Ìpàdé Àlàáfíà Westphalia—Ló Yí Ìgbà Padà Nílẹ̀ Yúróòpù
“NǸKAN tí kì í sábà wáyé ni pé káwọn olórí orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Yúróòpù kóra jọ bíi tòní yìí.” Roman Herzog, ààrẹ orílẹ̀-èdè olómìnira ti Jámánì tẹ́lẹ̀, ló sọ gbólóhùn yìí lóṣù October ọdún 1998. Ọba mẹ́rin, ọbabìnrin mẹ́rin, ọmọ ọba méjì, mọ́gàjí kan, àtàwọn ààrẹ mélòó kan ló wà níkàlẹ̀ nígbà tó sọ̀rọ̀ náà. Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù ló ṣonígbọ̀wọ́ ayẹyẹ yìí, ó sì ṣe pàtàkì gan-an nínú ìtàn àádọ́ta ọdún orílẹ̀-èdè Jámánì òde òní. Ayẹyẹ wo nìyẹn ná?
Ní oṣù October ọdún 1998 ni wọ́n ṣe àjọ̀dún àádọ́ta lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún ọdún [350] tí Ìpàdé Àlàáfíà Ìlú Westphalia wáyé. Níbi àdéhùn àlàáfíà ni wọ́n ti máa ń ṣe àwọn ìpinnu tó máa ń sọ bí ọjọ́ iwájú orílẹ̀-èdè á ṣe rí, mánigbàgbé sì ni Àdéhùn Àlàáfíà Ìlú Westphalia yìí. Àdéhùn tí wọ́n fọwọ́ sí lọ́dún 1648 yìí ló fòpin sí ogun tó jà fún ọgbọ̀n ọdún, òun ló sì jẹ́ kí Yúróòpù di ààlà ilẹ̀ tó láwọn orílẹ̀-èdè olómìnira nínú.
Wọ́n Jin Ètò Ìlú Lẹ́sẹ̀
Nígbà Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, ètò ẹ̀sìn àti ètò òṣèlú tó lágbára jù lọ nílẹ̀ Yúróòpù ni Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ilẹ̀ tó tóbi jura wọn lọ ló wà lábẹ́ ilẹ̀ ọba yẹn, àwọn ilẹ̀ yìí sì gbòòrò dé àwọn ibi tó wá di orílẹ̀-èdè Austria, ilẹ̀ olómìnira ti Czech, ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé, ilẹ̀ Jámánì, Switzerland, àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù àtàwọn apá ibì kan ní Ítálì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ilẹ̀ tó wà lábẹ́ Jámánì ló pọ̀ jù ní ilẹ̀ ọba yẹn, wọ́n kúkú ń pè é ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ ti orílẹ̀-èdè Jámánì. Àwọn alákòóso tó wà lábẹ́ olú ọba ló ń ṣàkóso ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì ni olú ọba náà fúnra rẹ̀, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Habsburg ti orílẹ̀-èdè Austria. Nígbà náà, bọ́ràn ṣe wá di pé ọwọ́ Olú Ọba àti ẹni tó bá wà nípò Póòpù ni agbára wà yìí, a jẹ́ pé Ilẹ̀ Yúróòpù bọ́ sọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì nìyẹn.
Àmọ́ ṣá, nígbà tó di ọ̀rúndún kẹrìndínlógún àti ìkẹtàdínlógún, àwọn èèyàn jin ètò ìṣèjọba yẹn lẹ́sẹ̀. Jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn èèyàn ń fọnmú nítorí ìwà ta-ló-máa-mú-mi tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ń hù. Àwọn atẹ́sìntò bíi Martin Luther àti John Calvin sọ̀rọ̀ nípa báwọn èèyàn ṣe máa padà sórí ìlànà Bíbélì. Èrò pọ̀ tó kọ́wọ́ ti Luther àti Calvin lẹ́yìn, àwọn wọ̀nyí ló sì dá àwọn ẹgbẹ́ tó di ẹ̀sìn Alátùn-úntò àti Pùròtẹ́sítáǹtì sílẹ̀. Àwọn Alátùn-úntò fi ẹ̀sìn Kátólíìkì, tàwọn ọmọlẹ́yìn Luther, àti tàwọn ọmọlẹ́yìn Calvin, fọ́ ilẹ̀ ọba náà sí mẹ́ta.
