti “wá ọ̀kan tí ó sọnù lọ.” Lóòótọ́, láti lè ṣe èyí lọ́nà tó dára jù lọ, èèyàn ní láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà. Ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn ohun kan láti ran ẹnì kan tó ní àìlera tẹ̀mí nínú ìjọ rẹ lọ́wọ́?
Fẹ̀sọ̀ Ṣe É
15. Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí olùṣọ́ àgùntàn náà hùwà lọ́nà tó gbà hùwà?
15 Kí ni olùṣọ́ àgùntàn náà ṣe nígbà tó wá rí àgùntàn tó sọ nù náà? Ó “gbé e lé èjìká rẹ̀.” (Lúùkù 15:5) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí wúni lórí gan-an! Ó ṣeé ṣe kí àgùntàn náà ti rin ìrìn àrìnwọ́dìí fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ lágbègbè tí ò mọ̀ rí, kódà kìnnìún tó ń yọ́ kẹ́lẹ́ kiri pàápàá ì bá ti pa á jẹ́. (Jóòbù 38:39, 40) Kò sí ni, ebi á ti pa kísà sí i lára. Ẹ̀mí rẹ̀ ò ní lè gbé àwọn wàhálà tó máa kojú lọ́nà bó ṣe ń padà bọ̀ wá sáàárín agbo. Ìdí rèé tí olùṣọ́ àgùntàn náà fi bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, tó sì rọra gbé àgùntàn yìí kọjá àwọn ohun tó lè fún un ní wàhálà bó ṣe ń padà sáàárín agbo. Báwo la ṣe lè ṣe irú aájò tí olùṣọ́ àgùntàn yìí ṣe?
16. Èé ṣe tó fi yẹ ká hu irú ìwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí olùṣọ́ àgùntàn náà hù sí àgùntàn tó ṣáko lọ?
16 Àárẹ̀ tẹ̀mí lè ti mú ẹnì kan tí kò bá ìjọ ṣe pọ̀ mọ́. Bíi ti àgùntàn tó ti rìn lọ kúrò lọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn náà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ti máa rìn gbéregbère kiri nínú ayé búburú yìí. Láìsí ààbò látọ̀dọ̀ agbo, ìyẹn ìjọ Kristẹni, Èṣù tó “ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, [tó] ń wá ọ̀nà láti pani jẹ,” lè tètè ríbi ṣeni lọ́ṣẹ́. (1 Pétérù 5:8) Kò tán síbẹ̀ o, àìrí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ yóò tún jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu. Nítorí náà, tí ẹnikẹ́ni ò bá ràn án lọ́wọ́, kò lè lágbára láti kojú àwọn ìṣòro tó máa bá pàdé bó ṣe ń padà bọ̀ wá sínú ìjọ. Ìdí rèé tá a fi ní láti bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ká fẹ̀sọ̀ fa aláìlera náà dìde, ká sì mú un padà bọ̀ sípò. (Gálátíà 6:2) Báwo la ṣe lè ṣe èyí?
17. Báwo la ṣe lè ṣe bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà tá a bá lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tó jẹ́ aláìlera?
17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ta ni jẹ́ aláìléra tí n kò ní ìpín ninu àiléra rẹ̀?” (2 Kọ́ríńtì 11:29, Ìròyìn Ayọ̀; 1 Kọ́ríńtì 9:22) Pọ́ọ̀lù ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò sáwọn èèyàn, títí kan àwọn aláìlera. Ó yẹ kí àwa náà ní irú ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò yìí fún àwọn tó jẹ́ aláìlera. Nígbà tó o bá lọ sọ́dọ̀ Kristẹni kan tó jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí, fi í lọ́kàn balẹ̀ nípa jíjẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé àárò rẹ̀ ń sọ àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gan-an. (1 Tẹsalóníkà 2:17) Jẹ́ kó mọ̀ pé wọ́n múra tán láti tì í lẹ́yìn àti pé wọ́n ṣe tán láti jẹ́ “arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17; Sáàmù 34:18) Àwọn ọ̀rọ̀ tá a bá ń sọ látọkànwá lè bẹ̀rẹ̀ sí fún un níṣìírí débi táá fi lè padà sáàárín agbo. Kí la ó wàá ṣe lẹ́yìn èyí? Àkàwé obìnrin náà àti owó ẹyọ tó sọ nù tọ́ wa sọ́nà.
Má Ṣe Jẹ́ Kó Sú Ọ
18. (a) Èé ṣe tí obìnrin inú àkàwé náà ò fi sọ̀rètí nù? (b) Ìsapá wo ni obìnrin náà fi taratara ṣe, kí ló sì gbẹ̀yìn rẹ̀?
18 Obìnrin náà tó sọ ẹyọ owó kan nù mọ̀ pé ìṣòro ńlá ló délẹ̀ yìí àmọ́ kì í ṣe pé òun ò lè rí owó náà mọ́. Ká sọ pé inú igbó ni owó ẹyọ náà bọ́ sí tàbí inú ẹrọ̀fọ̀, ì bá ti gba kámú pé òun ò lè rí owó náà mọ́. Àmọ́, bó ṣe mọ̀ pé ibì kan nínú ilé ni owó náà bọ́ sí, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá a lójú méjèèjì. (Lúùkù 15:8) Iná ló kọ́kọ́ tàn kí òkùnkùn inú ilé náà lè pòórá. Lẹ́yìn náà ló ki ìgbálẹ̀ mọ́lẹ̀, tó bẹ̀rẹ̀ sí gbá gbogbo inú ilé pé bóyá òun á gbọ́ ìró owó ẹyọ náà. Ohun tó ṣe gbẹ̀yìn ni pé ó fara balẹ̀ wá gbogbo ibi kọ́lọ́fín inú ilé náà títí iná rẹ̀ fi kófìrí owó ẹyọ náà níbi tó gbé ń tàn yanranyanran. Ẹ ò rí i pé obìnrin yìí jèrè ìsapá tó fi taratara ṣe!
