Tatian—Ṣé Agbèjà Ìgbàgbọ́ Ni àbí Aládàámọ̀?
NÍGBÀ tó kù díẹ̀ kí ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ parí, ó bá àwọn àgbààgbà inú ìjọ tó wà ní Éfésù ṣèpàdé. Ó sọ fún wọn pé: “Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi, àwọn aninilára ìkookò yóò wọlé wá sáàárín yín, wọn kì yóò sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, àti pé láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.”—Ìṣe 20:29, 30.
Nígbà tọ́rọ̀ rẹ̀ yìí sì máa ṣẹ lóòótọ́, ìyípadà ńláǹlà ló wáyé ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa bẹ́ẹ̀ sì ni ìpẹ̀yìndà tó sọ̀rọ̀ rẹ̀ náà dé. Ẹ̀sìn Gnostic gbòde kan tòun ti ìmọ̀ ọgbọ́n orí, èyí sì ṣàkóbá fún àwọn onígbàgbọ́ bíi mélòó kan. Àwọn ẹlẹ́sìn Gnostic gbà gbọ́ pé àwọn nǹkan tẹ̀mí dára àti pé ti èṣù ni gbogbo nǹkan téèyàn bá ti lè fojú rí. Wọ́n sọ pé gbogbo ẹran ara ló jẹ́ ti èṣù, èyí ló mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí ọ̀ràn ìgbéyàwó àti ti ọmọ bíbí, wọ́n sọ pé Sátánì ló dá àwọn nǹkan yìí sílẹ̀. Àwọn kan lára wọn gbà gbọ́ pé níwọ̀n bó ti jẹ́ kìkì ohun tẹ̀mí nìkan ló ṣe pàtàkì, ohunkóhun tó bá wu olúkúlùkù ló lè fi ara rẹ̀ ṣe. Èrò yìí ló mú kí wọ́n máa gbé ìgbésí ayé tí kò yẹ, yálà ti ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ tàbí fífi ìwàkiwà kẹ́ra lákẹ̀ẹ́bàjẹ́. Àwọn ẹlẹ́sìn Gnostic sọ pé ìmọ̀ ara ẹni ló lè fúnni ní ìgbàlà, wọn ò tiẹ̀ ronú kan òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rárá.
Báwo làwọn tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn ṣe kojú ewu ẹ̀sìn Gnostic náà? Àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé ké gbàjarè pé àwọn ò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké náà, àwọn mìíràn sì jẹ́ kó nípa lórí àwọn. Bí àpẹẹrẹ, Irenaeus fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ gbógun ti ẹ̀kọ́ àwọn aládàámọ̀. Ọ̀dọ̀ Polycarp tó wà láàyè nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì ló ti kẹ́kọ̀ọ́. Polycarp sì gba àwọn èèyàn níyànjú láti rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi àti tàwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Àmọ́ nígbà tó ṣe, Florinus tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Irenaeus tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ Valentinus ìyẹn aṣáájú nínú ẹ̀sìn Gnostic bẹ́ẹ̀ sì rèé ẹnì kan náà ló kọ́ àwọn méjèèjì lẹ́kọ̀ọ́. Nǹkan ò fara rọ lákòókò náà lóòótọ́.
Àwọn ìwé tí Tatian, tó jẹ́ òǹkọ̀wé tó gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta ní ọ̀rúndún kejì kọ ló túbọ̀ jẹ́ ká mọ bọ́ràn ẹ̀sìn ṣe rí lákòókò náà. Irú èèyàn wo tiẹ̀ ni Tatian? Báwo ló ṣe di Kristẹni aláfẹnujẹ́? Àti pé báwo ni Tatian ṣe kojú ipa tí àdámọ̀ ẹ̀sìn Gnostic ní? Àwọn ìdáhùn rẹ̀ tó ń wúni lórí àti àpẹẹrẹ ti òun fúnra rẹ̀ jẹ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òótọ́ lóde òní.
Ó Bá “Àwọn Ẹ̀kọ́ Kan Tó Ṣàjèjì Pàdé”
Ọmọ Síríà ni Tatian. Ìrìn àjò tó máa ń rìn káàkiri àti bó ṣe jẹ́ òǹkàwé tó dáńtọ́ jẹ́ kó lóye àṣà ilẹ̀ Gíríìsì àti Róòmù ti àkókò rẹ̀ dáadáa. Jíjẹ́ tí Tatian jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó ń rìnrìn àjò kiri yìí ló gbé e dé Róòmù. Àmọ́ àsìkò tó wà ní Róòmù yìí lọkàn rẹ̀ fà sí ẹ̀sìn Kristẹni. Ó bẹ̀rẹ̀ sí bá Justin Martyr kẹ́gbẹ́, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kíyẹn kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ pàápàá.
Tatian sọ nínú àkọsílẹ̀ tó fi hàn bó ṣe yí padà sí ẹ̀sìn Kristẹni tìgbà ayé rẹ̀ pé: “Mo wá ọ̀nà tí mo lè gbà rí òtítọ́.” Nígbà tó sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìrírí tó ní nígbà tó láǹfààní láti ka Ìwé Mímọ́, ó sọ pé: “Bákan náà ni mo tún bá àwọn ẹ̀kọ́ kan tó ṣàjèjì pàdé, àwọn ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ògbólógbòó tá a bá fi wéra pẹ̀lú èrò àwọn Gíríìkì. Àwọn ẹ̀kọ́ yìí tún dára ju ohun tá a lè fi wéra pẹ̀lú àwọn àṣìṣe inú àwọn àkọsílẹ̀ Gíríìkì; àwọn ohun tó sì yí mi lérò padà tí mo fi gbà wọ́n gbọ́ ni báwọn èdè inú rẹ̀ ò ṣe fi igbá kan bọ ọ̀kan nínú, báwọn òǹkọ̀wé náà ṣe jẹ́ olóòótọ́ ọkàn, àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tó wà níbẹ̀, àwọn ìlànà inú rẹ̀ tí ò láfiwé àti bí wọ́n ṣe fi hàn pé Ẹnì kan ṣoṣo ló lágbára láti ṣàkóso ayé àti ọ̀run.”
Kíákíá ni Tatian ké sáwọn alájọgbáyé rẹ̀ pé káwọn náà ṣàyẹ̀wò ẹ̀sìn Kristẹni àkókò náà kí wọ́n sì kíyè sí bó ṣe rọrùn tó àti bí kì í ṣeé fi júújúú boni lójú, èyí tó mú kó yàtọ̀ sí ẹ̀sìn àwọn abọgibọ̀pẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àwọn ìwé tó kọ?
Kí Làwọn Ìwé Tó Kọ Fi Hàn?
Àwọn ìwé tí Tatian kọ fi hàn pé agbèjà ẹ̀sìn ni, òǹkọ̀wé tó gbójú gbóyà láti gbèjà ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn rẹ̀. Ńṣe ló ń tako ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn kèfèrí lójú méjèèjì. Nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Address to the Greeks, Tatian tẹnu mọ́ ọn pé ìranù gbáà ni ìsìn kèfèrí àmọ́ ìsìn gidi ni ìsìn Kristẹni gẹ́gẹ́ bóun ṣe mọ̀ ọ́n. Ọ̀nà tó gbà ń ṣe lámèyítọ́ báwọn Gíríìkì ṣe ń ṣe nǹkan fi hàn pé kò gba gbẹ̀rẹ́ rárá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa onímọ̀ ọgbọ́n orí náà Heracleitus, ó sọ pé: “Àmọ́ ṣá, ikú ló jẹ́ ká mọ bí ọ̀gbẹ́ni yìí ṣe ya òpònú tó; nítorí pé nígbà tí àìsàn ògùdùgbẹ̀ ń bá ọ̀gbẹ́ni yìí jà, tó sì jẹ́ pé ó nímọ̀ ìṣègùn àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí dáadáa, ìgbẹ́ màlúù ló lọ fi yí gbogbo ara rẹ̀ tíyẹn sì wá fa gbogbo ara rẹ̀ pọ̀ nígbà tó gbẹ tán débi tí gbogbo ẹran ara rẹ̀ fi ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ tó sì tibẹ̀ kú.”
Tatian ò fọwọ́ kékeré mú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kan ṣoṣo, tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. (Hébérù 3:4) Nínú ìwé Address to the Greeks, ó sọ pé “Ẹ̀mí” ni Ọlọ́run àti pé: “Òun nìkan ni kò níbẹ̀rẹ̀, Òun Fúnra rẹ̀ sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo.” (Jòhánù 4:24; 1 Tímótì 1:17) Tatian kò fara mọ́ lílo ère nínú ìjọsìn rárá, ó kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Báwo ni màá ṣe máa pe èérún igi àti òkúta ní ọlọ́run?” (1 Kọ́ríńtì 10:14) Ó gbà pé Ọ̀rọ̀ náà tàbí Logos ni àkọ́bí nínú iṣẹ́ ọwọ́ Baba ọ̀run àti pé òun la lò nígbà tó yá láti ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 1:1-3; Kólósè 1:13-17) Lórí ọ̀ràn àjíǹde lákòókò tá a ti ṣètò, ohun tí Tatian sọ ni pé: “A gbà gbọ́ pé a óò jí àwọn òkú dìde lẹ́yìn tí ohun gbogbo bá ti wá sópin.” Àkọsílẹ̀ tó tún kọ nípa ìdí tá a fi ń kú ni pé: “A ò ṣẹ̀dá wa pé ká máa kú, àmọ́ àfọwọ́fà àwa fúnra wa ló mú ká máa kú. Òmìnira tá a ní láti ṣe ohun tó bá wù wá ló ba tiwa jẹ́; àwa tá a lómìnira tẹ́lẹ̀ ti wá di ẹrú; ẹ̀ṣẹ̀ ló sì tà wá sóko ẹrú.”
Àlàyé tí Tatian ṣe nípa ọkàn kò lórí kò nídìí. Ó sọ pé: “Ọkàn fúnra rẹ̀ kì í ṣe ohun tí kò lè kú, ó lè kú dáadáa, kẹ́ ẹ yáa gbọ́ ẹyín Gíríìkì. Àmọ́ ó tún ṣeé ṣe kó máà kú. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn kan kò mọ òtítọ́, kíkú ló máa kú tó sì máa jẹrà pẹ̀lú ẹran ara, àmọ́ á tún jíǹde nígbẹ̀yìngbẹ́yín pẹ̀lú ẹran ara nígbà táyé bá wá sópin táá sì wá gba ìdájọ́ ikú nípa jíjoró títí láé.” Ohun tí Tatian ní lọ́kàn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó sọ yìí kò yéni. Ṣé kì í ṣe pé bó ṣe gba àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tó sì tún ń gbìyànjú láti má ṣe tẹ́ lọ́dọ̀ àwọn alájọgbáyé rẹ̀ ló mú kó wá ṣe àmúlùmálà àwọn òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn kèfèrí?
Ìwé mìíràn tó gbajúmọ̀ tí Tatian tún kọ ni ìwé Diatessaron, tàbí Harmony of the Four Gospels. Tatian lẹni àkọ́kọ́ tó jẹ́ káwọn ìjọ tó wà ní Síríà láwọn ìwé Ìhìn Rere lédè ìbílẹ̀ wọn. Àwọn èèyàn kan sáárá fún ìwé náà gan-an, nítorí pé ńṣe ló ṣàkópọ̀ Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sójú kan náà. Kódà Ìjọ àwọn ará Síríà lò ó.
Ṣé Kristẹni Ni àbí Aládàámọ̀?
Àyẹ̀wò àfẹ̀sọ̀ṣe nípa àwọn ìwé tí Tatian kọ fi hàn pé ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa ó sì bọ̀wọ̀ fún un. Ohun tó kọ nípa ipa tí wọ́n ní lórí rẹ̀ ni pé: “N kì í ṣàníyàn láti di olówó; mi ò wọṣẹ́ ológun; mo kórìíra ìwà àgbèrè; mi ò tìtorí àtidi ọlọ́rọ̀ lọ di awakọ̀ òkun; . . . Dídi ìlúmọ̀ọ́ká kò sí lórí ẹ̀mí mi; . . . Oòrùn kan náà ló ń ràn sí gbogbo wa pátá lórí, gbogbo wa la sì ń kú, à báà jẹ́ ọlọ́lá tàbí òtòṣì.” Tatian wá fúnni nímọ̀ràn pé: “Má fara mọ́ ayé o, má sì lọ́wọ́ nínú ìwà ibi tó kúnnú rẹ̀. Ti Ọlọ́run ni kó o ṣe, gbà Á sínú ayé ẹ kó o sì jáwọ́ nínú àwọn ìwà tóò ń hù tẹ́lẹ̀.”—Mátíù 5:45; 1 Kọ́ríńtì 6:18; 1 Tímótì 6:10.
Àmọ́ ṣa, wo ìwé kan tí Tatian kọ, tó pe àkọlé rẹ̀ ní On Perfection According to the Doctrine of the Savior. Ó sọ nínú ìwé yìí pé Èṣù ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀. Ó sọ pé ńṣe làwọn èèyàn ń sọra wọn dẹrú ayé tó ti díbàjẹ́ yìí nípa ṣíṣe ìgbéyàwó, Tatian sì tako ètò ìgbéyàwó pátápátá.
Ó dà bí ẹni pé ní nǹkan bí ọdún 166 Sànmánì Tiwa, lẹ́yìn ìgbà tí Justin Martyr ti kú, ni Tatian dá ẹ̀ya ìsìn aṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń pè ní Encratites sílẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ló dara pọ̀ mọ́ wọn. Ìkóra-ẹni-níjàánu àwọn tó ń ṣẹ̀sìn yìí kọjá bó ṣe yẹ, wọ́n sì sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣàkóso ara rẹ̀ bó ṣe wù ú. Wọ́n máa ń ṣẹ́ ara wọn níṣẹ̀ẹ́, wọn kì í mu wáìnì, wọ́n kì í ṣègbéyàwó wọn kì í sì í ní nǹkan ìní.
Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́
Kí ló mú kí Tatian yapa kúrò nínú Ìwé Mímọ́ tó bẹ́ẹ̀? Ṣé ó di “olùgbọ́ tí ń gbàgbé” ni? (Jákọ́bù 1:23-25) Ṣé Tatian kùnà láti pa àwọn ìtàn èké tì ni tó sì tipa bẹ́ẹ̀ kó sínú páńpẹ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí ẹ̀dá èèyàn? (Kólósè 2:8; 1 Tímótì 4:7) Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé àwọn ìṣìnà tó kọ́wọ́ tì lẹ́yìn pọ̀ gan-an, ǹjẹ́ a lè lọ sọ pé àrùn ọpọlọ díẹ̀ ló ń yọ ọ́ lẹ́nu?
Ohun yòówù kó jẹ́, àwọn ìwé tí Tatian kọ àti àpẹẹrẹ rẹ̀ jẹ́ ká lóye bí ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣe rí nígbà ayé rẹ̀. Wọ́n jẹ́ ká rí bí ìmọ̀ ọgbọ́n orí inú ayé ṣe lè ní ipa búburú lórí ẹni tó. Ǹjẹ́ ká fi ìkìlọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé ká yẹra fún “àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’”—1 Tímótì 6:20.