Fífọkàntánni Ló Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Èèyàn Láyọ̀
JÍJẸ oúnjẹ tó ti bà jẹ́ máa ń fa inú rírun. Ẹni tí irú rẹ̀ bá sì ń ṣẹlẹ̀ sí ní gbogbo ìgbà gbọ́dọ̀ kíyè sí ohun tó ń jẹ. Àmọ́ kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu rárá kéèyàn sọ pé òun ò ní jẹun mọ́ kí oúnjẹ tó ti bà jẹ́ má bàa yọ òun lẹ́nu. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí ọ̀ràn náà túbọ̀ burú sí i ni dípò tí ì bá fi yanjú rẹ̀. Téèyàn ò bá jẹun, onítọ̀hún ò ní pẹ́ kú.
Lọ́nà kan náà, ó máa ń dunni gan-an nígbà tẹ́ni kan bá já wa kulẹ̀. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá sì ń ṣẹlẹ̀ léraléra, a jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ ronú dáadáa ká tó yan àwọn tá a fẹ́ bá kẹ́gbẹ́. Àmọ́ sísá fún gbogbo èèyàn nítorí ìbẹ̀rù kí wọ́n má bàa já wa kulẹ̀ kọ́ ló máa yanjú ìṣòro náà. Kí nìdí? Nítorí pé tá ò bá fọkàn tán àwọn ẹlòmíràn, àwa fúnra wa ò ní láyọ̀. Tá a bá fẹ́ gbé ìgbésí ayé aláyọ̀, ó yẹ ká fọkàn tán àwọn ẹlòmíràn.
Ìwé Jugend 2002 sọ pé: “Ìfọkàntánnì jẹ́ ọ̀kan lára ìpìlẹ̀ tá a gbé àjọṣe tá a ń ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lójoojúmọ́ kà.” Ìwé ìròyìn Neue Zürcher Zeitung sọ pé: “Kò sẹ́ni tí kò fẹ́ ká fọkàn tán òun. Ìfọkàntánnì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé dùn” débi pé “ó ṣe pàtàkì gan-an téèyàn bá fẹ́ máa wà láàyè nìṣó.” Ìwé ìròyìn náà ń bá a lọ pé, láìsí àní-àní, téèyàn ò bá fọkàn tán ẹnikẹ́ni, “ilé ayé á sú onítọ̀hún.”
Níwọ̀n bó ti di dandan fún wa láti fọkàn tán ẹnì kan, ta ló wá yẹ ká fọkàn tán tí kò ní já wa kulẹ̀?
Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
Bíbélì sọ fún wa pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” (Òwe 3:5) Kódà, léraléra ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa.
Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run? Lákọ̀ọ́kọ́, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ mímọ́. Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà.” (Aísáyà 6:3) Ǹjẹ́ jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni mímọ́ yẹn tiẹ̀ fa ọ́ mọ́ra? Láìsí àní-àní, ó yẹ kó fà ọ́ mọ́ra, nítorí pé ìjẹ́mímọ́ Jèhófà túmọ̀ sí pé ó mọ́ látòkèdélẹ̀, kì í ṣe àṣìṣe kankan, ó sì ṣeé gbára lé pátápátá. Kò lè ṣojúsàájú tàbí kó yanni jẹ láé, kò sì sóun tó lè mú un ja wá kulẹ̀.
Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nítorí pé ó ní agbára láti ti àwọn tó ń sìn ín lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, agbára ńlá rẹ̀ ló ń jẹ́ kó ṣe ohun tó bá fẹ́. Ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n rẹ̀ pípé ló ń darí ọ̀nà tó gba ń ṣe nǹkan. Ìfẹ́ rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ ló sì ń sún un láti ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣe. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ìfẹ́ Ọlọ́run ló ń sún un ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Ìjẹ́mímọ́ Jèhófà àtàwọn ànímọ́ títayọ mìíràn tó ní ló jẹ́ ká mọ̀ ọ́n sí Baba tí kò lábùkù, ìyẹn ẹnì kan tá a lè gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá. Kò sí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tá a lè fọkàn tán bíi Jèhófà.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O sì Jẹ́ Aláyọ̀
Ìdí pàtàkì mìíràn tó tún fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni pé ó mọ̀ wá ju bí ẹnikẹ́ni mìíràn ṣe mọ̀ wá lọ. Ó mọ̀ pé gbogbo èèyàn ló yẹ kó ní àjọṣe tó fini lọ́kàn balẹ̀, tó wà pẹ́ títí, tó sì ṣeé fọkàn tán pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá. Ọkàn àwọn tó ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ máa ń balẹ̀ ju ti àwọn èèyàn yòókù lọ. Dáfídì Ọba sọ pé: “Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó fi Jèhófà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.” (Sáàmù 40:4) Lóde òní, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ní irú èrò tí Dáfídì ní yẹn.
Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò. Doris ti gbé ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic, ilẹ̀ Jámánì, ilẹ̀ Gíríìsì, àti ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rí. Ó sọ pé: “Inú mi dùn gan-an láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ó mọ ọ̀nà tó lè gbà tọ́jú mi nípa tara, nípa tẹ̀mí, àti ní ti ìmí ẹ̀dùn. Òun ni ọ̀rẹ́ tó dára jù lọ téèyàn lè ní.” Wolfgang, tó jẹ́ agbẹjọ́rò ṣàlàyé pé: “Ohun tó dáa gan-an ni láti gbẹ́kẹ̀ lé ẹnì kan tó fẹ́ ire ẹni, ìyẹn ẹni tó lè ṣe ohun tó dára jù lọ fún ọ, tó sì máa ṣe é ní ti gidi!” Ham, tí wọ́n bí ní Éṣíà àmọ́ tó ń gbé ilẹ̀ Yúróòpù báyìí sọ pé: “Ó dá mi lójú pé ọwọ́ Jèhófà ni gbogbo nǹkan wà, kì í sì í ṣe àṣìṣe, nítorí náà inú mi dùn gan-an pé mo gbára lé e.”
Ká sòótọ́, kì í ṣe pé ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbẹ́kẹ̀ lé Ẹlẹ́dàá wa nìkan, àmọ́ ó tún yẹ ká fọkàn tán àwọn èèyàn pẹ̀lú. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà tá a mọ̀ sí ọ̀rẹ́ wa tó jẹ́ ọlọgbọ́n tó sì mọ ohun gbogbo fi gbà wá nímọ̀ràn nípa irú àwọn èèyàn tó yẹ ká fọkàn tán. Tá a bá fara balẹ̀ ka Bíbélì, a óò rí ìmọ̀ràn tó fún wa lórí ọ̀ràn yìí.
Àwọn Èèyàn Tá A Lè Fọkàn Tán
Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 146:3) Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Kódà, a ò kàn lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn tá a buyì fún gidigidi bí “àwọn ọ̀tọ̀kùlú” ayé yìí, irú àwọn bí ògbógi nínú ìmọ̀ tàbí nínú iṣẹ́ kan pàtó. Ìtọ́sọ́nà wọn sábà máa ń ṣini lọ́nà, ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni nínú irú “àwọn ọ̀tọ̀kùlú” bẹ́ẹ̀ sì lè tètè yọrí sí ìjákulẹ̀.
Àmọ́ ṣá o, èyí ò wá túmọ̀ sí pé a ò ní fọkàn tán ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n ó hàn gbangba pé a gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ dáadáa nígbà tá a bá ń yan àwọn tá a máa fọkàn tán. Ìlànà wo ló yẹ ká lò fún èyí? Àpẹẹrẹ kan ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì lè ràn wá lọ́wọ́. Nígbà to di dandan láti yan àwọn tí yóò máa gbé ẹrù iṣẹ́ wíwúwo ní Ísírẹ́lì, a gbá Mósè níyànjú láti “yàn nínú gbogbo àwọn ènìyàn náà, àwọn ọkùnrin dídáńgájíá, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwọn ọkùnrin tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí ó kórìíra èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu.” (Ẹ́kísódù 18:21) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí?
Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ní àwọn ànímọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí kó tó di pé a yàn wọ́n sípò tá a ti lè fọkàn tán wọn. Wọ́n ti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá, wọ́n sì ń bẹ̀rù pé káwọn má ṣe ohun tó lè múnú bí i. Ó hàn gbangba sí gbogbo èèyàn pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sa gbogbo ipá wọn láti pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́. Wọ́n kórìíra èrè ìjẹkújẹ, tó fi hàn pé ìwà wọn dáa gan-an, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí agbára máa gun wọn gàlègàlè. Wọn ò ní sọ ara wọn di ẹni tí kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé mọ́ nítorí èrè tí wọ́n fẹ́ jẹ tàbí nítorí àtiwá ire àwọn mọ̀lẹ́bí àti tàwọn ọ̀rẹ́ wọn.
Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu fún àwa náà láti tẹ̀ lé irú ìlànà kan náà nígbà tá a bá ń yan àwọn tá ó fọkàn tán lónìí? Ǹjẹ́ a mọ àwọn èèyàn kan tí ìwà wọn fi hàn pé wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run? Ṣé wọ́n ti pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà híhù tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀? Ǹjẹ́ wọ́n lẹ́mìí àtisá fún ṣíṣe àwọn ohun tí kò dáa? Ǹjẹ́ wọ́n jẹ́ olóòótọ́ débi pé wọn kì í lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá? Dájúdájú àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ní irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí yẹ lẹ́ni tá a ń fọkàn tán.