Inú fu àyà fu làwọn Kátólíìkì fi ń bá àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì lò, àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì náà sí kórìíra àwọn Kátólíìkì gan-an. Èyí ló fà á tí wọ́n fi dá Ìparapọ̀ Pùròtẹ́sítáǹtì àti Ìmùlẹ̀ Àwọn Kátólíìkì sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún. Àwọn ọba kan ní ilẹ̀ ọba yẹn dara pọ̀ mọ́ Ìparapọ̀ Pùròtẹ́sítáǹtì táwọn mìíràn sì dára pọ̀ mọ́ Ìmùlẹ̀ Àwọn Kátólíìkì. Ilẹ̀ Yúróòpù, àti ilẹ̀ ọba yẹn ní pàtàkì, di ibi tí wọ́n ti ń fura síra wọn. Ó wá dà bí ẹni pé orí àgbá ẹ̀tù ni wọ́n wà, bí iná kékeré bá sì rọra gbà báyìí, ńṣe ni gbẹgẹdẹ á gbiná. Nígbà tí gbẹgẹdẹ ọ̀hún sì wá pàpà gbiná, ó gba ọgbọ̀n ọdún gbáko tí wọ́n fi ja ìjà àjàkú akáta.
Gbẹgẹdẹ Gbiná ní Yúróòpù
Àwọn alákòóso ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì gbìyànjú láti jẹ́ káwọn Kátólíìkì tó jẹ́ ara àwọn Habsburg fàyè gba òmìnira ẹ̀sìn díẹ̀ sí i. Ṣùgbọ́n wọn ò gbà tinútinú, nítorí pé lọ́dún 1617 sí 1618, wọ́n ti ìjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Luther méjì tó wà ní Bohemia (ilẹ̀ olómìnira ti Czech) pa tipátipá. Àwọn sànmàrí inú Ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì fárígá, wọ́n ya wọnú ààfin Prague, wọ́n kó àwọn òṣìṣẹ́ Kátólíìkì mẹ́ta, wọ́n sì gba ojú fèrèsé jù wọn sílẹ̀ látorí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ló tanná ran ìjà àjàkú akátá tó sọ ilẹ̀ Yúróòpù di ojú ogun.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, Ọmọ Aládé Àlàáfíà ni wọ́n pera wọn, síbẹ̀ àwọn ìsìn méjèèjì ṣígun fúnra wọn. (Aísáyà 9:6) Nínú ìjà tí wọ́n pè ní Ogun Orí Òkè Funfun, Ìmùlẹ̀ Àwọn Kátólíìkì ṣẹ́gun ṣẹ́tẹ̀ Ìparapọ̀ Pùròtẹ́sítáǹtì, débi tó fi túká. Àárín ọjà ìlú Prague ni wọ́n pa àwọn bọ̀rọ̀kìnní ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì sí. Káàkiri ẹkùn ilẹ̀ Bohemia, wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tó kọ̀ láti jáwọ́ nínú ohun tí wọ́n gbà gbọ́, wọ́n sì pín ẹrù wọn mọ́wọ́. Ìwé náà 1648—Krieg und Frieden in Europa (1648—Ogun àti Àlàáfíà ní Yúróòpù) ṣàpèjúwe bí wọ́n ṣe gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù ẹlẹ́rù lọ́tẹ̀ yìí bí “èyí tó burú jù lọ látìgbà tí wọ́n ti ń gba ẹrù ẹlẹ́rù láàárín gbùngbùn Yúróòpù.”
Ohun tó bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ bí ìjà ẹ̀sìn lẹ́kùn ilẹ̀ Bohemia ló wá di ìjàdù agbára láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ní ọgbọ̀n ọdún tó tẹ̀ lé e, ńṣe làwọn orílẹ̀-èdè Denmark, Faransé, Netherlands, Sípéènì, àti Sweden ń jagun lọ ràì. Nítorí ọ̀kánjúwà àti ìjàdù agbára tó máa ń sábà dààmú àwọn aṣáájú Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì, wọ́n máa ń du ipò òṣèlú àti èrè orí okòwò mọ́ra wọn lọ́wọ́. Ìpele-ìpele ni wọ́n pín Ogun Ọgbọ̀n Ọdún náà sí, tí wọ́n sì fi orúkọ àwọn alátakò tó bá gbéjà ko olú ọba pe ìpele kọ̀ọ̀kan. Ìpele mẹ́rin ni wọ́n pín ogun náà sí nínú ọ̀pọ̀ ìwé ìwádìí, wọ́n pè wọ́n ní: Ogun Àárín Bohemia òun Palatine, Ogun Àárín Denmark òun Saxony Ìsàlẹ̀, Ogun Sweden àti Ogun Faransé òun Sweden. Lórí Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ ni wọ́n ti ja èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ogun yìí.
