Ǹjẹ́ Ìfẹ́ Ọlọ́run Ló Ń Ṣẹ?
“Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.
ỌKÀN Julio àti Christina gbọgbẹ́ bí wọ́n ti ń wo mẹ́rin lára àwọn ọmọ wọn títí tí wọ́n fi jóná kú. Awakọ̀ kan tó ti mutí yó ló kọ lu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn níbi tí wọ́n gbé e sí, ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà bá gbaná. Wọ́n yọ Marcos, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án tó jẹ́ ọmọ wọn karùn ún, jáde nínú iná náà, àmọ́ iná ti ba ara ẹ̀ jẹ́. Ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ bàbá ọmọ náà. Ọ̀rọ̀ tó fi ń tu ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀ nínú ni pé: “Ìfẹ́ Ọlọ́run ni, ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, ì báà ṣe ohun rere tàbí ohun búburú, ó yẹ ká gbà fún Ọlọ́run.”
Irú ọ̀rọ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ nìyẹn nígbà tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí bá wáyé. Wọ́n á sọ pé, ‘Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ alágbára gbogbo tó sì bìkítà nípa wa, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní láti jẹ́ fún ire wa láwọn ọ̀nà kan, kódà bó tiẹ̀ ṣòroó lóye.’ Ǹjẹ́ o fara mọ́ èrò yẹn?
Èrò àwọn èèyàn pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, yálà rere tàbí búburú, jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, ni wọ́n máa ń gbé ka àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tá a fà yọ lókè yìí tí ń bẹ nínú àdúrà tá à ń pè ní Àdúrà Olúwa. Ìfẹ́ Ọlọ́run ń ṣẹ ní ọ̀run, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Nítorí náà, tá a bá gbàdúrà pé, ‘Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,’ ṣé a kò gbà pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ni?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni èrò yìí kò tẹ́ lọ́rùn. Lójú wọn, ńṣe ló dà bíi pé bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára ẹ̀dá èèyàn kò kan Ọlọ́run. Wọ́n béèrè pé, ‘Báwo ni Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ṣe máa fẹ́ kí nǹkan búburú ṣẹlẹ̀ sáwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀? Tí ẹ̀kọ́ kankan bá tiẹ̀ wà tá a lè kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀, kí ni ẹ̀kọ́ náà lè jẹ́?’ Bóyá bí ìwọ náà ṣe rí ọ̀rọ̀ náà nìyẹn.
Nítorí èyí, ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà Jákọ́bù tó tún jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Ọlọ́run kọ́ lẹni tó ń fa àwọn nǹkan búburú o. Nígbà náà, ó ṣe kedere pé kì í ṣe gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lónìí ni ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ ènìyàn, ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè àti ìfẹ́ Èṣù. (Jòhánù 1:13; 2 Tímótì 2:26; 1 Pétérù 4:3) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Julio àti Christina kì í ṣe ìfẹ́ Baba ọ̀run onífẹ̀ẹ́, ṣé o gbà bẹ́ẹ̀?
Nígbà náà, kí wá ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: ‘Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ’? Ṣé ó kàn ń bẹ Ọlọ́run pé kó dá sí ọ̀ràn pàtó kan ni tàbí ńṣe ni Jésù ń kọ́ wa láti máa gbàdúrà fún ohun kan tó jọjú tó sì sàn jùyẹn lọ, ìyẹn ìyípadà kan tí gbogbo wa lè máa wọ̀nà fún? Ẹ jẹ́ ká ṣe àyẹ̀wò síwájú sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́: Àwọn Àwòrán Dominique Faget-STF/AFP/Getty; ọmọdé: FAO photo/B. Imevbore