Ǹjẹ́ O Máa Ń Béèrè Pé “Jèhófà Dà?”
“Wọ́n [ti] jìnnà réré sí mi . . . Wọn kò sì sọ pé, ‘Jèhófà dà?’”—JEREMÁYÀ 2:5, 6.
1. Kí ló ṣeé ṣe káwọn èèyàn ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n bá béèrè pé “Ọlọ́run dà?”
“ỌLỌ́RUN dà?” Àìmọye èèyàn ló ti béèrè ìbéèrè yìí. Lára àwọn tó ń béèrè irú ìbéèrè yìí kàn fẹ́ mọ òtítọ́ tó ṣe pàtàkì nípa Ẹlẹ́dàá náà ni, ìyẹn ni pé ibo ló wà? Àwọn mìíràn sì rèé, ìgbà tí wọ́n rí àjálù kan tó délé dóko tàbí ìgbà tí òde ò dẹrùn fún wọn tí wọn ò sì mọ ìdí tí Ọlọ́run ò fi dá sọ́ràn náà, ni wọ́n béèrè ìbéèrè yìí. Àwọn kan tún wà tí wọn ò tiẹ̀ béèrè irú ìbéèrè yìí rárá nítorí pé wọn ò gbà pé Ọlọ́run wà.—Sáàmù 10:4.
2. Àwọn wo ló ti wá Ọlọ́run láwàárí?
2 Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí ẹgbàágbèje ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà. (Sáàmù 19:1; 104:24) Ọkàn wọn sì ti balẹ̀ pé àwọn ṣáà ti ní ẹ̀sìn kan táwọn ń ṣe. Àmọ́ ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn kan ti ní ní gbogbo orílẹ̀-èdè ti mú kí wọ́n wá Ọlọ́run tòótọ́ náà láwàárí. Akitiyan wọn yìí kò sì já sásán nítorí pé Ọlọ́run “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:26-28.
3. (a) Ibo ni Ọlọ́run ń gbé? (b) Kí ni ìtumọ̀ ìbéèrè inú Ìwé Mímọ́ náà “Jèhófà dà”?
3 Nígbà tí ẹnì kan bá wá Jèhófà láwàárí lóòótọ́, onítọ̀hún á mọ̀ pé “Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀mí,” tí ẹ̀dá èèyàn ò lè fojú rí. (Jòhánù 4:24) Jésù pe Ọlọ́run òtítọ́ náà ní “Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Nípa tẹ̀mí, ó túmọ̀ sí pé ibi tí Baba wa ọ̀run gúnwà sí jẹ́ ibi tó ga gan-an, gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ṣe ga ju ilẹ̀ ayé lọ. (Mátíù 12:50; Aísáyà 63:15) Òótọ́ ni pé a ò lè fi ojúyòójú rí Ọlọ́run, àmọ́ ó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ̀ ọ́n ká sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ète rẹ̀. (Ẹ́kísódù 33:20; 34:6, 7) Ó ń dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n fẹ́ mọ ohun tí ìgbésí ayé túmọ̀ sí ń béèrè. Tó bá sì kan àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìgbésí ayé wa, ó ń fún wa láwọn ìlànà tó ṣeé gbára lé lórí àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ìyẹn ohun tó jẹ́ èrò rẹ̀ nípa àwọn ọ̀ràn yìí àti pé bóyá àwọn ohun tá à ń fẹ́ wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ète rẹ̀. Ó ń fẹ́ ká béèrè àwọn ìbéèrè nípa àwọn ọ̀ràn tó kan ìgbésí ayé wa ká sì sapá gidigidi láti wá ìdáhùn tó yẹ sí wọn. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Jeremáyà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì wí nítorí pé wọ́n kùnà láti ṣe èyí. Wọ́n mọ orúkọ Ọlọ́run, àmọ́ wọn ò béèrè pé “Jèhófà dà?” (Jeremáyà 2:6) Wọn ò kọbi ara sáwọn ètè Jèhófà. Wọn ò wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Tó bá di pé o fẹ́ ṣèpinnu, yálà kékeré ni tàbí ńlá, ǹjẹ́ o máa ń béèrè pé, “Jèhófà dà?”
