Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ Mẹ́síkò Ń Gbọ́ Ìhìn Rere Náà
NÍ November 10, 2002, àwùjọ kan tó ń sọ èdè Mixe, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Mẹ́síkò, pé jọ sílùú San Miguel, Quetzaltepec. Ìlú yìí wà ní gúúsù ìpínlẹ̀ ẹlẹ́wà tó ń jẹ́ Oaxaca. Àpéjọ àgbègbè ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwùjọ náà ń ṣe lọ́wọ́. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ apá pàtàkì kan lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ ọjọ́ náà.
Nígbà tí àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ inú àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà dún jáde látinú ẹ̀rọ gbohùngbohùn, ńṣe ló dà bíi nǹkan àrà lójú àwùjọ náà. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́ nìyẹn, tí ọ̀pọ̀ lára wọn sì ń da omi lójú. Èdè Mixe ni wọ́n fi ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà! Nígbà tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà parí, ọ̀pọ̀ ló fi hàn pé àwọn mọrírì ìbùkún tí wọn ò retí yìí. Ọ̀kan lára wọn sọ pé, “èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ yé mi dáadáa. Ó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni.” Òmíràn lára wọn sọ pé, “Bí n bá tiẹ̀ kú báyìí, ó ti tẹ́ mi lọ́rùn nítorí pé Jèhófà ti jẹ́ kí n gbọ́ àwòkẹ́kọ̀ọ́ lédè mi.”
Àwòkẹ́kọ̀ọ́ tá a ṣe ní èdè Mixe láàárọ̀ ọjọ́ yẹn wà lára akitiyan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ń ṣe lójú méjèèjì lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti mú káwọn ọmọ ìbílẹ̀ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.
Jèhófà Gbọ́ Àdúrà Wọn
Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Mẹ́síkò tó ń gbé lórílẹ̀-èdè náà lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà, iye yìí sì pọ̀ tó orílẹ̀-èdè kan lọ́tọ̀, ó ní onírúurú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, èdè méjìlélọ́gọ́ta ni wọ́n sì ń sọ níbẹ̀. Èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára wọn ni iye àwọn tó ń sọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] èèyàn. Ó lé ní àádọ́ta ọ̀kẹ́ [1,000,000] lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà tí kò gbọ́ èdè Spanish, tó jẹ́ èdè àjùmọ̀lò ní Mẹ́síkò. Àti pé lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tó gbédè Spanish pàápàá, èdè wọn ló rọ̀ wọ́n lọ́rùn jù láti fi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì. (Ìṣe 2:6; 22:2) Ó ti pẹ́ táwọn kan nínú wọn ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ti ń wá sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, síbẹ̀ òye wọn ò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Abájọ tí wọ́n fi ń gbàdúrà látọjọ́ yìí pé kí ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà wà ní èdè àbínibí wọn.
Kí ìṣòro yìí lè yanjú, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bẹ lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò bẹ̀rẹ̀ ètò kan lọ́dún 1999, ìyẹn láti máa ṣe ìpàdé làwọn èdè ìbílẹ̀. Wọ́n tún ṣètò àwọn ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè. Nígbà tó fi máa di ọdún 2000, wọ́n ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa ń ṣe nígbà àpéjọ àgbègbè ní èdè Maya, nígbà tó sì yá, wọ́n ṣe é láwọn èdè mìíràn kan.
Ohun tí ọpọ́n wá sún kàn ni títúmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n túmọ̀ ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! sí èdè Huave, Maya, Mazatec, Totonac, Tzeltal, àti Tzotzil. Wọ́n tún wá túmọ̀ àwọn ìwé mìíràn, títí kan Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tí yóò máa jáde déédéé ní èdè Maya. Wọ́n tún ka àwọn ìwé kan sínú kásẹ́ẹ̀tì àfetígbọ́. Wọ́n ṣe àtúnṣe tó bá èdè wọn mu sí ìwé tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Apply Yourself to Reading and Writing kí wọ́n lè máa lò ó láti kọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà kí wọ́n bàa mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà ní èdè wọn. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọ́n ń tẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde ní èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára àwọn èdè àbínibí náà, wọ́n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni.
