Rèbékà—Akíkanjú Obìnrin Tó Bẹ̀rù Ọlọ́run
KÁ NI o fẹ́ wá ìyàwó fọ́mọ rẹ. Irú èèyàn wo lo máa wá fún un? Irú àwọn ànímọ́ wo lo máa fẹ́ kó ní? Ṣé arẹwà obìnrin, tó jẹ́ onílàákàyè, tó jẹ́ onínúure àti òṣìṣẹ́kára lo máa wá fún un? Tàbí nǹkan míì lo máa kọ́kọ́ wò lára onítọ̀hún?
Irú wàhálà tí Ábúráhámù dojú kọ nìyẹn. Jèhófà ti ṣèlérí pé àtọmọdọ́mọ rẹ̀ yóò tipasẹ̀ Ísákì ọmọ rẹ̀ rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. Níbi tá a ti bẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí, Ábúráhámù ti di àgbàlagbà, ṣùgbọ́n ọmọ rẹ̀ kò tíì fẹ́yàwó. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3, 7; 17:19; 22:17, 18; 24:1) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ísákì àti aya tá ò tíì rí yìí títí kan gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn ni yóò jọ gbádùn ìbùkún náà, Ábúráhámù ní láti ṣètò kí Ísákì lè rí aya rere fẹ́. Olórí gbogbo rẹ̀ ni pé, obìnrin náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Nítorí kò sí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ nílẹ̀ Kénáánì tí Ábúráhámù ń gbé, ó ní láti wá a lọ sílẹ̀ ibòmíràn. Rèbékà lẹni tí wọ́n wá yàn láti fẹ́ níkẹyìn. Báwo ni wọ́n ṣe rí i? Ṣé ẹni tẹ̀mí ni? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ tá a bá gbé àpẹẹrẹ rẹ̀ yẹ̀ wò?
Wíwá Obìnrin Tó Kúnjú Ìwọ̀n
Ábúráhámù rán ìránṣẹ́ rẹ̀ tó dàgbà jú lọ, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Élíésérì, lọ sí Mesopotámíà tó jìnnà rere láti lọ wá aya wá fún Ísákì láàárín àwọn ìbátan Ábúráhámù tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà bíi tirẹ̀. Ọ̀ràn náà ṣe pàtàkì débi pé Ábúráhámù sọ fún Élíésérì pé kó búra pé òun ò ní mú lára àwọn ọmọ Kénáánì wá fún Ísákì láti fi ṣaya. Bí Ábúráhámù ṣe rin kinkin mọ̀ ọ́n pé òun kò nífẹ̀ẹ́ sáwọn ọmọ Kénáánì fi hàn pé ọ̀ràn náà yẹ fún àfiyèsí.—Jẹ́nẹ́sísì 24:2-10.
Nígbà tí Élíésérì dé ìlú àwọn ìbátan Ábúráhámù, ó da ràkúnmí rẹ̀ mẹ́wàá lọ sẹ́bàá kànga kan. Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀! Ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ni, Élíésérì gbàdúrà pé: “Kíyè sí i, èmi dúró níbi ìsun omi, àwọn ọmọbìnrin àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà sì ń jáde bọ̀ wá fa omi. Kí ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́bìnrin tí èmi bá wí fún pé, ‘Jọ̀wọ́, sọ ìṣà omi rẹ kalẹ̀, kí èmi lè mu,’ tí yóò sì wí ní ti gidi pé, ‘Mu, èmi yóò sì tún fi omi fún àwọn ràkúnmí rẹ,’ ẹni yìí ni kí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ, fún Ísákì.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:11-14.
Ó ṣeé ṣe káwọn obìnrin ìlú yẹn mọ̀ pé ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ gan-an lè mu omi tí ó tó ọgọ́rùn-ún lítà (gálọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n). Nítorí náà obìnrin tó bá gbà láti fún ràkúnmí mẹ́wàá lómi gbọ́dọ̀ ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ ńlá. Bó ṣe ń ṣiṣẹ́ yìí táwọn yòókù sì ń wò ó níran, tí wọn ò sì ràn án lọ́wọ́ fi hàn pé ó jẹ́ alágbára, onísùúrù, onírẹ̀lẹ̀ àti pé ó láàánú èèyàn àti ẹranko.
Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Kí ó tó parí ọ̀rọ̀ sísọ, họ́wù, kíyè sí i, ẹni tí ó jáde wá ni Rèbékà, tí a bí fún Bẹ́túélì, ọmọkùnrin Mílíkà, aya Náhórì, arákùnrin Ábúráhámù, ìṣà omi rẹ̀ sì wà lórí èjìká rẹ̀. Wàyí o, ọ̀dọ́bìnrin náà fani mọ́ra gidigidi ní ìrísí, wúńdíá ni, . . . ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀ sí ibi ìsun omi náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pọn omi kún ìṣà rẹ̀, ó sì gòkè wá. Ní kíá, ìránṣẹ́ náà sáré pàdé rẹ̀, ó sì wí pé: ‘Jọ̀wọ́ fún mi ní òfèrè omi díẹ̀ láti inú ìṣà omi rẹ.’ Ẹ̀wẹ̀, obìnrin náà wí pé: ‘Mu, olúwa mi.’ Pẹ̀lú ìyẹn, ó yára sọ ìṣà rẹ̀ ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún un ní omi mu.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:15-18.
Ǹjẹ́ Rèbékà Kúnjú Ìwọ̀n?
Ọmọ ọmọ arákùnrin Ábúráhámù ni Rèbékà, yàtọ̀ sì pé o jẹ́ arẹwà obìnrin, ó tún jẹ́ oníwà mímọ́. Ara rẹ̀ yá mọ́ àwọn àlejò, àmọ́ kì í ṣe é ní àṣejù. Oore ló ṣe fún Élíésérì nígbà tí ìyẹn sọ fún un pé kó fóun lómi. Ohun tó yẹ kó ṣe náà nìyẹn nítorí pé bó ṣe yẹ kí ọmọlúwàbí hùwà nìyẹn. Ìdánwò kejì wá ńkọ́?
Rèbékà sọ pé: “Mu, olúwa mi.” Àmọ́ kò fi mọ síbẹ̀. Rèbékà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Àwọn ràkúnmí rẹ ni èmi yóò tún fa omi fún títí tí wọn yóò fi mu tẹ́rùn.” Ohun tó ṣe fún wọ́n ju nǹkan tí wọ́n ń retí pé kó ṣe lọ. Pẹ̀lú ìháragàgà, “ó yára tú ìṣà rẹ̀ sínú ọpọ́n ìmumi, ó sì sáré léraléra lọ síbi kànga náà láti fa omi, ó sì ń bá a nìṣó láti fa omi fún gbogbo àwọn ràkúnmí rẹ̀.” Akíkanjú obìnrin ni lóòótọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ṣe sọ, ‘ní gbogbo àkókò yẹn, ọkùnrin náà tẹjú mọ́ ọn pẹ̀lú kàyéfì.’—Jẹ́nẹ́sísì 24:19-21.
Nígbà tí Élíésérì mọ̀ pé ìbátan Ábúráhámù ni ọ̀dọ́bìnrin yìí, ńṣe ló wólẹ̀ tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Ó wá béèrè lọ́wọ́ Rèbékà bóyá àyè wà nílé bàbá rẹ̀ tí òun àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ lè sùn sí mọ́jú. Rèbékà sọ fún un pé àyè wà, ó sì sáré lọ sọ fáwọn ara ilé nípa àwọn àlejò náà.—Jẹ́nẹ́sísì 24:22-28.