Àwọn Tí Wọ́n Wá Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run
4. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ tí Dáfídì fi lélẹ̀ nínú ọ̀ràn wíwá ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ Jèhófà?
4 Nígbà tí Dáfídì, ọmọ Jésè ṣì wà ní ọ̀dọ́, ó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Ó mọ̀ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run alààyè.” Dáfídì ti fúnra rẹ̀ rí bí Jèhófà ṣe ń dáàbò boni. Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí Dáfídì ní nínú “orúkọ Jèhófà,” ló mú kó pa Gòláyátì òmìrán ará Filísínì náà tó dì káká dì kuku. (1 Sámúẹ́lì 17:26, 34-51) Àmọ́ ṣá, Dáfídì ò tìtorí àṣeyọrí tó ṣe yìí bẹ̀rẹ̀ sí dá ara rẹ̀ lójú. Kò bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ohunkóhun tó wù kóun dáwọ́ lé níbi tọ́ràn dé yìí ni Jèhófà á máa jẹ́ kó yọrí sí rere. Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, léraléra ni Dáfídì máa ń kàn sí Jèhófà táwọn ìpinnu kan bá délẹ̀ tó fẹ́ ṣe. (1 Sámúẹ́lì 23:2; 30:8; 2 Sámúẹ́lì 2:1; 5:19) Kò dáwọ́ àdúrà gbígbà dúró, pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi. Mo ti ní ìrètí nínú rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sáàmù 25:4, 5) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dára gan-an lèyí jẹ́ fún wa láti tẹ̀ lé!
5, 6. Báwo ni Jèhóṣáfátì ṣe wá Jèhófà ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ̀?
5 Nígbà ayé Jèhóṣáfátì Ọba, tó jẹ́ ọba karùn-ún láti ìlà ìdílé Dáfídì, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ para pọ̀ wọ́n sì kógun wá bá Júdà. Nígbà tí wàhálà ńlá yìí dé bá Jèhóṣáfátì, kò sí ohun mìíràn tó ṣe jù pé ó “gbé ojú rẹ̀ lé wíwá Jèhófà.” (2 Kíróníkà 20:1-3) Eléyìí kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí Jèhóṣáfátì máa wá Jèhófà. Ọba yìí kò bá wọn lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Báálì tó gbilẹ̀ láàárín àwọn apẹ̀yìndà ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá, ó sì ti yàn láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà. (2 Kíróníkà 17:3, 4) Àmọ́ o, ní báyìí tí ogun wà níwájú tó sì tún wà lẹ́yìn, báwo ni Jèhóṣáfátì ṣe ‘wá Jèhófà’?
6 Nínú àdúrà kan tí Jèhóṣáfátì gbà ní gbangba ní Jerúsálẹ́mù lákòókò tí òde ò dẹrùn yìí, ó fi hàn níbẹ̀ pé òun ò gbàgbé agbára ńlá tí Jèhófà ní. Ó ti ronú jinlẹ̀jinlẹ̀ nípa ète Jèhófà èyí tó hàn sójútáyé nípa bó ṣe lé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn kúrò lórí àwọn ilẹ̀ kan tó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún. Ọba yìí sọ pé òun ò lè rọ́nà gbé e gbà láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. (2 Kíróníkà 20:6-12) Ǹjẹ́ Jèhófà jẹ́ kí ọba yìí rí òun lákòókò náà? Ó kúkú ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà gba ẹnu Jahasíẹ́lì, tí í ṣe ọmọ Léfì, sọ àwọn ìlànà pàtó kan, Ó sì mú káwọn èèyàn Rẹ̀ ṣẹ́gun ní ọjọ́ kejì. (2 Kíróníkà 20:14-28) Báwo ni ìwọ náà ṣe lè ní ìdánilójú pé Jèhófà á jẹ́ kó o rí òun nígbà tó o bá nílò ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ rẹ̀?