Àwọn nǹkan ìjà tí wọ́n lò nígbà yẹn ni ìbọn ìléwọ́, ìbọn ṣakabùlà, ìbọn jagamù, àti àwọn àgbá ayinta, orílẹ̀-èdè Sweden sì làgbà nínú àwọn tó ń ta nǹkan ogun. Àwọn Kátólíìkì àtàwọn Pùròtẹ́sítáǹtì wà á kò. Àwọn ọmọ ogun ń pariwo “Santa Maria” tàbí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa,” bí wọn ṣe ń lọ sójú ogun. Àwọn jagunjagun ń run gbogbo nǹkan tí wọ́n bá kàn lọ́nà bí wọ́n ṣe ń ṣígun wọnú àwọn ìlú tó wà lábẹ́ ilẹ̀ Jámánì, wọ́n sì ń ṣe àwọn ọmọ ogun tó ń bá wọn jà àtàwọn aráàlú bí ẹranko. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn aráàlú bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú. Èyí mà yàtọ̀ pátápátá gbáà sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó sọ pé: “Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́”!—Míkà 4:3.
Àwọn ọmọ kan tiẹ̀ wà ní Jámánì tó jẹ́ pé inú ogun ni wọ́n bí wọn sí, inú ẹ̀ náà ni wọ́n sì dàgbà sí, igbe àlàáfíà ni irú wọn ń ké. Ó ṣe kedere pé àlàáfíà ì bá ti wà bí kì í bá ṣe tàwọn alákòóso wọn tí èrò wọn nídìí òṣèlú ò jọra. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí ki òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ ogun náà, ó sì ti ń kọjá ìjà ẹ̀sìn nìkan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, òjíṣẹ́ onípò gíga kan nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ló rúná sógun ọ̀hún o.
Kádínà Richelieu Lo Agbára Rẹ̀
Orúkọ oyè Armand-Jean du Plessis ni Cardinal de Richelieu. Òun tún ni olórí ìjọba ilẹ̀ Faransé látọdún 1624 sí 1642. Richelieu ń wá bó ṣe máa sọ orílẹ̀-èdè Faransé di orílẹ̀-èdè tó lágbára jù nílẹ̀ Yúróòpù. Nítorí náà, ó gbìyànjú láti dín agbára àwọn Habsburg, tó jẹ́ Kátólíìkì bíi tiẹ̀, kù. Ọgbọ́n wo ló dá sí i? Ó gbówó fáwọn ọmọ ogun Pùròtẹ́sítáǹtì tó wà láwọn ìlú abẹ́ Jámánì, Denmark, Netherlands, àti Sweden, gbogbo àwọn wọ̀nyí ló sì ń gbogun ti àwọn Habsburg.
Lọ́dún 1635, Richelieu rán àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Faransé lọ sójú ogun fún ìgbà àkọ́kọ́. Ìwé náà vivat pax—Es lebe der Friede! (Kí Àlááfíà Wà Pẹ́ Títí!) ṣàlàyé pé nígbà tí “Ogun Ọgbọ̀n Ọdún náà” ń parí lọ ó ti “yí kúrò ní ogun láàárín àwọn ẹlẹ́sìn. . . . Ó ti di ti ìjà àgbà nídìí òṣèlú ní Yúróòpù.” Ohun tó jẹ́ pé nígbà tó bẹ̀rẹ̀, ìjà láàárín Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ni, ti wá di èyí tí Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ti jọ ń dojú kọ àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì bíi tiwọn. Nígbà tó fi máa di ọdún 1630, Ìmùlẹ̀ Àwọn Kátólíìkì ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́, wọ́n sì tú u ká ní ọdún 1635.
Àpérò Àlàáfíà ní Westphalia
Ogun ti piyẹ́ ilẹ̀ Yúróòpù, ìpànìyàn, ìfipábánilòpọ̀ àti àrùn wá fi ibẹ̀ ṣe ibùba. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ́n wá túbọ̀ ń wá àlàáfíà lójú méjèèjì nígbà tó ti yé wọn pé kò sẹ́ni tó máa borí nínú ogun tí wọ́n ń jà. Ìwé vivat pax—Es lebe der Friede! sọ pé “nígbà tó fi máa di ìparí ọdún 1630, àwọn ọba tó wà lórí oyè wá rí i lẹ́yìn-ọ-rẹyìn pé ogun ò lè jẹ́ kọ́wọ́ wọn tẹ ohun tí wọ́n ń wá.” Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé àlàáfíà ni gbogbo wọn ń fẹ́, báwo lọ́wọ́ wọn á ṣe tẹ̀ ẹ́?