“Sísapá Lójú Méjèèjì”
Iṣẹ́ ìtumọ̀ náà ò rọrùn rárá. Ìdí kan ni pé, ìwé táwọn èèyàn ṣe jáde ní èdè ìbílẹ̀ Mẹ́síkò kò tó nǹkan. Lọ́pọ̀ ìgbà, agbára káká ni wọ́n fi ń rí ìwé atúmọ̀ èdè. Àti pé àwọn kan lára àwọn èdè náà tún pín sí ọ̀pọ̀ èdè àdúgbò. Bí àpẹẹrẹ, ó kéré tán, èdè àdúgbò márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà nínú èdè Zapotec nìkan ṣoṣo. Àwọn èdè ọ̀hún sì yàtọ̀ síra débi pé àwọn ọmọ Zapotec tí wọ́n wá láti àdúgbò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kì í gbọ́ èdè ara wọn.
Yàtọ̀ síyẹn, tí kò bá sí ìlànà kan pàtó fún èdè kan, ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè ní láti wá bí wọ́n ṣe máa gbé àwọn ìlànà kan kalẹ̀ fúnra wọn. Èyí sì gba pé kí wọ́n ṣe ìwádìí káàkiri. Abájọ tó fi kọ́kọ́ ṣe ọ̀pọ̀ lára wọn bó ṣe ṣe Élida, ọmọbìnrin kan tó wà nínú ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè Huave! Élida rántí bí òun ṣe ṣe, ó ní: “Nígbà tí wọ́n pè mí pé kí n wá ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò, bákan méjì ló ṣe rí lára mi—inú mi dùn, bẹ́ẹ̀ lẹ̀rù sì tún ń bà mi.”
Àwọn atúmọ̀ èdè wọ̀nyí kọ́kọ́ kọ́ bá a ṣe ń lo kọ̀ǹpútà, bá a ṣe ń ṣètò iṣẹ́, wọ́n sì tún kọ́ gbogbo àpadé-àludé iṣẹ́ ìtumọ̀. Ká sòótọ́, iṣẹ́ náà ò rọrùn fún wọn. Àmọ́, báwo niṣẹ́ náà ṣe rí lára wọn? Gloria tó jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè Maya sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé a wà lára àwọn tó ń túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Maya, tó jẹ́ èdè àbínibí wa.” Alábòójútó kan ní Ẹ̀ka Ìtumọ̀ Èdè náà sọ ohun tó kíyè sí lára àwọn atúmọ̀ èdè wọ̀nyẹn, ó ní: “Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí títúmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè wọn pọ̀ gan-an débi pé wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè borí ìṣòro náà.” Ǹjẹ́ ìsapá wọn yọrí sí rere?
“Jèhófà, Mo Mà Dúpẹ́ O!”
Ó hàn kedere pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ tá à ń ṣe fún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà. Àwọn tó ń wá sáwọn ìpàdé Kristẹni àtàwọn àpéjọ túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 2001, igba ó lé mẹ́tàlélógún [223] Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sọ èdè Mixe pé jọ fún ayẹyẹ Ìrántí Ikú Kristi. Àmọ́, àròpọ̀ iye àwọn tó péjú pésẹ̀ síbi ayẹyẹ náà jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán dín mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [1,674]. Iye yìí fi ìlọ́po méje àtààbọ̀ ju iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbi ayẹyẹ náà lọ!
Àwọn kan lára àwọn tó tẹ́wọ́ gba òtítọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lóye rẹ̀ dáadáa látìbẹ̀rẹ̀ ni. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Mirna rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ṣáájú ká a tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣèpàdé lédè Maya. Ó ní: “Mo ṣèrìbọmi lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo mọ̀ pé ó yẹ kí n ṣèrìbọmi àmọ́, kí n sòótọ́, mi ò lóye àwọn òtítọ́ Bíbélì tó bó ṣe yẹ kí n lóye rẹ̀. Ohun tí mo rò pé ó fà á ni pé, Maya ni èdè àbínibí mi, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Spanish. Ó pẹ́ díẹ̀ kí n tó wá lóye òtítọ́ dáadáa.” Lónìí, ayọ̀ ńlá ló jẹ́ fóun àti ọkọ rẹ̀ pé wọ́n wà lára ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè Maya.