7. Irú èèyàn wo ni Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà rẹ̀?
7 Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú. Ó ń ké sáwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè láti wá a nípasẹ̀ àdúrà. (Sáàmù 65:2; Ìṣe 10:34, 35) Ó mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn tó ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i. Ó mú un dá wa lójú pé òun ń gbọ́ àdúrà àwọn olódodo. (Òwe 15:29) Ó ń jẹ́ káwọn tí ò kà á sí tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí wọ́n wá ń fi ìrẹ̀lẹ̀ wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ báyìí rí òun. (Aísáyà 65:1) Àní ó ń dáhùn àdúrà àwọn tí ò pa òfin rẹ̀ mọ́ tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí wọ́n ti wá fi ìrẹ̀lẹ̀ ronú pìwà dà báyìí. (Sáàmù 32:5, 6; Ìṣe 3:19) Àmọ́ ṣá, bí ọkàn ẹnì kan ò bá tẹrí ba fún Ọlọ́run, asán ni àdúrà irú ẹni bẹ́ẹ̀ á já sí. (Máàkù 7:6, 7) Gbé àwọn àpẹẹrẹ bíi mélòó kan yẹ̀ wò.
Wọ́n Gbàdúrà Àmọ́ Àdúrà Wọn Ò Gbà
8. Kí nìdí tí Jèhófà ò fi dáhùn àdúrà tí Sọ́ọ̀lù Ọba gbà?
8 Lẹ́yìn tí wòlíì Sámúẹ́lì ti sọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba pé Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nítorí àìgbọràn rẹ̀, ńṣe ni Sọ́ọ̀lù wólẹ̀ fún Jèhófà. (1 Sámúẹ́lì 15:30, 31) Àmọ́ ojú ayé lásán ló ń ṣe. Kì í ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run ló wu Sọ́ọ̀lù bí kò ṣe pé káwọn èèyàn máa ṣe sàdáńkátà fún un. Nígbà tó yá tó di pé àwọn Filísínì gbógun ti Ísírẹ́lì, Sọ́ọ̀lù ṣojú ayé, ó lọ béèrè ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ nígbà tí kò rí ìdáhùn kankan gbà, ńṣe ló gba ọ̀dọ̀ abẹ́mìílò lọ, bẹ́ẹ̀ ó mọ̀ pé Jèhófà ka èyí léèwọ̀. (Diutarónómì 18:10-12; 1 Sámúẹ́lì 28:6, 7) Ká má fa ọ̀rọ̀ gùn, 1 Kíróníkà 10:14, sọ nípa Sọ́ọ̀lù pé: “Kò sì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.” Kí ló fa èyí? Ìdí ni pé Sọ́ọ̀lù ò nígbàgbọ́ nínú àdúrà tó gbà. Nítorí náà, ńṣe ló dà bí ẹni pé kò tiẹ̀ gbàdúrà rárá.
9. Kí lohun tó burú nínú ẹ̀bẹ̀ tí Sedekáyà bẹ Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà?
9 Bákan náà, nígbà tí ìjọba gúúsù ti Júdà ń kógbá sílé, àwọn èèyàn túbọ̀ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà wọ́n sì ń lọ ṣèwádìí lọ́dọ̀ àwọn wòlíì Jèhófà. Àmọ́ ṣá, àwọn èèyàn náà fẹnu lásán sọ ọ́ pé àwọn bọlá fún Ọlọ́run, síbẹ̀ wọ́n ṣì ń bọ̀rìṣà. (Sefanáyà 1:4-6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lọ ń ṣèwádìí tí ò dénú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, síbẹ̀ wọn ò ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn. Sedekáyà Ọba bẹ Jeremáyà pé kó bá òun ṣèwádìí lọ́dọ̀ Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ Jèhófà ti sọ ohun tó yẹ kí ọba náà ṣe fún un tẹ́lẹ̀. Àmọ́ àìnígbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù èèyàn kò jẹ́ kí ọba náà ṣe ohun tí Jèhófà sọ, Jèhófà ò sì sọ ohunkóhun tí ì bá múnú ọba náà dùn mọ́.—Jeremáyà 21:1-12; 38:14-19.