19. Ẹ̀kọ́ nípa bá a ṣe lè ran àwọn tó ní àìlera tẹ̀mí lọ́wọ́ wo la lè rí nínú àkàwé obìnrin tó sọ owó ẹyọ nù?
19 Gẹ́gẹ́ bí àkàwé yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀, ẹrù iṣẹ́ tí Ìwé Mímọ́ gbé lé wa lọ́wọ́ láti ran Kristẹni tó bá jẹ́ aláìlera lọ́wọ́ kò kọjá agbára wá. Lẹ́sẹ̀ kan náà, a mọ̀ pé ó gba ìsapá. Ó ṣe tán, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn alàgbà ará Éfésù pé: “Nípa ṣíṣe òpò lọ́nà yìí, ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera.” (Ìṣe 20:35a) Fi sọ́kàn pé obìnrin yìí kì bá tí rí owó ẹyọ náà ká ní pé ó kàn wá a fúngbà díẹ̀ kó sì ti sú u tàbí kó kàn wá ìwọ̀nba ibì kan nínú ilé náà. Àmọ́, ó ṣàṣeyọrí nítorí pé ńṣe ló fara balẹ̀ ‘wá a títí tó fi rí i.’ Lọ́nà kan náà, tá a bá fẹ́ ran ẹnì kan tó ní àìlera tẹ̀mí lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ fi taratara ṣe é ká má sì jẹ́ kó sú wa. Ki la lè ṣe?
20. Kí la lè ṣe láti ran àwọn aláìlera lọ́wọ́?
20 Báwo la ṣe lè ran ẹnì kan tó ní àìlera tẹ̀mí lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ àti ìmọrírì? Ó lè jẹ́ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìtẹ̀jáde Kristẹni tó bá ipò rẹ̀ mu lóhun tó nílò. Àní, ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan tó ní àìlera tẹ̀mí á fún wa láǹfààní láti ráyè ràn án lọ́wọ́ bó ti tọ́ àti bó ti yẹ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ló máa lè mọ ẹni tó tóótun jù lọ láti ran aláìlera náà lọ́wọ́. Ó lè dábàá àwọn kókó ẹ̀kọ́ tó yẹ kí wọ́n jíròrò àti ìtẹ̀jáde tó lè ṣèrànwọ́ jù lọ. Obìnrin inú àkàwé náà lo àwọn ohun èlò tó yẹ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeyọrí, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ làwa náà ní àwọn ohun èlò tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ láṣeyanjú, ìyẹn iṣẹ́ ríran àwọn tó ní àìlera tẹ̀mí lọ́wọ́. Méjì nínú àwọn ohun èlò tàbí ìtẹ̀jáde àkọ̀tun tá a ní, lè ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti ṣe èyí. Àwọn ìwé náà ni Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà àti Sún Mọ́ Jèhófà.a
21. Báwo ni ríran àwọn tó ní àìlera nípa tẹ̀mí lọ́wọ́ ṣe ń mú ìbùkún bá gbogbo wa pátá?
21 Ríran àwọn tó jẹ́ aláìlera lọ́wọ́ á mú ìbùkún wá fún gbogbo wa pátá. Inú ẹni tá a ràn lọ́wọ́ á máa dùn ṣìnkìn pé òun ti tún bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ kẹ́gbẹ́. À ń ní ayọ̀ àtọkànwá téèyàn ń rí nínú fífúnni. (Lúùkù 15:6, 9; Ìṣe 20:35b) Ìfẹ́ ló máa jọba láàárín gbogbo ìjọ lápapọ̀ nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá fẹ́ràn ẹnì kejì rẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, èyí á fi ọlá fún àwọn Olùṣọ́ àgùntàn wa onífẹ̀ẹ́, Jèhófà àti Jésù, bí àwọn ìránṣẹ́ wọn orí ilẹ̀ ayé ṣe ń gbé ìfẹ́ wọn láti ṣètìlẹ́yìn fáwọn aláìlera yọ. (Sáàmù 72:12-14; Mátíù 11:28-30; 1 Kọ́ríńtì 11:1; Éfésù 5:1) Ẹ ò rí i pé ìsúnniṣe ńláǹlà lèyí jẹ́ láti má ṣe dẹ́kun níní ‘ìfẹ́ láàárín ara wa’!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Èé ṣe tí fífi ìfẹ́ hàn fi ṣe pàtàkì fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa?
• Èé ṣe tó fi yẹ kí ìfẹ́ wa dé ọ̀dọ̀ àwọn aláìlera?
• Ẹ̀kọ́ wo ni àkàwé àgùntàn àti ẹyọ owó tó sọ nù kọ́ wa?
• Àwọn ìgbésẹ̀ tó dára wo la lè gbé láti ran ẹnì kan tó jẹ́ aláìlera lọ́wọ́?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Tá a bá fẹ́ ran àwọn tó ní àìlera lọ́wọ́, a óò lo ìdánúṣe, àá fẹ̀sọ̀ ṣe é, a ò sì ní jẹ́ kó sú wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ríran àwọn aláìlera lọ́wọ́ á mú ìbùkún wá fún gbogbo wa pátá