Olú ọba Ferdinand Kẹta ti Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́, Ọba Louis Kẹtàlá ti ilẹ̀ Faransé, àti Ọbabìnrin Christina ti ilẹ̀ Sweden fohùn ṣọ̀kan pé ó yẹ kí àpérò kan wáyé níbi tí gbogbo àwọn tọ́ràn kàn yóò ti lè fikùnlukùn lórí bí àlàáfíà yóò ṣe jọba. Ibi méjì ni wọ́n yàn pé kí ìpàdé náà ti wáyé, ìlú Osnabrück àti ìlú Münster táwọn méjèèjì wà ní Westphalia tó jẹ́ ẹkùn-ìpínlẹ̀ Jámánì. Wọ́n yan ibi méjì yìí nítorí pé àwọn ló wà lágbedeméjì ọ̀nà béèyàn bá ń ti olú ìlú ilẹ̀ Sweden lọ sí olú ìlú ilẹ̀ Faransé. Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1643, àwọn aṣojú bí àádọ́jọ, táwọn kan nínú wọn kó agbo agbaninímọ̀ràn dání, gúnlẹ̀ sílùú méjèèjì. Àwọn aṣojú Kátólíìkì kóra jọ sí ìlú Münster, tí àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì sì wà ní Osnabrück.
Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n ṣètò bí wọn yòó ṣe máa bójú tó àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ipò tí wọ́n máa fi àwọn aṣojú tó wá sí, bí wọ́n ṣe máa tò wọ́n sórí ìjókòó àti bí ìpàdé náà ṣe máa lọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò àlàáfíà, àwọn alárinà ló sì ń bá wọn fi àbá ṣọwọ́ látọ̀dọ̀ àwọn aṣojú kan sí òmíràn. Lẹ́yìn bí ọdún márùn-ún tí wọ́n fi ṣèpàdé, tí ogun ò sì tíì dáwọ́ dúró, wọ́n fẹnu kò sórí bí àlàáfíà ṣe máa jọba. Ìwé tí wọ́n kọ Àdéhùn Àlàáfíà Westphalia sí ju ẹyọ kan lọ. Olú ọba Ferdinand Kẹta àti orílẹ̀-èdè Sweden tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn kan ní Osnabrück, olú ọba náà sì tọwọ́ bọ òmíràn pẹ̀lú ilẹ̀ Faransé ní Münster.
Bí ìròyìn ṣe ń tàn kálẹ̀ pé wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà báyìí, ńṣe làwọn èèyàn ń ṣàjọyọ̀ lọ ní rẹbutu. Lọ́pọ̀lọpọ̀ ìlú làwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí yin ìṣeré màjèṣín tó ń túká sójú òfuurufú. Aago ń ró nínú àwọn ilé ìjọsìn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yìnbọn sókè láti fi ìdùnnú wọn hàn sí àdéhùn náà, orin àwọn èèyàn sì gba ìgboro kan. Ṣé àwọn ara Yúróòpù lè máa retí àlàáfíà wíwà pẹ́ títí báyìí?
Ṣé Àlàáfíà Wíwà Pẹ́ Títí Ṣeé Ṣe?
Àdéhùn Àlàáfíà Westphalia fàyè gba dída ìjọba ṣe. Èyí túmọ̀ sí pé olúkúlùkù ilẹ̀ tó fọwọ́ sí àdéhùn náà gbà pé ó níbi tí ààlà ilẹ̀ òun dé àti pé òun ò ní yọjúràn sí ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ò bá pe òun sí. Bó ṣe di pé ààlà ilẹ̀ tó ń jẹ́ Yúróòpù tó láwọn orílẹ̀-èdè tó lómìnira wáyé nìyẹn. Àwọn orílẹ̀-èdè kan jàǹfààní nínú àdéhùn náà ju àwọn tó kù lọ.