Máà Jẹ́ Kí Ìjákulẹ̀ Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan Kó Ìrẹ̀wẹ̀sì Bá Ọ
A gbọ́dọ̀ ní sùúrù dáadáa nígbà tá a bá ń pinnu ẹni tá a máa gbẹ́kẹ̀ lé, nítorí pé ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè fọkàn tánni. Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé ká má tètè máa fi gbogbo ara gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn. Lọ́nà wo? Tóò, a lè kíyè sí ìwà ẹnì kan fún àkókò díẹ̀, ká máa wo bó ṣe ń ṣe nínú àwọn ipò kan. Ǹjẹ́ onítọ̀hún jẹ́ olóòótọ́ nínú àwọn ọ̀ràn kéékèèké? Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ó máa ń dá àwọn ohun tó bá yá lọ́wọ́ èèyàn padà lákòókò tó sọ pé òun á dá wọn padà, ṣe kì í sì í yẹ àdéhùn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọkàn wa lè balẹ̀ láti fọkàn tán onítọ̀hún nínú àwọn ọ̀ràn pàtàkì pẹ̀lú. Èyí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìlànà tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) Fífara balẹ̀ yan ẹni tá a ó fọkàn tán, ká sì fi sùúrù ṣe é lè ràn wá lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ ìjákulẹ̀ tó kàmàmà.
Bí ẹnì kan bá já wa kulẹ̀ ńkọ́? Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á rántí pé àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi já a kulẹ̀ pátápátá ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú un yẹn. Júdásì Ísíkáríótù dà á, ìbẹ̀rù sì mú kí àwọn tó kù sá lọ. Kódà ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sẹ́ Jésù. Àmọ́ Jésù mọ̀ pé Júdásì nìkan ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó ṣe. Jíjá tí wọ́n já Jésù kulẹ̀ nírú àkókò líle koko bẹ́ẹ̀ kò dí i lọ́wọ́ láti padà mú un dá àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó kù lójú ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn pé òun fọkàn tán wọn. (Mátíù 26:45-47, 56, 69-75; 28:16-20) Bákan náà, tá a bá sọ pé ẹnì kan já wa kulẹ̀, ó yẹ ká fara balẹ̀ wò ó bóyá ẹni tá a sọ pé ó dà wá yìí jẹ́ ẹni tí kò ṣeé fọkàn tán lóòótọ́ tàbí bóyá àìpé ẹ̀dá ló kàn jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀.
Ǹjẹ́ Mo Ṣeé Fọkàn Tán?
Ẹnì tó pinnu láti fara balẹ̀ yan ẹni tó lè fọkàn tán gbọ́dọ̀ fi òótọ́ inú bi ara rẹ̀ pé: ‘Ǹjẹ́ èmi fúnra mi ṣeé fọkàn tán? Ibo ni mo retí pé kí èmi àtàwọn ẹlòmíràn ṣeé fọkàn tán dé?’
Dájúdájú, ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń sọ òótọ́ ní gbogbo ìgbà. (Éfésù 4:25) Kì í fi dúdú pe funfun láti múnú àwọn olùgbọ́ rẹ̀ dùn kí nǹkan bàa lè ṣẹnuure fún un. Tí ẹni tó ṣeé fọkàn tán bá sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan, ó máa ń rí i pé òun sa gbogbo ipá òun láti mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ. (Mátíù 5:37) Bí ẹnì kan bá sọ ọ̀rọ̀ àṣírí fún ẹni tó ṣeé fọkàn tán, kó ní sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹlòmíràn, kó sì ní ṣe òfófó. Ẹni tó ṣeé fọkàn tán máa ń jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya rẹ̀. Kì í wo àwọn àwòrán arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, kì í ronú nípa adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, kì í sì í bá ẹ̀yà kejì tage. (Mátíù 5:27, 28) Ẹni tó yẹ ká fọkàn tán gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ àti ti ìdílé rẹ̀, kì í sì í rẹ́ àwọn èèyàn jẹ kó lè tètè lówó. (1 Tímótì 5:8) Fífi àwọn ìlànà tó bọ́gbọ́n mu látinú Ìwé Mímọ́ yìí sọ́kàn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn èèyàn tá a lè fọkàn tán. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, híhu ìwà tó bá ìlànà kan náà yìí mu yóò ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti di ẹni tó yẹ káwọn ẹlòmíràn fọkàn tán.
Inú wa yóò dùn gan-an láti gbé nínú ayé kan tí gbogbo èèyàn ti ṣeé fọkàn tán, níbi tí ìjákulẹ̀ tá a máa ń ní nígbà téèyàn bá dà wá yóò ti di ohun àtijọ́! Ṣé àlá tí kò lè ṣẹ nìyẹn? Ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ lójú àwọn tó gba àwọn ìlérí inú Bíbélì gbọ́, nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ayé tuntun” rírẹwà tó ń bọ̀, níbi tí kò ti ní sí ẹ̀tàn, irọ́, àti ìrẹ́jẹ, tí kò ní sí ìbànújẹ́ àti àìsàn kankan, kódà ikú pàápàá kò ní sí níbẹ̀! (2 Pétérù 3:13; Sáàmù 37:11, 29; Ìṣípayá 21:3-5) Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu láti túbọ̀ mọ̀ nípa ohun tó ń bọ̀ lọ́nà yìí? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti fún ọ ní ìsọfúnni lórí èyí àti lórí àwọn kókó pàtàkì mìíràn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àìfọkàntán ẹnikẹ́ni kì í jẹ́ kéèyàn láyọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Jèhófà ló yẹ ká fọkàn tán jù lọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Gbogbo wa la fẹ́ àjọṣe tá a gbé karí fífọkàn tán ara wa lẹ́nì kìíní kejì