Nígbà tí Élíésérì ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Lábánì, ẹ̀gbọ́n Rèbékà àti Bẹ́túélì, bàbá rẹ̀, wọ́n róye pé ọwọ́ Ọlọ́run wà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó dájú pé Rèbékà ni Ísákì yóò fẹ́. Wọ́n ní: “Máa mú un lọ, sì jẹ́ kí ó di aya fún ọmọkùnrin ọ̀gá rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ.” Kí wá lèrò Rèbékà? Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé bóyá ó máa fẹ́ bá wọn lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó fi gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan fèsì ní èdè Hébérù, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà sì ni pé “Mo ti ṣe tán láti lọ.” Kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ kó lọ́kọ tipátipá o. Ábúráhámù sì ti jẹ́ kí Élíésérì mọ̀ ní kedere pé, “bí obìnrin náà kò bá fẹ́” wá, kò ní sí lábẹ́ ìbúra náà mọ́. Rèbékà náà rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú ọ̀ràn náà. Nítorí náà, kíá ló fi àwọn ará ilé rẹ̀ sílẹ̀ láti lọ fẹ́ ọkùnrin kan tí kò tíì mọ̀ rí. Ìpinnu tó fi ìgboyà ṣe yẹn jẹ́ ọ̀nà títayọ kan tó fi ìgbàgbọ́ hàn. Òun gan-an lẹni tó yẹ!—Jẹ́nẹ́sísì 24:29-59.
Nígbà tí Rèbékà dé ọ̀dọ̀ Ísákì, ó fi aṣọ bojú, tó fi hàn pé ó tẹrí ba fún un. Ísákì fi í ṣe aya, ó sì dájú pé àwọn ànímọ́ rere tó ní mú kí Ísákì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.—Jẹ́nẹ́sísì 24:62-67.
Àwọn Ìbejì Ọkùnrin
Nǹkan bí ọdún mọ́kàndínlógún ni Rèbékà fi wà láìrọ́mọ bí. Níkẹyìn, Rèbékà lóyún ìbejì, ṣùgbọ́n oyún náà yọ ọ́ lẹ́nu gan-an nítorí pé àwọn ọmọ méjèèjì tó wà nínú rẹ̀ bá ara wọn jìjàkadì, èyí sì mú kó ké pe Ọlọ́run. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí ipò kan bá kó ìdààmú ọkàn bá wa. Jèhófà gbọ́ igbe Rèbékà, ó sì fi í lọ́kàn balẹ̀. Rèbékà yóò di ìyá orílẹ̀-èdè méjì, èyí “ẹ̀gbọ́n ni yóò sì sin àbúrò.”—Jẹ́nẹ́sísì 25:20-26.
Ó lè máà jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ni kìkì ohun tó mú kí Rèbékà nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù tó jẹ́ àbúrò ju ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. Àwọn ọmọkùnrin náà yàtọ̀ síra. Jékọ́bù jẹ́ “aláìlẹ́gàn,” àmọ́ Ísọ̀ jẹ́ ẹnì kan tí kì í ka nǹkan tẹ̀mí sí rárá débi pé ó tìtorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ta ogun ìbí rẹ̀ fún Jékọ́bù, ìyẹn ẹ̀tọ́ tó ní láti jogún àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣèlérí. Fífi tí Ísọ̀ fi ọmọ Hétì méjì ṣaya fi hàn pé nǹkan tẹ̀mí ò jọ ọ́ lójú rárá, àní ńṣe ló fojú tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, èyí sì mú káwọn òbí rẹ̀ ní ìrora ọkàn ńlá.—Jẹ́nẹ́sísì 25:27-34; 26:34, 35.
Ó Ṣakitiyan Láti Jẹ́ Kí Jékọ́bù Rí Ìbùkún Gbà
Bíbélì ò sọ bóyá Ísákì mọ̀ pé Ísọ̀ yóò ṣe ìránṣẹ́ fún Jékọ́bù. Bó ti wù kó rí, Rèbékà àti Jékọ́bù mọ̀ pé Jékọ́bù ni yóò gba ìbùkún náà. Nígbà tí Rèbékà gbọ́ pé Ísákì fẹ́ súre fún Ísọ̀ tó bá ti gbé oúnjẹ ẹran ìgbẹ́ lọ fún bàbá rẹ̀, kíá ló káràmáásìkí ọ̀rọ̀ náà. Ẹ̀mí ṣíṣe nǹkan ní kánmọ́ àti ẹ̀mí ìtara tó ní nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ ṣì wà lára rẹ̀. Ó ‘pàṣẹ’ fún Jékọ́bù pé kó lọ mú ọmọ ewúrẹ́ méjì wá fóun. Ó fẹ́ fi se oúnjẹ tí ọkọ rẹ̀ fẹ́ràn gan-an. Jékọ́bù gbọ́dọ̀ dọ́gbọ́n ṣe bíi pé òun ni Ísọ̀ láti lè rí ìbùkún náà gbà. Àmọ́, Jékọ́bù sọ pé òun kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ó di dandan kí àṣírí ìwà arúmọjẹ yìí tú sí bàbá rẹ̀ lọ́wọ́, yóò sì fi í ré! Rèbékà sọ pé àfi dandan kó ṣe ohun tóun sọ. Ó ní, “orí mi ni kí ìfiré tí ó wà fún ọ wá, ọmọkùnrin mi.” Ó wá se oúnjẹ náà, ó sì dọ́gbọ́n kan tí ara Jékọ́bù fi dà bíi ti Ísọ̀, ó wá ní kó lọ bá ọkọ òun.—Jẹ́nẹ́sísì 27:1-17.
Wọn ò sọ ìdí tí Rèbékà fi hùwà lọ́nà yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé ohun tó ṣe yẹn kò dára, ṣùgbọ́n Bíbélì ò sọ bẹ́ẹ̀, àní Ísákì pàápàá kò sọ pé ohun tó ṣe burú lẹ́yìn tó mọ̀ pé Jékọ́bù ti gba ìbùkún náà. Dípò ìyẹn ńṣe ni Ísákì tún fi kún ìbùkún náà. (Jẹ́nẹ́sísì 27:29; 28:3, 4) Rèbékà mọ ohun tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọmọ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣe nǹkan kan láti lè rí i dájú pé Jékọ́bù ló gbà ìbùkún náà, torí pé òun ló tọ́ sí. Ó ṣe kedere pé èyí bá ìfẹ́ Jèhófà mu.—Róòmù 9:6-13.
Wọ́n Ní Kí Jékọ́bù Lọ sí Háránì
Rèbékà ba ohun tí Ísọ̀ gbèrò àtiṣe jẹ́, ó rọ Jékọ́bù pé kó sá kúrò nílé títí dìgbà tí ìbínú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò fi rọlẹ̀. Ó kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Ísákì bóyá ó fara mọ́ ohun tóun ń gbèrò yìí, àmọ́ kò jẹ́ kó mọ̀ pé Ísọ̀ ń bínú gan-an sí Jékọ́bù. Dípò ìyẹn, ńṣe ló dọ́gbọ́n sọ àníyàn rẹ̀ fún ọkọ rẹ̀ pé Jékọ́bù lè lọ fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin Kénáánì. Gbígbọ́ tí Ísákì gbọ́ pé Jékọ́bù lè lọ fẹ́ ọmọ Kénáánì ti tó láti mú kó pàṣẹ fún Jékọ́bù pé kò gbọ́dọ̀ dán irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ wò, kí ó sì sọ fún un pé kó lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn Rèbékà láti lọ wá ìyàwó tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé Rèbékà tún padà rí Jékọ́bù, àmọ́ àwọn ìgbésẹ̀ tí Rèbékà gbé yọrí sí ọ̀pọ̀ ìbùkún fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ọjọ́ iwájú.—Jẹ́nẹ́sísì 27:43–28:2.
Nǹkan tá a mọ̀ nípa Rèbékà mú ká fẹ́ràn rẹ̀. Arẹwà obìnrin ni, àmọ́ sísìn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ló jẹ́ kó lẹ́wà ní ti gidi. Ànímọ́ tí Ábúráhámù ń fẹ́ kí aya ọmọ òun ní nìyẹn. Bóyá tiẹ̀ ni àwọn ànímọ́ rere mìíràn tó ní kò fi kọjá gbogbo ànímọ́ tí Ábúráhámù ń retí pé kó ní. Ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó fi ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ìtara rẹ̀, ẹ̀mí ṣíṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tó ní jẹ́ àwọn ànímọ́ tó yẹ kí gbogbo Kristẹni obìnrin ní. Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ànímọ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ń wò lára àwọn obìnrin tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere lóòótọ́.