10. Kí lohun tó burú nínú ọ̀nà tí Jóhánánì gbà wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ látinú àṣìṣe rẹ̀?
10 Ẹ̀yìn ìgbà tí wọ́n ti pa Jerúsálẹ́mù run táwọn ọmọ ogun Bábílónì sì kó àwọn Júù lọ sígbèkùn ni Jóhánánì gbára dì láti kó àwọn Júù bíi mélòó kan tó ṣẹ́ kù ní Júdà lọ sí Íjíbítì. Gbogbo ètò ti tò lórí bí wọ́n á ṣe rin ìrìn náà, àmọ́ kí wọ́n tó lọ wọ́n sọ pé kí Jeremáyà gbàdúrà fún àwọn kó sì béèrè ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ ṣá, ohun tí wọ́n fẹ́ kọ́ ni Jèhófà fi dá wọn lóhùn, síbẹ̀ wọ́n ranrí mọ́ ohun tí wọ́n ti dáwọ́ lé náà. (Jeremáyà 41:16–43:7) Nínú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, ǹjẹ́ o ti rí àwọn ẹ̀kọ́ tó lè ṣe ọ́ láǹfààní táá sì jẹ́ kó o rí Jèhófà nígbà tó o bá wá a?
“Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Wíwádìí . . . . Dájú”
11. Èé ṣe tá a fi gbọ́dọ̀ fi ohun tó wà nínú Éfésù 5:10 sílò?
11 Kì í ṣe orí wíwulẹ̀ fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi, lílọ́ sáwọn ìpàdé ìjọ àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún gbogbo èèyàn ni ìjọsìn tòótọ́ pin sí. Ó kan gbogbo ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa. Ojoojúmọ́ là ń kojú ìṣòro—yálà àwọn tó fara sin tàbí àwọn tó hàn sójú táyé—tó lè mú wa kúrò lójú ọ̀nà tó bá ìfọkànsìn Ọlọ́run mu. Báwo la ṣe máa kojú àwọn ìṣòro wọ̀nyí? Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni tòótọ́ ní Éfésù, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.” (Éfésù 5:10) Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tá a kọ sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ èrè tá a máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.
12. Kí nìdí tí Jèhófà fi bínú nígbà tí Dáfídì gbé àpótí májẹ̀mú lọ sí Jerúsálẹ́mù?
12 Lẹ́yìn tí àpótí májẹ̀mú ti padà sí Ísírẹ́lì tí wọ́n sì ti gbé e sí Kiriati-jéárímù fún ọ̀pọ̀ ọdún, Dáfídì Ọba fẹ́ láti gbé e kúrò níbẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ó kàn sí àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí láàárín àwọn èèyàn náà ó sì sọ fún wọn pé òun á gbé Àpótí Ẹ̀rí náà kúrò níbi tó wà ‘bó bá dára bẹ́ẹ̀ lójú wọn àti bí Jèhófà bá fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.’ Àmọ́ kò fara balẹ̀ wádìí dáadáa láti mọ bí Jèhófà ṣe fẹ́ kí ọ̀ràn náà lọ. Ká ló ti ṣe bẹ́ẹ̀ ni, wọn kì bá gbé Àpótí Ẹ̀rí náà sínú kẹ̀kẹ́ rárá. Àwọn ọmọ Léfì tó wá láti ìlà ìdílé Kóhátì ni ì bá gbé e sí èjìká wọn, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sọ ọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni Dáfídì máa ń wádìí ọ̀rọ̀ wò lọ́dọ̀ Jèhófà, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó tọ́ nínú ọ̀ràn yìí. Ohun tó sì tẹ̀yìn rẹ̀ jáde kò dáa rárá. Nígbà tó yá, Dáfídì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa ya lù wá, nítorí a kò wá a gẹ́gẹ́ bí àṣà.”—1 Kíróníkà 13:1-3; 15:11-13; Númérì 4:4-6, 15; 7:1-9.