Inú gbogbo àwọn ara ìjọ dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ gbà lédè wọn. Nígbà tá a kó ìwé pẹlẹbẹ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí èdè Tzotzil wá fáwọn ará, ìyẹn ìwé Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, ńṣe ni obìnrin kan tó máa ń wá sáwọn ìpàdé Kristẹni fayọ̀ gbá ìwé náà mọ́ra, ó wá sọ pé: “Jèhófà, mo mà dúpẹ́ o!” Ìròyìn fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló tètè ń tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe ìrìbọmi, àwọn akéde tí kì í wàásù déédéé tẹ́lẹ̀ dẹni tó ń wàásù déédéé, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ló sì wá rí i pé àwọn tóótun láti tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti wá ń gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà lédè wọn, wọ́n sì ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀.
Àpẹẹrẹ kan ni tí obìnrin Ẹlẹ́rìí kan tó fẹ́ lọ bá obìnrin kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà ò sí nílé. Nígbà tí ọkọ obìnrin náà wá sẹ́nu ọ̀nà, obìnrin Ẹlẹ́rìí yìí sọ fún ọkùnrin náà pé òun fẹ́ ka ibì kan fún un látinú ìwé pẹlẹbẹ ọwọ́ òun. Ọkùnrin náà fèsì pé, “Mi ò fẹ́ gbọ́ nǹkan kan.” Arábìnrin náà fi èdè Totonac sọ fún ọkùnrin náà pé èdè rẹ̀ ni wọ́n fi kọ ìwé pẹlẹbẹ náà. Bí ọkùnrin náà ṣe gbọ́ pé èdè òun ní wọ́n fi kọ̀wé náà, kíá ló fa bẹ́ǹṣì kan jáde tó sì jókòó. Bí arábìnrin náà ṣe ń kà á sí i létí, ńṣe lọ́kùnrin náà sáà ń sọ pé “Òótọ́ ni. Àní, òótọ́ ni.” Ọkùnrin náà ti ń wá sáwọn ìpàdé Kristẹni báyìí.
Ní ìpínlẹ̀ Yucatán, ọkọ obìnrin Ẹlẹ́rìí kan ò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ rárá, kódà, ó máa ń lu obìnrin yìí nígbà míì tó bá dé láti ìpàdé. Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìpàdé ní èdè Maya, obìnrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé kí wọ́n jọ lọ sípàdé. Ọkùnrin náà wá sípàdé, ó sì gbádùn rẹ̀ gan-an. Ọkùnrin náà ti ń lọ sáwọn ìpàdé déédéé báyìí, ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ, kò lu ìyàwó ẹ̀ mọ́.
Ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Totonac sọ fáwọn Ẹlẹ́rìí méjì pé òun ò tíì gbàdúrà rí láyé òun nítorí pé àlùfáà Kátólíìkì sọ fóun pé àdúrà téèyàn bá fi èdè Spanish gbà nìkan ni Ọlọ́run máa ń gbọ́. Àní, ó tiẹ̀ sanwó fún àlùfáà náà pé kó bá òun gbàdúrà fún àwọn Totonac. Àwọn Ẹlẹ́rìí yìí ṣàlàyé fún ọkùnrin náà pé kò sí èdè tẹ́nì kan fi gbàdúrà tí Ọlọ́run ò gbọ́, wọ́n wá fún un ní ìwé pẹlẹbẹ kan tó wà ní èdè Totonac, inú ọkùnrin náà sì dùn láti gbàwé náà.—2 Kíróníkà 6:32, 33; Sáàmù 65:2.
“Kualtsin Tajtoua”
Nítorí pé inú àwọn akéde Ìjọba dùn sí ìtẹ̀síwájú yìí, ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń sapá láti kọ́ èdè ìbílẹ̀ kan tàbí kí wọ́n túbọ̀ fi kún ìmọ̀ wọn nípa èyí tí wọ́n ti gbọ́ tẹ́lẹ̀. Ohun tí alábòójútó àyíká kan tó ń ṣèbẹ̀wò sí ìjọ márùn-ún tí wọ́n ti ń sọ èdè Nahuatl ní àríwá Puebla ń ṣe nìyẹn. Alábòójútó àyíká náà sọ pé: “Ńṣe làwọn ọmọdé tí wọ́n máa ń sùn nípàdé tẹ́lẹ̀ máa ń wà lójúfò tí wọ́n sì máa ń tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí mo bá ń fi èdè Nahuatl sọ àsọyé. Nígbà tá a parí ìpàdé lọ́jọ́ kan, ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́rin kan tọ̀ mí wá, ó sì sọ pé: ‘Kualtsin tajtoua’ (ọ̀rọ̀ yin dáa gan-an ni). Ọ̀rọ̀ tọ́mọ yìí sọ mú kí n gbà pé akitiyan mi ò já sásán.”
Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tó ń sọ èdè àbínibí yìí ti dà bí ohun ọ̀gbìn tó “ti funfun fún kíkórè” lóòótọ́, gbogbo àwọn tó sì ń ṣíṣẹ ìkórè náà ni iṣẹ́ ọ̀hún máa ń wú lórí. (Jòhánù 4:35) Roberto, tó ṣètò àwọn ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè ṣe àkótán ọ̀rọ̀ náà pé: “Ó jẹ́ ohun mánigbàgbé kan láti rí omijé ayọ̀ tó ń dà lójú àwọn arákùnrin àti arábìnrin bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà ní èdè wọn, tó sì ń yé wọn yékéyéké. Nígbàkigbà tí mo bá ń ronú kàn án, ńṣe lórí mi máa ń wú.” Láìsí àní-àní, ríran àwọn olóòótọ́ ọkàn wọ̀nyí lọ́wọ́ láti ti Ìjọba náà lẹ́yìn ń múnú Jèhófà dùn.—Òwe 27:11.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Látẹnu Díẹ̀ Lára Àwọn Atúmọ̀ Èdè Náà
● “Láti kékeré làwọn òbí mi ti fi òtítọ́ kọ́ mi. Ó báni nínú jẹ́ pé, nígbà tí mó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá, bàbá mi fi ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Ọdún méjì lẹ́yìn ìgbà yẹn, màmá mi pa gbogbo wá tì ó sì bá tiẹ̀ lọ. Àmọ́, nítorí pé èmi làgbà nínú àwa ọmọ márùn-ún, èmi ni mo wá ń ṣe ojúṣe màmá mi bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì jáde iléèwé.
“Àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí ò fi wá sílẹ̀, wọ́n ṣe bẹbẹ fún wa, àmọ́ nǹkan ò rọrùn. Nígbà míì, màá bi ara mi pé: ‘Kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí mi? Ọmọdé mà ni mí!’ Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà tó ràn mí lọ́wọ́ ni mo fi kojú ipò yẹn. Nígbà tí mo jáde iléèwé girama, mo di òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, èyí sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Nígbà tí wọ́n ṣètò ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè Nahuatl, wọ́n pè mi láti jẹ́ ọ̀kan lára wọn.
“Bàbá mi ti padà sínú ìjọ báyìí, àwọn àbúrò mi ọkùnrin àti obìnrin náà ń sin Jèhófà. Kò sóhun tó dáa tó kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Jèhófà sì ti bù kún ìdílé wa lọ́pọ̀lọpọ̀.”—Alicia.
● “Ọmọ kíláàsì mi kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí sọ àsọyé kan tó dá lórí bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀. Nítorí pé mi ò sí ní kíláàsì lọ́jọ́ náà, mo wá ń ṣàníyàn pé tí ìbéèrè bá jáde lórí kókó yìí nígbà ìdánwò, mi ò ní lè dáhùn, ni mo bá ní kọ́mọ náà ṣàlàyé rẹ̀ fún mi. Ó ti pẹ́ ti mo ti máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí téèyàn fi ń kú. Nígbà tí ọmọbìnrin náà fi ìwé Creationa lọ̀ mi, tó sì lóun yóò fẹ́ láti máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo gbà. Àwọn ohun tí Ẹlẹ́dàá fẹ́ ṣe àti ìfẹ́ tó ní sí wa wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni.
“Nígbà tí mo jáde iléèwé, mo láǹfààní àtidi olùkọ́ èdè méjì, ìyẹn èdè Spanish àti Tzotizil. Àmọ́, ìyẹn á gba pé kí n ṣí lọ síbi tó jìnnà, kí n máa kọ́ àwọn ọmọ iléèwé ní òpin ọ̀sẹ̀, èyí á sì mú kí n máa pa ìpàdé Kristẹni jẹ. Dípò tí máa fi ṣèyẹn, mo wá ń ṣiṣẹ́ bíríkìlà. Inú bàbá mi, tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, kò dùn sí ìpinnu mi yìí rárá. Nígbà tó yá, bí mo ṣe ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, wọ́n ṣètò ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè tí yóò máa túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Tzotzil. Inú mi dùn láti kópa nínú iṣẹ́ náà.
“Mo wá rí i pé títẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde ní èdè àbínibí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ń mú kí wọ́n rí i pé a ka àwọn sí, a ò sì fọ̀rọ̀ àwọn ṣeré. Irú nǹkan báyìí máa ń múnú èèyàn dùn gan-an ni. Àǹfààní ńlá ni mo ka iṣẹ́ ọ̀hún sí.”—Humberto.
● “Ọmọ ọdún mẹ́fà ni mo wà nígbà tí màmá mi fi wá sílẹ̀ lọ. Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń di ọ̀dọ́ ni bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́jọ́ kan báyìí, arábìnrin kan fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ mí, ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yóò sì jẹ́ kí n rí àmọ̀ràn tó wà fáwọn ọ̀dọ́. Nítorí pé ọ̀dọ́langba tí kò ní ìyá ni mí, mó gbà pé ohun tí mo nílò gan-an nìyẹn. Mo ṣèrìbọmi nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún
“Ní ọdún 1999, àwọn ẹni ibi tí ojú wọn wọ ilẹ̀ bàbá mi gbẹ̀mí ẹ̀. Èyí mọ́kàn mi gbọgbẹ́. Ìbànújẹ́ wá dórí mi kodò, ilé ayé sì sú mi. Àmọ́, mi ò yéé gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi ní okun. Alábòójútó àyíká àti ìyàwó rẹ̀ fún mi níṣìírí gan-an. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo di aṣáájú ọ̀nà déédéé.
“Lọ́jọ́ kan, mo kíyè sí àwọn kan tó fẹsẹ̀ rin ìrìn wákàtí mẹ́fà láti wa gbọ́ àsọyé ogún ìṣẹ́jú ní èdè Totonac, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Spanish ni wọ́n fi sọ gbogbo apá yòókù nínú ìpàdé náà, kò sì yé wọn. Ìdí rèé tínú mi fi dùn gan-an nígbà tí wọ́n ní kí n wá ṣèrànwọ́ láti máa túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Totonac.
“Mo sábà máa ń sọ fún bàbá mi pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí màá máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bàbá mi sọ fún mi pé kò ní rọrùn fún irú èmi tí ò tíì lọ́kọ láti sìn níbẹ̀. Áà, inú bàbá mi á mà dùn o nígbà tó bá jíǹde tó sì rí i pé ó ṣeé ṣe fún mi láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì, tí mo sì tún ń túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè wa!”—Edith.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde lọ́dún 1985.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ atúmọ̀ èdè Tzotzil rèé níbi tí wọ́n ti ń ṣe atótónu lórí ọ̀rọ̀ kan tó ṣòro túmọ̀