Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ìrànlọ́wọ́ Láti Múni Dúró Ṣinṣin Lórí Ọ̀ràn Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀
JÁKÈJÁDÒ ayé làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń fi ìdúróṣinṣin wọn sí Ọlọ́run hàn lórí ọ̀ràn ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà ti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará. (Mátíù 24:45-47) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀ lórílẹ̀ èdè Philippines.
Ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti Philippines ròyìn pé: “A fi tó wa létí lọ́dún 1990 pé àwọn aṣojú láti orílé iṣẹ́ ní Brooklyn yóò ṣèpàdé kan níhìn-ín ní Philippines. Wọ́n ké sí àwọn arákùnrin láti àwọn ẹ̀ka bíi mélòó kan ní Éṣíà àti lórílẹ̀ èdè Kòríà, Taiwan, àti Hong Kong. Ète ìpàdé yíì ni láti ṣètò bí wọ́n á ṣe dá Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni Ilé Ìwòsàn sílẹ̀ ní olúkúlùkù ẹ̀ka iléeṣẹ́ wọ̀nyí àti kí wọ́n lè ṣètò bí wọn á ṣe yan àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Ìlú ńlá mẹ́rin ní Philippines la ti kọ́kọ́ dá ìgbìmọ̀ yìí sílẹ̀. Àwọn ìgbìmọ̀ yìí yóò ṣakitiyan láti wá àwọn dókítà tó máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tó bá di ọ̀ràn ohun tí a gbà gbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Wọ́n á tún ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà tí ìṣòrò tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ bá wáyé pẹ̀lú.
Wọ́n yan Remegio sínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn nílùú Baguio. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn dókítà wá bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀ nípa ètò náà. Remegio rántí àkókò kan tí àwọn dókítà bíi mélòó kan ṣèpàdé pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn kan, wọ́n fẹ́ mọ ọ̀nà tí àwọn yóò máa gbà tọ́jú àwọn Ẹlẹ́rìí tó bá kọ̀ láti gbẹ̀jẹ̀ sára. Remegio sọ pé: “Àwọn dókítà náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ìbéèrè, àmọ́ ọ̀ràn náà tojú sú mi, torí pé ìbéèrè wọn ti takókó jù.” Ó wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kó lè borí ìṣòro náà. Remegio ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Lẹ́yìn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan, àwọn dókítà kan á nawọ́ sókè láti dáhùn, wọn á sì sọ bí àwọn ṣe bojú tó ipò tó jọ èyí tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́wọ́.” Inú Remegio dùn pé wọ́n ran òun lọ́wọ́, pàápàá jù lọ bó ṣe jẹ́ pé odindi wákàtí méjì gbáko ni wọ́n fi wà lẹ́nu ìbéèrè àti ìdáhùn náà.
Ìgbìmọ̀ mọ́kànlélógún ló wà jákèjádò orílẹ̀ èdè náà nísinsìnyí, tó ní àwọn arákùnrin mẹ́tàdínlọ́gọ́rin nínú. Danilo, ẹni tó jẹ́ dókítà tó tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí sọ pé: “Àwọn dókítà wá rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí táwọn ń tọ́jú ń rí ìtìlẹ́yìn gbà látọ̀dọ̀ ètò àjọ̀ kan tó bìkítà nípa wọn tìfẹ́tìfẹ́.” Oníṣègùn kan kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀ láti ṣe iṣẹ́ abẹ fún arákùnrin kan láìfa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Àmọ́ ṣá o, arákùnrin náà dúró gbọn-in ti ìpinnu rẹ̀. Wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ náà láìséwu kankan. Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni Ilé Ìwòsàn ròyìn pé: “Ńṣe lẹnu ya dókítà náà sí bí arákùnrin yìí ṣe kọ́fẹ padà. Ó wá sọ pé: ‘Fún ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dọ̀ mi yìí, tó bá ṣẹlẹ̀ nígbà míì pé ọ̀kan lára yín fẹ́ ṣe irú iṣẹ́ abẹ yìí láìfẹ́ gbẹ̀jẹ̀ sára, inú mi á dùn láti ṣe é.’”