13. Ìránnilétí wo ló wà nínú orin táwọn èèyàn kọ nígbà tí wọ́n gbé Àpótí Májẹ̀mú náà nígbẹ̀yìngbẹ́yín?
13 Nígbà táwọn ọmọ Léfì wá gbé Àpótí Májẹ̀mú náà nígbẹ̀yìngbẹ́yín láti ilé Obedi-édómù lọ sí Jerúsálẹ́mù, orin kan tí Dáfídì kọ sílẹ̀ ni wọ́n fi bọnu. Ìránnilétí àtọkànwá kan wà nínú rẹ̀ pé: “Ẹ máa wá Jèhófà àti okun rẹ̀, ẹ máa wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa rántí àwọn ìṣe àgbàyanu rẹ̀ tí ó ti ṣe, àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ ẹnu rẹ̀.”—1 Kíróníkà 16:11, 12.
14. Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ rere Sólómọ́nì àti àwọn àṣìṣe tó ṣe lọ́jọ́ ogbó rẹ̀?
14 Kí Dáfídì tó kú, ó gba Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ níyànjú pé: “Bí ìwọ bá wá [Jèhófà], yóò jẹ́ kí o rí òun.” (1 Kíróníkà 28:9) Gbàrà tí Sólómọ́nì sì gorí ìtẹ́, Gíbéónì ló forí lé níbi tí àgọ́ ìpàdé wà, ó sì lọ rúbọ sí Jèhófà níbẹ̀. Ibẹ̀ ni Jèhófà ti sọ fún Sólómọ́nì pé: “Béèrè! Kí ni kí n fún ọ?” Nígbà tí Jèhófà sì máa dáhùn ìbéèré Sólómọ́nì, ńṣe ló fún un ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọgbọ́n àti ìmọ̀ tó máa fi ṣèdájọ́ Ísírẹ́lì, àní Ó tún fún un ní ọrọ̀ àti ọlá pàápàá. (2 Kíróníkà 1:3-12) Sólómọ́nì fi àwòrán ilé kíkọ́ tí Jèhófà fún Dáfídì, kọ́ tẹ́ńpìlì kan tó kàmàmà. Àmọ́ nígbà tọ́rọ̀ wá dórí ọ̀ràn lílóbìnrin, Sólómọ́nì ò wá Jèhófà rárá. Àwọn obìnrin tí wọn kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà ni Sólómọ́nì fi ṣaya. Nígbà tó si di arúgbó, àwọn obìnrin wọ̀nyí yí ọkàn rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. (1 Àwọn Ọba 11:1-10) Bó ti wù ká gbajúmọ̀, ká gbọ́n, ká sì nímọ̀ tó, ó ṣe pàtàkì pé ká “máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú”!
15. Nígbà tí Síírà ará Etiópíà gbógun ti Júdà, kí nìdí tí Ásà fi lè gbàdúrà tọ́kàn rẹ̀ sì balẹ̀ pé Jèhófà á gba Júdà sílẹ̀?