Ilẹ̀ Faransé ló lágbára jù, nígbà táwọn orílẹ̀-èdè Netherlands àti Switzerland gbòmìnira. Ní ti àwọn ìlú tó wà lábẹ́ Jámánì, tí ogun náà run ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, àdéhùn náà kù díẹ̀ káàtó, ìdí ni pé ilẹ̀ Jámánì ò lè dá dúró láìfi tàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ròyìn pé: “Bí nǹkan bá ṣe pé àwọn agbára ayé bí ilẹ̀ Faransé, Sweden àti Austria sí ló máa sọ èrè tàbí àdánù táwọn ọba Jámánì máa rí.” Dípò kí wọ́n pa àwọn ìlú tó wà lábẹ́ Jámánì yìí pọ̀ di orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo, ńṣe ni wọ́n tú wọn ká bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n tún fa àkóso àwọn ìpínlẹ̀ kan níbẹ̀ lé àwọn alákòóso ilẹ̀ òkèèrè lọ́wọ́, irú bí àwọn odò pàtàkì tó wà ní Jámánì bí odò Rhine, Elbe, àti ti Oder.
Ipò kan náà ni wọ́n to àwọn onísìn Kátólíìkì, onísìn Luther, àti ti Calvin sí. Gbogbo èèyàn kọ́ lèyí dùn mọ́ nínú. Póòpù Innocent Kẹwàá tako àdéhùn àlàáfíà náà, ó sì kéde pé kò lè múlẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tí wọ́n là sílẹ̀ nípa ipò táwọn ìsìn máa wà kò yí padà fún ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta tó tẹ̀ lé e. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìnira ẹ̀sìn fún mùtúmùwà ò tíì dé, ó ti ń wọlé bọ̀ díẹ̀díẹ̀.
Àdéhùn yẹn ló fòpin sí Ogun Ọgbọ̀n Ọdún, tó sì paná ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀tẹ̀ tó bá a rìn. Èyí logun ẹ̀sìn lílágbára tó jà kẹ́yìn nílẹ̀ Yúróòpù. Ogun ò tí ì kásẹ̀ nílẹ̀ o, ṣùgbọ́n ohun tó ń fa ogun ti kúrò ní ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ó ti di ti òṣèlú tàbí ti ètò okòwò. Ìyẹn ò fi hàn pé ìsìn ò lọ́wọ́ nínú gbogbo rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Yúróòpù mọ́. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní àti Ìkejì àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Jámánì dé bẹ́líìtì tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ tó jọ tàwọn ẹlẹ́sìn sí, ìyẹn ni: “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.” Lákòókò tí wọ́n pa ara wọn nípakúpa yẹn, àwọn Kátólíìkì àtàwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tò sápá kan tí wọn sì ń pa àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì tó wà lápá kejì.
Dájúdájú, Àdéhùn Àlàáfíà Westphalia kò mú àlàáfíà tó wà pẹ́ títí wá. Àmọ́ ṣá o, aráyé onígbọràn yóò gbádùn irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ láìpẹ́. Jèhófà Ọlọ́run yóò mú àlàáfíà wá nípasẹ̀ Ìjọba ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ Mèsáyà, ìyẹn Jésù Kristi. Lábẹ́ ìjọba náà, ìsìn kan ṣoṣo ló máa wà, ìsìn náà yòó sì so gbogbo èèyàn pọ̀ ni, kò ní da àárín wọn rú. Kò sí nǹkan tó máa gbé ẹnì kankan dójú ogun mọ́, ì báà ṣe ogun ẹ̀sìn tàbí ogun mìíràn. Ìtura ńláǹlà ni yóò mà jẹ́ o nígbà tí ìjọba Ọlọ́run bá gba àkóso gbogbo ayé tí “àlàáfíà kì yóò [sì] lópin”!—Aísáyà 9:6, 7.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
Ohun tó jẹ́ pé nígbà tó bẹ̀rẹ̀, ìjà láàárín Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ni, ti wá di èyí tí Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ti jọ ń dojú kọ àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì bíi tiwọn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
Àwọn ọmọ ogun ń pariwo “Santa Maria” tàbí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa” bí wọ́n ṣe ń lọ sójú ogun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Kádínà Richelieu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwòrán tí wọ́n yà ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún tó ń fi ìtàpórógan àárín Luther, Calvin, àti póòpù hàn
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
Látinú ìwé Spamers Illustrierte Weltgeschichte VI
[Àwon àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń tàpórógan: Látinú ìwé Wider die Pfaffenherrschaft; àwòrán ilẹ̀: The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck