Bí a Ṣe Lè Máa Finú Rere Hàn Nínú Ayé Oníwà Òǹrorò Yìí
“Ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra nínú ará ayé ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.”—ÒWE 19:22.
1. Kí nìdí tó fi ṣòro láti máa fi inú rere hàn?
ṢÉ ONÍNÚURE èèyàn ni ọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣòro fún ọ láti gbé nínú ayé òde òní. Lóòótọ́, Bíbélì tọ́ka sí inú rere gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára “èso ti ẹ̀mí,” àmọ́ kí nìdí tó fi ṣòro láti máa fi inú rere hàn kódà láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni? (Gálátíà 5:22) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ pé gbogbo ayé wà lábẹ́ ìdarí ẹni ẹ̀mí kan tó jẹ́ òǹrorò, ìyẹn Sátánì Èṣù. (1 Jòhánù 5:19) Jésù Kristi pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé.” (Jòhánù 14:30) Abájọ tí ayé yìí fi dà bí alákòóso rẹ̀ tó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀, ẹni tí ìwà rẹ̀ burú jáì.—Éfésù 2:2.
2. Àwọn ìṣòro wo ló lè nípa lórí ọ̀nà tá a ń gbà fi inú rere hàn?
2 Ipa tí kò dára ló máa ń ní lórí ìgbésí ayé wa nígbà táwọn èèyàn ò bá fi inú rere hàn sí wa. Irú ìwà òǹrorò yìí lè wá látọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò tó ń pẹ̀gàn, àwọn àjèjì tí kò níwà bí ọ̀rẹ́, kódà ó lè jẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn tá a jọ jẹ́ ara ìdílé kan náà, tí wọ́n máa ń hu ìwà tí ò dáa síni nígbà mìíràn. Ìdààmú ọkàn tá a máa ń ní nígbà tá a bá bá àwọn tí kì í bọ̀wọ̀ fúnni, àwọn tó máa ń jágbe mọ́ni àtàwọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú da nǹkan pọ̀ máa ń pọ̀ gan-an. Táwọn èèyàn ò bá fi inú rere hàn sí wa, ìyẹn lè sọ àwa náà di òṣónú ká sì máa ronú bá a ṣe máa fi búburú san búburú. Ìyẹn sì lè wá sọ wá di aláìlera nípa tẹ̀mí tàbí nípa tara.—Róòmù 12:17.
3. Kí ni ìṣòro líle koko táwọn èèyàn ń dojú kọ tí kì í jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti jẹ́ onínúure?
3 Àwọn ipò tó nira nínú ayé tún lè mú kó ṣòro fún wa láti máa fi inú rere hàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn ń bára wọn nínú másùnmáwo nítorí ìbẹ̀rù àwọn apániláyà àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn, títí kan ìbẹ̀rù pé ó ṣeé ṣe káwọn kan lo ohun ìjà oníkòkòrò àrùn tàbí ohun ìjà tó ń pa àwọn èèyàn lọ bẹẹrẹ. Yàtọ̀ síyẹn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló jẹ́ òtòṣì paraku, tó jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ń rí oúnjẹ jẹ, tí ilé àti aṣọ wọn kò fí bẹ́ẹ̀ bójú mu, tó sì jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ń rí ìtọ́jú ìwòsàn gbà. Fífi inú rere hàn yóò wá di ohun tó nira nígbà tí ipò nǹkan bá ń burú sí i.—Oníwàásù 7:7.
4. Èrò òdì wo làwọn kan lè ní nígbà tí wọ́n bá ń ronú nípa fífi inú rere hàn sí àwọn ẹlòmíràn?
4 Ẹnì kan lè sọ pé fífi inú rere hàn kì í ṣe ohun tó pọn dandan, tàbí pé ó jẹ́ àmì ìwà òmùgọ̀ pàápàá. Ó tiẹ̀ lè máa rò pé wọ́n ń yan òun jẹ, àgàgà nígbà táwọn èèyàn ò bá gba tiẹ̀ rò. (Sáàmù 73:2-9) Àmọ́, Bíbélì fún wa ní ìtọ́ni tó dára nígbà tó sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Ìwà tútù àti inú rere jẹ́ méjì lára èso tẹ̀mí tó tan mọ́ra gan-an tó sì máa ń wúlò dáadáa nígbà tá a bá ń kojú àwọn ipò líle koko.
5. Mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn ibi tó yẹ ká ti máa fi inú rere hàn nínú ìgbésí ayé wa?
5 Níwọ̀n bó ti ṣe pàtàkì gan-an fún àwa Kristẹni láti máa fi èso ẹ̀mí Ọlọ́run hàn, á dára ká ṣe àyẹ̀wò ọ̀nà tá a lè gbà fi inú rere, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn hàn. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti fi inú rere hàn nínú ayé oníwà òǹrorò yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a kò ní jẹ́ kí ipa tí Sátánì ń ní lórí ẹni, sọ wá di ẹni tí kò ní inú rere mọ́, àgàgà nínú àwọn ipò tó lè pinni lẹ́mìí? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè máa fi inú rere hàn nínú ìdílé, níbi iṣẹ́, nílé ìwé, láàárín àwọn aládùúgbò, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, àti láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́.
Fífi Inú Rere Hàn Láàárín Ìdílé
6. Kí nìdí tí inú rere láàárín ìdílé fi ṣe pàtàkì gan-an, báwo la ṣe lè fi í hàn?
6 Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà bù kún wa kó sì máa tọ́ wá sọ́nà, ó pọn dandan fún wa láti ní èso tẹ̀mí ká sì máa lò ó dáadáa. (Éfésù 4:32) Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí àwọn tó wà nínú ìdílé kan náà fi ní láti máa fi inú rere hàn sí ara wọn. Nínú àjọṣe ojoojúmọ́, ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ jẹ́ onínúure sí ara wọn kí wọ́n sì máa bìkítà fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú. (Éfésù 5:28-33; 6:1, 2) Irú inú rere bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ fara hàn nínú ọ̀nà táwọn tó jọ wà nínú ìdílé kan náà gbà ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, kí àwọn ọmọ máa bọlá fún àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn pẹ̀lú, káwọn òbí sì máa bá àwọn ọmọ wọn lò lọ́nà tó dára. Kí wọ́n máa yìn wọ́n, kí wọ́n má kàn máa bẹnu àtẹ́ lù wọ́n.
7, 8. (a) Irú ìwà wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún tá a bá fẹ́ fi inú rere tòótọ́ hàn nínú ìdílé? (b) Báwo ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó lárinrin ṣe ń jẹ́ kí ìdè ìdílé túbọ̀ lágbára sí i? (d) Báwo lo ṣe lè fi inú rere hàn nínú ìdílé rẹ?
7 Jíjẹ́ onínúure sáwọn tó wà nínú ìdílé wa gba pé ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ní ti gidi, ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.” Ojoojúmọ́ ni àwọn ìdílé tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi ọ̀wọ̀ hàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó lárinrin ló ń jẹ́ kí ìdè ìdílé túbọ̀ lágbára sí i. Nígbà tí àríyànjiyàn bá wáyé nínú ìdílé, tó o bá fẹ́ kí wàhálà náà rọlẹ̀, gbìyànjú láti yanjú ìṣòro náà dípò kó o máa wá bí ọ̀rọ̀ tìẹ ṣe máa borí. Àwọn tó wà nínú ìdílé aláyọ̀ máa ń sa gbogbo ipá wọn láti fi inú rere hàn sí ara wọn àti láti gba ti ẹnì kejì wọn rò.—Kólósè 3:8, 12-14.
8 Inú rere dára, ó sì máa ń jẹ́ ká fẹ́ ṣe ohun tó dára fún ẹlòmíràn. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó gbìyànjú láti wúlò fún àwọn tá a jọ wà nínú ìdílé kan náà, ká máa gba tiwọn rò, ká sì máa ṣèrànwọ́ lọ́nà tí yóò tẹ́ wọn lọ́rùn. Ó gba pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan sapá, kí gbogbo ìdílé sì tún sapá lápapọ̀ kí wọ́n tó lè fi inú rere tó máa jẹ́ kí wọ́n ní orúkọ rere hàn. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé wọ́n máa rí ìbùkún Ọlọ́run gbà nìkan ni, àmọ́ wọ́n á tún bọlá fún Jèhófà, Ọlọ́run inú rere nínú ìjọ àti láàárín àdúgbò.—1 Pétérù 2:12.
Fífi Inú Hàn Rere Níbi Iṣẹ́
9, 10. Ṣàpèjúwe àwọn ìṣòro tó lè yọjú níbi iṣẹ́, kó o sì sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà tá a lè gbà fi inú rere bójú tó wọn.
9 Ìgbòkègbodọ̀ ojoojúmọ́ níbi iṣẹ́ lè máà jẹ́ kó rọrùn fún Kristẹni kan láti fi inú rere hàn sí àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ìdíje láàárín àwọn òṣìṣẹ́ lè jẹ́ kí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni kan tó jẹ́ ẹlẹ́tàn àti alárèékérekè fi iṣẹ́ ẹni sínú ewu, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ bani lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ẹni tó gbani síṣẹ́. (Oníwàásù 4:4) Kò rọrùn láti fi inú rere hàn ní irú àkókò bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé kò sóhun tó dára tó kéèyàn jẹ́ onínúure, ìránṣẹ́ Jèhófà si ní láti sa gbogbo ipá rẹ̀ láti yí àwọn tí kò rọrùn láti bá da nǹkan pọ̀ lọ́kàn padà. Níní ẹ̀mí aájò lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí. Bóyá o lè ṣaájò nígbà tí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ kan bá ń ṣàìsàn tàbí nígbà tí ara àwọn kan nínú ìdílé rẹ̀ kò bá yá. Kódà bíbéèrè àlàáfíà ìdílé rẹ̀ lè ní ipa tó dára lórí onítọ̀hún. Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn Kristẹni ní láti sapá láti jẹ́ kí ìṣọ̀kan àti àlàáfíà gbilẹ̀ níwọ̀n bó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ wọn ló wà. Nígbà mìíràn, ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ tó fi hàn pé a bìkítà, pé a sì ní ire àwọn èèyàn lọ́kàn lè yanjú ọ̀ràn náà.
10 Ní àwọn ìgbà mìíràn, agbanisíṣẹ́ lè sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ gbọ́dọ̀ gba ohun tí òun bá sọ, kó sì fẹ́ kí gbogbo wọn lọ́wọ́ nínú àwọn ohun kan tó fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni hàn tàbí ayẹyẹ kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Nígbà tí ẹ̀rí ọkàn Kristẹni kan kò bá gbà á láyè láti lọ́wọ́ nínú irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè fa èdè àìyedè láàárín òun àti ọ̀gá rẹ̀. Ní àkókò yẹn, ó lè má bọ́gbọ́n mu láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìdí tí kò fi tọ́ láti fara mọ́ ohun tí agbanisíṣẹ́ náà fẹ́ ká ṣe. Ó ṣe tán, ohun tí wọ́n sọ pé ká ṣe yẹn lè dà bí ohun tí ó tọ́ lójú àwọn tí èrò wọn yàtọ̀ sí ohun tí àwa Kristẹni gbà gbọ́. (1 Pétérù 2:21-23) O lè rọra fi sùúrù ṣàlàyé ìdí tí o kò fẹ́ fi bá wọn lọ́wọ́ sí i. Má ṣe fi ọ̀rọ̀ kòbákùngbé fèsì ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí wọ́n bá sọ sí ọ. Á dára káwọn Kristẹni tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àtàtà tó wà nínú Róòmù 12:18 tó sọ pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”
Fífi Inú Rere Hàn Nílé Ìwé
11. Àwọn ìṣòro wo ló ń dojú kọ àwọn ọ̀dọ́ nínú fífi inú rere hàn sí àwọn ọmọ ilé ìwé wọn?
11 Ó lè jẹ́ ìṣòro gidi fún àwọn ọ̀dọ́ láti fi inú rere hàn sí àwọn tí wọ́n jọ ń lọ sílé ìwé. Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń fẹ́ kí àwọn tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì gba tiwọn. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kan máa ń hùwà ìpáǹle káwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù lè gba tiwọn, kódà wọ́n máa ń bá a débi pé kí wọ́n máa halẹ̀ mọ́ àwọn ẹlòmíràn nílé ìwé. (Mátíù 20:25) Àwọn ọ̀dọ́ mìíràn máa ń fi bí wọ́n ṣe mọ̀wé tó àti bí wọn ṣe mọ eré ìdárayá tàbí àwọn ìgbòkègbodò mìíràn ṣe tó ṣakọ. Nígbà tí wọ́n bá ń fi ẹ̀bùn tí wọ́n ní yìí ṣakọ, wọ́n sábà máa ń ṣàìdáa sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù, tí wọ́n á sì máa fi àṣìṣe ronú pé ẹ̀bùn àwọn jẹ́ káwọn sàn ju àwọn yòókù lọ. Ọ̀dọ́ Kristẹni kan ní láti ṣọ́ra kí ó má bàá fara wé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. (Mátíù 20:26, 27) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere” àti pé ìfẹ́ “kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀.” Nítorí náà, ó di dandan fún Kristẹni kan láti máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ nínú bó ṣe ń bá àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ̀ lò, kì í ṣe pé kó máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó ń ṣàìdáa sáwọn èèyàn.—1 Kọ́ríńtì 13:4.
12. (a) Kí nìdí tó fi lè jẹ́ ìṣòro fún àwọn ọ̀dọ́ láti jẹ́ onínúure sí àwọn olùkọ́ wọn? (b) Tá ni àwọn ọ̀dọ́ lè fọkàn sí pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fagbára mú wọn hu ìwà ìkà?
12 Ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa fi inú rere hàn sí àwọn olùkọ́ wọn pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń fẹ́ mú àwọn olùkọ́ wọn bínú. Wọ́n máa ń ka ara wọn sí ẹni tó gbọ́n féfé nígbà tí wọn ò bá bọ̀wọ̀ fún àwọn olùkọ́ wọn tí wọ́n sì ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò kan tó lòdì sí òfin ilé ìwé. Wọ́n lè kó jìnnìjìnnì bá àwọn mìíràn káwọn yẹn lè dara pọ̀ mọ́ wọn. Nígbà tí Kristẹni ọ̀dọ́ kan bá kọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ wọn, ó lè wá dẹni tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i fi ṣẹ̀sín tí wọ́n á sì máa bú. Kíkojú irú ipò bẹ́ẹ̀ nígbà téèyàn wà nílé ìwé lè nípa lórí bó ṣe yẹ kí Kristẹni kan fi inú rere hàn. Àmọ́ ṣá o, máa rántí pé ó ṣe pàtàkì gan-an láti jẹ́ adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà. Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tì ọ́ lẹ́yìn ní àkókò tí nǹkan le koko fún ọ yìí.—Sáàmù 37:28.
Fífi Inú Rere Hàn sí Àwọn Aládùúgbò Wa
13-15. Kí ló lè mú ká máà fẹ́ fi inú rere hàn sí àwọn aládùúgbò ẹni, báwo la sì ṣe lè borí ìṣòro yìí?
13 Yálà inú ilé ńlá kan lò ń gbé, ì báà jẹ́ ilé fúláàtì ni, bóyá inú ọkọ̀ àfiṣelé sì ni tàbí ibòmíràn, o lè ronú àwọn ọ̀nà tó o lè gbà fi inú rere hàn sí àwọn aládùúgbò rẹ kó o sì jẹ́ kí ire wọn jẹ ọ́ lọ́kàn. Èyí pẹ̀lú kì í sábà rọrùn.
14 Nígbà tí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbé ilé kan náà tàbí àwọn tó múlé gbè ọ́ bá ní ẹ̀tanú sí ọ nítorí ẹ̀yà rẹ, orílẹ̀-èdè tó o ti wá tàbí nítorí ìsìn rẹ ńkọ́? Tí wọ́n ò bá bọ̀wọ̀ fún ọ nígbà mìíràn ńkọ́ tàbí tí wọn ò tiẹ̀ dá sí ọ rárá? Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, fífi inú rere hàn débi tó o ba lè fi hàn dé yóò ṣàǹfààní. Wàá yàtọ̀ pátápátá sí àwọn yòókù, ìyẹn á sì jẹ́ fún ìyìn Jèhófà, ẹni tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú fífi inú rere hàn. O ò lè mọ ìgbà tí aládùúgbò rẹ̀ náà yóò yí ìwà rẹ̀ padà nítorí inú rere tó ò ń fi hàn sí i. Ó tiẹ̀ lè wá di olùyin Jèhófà pàápàá.—1 Pétérù 2:12.
15 Báwo la ṣe lè máa fi inú rere hàn sí aládùúgbò wa? Lọ́nà kan, nípa jíjẹ́ kí ìwà wa dára láàárín ìdílé bí gbogbo wa ṣe ń fi èso tẹ̀mí hàn. Àwọn aládùúgbò wa sì lè máa kíyè sí èyí. Nígbà mìíràn, o lè wà nípò láti ṣoore fún àwọn aládùúgbò rẹ. Rántí pé inú rere túmọ̀ sí jíjẹ́ kí ire àwọn ẹlòmíràn máa jẹ wá lógún.—1 Pétérù 3:8-12.
Fífi Inú Rere Hàn Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
16, 17. (a) Kí nìdí tí inú rere fi ṣe pàtàkì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá à ń ṣe? (b) Báwo la ṣe lè fi inú rere hàn nínú onírúurú ọ̀nà tá a gbà ń wàásù?
16 Inú rere gbọ́dọ̀ hàn kedere nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn nínú ilé wọn, níbi iṣẹ́ wọn, àti láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí. Ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà là ń ṣojú fún, ẹni tó jẹ́ onínúure nígbà gbogbo.—Ẹ́kísódù 34:6.
17 Kí làwọn nǹkan mìíràn tó yẹ kó o mọ̀ bó o ṣe ń sapá láti fi inú rere hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó o bá ń wàásù lójú pópó, o lè fi inú rere hàn nípa jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ṣókí kó o sì máa fi ẹ̀mí ìgbatẹnirò hàn nígbà tó o bá lọ bá àwọn èèyàn. Ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ sábà máa ń kún fún àwọn èrò, nítorí náà ṣọ́ra kí o má bàa dí ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà kọjá. Bákan náà, nígbà tó o bá ń wàásù ní àgbègbè tí ilé ìtajà pọ̀ sí, fi inú rere hàn nípa jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ṣókí, kó o rántí pé àwọn tó ń tajà máa dá àwọn oníbàárà wọn lóhùn.
18. Ipa wo ni ìfòyemọ̀ ń kó nínú fífi inú rere hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
18 Lo ọgbọ́n nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Má ṣe pẹ́ jù nílé ibi tó o ti ń wàásù, àgàgà tí ojú ọjọ́ kò bá dára. Ǹjẹ́ o lè mọ ìgbà tí ara ẹnì kan ò balẹ̀ mọ́ tàbí tí wíwà tó o wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tiẹ̀ ń bí i nínú? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé apá ibi táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń lọ sílé àwọn èèyàn déédéé lò ń gbé. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rí i pé o ń gba tiwọn rò gan-an, kó o máa jẹ́ onínúure àti ẹni tó ń kóni mọ́ra. (Òwe 17:14) Gbìyànjú láti rí ohun tí onílé sọ pé ó fà á tóun ó fi fẹ́ gbọ́rọ̀ lọ́jọ́ yẹn gẹ́gẹ́ bí ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Rántí pé ọ̀kan lára àwọn Kristẹni arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ tún lè wá wàásù nílé yẹn lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá pàdé ẹnì kan tí kò mọ bá a ṣe ń bọ̀wọ̀ fúnni, sá gbogbo ipá rẹ láti fi inú rere hàn sí i. Má ṣe jágbe mọ́ ọn tàbí kó o fajú ro, àmọ́ ńṣe ni kó o fohùn pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Kristẹni tó jẹ́ onínúure kò ní fẹ́ múnú bí onílé débi tí wọ́n á ti máa ṣàríyànjiyàn. (Mátíù 10:11-14) Ó ṣeé ṣe kí onítọ̀hún fetí sí ìhìn rere náà nígbà mìíràn.
Fífi Inú Rere Hàn Láwọn Ìpàdé Ìjọ
19, 20. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi inú rere hàn nínú ìjọ, báwo la sì ṣe lè ṣe é?
19 Ó tún ṣe pàtàkì láti fi inú rere hàn sí àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Hébérù 13:1) Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ara ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé, inú rere tún ṣe pàtàkì nínú bá a ṣe ń bá ara wa lò.
20 Tí ẹ̀yin tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà bá tó ìjọ méjì tàbí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ṣe pàtàkì láti fi inú rere hàn sí àwọn tó wà nínú àwọn ìjọ yòókù, kó o máa bá wọn lò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ẹ̀mí ìbánidíje máa ń jẹ́ kó ṣòro láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dórí ṣíṣètò àwọn àkókò ìpàdé àti àwọn nǹkan mìíràn bí ìmọ́tótó tàbí títún àwọn ibi tó bá bà jẹ́ ṣe. Jẹ́ onínúure kó o sì gba ti àwọn ẹlòmíràn rò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò yín lè máà bára mu nígbà mìíràn. Nípa ṣíṣe èyí, inú rere yóò gbilẹ̀, Jèhófà yóò sì bù kún ìfẹ́ tó o ní sí ire àwọn ẹlòmíràn.
Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Fífi Inú Rere Hàn
21, 22. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Kólósè 3:12, kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
21 Inú rere jẹ́ ànímọ́ kan tó gbòòrò gan-an débì pé ó kan gbogbo apá ìgbésí ayé wa. Nítorí náà, ó yẹ ká fi ṣe apá pàtàkì lára àwọn àkópọ̀ ìwà wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. A sì ní láti sọ fífi inú rere hàn sí àwọn ẹlòmíràn dàṣà.
22 Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa fi inú rere hàn sáwọn èèyàn lójoojúmọ́ ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sílò, èyí tó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:12.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ló máa ń jẹ́ kó ṣòro fún Kristẹni láti fi inú rere hàn?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa fi inú rere hàn nínú ìdílé ẹni?
• Kí ló máa ń mú kó ṣòro láti fi inú rere hàn nílé ìwé, níbi iṣẹ́ àti láàárín àwọn aládùúgbò ẹni?
• Ṣàlàyé ọ̀nà táwọn Kristẹni lè gbà fi inú rere hàn nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Inú rere tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé bá fi hàn máa ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
O lè fi inú rere hàn nígbà tí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ kan bá ń ṣàìsàn tàbí ti ara àwọn kan nínú ìdílé rẹ̀ kò bá yá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Jèhófà máa ń dúró ti àwọn tó ń fi inú rere hàn láìfi ìfiniṣẹ̀sín pè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ṣíṣe ìrànwọ́ fún aládùúgbò wa kan jẹ́ ọ̀nà tá a lè gbà fi inú rere hàn