15 Àkọsílẹ̀ ọba Ásà tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Sólómọ́nì, jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìdí tí ọ̀rọ̀ yìí fi ṣe pàtàkì. Ọdún mọ́kànlá lẹ́yìn tí Ásà gorí ìtẹ́ ni Síírà ará Etiópíà àti àádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọ ogun tó kó sòdí kógun wá ja Júdà. Ṣé Jèhófà á kó Júdà yọ báyìí? Ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún ṣáájú àkókò yẹn ni Jèhófà ti sọ ọ́ ní kedere ohun táwọn èèyàn rẹ̀ lè ní ìdánilójú pé òun á ṣe tí wọ́n bá gbọ́ràn sí i lẹ́nu tí wọ́n sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Bákan náà ló sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn. (Diutarónómì 28:1, 7, 15, 25) Nígbà tí Ásà ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́, gbogbo pẹpẹ àti òpó táwọn èèyàn ń lò fún ìjọsìn èké ló ti mú kúrò ní Júdà. Ó sì ti rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n ‘wá Jèhófà.’ Kó tó di pé wàhálà dé ni Ásà ti ṣe gbogbo ohun tá a sọ yìí o. Nítorí náà, ìgbàgbọ́ tí Ásà ní nínú Jèhófà ló mú kó lè fi gbogbo ẹnu gbàdúrà pé kó wá gbèjà àwọn. Kí sì ni àbájáde rẹ̀? Júdà borí nínú ogun tá à ń wí yìí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.—2 Kíróníkà 14:2-12.
16, 17. (a) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ásà ja àjàṣẹ́gun, ìránnilétí wo ni Jèhófà fún un? (b) Nígbà tí Ásà hùwà lọ́nà tí kò yẹ, ìrànlọ́wọ́ wo la fún un, àmọ́ báwo ló ṣe gbà á? (d) Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú ṣíṣàyẹ̀wò ìwà Ásà?
16 Àmọ́ nígbà tí Ásà ti ṣẹ́gun tó sì padà sílé, Jèhófà rán Asaráyà lọ pàdé ọba náà kó sì sọ fún un pé: “Gbọ́ mi, ìwọ Ásà àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì! Jèhófà wà pẹ̀lú yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà pẹ̀lú rẹ̀; bí ẹ bá sì wá a, òun yóò jẹ́ kí ẹ rí òun, ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi í sílẹ̀, òun yóò fi yín sílẹ̀.” (2 Kíróníkà 15:2) Èyí tún koná mọ́ ìtara Ásà, ó sì gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Àmọ́ ní ọdún mẹ́rìnlélógún lẹ́yìn náà, tí ogún tún dé, Ásà ò wá Jèhófà mọ́ o. Kò yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni kò rántí bí Jèhófà ṣe ṣe bẹbẹ nígbà tí ọmọ ogun àwọn ará Etiópíà gbógun ti Júdà. Ńṣe ló lọ fi ìwà òpònú bá Síríà gbìmọ̀ pọ̀.—2 Kíróníkà 16:1-6.
17 Nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jèhófà mú kí Hánáánì aríran bá Ásà wí. Ásà ṣì lè jàǹfààní níbi tọ́ràn dé yìí nígbà tí wọ́n ṣàlàyé ojú tí Jèhófà fi wo ọ̀ràn náà fún un. Àmọ́ dípò ìyẹn, ńṣe ló tutọ́ sókè tó fojú gbà á tó sì fi Hánáánì sínú ilé àbà. (2 Kíróníkà 16:7-10) Ọ̀ràn ìbànújẹ́ gbáà lèyí! Àwa náà ńkọ́? Ǹjẹ́ a máa ń wá Ọlọ́run síbẹ̀ ká máa kọ ìmọ̀ràn? Bí alàgbà kan tí kì í fọ̀rọ̀ wa ṣeré tó sì nífẹ̀ẹ́ wa bá fi Bíbélì gbà wá níyànjú nítorí pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí bá ayé ṣe, ǹjẹ́ a máa ń fi ìmọrírì hàn fún ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ tó fún wa láti lè mọ “ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?”
Má Gbàgbé Láti Béèrè O
18. Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Élíhù sọ fún Jóòbù?
18 Bí wàhálà bá dé, kódà ẹni tó ti ń ṣe dáadáa bọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà látọjọ́ pípẹ́ lè ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Nígbà tí àìsàn burúkú kọ lu Jóòbù, tí gbogbo ọmọ rẹ̀ kú, táwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ ò sí mọ́, táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tún fẹ̀sùn èké kàn án, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ara rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Élíhù rán an létí pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó sọ pé, ‘Ọlọ́run Olùṣẹ̀dá mi Atóbilọ́lá dà?’” (Jóòbù 35:10) Ó di dandan kí Jóòbù yí èrò rẹ̀ padà kó bẹ̀rẹ̀ síí ṣàgbéyẹ̀wò èrò Jèhófà lórí bí ipò nǹkan ṣe ń lọ sí. Jóòbù fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìránnilétí náà, àpẹẹrẹ rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bákan náà.
19. Kí lohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sábà máa ń kùnà láti ṣe?
19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ìtàn bí Ọlọ́run ṣe bá orílẹ̀-èdè wọn lò sẹ́yìn. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í fi èyí sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ọ̀ràn kan nínú ìgbésí ayé wọn. (Jeremáyà 2:5, 6, 8) Tó bá di pé kí wọ́n ṣe àwọn ìpinnu kan nínú ìgbésí ayé wọn, ìgbádùn ara wọn ni wọ́n máa ń fi sípò àkọ́kọ́ dípò tí wọn ì bá fi béèrè pé, “Jèhófà dà?”—Aísáyà 5:11, 12.
Máa Béèrè Pé, “Jèhófà Dà?”
20, 21. (a) Àwọn wo ló ti fi irú ẹ̀mí tí Èlíṣà ní hàn nínú wíwá ìtọ́sọ́nà Jèhófà lóde òní? (b) Báwo la ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn ká sì jàǹfààní nínú rẹ̀?
20 Nígbà tí Èlíjà parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Èlíṣà tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ mú ẹ̀wù oyè tó já bọ́ lára Èlíjà, ó lọ sí odò Jọ́dánì, ó lu omi náà ó sì béèrè pé: “Jèhófà Ọlọ́run Èlíjà dà, àní Òun?” (2 Àwọn Ọba 2:14) Jèhófà dá a lóhùn nípa fífi hàn pé ẹ̀mí òun ti wà lára Èlíṣà. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí?
21 Ohun kan tó fara jọ èyí ṣẹlẹ̀ lákòókò tiwa náà. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan tí wọ́n ti mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù náà kú. Àwọn tá a wá gbé ẹrù iṣẹ́ ṣíṣe àbójútó lé lọ́wọ́ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ wọ́n sì gbàdúrà sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń béèrè pé, “Jèhófà dà?” Èyí ló mú kí Jèhófà máa ṣe aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀ tó sì ń mú kí ìgbòkègbodò wọn máa tẹ̀ síwájú. Ǹjẹ́ àwa náà ń fara wé ìgbàgbọ́ wọn? (Hébérù 13:7) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò sún mọ́ ètò àjọ Jèhófà tímọ́tímọ́, àá máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, àá sì máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó ń ṣe lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi ní kíkún.—Sekaráyà 8:23.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí la gbọ́dọ̀ ní lọ́kàn nígbà tá a bá ń béèrè pé, “Jèhófà dà?”
• Lóde òní, báwo la ṣe lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà “Jèhófà dà?”
• Kí nìdí tí Ọlọ́run kì í fi í dáhùn àwọn àdúrà táwọn kan gbà fún ìtọ́sọ́nà?
• Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká “máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Báwo ni Jèhóṣáfátì Ọba ṣe wá Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi lọ sọ́dọ̀ abẹ́mìílò?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Máa gbàdúrà, máa kẹ́kọ̀ọ́ kó o sì máa ṣàṣàrò kó o lè mọ ‘ibi ti Jèhófà wà’ ní àmọ̀dájú